Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

ÀPILẸ̀KỌ FÚN ÌKẸ́KỌ̀Ọ́ 2

O Lè Jẹ́ “Orísun Ìtùnú” Fáwọn Míì

O Lè Jẹ́ “Orísun Ìtùnú” Fáwọn Míì

Àwọn yìí la jọ ń ṣiṣẹ́ fún Ìjọba Ọlọ́run, wọ́n sì ti di orísun ìtùnú fún mi gan-an.’​KÓL. 4:11.

ORIN 90 Ẹ Máa Gba Ara Yín Níyànjú

OHUN TÁ A MÁA JÍRÒRÒ *

1. Ìṣòro wo ló ń kó ìdààmú ọkàn bá àwọn ará wa lóde òní?

Ọ̀PỌ̀ àwọn ará wa ló ń kojú onírúurú ìṣòro, bóyá ni ibì kan wà láyé yìí tí nǹkan ti dẹrùn, àwọn ìṣòro ọ̀hún ń kó ẹ̀dùn ọkàn báni, wọ́n sì ń tánni lókun. Báwo ni nǹkan ṣe rí nínú ìjọ tó o wà? Àìsàn tó lágbára tàbí àìsàn ọlọ́jọ́ pípẹ́ ló ń bá àwọn kan fínra, nígbà táwọn míì ń ṣọ̀fọ̀ èèyàn wọn tó kú. Ohun tó ń ba àwọn míì nínú jẹ́ ni ti èèyàn wọn tí kò sin Jèhófà mọ́. Ní tàwọn míì, àjálù tó ṣẹlẹ̀ àti ràbọ̀ràbọ̀ ẹ̀ ló ń fa ẹ̀dùn ọkàn fún wọn. Ó ṣe kedere pé àwọn ará wa yìí nílò ìtùnú, àbí bẹ́ẹ̀ kọ́? Ìbéèrè náà ni pé, kí la lè ṣe láti tù wọ́n nínú?

2. Kí nìdí tí àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù fi nílò ìtùnú?

2 Ẹ rántí pé ọ̀pọ̀ ìgbà ni àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù náà kojú onírúurú ìṣòro tó fẹ́rẹ̀ẹ́ gba ẹ̀mí ẹ̀. (2 Kọ́r. 11:23-28) Ó tún fara da ohun tó pè ní ‘ẹ̀gún kan nínú ara rẹ̀,’ tó ṣeé ṣe kó jẹ́ ìṣòro àìlera. (2 Kọ́r. 12:7) Bákan náà, ìdààmú bá a nígbà tí Démà tí wọ́n jọ ń ṣiṣẹ́ pa á tì, “torí [Démà] nífẹ̀ẹ́ ètò àwọn nǹkan yìí.” (2 Tím. 4:10) Ẹni àmì òróró tó nígboyà ni Pọ́ọ̀lù, ó sì máa ń fara ẹ̀ jìn fáwọn míì. Síbẹ̀ àwọn ìgbà kan wà tóun náà rẹ̀wẹ̀sì.​—Róòmù 9:1, 2.

3. Àwọn wo ló dúró ti Pọ́ọ̀lù tí wọ́n sì tù ú nínú?

3 Kí ló ran Pọ́ọ̀lù lọ́wọ́ tí kò fi bọ́hùn? Kò sí àní-àní pé Jèhófà fún un lókun nípasẹ̀ ẹ̀mí mímọ́ rẹ̀. (2 Kọ́r. 4:7; Fílí. 4:13) Yàtọ̀ síyẹn, Jèhófà tún lo àwọn onígbàgbọ́ bíi tiẹ̀ láti tù ú nínú. Nígbà tí Pọ́ọ̀lù ń sọ̀rọ̀ nípa àwọn tí wọ́n jọ ṣiṣẹ́, ó ní wọ́n jẹ́ “orísun ìtùnú fún [òun] gan-an.” (Kól. 4:11) Lára àwọn tó dárúkọ ni Àrísítákọ́sì, Tíkíkù àti Máàkù. Wọ́n ran Pọ́ọ̀lù lọ́wọ́, wọ́n tù ú nínú, wọ́n sì mú kó lè fara da àwọn ìṣòro rẹ̀. Ànímọ́ wo làwọn arákùnrin yẹn ní tó mú kí wọ́n lè fún Pọ́ọ̀lù níṣìírí tí ara sì tù ú? Bíi tiwọn, kí làwa náà lè ṣe táá mú ká lè máa fún àwọn míì níṣìírí kára sì tù wọ́n?

