Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

ÀPILẸ̀KỌ FÚN ÌKẸ́KỌ̀Ọ́ 3

Jèhófà Nífẹ̀ẹ́ Rẹ, Ó sì Mọyì Ẹ Gan-an!

Jèhófà Nífẹ̀ẹ́ Rẹ, Ó sì Mọyì Ẹ Gan-an!

“Ó rántí wa nígbà tí wọ́n rẹ̀ wá sílẹ̀.”​—SM. 136:23.

ORIN 33 Ju Ẹrù Rẹ Sọ́dọ̀ Jèhófà

OHUN TÁ A MÁA JÍRÒRÒ *

1-2. Ìṣòro wo ni ọ̀pọ̀ àwọn ará wa ń dojú kọ, báwo ló sì ṣe rí lára wọn?

Ẹ JẸ́ ká wo àpẹẹrẹ mẹ́ta yìí: Dókítà ṣàyẹ̀wò arákùnrin ọ̀dọ́ kan, wọ́n sì rí i pé ó ní àìsàn tó lágbára. Iṣẹ́ bọ́ lọ́wọ́ arákùnrin kan tó ti lé lẹ́ni àádọ́ta (50) ọdún bó tiẹ̀ jẹ́ pé kì í fiṣẹ́ ṣeré. Ó gbìyànjú gbogbo ohun tó lè ṣe, síbẹ̀ kò rí iṣẹ́ míì. Arábìnrin àgbàlagbà kan tó ti ń fòótọ́ inú sin Jèhófà bọ̀ fún ọ̀pọ̀ ọdún kò lè ṣe tó bó ti ń ṣe tẹ́lẹ̀ nínú ìjọsìn Jèhófà torí ọjọ́ ogbó.

2 Ó ṣeé ṣe kó o máa dojú kọ ọ̀kan lára àwọn ìṣòro tá a sọ tán yìí. Tó bá rí bẹ́ẹ̀, o lè máa ronú pé o ò wúlò mọ́. Ìdí sì ni pé, àwọn ìṣòro yìí máa ń kó ẹ̀dùn ọkàn báni, ó sì lè mú kéèyàn máa fojú ẹni tí kò já mọ́ nǹkan kan wo ara rẹ̀ tàbí kó tiẹ̀ ba àjọṣe téèyàn ní pẹ̀lú àwọn míì jẹ́.

3. Ojú wo ni Sátánì àtàwọn tó ń darí fi ń wo àwa èèyàn?

3 Ojú tí Sátánì fi ń wo ẹ̀mí èèyàn làwọn èèyàn ayé yìí náà fi ń wò ó. Ọjọ́ pẹ́ tí Sátánì ti máa ń fojú àbùkù wò wá, ó gbà pé àwa èèyàn ò já mọ́ nǹkan kan. Bí àpẹẹrẹ, ó ṣèlérí fún Éfà pé nǹkan máa sàn fún wọn tí wọ́n bá ṣàìgbọràn sí Jèhófà, bó tiẹ̀ jẹ́ pé ó mọ̀ lọ́kàn ẹ̀ pé wọ́n máa kú. Ẹ ò rí i pé ìwà ìkà gbáà nìyẹn! Torí pé Sátánì ni alákòóso ayé yìí, òun ló ń darí ètò ìṣèlú, ètò ìṣòwò àtàwọn ìsìn. Abájọ tí ẹ̀mí àwọn èèyàn ò fi jọ àwọn olóṣèlú, àwọn oníṣòwò àtàwọn onísìn lójú, wọn ò sì bìkítà nípa ẹnikẹ́ni.

