Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

ÀPILẸ̀KỌ FÚN ÌKẸ́KỌ̀Ọ́ 44

Ní Àjọṣe Tó Dáa Pẹ̀lú Àwọn Ará Kí Òpin Tó Dé

Ní Àjọṣe Tó Dáa Pẹ̀lú Àwọn Ará Kí Òpin Tó Dé

“Ọ̀rẹ́ tòótọ́ máa ń nífẹ̀ẹ́ ẹni nígbà gbogbo.”​—ÒWE 17:17.

ORIN 101 À Ń Ṣiṣẹ́ Níṣọ̀kan

OHUN TÁ A MÁA JÍRÒRÒ *

A máa nílò àwọn ọ̀rẹ́ tòótọ́ nígbà “ìpọ́njú ńlá” (Wo ìpínrọ̀ 2) *

1-2. Bó ṣe wà nínú 1 Pétérù 4:7, 8, kí ló máa ràn wá lọ́wọ́ láti fara da ìṣòro?

BÁ A ṣe túbọ̀ ń wọnú “àwọn ọjọ́ ìkẹyìn” yìí, ṣe ni ìṣòro ń peléke sí i. (2 Tím. 3:1) Bí àpẹẹrẹ, lẹ́yìn ètò ìdìbò tó wáyé ní orílẹ̀-èdè kan ní apá ìwọ̀ oòrùn Áfíríkà, rògbòdìyàn bẹ́ sílẹ̀, gbogbo nǹkan sì dojú rú. Ohun tó lé lóṣù mẹ́fà làwọn ará wa ò fi lè rìn kiri bó ṣe wù wọ́n torí pé wàhálà yẹn pọ̀ gan-an. Kí ló ràn wọ́n lọ́wọ́ láti fara da ìṣòro yẹn? Ṣe làwọn kan sá lọ sílé àwọn ará tó wà ní àdúgbò tí nǹkan ti dẹrùn díẹ̀. Arákùnrin kan tiẹ̀ sọ pé: “Inú mi dùn gan-an pé mo wà pẹ̀lú àwọn ọ̀rẹ́ mi nígbà ìṣòro yẹn. Ṣe ni gbogbo wa ń fún ara wa níṣìírí.”

2 Nígbà tí “ìpọ́njú ńlá” bá dé, inú wa máa dùn gan-an tá a bá ní àwọn ọ̀rẹ́ gidi tó nífẹ̀ẹ́ wa. (Ìfi. 7:14) Torí náà, ó ṣe pàtàkì pé ká tètè mú kí okùn ọ̀rẹ́ wa pẹ̀lú àwọn ará túbọ̀ le gan-an nísinsìnyí. (Ka 1 Pétérù 4:7, 8.) Ọ̀pọ̀ ẹ̀kọ́ la lè rí kọ́ lára Jeremáyà torí pé àwọn ọ̀rẹ́ rẹ̀ ràn án lọ́wọ́ ní gbogbo àsìkò tó ṣáájú ìparun Jerúsálẹ́mù. * Báwo la ṣe lè tẹ̀ lé àpẹẹrẹ Jeremáyà?

KẸ́KỌ̀Ọ́ LÁRA JEREMÁYÀ

3. (a) Kí ló lè mú kí Jeremáyà máa yara ẹ̀ sọ́tọ̀? (b) Kí ni Jeremáyà sọ fún Bárúkù akọ̀wé rẹ̀, kí nìyẹn sì yọrí sí?

3 Nǹkan bí ogójì (40) ọdún ni Jeremáyà fi gbé láàárín àwọn tó jẹ́ aláìṣòótọ́, àwọn ará àdúgbò rẹ̀ wà lára wọn, ó tún ṣeé ṣe káwọn mọ̀lẹ́bí rẹ̀ kan ní Ánátótì ìlú ìbílẹ̀ rẹ̀ náà wà lára àwọn aláìṣòótọ́ yìí. (Jer. 11:21; 12:6) Àmọ́ kò torí ìyẹn yara ẹ̀ sọ́tọ̀. Kódà, ó sọ bí nǹkan ṣe rí lára rẹ̀ fún Bárúkù akọ̀wé rẹ̀ tó dúró tì í, gbogbo ẹ̀ sì wà lákọọ́lẹ̀ fún wa lónìí. (Jer. 8:21; 9:1; 20:14-18; 45:1) Kò sí àní-àní pé bí Bárúkù ṣe ń kọ gbogbo ọ̀rọ̀ tí Jeremáyà ń sọ fún un sílẹ̀, ṣe làwọn méjèèjì á túbọ̀ sún mọ́ra pẹ́kípẹ́kí, wọ́n á sì mọyì ara wọn.​—Jer. 20:1, 2; 26:7-11.

