Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

ÀPILẸ̀KỌ FÚN ÌKẸ́KỌ̀Ọ́ 11

Ṣé O Ti Ṣe Tán Láti Ṣèrìbọmi?

Ṣé O Ti Ṣe Tán Láti Ṣèrìbọmi?

“Ìrìbọmi . . . tún ń gbà yín là báyìí.”​—1 PÉT. 3:21.

ORIN 28 Bá A Ṣe Lè Jẹ́ Ọ̀rẹ́ Jèhófà

OHUN TÁ A MÁA JÍRÒRÒ *

1. Kí ló yẹ kẹ́nì kan ṣe kó tó bẹ̀rẹ̀ sí í kọ́lé?

JẸ́ KÁ sọ pé ẹnì kan ń ronú àtikọ́ ilé, ó sì ti mọ irú ilé tóun fẹ́ kọ́. Ṣé á kàn gba ọjà lọ, á sì bẹ̀rẹ̀ sí í ra àwọn nǹkan tó fẹ́ fi kọ́ ilé náà ni? Ó dájú pé kò ní ṣe bẹ́ẹ̀. Ìdí ni pé ohun pàtàkì kan wà tó yẹ kó kọ́kọ́ ṣe, ó yẹ kó jókòó kó sì ṣírò iye tó máa ná an. Kí nìdí tíyẹn fi ṣe pàtàkì? Ìdí ni pé ó yẹ kó mọ̀ bóyá owó tóun ní lọ́wọ́ máa kọ́ ilé náà parí. Tó bá fara balẹ̀ ṣírò iye tó máa ná an, ó ṣeé ṣe kó lè kọ́lé náà parí.

2. Bó ṣe wà nínú Lúùkù 14:27-30, kí ló yẹ kó o fara balẹ̀ ronú lé kó o tó ṣèrìbọmi?

2 Ṣé ìfẹ́ tó o ní fún Jèhófà àti bó o ṣe mọyì rẹ̀ ń mú kó wù ẹ́ láti ṣèrìbọmi? Tó bá rí bẹ́ẹ̀, a jẹ́ pé ọ̀rọ̀ rẹ dà bíi ti ọkùnrin ẹ̀ẹ̀kan tó ń ronú àtikọ́ ilé. Kí nìdí tá a fi sọ bẹ́ẹ̀? Jẹ́ ká wo ohun tí Jésù sọ nínú Lúùkù 14:27-30. (Kà á.) Nínú Ìwé Mímọ́ yìí, Jésù ń sọ ohun tó yẹ kí ẹnì kan ṣe tó bá fẹ́ di ọmọ ẹ̀yìn òun. Ó sọ pé onítọ̀hún gbọ́dọ̀ múra sílẹ̀ de “ohun tó máa ná an.” Lédè míì, a gbọ́dọ̀ ṣe tán láti fara da ìṣòro, ká sì ṣe tán láti yááfì àwọn nǹkan. (Lúùkù 9:23-26; 12:51-53) Nítorí náà, kó o tó ṣèrìbọmi, á dáa kó o ronú jinlẹ̀ nípa àwọn nǹkan tó o máa kojú tó o bá di ọmọ ẹ̀yìn Kristi. Tó o bá ṣe bẹ́ẹ̀, wàá lè pinnu pé bíná ń jó, bíjì ń jà, ìfẹ́ Ọlọ́run ni wàá máa ṣe lẹ́yìn tó o bá ṣèrìbọmi.

3. Kí la máa jíròrò nínú àpilẹ̀kọ yìí?

3 Ṣé ìrìbọmi tó ohun téèyàn ń tìtorí ẹ̀ yááfì àwọn nǹkan, téèyàn á sì tún fara da ìṣòro? Bẹ́ẹ̀ ni, ó tó bẹ́ẹ̀, kódà ó jù bẹ́ẹ̀ lọ! Ìdí ni pé ọ̀pọ̀ ìbùkún lo máa rí gbà tó o bá ṣèrìbọmi, wàá rí ìbùkún gbà nísinsìnyí àti lọ́jọ́ iwájú. Ní báyìí, ẹ jẹ́ ká jíròrò àwọn ìbéèrè pàtàkì mélòó kan nípa ìrìbọmi. Èyí máa jẹ́ kó o lè dáhùn ìbéèrè náà pé: “Ṣé mo ti ṣe tán láti ṣèrìbọmi?”