4. Kí la máa jíròrò nínú àpilẹ̀kọ yìí?

4 Àmọ́, Ọlọ́run ìfẹ́ ni Jèhófà Baba wa ọ̀run, kò fẹ́ ká máa ronú pé a ò já mọ́ nǹkan kan, kódà ó ń ràn wá lọ́wọ́ tá a bá níṣòro. (Sm. 136:23; Róòmù 12:3) Nínú àpilẹ̀kọ yìí, a máa sọ̀rọ̀ nípa bí Jèhófà ṣe ń ràn wá lọ́wọ́ nígbà: (1) tá a bá ń ṣàìsàn, (2) tọ́rọ̀ àtijẹ àtimu bá nira torí pé a ò lówó lọ́wọ́ àti (3) tí ìṣòro ọjọ́ ogbó bá mú ká ronú pé a ò wúlò mọ́ fún Jèhófà. Lákọ̀ọ́kọ́ ná, ẹ jẹ́ ká jíròrò ìdí tó fi yẹ kó dá wa lójú pé Jèhófà mọyì wa.

JÈHÓFÀ MỌYÌ WA GAN-AN

5. Kí ló jẹ́ kó dá ẹ lójú pé Jèhófà mọyì rẹ gan-an?

5 Bó tiẹ̀ jẹ́ pé erùpẹ̀ ni Jèhófà fi dá àwa èèyàn, kò fojú eruku lásán-làsàn wò wá. (Jẹ́n. 2:7) Ẹ jẹ́ ká wo ìdí mélòó kan tó jẹ́ ká mọ̀ pé a ṣeyebíye gan-an lójú Jèhófà. Ó dá àwa èèyàn ní àwòrán ara rẹ̀, lédè míì lọ́nà tá a fi lè gbé àwọn ànímọ́ rẹ̀ yọ. (Jẹ́n. 1:27) Lọ́nà yìí, ó mú ká yàtọ̀ pátápátá sáwọn nǹkan míì tó dá, ó sì fi wá jọba lórí àwọn ẹranko, ẹyẹ, ẹja àtàwọn nǹkan míì tó dá sáyé.​—Sm. 8:​4-8.

6. Sọ ìdí míì tó jẹ́ kó dá wa lójú pé Jèhófà mọyì àwa èèyàn, ó sì nífẹ̀ẹ́ wa gan-an.

6 Kódà lẹ́yìn tí Ádámù ṣàìgbọràn, Jèhófà ṣì fi hàn pé òun ò fọ̀rọ̀ wa ṣeré. Ó fi hàn pé òun mọyì wa, òun sì nífẹ̀ẹ́ wa gan-an nígbà tó yọ̀ǹda Jésù Ọmọ rẹ̀ ọ̀wọ́n pé kó kú torí ẹ̀ṣẹ̀ wa. (1 Jòh. 4:​9, 10) Ìràpadà tí Jésù san yìí ni Jèhófà máa wò mọ́ aráyé lára táá sì mú kó jí àwọn tó ti kú nítorí ẹ̀ṣẹ̀ Ádámù dìde, ìyẹn “àwọn olódodo àti àwọn aláìṣòdodo.” (Ìṣe 24:15) Bíbélì Ọ̀rọ̀ rẹ̀ fi dá wa lójú pé Jèhófà mọ àwọn ìṣòro tó ń bá wa fínra, bí àìlera, àìrówóná àti hẹ́gẹhẹ̀gẹ ọjọ́ ogbó. Síbẹ̀, ó mọyì wa, ó sì nífẹ̀ẹ́ wa gan-an.​—Ìṣe 10:​34, 35.

7. Àwọn ẹ̀rí míì wo ló mú kó dá wa lójú pé Jèhófà mọyì wa?

