Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

ÀPILẸ̀KỌ FÚN ÌKẸ́KỌ̀Ọ́ 16

Túbọ̀ Mọ Àwọn Ará, Kó O sì Máa Gba Tiwọn Rò

Túbọ̀ Mọ Àwọn Ará, Kó O sì Máa Gba Tiwọn Rò

“Ẹ yéé fi ìrísí òde ṣe ìdájọ́, àmọ́ ẹ máa dá ẹjọ́ òdodo.”​—JÒH. 7:24.

ORIN 101 À Ń Ṣiṣẹ́ Níṣọ̀kan

OHUN TÁ A MÁA JÍRÒRÒ *

1. Ọ̀rọ̀ tó ń tuni nínú wo ni Bíbélì sọ nípa Jèhófà?

ṢÉ INÚ ẹ máa dùn táwọn èèyàn bá dá ẹ lẹ́jọ́ torí àwọ̀ ẹ, bí ojú ẹ ṣe rí tàbí torí pé o sanra tàbí o pẹ́lẹ́ńgẹ́? Ó dájú pé inú ẹ ò ní dùn. A mà dúpẹ́ o pé kì í ṣe ohun tó hàn sójú táyé ni Jèhófà fi ń dá wa lẹ́jọ́! Bí àpẹẹrẹ, nígbà tí Sámúẹ́lì rí àwọn ọmọ Jésè, kì í ṣe ohun tí Jèhófà rí ló rí. Jèhófà ti sọ fún Sámúẹ́lì pé ọ̀kan lára àwọn ọmọkùnrin Jésè ló máa di ọba Ísírẹ́lì. Àmọ́ èwo ló máa jẹ́ nínú wọn? Nígbà tí Sámúẹ́lì rí àkọ́bí Jésè tó ń jẹ́ Élíábù, ó sọ pé “ó dájú pé ẹni àmì òróró Jèhófà ló dúró yìí.” Élíábù sì dà bí ọba lóòótọ́. “Ṣùgbọ́n Jèhófà sọ fún Sámúẹ́lì pé: ‘Má wo ìrísí rẹ̀ àti bí ó ṣe ga tó, torí pé mo ti kọ̀ ọ́.’” Kí lèyí kọ́ wa? Jèhófà fi kún un pé: “Ohun tí ó bá hàn síta ni èèyàn ń rí, ṣùgbọ́n Jèhófà ń rí ohun tó wà nínú ọkàn.”​—1 Sám. 16:1, 6, 7.

2. Bó ṣe wà nínú Jòhánù 7:24, kí nìdí tí kò fi yẹ ká máa fi ìrísí dá àwọn èèyàn lẹ́jọ́? Ṣàpèjúwe.

2 Torí pé aláìpé ni wá, gbogbo wa la máa ń fẹ́ fi ìrísí ojú tàbí ohun míì dá àwọn èèyàn lẹ́jọ́. (Ka Jòhánù 7:24.) Àmọ́, bí wọ́n ṣe máa ń sọ, a kì í gbé òkèèrè mọ dídùn ọbẹ̀, ó dìgbà tá a bá sún mọ́ ẹnì kan ká tó lè mọ ìṣe rẹ̀. Ẹ jẹ́ ká ṣe àkàwé ẹ̀ pẹ̀lú dókítà kan tó mọṣẹ́ gan-an. Nǹkan mélòó ló lè sọ pé òun mọ̀ nípa aláìsàn kan tó wá sọ́dọ̀ ẹ̀ kó tó yẹ̀ ẹ́ wò? Kó tó lè sọ irú àìsàn tó ń ṣe é, ó gbọ́dọ̀ tẹ́tí sí i dáadáa, kó mọ irú àìsàn tó máa ń ṣe é tẹ́lẹ̀, bí nǹkan ṣe máa ń rí lára ẹ̀ àtàwọn nǹkan míì táá jẹ́ kó mọ irú àìsàn tó ń ṣe é gan-an. Kódà, dókítà náà lè ní kí onítọ̀hún lọ ya àwòrán ibi tó ń dùn ún tàbí lédè míì kó lọ ṣe X-ray, àìjẹ́ bẹ́ẹ̀ dókítà náà lè fi ẹ̀fọ́rí pe inú rírun. Lọ́nà kan náà, ìwọ̀nba la lè sọ nípa àwọn ará wa tó bá jẹ́ pé ìrísí wọn nìkan là ń wò. Torí náà, irú ẹni tí wọ́n jẹ́ nínú gan-an ló yẹ ká máa wò. Àmọ́ o, bó ti wù ká gbìyànjú tó, a ò lè rí ohun tó wà lọ́kàn wọn, torí náà kò sí bá a ṣe lè lóye àwọn ará wa bíi ti Jèhófà. Síbẹ̀, a lè sapá láti fara wé Jèhófà. Lọ́nà wo?