4. Kí ni Jèhófà sọ pé kí Jeremáyà ṣe, báwo sì ni iṣẹ́ yẹn ṣe mú kí Jeremáyà àti Bárúkù túbọ̀ sún mọ́ra?

4 Ọ̀pọ̀ ọdún ni Jeremáyà fi kìlọ̀ fáwọn ọmọ Ísírẹ́lì tìgboyàtìgboyà nípa nǹkan tó máa ṣẹlẹ̀ sí ìlú Jerúsálẹ́mù. (Jer. 25:3) Àmọ́ torí Jèhófà fẹ́ káwọn ọmọ Ísírẹ́lì yí pa dà, ó tún kìlọ̀ fún wọn, ó sì sọ fún Jeremáyà pé kó ṣàkọsílẹ̀ ìkìlọ̀ náà sínú àkájọ ìwé kan. (Jer. 36:1-4) Ó ṣeé ṣe kí iṣẹ́ tí Jèhófà gbé fún Jeremáyà àti Bárúkù gbà wọ́n ní ọ̀pọ̀ oṣù, bí wọ́n ṣe jọ ń ṣiṣẹ́ yẹn, ó dájú pé àwọn méjèèjì á jọ máa sọ àwọn ọ̀rọ̀ tó gbé ìgbàgbọ́ wọn ró.

5. Báwo la ṣe mọ̀ pé ọ̀rẹ́ tòótọ́ ni Bárúkù jẹ́ sí Jeremáyà?

5 Nígbà tí àsìkò tó láti ka ohun tó wà nínú àkájọ ìwé náà fáwọn ọmọ Ísírẹ́lì, Bárúkù ni Jeremáyà ní kó lọ jíṣẹ́ náà. (Jer. 36:5, 6) Bárúkù fi ìgboyà jíṣẹ́ yìí bó tilẹ̀ jẹ́ pé iṣẹ́ náà le gan-an. Ṣé ẹ lè fojú inú wo bí inú Jeremáyà ṣe máa dùn tó nígbà tí Bárúkù lọ sínú àgbàlá tẹ́ńpìlì tó sì jíṣẹ́ náà? (Jer. 36:8-10) Nígbà tí àwọn ìjòyè Júdà gbọ́ ohun tí Bárúkù ṣe, wọ́n pàṣẹ pé kó wá ka àkájọ ìwé náà sáwọn létí. (Jer. 36:14, 15) Wọ́n wá sọ fún un pé àwọn máa sọ fún Ọba Jèhóákímù, àmọ́ wọ́n káàánú òun àti Jeremáyà, wọ́n sì sọ fún un pé: “Lọ fara pa mọ́, ìwọ àti Jeremáyà, ẹ má sì jẹ́ kí ẹnì kankan mọ ibi tí ẹ wà.” (Jer. 36:16-19) Ìmọ̀ràn yẹn mà dáa o!

6. Kí ni Jeremáyà àti Bárúkù ṣe nígbà tí wọ́n kojú inúnibíni?

6 Inú bí Ọba Jèhóákímù gan-an nígbà tó gbọ́ gbogbo ọ̀rọ̀ tí Jeremáyà kọ sílẹ̀, débi pé ó ju àkájọ ìwé náà sínú iná, ó sì pàṣẹ pé kí wọ́n lọ mú Jeremáyà àti Bárúkù. Àmọ́ dípò kẹ́rù ba Jeremáyà, ṣe ló mú àkájọ ìwé míì, ó fún Bárúkù, ó sì sọ àwọn ọ̀rọ̀ Jèhófà fún un. Bíbélì jẹ́ ká mọ̀ pé Bárúkù tún “kọ gbogbo ọ̀rọ̀ inú àkájọ ìwé tí Jèhóákímù ọba Júdà sun nínú iná.”​—Jer. 36:26-28, 32.

