Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

ÀPILẸ̀KỌ FÚN ÌKẸ́KỌ̀Ọ́ 7

A Nífẹ̀ẹ́ Jèhófà Baba Wa Gan-an

A Nífẹ̀ẹ́ Jèhófà Baba Wa Gan-an

“A nífẹ̀ẹ́ torí òun ló kọ́kọ́ nífẹ̀ẹ́ wa.”​—1 JÒH. 4:19.

ORIN 3 Agbára Wa, Ìrètí Wa, Ìgbọ́kànlé Wa

OHUN TÁ A MÁA JÍRÒRÒ *

1-2. Báwo ni Jèhófà ṣe mú ká di ara ìdílé rẹ̀, kí sì nìdí?

JÈHÓFÀ pè wá pé ká wá di ara ìdílé òun. Ẹ ò rí i pé àǹfààní aláìlẹ́gbẹ́ nìyẹn! Àwa tá a ti ya ara wa sí mímọ́ tá a sì ń lo ìgbàgbọ́ nínú ẹbọ ìràpadà Jésù Ọmọ rẹ̀ la wà nínú ìdílé yìí. Ìdílé aláyọ̀ ni ìdílé wa. Ìgbésí ayé wa nítumọ̀ nísinsìnyí, a sì tún ń retí àtiwà láàyè títí láé yálà ní ọ̀run tàbí nínú Párádísè orí ilẹ̀ ayé lọ́jọ́ iwájú.

2 Ìfẹ́ ló mú kí Jèhófà fún wa láǹfààní pé ká di ara ìdílé òun bó tiẹ̀ jẹ́ pé ohun tó ná an kò kéré. (Jòh. 3:16) Ó ṣe tán, Bíbélì sọ pé a ti rà wá “ní iye kan.” (1 Kọ́r. 6:20) Ìràpadà yìí ló mú kó ṣeé ṣe fún wa láti ní àjọṣe tó dáa pẹ̀lú Jèhófà. Èyí mú ká lè máa pe Ẹni Gíga Jù Lọ láyé àti lọ́run ní Baba wa, ẹ ò rí i pé àǹfààní aláìlẹ́gbẹ́ nìyẹn! Bá a sì ṣe sọ nínú àpilẹ̀kọ tó ṣáájú, Jèhófà ni Baba tó dáa jù.

3. Àwọn ìbéèrè wo ló yẹ ká béèrè? (Tún wo àpótí náà “ Ṣé Jèhófà Ń Kíyè sí Mi?”)

3 Àwa náà lè béèrè bí onísáàmù kan ṣe béèrè pé: “Kí ni màá san pa dà fún Jèhófà lórí gbogbo oore tó ṣe fún mi?” (Sm. 116:12) Òótọ́ ibẹ̀ ni pé kò sóhun tá a lè fi san oore tí Jèhófà ṣe fún wa. Àmọ́ a lè nífẹ̀ẹ́ rẹ̀. Àpọ́sítélì Jòhánù sọ pé: “A nífẹ̀ẹ́ torí òun ló kọ́kọ́ nífẹ̀ẹ́ wa.” (1 Jòh. 4:19) Báwo la ṣe lè jẹ́ kí Jèhófà mọ̀ pé a nífẹ̀ẹ́ òun?

TÚBỌ̀ SÚN MỌ́ JÈHÓFÀ

À ń fi hàn pé a nífẹ̀ẹ́ Jèhófà Baba wa ọ̀run tá a bá ń gbàdúrà sí i nígbà gbogbo, tá à ń ṣègbọràn sí i, tá a sì ń ran àwọn míì lọ́wọ́ láti wá mọ̀ ọ́n (Wo ìpínrọ̀ 4 sí 14)

