Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

ÀPILẸ̀KỌ FÚN ÌKẸ́KỌ̀Ọ́ 4

“Ẹ̀mí Fúnra Rẹ̀ Ń Jẹ́rìí”

“Ẹ̀mí Fúnra Rẹ̀ Ń Jẹ́rìí”

“Ẹ̀mí fúnra rẹ̀ ń jẹ́rìí pẹ̀lú ẹ̀mí wa pé ọmọ Ọlọ́run ni wá.”​—RÓÒMÙ 8:16.

ORIN 25 Àkànṣe Ìní

OHUN TÁ A MÁA JÍRÒRÒ *

Jèhófà tú ẹ̀mí mímọ́ rẹ̀ lọ́nà ìyanu sórí àwọn Kristẹni bí ọgọ́fà (120) tó pé jọ ní Pẹ́ńtíkọ́sì (Wo ìpínrọ̀ 1-2)

1-2. Kí ni nǹkan àrà ọ̀tọ̀ tó ṣẹlẹ̀ lọ́jọ́ Pẹ́ńtíkọ́sì ọdún 33 Sànmánì Kristẹni?

OHUN àrà ọ̀tọ̀ kan ṣẹlẹ̀ láàárọ̀ ọjọ́ Sunday kan ní Jerúsálẹ́mù. Ọjọ́ Pẹ́ńtíkọ́sì ọdún 33 Sànmánì Kristẹni lohun tá à ń wí yìí ṣẹlẹ̀. Inú yàrá òkè kan ni àwọn bí ọgọ́fà (120) lára àwọn ọmọ ẹ̀yìn Jésù wà lọ́jọ́ yẹn. (Ìṣe 1:13-15; 2:1) Ọjọ́ mélòó kan ṣáájú ìgbà yẹn ni Jésù ti sọ fún wọn pé kí wọ́n ṣì wà ní Jerúsálẹ́mù torí pé wọ́n máa rí ẹ̀bùn pàtàkì kan gbà. (Ìṣe 1:4, 5) Kí ló wá ṣẹlẹ̀ lọ́jọ́ yẹn gan-an?

2 “Lójijì, ariwo kan dún láti ọ̀run, ó dà bíi ti atẹ́gùn líle tó ń rọ́ yìì.” Kódà gbogbo àwọn tó wà nínú ilé náà ló gbọ́ ariwo yẹn. Ẹ̀yìn náà ni “àwọn ohun tó jọ iná tó rí bí ahọ́n” fara hàn lórí ọ̀kọ̀ọ̀kan àwọn ọmọ ẹ̀yìn náà, gbogbo wọn sì “kún fún ẹ̀mí mímọ́.” (Ìṣe 2:2-4) Jèhófà tipa bẹ́ẹ̀ tú ẹ̀mí mímọ́ rẹ̀ sórí àwọn tó pé jọ lọ́jọ́ yẹn. (Ìṣe 1:8) Torí náà, àwọn ló kọ́kọ́ di ẹni àmì òróró tàbí lédè míì àwọn ni Jèhófà kọ́kọ́ fi ẹ̀mí mímọ́ yàn, * wọ́n sì nírètí àtibá Jésù ṣàkóso ní ọ̀run.

BÁWO LÓ ṢE MÁA Ń RÍ TẸ́NÌ KAN BÁ DI ẸNI ÀMÌ ÒRÓRÓ?

3. Kí nìdí tó fi dá àwọn tó wà ní yàrá òkè yẹn lójú pé àwọn ti di ẹni àmì òróró?

3 Ká sọ pé o wà lára àwọn tó wà nínú yàrá òkè yẹn, ó dájú pé o ò ní gbàgbé ohun tó ṣẹlẹ̀. O rí ohun tó jọ iná tó rí bí ahọ́n lórí rẹ, o sì bẹ̀rẹ̀ sí í sọ èdè àjèjì! (Ìṣe 2:5-12) Ó dájú pé o ò ní ṣiyèméjì pé Jèhófà ti fi ẹ̀mí mímọ́ yàn ẹ́. Àmọ́ ṣé gbogbo àwọn ẹni àmì òróró ni ẹ̀mí mímọ́ bà lé lọ́nà ìyanu, ṣé gbàrà tí wọ́n ṣèrìbọmi tàbí ṣáájú ìrìbọmi ni gbogbo wọn rí ẹ̀mí mímọ́ gbà? Rárá ni ìdáhùn. Báwo la ṣe mọ̀?

