Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

MÁA HÙWÀ TÓ YẸ KRISTẸNI

Àwọn Olùṣọ́ Àgùntàn Tó Ń Ṣiṣẹ́ Kára fún Ire Àwọn Èèyàn Ọlọ́run

Àwọn Olùṣọ́ Àgùntàn Tó Ń Ṣiṣẹ́ Kára fún Ire Àwọn Èèyàn Ọlọ́run

Ọ̀pọ̀ èèyàn ni ò fọkàn tán àwọn aláṣẹ. Kí nìdí? Torí pé wọ́n máa ń lo àṣẹ tí wọ́n ní lọ́nà tí ò tọ́, tara wọn nìkan ni wọ́n sì mọ̀. (Mik 7:3) Ẹ ò ri bí inú wa ṣe dùn tó pé a ní àwọn alábòójútó tó ti gba ìdálẹ́kọ̀ọ́ nípa bí wọ́n á ṣe máa bójú tó àwọn èèyàn Jèhófà lọ́nà tó máa ṣe wọ́n láǹfààní.—Ẹst 10:3; Mt 20:​25, 26.

Àwọn alàgbà yàtọ̀ pátápátá sáwọn aláṣẹ tó wà nínú ayé. Ìdí ni pé, ìfẹ́ tí wọ́n ní fún Jèhófà àtàwọn èèyàn rẹ̀ ló mú kí wọ́n máa fìfẹ́ bójú tó àwọn ará. (Jo 21:16; 1Pe 5:​1-3) Àwọn alàgbà máa ń tẹ̀ lé àpẹẹrẹ Jésù ní ti pé wọ́n máa ń jẹ́ kí ara tu àwọn tó wà nínú ìjọ kí wọ́n sì gbà pé ara ìdílé Jèhófà ni wọ́n. Bákan náà, wọ́n máa ń jẹ́ kí àwọn ará túbọ̀ sún mọ́ Jèhófà. Tí wọ́n bá rí i pé ẹnì kan rẹ̀wẹ̀sì, wọ́n máa ń tètè fún irú ẹni bẹ́ẹ̀ níṣìírí, wọ́n sì máa ń ran àwọn ará lọ́wọ́ tí wọ́n bá nílò ìtọ́jú pàjáwìrì tàbí tí àjálù bá ṣẹlẹ̀. Tó o bá nílò ìrànlọ́wọ́ èyíkéyìí, o ò ṣe kàn sí ọ̀kan lára àwọn alàgbà ìjọ rẹ?—Jem 5:14.

JẸ́ KÍ ÀWỌN ARÁ WO FÍDÍÒ ÀWỌN OLÙṢỌ́ ÀGÙNTÀN TÓ Ń BÓJÚ TÓ AGBO, KẸ́ Ẹ SÌ DÁHÙN ÀWỌN ÌBÉÈRÈ TÓ TẸ̀ LÉ E YÌÍ:

  • Báwo làwọn alàgbà ṣe ran Mariana lọ́wọ́, àǹfààní wo nìyẹn sì ṣe é?

  • Báwo làwọn alàgbà ṣe ran Elias lọ́wọ́, àǹfààní wo nìyẹn sì ṣe é?

  • Báwo ni fídíò yìí ṣe jẹ́ ká túbọ̀ mọrírì iṣẹ́ táwọn alàgbà ń ṣe?