Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

ÀPILẸ̀KỌ FÚN ÌKẸ́KỌ̀Ọ́ 15

Ojú Wo Lo Fi Ń Wo Àwọn Tó Wà ní Ìpínlẹ̀ Ìwàásù Rẹ?

Ojú Wo Lo Fi Ń Wo Àwọn Tó Wà ní Ìpínlẹ̀ Ìwàásù Rẹ?

“Ẹ gbé ojú yín sókè, kí ẹ sì wo àwọn pápá, pé wọ́n ti funfun, wọ́n ti tó kórè.”​—JÒH. 4:35.

ORIN 64 À Ń Fayọ̀ Ṣe Iṣẹ́ Ìkórè Náà

OHUN TÁ A MÁA JÍRÒRÒ *

1-2. Kí nìdí tí Jésù fi sọ ohun tó wà nínú Jòhánù 4:35, 36?

ÌGBÀ kan wà tí Jésù rìnrìn àjò gba inú oko tí wọ́n gbin ọkà bálì sí. (Jòh. 4:3-6) Ó ṣeé ṣe kó jẹ́ oko ọkà bálì tó ṣẹ̀ṣẹ̀ ń hù, tó sì máa tó oṣù mẹ́rin kí wọ́n tó lè kórè rẹ̀. Jésù wá sọ ohun kan tó ṣàjèjì sáwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀, ó ní: “Ẹ gbé ojú yín sókè, kí ẹ sì wo àwọn pápá, pé wọ́n ti funfun, wọ́n ti tó kórè.” (Ka Jòhánù 4:35, 36.) Kí ni Jésù ní lọ́kàn?

2 Ó ṣeé ṣe kó jẹ́ pé bí a ṣe máa sọ àwọn èèyàn di ọmọ ẹ̀yìn ni Jésù ń sọ. Ẹ jẹ́ ká wo ohun tó ṣe. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn Júù kì í ní ohunkóhun ṣe pẹ̀lú àwọn ará Samáríà, Jésù wàásù fún obìnrin ará Samáríà kan. Ìyàlẹ́nu gbáà ló jẹ́ pé obìnrin yẹn fara balẹ̀ tẹ́tí sí Jésù, ó sì mọyì rẹ̀! Kódà, Jésù ṣì ń sọ̀rọ̀ nípa pápá tó ‘funfun, tó sì ti tó kórè’ lọ́wọ́ nígbà táwọn tó gbọ́ nípa rẹ̀ lẹ́nu obìnrin yẹn ti ń bọ̀ lọ́dọ̀ ẹ̀. (Jòh. 4:9, 39-42) Nígbà tí ìwé kan tó ń ṣàlàyé Bíbélì ń sọ̀rọ̀ nípa ohun tó ṣẹlẹ̀ yìí, ó ní: “Bó ṣe wu àwọn èèyàn náà láti kẹ́kọ̀ọ́ lọ́dọ̀ Jésù . . . fi hàn pé wọ́n ṣe tán láti di ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ bíi ti ọkà tó ti tó kórè.”

Kí ló yẹ ká ṣe tá a bá rí i pé ìpínlẹ̀ ìwàásù wa “ti funfun, wọ́n ti tó kórè”? (Wo ìpínrọ̀ 3)