4. Ṣé àsìkò kan náà ni gbogbo àwọn ẹni àmì òróró ní ọgọ́rùn-ún ọdún kìíní gba ẹ̀mí mímọ́? Ṣàlàyé.

4 Ẹ jẹ́ ká sọ̀rọ̀ nípa àsìkò tí Jèhófà fi ẹ̀mí yàn wọ́n. Kì í ṣe àwọn bí ọgọ́fà (120) yẹn nìkan ni Jèhófà fẹ̀mí yàn ní Pẹ́ńtíkọ́sì ọdún 33 Sànmánì Kristẹni. Lọ́jọ́ yẹn kan náà, Jèhófà tún fẹ̀mí yan àwọn bí ẹgbẹ̀rún mẹ́ta (3,000) míì. Ìgbà tí wọ́n ṣèrìbọmi ni Jèhófà fi ẹ̀mí mímọ́ yàn wọ́n. (Ìṣe 2:37, 38, 41) Àmọ́ bọ́dún ṣe ń gorí ọdún, nǹkan yàtọ̀ torí pé kì í ṣe ìgbà ìrìbọmi ni Jèhófà fẹ̀mí yan gbogbo Kristẹni tó jẹ́ ẹni àmì òróró. Bí àpẹẹrẹ, ó ti ṣe díẹ̀ lẹ́yìn táwọn ará Samáríà kan ṣèrìbọmi kí wọ́n tó rí ẹ̀mí mímọ́ gbà. (Ìṣe 8:​14-17) Ti Kọ̀nílíù àtàwọn ará ilé rẹ̀ tiẹ̀ yàtọ̀ pátápátá torí pé kí wọ́n tó ṣèrìbọmi rárá ni Jèhófà ti fẹ̀mí yàn wọ́n.​—Ìṣe 10:44-48.

5. Bó ṣe wà nínú 2 Kọ́ríńtì 1:21, 22, báwo ló ṣe máa ń rí tẹ́nì kan bá di ẹni àmì òróró?

5 Ẹ jẹ́ ká tún sọ̀rọ̀ nípa bó ṣe máa ń rí tẹ́nì kan bá di ẹni àmì òróró. Ó lè ṣòro fún àwọn kan láti gbà pé Jèhófà yan àwọn nígbà tí wọ́n bá di ẹni àmì òróró. Wọ́n lè ronú pé, ‘Kí ni Jèhófà rí lára mi tó fi yàn mí?’ Àwọn míì ní tiwọn sì lè má ronú bẹ́ẹ̀. Bó ti wù kó rí, àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù sọ bó ṣe máa ń rí tẹ́nì kan bá di ẹni àmì òróró, ó ní: “Lẹ́yìn tí ẹ gbà á gbọ́, a fi ẹ̀mí mímọ́ tí a ṣèlérí gbé èdìdì * lé yín nípasẹ̀ rẹ̀, ẹ̀mí mímọ́ yìí jẹ́ àmì ìdánilójú ogún tí à ń retí.” (Éfé. 1:​13, 14; àlàyé ìsàlẹ̀) Torí náà, Jèhófà lo ẹ̀mí mímọ́ rẹ̀ láti mú kó dá àwọn Kristẹni náà lójú pé òun ti yàn wọ́n. Nípa bẹ́ẹ̀, ẹ̀mí mímọ́ ni “àmì ìdánilójú [ìyẹn ẹ̀jẹ́ tàbí ìlérí]” tí Jèhófà fún wọn láti mú kó dá wọn lójú pé ọ̀run ni wọ́n máa gbé títí láé kì í ṣe ayé yìí.​—Ka 2 Kọ́ríńtì 1:21, 22.

