Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

ÀPILẸ̀KỌ FÚN ÌKẸ́KỌ̀Ọ́ 49

Ó Yẹ Ká Ní Àkókò fún Iṣẹ́ àti Ìsinmi

Ó Yẹ Ká Ní Àkókò fún Iṣẹ́ àti Ìsinmi

“Ẹ máa bọ̀, ẹ wá síbi tó dá . . . kí ẹ sì sinmi díẹ̀.”​—MÁÀKÙ 6:31.

ORIN 143 Tẹpá Mọ́ṣẹ́, Wà Lójúfò, Kó O sì Máa Retí

OHUN TÁ A MÁA JÍRÒRÒ *

1. Ọwọ́ wo lọ̀pọ̀ èèyàn fi ń mú iṣẹ́?

ỌWỌ́ wo lọ̀pọ̀ èèyàn fi ń mú iṣẹ́ lágbègbè tó o wà? Ní ọ̀pọ̀ orílẹ̀-èdè, ṣe làwọn èèyàn ń ṣiṣẹ́ kára tí wọ́n sì ń lo ọ̀pọ̀ àkókò nídìí iṣẹ́ ju ti ìgbàkígbà rí lọ. Àwọn tó máa ń ṣe iṣẹ́ àṣekúdórógbó kì í fi bẹ́ẹ̀ sinmi, wọn kì í ráyè gbọ́ ti ìdílé wọn, bẹ́ẹ̀ sì ni wọn kì í ráyè fún ìjọsìn Ọlọ́run. (Oníw. 2:23) Ní tàwọn míì, wọn ò fẹ́ṣẹ́ ṣe rárá, téèyàn bá sì bi wọ́n, àwáwí ni wọ́n á máa ṣe.​—Òwe 26:​13, 14.

2-3. Ọwọ́ wo ni Jèhófà àti Jésù fi mú iṣẹ́?

2 Tá a bá fi ojú tí Jèhófà àti Jésù fi ń wo iṣẹ́ wò ó, àá rí i pé ó yàtọ̀ pátápátá sí ojú tí aráyé fi ń wò ó. Kò sí àní-àní pé Jèhófà kì í fiṣẹ́ ṣeré. Jésù mú kí kókó yìí ṣe kedere nígbà tó sọ pé: “Baba mi ń ṣiṣẹ́ títí di báyìí, èmi náà ṣì ń ṣiṣẹ́.” (Jòh. 5:17) Ẹ gbọ́ ná, mélòó la fẹ́ kà nínú àwọn nǹkan tí Jèhófà ṣẹ̀dá? Ṣé ti àìmọye àwọn áńgẹ́lì tó wà lọ́run ni ká sọ ni àbí ti àgbáálá ayé yìí tó lọ salalu? Nínú ayé tá a wà yìí, kò síbi tá a yíjú sí tá ò rí àwọn ohun àgbàyanu tí Jèhófà ṣẹ̀dá. Abájọ tí onísáàmù náà fi sọ pé: “Àwọn iṣẹ́ rẹ mà pọ̀ o, Jèhófà! Gbogbo wọn lo fi ọgbọ́n ṣe. Ayé kún fún àwọn ohun tí o ṣe.”​—Sm. 104:24.

3 Jésù fìwà jọ Baba rẹ̀ láìkù síbì kan. Nígbà tó wà lọ́run, ó bá Baba rẹ̀ ṣiṣẹ́ “nígbà tó dá ọ̀run.” Kódà, Bíbélì pe Jésù ní “àgbà òṣìṣẹ́.” (Òwe 8:​27-31) Nígbà tó sì wá sáyé, kò fiṣẹ́ ṣeré, kódà ọ̀pọ̀ nǹkan ló gbéṣe. Àní sẹ́, iṣẹ́ dà bí oúnjẹ fún un, àwọn ohun tó ṣe sì fi hàn pé Ọlọ́run ló rán an wá.​—Jòh. 4:34; 5:36; 14:10.