3. Báwo làwọn àpẹẹrẹ tá a máa jíròrò nínú àpilẹ̀kọ yìí ṣe lè mú ká fara wé Jèhófà?

3 Báwo ni Jèhófà ṣe máa ń bá àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ lò? Ó máa ń tẹ́tí sí wọn. Ó máa ń wo ipò àtilẹ̀wá wọn mọ́ wọn lára, ó sì mọ ohun tó mú kí wọ́n máa ṣe bí wọ́n ṣe ń ṣe. Bákan náà, ó máa ń gba tiwọn rò. Ní báyìí, a máa jíròrò bí Jèhófà ṣe ṣe bẹ́ẹ̀ fún Jónà, Èlíjà, Hágárì àti Lọ́ọ̀tì, àá sì rí bá a ṣe lè fara wé Jèhófà nínú bá a ṣe ń bá àwọn arákùnrin àtàwọn arábìnrin wa lò.

MÁA FARA BALẸ̀ TẸ́TÍ SÍLẸ̀

4. Èrò tí kò tọ́ wo la lè ní nípa Jónà?

4 Tí wọ́n bá ní ká sọ èrò wa nípa Jónà, torí pé ìwọ̀nba lohun tá a mọ̀ nípa ẹ̀, a lè sọ pé kì í ṣẹni tó ṣeé gbára lé, kò sì dúró ṣinṣin. Àbí kí ni ká ti gbọ́, Jèhófà dìídì rán Jónà pé kó lọ kéde ìdájọ́ òun fáwọn èèyàn Nínéfè, àmọ́ dípò kó gbabẹ̀ lọ, ṣe ló kọrí síbòmíì “kó lè sá fún Jèhófà.” (Jónà 1:1-3) Tó bá jẹ́ ìwọ ni, ṣé wàá tún gbéṣẹ́ yẹn fún un? Kò dájú pé wàá ṣe bẹ́ẹ̀. Síbẹ̀, Jèhófà rídìí tó fi yẹ kóun ṣe bẹ́ẹ̀.​—Jónà 3:1, 2.

5. Kí lo rí kọ́ nípa Jónà nínú àdúrà tó gbà nínú Jónà 2:1, 2, 9?

5 Àdúrà tí Jónà gbà jẹ́ ká mọ irú ẹni tó jẹ́ gan-an. (Ka Jónà 2:1, 2, 9.) Kò sí àní-àní pé ọ̀pọ̀ ìgbà ni Jónà gbàdúrà, ọ̀kan lára àdúrà tó gbà yìí jẹ́ ká rí i pé kì í ṣe pé kò fẹ́ṣẹ́ ṣe. Àwọn ohun tó sọ nínú àdúrà yẹn fi hàn pé ó lẹ́mìí ìrẹ̀lẹ̀, ó moore, ó sì ṣe tán láti ṣe ohun tí Jèhófà fẹ́. Abájọ tí Jèhófà fi gbójú fo àṣìṣe ẹ̀, tó gbọ́ àdúrà ẹ̀, tó sì jẹ́ kó máa báṣẹ́ wòlíì ẹ̀ lọ.