OHUN TÓ YẸ KÓ O MỌ̀ NÍPA ÌYÀSÍMÍMỌ́ ÀTI ÌRÌBỌMI

4. (a) Kí ni ìyàsímímọ́? (b) Kí ló túmọ̀ sí pé kéèyàn “sẹ́ ara rẹ̀” bó ṣe wà nínú Mátíù 16:24?

4 Kí ni ìyàsímímọ́? Kó o tó lè ṣèrìbọmi, o gbọ́dọ̀ ya ara ẹ sí mímọ́. Tó o bá fẹ́ ya ara ẹ sí mímọ́, wàá gbàdúrà sí Jèhófà tọkàntọkàn, wàá sì sọ fún un pé òun lo máa fayé rẹ sìn títí láé. Bíbélì sọ pé ẹni tó bá ya ara ẹ̀ sí mímọ́ fún Jèhófà “sẹ́ ara rẹ̀.” (Ka Mátíù 16:24.) Tó o bá yara ẹ sí mímọ́, ó túmọ̀ sí pé ìwọ kọ́ lo ni ara ẹ mọ́, ti Jèhófà lo jẹ́, àǹfààní aláìlẹ́gbẹ́ sì nìyẹn. (Róòmù 14:8) Ńṣe lò ń tipa bẹ́ẹ̀ sọ fún Jèhófà pé láti ìsinsìnyí lọ, ìfẹ́ rẹ̀ ni wàá máa ṣe kì í ṣe ìfẹ́ tìrẹ. Ẹ̀jẹ́ tàbí ìlérí pàtàkì ni ìyàsímímọ́ tó o ṣe jẹ́. Jèhófà kì í fipá múni láti jẹ́ ẹ̀jẹ́ yìí. Àmọ́ tá a bá ṣe bẹ́ẹ̀, ó retí pé ká mú ẹ̀jẹ́ wa ṣẹ.​—Sm. 116:12, 14.

5. Kí ni ìyàtọ̀ tó wà láàárín ìyàsímímọ́ àti ìrìbọmi?

5 Kí ni ìyàtọ̀ tó wà láàárín ìyàsímímọ́ àti ìrìbọmi? Kò sẹ́ni tó mọ̀ nígbà tó o ya ara ẹ sí mímọ́, àárín ìwọ àti Jèhófà nìkan lọ̀rọ̀ náà mọ. Àmọ́ ó ṣojú àwọn míì nígbà tó o ṣèrìbọmi, bóyá ní àpéjọ àyíká tàbí ti agbègbè. Nígbà tó o ṣèrìbọmi, ńṣe lò ń jẹ́ káwọn míì mọ̀ pé o ti yara ẹ sí mímọ́ fún Jèhófà. * Lédè míì, ò ń jẹ́ káwọn míì mọ̀ pé o nífẹ̀ẹ́ Jèhófà pẹ̀lú gbogbo ọkàn rẹ, gbogbo ara rẹ, gbogbo èrò rẹ àti gbogbo okun rẹ. Bákan náà, o ti pinnu pé Jèhófà ni wàá fayé rẹ sìn títí láé.​—Máàkù 12:30.

6-7. Bó ṣe wà nínú 1 Pétérù 3:18-22, kí nìdí méjì tó fi yẹ kó o ṣèrìbọmi?

6 Ṣó pọn dandan kéèyàn ṣèrìbọmi? Jẹ́ ká wo ohun tó wà nínú 1 Pétérù 3:18-22. (Kà á.) Bí áàkì tí Nóà kàn ṣe mú káwọn èèyàn mọ̀ pé Nóà nígbàgbọ́, bẹ́ẹ̀ ni ìrìbọmi rẹ ṣe fi hàn pé o ti yara ẹ sí mímọ́ fún Jèhófà. Àmọ́ ṣó pọn dandan pé kéèyàn ṣèrìbọmi ni? Bẹ́ẹ̀ ni, ó pọn dandan. Àpọ́sítélì Pétérù sọ ìdí tó fi pọn dandan. Àkọ́kọ́, ó sọ pé ìrìbọmi “ń gbà yín là.” Ìrìbọmi lè gbà wá là lẹ́yìn tá a bá ti gbé àwọn ìgbésẹ̀ tó fi hàn pé a ní ìgbàgbọ́ nínú Jésù, a gbà pé ó kú nítorí wa, pé Ọlọ́run jí i dìde sí ọ̀run àti pé ó ti wà “ní ọwọ́ ọ̀tún Ọlọ́run.”