4. Kí la rí kọ́ nínú àpẹẹrẹ Jèhófà àti Jésù tó bá di pé ká sinmi?

4 Ṣé bí Jèhófà àti Jésù kò ṣe fiṣẹ́ ṣeré yìí wá túmọ̀ sí pé àwa náà ò gbọ́dọ̀ sinmi? Ọ̀rọ̀ ò rí bẹ́ẹ̀. Kì í rẹ Jèhófà, torí náà kò nílò ìsinmi báwa èèyàn ṣe máa ń sinmi. Bó ti wù kó rí, Bíbélì sọ pé lẹ́yìn tí Jèhófà dá ọ̀run àti ayé, ‘ó sinmi, ara sì tù ú.’ (Ẹ́kís. 31:17) Ohun tí ẹsẹ Ìwé Mímọ́ yìí ń sọ ni pé Jèhófà dáwọ́ dúró díẹ̀ kó lè fara balẹ̀ wo àwọn nǹkan tó dá, ìyẹn sì múnú rẹ̀ dùn. Jésù náà ṣiṣẹ́ kára nígbà tó wà láyé, síbẹ̀ ó wáyè láti sinmi, òun àtàwọn ọ̀rẹ́ rẹ̀ sì jọ gbádùn ara wọn.​—Mát. 14:13; Lúùkù 7:34.

5. Kí ló ṣòro fáwọn kan láti ṣe?

5 Bíbélì rọ àwa èèyàn Jèhófà pé ká fọwọ́ gidi mú iṣẹ́. Òṣìṣẹ́ kára làwa ìránṣẹ́ Ọlọ́run gbọ́dọ̀ jẹ́, a ò gbọ́dọ̀ ya ọ̀lẹ. (Òwe 15:19) Ó ṣeé ṣe kó o jẹ́ onídìílé, tó o sì ń ṣiṣẹ́ kára láti bójú tó ìdílé rẹ. Bákan náà, torí pé o jẹ́ ọmọlẹ́yìn Kristi, o mọ̀ pé o tún ní ojúṣe láti máa wàásù ìhìn rere Ìjọba Ọlọ́run. Bó ti wù kó rí, ó ṣe pàtàkì pé kó o máa wáyè sinmi dáadáa. Bọ́rọ̀ ṣe rí yìí, ṣé kì í ṣòro fún ẹ láti ṣètò àkókò tó o máa fi ṣiṣẹ́, tó o máa fi sinmi, kó o sì tún lọ́wọ́ nínú iṣẹ́ ìwàásù láìjẹ́ kí ọ̀kan pa òmíì lára? Ọgbọ́n wo lèèyàn lè dá tí kò fi ní ṣàṣejù nídìí iṣẹ́ àti ìsinmi?

MÁA FOJÚ TÓ TỌ́ WO IṢẸ́ ÀTI ÌSÌNMI

6. Báwo ni àkọsílẹ̀ Máàkù 6:​30-34 ṣe fi hàn pé Jésù ò ṣàṣejù tó bá di pé ká ṣiṣẹ́ ká sì sinmi?

6 Kò yẹ ká tún ṣàṣejù tó bá dọ̀rọ̀ iṣẹ́. Ọlọ́run mí sí Ọba Sólómọ́nì láti sọ pé: “Ohun gbogbo ni àkókò wà fún.” Ó mẹ́nu kan ìgbà gbígbìn, ìgbà kíkọ́, ìgbà sísunkún, ìgbà rírẹ́rìn-ín, ìgbà jíjó àtàwọn ìgbòkègbodò míì. (Oníw. 3:​1-8) Ó ṣe kedere pé bó ti ṣe pàtàkì pé ká máa ṣiṣẹ́ bẹ́ẹ̀ náà ló ṣe pàtàkì ká máa wáyè sinmi. Ojú tó tọ́ ni Jésù fi wo iṣẹ́ àti ìsinmi. Bí àpẹẹrẹ, ìgbà kan wà tí Bíbélì ròyìn pé ọwọ́ àwọn àpọ́sítélì rẹ̀ dí gan-an lẹ́nu iṣẹ́ ìwàásù débi pé “wọn ò . . . ní àkókò kankan tí ọwọ́ wọn dilẹ̀, kódà, wọn ò ráyè jẹun.” Lẹ́yìn tí wọ́n dé, Jésù sọ fún wọn pé: “Ẹ máa bọ̀, ẹ wá síbi tó dá ní ẹ̀yin nìkan, kí ẹ sì sinmi díẹ̀.” (Ka Máàkù 6:​30-34.) Lóòótọ́, kì í ṣe gbogbo ìgbà ni Jésù àtàwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ máa ń ráyè sinmi, síbẹ̀ Jésù mọ̀ pé ó ṣe pàtàkì káwọn sinmi.