JẸ́ ADÚRÓṢINṢIN BÍI TI ÀRÍSÍTÁKỌ́SÌ

Bíi ti Àrísítákọ́sì, àwa náà lè jẹ́ ọ̀rẹ́ gidi fáwọn ará wa lọ́kùnrin àti lóbìnrin tá a bá dúró tì wọ́n ní “ìgbà wàhálà” (Wo ìpínrọ̀ 4-5) *

4. Kí ni Àrísítákọ́sì ṣe fún Pọ́ọ̀lù tó fi hàn pé ọ̀rẹ́ gidi ni?

4 Ọ̀rẹ́ gidi ni Àrísítákọ́sì ará Makedóníà jẹ́ fún Pọ́ọ̀lù. Ìgbà àkọ́kọ́ tí Bíbélì mẹ́nu kan Àrísítákọ́sì nìgbà tí Pọ́ọ̀lù wà lẹ́nu ìrìn àjò míṣọ́nnárì rẹ̀ ẹlẹ́ẹ̀kẹta tó sì ṣèbẹ̀wò sí Éfésù. Lásìkò tí Pọ́ọ̀lù wà ní Éfésù, àwọn èèyàn dá rúgúdù sílẹ̀, wọ́n sì mú Àrísítákọ́sì. (Ìṣe 19:29) Lẹ́yìn tó jàjàbọ́ lọ́wọ́ àwọn èèyànkéèyàn náà, kò wá ibi tó lè forí pa mọ́ sí, kàkà bẹ́ẹ̀ ṣe ló tún ń bá Pọ́ọ̀lù ṣiṣẹ́. Oṣù mélòó kan lẹ́yìn náà, a tún gbọ́ pé Àrísítákọ́sì wà pẹ̀lú Pọ́ọ̀lù nílùú Gíríìsì bó tiẹ̀ jẹ́ pé àwọn alátakò ń wá bí wọ́n ṣe máa gbẹ̀mí Pọ́ọ̀lù. (Ìṣe 20:2-4) Nígbà tó fi máa dọdún 58 Sànmánì Kristẹni, wọ́n ní kí Pọ́ọ̀lù lọ ṣẹ̀wọ̀n ní Róòmù. Kò ní yà yín lẹ́nu pé Àrísítákọ́sì wà lára àwọn tó bá Pọ́ọ̀lù rìnrìn àjò tó jìnnà yẹn, òun náà wà ńbẹ̀ nígbà tí ọkọ̀ ojú omi wọn rì. (Ìṣe 27:1, 2, 41) Nígbà tí wọ́n dé Róòmù, kò fi Pọ́ọ̀lù sílẹ̀, kódà ó wà pẹ̀lú rẹ̀ nínú ẹ̀wọ̀n yẹn fúngbà díẹ̀. (Kól. 4:10) Abájọ tí Pọ́ọ̀lù fi sọ pé orísun ìṣírí ló jẹ́ fún òun, ó jẹ́ ọ̀rẹ́ tí ń dúró tini nígbà ìṣòro!

5. Òwe 17:17 ṣe sọ, báwo la ṣe lè jẹ́ ọ̀rẹ́ gidi?