7 Ìkejì, ìrìbọmi máa jẹ́ ká ní “ẹ̀rí ọkàn rere.” Tá a bá yara wa sí mímọ́ fún Jèhófà, tá a sì ṣèrìbọmi, àá ní àjọṣe tó ṣàrà ọ̀tọ̀ pẹ̀lú rẹ̀. Jèhófà máa dárí àwọn ẹ̀ṣẹ̀ wa jì wá torí pé a ti ronú pìwà dà tọkàntọkàn, a sì ní ìgbàgbọ́ nínú ìràpadà Kristi. Èyí á sì mú ká ní ẹ̀rí ọkàn rere níwájú rẹ̀.

8. Kí nìdí tó ṣe pàtàkì jù tó fi yẹ kó o fẹ́ láti ṣèrìbọmi?

8 Kí nìdí tó ṣe pàtàkì jù tó fi yẹ kó o pinnu pé wàá ṣèrìbọmi? Torí pé o fara balẹ̀ kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, ọ̀pọ̀ nǹkan lo ti mọ̀ nípa Jèhófà, o mọ àwọn ànímọ́ rẹ̀, àwọn ohun tó fẹ́ àtohun tí kò fẹ́. Àwọn ohun tó o kọ́ yìí múnú rẹ dùn, ó sì mú kó o nífẹ̀ẹ́ rẹ̀ gan-an. Torí náà, ìfẹ́ tó o ní fún Jèhófà ni ìdí tó ṣe pàtàkì jù tó fi yẹ kó o pinnu pé wàá ṣèrìbọmi.

9. Kí ló túmọ̀ sí pé kéèyàn ṣèrìbọmi ní orúkọ Baba àti ti Ọmọ àti ti ẹ̀mí mímọ́ bó ṣe wà nínú Mátíù 28:19, 20?

9 Ìdí míì tó fi yẹ kó o pinnu pé wàá ṣèrìbọmi ni pé o kẹ́kọ̀ọ́ òtítọ́ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run, o sì gba àwọn ẹ̀kọ́ náà gbọ́. Àpẹẹrẹ kan lohun tí Jésù sọ nígbà tó pàṣẹ pé ká máa sọ àwọn èèyàn di ọmọ ẹ̀yìn. (Ka Mátíù 28:19, 20.) Bí Jésù ṣe sọ, àwọn tó fẹ́ ṣèrìbọmi gbọ́dọ̀ ṣe bẹ́ẹ̀ “ní orúkọ Baba àti ti Ọmọ àti ti ẹ̀mí mímọ́.” Kí ni èyí túmọ̀ sí? Ohun tó ń sọ ni pé o gbọ́dọ̀ gba ohun tí Bíbélì sọ nípa Jèhófà, Jésù Ọmọ rẹ̀ àti ẹ̀mí mímọ́ gbọ́ láìsí-tàbí-ṣùgbọ́n. Ẹ̀kọ́ òtítọ́ yìí lágbára gan-an, ó sì lè mú kéèyàn pinnu àtiṣe ohun tó tọ́. (Héb. 4:12) Jẹ́ ká sọ̀rọ̀ díẹ̀ lórí ẹ̀kọ́ òtítọ́ yìí.

10-11. Òtítọ́ wo lo ti kọ́ nípa Baba tó o sì gbà gbọ́?