7. Báwo ló ṣeé ṣe kí àárín Jeremáyà àti Bárúkù rí bí wọ́n ṣe jọ ń ṣiṣẹ́?

7 Àwọn tó bá kojú ìṣòro kan náà lásìkò kan náà sábà máa ń sún mọ́ra. Torí náà a lè gbà pé bí Jeremáyà àti Bárúkù ṣe jọ ń ṣiṣẹ́ láti tún ìwé náà kọ, ìyẹn àkájọ ìwé tí Ọba Jèhóákímù sun nínú iná, ó dájú pé àwọn méjèèjì máa túbọ̀ mọyì àwọn ànímọ́ tí wọ́n ní. Kí la wá rí kọ́?

MÁA SỌ OHUN TÓ WÀ LỌ́KÀN RẸ

8. Kí ló lè mú kó ṣòro fún wa láti láwọn ọ̀rẹ́ tó máa nífẹ̀ẹ́ wa dénú, kí sì nìdí tí kò fi yẹ kó sú wa?

8 Ó lè ṣòro fún wa láti sọ tinú wa fún àwọn ẹlòmíì bóyá torí pé ẹnì kan ti ṣe ohun tó dùn wá nígbà kan rí. (Òwe 18:19, 24) Ó sì lè máa ṣe wá bíi pé a ò ráyè, a ò sì lè ṣe wàhálà àtimáa wá àwọn ọ̀rẹ́ kan kiri. Tó bá rí bẹ́ẹ̀, ẹ má jẹ́ kó sú wa. Tá a bá fẹ́ káwọn ará wa dúró tì wá nígbà ìṣòro, ìsinsìnyí gan-an ló yẹ ká kọ́ bá a ṣe lè máa sọ tinú wa fún wọn. Tá a bá ń ṣe bẹ́ẹ̀, okùn ọ̀rẹ́ wa á túbọ̀ le sí i.​—1 Pét. 1:22.

9. (a) Báwo ni Jésù ṣe fi hàn pé òun fọkàn tán àwọn ọ̀rẹ́ òun? (b) Báwo ni ìjùmọ̀sọ̀rọ̀pọ̀ ṣe lè ràn ẹ́ lọ́wọ́ láti túbọ̀ ní àwọn ọ̀rẹ́ tí wàá nífẹ̀ẹ́? Sọ àpẹẹrẹ kan.

9 Jésù máa ń báwọn ọ̀rẹ́ rẹ̀ sọ gbogbo nǹkan tó wà lọ́kàn rẹ̀, ìyẹn sì fi hàn pé ó fọkàn tán wọn. (Jòh. 15:15) Àwa náà lè fara wé Jésù tá a bá ń sọ àwọn nǹkan tó ń múnú wa dùn àtàwọn nǹkan tó ń bà wá nínú jẹ́ fáwọn míì. Tẹ́nì kan bá ń bá ẹ sọ̀rọ̀, fara balẹ̀ tẹ́tí sí i, tó o bá ṣe bẹ́ẹ̀, wàá rí i pé ọ̀pọ̀ nǹkan lẹ fi jọra. Ẹ jẹ́ ká wo àpẹẹrẹ arábìnrin kan tó ti lé lógún ọdún, Cindy lorúkọ ẹ̀. Ọ̀rẹ́ lòun àti Arábìnrin Marie-Louise tó ti lé lẹ́ni ọgọ́ta ọdún. Cindy àti Marie-Louise jọ máa ń ṣiṣẹ́ lóde ẹ̀rí ní gbogbo àárọ̀ Thursday, wọ́n sì jọ máa ń bá ara wọn sọ oríṣiríṣi ọ̀rọ̀ láìfi nǹkan kan pa mọ́. Cindy sọ pé: “Inú mi máa ń dùn tí mo bá ń sọ ohun tó wà lọ́kàn mi fáwọn ọ̀rẹ́ mi torí pé ó máa ń jẹ́ kí n túbọ̀ lóye wọn, kí n sì mọ irú ẹni tí wọ́n jẹ́.” Tí àwọn ọ̀rẹ́ méjì bá ń bára wọn sọ̀rọ̀ látọkàn wá, okùn ọ̀rẹ́ wọn máa túbọ̀ le sí i. Bíi ti Cindy, tí ìwọ náà bá ń gbìyànjú láti bá àwọn èèyàn sọ̀rọ̀ láìfi ohunkóhun pa mọ́, ó dájú pé wàá túbọ̀ láwọn ọ̀rẹ́ tẹ́ ẹ jọ máa sún mọ́ra pẹ́kípẹ́kí.​—Òwe 27:9.