5 Bíi ti Àrísítákọ́sì, àwa náà lè jẹ́ ọ̀rẹ́ tí ń dúró tini fáwọn ará wa lọ́kùnrin àti lóbìnrin nígbà dídùn àti ní “ìgbà wàhálà.” (Ka Òwe 17:17.) Àwọn ará wa ṣì lè nílò ìtùnú kódà lẹ́yìn tí wọ́n bá ti la ìṣòro tó ń bá wọn fínra kọjá. Àpẹẹrẹ Arábìnrin Frances * jẹ́ ká rídìí tá a fi sọ bẹ́ẹ̀. Àárín oṣù mẹ́ta síra làwọn òbí rẹ̀ méjèèjì kú nítorí àrùn jẹjẹrẹ. Nígbà tó ń sọ bí nǹkan ṣe rí lára ẹ̀ àti báwọn ará ṣe ràn án lọ́wọ́, ó sọ pé: “Ẹ̀dùn ọkàn tá a ní kò lọ bọ̀rọ̀. Torí náà, mo mọyì báwọn ará ṣe dúró tì mí, bó tiẹ̀ jẹ́ pé ó ti ṣe díẹ̀ táwọn òbí mi ti kú, wọ́n kíyè sí i pé ọgbẹ́ ọkàn mi ò tíì jinná, ìyẹn ni ò jẹ́ kí wọ́n fi mí sílẹ̀. Ọ̀rẹ́ gidi ni wọ́n lóòótọ́.”

6. Tá a bá jẹ́ ọ̀rẹ́ gidi, kí la máa ṣe?

6 Àwọn ọ̀rẹ́ tó ń dúró tini nígbà ìṣòro máa ń fi ara wọn jìn nítorí àwọn arákùnrin àtàwọn arábìnrin wọn. Bí àpẹẹrẹ, lẹ́yìn tí wọ́n ṣàyẹ̀wò fún arákùnrin kan tó ń jẹ́ Peter, dókítà sọ fún un pé ó ní àìsàn burúkú kan tó máa tó gbẹ̀mí ẹ̀. Kathryn ìyàwó rẹ̀ sọ pé: “Tọkọtaya kan tá a jọ wà nínú ìjọ ló gbé wa lọ sílé ìwòsàn tí wọ́n ti ṣe àyẹ̀wò fún ọkọ mi. Ojú ẹsẹ̀ níbẹ̀ ni wọ́n ti pinnu pé àwọn ò ní dá wa dá ìṣòro náà, pé àwọn á dúró tì wá, ohun tí wọ́n sì ṣe gan-an nìyẹn torí pé wọn ò fi wá sílẹ̀ rárá.” Ẹ wo bó ṣe máa tuni lára tó téèyàn bá ní àwọn ọ̀rẹ́ tó ń dúró tini nígbà ìṣòro!

BÍI TÍKÍKÙ, JẸ́ ẸNI TÓ ṢEÉ FỌKÀN TÁN

Bíi Tíkíkù, a lè fi hàn pé a jẹ́ ọ̀rẹ́ tó ṣeé fọkàn tán lásìkò táwọn míì bá wà nínú ìṣòro (Wo ìpínrọ̀ 7-9) *

7-8. Kí ni Kólósè 4:7-9 sọ tó jẹ́ ká mọ̀ pé Tíkíkù ṣeé fọkàn tán?

7 Agbègbè Éṣíà ni Kristẹni kan tó ń jẹ́ Tíkíkù ti wá, alábàáṣiṣẹ́ tó ṣeé gbára lé ló sì jẹ́ fún Pọ́ọ̀lù. (Ìṣe 20:4) Ní nǹkan bí ọdún 55 Sànmánì Kristẹni, Pọ́ọ̀lù ṣètò báwọn Kristẹni tó wà lágbègbè yẹn ṣe máa kówó jọ kí wọ́n sì fi í ránṣẹ́ sáwọn Kristẹni tó wà ní Jùdíà láti dín ìṣòro wọn kù. Ó sì ṣeé ṣe kó jẹ́ pé Tíkíkù ni Pọ́ọ̀lù gbé iṣẹ́ ńlá yẹn fún. (2 Kọ́r. 8:18-20) Ẹ̀yìn ìyẹn ni wọ́n fi Pọ́ọ̀lù sẹ́wọ̀n fúngbà àkọ́kọ́ ní Róòmù, ní gbogbo àsìkò yẹn Tíkíkù wà pẹ̀lú rẹ̀, ó sì ń ràn án lọ́wọ́. Òun náà ló fi àwọn lẹ́tà àti ọ̀rọ̀ ìṣírí tí Pọ́ọ̀lù kọ sáwọn ìjọ tó wà ní Éṣíà jíṣẹ́.​—Kól. 4:7-9.