7. Kí la máa rí kọ́ tá a bá ṣàyẹ̀wò ohun tí Òfin Mósè sọ nípa Sábáàtì?

7 Nígbà míì, ó lè gba pé ká sinmi tàbí ká ṣe àwọn ìyípadà kan nínú bá a ṣe ń ṣiṣẹ́. Èyí ṣe kedere nínú ètò kan tí Jèhófà ṣe fáwọn èèyàn rẹ̀ nígbà àtijọ́, ìyẹn Sábáàtì táwọn ọmọ Ísírẹ́lì ń pa mọ́ lọ́sọ̀ọ̀sẹ̀. Òótọ́ ni pé a ò sí lábẹ́ Òfin Mósè, àmọ́ a lè rí ẹ̀kọ́ kọ́ tá a bá ṣàyẹ̀wò ohun tí òfin yẹn sọ nípa Sábáàtì. Àyẹ̀wò yìí máa jẹ́ ká mọ̀ bóyá ojú tó tọ́ la fi ń wo iṣẹ́ àti ìsinmi.

SÁBÁÀTÌ WÀ FÚN ÌJỌSÌN ÀTI ÌSINMI

8. Bó ṣe wà nínú Ẹ́kísódù 31:​12-15, kí lọjọ́ Sábáàtì wà fún?

8 Bíbélì sọ pé lẹ́yìn “ọjọ́” mẹ́fà tí Ọlọ́run fi ṣẹ̀dá àwọn nǹkan tó wà láyé, ó dáwọ́ dúró. (Jẹ́n. 2:2) Àmọ́ ohun kan ni pé Ọlọ́run fẹ́ràn àtimáa ṣiṣẹ́, kódà Bíbélì sọ pé ó ṣì “ń ṣiṣẹ́.” (Jòh. 5:17) Ètò tí Ọlọ́run ṣe fáwọn ọmọ Ísírẹ́lì pé kí wọ́n máa sinmi ní gbogbo ọjọ́ Sábáàtì jọra pẹ̀lú ọjọ́ keje tí ìwé Jẹ́nẹ́sísì sọ pé Jèhófà fi sinmi. Ọlọ́run sọ pé àmì ni Sábáàtì jẹ́ láàárín òun àtàwọn ọmọ Ísírẹ́lì. Ó fẹ́ kó jẹ́ “ọjọ́ ìsinmi tí [wọn] ò ní ṣiṣẹ́ rárá . . . . Ohun mímọ́ ló jẹ́ fún Jèhófà.” (Ka Ẹ́kísódù 31:​12-15.) Kì í ṣe àwọn àgbàlagbà nìkan ni kò gbọ́dọ̀ ṣiṣẹ́, ó kan àwọn ọmọdé àtàwọn ẹrú, kódà ó kan àwọn ẹran ọ̀sìn pàápàá. (Ẹ́kís. 20:10) Ètò yìí mú kó ṣeé ṣe fún àwọn èèyàn náà láti túbọ̀ jọ́sìn Ọlọ́run.

9. Nígbà tí Jésù wà láyé, èrò tí kò tọ́ wo làwọn kan ní nípa Sábáàtì?

9 Ètò Sábáàtì yẹn ṣe àwọn èèyàn Ọlọ́run láǹfààní gan-an, àmọ́ àwọn aṣáájú ìsìn ìgbà yẹn ti àṣejù bọ̀ ọ́. Wọ́n sọ pé kò bófin mu bí àwọn ọmọlẹ́yìn Jésù ṣe já ọkà jẹ nínú oko àti bí Jésù ṣe wo àwọn èèyàn sàn lọ́jọ́ Sábáàtì. (Máàkù 2:​23-27; 3:​2-5) Èrò tí wọ́n ní yẹn ta ko èrò Ọlọ́run, Jésù sì mú kíyẹn ṣe kedere sáwọn tó ń fetí sí ọ̀rọ̀ rẹ̀.