Ẹ MÁA ṢIṢẸ́ PỌ̀

Àwọn ọ̀rẹ́ tòótọ́ máa ń ṣiṣẹ́ pọ̀ lóde ẹ̀rí (Wo ìpínrọ̀ 10)

10. Bó ṣe wà nínú Òwe 27:17, àwọn àǹfààní wo la máa rí tá a bá ń ṣiṣẹ́ pẹ̀lú àwọn ará wa?

10 Bíi ti Jeremáyà àti Bárúkù, tá a bá ń ṣiṣẹ́ pẹ̀lú àwọn ará wa, a máa rí àwọn ànímọ́ tó dáa tí wọ́n ní, ìyẹn á mú ká kẹ́kọ̀ọ́ lára wọn, ká sì túbọ̀ sún mọ́ wọn. (Ka Òwe 27:17.) Bí àpẹẹrẹ, báwo ló ṣe máa ń rí lára rẹ tó o bá wà lóde ẹ̀rí, tó o sì rí bí ọ̀rẹ́ rẹ kan ṣe ń fi ìgboyà sọ ohun tó gbà gbọ́ tàbí tó ń sọ̀rọ̀ látọkàn wá nípa Jèhófà àtohun tó fẹ́ ṣe fáráyé? Ó ṣeé ṣe kíyẹn mú kó o túbọ̀ sún mọ́ ọn, àbí bẹ́ẹ̀ kọ́?

11-12. Sọ àpẹẹrẹ kan tó jẹ́ ká mọ̀ pé iṣẹ́ ìwàásù lè jẹ́ ká túbọ̀ sún mọ́ ẹnì kan.

11 Ẹ jẹ́ ká wo ìrírí méjì tó fi hàn pé iṣẹ́ ìwàásù lè jẹ́ ká túbọ̀ sún mọ́ àwọn ará wa. Arábìnrin Adeline tó jẹ́ ẹni ọdún mẹ́tàlélógún (23) sọ fún Candice ọ̀rẹ́ rẹ̀ pé káwọn jọ lọ sí ìpínlẹ̀ ìwàásù tí a kì í ṣe déédéé. Ó ní: “A fẹ́ kí ìtara wa lẹ́nu iṣẹ́ ìwàásù pọ̀ sí i, ká sì túbọ̀ gbádùn òde ẹ̀rí. A gbà pé ìyẹn máa jẹ́ ká lè ṣe púpọ̀ sí i.” Àwọn àǹfààní wo ni wọ́n rí bí wọ́n ṣe jọ ṣiṣẹ́? Adeline sọ pé: “Lọ́jọ́ kọ̀ọ̀kan tá a bá ti parí iṣẹ́, gbogbo nǹkan tó wà lọ́kàn wa la máa ń sọ fún ara wa, títí kan ohun tó wọ̀ wá lọ́kàn jù lọ lẹ́nu iṣẹ́ ìwàásù lọ́jọ́ yẹn. A sì tún máa ń sọ bá a ṣe rí ọwọ́ Jèhófà lẹ́nu iṣẹ́ ìwàásù wa. Àwa méjèèjì máa ń gbádùn ìjíròrò yẹn gan-an, ó sì ti jẹ́ ká túbọ̀ sún mọ́ra ju ti tẹ́lẹ̀ lọ.”