4. Bó ṣe wà nínú Jémíìsì 4:​8, kí nìdí tó fi yẹ ká sapá láti sún mọ́ Jèhófà?

4 Jèhófà fẹ́ ká sún mọ́ òun, ká máa bá òun sọ̀rọ̀, ká sì máa tẹ́tí sí òun. (Ka Jémíìsì 4:8.) Jèhófà gbà wá níyànjú pé ká “tẹra mọ́ àdúrà gbígbà,” ó sì fi wá lọ́kàn balẹ̀ pé òun máa tẹ́tí sí wa. (Róòmù 12:12) Ọwọ́ rẹ̀ kì í dí láti tẹ́tí sí wa, ọ̀rọ̀ wa kì í sì í sú u. Lọ́wọ́ kejì, àwa náà lè tẹ́tí sí i tá a bá ń ka Bíbélì Ọ̀rọ̀ rẹ̀, tá a sì ń ka àwọn ìtẹ̀jáde ètò Ọlọ́run. Ó tún ṣe pàtàkì pé ká máa fetí sílẹ̀ dáadáa nípàdé. Bí ìjùmọ̀sọ̀rọ̀ ṣe máa ń jẹ́ káwọn òbí àtàwọn ọmọ túbọ̀ sún mọ́ra, bẹ́ẹ̀ làwa náà máa túbọ̀ sún mọ́ Jèhófà tá a bá ń bá a sọ̀rọ̀, tá a sì ń tẹ́tí sí i.

Wo ìpínrọ̀ 5

5. Báwo la ṣe lè jẹ́ kí àdúrà wa túbọ̀ sunwọ̀n sí i?

5 Báwo ni àdúrà tó ò ń gbà sí Jèhófà ṣe máa ń rí? Jèhófà fẹ́ ká sọ gbogbo bí nǹkan ṣe rí lára wa fún òun. (Sm. 62:8) Torí náà, ó yẹ ká bi ara wa pé: ‘Ṣé àdúrà mi kì í ṣe oréfèé bí ọ̀rọ̀ inú ìwé téèyàn dà kọ? Àbí ó máa ń tọkàn mi wá bí ọ̀rọ̀ téèyàn fúnra ẹ̀ kọ sínú lẹ́tà?’ Kò sí àní-àní pé o nífẹ̀ẹ́ Jèhófà, o sì fẹ́ kí àárín yín túbọ̀ gún régé sí i. Kíyẹn lè ṣeé ṣe, o gbọ́dọ̀ máa tẹ́tí sí Jèhófà kó o sì máa bá a sọ̀rọ̀ déédéé. Sọ àwọn nǹkan tó ò lè sọ fún ẹlòmíì fún un. Sọ àwọn nǹkan tó ń múnú ẹ dùn àtohun tó ń bà ẹ́ lọ́kàn jẹ́ fún un. Torí náà, jẹ́ kó dá ẹ lójú pé ìgbàkigbà lo lè yíjú sí Jèhófà pé kó ràn ẹ́ lọ́wọ́.

6. Kí la gbọ́dọ̀ ṣe tá a bá fẹ́ túbọ̀ sún mọ́ Jèhófà Baba wa ọ̀run?

6 Tá a bá fẹ́ túbọ̀ sún mọ́ Jèhófà, a gbọ́dọ̀ lẹ́mìí ìmoore. Àwa náà gbà pẹ̀lú onísáàmù tó sọ pé: “Wo bí àwọn ohun tí o ṣe ti pọ̀ tó, Jèhófà Ọlọ́run mi, àwọn iṣẹ́ àgbàyanu rẹ àti èrò rẹ sí wa. Kò sí ẹni tí a lè fi ọ́ wé; tí mo bá ní kí n máa wí, kí n sì máa sọ nípa wọn, wọ́n pọ̀ ju ohun tí mo lè ròyìn!” (Sm. 40:5) Kì í ṣe ká kàn mọ oore tí Jèhófà ṣe fún wa nìkan ni, ó tún yẹ ká fi hàn nínú ọ̀rọ̀ àti ìṣe wa. Èyí ń jẹ́ ká yàtọ̀ sí ọ̀pọ̀ àwọn èèyàn inú ayé torí pé inú ayé táwọn èèyàn ò ti mọyì nǹkan tí Ọlọ́run ṣe fún wọn là ń gbé. Kódà, ọ̀kan lára ohun tó fi hàn pé “ọjọ́ ìkẹyìn” là ń gbé ni pé àwọn èèyàn jẹ́ aláìmoore. (2 Tím. 3:1, 2) Torí náà, ẹ má ṣe jẹ́ ká ya aláìmoore láé!