3. Tó o bá ń fojú tó tọ́ wo àwọn èèyàn bíi ti Jésù, báwo nìyẹn ṣe máa mú kó o túbọ̀ já fáfá lẹ́nu iṣẹ́ ìwàásù?

3 Ojú wo lo fi ń wo àwọn tó ò ń wàásù fún? Ṣé ò ń wò wọ́n bí ọkà tó ti tó kórè? Tó bá jẹ́ bẹ́ẹ̀, àwọn nǹkan mẹ́ta kan wà tó o gbọ́dọ̀ ṣe. Àkọ́kọ́, ó yẹ kó o fi kún ìtara tó o fi ń wàásù. Àkókò ìkórè ti dín kù, kò sì yẹ ká fàkókò ṣòfò. Ìkejì, ó yẹ kí inú rẹ máa dùn bó o ṣe ń rí i táwọn èèyàn ń tẹ́tí sí ìhìn rere, ó ṣe tán Bíbélì sọ pé: ‘Àwọn èèyàn ń yọ̀ nígbà ìkórè.’ (Àìsá. 9:3) Ìkẹta, máa fi sọ́kàn pé kò sẹ́ni tí kò lè di ọmọ ẹ̀yìn, ìyẹn á sì mú kó o máa yí bó o ṣe ń bá onírúurú èèyàn sọ̀rọ̀ pa dà.

4. Nínú àpilẹ̀kọ yìí, kí la máa kọ́ lára àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù?

4 Jésù kò fojú táwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ fi wo àwọn ará Samáríà wò wọ́n. Kàkà bẹ́ẹ̀, ó gbà pé wọ́n lè yí pa dà kí wọ́n sì di ọmọ ẹ̀yìn òun. Ó yẹ káwa náà gbà pé àwọn tó wà ní ìpínlẹ̀ ìwàásù wa lè di ọmọ ẹ̀yìn Jésù. Àpẹẹrẹ àtàtà ni àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù fi lélẹ̀ fún wa tó bá dọ̀rọ̀ iṣẹ́ ìwàásù. Kí la lè kọ́ látinú àpẹẹrẹ rẹ̀? Nínú àpilẹ̀kọ yìí, a máa sọ̀rọ̀ nípa bí àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù ṣe mọ ohun táwọn èèyàn gbà gbọ́, ohun tí wọ́n nífẹ̀ẹ́ sí àti ìdí tó fi gbà pé wọ́n lè di ọmọ ẹ̀yìn.

KÍ NI WỌ́N GBÀ GBỌ́?

5. Kí ló mú kí Pọ́ọ̀lù lè wàásù fáwọn Júù tó wà nínú sínágọ́gù?

5 Ọ̀pọ̀ ìgbà ni Pọ́ọ̀lù wàásù nínú sínágọ́gù àwọn Júù. Bí àpẹẹrẹ, ó wàásù nínú sínágọ́gù tó wà ní Tẹsalóníkà, ó “bá [àwọn Júù] fèròwérò látinú Ìwé Mímọ́ fún sábáàtì mẹ́ta.” (Ìṣe 17:1, 2) Ó ṣeé ṣe kí ọkàn Pọ́ọ̀lù balẹ̀ nínú sínágọ́gù náà torí pé Júù lòun náà. (Ìṣe 26:4, 5) Ẹ̀rù ò ba Pọ́ọ̀lù láti wàásù fáwọn Júù torí ó mọ̀ wọ́n dáadáa.​—Fílí. 3:4, 5.

6. Báwo làwọn ará Áténì tí Pọ́ọ̀lù wàásù fún níbi ọjà ṣe yàtọ̀ sáwọn Júù tó wà nínú sínágọ́gù?

6 Lẹ́yìn táwọn alátakò lé Pọ́ọ̀lù kúrò ní Tẹsalóníkà àti Bèróà, ó lọ sí Áténì. Gẹ́gẹ́ bí ìṣe ẹ̀, “ó bẹ̀rẹ̀ sí í bá àwọn Júù àti àwọn míì tó ń jọ́sìn Ọlọ́run fèròwérò nínú sínágọ́gù.” (Ìṣe 17:17) Àmọ́ nígbà tó ń wàásù fáwọn èèyàn níbi ọjà, ó pàdé àwọn èèyàn míì tó yàtọ̀. Lára wọn ni àwọn onímọ̀ ọgbọ́n orí àtàwọn Kèfèrí míì tó gbà pé “ẹ̀kọ́ tuntun” ni Pọ́ọ̀lù fi ń kọ́ àwọn. Wọ́n wá sọ fún un pé: “Àwọn ohun tó ṣàjèjì sí etí wa lò ń sọ.”​—Ìṣe 17:18-20.