12 Arábìnrin méjì kan wà tí kò tíì lọ́kọ, Laïla àti Marianne lorúkọ wọn, orílẹ̀-èdè Faransé ni wọ́n ti wá, àwọn méjèèjì lọ wàásù fún ọ̀sẹ̀ márùn-ún nílùú Bangui lórílẹ̀-èdè Central African Republic. Laïla sọ pé: “Èmi àti Marianne dojú kọ àwọn ìṣòro kan, àmọ́ torí pé a jọ máa ń sọ̀rọ̀ dáadáa àti pé a nífẹ̀ẹ́ ara wa, ṣe ni okùn ọ̀rẹ́ wa túbọ̀ ń lágbára sí i. Mo kíyè sí pé ara Marianne tètè mọlé, ó nífẹ̀ẹ́ àwọn tó wà ní ìpínlẹ̀ ìwàásù wa, ó sì tún nítara gan-an. Àwọn nǹkan tí mo kíyè sí yìí jẹ́ kí n túbọ̀ mọyì rẹ̀.” Ìwọ ńkọ́, ṣó dìgbà tó o bá lọ wàásù lórílẹ̀-èdè míì kó o tó mọyì àwọn ará? Rárá, kàkà bẹ́ẹ̀ gbogbo ìgbà tó o bá ń ṣiṣẹ́ pẹ̀lú wọn lóde ẹ̀rí ni kó o máa gbìyànjú láti túbọ̀ mọ̀ wọ́n, torí pé ìyẹn máa jẹ́ kẹ́ ẹ túbọ̀ sún mọ́ra.

MÁA WO IBI TÁWỌN ÈÈYÀN DÁA SÍ, KÓ O SÌ MÁA DÁRÍ JINI

13. Kí làwọn nǹkan tó ṣeé ṣe ká rí tá a bá ṣiṣẹ́ pẹ̀lú àwọn ọ̀rẹ́ wa?

13 Tá a bá ń ṣiṣẹ́ pẹ̀lú àwọn ọ̀rẹ́ wa, kì í ṣe ibi tí wọ́n dáa sí nìkan la máa ń rí, a tún máa ń rí ibi tí wọ́n kù díẹ̀ káàtó sí. Kí ló lè ràn wá lọ́wọ́ tírú nǹkan báyìí bá ṣẹlẹ̀? Ẹ jẹ́ ká tún wo àpẹẹrẹ Jeremáyà, ká lè rí ohun tó ràn án lọ́wọ́ láti gbájú mọ́ ibi táwọn ọ̀rẹ́ rẹ̀ dáa sí dípò ibi tí wọ́n kù sí.

14. Ẹ̀kọ́ wo ni Jeremáyà kọ́ nípa Jèhófà, báwo nìyẹn sì ṣe ràn án lọ́wọ́?

14 Jeremáyà fúnra ẹ̀ ló kọ ìwé Jeremáyà, ó sì ṣeé ṣe kó jẹ́ pé òun náà ló kọ ìwé Àwọn Ọba Kìíní àti Kejì. Ó dájú pé iṣẹ́ tí Jèhófà gbé fún un yẹn jẹ́ kó túbọ̀ mọ̀ pé Jèhófà máa ń ṣàánú àwa èèyàn aláìpé gan-an. Bí àpẹẹrẹ, Jeremáyà mọ̀ pé nígbà tí Ọba Áhábù ronú pìwà dà, Jèhófà kò jẹ́ kí ìdílé rẹ̀ pa run lójú ẹ̀. (1 Ọba 21:27-29) Bákan náà, Jeremáyà mọ̀ pé ohun tí Ọba Mánásè ṣe burú ju ti Áhábù lọ. Síbẹ̀, Jèhófà dárí ji Mánásè nígbà tó ronú pìwà dà. (2 Ọba 21:16, 17; 2 Kíró. 33:10-13) Ó dájú pé àwọn àpẹẹrẹ yìí máa mú kí Jeremáyà rí ìdí tó fi yẹ kóun náà máa mú sùúrù fún àwọn ọ̀rẹ́ òun, kóun sì máa ṣàánú wọn.​—Sm. 103:8, 9.