Nínú ìdílé tí Jésù dàgbà sí, àwọn nǹkan tó jẹ mọ́ ìjọsìn Jèhófà ni wọ́n máa ń ṣe lọ́jọ́ Sábáàtì (Wo ìpínrọ̀ 10) *

10. Èrò wo ni Jésù ní nípa Sábáàtì bó ṣe wà nínú Mátíù 12:​9-12, kí nìyẹn sì kọ́ wa?

10 Jésù àtàwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ pa Sábáàtì mọ́ torí pé Júù ni wọ́n, wọ́n sì wà lábẹ́ Òfin Mósè. * Àwọn ohun tí Jésù sọ àtohun tó ṣe fi hàn pé òfin yẹn ò ní kéèyàn má fojú àánú hàn, bẹ́ẹ̀ ni kò sọ pé kí wọ́n má ran àwọn míì lọ́wọ́. Ó tiẹ̀ là á mọ́lẹ̀ pé: “Ó bófin mu láti ṣe ohun tó dáa ní Sábáàtì.” (Ka Mátíù 12:​9-12.) Ó jẹ́ kó ṣe kedere pé èèyàn ò rú òfin Sábáàtì téèyàn bá ṣe rere fáwọn míì tàbí tó ran àwọn míì lọ́wọ́. Àwọn nǹkan tí Jésù ṣe fi hàn pé ó lóye ìdí tí Jèhófà fi ṣòfin Sábáàtì. Torí pé àwọn ọmọ Ísírẹ́lì kì í ṣiṣẹ́ lọ́jọ́ Sábáàtì, ó ṣeé ṣe fún wọn láti pọkàn pọ̀ sórí ohun tó jẹ mọ́ ìjọsìn Ọlọ́run. Nínú ìdílé tí Jésù dàgbà sí, ó dájú pé nǹkan tẹ̀mí ni wọ́n máa ń ṣe lọ́jọ́ Sábáàtì. Èyí ṣe kedere nínú àkọsílẹ̀ nípa Jésù nígbà tó wà ní Násárẹ́tì tó jẹ́ ìlú ìbílẹ̀ rẹ̀. Bíbélì sọ pé: “[Jésù] wọnú sínágọ́gù, ó sì dìde dúró láti kàwé, bó ṣe máa ń ṣe ní ọjọ́ Sábáàtì.”​—Lúùkù 4:​15-19.

ỌWỌ́ WO LO FI Ń MÚ IṢẸ́?

11. Kí ni Jésù rí kọ́ lára Jósẹ́fù tó bá di pé kéèyàn ṣiṣẹ́?

11 Kò sí àní-àní pé ojú tí Ọlọ́run fi ń wo iṣẹ́ ni Jósẹ́fù náà fi ń wò ó, ó sì jẹ́ kó hàn nígbà tó kọ́ Jésù níṣẹ́ káfíńtà. (Mát. 13:​55, 56) Ó dájú pé Jésù rí bí Jósẹ́fù ṣe ń ṣiṣẹ́ kára kó lè bójú tó Màríà, òun àtàwọn ọmọ wọn yòókù. Kò yani lẹ́nu nígbà tí Jésù sọ fáwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ pé: “Owó iṣẹ́ tọ́ sí òṣìṣẹ́.” (Lúùkù 10:7) Ó ṣe kedere pé òṣìṣẹ́ kára ni Jésù.

12. Àwọn ẹsẹ Ìwé Mímọ́ wo ló sọ ọwọ́ tí Pọ́ọ̀lù fi mú iṣẹ́?