7. Bó ṣe wà nínú Ìṣe 17:22, 23, ọ̀nà wo ni Pọ́ọ̀lù gbà mú kí ọ̀rọ̀ rẹ̀ bá àwọn ará Áténì mu?

7 Ka Ìṣe 17:22, 23. Bí Pọ́ọ̀lù ṣe wàásù fáwọn Kèfèrí tó wà ní Áténì yàtọ̀ sí bó ṣe wàásù fáwọn Júù tó wà nínú sínágọ́gù. Ó ṣeé ṣe kí Pọ́ọ̀lù bi ara ẹ̀ pé, ‘Kí làwọn ará Áténì yìí gbà gbọ́?’ Ó fara balẹ̀ kíyè sí àyíká rẹ̀ àtàwọn àṣà tó wà nínú ẹ̀sìn àwọn èèyàn náà. Lẹ́yìn náà, ó wá ibi tọ́rọ̀ rẹ̀ àti tiwọn ti jọra. Ẹnì kan tó ń ṣàlàyé àwọn ọ̀rọ̀ inú Bíbélì sọ pé: “Torí pé Júù tó di Kristẹni ni àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù, ó mọ̀ pé ọlọ́run táwọn Gíríìkì ń jọ́sìn yàtọ̀ sí Ọlọ́run ‘tòótọ́’ táwọn Júù àtàwọn Kristẹni ń jọ́sìn, àmọ́ ó jẹ́ kí wọ́n mọ̀ pé Ọlọ́run tóun ń wàásù rẹ̀ fún wọn kò ṣàjèjì sí wọn rárá.” Torí náà Pọ́ọ̀lù jẹ́ kí ọ̀rọ̀ rẹ̀ bá àwọn ará Áténì mu. Ó sọ fún wọn pé ọ̀dọ̀ “Ọlọ́run Àìmọ̀” tí wọ́n fẹ́ jọ́sìn ni ohun tóun ń bá wọn sọ ti wá. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn Kèfèrí yẹn ò fi bẹ́ẹ̀ lóye Ìwé Mímọ́, Pọ́ọ̀lù ò ronú pé wọn ò lè di Kristẹni láéláé. Kàkà bẹ́ẹ̀, ó wò wọ́n bí ọkà tó ti tó kórè, ìyẹn sì mú kó yí bó ṣe wàásù fún wọn pa dà.

Fara wé àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù, máa kíyè sí àyíká ibi tó o ti lọ wàásù, mú ọ̀rọ̀ rẹ bá èèyàn kọ̀ọ̀kan mu, kó o sì gbà pé wọ́n lè di ọmọ ẹ̀yìn (Wo ìpínrọ̀ 8, 12, àti 18) *

8. (a) Báwo la ṣe lè mọ ohun táwọn tó wà ní ìpínlẹ̀ wa gbà gbọ́? (b) Kí lo máa sọ tí ẹnì kan bá sọ pé òun ní ẹ̀sìn tòun?

8 Bíi ti Pọ́ọ̀lù, máa kíyè sí àyíká ẹ. Kíyè sí àwọn nǹkan táá jẹ́ kó o mọ ohun táwọn èèyàn tó wà ní ìpínlẹ̀ ìwàásù yín gbà gbọ́. Àwọn nǹkan ẹ̀ṣọ́ wo ni wọ́n fi sára ilé tàbí ohun ìrìnnà wọn? Ṣé orúkọ ẹni náà, aṣọ tó wọ̀, bó ṣe múra tàbí ọ̀rọ̀ rẹ̀ fi irú ẹ̀sìn tó ń ṣe hàn? Ó sì ṣeé ṣe kó sọ ẹ̀sìn tó ń ṣe fún ẹ. Nígbà tẹ́nì kan sọ ẹ̀sìn tó ń ṣe fún aṣáájú-ọ̀nà àkànṣe kan tó ń jẹ́ Flutura, arábìnrin náà dá a lóhùn pé, “Kì í ṣe pé mo fẹ́ kẹ́ ẹ yí ẹ̀sìn yín pa dà, ohun tí mo fẹ́ bá yín sọ ni . . . ”