6. Kí làwọn ẹni àmì òróró gbọ́dọ̀ ṣe kí wọ́n tó lè rí èrè náà gbà?

6 Tí Kristẹni kan bá di ẹni àmì òróró, ṣé ó ti dájú nìyẹn pé ó máa lọ sọ́run? Rárá. Ó dá Kristẹni bẹ́ẹ̀ lójú pé Jèhófà ti yan òun láti lọ sọ́run. Àmọ́ irú ẹni bẹ́ẹ̀ gbọ́dọ̀ fi ìmọ̀ràn Bíbélì yìí sọ́kàn pé: “Ẹ̀yin ará, ẹ túbọ̀ ṣe gbogbo ohun tí ẹ lè ṣe, kí pípè àti yíyàn yín lè dá yín lójú, torí tí ẹ bá ń ṣe àwọn nǹkan yìí, ẹ ò ní kùnà láé.” (2 Pét. 1:10) Torí náà, bó tiẹ̀ jẹ́ pé Jèhófà ti yan Kristẹni ẹni àmì òróró kan láti lọ sọ́run, tí Kristẹni náà bá jẹ́ olóòótọ́ dópin nìkan ló tó lè rí èrè náà gbà.​—Fílí. 3:12-14; Héb. 3:1; Ìfi. 2:10.

BÁWO LẸNÌ KAN ṢE MÁA MỌ̀ PÉ JÈHÓFÀ TI FẸ̀MÍ YAN ÒUN?

7. Báwo lẹnì kan ṣe máa mọ̀ pé ẹni àmì òróró lòun?

7 Àmọ́ báwo lẹnì kan ṣe máa mọ̀ pé Jèhófà ti fi ẹ̀mí yan òun tàbí pé ẹni àmì òróró lòun? Èyí ṣe kedere nínú ọ̀rọ̀ tí Pọ́ọ̀lù sọ fún àwọn tí Jèhófà “pè láti jẹ́ ẹni mímọ́” nílùú Róòmù. Ó sọ fún wọn pé: “Kì í ṣe ẹ̀mí ìsìnrú tó ń múni pa dà sínú ìbẹ̀rù lẹ gbà, ẹ̀mí ìsọdọmọ lẹ gbà, ẹ̀mí tó ń mú ká ké jáde pé: ‘Ábà, Bàbá!’ Ẹ̀mí fúnra rẹ̀ ń jẹ́rìí pẹ̀lú ẹ̀mí wa pé ọmọ Ọlọ́run ni wá.” (Róòmù 1:7; 8:15, 16) Torí náà, ẹ̀mí mímọ́ ni Jèhófà lò láti mú kó ṣe kedere sáwọn ẹni àmì òróró pé ọ̀run ni wọ́n ń lọ.​—1 Tẹs. 2:12.

8. Báwo ni 1 Jòhánù 2:20, 27 ṣe jẹ́ ká mọ̀ pé ẹni àmì òróró kan ò nílò kí ẹlòmíì ṣẹ̀ṣẹ̀ sọ fún un pé ẹni àmì òróró ni?

8 Jèhófà máa ń mú kó ṣe kedere láìsí tàbí ṣùgbọ́n sí àwọn tó jẹ́ ẹni àmì òróró pé òun ti fi ẹ̀mí yàn wọ́n láti lọ sí ọ̀run. (Ka 1 Jòhánù 2:20, 27.) Àmọ́ o, bíi tàwa yòókù nínú ìjọ àwọn ẹni àmì òróró náà ní láti máa kẹ́kọ̀ọ́ lọ́dọ̀ Jèhófà. Wọn ò nílò kẹ́nì kan ṣẹ̀ṣẹ̀ sọ fún wọn kí wọ́n tó mọ̀ pé Jèhófà ti fẹ̀mí yan àwọn. Ẹ̀rí tó lágbára jù lọ láyé àti lọ́run, ìyẹn ẹ̀mí mímọ́ ni Jèhófà fi mú kó ṣe kedere sí wọn pé ẹni àmì òróró ni wọ́n!