10 Nígbà tó o bẹ̀rẹ̀ sí í kẹ́kọ̀ọ́, o mọ àwọn òtítọ́ yìí nípa Baba. O mọ̀ pé “orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Jèhófà,” ó ye ẹ́ pé òun ni “Ẹni Gíga Jù Lọ lórí gbogbo ayé” àti pé òun nìkan ni “Ọlọ́run tòótọ́.” (Sm. 83:18; Àìsá. 37:16) Òun ni Ẹlẹ́dàá wa, o sì gbà gbọ́ pé “ti Jèhófà ni ìgbàlà.” (Sm. 3:8; 36:9) Òun ló ṣètò bá a ṣe bọ́ lọ́wọ́ ẹ̀ṣẹ̀ àti ikú tó sì mú kó ṣeé ṣe fún wa láti ní ìyè àìnípẹ̀kun lọ́jọ́ iwájú. (Jòh. 17:3) Ìyàsímímọ́ àti ìrìbọmi rẹ máa fi hàn pé o ti di ọ̀kan lára àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà. (Àìsá. 43:10-12) Wàá tipa bẹ́ẹ̀ wà lára ẹgbẹ́ ará tó kárí ayé tá à ń fi orúkọ Ọlọ́run pè, tí wọ́n sì ń fayọ̀ kéde orúkọ náà fáráyé gbọ́.​—Sm. 86:12.

11 Kò sí àní-àní pé àǹfààní aláìlẹ́gbẹ́ ló jẹ́ pé o lóye ohun tí Ìwé Mímọ́ sọ nípa Baba! Tó o bá gba òtítọ́ tó ṣeyebíye yìí gbọ́, wàá fẹ́ ya ara ẹ sí mímọ́ fún Jèhófà kó o sì ṣèrìbọmi.

12-13. Òtítọ́ wo lo ti kọ́ nípa Ọmọ, tó o sì gbà gbọ́?

12 Báwo ló ṣe rí lára ẹ nígbà tó o mọ òtítọ́ nípa ẹni tí Ọmọ jẹ́? O kẹ́kọ̀ọ́ pé Jésù lẹnì kejì tó ṣe pàtàkì jù lọ láyé àti lọ́run. Òun ni Olùràpadà wa torí ó fínnúfíndọ̀ fi ẹ̀mí rẹ̀ lélẹ̀ fún wa. Tá a bá fi hàn nínú ìwà àti ìṣe wa pé a nígbàgbọ́ nínú ìràpadà Kristi, Ọlọ́run máa dárí ẹ̀ṣẹ̀ wa jì wá, àá di ọ̀rẹ́ Ọlọ́run, àá sì ní ìyè àìnípẹ̀kun. (Jòh. 3:16) Jésù ni Àlùfáà Àgbà wa. Ó ń ràn wá lọ́wọ́ ká lè jàǹfààní nínú ìràpadà náà, ká sì ní àjọṣe tó dáa pẹ̀lú Ọlọ́run. (Héb. 4:15; 7:24, 25) Torí pé òun ni Ọba Ìjọba Ọlọ́run, òun ni Jèhófà máa lò láti ya orúkọ rẹ̀ sí mímọ́, á pa gbogbo ẹni ibi run, á sì mú kí aráyé gbádùn ìbùkún ayérayé nínú Párádísè. (Mát. 6:​9, 10; Ìfi. 11:15) Jésù ni àwòkọ́ṣe wa. (1 Pét. 2:21) Ó ṣe tán, ìfẹ́ Ọlọ́run ló fi gbogbo ìgbésí ayé ẹ̀ ṣe, ó sì tipa bẹ́ẹ̀ fi àpẹẹrẹ lélẹ̀ fún wa.​—Jòh. 4:34.

13 Tó o bá gba òtítọ́ tí Bíbélì sọ nípa Jésù gbọ́, wàá nífẹ̀ẹ́ Ọmọ tí Ọlọ́run nífẹ̀ẹ́ gan-an. Èyí á mú kó o fayé rẹ ṣe ìfẹ́ Ọlọ́run bíi ti Jésù. Ìfẹ́ yìí á mú kó o ya ara ẹ sí mímọ́ fún Jèhófà, kó o sì ṣèrìbọmi.

14-15. Òtítọ́ wo lo ti kọ́ tó o sì gbà gbọ́ nípa ẹ̀mí mímọ́?