9. Sọ àwọn ibi tí ọ̀rọ̀ rẹ ti lè jọra pẹ̀lú ẹni tó sọ pé òun ní ẹ̀sìn tòun.

9 Kí lohun tó o lè bá ẹni tó sọ pé òun ní ẹ̀sìn tòun sọ? Ronú ibi tí ọ̀rọ̀ yín ti jọra. Ẹni náà lè gbà pé Ọlọ́run kan ló wà, ó lè gbà pé Jésù ni Olùgbàlà aráyé, ó sì lè gbà pé ọjọ́ ìkẹyìn tá à ń gbé yìí máa tó wá sópin. Tó o bá ti mọ ibi tọ́rọ̀ yín ti jọra, wàá lè wàásù fún un lọ́nà tí ìhìn rere náà á fi wọ̀ ọ́ lọ́kàn.

10. Kí ló yẹ ká ṣe, kí sì nìdí?

10 Fi sọ́kàn pé àwọn èèyàn lè má gba gbogbo ohun tí ẹ̀sìn wọn fi ń kọ́ wọn gbọ́. Lẹ́yìn tó o bá ti mọ ẹ̀sìn tẹ́nì kan ń ṣe, gbìyànjú láti mọ ohun tí òun fúnra rẹ̀ gbà gbọ́. Arákùnrin David tó jẹ́ aṣáájú-ọ̀nà àkànṣe lórílẹ̀-èdè Ọsirélíà sọ pé: “Ọ̀pọ̀ ti mú ìmọ̀ ọgbọ́n orí wọnú ẹ̀sìn wọn.” Arábìnrin Donalta tó wà ní Alibéníà náà sọ pé: “Àwọn kan tá à ń bá pàdé máa ń sọ pé àwọn ní ẹ̀sìn tàwọn, àmọ́ tó bá yá wọ́n á sọ pé àwọn ò gba Ọlọ́run gbọ́.” Arákùnrin kan tó jẹ́ míṣọ́nnárì lórílẹ̀-èdè Ajẹntínà kíyè sí i pé àwọn kan máa ń sọ pé àwọn gba Mẹ́talọ́kan gbọ́, àmọ́ wọ́n lè má gbà pé Baba, Ọmọ àti ẹ̀mí mímọ́ jẹ́ ọ̀kan ṣoṣo. Ó wá fi kún un pé, “ìyẹn máa ń jẹ́ kó rọrùn láti ríbi tí ọ̀rọ̀ wa ti jọra.” Torí náà, gbìyànjú láti mọ ohun táwọn èèyàn gbà gbọ́ gan-an. Tó o bá ṣe bẹ́ẹ̀, wàá dà bíi Pọ́ọ̀lù tó “di ohun gbogbo nítorí gbogbo èèyàn.”​—1 Kọ́r. 9:19-23.

KÍ NI WỌ́N NÍFẸ̀Ẹ́ SÍ?

11. Bó ṣe wà nínú Ìṣe 14:14-17, báwo ni Pọ́ọ̀lù ṣe wàásù fáwọn èèyàn Lísírà lọ́nà tí wọ́n fi lóye ohun tó ń sọ?

11 Ka Ìṣe 14:14-17. Pọ́ọ̀lù mọ ohun táwọn èèyàn náà nífẹ̀ẹ́ sí, torí náà ó gbé ọ̀rọ̀ rẹ̀ kalẹ̀ lọ́nà táá fi wọ̀ wọ́n lọ́kàn. Bí àpẹẹrẹ, àwọn èèyàn Lísírà tí Pọ́ọ̀lù bá sọ̀rọ̀ kò fi bẹ́ẹ̀ mọ̀ nípa Ìwé Mímọ́. Torí náà Pọ́ọ̀lù bá wọn sọ̀rọ̀ lọ́nà tí wọ́n á fi tètè lóye ohun tó ń sọ. Ó sọ̀rọ̀ nípa bí irè oko ṣe ń jáde àti bí Ọlọ́run ṣe ń fi ayọ̀ kún ọkàn wọn. Ó lo àwọn ọ̀rọ̀ àtàwọn àpèjúwe tó máa tètè yé àwọn tó ń bá sọ̀rọ̀.