7. Kí ni Jèhófà fẹ́ ká ṣe, kí sì nìdí?

7 Àwọn òbí kì í fẹ́ káwọn ọmọ wọn máa bára wọn jà. Lọ́nà kan náà, Jèhófà ò fẹ́ ká máa bára wa jà, ó fẹ́ ká wà ní àlàáfíà. Kódà, ìfẹ́ tá a ní síra wa yìí ló ń fi hàn pé Kristẹni tòótọ́ ni wá. (Jòh. 13:35) A gbà pé òótọ́ lohun tí onísáàmù sọ pé: “Ó mà dára o, ó mà dùn o pé kí àwọn ará máa gbé pọ̀ ní ìṣọ̀kan!” (Sm. 133:1) Tá a bá nífẹ̀ẹ́ àwọn arákùnrin àtàwọn arábìnrin wa, ṣe là ń fi hàn pé a nífẹ̀ẹ́ Jèhófà. (1 Jòh. 4:20) Ẹ wo bó ṣe dùn tó pé a wà lára ìdílé tá a ti ń ṣe bí ọmọ ìyá, tá a ‘jẹ́ onínúure, tá a sì ń ṣàánú ara wa!’​—Éfé. 4:32.

MÁA ṢÈGBỌRÀN SÍ JÈHÓFÀ TORÍ PÉ O NÍFẸ̀Ẹ́ RẸ̀

Wo ìpínrọ̀ 8

8. Bó ṣe wà nínú 1 Jòhánù 5:3, kí nìdí tó ṣe pàtàkì jù tá a fi ń ṣègbọràn sí Jèhófà?

8 Jèhófà fẹ́ káwọn ọmọ máa ṣègbọràn sáwọn òbí wọn, ó sì retí pé kí gbogbo wa náà máa ṣègbọràn sí òun. (Éfé. 6:1) Ó yẹ ká máa ṣègbọràn sí i torí pé òun ni Ẹlẹ́dàá wa, òun ló sì ń pèsè àwọn nǹkan tó ń gbẹ́mìí wa ró. Yàtọ̀ síyẹn, òun ni Baba tó gbọ́n jù lọ láyé àti lọ́run. Àmọ́, ìdí tó ṣe pàtàkì jù tá a fi ń ṣègbọràn sí Jèhófà ni pé a nífẹ̀ẹ́ rẹ̀. (Ka 1 Jòhánù 5:3.) Lóòótọ́, ọ̀pọ̀ ìdí ló wà tó fi yẹ ká máa ṣègbọràn sí Jèhófà, síbẹ̀ kì í fipá mú wa láti ṣe bẹ́ẹ̀. Ó fún wa lómìnira láti yàn bóyá a máa ṣègbọràn sóun tàbí a ò ní ṣe bẹ́ẹ̀, torí náà inú rẹ̀ máa ń dùn tá a bá ṣègbọràn sí i torí pé a nífẹ̀ẹ́ rẹ̀.

9-10. Kí nìdí tó fi yẹ ká mọ àwọn ìlànà Ọlọ́run ká sì máa tẹ̀ lé e?

9 Àwọn òbí máa ń dáàbò bo àwọn ọmọ wọn. Ìdí nìyẹn tí wọ́n fi máa ń fún wọn láwọn òfin tó máa dáàbò bò wọ́n. Táwọn ọmọ bá ń tẹ̀ lé àwọn ìlànà táwọn òbí wọn fi lélẹ̀, wọ́n á fi hàn pé àwọn fọkàn tán àwọn òbí wọn, àwọn sì bọ̀wọ̀ fún wọn. Tó bá rí bẹ́ẹ̀, mélòómélòó ni ti Baba wa ọ̀run, ṣé kò yẹ ká mọ àwọn ìlànà rẹ̀, ká sì máa fi wọ́n sílò nígbèésí ayé wa? Tá a bá ń ṣe bẹ́ẹ̀, a máa jẹ́ kí Jèhófà mọ̀ pé a nífẹ̀ẹ́ òun a sì bọ̀wọ̀ fún òun. Yàtọ̀ síyẹn, a tún máa ṣe ara wa láǹfààní. (Àìsá. 48:17, 18) Lọ́wọ́ kejì, àwọn tó kọ ìlànà Jèhófà máa ń kó sínú ìṣòro àti wàhálà.​—Gál. 6:7, 8.