14 Báwo ló ṣe rí lára ẹ nígbà tó o lóye òtítọ́ tí Bíbélì fi kọ́ni nípa ẹ̀mí mímọ́? O kẹ́kọ̀ọ́ pé ẹ̀mí mímọ́ kì í ṣe ọlọ́run, àmọ́ ó jẹ́ agbára ìṣiṣẹ́ Ọlọ́run. Ẹ̀mí mímọ́ ni Jèhófà lò láti mí sí àwọn tó kọ Bíbélì, ẹ̀mí yìí náà ló sì ń jẹ́ ká lóye àwọn ọ̀rọ̀ inú ẹ̀ ká sì fi wọ́n sílò. (Jòh. 14:26; 2 Pét. 1:21) Ẹ̀mí yìí kan náà ni Jèhófà fi ń mú ká ní “agbára tó kọjá ti ẹ̀dá.” (2 Kọ́r. 4:7) Ẹ̀mí mímọ́ ló ń mú ká lè máa wàásù ìhìn rere, òun ni kì í jẹ́ ká kó sínú ìdẹwò, òun ló ń jẹ́ ká borí ìrẹ̀wẹ̀sì, ká sì fara da ìṣòro. Bákan náà, òun ló ń jẹ́ ká máa fàwọn ànímọ́ Ọlọ́run ṣèwàhù, èyí tí Bíbélì pè ní “èso ti ẹ̀mí.” (Gál. 5:22) Tinútinú ni Jèhófà máa ń fi ẹ̀mí mímọ́ rẹ̀ fún àwọn tó gbẹ́kẹ̀ lé e tí wọ́n sì ń béèrè fún un.​—Lúùkù 11:13.

15 Ẹ wo bó ṣe tuni nínú, tó sì fini lọ́kàn balẹ̀ pé àwa ìránṣẹ́ Jèhófà lè gbára lé ẹ̀mí mímọ́ láti ràn wá lọ́wọ́ ká lè máa sin Jèhófà láìbọ́hùn! Tó o bá gba òtítọ́ yìí gbọ́ nípa ẹ̀mí mímọ́, wàá fẹ́ ya ara ẹ sí mímọ́ fún Jèhófà wàá sì fẹ́ ṣèrìbọmi.

16. Kí làwọn nǹkan tá a ti kọ́ nínú àpilẹ̀kọ yìí?

16 Ìpinnu pàtàkì lo ṣe pé wàá ya ara ẹ sí mímọ́ fún Jèhófà, wàá sì ṣèrìbọmi. Bá a ṣe sọ nínú àpilẹ̀kọ yìí, o gbọ́dọ̀ ronú ohun tó máa ná ẹ, kó o ṣe tán láti fara da ìṣòro, kó o sì ṣe tán láti yááfì àwọn nǹkan. Àmọ́ èrè tó o máa rí kọjá ohun tó máa ná ẹ. Ìrìbọmi máa gbà ẹ́ là, á sì jẹ́ kó o ní ẹ̀rí ọkàn rere. A kẹ́kọ̀ọ́ pé ìfẹ́ tó o ní fún Jèhófà ni ìdí tó ṣe pàtàkì jù tó fi yẹ kó o pinnu láti ṣèrìbọmi. O tún gbọ́dọ̀ gba ohun tí Bíbélì sọ nípa Baba, Ọmọ àti ẹ̀mí mímọ́ gbọ́ láìsí-tàbí-ṣùgbọ́n. Níbi tá a bá ìjíròrò dé yìí, ṣé wàá lè fọwọ́ sọ̀yà pé o ti ṣe tán láti ṣèrìbọmi?