12. Báwo ni ọ̀nà tó o gbà gbé ọ̀rọ̀ rẹ kalẹ̀ ṣe lè jẹ́ kó o mọ ohun táwọn èèyàn nífẹ̀ẹ́ sí?

12 Lo òye kó o lè mọ ohun táwọn èèyàn nífẹ̀ẹ́ sí ní ìpínlẹ̀ ìwàásù yín, kó o wá nasẹ̀ ọ̀rọ̀ ẹ lọ́nà tó bá a mu. Báwo lo ṣe lè mọ ohun tí ẹnì kan nífẹ̀ẹ́ sí kó o tó dé ọ̀dọ̀ rẹ̀? Ṣe ni kó o kíyè sí ohun tó wà ní àyíká rẹ̀. O ò ṣe bẹ̀rẹ̀ ọ̀rọ̀ rẹ pẹ̀lú ohun tí ẹni yẹn ń ṣe lọ́wọ́, bóyá ó ń tún ọgbà ẹ̀ ṣe tàbí ó ń kàwé lọ́wọ́, ó sì lè máa tún ọkọ̀ rẹ̀ ṣe tàbí kó máa ṣe nǹkan míì. (Jòh. 4:7) Kódà aṣọ tí ẹnì kan wọ̀ lè jẹ́ kó o mọ ibi tí ẹnì kan ti wá, iṣẹ́ tó ń ṣe tàbí irú ẹgbẹ́ agbábọ́ọ̀lù tó nífẹ̀ẹ́ sí. Arákùnrin Gustavo sọ pé: “Mo pàdé ọ̀dọ́kùnrin ẹni ọdún mọ́kàndínlógún (19) tó wọ aṣọ olórin kan. Mo wá bi í pé kí nìdí tó fi fẹ́ràn olórin náà, ó sì ṣàlàyé fún mi. Bá a ṣe bẹ̀rẹ̀ ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì nìyẹn, ní báyìí ó ti di ọ̀kan lára wa.”

13. Báwo lo ṣe lè mú kí ẹnì kan nífẹ̀ẹ́ sí ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì?

13 Tó o bá fẹ́ bẹ̀rẹ̀ sí í kọ́ ẹnì kan lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, ṣe é lọ́nà tó máa fi nífẹ̀ẹ́ sí i, kó o sì jẹ́ kó rí àǹfààní tó wà nínú ẹ̀. (Jòh. 4:13-15) Bí àpẹẹrẹ, nígbà tí Arábìnrin Poppy wàásù fún obìnrin kan, obìnrin náà ní kó wọlé. Poppy kíyè sí ìwé ẹ̀rí tí obìnrin náà gbé kọ́ sínú ilé rẹ̀, ó sì rí i pé ọ̀jọ̀gbọ́n ni nínú ìmọ̀ ẹ̀kọ́, ó wá sọ fún un pé àwa náà máa ń kọ́ àwọn èèyàn lẹ́kọ̀ọ́ nínú ilé, lórí ìkànnì àti láwọn ìpàdé wa. Obìnrin náà bẹ̀rẹ̀ sí í kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, ó lọ sípàdé lọ́jọ́ kejì, ó sì lọ sípàdé àyíká tí wọ́n ṣe lẹ́yìn náà. Ọdún kan lẹ́yìn ìyẹn, ó ṣèrìbọmi. Torí náà bi ara ẹ pé: ‘Kí làwọn ìpadàbẹ̀wò mi nífẹ̀ẹ́ sí? Báwo ni mo ṣe lè mú kí wọ́n nífẹ̀ẹ́ sí ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì?’

