Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

ÌTÀN ÌGBÉSÍ AYÉ

“Àwa Nìyí! Rán Wa!”

“Àwa Nìyí! Rán Wa!”

ṢÉ O ti ń ronú àtilọ sìn níbi tí àìní gbé pọ̀, bóyá lórílẹ̀-èdè míì? Tó bá rí bẹ́ẹ̀, ọ̀pọ̀ ẹ̀kọ́ lo máa rí kọ́ látinú ìrírí Arákùnrin àti Arábìnrin Bergame.

Àtọdún 1988 ni Jack àti Marie-Line ti jọ ń ṣiṣẹ́ ìsìn alákòókò kíkún. Torí pé wọ́n máa ń tètè mú ara wọn bá ibi tí wọ́n ti ń sìn mu, ọ̀pọ̀ ibi ni wọ́n ti sìn ní Guadeloupe àti French Guiana. Ẹ̀ka ọ́fíìsì wa lórílẹ̀-èdè Faransé ló ń bójú tó ibi méjèèjì yìí báyìí. Ẹ jẹ́ ká béèrè ìbéèrè díẹ̀ lọ́wọ́ Jack àti Marie-Line.

Kí ló mú kẹ́ ẹ bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ ìsìn alákòókò kíkún?

Marie-Line: Nígbà tí mo wà lọ́mọdé ní Guadeloupe, àtàárọ̀ ṣúlẹ̀ lèmi àti mọ́mì mi fi máa ń wàásù, wọ́n mà nítara o. Mo nífẹ̀ẹ́ àwọn èèyàn gan-an, torí náà nígbà tí mo parí ilé ìwé lọ́dún 1985, mo bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ aṣáájú-ọ̀nà.

Jack: Nígbà tí mo wà lọ́mọdé, àwọn òjíṣẹ́ alákòókò kíkún tó nífẹ̀ẹ́ iṣẹ́ ìsìn ló yí mi ká. Mo máa ń ṣe iṣẹ́ aṣáájú-ọ̀nà olùrànlọ́wọ́ nígbà ọlidé. Lópin ọ̀sẹ̀, èmi àti mọ́mì mi tàbí arákùnrin míì máa ń wọkọ̀ lọ bá àwọn aṣáájú-ọ̀nà ní ìpínlẹ̀ wọn. Àtàárọ̀ ṣúlẹ̀ la fi máa ń wàásù, tá a bá sì ti ṣíwọ́, a máa ń lọ ṣeré létíkun. A máa ń gbádùn ara wa gan-an!

Kò pẹ́ lẹ́yìn tí mo fẹ́ Marie-Line lọ́dún 1988 ni mo sọ fúnra mi pé, ‛Kò sóhunkóhun tó ń dí wa lọ́wọ́, kí ló wá dé tá ò ṣe púpọ̀ sí i lẹ́nu iṣẹ́ ìsìn wa?’ Bí mo ṣe dara pọ̀ mọ́ ìyàwó mi lẹ́nu iṣẹ́ aṣáájú-ọ̀nà nìyẹn. Lẹ́yìn ọdún kan, a lọ sílé ẹ̀kọ́ àwọn aṣáájú-ọ̀nà, ètò Ọlọ́run sì sọ wá di aṣáájú-ọ̀nà àkànṣe. Ọ̀pọ̀ ìpínlẹ̀ la ti sìn ní Guadeloupe, a sì gbádùn wọn gan-an kí wọ́n tó gbé wa lọ sí French Guiana.

Ọ̀pọ̀ ìgbà ni ètò Ọlọ́run ti rán yín lọ síbi ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ láwọn ọdún yìí. Kí ló ràn yín lọ́wọ́ láti mú ara yín bá àwọn ìpínlẹ̀ tuntun náà mu? 

Marie-Line: Àwọn arákùnrin tó wà ní Bẹ́tẹ́lì French Guiana mọ̀ pé ẹsẹ Bíbélì tá a fẹ́ràn jù ni Àìsáyà 6:8. Torí náà tí wọ́n bá ti pè wá, ohun ti wọ́n sábà máa ń kọ́kọ́ sọ ni pé, “Ṣé ẹ rántí ẹsẹ Bíbélì tẹ́ ẹ fẹ́ràn jù?” Tá a bá ti gbọ́ bẹ́ẹ̀, a ti mọ̀ pé wọ́n fẹ́ rán wa lọ síbòmíì nìyẹn. Àwa náà á sì dáhùn pé, “Àwa Nìyí! Ẹ Rán Wa!”