8 Ọ̀rẹ́ tó ṣeé gbára lé tó sì ṣeé fọkàn tán ni Tíkíkù jẹ́ sí Pọ́ọ̀lù. (Títù 3:12) Àmọ́, kì í ṣe gbogbo àwọn Kristẹni tó wà nígbà yẹn ló dà bíi Tíkíkù. Bí àpẹẹrẹ, ní nǹkan bíi 65 Sànmánì Kristẹni, ìyẹn lásìkò tí Pọ́ọ̀lù ń ṣẹ̀wọ̀n ẹlẹ́ẹ̀kejì nílùú Róòmù, ó sọ pé ńṣe làwọn Kristẹni tó wà lágbègbè Éṣíà pa òun tì, bóyá nítorí ìbẹ̀rù àwọn alátakò. (2 Tím. 1:15) Àmọ́ Tíkíkù ọ̀rẹ́ rẹ̀ kò fi í sílẹ̀, kódà Pọ́ọ̀lù tún gbé iṣẹ́ ńlá míì fún un. (2 Tím. 4:12) Ó dájú pé Pọ́ọ̀lù mọyì Tíkíkù ọ̀rẹ́ rẹ̀ yìí gan-an.

9. Báwo la ṣe lè fara wé Tíkíkù?

9 Àwa náà lè dà bíi Tíkíkù tá a bá jẹ́ ọ̀rẹ́ tó ṣeé fọkàn tán, tó sì ṣeé gbára lé. Bí àpẹẹrẹ, ó dáa ká ṣèlérí fáwọn ará wa lọ́kùnrin àti lóbìnrin pé a máa ràn wọ́n lọ́wọ́, àmọ́ kò yẹ ká fi mọ ní ọ̀rọ̀ ẹnu nìkan. Ó tún yẹ ká ṣe àwọn nǹkan pàtó láti ràn wọ́n lọ́wọ́. (Mát. 5:37; Lúùkù 16:10) Táwọn tó nílò ìrànwọ́ bá mọ̀ pé àwọn lè gbára lé wa, ọkàn wọn á balẹ̀, ara á sì tù wọ́n. Ẹ gbọ́ ohun tí arábìnrin kan sọ lórí kókó yìí, ó ní: “Kò sí pé èèyàn ń ṣàníyàn bóyá onítọ̀hún máa wá tàbí kò ní wá, ọkàn wa balẹ̀ pé á dé lásìkò.”

10. Bó ṣe wà nínú Òwe 18:24, ta ló lè tu àwọn tó níṣòro nínú?

10 Ọkàn àwọn tó níṣòro máa ń balẹ̀ tí wọ́n bá rẹ́ni fọkàn tán, tí wọ́n á sì sọ tinú wọn fún. (Ka Òwe 18:24.) Arákùnrin kan tó ń jẹ́ Bijay sọ bí nǹkan ṣe rí lára ẹ̀ lẹ́yìn tí wọ́n yọ ọmọkùnrin rẹ̀ lẹ́gbẹ́, ó ní: “Ó ń ṣe mí bíi kí n rẹ́ni tó ṣeé fọkàn tán tí màá sọ ẹ̀dùn ọkàn mi fún.” Ẹlòmíì ni Arákùnrin Carlos tó pàdánù àǹfààní iṣẹ́ ìsìn rẹ̀ torí àṣìṣe kan tó ṣe. Òun náà sọ pé: “Mo nílò ẹni tó ṣeé finú hàn, tí màá lè sọ ìṣòro mi fún, táá sì tù mí nínú láìkàn mí lábùkù.” Ǹjẹ́ Arákùnrin Carlos rẹ́ni tó ṣeé fọkàn tán? Bẹ́ẹ̀ ni, àwọn alàgbà ìjọ rẹ̀ ràn án lọ́wọ́ gan-an láti borí ẹ̀dùn ọkàn rẹ̀. Yàtọ̀ síyẹn, ọkàn ẹ̀ tún balẹ̀ pé àwọn alàgbà kò ní sọ̀rọ̀ náà fún ẹlòmíì.

