Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

MÁA HÙWÀ TÓ YẸ KRISTẸNI

Ẹ̀yin Òbí​—⁠Ẹ Ran Àwọn Ọmọ Yín Lọ́wọ́ Kí Wọ́n Lè Ní Ọgbọ́n Ọlọ́run

Ẹ̀yin Òbí​—⁠Ẹ Ran Àwọn Ọmọ Yín Lọ́wọ́ Kí Wọ́n Lè Ní Ọgbọ́n Ọlọ́run

Ó dájú pé ẹ̀yin òbí máa fẹ́ káwọn ọmọ yín ní ọgbọ́n Ọlọ́run. Ọ̀nà kan tẹ́ ẹ lè gbà ràn wọ́n lọ́wọ́ ni pé kẹ́ ẹ jẹ́ kí wọ́n máa wá sípàdé déédéé, kí wọ́n sì máa kópa nínú ẹ̀. Ohun táwọn ọmọdé bá rí tí wọ́n sì gbọ́ nípàdé títí kan ìdáhùn táwọn fúnra wọn bá sọ máa mú kí wọ́n túbọ̀ mọ Jèhófà, kí wọ́n sì dọ̀rẹ́ rẹ̀. (Di 31:​12, 13) Tó o bá jẹ́ òbí, kí lo lè ṣe kí àwọn ìpàdé wa lè túbọ̀ ṣe ọmọ rẹ láǹfààní?

  • Ṣe gbogbo ohun tó o lè ṣe láti máa wá sípàdé lójúkojú.—Sm 22:22

  • Tètè máa dé sípàdé, má sì máa kánjú lọ sílé kó o lè ráyè bá àwọn ará sọ̀rọ̀.—Heb 10:25

  • Rí i dájú pé ẹnì kọ̀ọ̀kan yín ní àwọn ìwé tẹ́ ẹ máa lò nípàdé, ì báà jẹ́ tórí ìwé tàbí torí ẹ̀rọ

  • Ran ọmọ rẹ lọ́wọ́ kó lè múra ìdáhùn sílẹ̀ lọ́rọ̀ ara ẹ̀.—Mt 21:15, 16

  • Máa sọ ohun tó dáa nípa àwọn ìpàdé wa àtohun tá à ń kọ́ níbẹ̀

  • Jẹ́ kí ọmọ rẹ máa lọ́wọ́ nínú ìmọ́tótó Ilé Ìpàdé, kí wọ́n sì máa bá àwọn àgbàlagbà sọ̀rọ̀ nínú ìjọ

Iṣẹ́ ńlá ló gbà kéèyàn tó lè ran ọmọ kan lọ́wọ́ láti sún mọ́ Jèhófà, iṣẹ́ yẹn sì lè kà ẹ́ láyà nígbà míì. Àmọ́ jẹ́ kó dá ẹ lójú pé Jèhófà máa ràn ẹ́ lọ́wọ́.—Ais 40:29.

Ẹ WO FÍDÍÒ Ẹ̀YIN ÒBÍ, Ẹ GBÁRA LÉ JÈHÓFÀ KÓ LÈ FÚN YÍN LÓKUN, KẸ́ Ẹ SÌ DÁHÙN ÀWỌN ÌBÉÈRÈ YÌÍ:

  • Ìṣòro wo ni Zack àti Leah ní lẹ́yìn tí wọ́n bímọ?

  • Kí nìdí tó fi yẹ káwọn òbí bẹ Jèhófà pé kó fún àwọn lókun?

  • Àwọn nǹkan wo ni Zack àti Leah ṣe tó fi hàn pé wọ́n gbára lé Jèhófà kó lè ràn wọ́n lọ́wọ́?