15. Báwo ni Jeremáyà ṣe fara wé Jèhófà nígbà tí Bárúkù ní ìpínyà ọkàn?

15 Ẹ jẹ́ ká wo bí Jeremáyà ṣe ran Bárúkù lọ́wọ́ nígbà kan tó ní ìpínyà ọkàn. Dípò kí Jeremáyà gbà pé ọ̀rẹ́ òun ò wúlò mọ́, ṣe ló ràn án lọ́wọ́ tìfẹ́tìfẹ́, kò sì fi ọ̀rọ̀ sábẹ́ ahọ́n sọ nígbà tó ń sọ ìkìlọ̀ Jèhófà fún un. (Jer. 45:1-5) Kí la rí kọ́ nínú ìtàn yìí?

Àwọn ọ̀rẹ́ tòótọ́ máa ń dárí ji ara wọn fàlàlà (Wo ìpínrọ̀ 16)

16. Bó ṣe wà nínú Òwe 17:9, kí la gbọ́dọ̀ ṣe tá ò bá fẹ́ kí àárín àwa àtàwọn ọ̀rẹ́ wa dà rú?

16 Ká sòótọ́, a ò lè retí pé káwọn ará wa má ṣàṣìṣe. Torí náà, tá a bá ní ọ̀rẹ́ kan, a gbọ́dọ̀ ṣe gbogbo nǹkan tá a lè ṣe kí àárín wa má bàa dà rú. Tí ọ̀rẹ́ wa bá ṣàṣìṣe, ó yẹ ká fún un ní ìmọ̀ràn látinú Ìwé Mímọ́ láì fọ̀rọ̀ sábẹ́ ahọ́n sọ, síbẹ̀ ká ṣe bẹ́ẹ̀ tìfẹ́tìfẹ́. (Sm. 141:5) Tí wọ́n bá ṣe ohun tó dùn wá, á dáa ká dárí jì wọ́n. Tá a bá sì ti dárí jì wọ́n, ká gbàgbé ẹ̀, ká má sì mẹ́nu kàn án mọ́. (Ka Òwe 17:9.) Ẹ ò rí i pé ó ṣe pàtàkì pé ibi táwọn ará wa dáa sí ló yẹ ká gbájú mọ́, dípò ibi tí wọ́n kù sí torí pé àkókò tí nǹkan nira gan-an là ń gbé yìí. Tá a bá ń ṣe bẹ́ẹ̀, okùn ọ̀rẹ́ wa á túbọ̀ lágbára, ká má sì gbàgbé pé a máa nílò àwọn ọ̀rẹ́ pàtàkì yẹn nígbà ìpọ́njú ńlá.

MÁA FI ÌFẸ́ TÍ KÌ Í YẸ̀ HÀN

17. Báwo ni Jeremáyà ṣe fi hàn pé ọ̀rẹ́ tòótọ́ lòun nígbà ìpọ́njú?

17 Wọ́n máa ń sọ pé ìgbà ìpọ́njú là ń mọ̀rẹ́, wòlíì Jeremáyà sì fi hàn pé ọ̀rẹ́ tòótọ́ lòun. Bí àpẹẹrẹ, lẹ́yìn tí Ebedi-mélékì tó ń ṣiṣẹ́ ní ààfin yọ Jeremáyà kúrò nínú kòtò jíjìn kan tí ẹrẹ̀ wà, ẹ̀rù bẹ̀rẹ̀ sí í ba Ebedi-mélékì pé àwọn ìjòyè máa fojú òun rí màbo. Nígbà tí Jeremáyà gbọ́, kò kàn dákẹ́, kó wá máa rò pé Ebedi-mélékì máa wá nǹkan ṣe sọ́rọ̀ ara ẹ̀. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé inú ẹ̀wọ̀n ni Jeremáyà wà, ó ṣe gbogbo nǹkan tó lè ṣe, ó sọ̀rọ̀ Jèhófà fún Ebedi-mélékì ọ̀rẹ́ rẹ̀ kó lè tù ú nínú.​—Jer. 38:7-13; 39:15-18.