11. Báwo la ṣe lè fi hàn pé ọ̀rẹ́ gidi ni wá àti pé a ṣeé finú hàn?

11 Tá a bá fẹ́ jẹ́ ọ̀rẹ́ gidi àti ẹni tó ṣeé finú hàn, ó ṣe pàtàkì pé ká jẹ́ onísùúrù. Lẹ́yìn tí ọkọ Arábìnrin Zhanna kọ̀ ọ́ sílẹ̀, ọkàn ẹ̀ gbọgbẹ́ gan-an. Àmọ́ lẹ́yìn tó sọ bí nǹkan ṣe rí lára ẹ̀ fáwọn ọ̀rẹ́ ẹ̀, ọkàn ẹ̀ balẹ̀. Ó sọ pé: “Wọ́n fara balẹ̀ tẹ́tí sí mi, wọ́n sì mú sùúrù fún mi bó tiẹ̀ jẹ́ pé ohun kan náà ni mò ń sọ lásọtúnsọ.” Ìwọ náà lè fi hàn pé ọ̀rẹ́ gidi ni ẹ́ tó o bá ń fara balẹ̀ tẹ́tí sáwọn tó níṣòro, tó o sì ń mú sùúrù fún wọn.

BÍI TI MÁÀKÙ, MÚRA TÁN LÁTI ṢIṢẸ́ SIN ÀWỌN MÍÌ

Àwọn nǹkan tí Máàkù ṣe mú kí Pọ́ọ̀lù lè fara da àwọn ìṣòro rẹ̀, àwa náà lè ran àwọn ará wa lọ́wọ́ nígbà àjálù (Wo ìpínrọ̀ 12-14) *

12. Ta ni Máàkù, báwo la ṣe mọ̀ pé ó máa ń wù ú láti ṣiṣẹ́ sin àwọn míì?

12 Júù tó di Kristẹni ni Máàkù, ìlú Jerúsálẹ́mù ló sì ń gbé. Míṣọ́nnárì táwọn èèyàn mọ̀ bí ẹni mowó ni Bánábà ìbátan rẹ̀. (Kól. 4:10) Ó jọ pé àwọn òbí Máàkù rí jájẹ, síbẹ̀ kì í ṣe ọ̀rọ̀ owó àtàwọn ohun ìní ló gba Máàkù lọ́kàn. Àtìgbà tí Máàkù ti wà lọ́dọ̀ọ́ ló ti hàn pé ó lẹ́mìí tó dáa, inú ẹ̀ sì máa ń dùn láti ṣiṣẹ́ sin àwọn míì. Bí àpẹẹrẹ, àwọn ìgbà kan wà tó bá àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù àti Pétérù ṣiṣẹ́, tó sì ràn wọ́n lọ́wọ́ láti ṣe àwọn nǹkan, bíi kó bá wọn ra oúnjẹ, kó wá ibi tí wọ́n lè dé sí àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ. (Ìṣe 13:2-5; 1 Pét. 5:13) Máàkù wà lára àwọn tí Pọ́ọ̀lù dárúkọ pé àwọn “jọ ń ṣiṣẹ́ fún Ìjọba Ọlọ́run,” ó sì tún sọ pé wọ́n jẹ́ “àrànṣe afúnnilókun” tàbí orísun ìtùnú fún òun.​—Kól. 4:​10, 11, àlàyé ìsàlẹ̀.