A TÚN WỌN BÍ

9. Bó ṣe wà nínú Éfésù 1:18, èrò tó yàtọ̀ wo ni Kristẹni kan máa ń ní lẹ́yìn tí Jèhófà bá fi ẹ̀mí yàn án?

9 Ó máa ń ṣòro fún èyí tó pọ̀ jù lára àwa ìránṣẹ́ Jèhófà láti lóye bó ṣe máa ń rí lára ẹni tí Jèhófà fẹ̀mí yàn. Kí nìdí? Ìdí ni pé ọ̀pọ̀ wa ni kì í ṣe ẹni àmì òróró. Ayé yìí ni Jèhófà dá àwa èèyàn láti gbé, kì í ṣe ọ̀run. (Jẹ́n. 1:28; Sm. 37:29) Àmọ́ Jèhófà yan àwọn kan pé kí wọ́n wá gbé lọ́run. Torí náà, tó bá ti fẹ̀mí yàn wọ́n, ìrònú wọn máa yí pa dà, wọ́n á sì máa retí àtigbé lọ́run.​—Ka Éfésù 1:18.

10. Kí ló túmọ̀ sí tá a bá sọ pé a tún ẹnì kan bí? (Tún wo àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé.)

10 Tí Jèhófà bá fẹ̀mí yan Kristẹni kan, á jẹ́ pé onítọ̀hún ti di àtúnbí nìyẹn tàbí pé wọ́n bí i “láti òkè.” * Jésù tún jẹ́ kó ṣe kedere pé kò sí bí àwọn tí kì í ṣe ẹni àmì òróró ṣe lè lóye bó ṣe máa ń rí lára àwọn tí a tún bí tàbí àwọn tí a “bí látinú ẹ̀mí,” bí wọ́n tiẹ̀ ṣàlàyé ẹ̀ fún wọn.​—Jòh. 3:3-8; àlàyé ìsàlẹ̀.

11. Báwo ni ìrònú ẹnì kan ṣe máa ń yí pa dà nígbà tí Ọlọ́run bá fi ẹ̀mí mímọ́ yàn án?

11 Báwo ni ìrònú ẹnì kan ṣe máa ń yí pa dà nígbà tí Ọlọ́run bá fi ẹ̀mí mímọ́ yàn án? Kí Jèhófà tó fẹ̀mí yan àwọn Kristẹni ẹni àmì òróró láti lọ sọ́run, wọ́n ti nírètí àtigbé lórí ilẹ̀ ayé títí láé. Wọ́n ń retí ìgbà tí Jèhófà máa mú gbogbo ìwà ibi kúrò táá sì sọ ayé di Párádísè. Wọ́n tiẹ̀ ti lè máa fojú inú wo bí wọ́n á ṣe kí tẹbí-tọ̀rẹ́ káàbọ̀ nígbà àjíǹde. Àmọ́ ìrònú wọn yí pa dà lẹ́yìn tí Jèhófà fi ẹ̀mí yàn wọ́n. Kí nìdí? Kì í ṣe torí pé wọn ò nífẹ̀ẹ́ àtigbé títí láé lórí ilẹ̀ ayé mọ́. Bákan náà, kì í ṣe torí àwọn ìṣòro àti ìyà tó pọ̀ láyé ló mú kí wọ́n yí ìrònú wọn pa dà. Bẹ́ẹ̀ sì ni kì í ṣe torí pé wọ́n kàn ṣàdéédéé pinnu pé ayé yìí ò dùn mọ́ àti pé á sú àwọn táwọn bá ń gbé lórí ilẹ̀ ayé títí láé. Kàkà bẹ́ẹ̀, ńṣe ni Jèhófà lo ẹ̀mí mímọ́ rẹ̀ láti yí ìrònú wọn pa dà, ó sì mú kí wọ́n máa retí àtigbé lọ́run dípò ayé.

12. Bó ṣe wà nínú 1 Pétérù 1:3, 4, báwo ni ìrètí àtigbé lọ́run ṣe rí lára àwọn ẹni àmì òróró?

12 Ẹnì kan tí Jèhófà fẹ̀mí yàn lè máa ronú pé òun ò yẹ lẹ́ni tí Jèhófà ń fẹ̀mí yàn. Àmọ́, kò jẹ́ ṣiyè méjì láé pé Jèhófà ti fẹ̀mí yan òun. Ṣe ni inú ẹ̀ á máa dùn gan-an, á sì mọyì àǹfààní tó ní pé òun máa gbé lọ́run.​—Ka 1 Pétérù 1:3, 4.