14. Báwo lo ṣe lè mú kí ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì bá ipò akẹ́kọ̀ọ́ kọ̀ọ̀kan mu?

14 Lẹ́yìn tó o bá ti bẹ̀rẹ̀ sí í kọ́ àwọn èèyàn lẹ́kọ̀ọ́, máa múra ìkẹ́kọ̀ọ́ kọ̀ọ̀kan sílẹ̀, kó o sì máa fi ibi tí wọ́n ti wá àtohun tí ọ̀kọ̀ọ̀kan wọn nífẹ̀ẹ́ sí sọ́kàn. Bó o ṣe ń múra sílẹ̀, máa ronú ẹsẹ Bíbélì tó o máa kà, fídíò tí wàá fi hàn wọ́n àtàwọn àpèjúwe tí wàá lò láti mú kí wọ́n lóye ẹ̀kọ́ òtítọ́. Bi ara ẹ pé, ‘Kí ni mo lè sọ tó máa jẹ́ kí òtítọ́ wọ ẹni yìí lọ́kàn?’ (Òwe 16:23) Lórílẹ̀-èdè Alibéníà, aṣáájú-ọ̀nà kan tó ń jẹ́ Flora ń kọ́ obìnrin kan lẹ́kọ̀ọ́, obìnrin náà sọ pé, “Mi ò lè gbà láé pé àwọn èèyàn máa jíǹde.” Síbẹ̀, Arábìnrin Flora kò fipá mú un. Flora sọ pé: “Mo ronú pé á dáa kó kọ́kọ́ mọ Ọlọ́run tó ṣèlérí àjíǹde.” Torí náà, ní gbogbo ìgbà tí wọ́n bá ń ṣe ìkẹ́kọ̀ọ́, Flora máa ń tẹnu mọ́ bí ìfẹ́, ọgbọ́n àti agbára Jèhófà ṣe pọ̀ tó. Nígbà tó yá, obìnrin náà gbà láìjanpata pé àjíǹde wà lóòótọ́. Ní báyìí, ó ti di Ẹlẹ́rìí Jèhófà tó ń fìtara wàásù.

GBÀ PÉ WỌ́N LÈ DI ẸLẸ́RÌÍ JÈHÓFÀ

15. Bó ṣe wà nínú Ìṣe 17:16-18, àwọn ìwà tí kò bójú mu wo làwọn èèyàn Áténì ń hù, àmọ́ kí nìdí tí Pọ́ọ̀lù fi wàásù fún wọn?

15 Ka Ìṣe 17:16-18. Pọ́ọ̀lù gbà pé àwọn èèyàn Áténì lè di ọmọ ẹ̀yìn bó tiẹ̀ jẹ́ pé ìbọ̀rìṣà, ìṣekúṣe àti ìmọ̀ ọgbọ́n orí ló kún ìlú náà, bẹ́ẹ̀ sì ni kò jẹ́ kí ọ̀rọ̀ kòbákùngbé tí wọ́n sọ sí òun mú kóun rẹ̀wẹ̀sì. Ẹ rántí pé kí Pọ́ọ̀lù alára tó di Kristẹni, ó jẹ́ ‘asọ̀rọ̀ òdì, ó máa ń ṣe inúnibíni, ó sì jẹ́ aláfojúdi.’ (1 Tím. 1:13) Bí Jésù ṣe gbà pé Pọ́ọ̀lù lè di ọmọ ẹ̀yìn òun náà ni Pọ́ọ̀lù gbà pé àwọn èèyàn Áténì lè di ọmọ ẹ̀yìn Jésù. Bó sì ṣe rí gan-an nìyẹn torí pé àwọn kan lára wọn di ọmọ ẹ̀yìn.​—Ìṣe 9:13-15; 17:34.

16-17. Kí ló fi hàn pé kò sẹ́ni tí kò lè di ọmọ ẹ̀yìn Jésù? Sọ àpẹẹrẹ kan.