A kì í fi ibi tá a wà wé àwọn ibi tá a ti kúrò torí tá a bá ń ṣe bẹ́ẹ̀, a ò ní mọyì ìpínlẹ̀ tí wọ́n rán wa lọ. A tún máa ń sapá láti mọ àwọn ará lọ́kùnrin àti lóbìnrin ní ìpínlẹ̀ wa tuntun.

Jack: Nígbà kan, àwọn ọ̀rẹ́ wa kan sọ fún wa pé ká má lọ síbi tuntun tí wọ́n rán wa lọ ká lè wà nítòsí àwọn. Àmọ́ lẹ́yìn tá a kúrò ní Guadeloupe, arákùnrin kan rán wa létí ohun tí Jésù sọ nínú Mátíù 13:38 pé: “Ayé ni pápá náà.” Torí náà, tí wọ́n bá ti gbé wa lọ síbòmíì, a máa ń rán ara wa létí pé ibi yòówù ká ti máa sìn, pápá kan náà ṣì ni. Ó ṣe tán, ohun tó ṣe pàtàkì jù ni àwọn èèyàn náà àti ìpínlẹ̀ ìwàásù yẹn.

Tá a bá ti dé ìpínlẹ̀ ìwàásù tuntun, a máa ń kíyè sí i pé àwọn tó wà níbẹ̀ ń láyọ̀ láìka ìṣòro tí wọ́n ń kojú sí. Torí náà, a máa ń jẹ́ kí ara wa mọlé. Lóòótọ́, oúnjẹ wọn lè yàtọ̀, àmọ́ ohun tí wọ́n ń jẹ là ń jẹ, ohun tí wọ́n sì ń mu làwa náà ń mu, síbẹ̀ a kì í ṣe ohun tó lè ṣàkóbá fún ìlera wa. Yàtọ̀ síyẹn, a máa ń sapá láti ní èrò tó dáa nípa gbogbo ìpínlẹ̀ tí wọ́n rán wa lọ.

Marie-Line: Ọ̀pọ̀ nǹkan la tún kọ́ látọ̀dọ̀ àwọn ará yẹn. Mo rántí ohun tó ṣẹlẹ̀ nígbà tá a ṣẹ̀ṣẹ̀ dé French Guiana. Òjò rọ̀ gan-an lọ́jọ́ kan, mo sì ronú pé ó dìgbà tí òjò bá dá ká tó lọ wàásù. Àmọ́, arábìnrin kan bi mí pé, “Ṣó ti yá?” Ohun tó sọ yẹn yà mí lẹ́nu gan-an, mo bá béèrè pé, “Báwo la ṣe máa lọ nínú òjò yìí?” Ó wá sọ pé, “Ẹ mú agbòjò yín, ká sì máa gun kẹ̀kẹ́ wa lọ.” Bí mo ṣe kọ́ béèyàn ṣe ń lo agbòjò lórí kẹ̀kẹ́ nìyẹn o. Ká sọ pé mi ò kọ́ ọ ni, mi ò ní máa lọ sóde ẹ̀rí nígbà òjò!

Ó ti tó ìgbà mẹ́ẹ̀ẹ́dógún (15) tẹ́ ẹ ti kúrò láti ibì kan lọ síbòmíì. Ṣé ẹ ní ìmọ̀ràn tẹ́ ẹ fẹ́ gba àwọn tó ń lọ láti ìpínlẹ̀ ìwàásù kan sí òmíì?

Marie-Line: Kì í rọrùn láti ṣí láti ibì kan sí ibòmíì. Torí náà, ó ṣe pàtàkì kéèyàn rí ilé tó ń tuni lára, tọ́kàn èèyàn á sì balẹ̀ pẹ̀sẹ̀ tó bá ti òde ẹ̀rí dé.

Jack: Mo sábà máa ń kun inú ilé tá a bá kó sí. Nígbà míì táwọn arákùnrin tó wà ní ẹ̀ka ọ́fíìsì bá mọ̀ pé a ò ní pẹ́ níbi tí wọ́n gbé wa lọ, wọ́n máa ń sọ fún mi pé, “Arákùnrin Jack, ẹ má wulẹ̀ yọ ara yín lẹ́nu pé ẹ̀ ń kun ilé!”

Marie-Line mọ béèyàn ṣe ń di ẹrù gan-an. Ó máa ń kó ẹrù wa sínú páálí, á sì kọ orúkọ sára wọn. Lára ohun tó máa ń kọ ni, ohun èlò “ilé ìwẹ̀,” ohun èlò “yàrá,” ohun èlò “ilé ìdáná” àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ. Tá a bá wá dé ilé tuntun náà, ó máa ń rọrùn láti kó àwọn ẹrù náà síbi tó yẹ kí wọ́n wà. Ó tún máa ń kọ orúkọ àwọn nǹkan tó wà nínú páálí kọ̀ọ̀kan ká lè tètè rí àwọn ohun tá a nílò.