12 Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù náà mọ bó ti ṣe pàtàkì tó pé kéèyàn jẹ́ òṣìṣẹ́ kára. Bó ṣe máa wàásù nípa Jésù àtohun tó fi kọ́ni ló gbawájú nígbèésí ayé rẹ̀. Síbẹ̀, Pọ́ọ̀lù ṣiṣẹ́ kára kó lè rówó gbọ́ bùkátà ara rẹ̀. Kódà, àwọn ará Tẹsalóníkà mọ̀ nípa “òpò àti làálàá” tí Pọ́ọ̀lù máa ń ṣe àti bó ṣe máa ń “ṣiṣẹ́ tọ̀sántòru” kó má bàa fi tiẹ̀ ni àwọn míì lára tàbí “gbé ẹrù tó wúwo wọ” ẹnikẹ́ni lọ́rùn. (2 Tẹs. 3:8; Ìṣe 20:​34, 35) Iṣẹ́ wo ni Pọ́ọ̀lù ń tọ́ka sí? Ó ṣeé ṣe kó jẹ́ iṣẹ́ àgọ́ pípa. Nígbà tó wà ní Kọ́ríńtì, ilé Ákúílà àti Pírísílà ló dé sí, ó sì “ń bá wọn ṣiṣẹ́ torí iṣẹ́ àgọ́ pípa ni wọ́n ń ṣe.” Ti pé Pọ́ọ̀lù ń “ṣiṣẹ́ tọ̀sántòru” kò túmọ̀ sí pé ó ń ṣiṣẹ́ bí aago. Bí àpẹẹrẹ, ó máa ń wáyè sinmi lọ́jọ́ Sábáàtì. Ọjọ́ yẹn ló fi máa ń bá àwọn Júù sọ̀rọ̀ Ọlọ́run torí pé àwọn náà kì í ṣiṣẹ́ lọ́jọ́ Sábáàtì.​—Ìṣe 13:​14-16, 42-44; 16:13; 18:​1-4.

13. Kí ni àpẹẹrẹ Pọ́ọ̀lù kọ́ wa?

13 Àpẹẹrẹ àtàtà ni àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù fi lélẹ̀ fún wa. Ó mọ̀ pé ó yẹ kóun ṣiṣẹ́ kóun lè gbọ́ bùkátà ara òun, ó sì tún máa ń ṣe “iṣẹ́ mímọ́ ti ìhìn rere Ọlọ́run” déédéé. (Róòmù 15:16; 2 Kọ́r. 11:23) Kódà, ó gba àwọn míì níyànjú pé kí wọ́n fara wé òun. Ìyẹn jẹ́ ká rídìí tí Bíbélì fi sọ pé Ákúílà àti Pírísílà jẹ́ alábàáṣiṣẹ́ Pọ́ọ̀lù tí wọ́n “jọ ń ṣiṣẹ́ Kristi Jésù.” (Róòmù 12:11; 16:3) Pọ́ọ̀lù rọ àwọn ará Kọ́ríńtì pé kí wọ́n “máa ní ohun púpọ̀ láti ṣe nínú iṣẹ́ Olúwa.” (1 Kọ́r. 15:58; 2 Kọ́r. 9:8) Kódà Jèhófà mí sí àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù láti sọ pé: “Tí ẹnikẹ́ni ò bá fẹ́ ṣiṣẹ́, kó má jẹun.”​—2 Tẹs. 3:10.

14. Kí ni Jésù ní lọ́kàn nígbà tó sọ̀rọ̀ tó wà nínú Jòhánù 14:12?

14 Iṣẹ́ tó ṣe pàtàkì jù lọ láwọn ọjọ́ ìkẹyìn yìí ni iṣẹ́ ìwàásù àti sísọni di ọmọ ẹ̀yìn. Àní sẹ́, Jésù sọ tẹ́lẹ̀ pé àwọn ọmọ ẹ̀yìn òun máa ṣe ju bí òun ṣe ṣe lọ! (Ka Jòhánù 14:12.) Jésù ò sọ pé a máa ṣe iṣẹ́ ìyanu bíi tòun. Kàkà bẹ́ẹ̀, ohun tó ń sọ ni pé a máa ṣe iṣẹ́ ìwàásù, a sì máa kọ́ni lẹ́kọ̀ọ́ lọ́nà tó gbòòrò ju tòun lọ. Yàtọ̀ síyẹn, a máa wàásù láwọn ibi tí òun fúnra rẹ̀ kò dé, a máa wàásù fún ọ̀pọ̀ èèyàn, a sì máa pẹ́ lẹ́nu iṣẹ́ náà ju tòun lọ.