OHUN TÓ YẸ KÓ O ṢE ṢÁÁJÚ ÌRÌBỌMI

17. Sọ díẹ̀ lára àwọn ohun tó yẹ kẹ́nì kan ṣe ṣáájú ìrìbọmi.

17 Tó bá dá ẹ lójú pé lóòótọ́ lo ti ṣe tán láti ṣèrìbọmi, a jẹ́ pé o ti gbé àwọn ìgbésẹ̀ kan tó mú kó o ní àjọṣe tó dáa pẹ̀lú Jèhófà. * Bí àpẹẹrẹ, o ti fara balẹ̀ kẹ́kọ̀ọ́ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run, ìyẹn sì ti mú kó o mọ ọ̀pọ̀ nǹkan nípa Jèhófà àti Jésù. O ti ní ìgbàgbọ́. (Héb. 11:6) Ó dá ẹ lójú pé àwọn ìlérí tí Jèhófà ṣe nínú Bíbélì máa nímùúṣẹ, o sì nígbàgbọ́ pé ẹbọ ìràpadà Jésù máa mú kó o bọ́ lọ́wọ́ ẹ̀ṣẹ̀ àti ikú. O ti ronú pìwà dà àwọn ẹ̀ṣẹ̀ rẹ, lédè míì àwọn àṣìṣe rẹ mú kó o banú jẹ́, o sì ti bẹ Jèhófà pé kó dárí jì ẹ́. O ti yí bó o ṣe ń gbé ìgbésí ayé ẹ pa dà; lédè míì o kọ àwọn ìwà tí kò dáa tó ò ń hù tẹ́lẹ̀ sílẹ̀, o sì ti ń hùwà tó bá ìfẹ́ Ọlọ́run mu. (Ìṣe 3:19) Ó wù ẹ́ láti sọ ohun tó o gbà gbọ́ fáwọn míì. Nígbà tó yá, o di akéde aláìṣèrìbọmi, o sì ń bá ìjọ lọ sóde ẹ̀rí. (Mát. 24:14) Àwọn ìgbésẹ̀ tó o gbé yìí múnú Jèhófà dùn gan-an, àmúyangàn lo sì jẹ́ fún un.​—Òwe 27:11.

18. Kí làwọn nǹkan míì tó yẹ kó o ṣe kó o tó ṣèrìbọmi?

18 Kó o tó ṣèrìbọmi, àwọn nǹkan míì tún wà tó yẹ kó o ṣe. Bá a ṣe sọ ṣáájú, o gbọ́dọ̀ ya ara ẹ sí mímọ́ fún Jèhófà. Gbàdúrà sí Jèhófà tọkàntọkàn níwọ nìkan, kó o sì ṣèlérí fún un pé òun lo máa fayé rẹ sìn. (1 Pét. 4:2) Ẹ̀yìn ìyẹn ni wàá sọ fún olùṣekòkáárí ìgbìmọ̀ àwọn alàgbà pé o fẹ́ ṣèrìbọmi. Ó máa ṣètò àwọn alàgbà mélòó kan pé kí wọ́n bá ẹ sọ̀rọ̀. Má ṣe bẹ̀rù nígbà táwọn alàgbà náà bá ń bá ẹ sọ̀rọ̀. Ó dájú pé àwọn arákùnrin yìí mọ̀ ẹ́ dáadáa, wọ́n sì nífẹ̀ẹ́ ẹ. Àwọn nǹkan tó o ti kọ́ nínú Bíbélì ni wọ́n máa jíròrò pẹ̀lú ẹ. Wọ́n fẹ́ rí i dájú pé o lóye àwọn ẹ̀kọ́ òtítọ́ yẹn, wọ́n sì fẹ́ mọ̀ bóyá o mọ bí ìyàsímímọ́ àti ìrìbọmi ti ṣe pàtàkì tó. Tí wọ́n bá gbà pé o ti ṣe tán lóòótọ́, wọ́n á sọ fún ẹ pé o lè ṣèrìbọmi ní àpéjọ àyíká tàbí ti agbègbè tó ń bọ̀.

OHUN TÓ YẸ KÓ O ṢE LẸ́YÌN ÌRÌBỌMI

19-20. Kí ló yẹ kó o ṣe lẹ́yìn tó o bá ṣèrìbọmi, báwo lo sì ṣe máa ṣe é?

19 Kí ló yẹ kó o ṣe lẹ́yìn tó o bá ti ṣèrìbọmi? * Rántí pé ńṣe lo jẹ́jẹ̀ẹ́ fún Jèhófà nígbà tó o ya ara ẹ sí mímọ́, Jèhófà sì retí pé kó o mú ẹ̀jẹ́ náà ṣẹ. Torí náà, lẹ́yìn ìrìbọmi, o gbọ́dọ̀ mú ìlérí tó o ṣe nígbà tó o ya ara ẹ sí mímọ́ ṣẹ. Báwo lo ṣe lè ṣe é?