7 Ìdí míì tún wà tá a fi gbà pé Jèhófà mọyì wa gan-an. Òun ló fà wá sọ́dọ̀ ara rẹ̀ nípasẹ̀ ìhìn rere, ó sì kíyè sí i pé a nífẹ̀ẹ́ òtítọ́. (Jòh. 6:44) Bó ṣe di pé a bẹ̀rẹ̀ sí í sún mọ́ Jèhófà nìyẹn, òun náà sì túbọ̀ sún mọ́ wa. (Jém. 4:8) Torí pé Jèhófà nífẹ̀ẹ́ wa, ó máa ń lo okun rẹ̀ àti àkókò rẹ̀ láti kọ́ wa lẹ́kọ̀ọ́, ó sì máa ń tọ́ wa sọ́nà. Ó mọ irú ẹni tá a jẹ́ báyìí, ó sì tún mọ̀ pé a lè ṣe dáadáa sí i. Yàtọ̀ síyẹn, ó máa ń bá wa wí torí ìfẹ́ tó ní sí wa. (Òwe 3:​11, 12) Torí náà, ṣé àsọdùn ni tá a bá sọ pé Jèhófà mọyì wa, ó sì tún nífẹ̀ẹ́ wa gan-an? Kì í ṣe àsọdùn rárá, òótọ́ pọ́ńbélé ni!

8. Báwo lọ̀rọ̀ inú Sáàmù 18:​27-29 ṣe lè mú ká máa fojú tó tọ́ wo àwọn ìṣòro wa?

8 Ojú ẹni tí kò wúlò lọ̀pọ̀ fi wo Ọba Dáfídì, àmọ́ Dáfídì fúnra ẹ̀ mọ̀ pé Jèhófà nífẹ̀ẹ́ òun, ó sì ń ti òun lẹ́yìn. Èyí ló mú kí Dáfídì máa fojú tó tọ́ wo ìṣòro rẹ̀. (2 Sám. 16:​5-7) Tí ìbànújẹ́ bá dorí wa kodò tàbí tá a níṣòro, Jèhófà lè mú ká fojú tó tọ́ wo ohun tó ń ṣẹlẹ̀ sí wa, ó sì lè ràn wá lọ́wọ́ láti borí àwọn ìṣòro náà. (Ka Sáàmù 18:​27-29.) Lọ́lá ìtìlẹyìn Jèhófà, kò sóhun tó lè ba ayọ̀ wa jẹ́ nínú ìjọsìn rẹ̀. (Róòmù 8:31) Ní báyìí, ẹ jẹ́ ká jíròrò mẹ́ta lára àwọn ìṣòro tó lè mú ká rẹ̀wẹ̀sì àmọ́ tó máa gba pé ká rán ara wa létí pé Jèhófà nífẹ̀ẹ́ wa, ó sì mọyì wa gan-an.

TÁ A BÁ Ń ṢÀÌSÀN

Tá a bá ń ka Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run, àá lè borí ẹ̀dùn ọkàn tá a ní, àá sì lè fara da àìsàn tó ń ṣe wá (Wo ìpínrọ̀ 9-12)

9. Báwo ni àìsàn ṣe lè mú ká máa fojú tí kò tọ́ wo ara wa?

9 Èèyàn lè ní ẹ̀dùn ọkàn tó bá ń ṣàìsàn, ó sì lè mú kéèyàn gbà pé òun ò wúlò rárá. Ọkàn wa lè gbọgbẹ́ torí pé ara wa ò yá tàbí torí pé a ò lè dá ṣe nǹkan kan láìjẹ́ pé àwọn míì ràn wá lọ́wọ́. Àwọn míì tiẹ̀ lè má mọ̀ pé à ń ṣàìsàn, síbẹ̀ kí ojú máa tì wá nítorí pé agbára wa ti dín kù, a ò sì lè ṣe bíi ti tẹ́lẹ̀ mọ́. Láwọn àsìkò bẹ́ẹ̀, Jèhófà máa ń gbé wa ró, ó sì máa ń ràn wá lọ́wọ́. Ọ̀nà wo ló ń gbà ṣe bẹ́ẹ̀?