15. Àwọn ìbéèrè wo ló yẹ ká bi ara wa, kí sì nìdí?

15 Àwọn ìbéèrè kan wà tó yẹ ká bi ara wa, yálà à ń ṣiṣẹ́ lábẹ́ ẹnì kan tàbí iṣẹ́ ara wa là ń ṣe. Bi ara rẹ pé: ‘Ṣé àwọn èèyàn mọ̀ mí sí ẹni tí kì í fiṣẹ́ ṣeré? Ṣé mo máa ń tètè parí iṣẹ́ tó wà lọ́wọ́ mi, ṣé bẹ́ẹ̀ ni mi máa ń jẹ́ bẹ́ẹ̀ ni, ṣé mo sì máa ń ṣe gbogbo ohun tágbára mi gbé?’ Tí ìdáhùn rẹ bá jẹ́ bẹ́ẹ̀ ni sáwọn ìbéèrè yìí, ó ṣeé ṣe káwọn èèyàn tàbí ọ̀gá rẹ fọkàn tán ẹ. Yàtọ̀ síyẹn, á mú kó yá àwọn tẹ́ ẹ jọ ń ṣiṣẹ́ lára láti gbọ́rọ̀ rẹ tó o bá ń wàásù fún wọn. Tó bá dọ̀rọ̀ ìwàásù àti kíkọ́ni, bi ara rẹ láwọn ìbéèrè yìí: ‘Ṣé àwọn èèyàn mọ̀ mí sẹ́ni tí kì í fiṣẹ́ ìwàásù ṣeré? Ṣé mo máa ń múra ohun tí màá bá àwọn èèyàn sọ sílẹ̀ dáadáa? Ṣé mo máa ń mú àdéhùn mi ṣẹ tí mo bá ṣèlérí pé màá pa dà wá? Ṣé gbogbo apá tí iṣẹ́ ìwàásù wa pín sí ni mo máa ń lọ́wọ́ nínú ẹ̀ déédéé?’ Tí ìdáhùn rẹ bá jẹ́ bẹ́ẹ̀ ni sáwọn ìbéèrè yìí, ó dájú pé wàá máa láyọ̀ lẹ́nu iṣẹ́ náà.

OJÚ WO LO FI Ń WO ÌSINMI?

16. Ojú wo ni Jésù àtàwọn àpọ́sítélì rẹ̀ fi wo ìsinmi, báwo nìyẹn sì ṣe yàtọ̀ sí ojú tí ọ̀pọ̀ fi ń wò ó lónìí?

16 Jésù mọ̀ pé ó yẹ kí òun àtàwọn àpọ́sítélì òun máa sinmi lẹ́ẹ̀kọ̀ọ̀kan. Àmọ́ ọ̀rọ̀ àwọn èèyàn ìgbà yẹn àti tòde òní jọra pẹ̀lú ọkùnrin ọlọ́rọ̀ kan tí Jésù sọ nínú àkàwé kan tó ṣe. Ọkùnrin yẹn sọ fún ara rẹ̀ pé ohun tó kù fún òun báyìí ni pé kí òun ‘fọkàn balẹ̀, kóun máa jẹ, kóun máa mu, kóun sì máa gbádùn ara òun.’ (Lúùkù 12:19; 2 Tím. 3:4) Lédè míì, ohun tó gbà á lọ́kàn ni bó ṣe máa jẹ̀gbádùn, kó sì máa sinmi. Òdìkejì pátápátá nìyẹn jẹ́ sóhun tí Jésù àtàwọn àpọ́sítélì rẹ̀ fayé wọn ṣe, torí pé kì í ṣe bí wọ́n ṣe máa jẹ̀gbádùn ló gbà wọ́n lọ́kàn.