Marie-Line: Torí pé a ti mọ bá a ṣe ń ṣètò ara wa dáadáa, kì í pẹ́ tára wa fi máa ń mọlé.

Báwo lẹ ṣe máa ń ṣètò àkókò yín kẹ́ ẹ lè “ṣe iṣẹ́ òjíṣẹ́ [yín] láìkù síbì kan”?​—2 Tím. 4:5.

Marie-Line: Àwọn ọjọ́ Monday la máa fi ń sinmi, a sì máa ń múra àwọn ìpàdé sílẹ̀. Àmọ́ látọjọ́ Tuesday, òde ẹ̀rí la máa ń lọ.

Jack: Bó tiẹ̀ jẹ́ pé ó níye wákàtí tá a gbọ́dọ̀ lò lóṣù, kì í ṣèyẹn ló ṣe pàtàkì jù. Iṣẹ́ ìwàásù ló ṣe kókó. Àtìgbà tá a bá ti kúrò nílé la ti máa ń gbìyànjú láti bá gbogbo èèyàn tá a bá bá pàdé sọ̀rọ̀, bákan náà la sì máa ń ṣe tá a bá ń pa dà sílé.

Marie-Line: Tá a bá lọ gbafẹ́, mo máa ń kó ìwé àṣàrò kúkúrú dání. Àwọn kan máa ń ní ká fún àwọn níwèé bó tiẹ̀ jẹ́ pé a ò sọ fún wọn pé Ẹlẹ́rìí Jèhófà ni wá. Torí náà, a máa ń múra dáadáa, a sì máa ń hùwà ọmọlúàbí torí pé àwọn èèyàn máa ń kíyè sí wa.

Jack: Ìwà dáadáa tá à ń hù sáwọn tá a jọ ń gbélé tún máa ń jẹ́rìí fún wọn. Wọ́n máa ń kíyè sí i tí mo bá ń ṣa àwọn bébà tó wà nílẹ̀, tí mò ń da ìdọ̀tí nù, tí mo sì ń gbá àyíká ilé. Nígbà míì wọ́n máa ń sọ pé “Ẹ jọ̀ọ́, ṣé ẹ lè rí Bíbélì kan fún mi?”

Ọ̀pọ̀ ìgbà lẹ ti wàásù láwọn ìpínlẹ̀ àdádó, ṣé ẹ nírìírí kankan tó ṣàrà ọ̀tọ̀?

Jack: Ní Guiana, àwọn ìpínlẹ̀ kan ò rọrùn dé rárá. A sábà máa ń rìnrìn àjò nǹkan tó lé ní ọgọ́rùn-ún mẹ́ta ààbọ̀ máìlì (370 m tàbí 600 km) fún odindi ọ̀sẹ̀ kan, bẹ́ẹ̀ sì rèé, àwọn ọ̀nà yẹn ò dáa rárá. A ò lè gbàgbé ìgbà tá a lọ sí abúlé St. Élie nínú igbó Amazon. Ọ̀pọ̀ wákàtí la lò nínú mọ́tò ẹ-bá-mi-tì í-ẹ-rọmi-sí i àti ọkọ̀ ojú omi tó ń lo ẹ́ńjìnnì ká tó débẹ̀. Awakùsà lèyí tó pọ̀ jù lára àwọn tó ń gbébẹ̀. Torí náà, kí wọ́n lè fi hàn pé àwọn mọyì ìwé wa, wọ́n máa ń fún wa ní góòlù! Tó bá wá di ìrọ̀lẹ́, a máa ń fi fídíò ètò Ọlọ́run hàn wọ́n, ọ̀pọ̀ èèyàn ló sì máa ń wá.

Marie-Line: Lẹ́nu àìpẹ́ yìí, ètò Ọlọ́run ní kí ọkọ mi lọ sọ àsọyé Ìrántí Ikú Kristi nílùú Camopi. Àmọ́ ká tó débẹ̀, odindi wákàtí mẹ́rin la lò lórí odò Oyapock River. A ò lè gbàgbé àwọn ìrírí yẹn láé.