10. Kí ni Òwe 12:25 sọ tó lè ràn wá lọ́wọ́ nígbà tá a bá ń ṣàìsàn?

10 Tá a bá ń ṣàìsàn, “ọ̀rọ̀ rere” lè gbé wa ró. (Ka Òwe 12:25.) Tó o bá wo inú Bíbélì, wàá rí i pé àìmọye ìgbà ni Jèhófà sọ ọ̀rọ̀ rere tó ń fi wá lọ́kàn balẹ̀ pé òun nífẹ̀ẹ́ wa láìka ti àìsàn tó ń ṣe wá sí. (Sm. 31:19; 41:3) Torí náà, máa ka Bíbélì, kà á ní àkàtúnkà. Tó o bá ń ṣe bẹ́ẹ̀, Jèhófà máa mú kó o borí ẹ̀dùn ọkàn tó o ní, kó o sì fara da àìsàn tó ń ṣe ẹ́.

11. Báwo ni arákùnrin kan ṣe rí ọwọ́ Jèhófà láyé ẹ̀?

11 Ẹ jẹ́ ká wo àpẹẹrẹ arákùnrin kan tó ń jẹ́ Jorge. Nígbà tó wà lọ́dọ̀ọ́, ó ṣàìsàn kan tó lágbára tó mú kó gbà pé òun ò wúlò mọ́. Ó sọ pé: “Mi ò ronú ẹ̀ rí pé mo lè rẹ̀wẹ̀sì nítorí àìsàn tàbí pé ojú á máa tì mí táwọn èèyàn bá rí ohun tí àìsàn náà ti sọ mí dà. Bí àìsàn náà ṣe ń burú sí i, ẹ̀rù ń bà mí pé ìgbésí ayé mi máa dojú rú. Ẹ̀dùn ọkàn bá mi, mo sì bẹ Jèhófà kíkankíkan pé kó ràn mí lọ́wọ́.” Báwo ni Jèhófà ṣe ràn án lọ́wọ́? Arákùnrin Jorge sọ pé: “Torí pé mi ò kì í lè pọkàn pọ̀ tó bẹ́ẹ̀, wọ́n gbà mí níyànjú pé kí n máa ka ẹsẹ mélòó kan nínú Sáàmù, ìyẹn àwọn ẹsẹ tí Jèhófà fi sọ bóun ṣe nífẹ̀ẹ́ àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ gan-an. Àkàtúnkà ni mo máa ń ka àwọn ẹsẹ yẹn lójoojúmọ́, kí n sòótọ́ wọ́n tù mí nínú gan-an, wọ́n sì mú kí ọkàn mi balẹ̀. Kí n tó mọ̀, ìṣarasíhùwà mi ti yí pa dà, àwọn èèyàn sì kíyè sí i pé mò ń láyọ̀. Kódà, wọ́n sọ fún mi pé bí mo ṣe ń láyọ̀ láìka ìṣòro mi sí ń fún àwọn níṣìírí. Mo wá rí i pé Jèhófà dáhùn àdúrà mi! Ó ti mú kí n máa fojú tó tọ́ wo ara mi. Ní báyìí, mi ò rí ti àìsàn tó ń ṣe mí rò mọ́ bí kò ṣe ohun tí Bíbélì sọ nípa ojú tí Jèhófà fi ń wò mí.”

12. Báwo lo ṣe lè rí ọwọ́ Jèhófà láyé rẹ tó o bá ń ṣàìsàn?

12 Tó o bá ń ṣàìsàn, jẹ́ kó dá ẹ lójú pé Jèhófà mọ ohun tó ń ṣe ẹ́ àti bó ṣe rí lára ẹ. Bẹ̀ ẹ́ pé kó ràn ẹ́ lọ́wọ́ kó o lè máa fojú tó tọ́ wo ìṣòro rẹ. Lẹ́yìn náà, ka Bíbélì Ọ̀rọ̀ rẹ̀ kó o lè rí àwọn ọ̀rọ̀ tí Jèhófà sọ láti tù ẹ́ nínú. Ní pàtàkì, máa ronú lórí àwọn ẹsẹ tó fi hàn pé Jèhófà nífẹ̀ẹ́ àwa èèyàn rẹ̀, ó sì mọyì wa gan-an. Tó o bá ń ṣe bẹ́ẹ̀, wàá rí i pé adúrótini nígbà ìṣòro ni Jèhófà, kì í sì í fàwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ sílẹ̀.​—Sm. 84:11.