13. Báwo ló ṣe rí lára àwọn ẹni àmì òróró pé àwọn ṣì ń gbé lórí ilẹ̀ ayé?

13 Ṣé ohun tá à ń sọ ni pé ó ń wu àwọn ẹni àmì òróró pé kí wọ́n kú? Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù dáhùn ìbéèrè yìí nígbà tó ń fi ẹran ara tí wọ́n gbé wọ̀ báyìí wé àgọ́, ó sọ pé: “Kódà, àwa tí a wà nínú àgọ́ yìí ń kérora, ìdààmú bò wá mọ́lẹ̀, torí pé a ò fẹ́ bọ́ èyí kúrò, àmọ́ a fẹ́ gbé èkejì wọ̀, kí ìyè lè gbé èyí tó lè kú mì.” (2 Kọ́r. 5:⁠4) Àwọn Kristẹni yìí ò fẹ́ kú. Wọ́n fẹ́ wà láàyè, kí àwọn àtàwọn èèyàn wọn lè jọ máa sin Jèhófà lójoojúmọ́. Àmọ́ ohun yòówù kí wọ́n máa ṣe, wọn ò jẹ́ gbàgbé ìlérí àgbàyanu tí Ọlọ́run ṣe fún wọn.​—1 Kọ́r. 15:53; 2 Pét. 1:4; 1 Jòh. 3:2, 3; Ìfi. 20:6.

ṢÉ JÈHÓFÀ TI FI Ẹ̀MÍ YÀN Ẹ́?

14. Kí ni kò fi hàn pé Ọlọ́run ti fi ẹ̀mí mímọ́ yan ẹnì kan?

14 Àbí ò ń ronú pé Jèhófà ti yàn ẹ́ láti lọ sọ́run? Tó bá ń ṣe ẹ́ bíi pé Jèhófà ti yàn ẹ́, ronú nípa àwọn ìbéèrè pàtàkì yìí ná: Ṣé kò sí nǹkan míì tó máa ń wù ẹ́ bíi kó o ṣe ohun tí Jèhófà fẹ́? Ṣó máa ń ṣe ẹ́ bíi pé kò sí iṣẹ́ míì tó o kúndùn bí iṣẹ́ ìwàásù? Ṣé o fẹ́ràn láti máa ka Bíbélì gan-an tó sì máa ń wù ẹ́ láti máa kẹ́kọ̀ọ́ “àwọn ohun ìjìnlẹ̀ Ọlọ́run”? (1 Kọ́r. 2:10) Ṣé ò ń wò ó pé Jèhófà ti mú kó o ṣàṣeyọrí gan-an lẹ́nu iṣẹ́ òjíṣẹ́ rẹ? Ṣé o nífẹ̀ẹ́ àwọn èèyàn dénú tó o sì ń ṣe gbogbo ohun tó o lè ṣe láti ràn wọ́n lọ́wọ́ kí wọ́n lè sọ òtítọ́ di tiwọn? Ṣó o ti rí àwọn ọ̀nà pàtó tí Jèhófà ti gbà ràn ẹ́ lọ́wọ́ nígbèésí ayé rẹ? Bí ìdáhùn rẹ bá jẹ́ bẹ́ẹ̀ ni sí gbogbo ìbéèrè yìí, ṣé ìyẹn wá túmọ̀ sí pé Jèhófà ti yàn ẹ́ láti lọ sọ́run? Rárá, ìyẹn ò túmọ̀ sí pé Jèhófà ti fẹ̀mí yàn ẹ́. Kí nìdí? Ìdí ni pé gbogbo àwọn ìránṣẹ́ Jèhófà lè dáhùn bẹ́ẹ̀ ni sí gbogbo ìbéèrè yìí, yálà wọ́n jẹ́ ẹni àmì òróró tàbí wọn kì í ṣe ẹni àmì òróró. Bákan náà, Jèhófà lè tipasẹ̀ ẹ̀mí mímọ́ rẹ̀ fún àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ lágbára, yálà ọ̀run ni wọ́n máa gbé tàbí ayé. Ká sọ̀rọ̀ síbi tọ́rọ̀ wà, tó o bá ń ṣiyè méjì bóyá o wà lára àwọn tó ń lọ sọ́run, á jẹ́ pé Jèhófà ò tíì yàn ẹ́ nìyẹn. Àwọn tí Jèhófà yàn kì í ṣiyè méjì nípa ẹ̀! Ó dá wọn lójú hán-ún!