16 Ní ọgọ́rùn-ún ọdún kìíní, onírúurú èèyàn ló di ọmọ ẹ̀yìn Jésù. Nígbà tí Pọ́ọ̀lù kọ lẹ́tà sáwọn ará Kọ́ríńtì, ó sọ pé àwọn kan lára wọn ti fìgbà kan jẹ́ ọ̀daràn àti oníṣekúṣe. Ó wá sọ pé: “Ohun tí àwọn kan lára yín jẹ́ tẹ́lẹ̀ nìyẹn. Àmọ́ a ti wẹ̀ yín mọ́.” (1 Kọ́r. 6:9-11) Tó bá jẹ́ ìwọ ni, ṣé wàá gbà pé àwọn èèyàn yẹn lè yí pa dà kí wọ́n sì dọmọ ẹ̀yìn?

17 Lónìí, ọ̀pọ̀ ló ń ṣe ìyípadà kí wọ́n lè di ọmọ ẹ̀yìn Jésù. Bí àpẹẹrẹ lórílẹ̀-èdè Ọsirélíà, aṣáájú-ọ̀nà àkànṣe kan tó ń jẹ́ Yukina rí i pé kò sẹ́ni tí kò lè kẹ́kọ̀ọ́ òtítọ́ láìka ibi tó ti wá sí. Lọ́jọ́ kan tó ń wàásù, ó dé ibì kan tí wọ́n ti ń ta ilé àti ilẹ̀, ó rí obìnrin kan tó ya oríṣiríṣi nǹkan sára tó sì wọ aṣọ gbàgìẹ̀-gbagiẹ. Arábìnrin Yukina sọ pé: “Mi ò kọ́kọ́ fẹ́ wàásù fún un, àmọ́ mo ṣe bẹ́ẹ̀. Mo wá rí i pé ó fẹ́ràn Bíbélì gan-an, kódà àwọn ẹsẹ kan nínú ìwé Sáàmù wà lára ohun tó fín sára!” Ó gbà kí wọ́n máa kọ́ òun lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, ó sì bẹ̀rẹ̀ sí í wá sípàdé. *

18. Kí nìdí tí kò fi yẹ ká máa dá àwọn èèyàn lẹ́jọ́ tàbí pé ká pa wọ́n tì?

18 Ṣé torí pé Jésù gbà pé ọ̀pọ̀ èèyàn máa tẹ̀ lé òun ló ṣe sọ pé pápá ti tó kórè? Rárá. Ìwé Mímọ́ ti sọ tẹ́lẹ̀ pé ìwọ̀nba èèyàn ló máa ní ìgbàgbọ́ nínú rẹ̀. (Jòh. 12:37, 38) Yàtọ̀ síyẹn, Jésù lè mọ ohun tó wà lọ́kàn àwọn èèyàn lọ́nà ìyanu. (Mát. 9:4) Síbẹ̀, ó pọkàn pọ̀ sórí bó ṣe máa ran àwọn tó ní ìgbàgbọ́ lọ́wọ́, ó sì fìtara wàásù fún gbogbo èèyàn. Tí Jésù tó mọ ohun tó wà lọ́kàn àwọn èèyàn kò bá pa àwọn èèyàn tì, mélòómélòó àwa tá ò lè mọ ohun tó wà lọ́kàn àwọn èèyàn! Torí náà, kò yẹ ká máa dá àwọn èèyàn lẹ́jọ́ tàbí ká pa wọ́n tì. Kàkà bẹ́ẹ̀, ó yẹ ká gbà pé wọ́n lè di ọmọ ẹ̀yìn. Arákùnrin Marc tó jẹ́ míṣọ́nnárì ní Burkina Faso sọ pé: “Lọ́pọ̀ ìgbà àwọn tí mo rò pé wọ́n máa tẹ̀ síwájú máa ń dá ìkẹ́kọ̀ọ́ wọn dúró. Àmọ́ àwọn tí mo rò pé wọn ò ní tẹ̀ síwájú ni wọ́n máa ń ṣe dáadáa jù. Ohun tí mo rí kọ́ ni pé ká jẹ́ kí ẹ̀mí Jèhófà máa darí wa.”