ÌṢÒRO ÀTIJẸ ÀTIMU

Tá a bá ń rántí ìlérí tí Jèhófà ṣe pé òun máa pèsè fún wa, àá lè fara dà á tí iṣẹ́ bá bọ́ lọ́wọ́ wa (Wo ìpínrọ̀ 13-15)

13. Báwo ló ṣe máa ń rí lára olórí ìdílé kan tí iṣẹ́ bá bọ́ lọ́wọ́ ẹ̀?

13 Àwọn olórí ìdílé máa ń ṣe gbogbo ohun tí wọ́n lè ṣe láti pèsè ohun tí ìdílé wọn nílò. Àmọ́ báwo ló ṣe máa rí lára olórí ìdílé kan tí iṣẹ́ bọ́ lọ́wọ́ ẹ̀ láìṣẹ̀ láìrò tàbí tí nǹkan ò lọ déédéé mọ́? Ó gbìyànjú títí síbẹ̀ kò ríṣẹ́ míì, ó sì lè jẹ́ pé iṣẹ́ tó ń ṣe ò fi bẹ́ẹ̀ mówó wọlé mọ́. Irú nǹkan yìí lè mú kó rẹ̀wẹ̀sì kó sì ronú pé òun ò wúlò. Nírú ipò yìí, àǹfààní wo ló máa rí tó bá ń ronú nípa àwọn ìlérí Jèhófà?

14. Kí nìdí tí Jèhófà fi máa ń mú àwọn ìlérí rẹ̀ ṣẹ?

14 Kò sígbà tí Jèhófà ṣèlérí tí kì í mú un ṣẹ. (Jóṣ. 21:45; 23:14) Ó sì nídìí tó fi máa ń ṣe bẹ́ẹ̀. Àkọ́kọ́, ó máa ń ṣe bẹ́ẹ̀ nítorí orúkọ rẹ̀ tàbí nítorí irú ẹni tó jẹ́. Jèhófà ṣèlérí pé òun á pèsè fáwọn tó ń fi gbogbo ọkàn sin òun, ó sì máa ń rí i dájú pé òun ṣe bẹ́ẹ̀. (Sm. 31:​1-3) Ìdí míì ni pé ara ìdílé Jèhófà ni wá, ó sì mọ̀ pé inú wa ò ní dùn tá ò bá rí ohun tá a nílò. Ẹ má sì gbàgbé ìlérí tó ṣe pé òun máa pèsè ohun tá a nílò nípa tara àti nípa tẹ̀mí, kò sì sí nǹkan tó lè ní kó má ṣe bẹ́ẹ̀!​—Mát. 6:​30-33; 24:45.

15. (a) Ìṣòro wo làwọn Kristẹni ọgọ́rùn-ún ọdún kìíní ní? (b) Ọ̀rọ̀ tó ń fini lọ́kàn balẹ̀ wo ló wà nínú Sáàmù 37:​18, 19?

15 Tá a bá ń ronú lórí ìdí tí Jèhófà fi máa ń mú ìlérí rẹ̀ ṣẹ, a ò ní fòyà tá a bá níṣòro àtijẹ àtimu. Ẹ jẹ́ ká wo àpẹẹrẹ àwọn Kristẹni ọgọ́rùn-ún ọdún kìíní. Nígbà tí ìjọ tó wà ní Jerúsálẹ́mù dojú kọ inúnibíni tó gbóná janjan, gbogbo àwọn ọmọ ẹ̀yìn ló tú ká àyàfi “àwọn àpọ́sítélì nìkan ni kò tú ká.” (Ìṣe 8:1) Kí lẹ rò pé ó máa ṣẹlẹ̀ sáwọn Kristẹni yẹn? Ó dájú pé àtijẹ àtimu á nira fún wọn gan-an! Ó ṣe tán, ọ̀pọ̀ wọn ti fi ilé àti iṣẹ́ wọn sílẹ̀. Síbẹ̀, Jèhófà ò gbàgbé wọn, bẹ́ẹ̀ làwọn náà sì ń láyọ̀. (Ìṣe 8:4; Héb. 13:​5, 6; Jém. 1:​2, 3) Ó dájú pé Jèhófà máa tì wá lẹ́yìn bó ṣe ti àwọn Kristẹni yẹn lẹ́yìn.​—Ka Sáàmù 37:​18, 19.