10 Tá a bá ń fi àwọn ìlànà Jèhófà sílò, a ò ní ṣe ohun tó máa ṣe wá ní jàǹbá, tó máa kó ẹ̀dùn ọkàn bá wa tàbí tó máa ba àjọṣe tá a ní pẹ̀lú Ọlọ́run jẹ́. Jèhófà mọ ohun tó dáa jù fún wa. Arábìnrin Aurora tó ń gbé lórílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà sọ pé, “Mo mọ̀ pé ohun táá jẹ́ kí ayé wa dùn jù ni pé ká máa ṣègbọràn sí Jèhófà.” Ó sì dájú pé gbogbo wa la mọ̀ bẹ́ẹ̀. Ìbéèrè náà ni pé, àǹfààní wo lo ti rí bó o ṣe ń ṣe ohun tí Jèhófà fẹ́?

11. Báwo ni àdúrà ṣe ń ràn wá lọ́wọ́?

11 Àdúrà máa ń jẹ́ ká ṣègbọràn kódà tí kò bá tiẹ̀ rọrùn láti ṣe bẹ́ẹ̀. Nígbà míì, ó lè má rọrùn fún wa láti ṣe ohun tí Jèhófà fẹ́, àmọ́ a gbọ́dọ̀ máa sapá nígbà gbogbo ká má bàa ṣe ohun tó máa múnú bí Jèhófà. Onísáàmù kan bẹ Jèhófà pé: “Jẹ́ kó máa wù mí láti ṣègbọràn sí ọ.” (Sm. 51:12) Arábìnrin Denise tó jẹ́ aṣáájú-ọ̀nà déédéé sọ pé, “Tó bá ṣòro fún mi láti ṣe ohun tí Jèhófà fẹ́, mo máa ń gbàdúrà pé kí Jèhófà fún mi lókun kí n lè ṣe ohun tó tọ́.” Jẹ́ kó dá ẹ lójú pé tíwọ náà bá gba irú àdúrà yìí, Jèhófà máa dáhùn ẹ̀.​—Lúùkù 11:9-13.

RAN ÀWỌN MÍÌ LỌ́WỌ́ KÍ WỌ́N LÈ NÍFẸ̀Ẹ́ JÈHÓFÀ

12. Kí ni Éfésù 5:1 rọ̀ wá pé ká ṣe?

12 Ka Éfésù 5:⁠1. Torí pé “àyànfẹ́ ọmọ” Jèhófà ni wá, ó yẹ ká ṣe gbogbo ohun tá a lè ṣe láti fara wé e. A lè ṣe bẹ́ẹ̀ tá a bá ń fìfẹ́ hàn sáwọn èèyàn, tá à ń ṣenúure sí wọn tá a sì ń dárí jì wọ́n. Táwọn tí kì í ṣe Ẹlẹ́rìí bá rí ìwà rere tá à ń hù, ó lè mú kí wọ́n wá kẹ́kọ̀ọ́ nípa Jèhófà. (1 Pét. 2:12) Ó ṣe pàtàkì pé káwọn òbí tó jẹ́ Kristẹni fara wé Jèhófà nínú ọwọ́ tí wọ́n fi ń mú àwọn ọmọ wọn. Tí wọ́n bá ń ṣe bẹ́ẹ̀, àwọn ọmọ náà á fẹ́ di ọ̀rẹ́ Jèhófà.

Wo ìpínrọ̀ 13

13. Báwo la ṣe lè borí ìtìjú?

13 Àwọn ọmọ máa ń fi bàbá wọn yangàn, inú wọn sì máa ń dùn láti sọ̀rọ̀ nípa rẹ̀. Lọ́nà kan náà, ojú kì í tì wá láti sọ̀rọ̀ nípa Jèhófà a sì máa ń jẹ́ káwọn míì mọ̀ ọ́n. Ó máa ń ṣe wá bíi ti Ọba Dáfídì tó sọ pé: “Èmi yóò máa fi Jèhófà yangàn.” (Sm. 34:2) Àmọ́ tá a bá jẹ́ onítìjú ńkọ́? Báwo la ṣe lè borí ẹ̀? A lè ṣe bẹ́ẹ̀ tá a bá ń fi sọ́kàn pé bá a ṣe ń sọ̀rọ̀ nípa Jèhófà fáwọn míì ń múnú rẹ̀ dùn ó sì ń ṣe àwọn tá à ń wàásù fún láǹfààní. Jèhófà máa fún wa nígboyà tá a nílò. Ó máa fún wa nígboyà bó ṣe fún àwọn Kristẹni ọgọ́rùn-ún ọdún kìíní.​—1 Tẹs. 2:2.