Jack: Láwọn ibi tí odò yẹn ò ti jìn, èèyàn lè ṣèṣe bí omi yẹn ṣe ń tàkòtó torí pé ọkọ̀ ojú omi lè forí sọ òkúta. Àmọ́ ṣá o, àwọn òkúta inú omi yẹn máa ń dùn ún wò bá a ṣe ń kọjá. Torí náà, ẹni tó ń wa ọkọ̀ gbọ́dọ̀ mọ ohun tó ń ṣe. Síbẹ̀, a gbádùn ẹ̀ gan-an. Bó tiẹ̀ jẹ́ pé àwa Ẹlẹ́rìí mẹ́fà péré la wà níbi Ìrántí Ikú Kristi náà, àwọn tó tó àádọ́ta (50) ló wá síbẹ̀ títí kan àwọn tí wọ́n ń pè ní Amerindians!

Marie-Line: Àwọn ìrírí tó ń gbádùn mọ́ni bí irú èyí làwọn ọ̀dọ́ tó fẹ́ ṣe púpọ̀ sí i lẹ́nu iṣẹ́ ìsìn Jèhófà máa ní. Àmọ́, ó ṣe pàtàkì kí wọ́n gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà pátápátá. Bí wọ́n sì ṣe ń rí i tó ń dáhùn àdúrà wọn, ìgbàgbọ́ wọn á túbọ̀ máa lágbára. Kò sígbà tá à kì í rí ọwọ́ Jèhófà láyé wa.

Ọ̀pọ̀ èdè lẹ ti kọ́, ṣó máa ń rọrùn fún yín láti kọ́ èdè tuntun ni?

Jack: Rárá o, torí pé ó pọn dandan ni mo ṣe ń kọ́ èdè tuntun. Bí àpẹẹrẹ, nígbà tá a débi tí wọ́n ti ń sọ èdè Sranantongo, * mi ò tíì ṣiṣẹ́ Bíbélì kíkà rárá tí wọ́n ti ní kí n darí Ìkẹ́kọ̀ọ́ Ilé Ìṣọ́! Mo bi arákùnrin kan pé báwo ni mo ṣe ṣe sí. Ó ní “Nígbà míì, a kì í lóye ohun tẹ́ ẹ̀ ń sọ, àmọ́ ẹ gbìyànjú.” Àwọn ọmọdé tó wà níbẹ̀ ràn mí lọ́wọ́ gan-an. Tí mo bá ṣàṣìṣe, wọ́n máa ń sọ fún mi, àmọ́ àwọn àgbàlagbà kì í ṣe bẹ́ẹ̀. Ọ̀pọ̀ nǹkan ni mo kọ́ lára àwọn ọmọ yẹn.

Marie-Line: Ní ìpínlẹ̀ kan, mo ní àwọn akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì tó ń sọ èdè Faransé, Potogí àti èdè Sranantongo. Arábìnrin kan sọ fún mi pé kí n kọ́kọ́ lọ máa darí àwọn ìkẹ́kọ̀ọ́ lédè Potogí tí mi ò fi bẹ́ẹ̀ gbọ́, kí n tó máa lọ sọ́dọ̀ àwọn tó ń sọ èdè tí mo gbọ́ dáadáa. Kò pẹ́ tí mo fi rí i pé ìmọ̀ràn yẹn bọ́gbọ́n mu gan-an.

Lọ́jọ́ kan, mo fi èdè Sranantongo darí ìkẹ́kọ̀ọ́ kan, mo sì fi èdè Potogí darí èkejì. Nígbà tí mo bẹ̀rẹ̀ ìkẹ́kọ̀ọ́ kejì, arábìnrin tá a jọ ṣiṣẹ́ sọ fún mi pé, “Marie-Line, obìnrin yìí ò gbọ́ èdè tó ò ń sọ!” Ìgbà yẹn ni mo ṣẹ̀ṣẹ̀ wá rí i pé èdè Sranantongo ni mo fi ń bá obìnrin kan tó jẹ́ ọmọ ilẹ̀ Brazil sọ̀rọ̀ dípò èdè Potogí!

Àwọn ará tó wà láwọn ibi tẹ́ ẹ ti sìn nífẹ̀ẹ́ yín gan-an. Kí ló mú kẹ́ ẹ sún mọ́ àwọn ará tó bẹ́ẹ̀?

Jack: Òwe 11:25 sọ pé: “Ẹni tó bá lawọ́ máa láásìkí.” A máa ń lo àkókò pẹ̀lú àwọn ará, a sì jọ máa ń ṣe àwọn nǹkan pa pọ̀. Nígbà kan tá a fẹ́ ṣe àwọn àtúnṣe kan sí Gbọ̀ngàn Ìjọba wa, àwọn kan sọ fún mi pé: “Iṣẹ́ àwọn akéde nìyẹn.” Àmọ́ ohun tí mo sọ fún wọn ni pé: “Ẹn ẹn, akéde lèmi náà. Torí náà, tí iṣẹ́ kankan bá wà tó yẹ ká ṣe, èmi náà fẹ́ ṣe.” Gbogbo èèyàn ló máa ń wù pé kí wọ́n dá wà lẹ́ẹ̀kọ̀ọ̀kan, àmọ́ a kì í jẹ́ kíyẹn dí wa lọ́wọ́ àtiṣe ohun tó dáa fáwọn míì.