NÍGBÀ TÍ ARA BÁ Ń DI ARA ÀGBÀ

Tó bá jẹ́ pé gbogbo ohun tí agbára wa gbé là ń ṣe, bó tiẹ̀ jẹ́ pé ara ti ń dara àgbà, inú wa máa dùn pé Jèhófà nífẹ̀ẹ́ wa, ó sì mọyì ìṣòtítọ́ wa (Wo ìpínrọ̀ 16-18)

16. Kí ló lè mú ká ronú pé a ò fi bẹ́ẹ̀ wúlò mọ́ fún Jèhófà?

16 Bí ara ṣe túbọ̀ ń dara àgbà, a lè bẹ̀rẹ̀ sí í ronú pé a ò fi bẹ́ẹ̀ wúlò mọ́ fún Jèhófà. Ó ṣeé ṣe kí Ọba Dáfídì náà ronú bẹ́ẹ̀ bó ṣe ń darúgbó. (Sm. 71:9) Báwo ni Jèhófà ṣe lè ràn wá lọ́wọ́ nírú àsìkò yìí?

17. Kí la rí kọ́ nínú ìrírí Arábìnrin Jheri?

17 Ẹ jẹ́ ká wo ìrírí arábìnrin kan tó ń jẹ́ Jheri. Wọ́n ní kó wá sípàdé kan ní Gbọ̀ngàn àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà níbi tí wọ́n ti máa dá àwọn ará lẹ́kọ̀ọ́ lórí ọ̀rọ̀ ìmọ́tótó, àmọ́ kò fẹ́ lọ. Kí nìdí? Ó sọ pé: “Bí wọ́n bá tiẹ̀ ń wá ẹran tó níwo, ṣé bíi ti ìgbín ni? Ṣé èmi tí mo ti darúgbó, tọ́kọ mi ti kú, tí mi ò sì mọ nǹkan kan ṣe ni wọ́n máa dá lẹ́kọ̀ọ́? Mi ò rò pé màá wúlò.” Lálẹ́ ọjọ́ tó ṣáájú ìdálẹ́kọ̀ọ́ náà, Jheri sọ ẹ̀dùn ọkàn rẹ̀ fún Jèhófà. Nígbà tó sì débẹ̀ lọ́jọ́ kejì, ó ṣì gbà pé kì í ṣerú òun ni wọ́n ń wá. Àmọ́ lásìkò ìdálẹ́kọ̀ọ́ náà, ọ̀kan lára àwọn tó bá wọn sọ̀rọ̀ jẹ́ kí wọ́n mọ̀ pé ohun tó ṣe pàtàkì jù ni pé kéèyàn ṣe tán láti gba ìdálẹ́kọ̀ọ́ tí Jèhófà fẹ́ fún un. Arábìnrin Jheri wá sọ pé: “Áà, à ṣé mo lóhun tí mo lè fún Jèhófà! Kí n tó mọ̀, mo ti bẹ̀rẹ̀ sí í sunkún torí ó ṣe kedere sí mi pé Jèhófà gbọ́ àdúrà mi. Jèhófà jẹ́ kí n rí i pé mo ṣì wúlò fún òun àti pé òun ṣe tán láti dá mi lẹ́kọ̀ọ́!” Nígbà tó ń sọ ìrírí yìí, Arábìnrin Jheri sọ pé: “Kì í ṣe bí mo ṣe lọ ni mo ṣe bọ̀. Nígbà tí mò ń lọ, ọkàn mi ò balẹ̀, mi ò láyọ̀, mo sì gbà pé mi ò lè wúlò. Àmọ́ nígbà tí màá fi kúrò níbẹ̀, òdìkejì pátápátá ni, mo dẹni tó nígboyà, orí mi wú, mo sì wá rí i pé mo wúlò!”