Tá ò bá ṣàṣejù nídìí iṣẹ́ àti ìsinmi, àá máa pésẹ̀ sípàdé déédéé, àá sì máa lọ́wọ́ nínú iṣẹ́ ìwàásù tó ń fúnni láyọ̀ (Wo ìpínrọ̀ 17) *

17. Kí la máa ń fi àkókò wa ṣe tá a bá gba ìsinmi lẹ́nu iṣẹ́?

17 Àwa ọmọlẹ́yìn Jésù náà máa ń sapá láti lo àkókò wa lọ́nà tó tọ́ tá ò bá tiẹ̀ sí lẹ́nu iṣẹ́. Yàtọ̀ sí pé ká sinmi, a tún máa ń fi àkókò yẹn lọ́wọ́ nínú iṣẹ́ ìwàásù, a sì máa ń lọ sípàdé. Kódà, a kì í fọ̀rọ̀ ìpàdé àti iṣẹ́ ìwàásù ṣeré rárá, a gbà pé wọ́n ṣe pàtàkì gan-an ju ohunkóhun míì lọ. Fún ìdí yìí, a máa ń ṣe gbogbo ohun tá a lè ṣe láti lọ sípàdé ká sì wàásù. (Héb. 10:​24, 25) Tá a bá tiẹ̀ gba ìsinmi lẹ́nu iṣẹ́, a máa ń rí i dájú pé a ò pa ìpàdé jẹ, a sì máa ń lo gbogbo àǹfààní tó bá yọjú láti bá àwọn èèyàn sọ̀rọ̀ Ọlọ́run níbikíbi tá a bá wà.​—2 Tím. 4:2.

18. Kí ni Jésù Kristi Ọba wa fẹ́ ká ṣe?

18 A mà dúpẹ́ o pé Jésù Kristi Ọba wa ń gba tiwa rò, ó sì ń ràn wá lọ́wọ́ ká lè máa fojú tó tọ́ wo iṣẹ́ àti ìsinmi! (Héb. 4:15) Ó fẹ́ ká máa wáyè sinmi. Bákan náà, ó fẹ́ ká máa ṣiṣẹ́ kára ká lè gbọ́ bùkátà wa, ká sì máa lọ́wọ́ nínú iṣẹ́ ìwàásù tó ń fúnni láyọ̀. Nínú àpilẹ̀kọ tó kàn, a máa jíròrò ohun tí Jésù ṣe láti dá wa sílẹ̀ lómìnira kúrò lọ́wọ́ ìsìnrú tó burú jù.

ORIN 38 Yóò Sọ Ọ́ Di Alágbára

^ ìpínrọ̀ 5 Ìwé Mímọ́ jẹ́ ká mọ irú ọwọ́ tó yẹ ká fi mú iṣẹ́ àti ìsinmi. Nínú àpilẹ̀kọ yìí, a máa lo àpẹẹrẹ Sábáàtì táwọn ọmọ Ísírẹ́lì máa ń pa mọ́ lọ́sọ̀ọ̀sẹ̀ láti ṣàlàyé bá a ṣe lè máa fojú tó tọ́ wo iṣẹ́ àti ìsinmi.

^ ìpínrọ̀ 10 Àwọn ọmọlẹ́yìn Jésù ò fi Sábáàtì ṣeré rárá, kódà wọ́n dúró kí Sábáàtì parí kí wọ́n tó parí èròjà tí wọ́n fẹ́ fi bójú tó òkú Jésù tó wà nínú ibojì.​—Lúùkù 23:​55, 56.

^ ìpínrọ̀ 55 ÀWÒRÁN: Jósẹ́fù mú ìyàwó àtàwọn ọmọ rẹ̀ lọ sí sínágọ́gù lọ́jọ́ Sábáàtì.

^ ìpínrọ̀ 57 ÀWÒRÁN: Bàbá kan ń ṣiṣẹ́ kó lè rówó gbọ́ bùkátà ìdílé rẹ̀. Nígbà tó gba ìsinmi lẹ́nu iṣẹ́, ó lo àǹfààní tó ní láti wàásù, òun àti ìdílé rẹ̀ sì lọ́wọ́ nínú ohun tó jẹ mọ́ ìjọsìn Ọlọ́run.