13. Kí ló wà nínú 2 Tímótì 4:11 tó fi hàn pé Pọ́ọ̀lù mọyì ìrànwọ́ tí Máàkù ṣe fún un?

13 Kò sí àní-àní pé Máàkù wà lára àwọn ọ̀rẹ́ tímọ́tímọ́ tí Pọ́ọ̀lù ní. Bí àpẹẹrẹ, lásìkò tí Pọ́ọ̀lù wà lẹ́wọ̀n fúngbà ìkẹyìn nílùú Róòmù, ìyẹn ní nǹkan bíi 65 Sànmánì Kristẹni, ó kọ lẹ́tà rẹ̀ kejì sí Tímótì. Nínú lẹ́tà yẹn, ó sọ pé kí Tímótì wá bá òun ní Róòmù, kó sì mú Máàkù dání. (2 Tím. 4:11) Ó ṣe kedere pé Pọ́ọ̀lù mọyì àwọn ohun tí Máàkù ti ṣe sẹ́yìn, ó sì fẹ́ kó wà pẹ̀lú òun lásìkò tí nǹkan nira yẹn. Máàkù ṣèrànwọ́ fún Pọ́ọ̀lù lónírúurú ọ̀nà, bóyá kó bá a ra oúnjẹ tàbí àwọn nǹkan tí Pọ́ọ̀lù fi ń kọ̀wé. Ó dájú pé ìrànlọ́wọ́ tí wọ́n ṣe fún Pọ́ọ̀lù yẹn máa fún un níṣìírí gan-an, á sì jẹ́ kó rọrùn fún un láti fara dà á kí wọ́n tó pa á.

14-15. Báwo lohun tó wà nínú Mátíù 7:12 ṣe jẹ́ ká mọ ohun tá a lè ṣe láti ran àwọn míì lọ́wọ́?

14 Ka Mátíù 7:12Ẹ wo bí inú wa ṣe máa dùn tó táwọn èèyàn bá dúró tì wá nígbà ìṣòro tí wọ́n sì ràn wá lọ́wọ́! Arákùnrin Ryan tí bàbá rẹ̀ kú lójijì nínú ìjàǹbá ọkọ̀ kan sọ pé: “Téèyàn bá wà nínú ìṣòro, àwọn nǹkan téèyàn máa ń ṣe lójoojúmọ́ pẹ̀lú ìrọ̀rùn á wá dogun. Torí náà, a máa ń mọyì ẹ̀ gan-an tá a bá rẹ́ni ràn wá lọ́wọ́ láti ṣe àwọn nǹkan, kódà kó tiẹ̀ jẹ́ àwọn nǹkan tí kò fi bẹ́ẹ̀ jọjú.”

15 Tá a bá ní àkíyèsí tá a sì sún mọ́ àwọn tó níṣòro, ó ṣeé ṣe ká mọ àwọn ohun pàtó tí wọ́n nílò àti ọ̀nà tá a lè gbà ràn wọ́n lọ́wọ́. Bí àpẹẹrẹ, arábìnrin kan kíyè sí i pé Peter àti Kathryn tá a sọ̀rọ̀ wọn lẹ́ẹ̀kan nílò ẹni táá máa gbé wọn lọ sílé ìwòsàn. Tọkọtaya náà kò lè wa mọ́tò mọ́, torí náà arábìnrin yẹn ṣètò pẹ̀lú àwọn míì nínú ìjọ, oníkálukú wọn sì mú ọjọ́ táá máa gbé tọkọtaya náà lọ rí dókítà. Báwo ni ètò náà ṣe rí lára tọkọtaya yẹn? Kathryn sọ pé, “Ṣe ni wọ́n sọ ohun tó dà bí òkè ìṣòro wa di pẹ̀tẹ́lẹ̀, ara tù wá gan-an.” Torí náà, má ṣe fojú kéré ohun tó o lè ṣe láti tu àwọn tó níṣòro nínú, bó ti wù kó kéré mọ.