18. Kí ni Bíbélì sọ tó jẹ́ kó o mọ̀ pé Jèhófà mọyì ìjọsìn rẹ gan-an bó tiẹ̀ jẹ́ pé ara ti ń dara àgbà?

18 Bó tiẹ̀ jẹ́ pé ara ti ń dara àgbà, jẹ́ kó dá ẹ lójú pé Jèhófà mọyì rẹ àti pé ó ṣì níṣẹ́ fún ẹ láti ṣe. (Sm. 92:​12-15) Jésù jẹ́ ká mọ̀ pé bó ti wù kí agbára wa mọ tàbí bí ohun tá à ń ṣe nínú ìjọsìn Jèhófà ṣe kéré tó lójú wa, Jèhófà mọyì rẹ̀. (Lúùkù 21:​2-4) Torí náà, ohun tí agbára rẹ ká ni kó o máa ṣe. Bí àpẹẹrẹ, o lè sọ̀rọ̀ nípa Jèhófà fáwọn èèyàn, o lè gbàdúrà fáwọn ará, o sì lè fún àwọn míì níṣìírí kí wọ́n lè jẹ́ adúróṣinṣin. Jèhófà gbà pé alábàáṣiṣẹ́ òun lo jẹ́. Kì í ṣe nítorí bí agbára rẹ ṣe tó, àmọ́ torí pé ò ń ṣègbọràn sí i.​—1 Kọ́r. 3:​5-9.

19. Ọ̀rọ̀ tó ń fini lọ́kàn balẹ̀ wo ló wà nínú Róòmù 8:​38, 39?

19 A mà dúpẹ́ o pé Jèhófà ni Ọlọ́run wa, torí pé ó mọyì ohun tá à ń ṣe nínú ìjọsìn rẹ̀! Torí ká lè ṣe ìfẹ́ rẹ̀ ló ṣe dá wa, ó ṣe tán kò sì sóhun míì tó ń mú kí ìgbésí ayé ẹni nítumọ̀ ju pé kéèyàn máa jọ́sìn Jèhófà. (Ìfi. 4:11) Bí Èṣù àti ayé yìí bá tiẹ̀ ń fojú ẹni tí kò wúlò wò wá, ọkàn wa balẹ̀ pé Jèhófà ò fi irú ojú bẹ́ẹ̀ wò wá. (Héb. 11:​16, 38) Torí náà, nígbàkigbà tó o bá rẹ̀wẹ̀sì torí àìsàn, ìṣòro àtijẹ àtimu tàbí torí ara tó ń dara àgbà, máa rántí pé Jèhófà nífẹ̀ẹ́ rẹ gan-an, kò sì sóhun náà tó lè yà ọ́ ya ìfẹ́ Jèhófà, Baba rẹ ọ̀run.​—Ka Róòmù 8:38, 39.

^ ìpínrọ̀ 5 Ǹjẹ́ o ti kojú ìṣòro tó mú kí nǹkan tojú sú ẹ tàbí tó mú kó o ronú pé o ò já mọ́ nǹkan kan? Tó bá rí bẹ́ẹ̀, àpilẹ̀kọ yìí máa rán ẹ létí pé Jèhófà mọyì rẹ gan-an, o sì ṣeyebíye lójú rẹ̀. Àá tún jíròrò bó o ṣe lè máa fojú tó tọ́ wo ara rẹ láìka ìṣòro yòówù tó o ní sí.

ORIN 30 Bàbá Mi, Ọlọ́run Mi àti Ọ̀rẹ́ Mi