Àwọn ọ̀rẹ́ tòótọ́ máa ń ran ara wọn lọ́wọ́ nígbà ìṣòro (Wo ìpínrọ̀ 18)

18. Bó ṣe wà nínú Òwe 17:17, kí ló yẹ ká ṣe tí ọ̀rẹ́ wa kan bá níṣòro?

18 Oríṣiríṣi nǹkan ló ń ṣẹlẹ̀ sáwọn ará wa. Bí àpẹẹrẹ, àjálù máa ń ṣàdédé wáyé, nígbà míì sì rèé ó lè jẹ́ pé àwọn èèyàn ló fà á. Tírú ẹ̀ bá ṣẹlẹ̀, àwọn kan lára wa lè gba àwọn ará yìí sílé, àwọn míì sì lè fún wọn lówó. Àmọ́ ohun kan wà tí gbogbo wa lè ṣe, a lè bẹ Jèhófà pé kó ràn wọ́n lọ́wọ́. Tá a bá gbọ́ pé arákùnrin tàbí arábìnrin kan rẹ̀wẹ̀sì, a lè má mọ ohun tá a máa ṣe tàbí ohun tá a máa sọ fún wọn. Síbẹ̀ àwọn nǹkan míì wà tá a lè ṣe. Bí àpẹẹrẹ, a lè wáyè lọ rí ọ̀rẹ́ wa yẹn. Ká fara balẹ̀ tẹ́tí sí i bó ṣe ń sọ ohun tó wà lọ́kàn rẹ̀. A sì tún lè ka ẹsẹ Ìwé Mímọ́ kan tá a fẹ́ràn fún un láti tù ú nínú. (Àìsá. 50:4) Ohun tó ṣe pàtàkì jù ni pé kó o dúró ti ọ̀rẹ́ rẹ nígbà ìṣòro.​—Ka Òwe 17:17.

19. Àǹfààní wo la máa rí tá a bá jẹ́ kí okùn ọ̀rẹ́ wa lágbára nísinsìnyí?

19 Ìsinsìnyí gan-an ló yẹ ká pinnu pé a máa mú àwọn ará wa lọ́rẹ̀ẹ́, a ò sì ní jẹ́ kí ohunkóhun da àárín wa rú. Kí nìdí? Ìdí ni pé àwọn ọ̀tá máa wá gbogbo ọ̀nà láti ba àárín wa jẹ́, kódà wọ́n tiẹ̀ máa parọ́ mọ́ wa. Wọ́n á fẹ́ kẹ̀yìn wa síra wa. Àmọ́ pàbó ni ìsapá wọn máa já sí. Bó ti wù kí wọ́n gbìyànjú tó, wọn ò ní lè paná ìfẹ́ wa. Kò sóhun tí wọ́n lè ṣe tí àárín àwa àtàwọn ọ̀rẹ́ wa fi máa dà rú. Kódà, títí láéláé làá máa bára wa ṣọ̀rẹ́!

ORIN 24 Ẹ Wá sí Òkè Jèhófà

^ ìpínrọ̀ 5 Bí òpin ṣe ń sún mọ́lé, ó ṣe pàtàkì pé kí gbogbo wa túbọ̀ ṣera wa lọ́kan. Nínú àpilẹ̀kọ yìí, a máa jíròrò ohun tá a rí kọ́ lára Jeremáyà. A tún máa sọ̀rọ̀ nípa àǹfààní tá a máa rí tá a bá ṣera wa lọ́kan nísinsìnyí kí ìṣòro tó dé àti bí ìyẹn ṣe máa ràn wá lọ́wọ́ nígbà àdánwò.

^ ìpínrọ̀ 2 Bíbélì ò to àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ tó wà nínú ìwé Jeremáyà tẹ̀ léra bí wọ́n ṣe wáyé.

^ ìpínrọ̀ 57 ÀWÒRÁN: Àwòrán yìí jẹ́ ká rí ohun tó ṣeé ṣe kó ṣẹlẹ̀ nígbà “ìpọ́njú ńlá.” Àwọn arákùnrin àtàwọn arábìnrin kan forí pa mọ́ sínú iyàrá arákùnrin kan. Gbogbo wọn ń tura wọn nínú lásìkò tí nǹkan le gan-an. Àwọn àwòrán mẹ́ta tó tẹ̀ le é yìí fi hàn pé àwọn ará yẹn ti di ọ̀rẹ́ ara wọn kí ìpọ́njú ńlá tó bẹ̀rẹ̀