16. Kí la rí kọ́ nínú àpẹẹrẹ Máàkù?

16 Ó ṣe kedere pé ọwọ́ Máàkù tó jẹ́ ọmọ ẹ̀yìn Jésù ní ọgọ́rùn-ún ọdún kìíní dí gan-an. Ó ní àwọn ojúṣe tí Jèhófà fi síkàáwọ́ ẹ̀ tó ń bójú tó, títí kan ìwé Ìhìn Rere tí Jèhófà mí sí i láti kọ. Pẹ̀lú gbogbo ìyẹn náà, Máàkù wáyè láti tu Pọ́ọ̀lù nínú, ìyẹn sì mú kó rọrùn fún Pọ́ọ̀lù láti rán an níṣẹ́. Ọgbẹ́ ọkàn tó lágbára ni arábìnrin kan tó ń jẹ́ Angela ní látàrí báwọn ìkà ẹ̀dá ṣe pa ìyá-ìyá rẹ̀ ní ìpakúpa. Nígbà tó ń sọ bó ṣe mọyì àwọn ará tó wá tù ú nínú, ó sọ pé: “Àwọn ọ̀rẹ́ tó múra tán láti ṣèrànwọ́ máa ń rọrùn bá sọ̀rọ̀. Ó hàn lójú wọn pé wọ́n bá mi kẹ́dùn, wọn ò sì lọ́ tìkọ̀ rárá láti ràn mí lọ́wọ́.” Torí náà, ó yẹ ká bi ara wa pé: ‘Ṣé ó máa ń yá mi lára láti tu àwọn ará lọ́kùnrin àti lóbìnrin nínú, ṣé mo sì máa ń ṣèrànwọ́ fún wọn? Ṣérú ẹni táwọn èèyàn mọ̀ mí sí nìyẹn?’

PINNU PÉ WÀÁ MÁA TU ÀWỌN MÍÌ NÍNÚ

17. Tá a bá ronú jinlẹ̀ lórí 2 Kọ́ríńtì 1:3, 4, báwo nìyẹn ṣe lè mú kó máa wù wá láti tu àwọn míì nínú?

17 Kò dìgbà tá a bá lọ sí ìjọ míì ká tó rí àwọn ará lọ́kùnrin àti lóbìnrin tí wọ́n nílò ìtùnú, wọ́n wà nínú ìjọ wa náà. A lè lo ọ̀rọ̀ táwọn kan fi tù wá nínú láti tu àwọn míì nínú. Arábìnrin Nino tí ìyá-ìyá rẹ̀ kú sọ pé: “Jèhófà lè lò wá láti tu àwọn míì nínú, ìyẹn tá a bá jẹ́ kó lò wá.” (Ka 2 Kọ́ríńtì 1:3, 4.) Arábìnrin Frances tá a sọ̀rọ̀ ẹ̀ lẹ́ẹ̀kan sọ pé: “Òótọ́ lọ̀rọ̀ tó wà nínú 2 Kọ́ríńtì 1:4. A lè lo ọ̀nà táwọn èèyàn gbà tù wá nínú láti tu àwọn míì náà nínú.”

18. (a) Kí ló ń ba àwọn kan lẹ́rù? (b) Báwo la ṣe lè tu àwọn míì nínú? Sọ àpẹẹrẹ kan.