20 Má jìnnà sáwọn ará. Ní báyìí tó o ti ṣèrìbọmi, o ti di ọ̀kan lára “ẹgbẹ́ àwọn ará.” (1 Pét. 2:17, àlàyé ìsàlẹ̀) Àwọn arákùnrin àtàwọn arábìnrin tẹ́ ẹ jọ wà nínú ìjọ máa mú ẹ bí ọmọ ìyá. Tó o bá ń lọ sípàdé déédéé, àárín yín á túbọ̀ gún régé. Máa ka Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run lójoojúmọ́, kó o sì máa ṣàṣàrò lórí ẹ̀. (Sm. 1:1, 2) Lẹ́yìn tó o bá ka apá tó o fẹ́ kà tán, rí i pé o lo àkókò díẹ̀ láti ronú lórí ohun tó o kà. Ìgbà yẹn lohun tó o kà máa tó wọnú ọkàn rẹ. Bíbélì rọ̀ ẹ́ pé kó o “máa gbàdúrà nígbà gbogbo.” (Mát. 26:41) Àdúrà àtọkànwá tó ò ń gbà máa mú kó o túbọ̀ sún mọ́ Jèhófà. Bákan náà, “máa wá Ìjọba náà . . . lákọ̀ọ́kọ́.” (Mát. 6:33) O lè ṣe bẹ́ẹ̀ tó o bá ń jẹ́ kí iṣẹ́ ìwàásù gbawájú nígbèésí ayé ẹ. Tó o bá ń lọ́wọ́ nínú iṣẹ́ ìwàásù déédéé, ìgbàgbọ́ ẹ á túbọ̀ lágbára, wàá sì lè ran àwọn míì lọ́wọ́ kí wọ́n lè ní ìyè àìnípẹ̀kun.​—1 Tím. 4:16.

21. Àwọn ìbùkún wo ni wàá rí tó o bá ṣèrìbọmi?

21 Ìpinnu tó o ṣe pé wàá ya ara ẹ sí mímọ́ fún Jèhófà wàá sì ṣèrìbọmi ni ìpinnu tó ṣe pàtàkì jù tó o lè ṣe láyé ẹ. Òótọ́ ni pé ó máa ná ẹ láwọn nǹkan kan. Àmọ́ ṣé ìrìbọmi tó bẹ́ẹ̀? Bẹ́ẹ̀ ni, ó tó bẹ́ẹ̀, ó jù bẹ́ẹ̀ lọ! Ìṣòro yòówù kó o máa kojú nínú ayé èṣù yìí, jẹ́ kó dá ẹ lójú pé ‘fún ìgbà díẹ̀ ni, kò sì lágbára.’ (2 Kọ́r. 4:17) Àmọ́ tó o bá ṣèrìbọmi, ayé ẹ á ládùn á sì lóyin nísinsìnyí, wàá sì tún ní “ìyè tòótọ” lọ́jọ́ iwájú. (1 Tím. 6:19) Torí náà, a rọ̀ ẹ́ pé kó o ronú dáadáa, kó o sì gbàdúrà kó o lè dáhùn ìbéèrè náà pé, “Ṣé mo ti ṣe tán láti ṣèrìbọmi?”

ORIN 50 Àdúrà Ìyàsímímọ́ Mi

^ ìpínrọ̀ 5 Ṣé ó wù ẹ́ pé kó o ṣèrìbọmi? Tó bá rí bẹ́ẹ̀, àpilẹ̀kọ yìí máa ràn ẹ́ lọ́wọ́ torí pé ìwọ la dìídì ṣe é fún. Nínú àpilẹ̀kọ yìí, a máa jíròrò àwọn ìbéèrè pàtàkì kan lórí ọ̀rọ̀ ìrìbọmi. Ìdáhùn rẹ sáwọn ìbéèrè yìí máa jẹ́ kó o mọ̀ bóyá lóòótọ́ lo ti ṣe tán láti ṣèrìbọmi.

^ ìpínrọ̀ 19 Tí o ò bá tíì parí ìkẹ́kọ̀ọ́ rẹ nínú ìwé Kí Ni Bíbélì Kọ́ Wa? àti ìwé Ẹ Dúró Nínú Ìfẹ́ Ọlọ́run, rí i dájú pé ẹni tó kọ́ ẹ lẹ́kọ̀ọ́ tàbí ẹlòmíì ràn ẹ́ lọ́wọ́ láti parí ìwé méjèèjì.