19. Ojú wo ló yẹ ká máa fi wo àwọn tó wà ní ìpínlẹ̀ ìwàásù wa?

19 Tá a bá wo àwọn tó wà ní ìpínlẹ̀ ìwàásù wa, wọ́n lè má dà bí àwọn ọkà tó ti tó kórè. Àmọ́ ẹ má gbàgbé ohun tí Jésù sọ fáwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀. Ó sọ pé àwọn pápá ti funfun, ìyẹn ni pé wọ́n ti tó kórè. Èyí fi hàn pé àwọn èèyàn lè yí pa dà kí wọ́n sì di ọmọ ẹ̀yìn Kristi. Jèhófà gbà pé àwọn tó wà ní ìpínlẹ̀ ìwàásù wa lè di ọmọ ẹ̀yìn Jésù, ó sì gbà pé “ohun iyebíye” ni wọ́n. (Hág. 2:7) Tó bá jẹ́ pé ojú tí Jèhófà àti Jésù fi ń wo àwọn èèyàn làwa náà fi ń wò wọ́n, àá sapá láti mọ ohun tí wọ́n gbà gbọ́ àti ohun tí wọ́n nífẹ̀ẹ́ sí. A ò ní wò wọ́n bí ẹni tí kò lè kẹ́kọ̀ọ́ òtítọ́, kàkà bẹ́ẹ̀ àá gbà pé wọ́n lè kẹ́kọ̀ọ́ kí wọ́n sì di arákùnrin àti arábìnrin wa.

ORIN 57 Máa Wàásù fún Onírúurú Èèyàn

^ ìpínrọ̀ 5 Ojú wo lo fi ń wo àwọn tó wà ní ìpínlẹ̀ ìwàásù rẹ, ṣé ìyẹn sì mú kó o tẹra mọ́ iṣẹ́ ìwàásù àti kíkọ́ni? Nínú àpilẹ̀kọ yìí, a máa jíròrò ojú tí Jésù àti àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù fi wo àwọn tí wọ́n wàásù fún àti bá a ṣe lè tẹ̀ lé àpẹẹrẹ wọn. Àá rídìí tó fi yẹ ká mọ ohun táwọn tó wà ní ìpínlẹ̀ ìwàásù wa gbà gbọ́ àti ohun tí wọ́n nífẹ̀ẹ́ sí, ká sì tún ní in lọ́kàn pé wọ́n lè di ọmọ ẹ̀yìn.

^ ìpínrọ̀ 17 Ọ̀pọ̀ àpẹẹrẹ ló wà nínú ọ̀wọ́ àpilẹ̀kọ náà, “Bíbélì Máa Ń Yí Ìgbésí Ayé Àwọn Èèyàn Pa Dà.” A gbé ọ̀wọ́ àpilẹ̀kọ yìí jáde nínú Ilé Ìṣọ́ títí dọdún 2017. Ní báyìí, orí ìkànnì jw.org® ló ti ń jáde. Wo abẹ́ NÍPA WA > ÌRÍRÍ.

^ ìpínrọ̀ 57 ÀWÒRÁN: Bí tọkọtaya kan ṣe ń wàásù láti ilé dé ilé, wọ́n kíyè sí (1) ilé kan tí àyíká rẹ̀ mọ́ tónítóní, tí wọ́n gbin òdòdó sí; (2) ilé kan tí tọkọtaya kan àtàwọn ọmọ wọn kéékèèké ń gbé; (3) ilé kan tí inú àti ìta ẹ̀ dọ̀tí; àti (4) ilé kan táwọn èèyàn ibẹ̀ jẹ́ ẹlẹ́sìn. Inú ilé wo lo rò pé wàá ti rí ẹni tó máa di ọmọ ẹ̀yìn?