Jèhófà fi ẹ̀mí mímọ́ rẹ̀ ran Ábúráhámù, Sérà, Dáfídì àti Jòhánù Arinibọmi lọ́wọ́ kí wọ́n lè ṣe àwọn ohun àrà ọ̀tọ̀, àmọ́ kò fi yàn wọ́n láti lọ sọ́run (Wo ìpínrọ̀ 15-16) *

15. Báwo la ṣe mọ̀ pé kì í ṣe gbogbo àwọn tí Ọlọ́run fún ní ẹ̀mí mímọ́ ló yàn láti lọ sọ́run?

15 Ọ̀pọ̀ àpẹẹrẹ àwọn olóòótọ́ èèyàn tí Jèhófà fún ní ẹ̀mí mímọ́ àmọ́ tí wọn ò lọ sọ́run ló wà nínú Bíbélì. Bí àpẹẹrẹ, Jèhófà fi ẹ̀mí mímọ́ darí Dáfídì. (1 Sám. 16:13) Ẹ̀mí mímọ́ mú kó mọ àwọn ohun ìjìnlẹ̀ nípa Jèhófà, ó sì tún darí rẹ̀ láti kọ àwọn apá kan lára Ìwé Mímọ́. (Máàkù 12:36) Síbẹ̀, àpọ́sítélì Pétérù sọ pé Dáfídì “kò lọ sí ọ̀run.” (Ìṣe 2:34) Bákan náà, Bíbélì sọ pé ‘ẹ̀mí mímọ́ kún inú’ Jòhánù Arinibọmi. (Lúùkù 1:13-16) Jésù sọ pé kò sí ẹnì kankan tó tóbi ju Jòhánù lọ, àmọ́ ó tún sọ pé Jòhánù ò ní bá òun jọba lọ́run. (Mát. 11:10, 11) Jèhófà fi ẹ̀mí mímọ́ rẹ̀ ran àwọn ọkùnrin yìí lọ́wọ́ kí wọ́n lè ṣe àwọn ohun àrà ọ̀tọ̀, àmọ́ kò fi yàn wọ́n láti lọ sọ́run. Ṣé ìyẹn wá túmọ̀ sí pé wọn ò jẹ́ olóòótọ́ tó àwọn tó máa bá Jésù jọba lọ́run ni? Rárá. Ohun tó túmọ̀ sí ni pé Jèhófà máa jí wọn dìde sínú Párádísè lórí ilẹ̀ ayé.​—Jòh. 5:28, 29; Ìṣe 24:15.

16. Ìrètí wo lèyí tó pọ̀ jù lára àwa ìránṣẹ́ Jèhófà lónìí ní?

16 Èyí tó pọ̀ jù lára àwa ìránṣẹ́ Jèhófà lónìí kò ní lọ sọ́run. Bíi ti Ábúráhámù, Sérà, Dáfídì, Jòhánù Arinibọmi àti ọ̀pọ̀ àwọn ìránṣẹ́ Jèhófà míì lọ́kùnrin àti lóbìnrin tí wọ́n gbáyé nígbà tí wọ́n ń kọ Bíbélì, à ń fojú sọ́nà láti gbé lórí ilẹ̀ ayé nígbà tí Ìjọba Ọlọ́run bá ń ṣàkóso.​—Héb. 11:10.

17. Àwọn ìbéèrè wo la máa gbé yẹ̀ wò nínú àpilẹ̀kọ tó kàn?