Marie-Line: A máa ń sapá láti fìfẹ́ hàn sáwọn ará lọ́kùnrin àti lóbìnrin. Ìyẹn ló sì jẹ́ ká mọ ìgbà tí wọ́n nílò ẹni táá bá wọn bójú tó àwọn ọmọ wọn tàbí táá bá wọn mú àwọn ọmọ náà nílé ìwé. Tó bá ṣẹlẹ̀ bẹ́ẹ̀, a máa ń tún ìṣètò wa ṣe ká lè ràn wọ́n lọ́wọ́. Nípa bẹ́ẹ̀, a di ọ̀rẹ́ tímọ́tímọ́, a sì ṣe tán láti ràn wọ́n lọ́wọ́ nígbàkigbà tí wọ́n bá nílò wa.

Àwọn ìbùkún wo lẹ ti rí bẹ́ ẹ ṣe ń sìn níbi tí àìní gbé pọ̀?

Jack: Ọ̀pọ̀ ìbùkún la ti rí nínú iṣẹ́ alákòókò kíkún tá à ń ṣe. A máa ń rí àwọn nǹkan tí Jèhófà dá lóríṣiríṣi. Bó tiẹ̀ jẹ́ pé a máa ń kojú àwọn ìṣòro nígbà míì, ọkàn wa balẹ̀ torí a mọ̀ pé àwọn èèyàn Jèhófà máa dúró tì wá níbikíbi tí wọ́n bá rán wa lọ.

Nígbà tí mo ṣì wà lọ́dọ̀ọ́, wọ́n fi mí sẹ́wọ̀n ní French Guiana torí mi ò fẹ́ ṣiṣẹ́ ológun. Mi ò ronú ẹ̀ láé pé màá ṣiṣẹ́ míṣọ́nnárì níbẹ̀ lọ́jọ́ kan àti pé wọ́n á gbà mí láyè láti wàásù fáwọn tó wà lẹ́wọ̀n. Ká sòótọ́, ìbùkún tí Jèhófà fún wa kọjá àfẹnusọ!

Marie-Line: Ohun tó ń fún mi láyọ̀ jù ni bí mo ṣe ń lo ara mi fáwọn míì. Inú wa dùn pé iṣẹ́ Jèhófà là ń ṣe. Kódà, ó ti mú káwa méjèèjì túbọ̀ sún mọ́ra. Nígbà míì, Jack lè bi mí pé ṣé ká pe àwọn tọkọtaya kan tó rẹ̀wẹ̀sì wá jẹun nílé wa. Ọ̀pọ̀ ìgbà ni mo máa ń dáhùn pé, “Ohun témi gan-an ń rò nìyẹn!” Àbí ẹ ò rí nǹkan, ọ̀pọ̀ ìgbà ni èrò wa máa ń jọra.

Jack: Lẹ́nu àìpẹ́ yìí, àyẹ̀wò fi hàn pé mo ní àrùn jẹjẹrẹ inú okùn àpò ìtọ̀. Bó tiẹ̀ jẹ́ pé ìyàwó mi kì í fẹ́ gbọ́ ọ sétí, mo máa ń sọ fún un pé: “Onítèmi, ká tiẹ̀ ní mo kú lọ́la, òótọ́ ni pé mi ò ‘darúgbó.’ Àmọ́, ayé mi dára torí iṣẹ́ Jèhófà ni mo fayé mi ṣe, ohun tó sì dáa jù téèyàn lè fayé ẹ̀ ṣe nìyẹn.”​—Jẹ́n. 25:8.

Marie-Line: Jèhófà fún wa láwọn àǹfààní iṣẹ́ ìsìn tá ò lérò, ó sì jẹ́ ká gbé àwọn ohun ribiribi ṣe. Ìgbésí ayé wa ládùn, ó sì lóyin. Ó dá wa lójú pé Jèhófà máa wà pẹ̀lú wa, torí náà a ṣe tán láti lọ síbikíbi tí wọ́n bá rán wa lọ!

^ ìpínrọ̀ 32 Èdè Gẹ̀ẹ́sì, Dutch, Potogí àtàwọn èdè kan nílẹ̀ Áfíríkà ló wà nínú èdè Sranantongo, àwọn ẹrú ló sì pilẹ̀ èdè náà.