18 Bí ẹ̀rù bá tiẹ̀ ń bà wá, a ṣì lè wọ́nà láti tu àwọn míì nínú. Bí àpẹẹrẹ, a lè máa ronú pé kí la mọ̀ tá a fẹ́ sọ tàbí kí la lè ṣe fún ẹni tó wà nínú ìṣòro. Alàgbà kan tó ń jẹ́ Paul rántí bí àwọn ará ṣe sapá láti tù ú nínú lẹ́yìn ikú bàbá rẹ̀. Ó sọ pé: “Mo kíyè sí i pé kò rọrùn fún wọn torí pé wọn ò mọ ohun tí wọ́n máa sọ. Síbẹ̀, mo mọrírì gbogbo ìsapá wọn, bí wọ́n ṣe dúró tì mí tí wọ́n sì tù mí nínú.” Bọ́rọ̀ ṣe rí náà nìyẹn fún Arákùnrin Tajon táwọn ará tù nínú lẹ́yìn ìmìtìtì ilẹ̀ kan tó ṣẹlẹ̀. Ó ní: “Ká sòótọ́, bóyá ni mo lè rántí gbogbo ọ̀rọ̀ táwọn ará kọ ránṣẹ́ sí mi lẹ́yìn tí ìṣẹ̀lẹ̀ yẹn wáyé, àmọ́ mo rántí dáadáa pé tọmọdé tàgbà ló béèrè mi, tí wọ́n sì fẹ́ mọ bí nǹkan ṣe rí lára mi.” Àwa náà lè jẹ́ orísun ìtùnú fáwọn tó níṣòro tá a bá fi hàn pé a nífẹ̀ẹ́ wọn.

19. Kí nìdí tó o fi pinnu pé wàá jẹ́ “orísun ìtùnú” fáwọn míì?

19 Bí òpin ayé burúkú yìí ṣe túbọ̀ ń sún mọ́lé, bẹ́ẹ̀ ni nǹkan á túbọ̀ máa nira tí ayé náà á sì ṣòro gbé. (2 Tím. 3:13) Yàtọ̀ síyẹn, àwọn ìṣòro tó ń dé bá wa nítorí àìpé ẹ̀dá àti ẹ̀ṣẹ̀ tá a jogún máa mú kó pọn dandan pé káwọn míì tù wá nínú. Lára ohun tó mú kó ṣeé ṣe fún àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù láti fara dà á títí dójú ikú ni báwọn onígbàgbọ́ bíi tiẹ̀ ṣe gbárùkù tì í, tí wọ́n sì tù ú nínú. Torí náà, ẹ jẹ́ ká jẹ́ adúrótini bíi ti Àrísítákọ́sì, ká jẹ́ni tó ṣeé fọkàn tán bíi Tíkíkù, ká sì múra tán láti ran àwọn míì lọ́wọ́ bíi ti Máàkù. Tá a bá ṣe bẹ́ẹ̀, àá lè ran àwọn ará wa lọ́kùnrin àti lóbìnrin lọ́wọ́ kí wọ́n lè di ìgbàgbọ́ wọn mú bó ti wù kí nǹkan nira tó.​—1 Tẹs. 3:2, 3.

^ ìpínrọ̀ 5 Onírúurú ìṣòro ni àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù dojú kọ lẹ́nu iṣẹ́ òjíṣẹ́ rẹ̀. Lásìkò tí gbogbo nǹkan nira fún un yẹn, orísun ìtùnú làwọn tí wọ́n jọ ṣiṣẹ́ jẹ́ fún un. Nínú àpilẹ̀kọ yìí, a máa jíròrò àwọn ànímọ́ mẹ́ta tó jẹ́ káwọn alábàáṣiṣẹ́ rẹ̀ jẹ́ orísun ìtùnú fún un. A sì tún máa sọ̀rọ̀ nípa báwa náà ṣe lè jẹ́ orísun ìtùnú bíi tiwọn.

^ ìpínrọ̀ 5 A ti yí àwọn orúkọ kan nínú àpilẹ̀kọ yìí pa dà.

ORIN 111 Ohun Tó Ń Fún Wa Láyọ̀

^ ìpínrọ̀ 56 ÀWÒRÁN: Àrísítákọ́sì àti Pọ́ọ̀lù rèé lójú omi nígbà tí ọkọ̀ wọn rì.

^ ìpínrọ̀ 58 ÀWÒRÁN: Pọ́ọ̀lù fọkàn tán Tíkíkù, ó sì ní kó bá òun fi lẹ́tà jíṣẹ́ fáwọn ìjọ.

^ ìpínrọ̀ 60 ÀWÒRÁN: Máàkù yọ̀ǹda ara rẹ̀ láti ṣèrànwọ́ fún Pọ́ọ̀lù.