17 Torí pé àwọn ẹni àmì òróró kan ṣì wà láàárín àwa èèyàn Jèhófà, ó ṣeé ṣe kí àwọn ìbéèrè kan máa wá sí wa lọ́kàn. (Ìfi. 12:17) Bí àpẹẹrẹ, ojú wo ló yẹ káwọn tó jẹ́ ẹni àmì òróró fi máa wo ara wọn? Bí ẹnì kan nínú ìjọ rẹ bá bẹ̀rẹ̀ sí í jẹ àwọn ohun ìṣàpẹẹrẹ, báwo ló ṣe yẹ kó o máa ṣe sírú ẹni bẹ́ẹ̀? Bí iye àwọn tó sọ pé ẹni àmì òróró làwọn bá ń pọ̀ sí i, ṣó yẹ kíyẹn kó ìdààmú bá ẹ? A máa dáhùn àwọn ìbéèrè yìí nínú àpilẹ̀kọ tó kàn.

^ ìpínrọ̀ 5 Àtìgbà Pẹ́ńtíkọ́sì ọdún 33 Sànmánì Kristẹni ni Jèhófà ti ń fún àwọn Kristẹni kan ní ìrètí kan tó ṣàrà ọ̀tọ̀ pé wọ́n máa ṣàkóso pẹ̀lú Ọmọ òun lọ́run. Àmọ́ báwo làwọn Kristẹni yẹn ṣe mọ̀ pé àwọn ní àǹfààní àgbàyanu yìí? Kí ló máa ń ṣẹlẹ̀ tí Jèhófà bá yan ẹnì kan? Àpilẹ̀kọ yìí máa dáhùn àwọn ìbéèrè yìí. A gbé àpilẹ̀kọ yìí ka àpilẹ̀kọ kan tó jáde nínú Ilé Ìṣọ́ January 2016.

^ ìpínrọ̀ 2 ÀLÀYÉ Ọ̀RỌ̀: Ẹni àmì òróró: Ẹ̀mí mímọ́ ni Jèhófà fi ń yan ẹnì kan láti bá Jésù jọba lọ́run. Ẹ̀mí yìí ni Jèhófà fi máa ṣe “àmì ìdánilójú ogún” tí ẹni náà ń retí tàbí kó fi ṣèlérí fún un pé ọ̀run ni yóò ti gba èrè rẹ̀. (Éfé. 1:13, 14) Àwọn Kristẹni tí Jèhófà fẹ̀mí yàn yìí ló lè sọ pé ẹ̀mí mímọ́ “ń jẹ́rìí” tàbí pé ó ń mú kó ṣe kedere sáwọn pé ọ̀run làwọn ti máa gba èrè àwọn.​—Róòmù 8:⁠16.

^ ìpínrọ̀ 5 ÀLÀYÉ Ọ̀RỌ̀: Èdìdì. Èyí kì í ṣe èdìdì ìkẹyìn. Ó dìgbà tó bá kù díẹ̀ kí àwọn ẹni àmì òróró kú tí wọ́n sì jẹ́ olóòótọ́ tàbí tó bá kù díẹ̀ kí “ìpọ́njú ńlá” bẹ̀rẹ̀ ni Jèhófà máa tó fún wọn ní èdìdì ìkẹyìn.—Éfé. 4:30; Ìfi. 7:2-4; wo “Ìbéèrè Láti Ọwọ́ Àwọn Òǹkàwé” nínú Ilé Ìṣọ́ April 2016 lédè Gẹ̀ẹ́sì.

^ ìpínrọ̀ 10 Tó o bá fẹ́ mọ̀ sí i nípa ohun tó túmọ̀ sí láti di “àtúnbí,” wo Ilé Ìṣọ́ April 1, 2009, ojú ìwé 3 sí 12.

ORIN 27 Ọlọ́run Máa Ṣí Àwọn Ọmọ Rẹ̀ Payá

^ ìpínrọ̀ 57 ÀWÒRÁN: Yálà a lómìnira láti wàásù ká sì kọ́ni lẹ́kọ̀ọ́ òtítọ́ tàbí wọ́n jù wá sẹ́wọ̀n torí pé à ń sin Jèhófà, gbogbo wa pátá là ń fojú inú wo ìgbà tá a máa gbé títí láé lórí ilẹ̀ ayé nígbà tí Ìjọba Ọlọ́run bá ń ṣàkóso.