14. Kí nìdí tó fi yẹ ká máa lọ́wọ́ nínú iṣẹ́ sísọni di ọmọ ẹ̀yìn?

14 Jèhófà kì í ṣe ojúsàájú, inú ẹ̀ sì máa ń dùn tá a bá ń fìfẹ́ hàn sáwọn míì láìka ibi tí wọ́n ti wá sí. (Ìṣe 10:34, 35) Ọ̀nà kan tá a lè gbà fi hàn pé a nífẹ̀ẹ́ àwọn míì ni pé ká wàásù ìhìn rere fún wọn. (Mát. 28:19, 20) Àǹfààní wo làwọn tá à ń wàásù fún máa rí? Ní báyìí, ìgbésí ayé àwọn tó ń fetí sí wa máa sunwọ̀n sí i, tó bá sì tún dọjọ́ iwájú, wọ́n á nírètí àtigbé títí láé.​—1 Tím. 4:16.

NÍFẸ̀Ẹ́ BABA WA KÓ O LÈ LÁYỌ̀

15-16. Kí nìdí tó fi yẹ ká máa láyọ̀?

15 Baba onífẹ̀ẹ́ ni Jèhófà, torí náà ó fẹ́ káwọn tó wà nínú ìdílé rẹ̀ máa láyọ̀. (Àìsá. 65:14) Bó ti wù kí ìṣòro tá à ń kojú pọ̀ tó, a ní ìdí tó pọ̀ tó fi yẹ ká máa láyọ̀. Bí àpẹẹrẹ, ó dá wa lójú pé Jèhófà Baba wa ọ̀run nífẹ̀ẹ́ wa gan-an. A tún ní ìmọ̀ tó péye nínú Bíbélì Ọ̀rọ̀ rẹ̀. (Jer. 15:16) Yàtọ̀ síyẹn, a wà lára ìdílé tó nífẹ̀ẹ́ Jèhófà, tí wọ́n ń fi àwọn ìlànà rẹ̀ ṣèwà hù, tí wọ́n sì nífẹ̀ẹ́ ara wọn.​—Sm. 106:4, 5.

16 Ìdí míì tí inú wa fi ń dùn ni pé ó dájú pé ọjọ́ iwájú aláyọ̀ ń dúró dè wá. A mọ̀ pé láìpẹ́ Jèhófà máa pa gbogbo àwọn ẹni burúkú run, Ìjọba rẹ̀ á sì sọ ayé yìí di Párádísè. Yàtọ̀ síyẹn, ó tún dá wa lójú pé àwọn tó ti kú máa pa dà jíǹde, wọ́n á sì tún pa dà wà pẹ̀lú ìdílé wọn. (Jòh. 5:28, 29) Ẹ wo bí àsìkò yẹn ṣe máa dùn tó! Ohun tó ń fún wa láyọ̀ jù ni pé láìpẹ́ gbogbo ẹ̀dá tó wà láyé àti lọ́run lá máa jọ́sìn Baba wa ọ̀run, wọ́n á sì máa fún un ní ọlá, ìyìn àti ògo tó tọ́ sí i.

ORIN 12 Jèhófà, Ọlọ́run Atóbilọ́lá

^ ìpínrọ̀ 5 A mọ̀ pé Jèhófà Baba wa nífẹ̀ẹ́ wa gan-an, ó sì mú ká di ara ìdílé rẹ̀. Ìdí nìyẹn táwa náà fi nífẹ̀ẹ́ rẹ̀. Àmọ́ báwo la ṣe lè fi hàn pé a nífẹ̀ẹ́ rẹ̀? Nínú àpilẹ̀kọ yìí, a máa rí àwọn ohun pàtó tá a lè ṣe láti fi hàn bẹ́ẹ̀.