Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

ÀWỌN ÌṢÚRA INÚ Ọ̀RỌ̀ ỌLỌ́RUN

Ìfẹ́ Jèhófà Tí Kì í Yẹ̀ Ń Dáàbò Bò Wá Lọ́wọ́ Irọ́ Sátánì

Ìfẹ́ Jèhófà Tí Kì í Yẹ̀ Ń Dáàbò Bò Wá Lọ́wọ́ Irọ́ Sátánì

Sátánì fẹ́ káwọn èèyàn gbà pé àmúwá Ọlọ́run làwọn nǹkan burúkú tó ń ṣẹlẹ̀ (Job 8:4)

Ó fẹ́ ká máa ronú pé kò sí àǹfààní kankan nínú kéèyàn jẹ́ olóòótọ́ torí pé ojú kan náà ni Jèhófà fi ń wo ẹni burúkú àti ẹni rere (Job 9:​20-22; w15 7/1 12 ¶3)

Ìfẹ́ tí kì í yẹ̀ tí Jèhófà ní sí wa kò ní jẹ́ kí Sátánì fi irọ́ tàn wá jẹ, á sì jẹ́ ká lè jẹ́ olóòótọ́ sí Jèhófà (Job 10:12; Sm 32:​7, 10; w21.11 6 ¶14)

GBÌYÀNJÚ ÈYÍ WÒ: Tó o bá ń kojú àdánwò, ronú nípa àwọn ọ̀nà tí Jèhófà ti gbà fìfẹ́ tí kì í yẹ̀ hàn sí ẹ, kọ wọ́n sílẹ̀, kó o sì máa ṣàyẹ̀wò ẹ̀ látìgbàdégbà. Tó o bá ṣe bẹ́ẹ̀, ìyẹn ò ní jẹ́ kó o bọ́hùn.