Tá a bá mọ bí ọ̀rọ̀ ṣe rí gan-an, àá máa gba tàwọn míì rò (Wo ìpínrọ̀ 6) *

6. Kí nìdí tó fi ṣe pàtàkì pé ká máa tẹ́tí sílẹ̀?

6 Ká tó lè fara balẹ̀ tẹ́tí sẹ́nì kan, ó ṣe pàtàkì pé ká lẹ́mìí ìrẹ̀lẹ̀ ká sì ní sùúrù. Ẹ jẹ́ ká wo ìdí mẹ́ta ó kéré tán tó fi yẹ ká ṣe bẹ́ẹ̀. Àkọ́kọ́, kò ní jẹ́ ká máa ní èrò òdì nípa àwọn míì. Ìkejì, á jẹ́ ká lóye bí nǹkan ṣe rí lára àwọn arákùnrin wa, ìyẹn á sì mú ká túbọ̀ gba tiwọn rò. Ìkẹta, á jẹ́ ká lè ran ẹni náà lọ́wọ́ láti mọ àwọn nǹkan kan nípa ara ẹ̀. Àwọn ìgbà míì máa ń wà téèyàn kì í lè sọ bí nǹkan ṣe rí lára rẹ̀ àfìgbà tó bá rẹ́ni sọ ọ́ fún. (Òwe 20:5) Alàgbà kan nílẹ̀ Éṣíà sọ pé: “Mo rántí ìgbà kan tí mo fún ẹnì kan nímọ̀ràn láìgbọ́ tẹnu ẹ̀. Mo sọ fún arábìnrin kan pé ó yẹ kó túbọ̀ mọ béèyàn ṣe ń dáhùn nípàdé. Ẹ̀yìn-ọ̀-rẹyìn ni mo wá mọ̀ pé kò fi bẹ́ẹ̀ mọ ìwé kà, ìyẹn sì máa ń jẹ́ kó nira fún un láti dáhùn.” Ẹ wo bó ti ṣe pàtàkì tó pé kí ẹ̀yin alàgbà máa “gbọ́ kúlẹ̀kúlẹ̀” kẹ́ ẹ tó fúnni nímọ̀ràn!​—Òwe 18:13.

7. Kí lo rí kọ́ látinú bí Jèhófà ṣe bá Èlíjà lò?

7 Ó máa ń ṣòro fáwọn ará wa kan láti sọ bí nǹkan ṣe rí lára wọn torí ohun tójú wọn ti rí sẹ́yìn, àṣà ìbílẹ̀ wọn tàbí irú ẹni tí wọ́n jẹ́. Kí la lè ṣe táá jẹ́ kó rọrùn fún wọn láti sọ ohun tó wà lọ́kàn wọn? Ẹ rántí bí Jèhófà ṣe ran Èlíjà lọ́wọ́ nígbà tó ń sá fún Jésíbẹ́lì. Ọ̀pọ̀ ọjọ́ ti kọjá kí Èlíjà tó sọ bí nǹkan ṣe rí lára ẹ̀ fún Baba rẹ̀ ọ̀run. Jèhófà tẹ́tí sí i dáadáa. Ẹ̀yìn náà ló wá gbé iṣẹ́ pàtàkì kan fún un. (1 Ọba 19:1-18) Bíi ti Èlíjà, ó lè má fi bẹ́ẹ̀ rọrùn fáwọn ará wa láti sọ ohun tó wà lọ́kàn wọn, àmọ́ tí wọ́n bá ṣe bẹ́ẹ̀, àá lóye bí nǹkan ṣe rí lára wọn gan-an. Tá a bá ń mú sùúrù fún wọn bíi ti Jèhófà, wọ́n á fọkàn tán wa. Tí wọ́n bá sì ṣe tán láti sọ ohun tó ń ṣe wọ́n fún wa, ẹ jẹ́ ká fara balẹ̀ tẹ́tí sí wọn.

TÚBỌ̀ MỌ ÀWỌN ARÁKÙNRIN ÀTÀWỌN ARÁBÌNRIN RẸ

8. Bó ṣe wà nínú Jẹ́nẹ́sísì 16:7-13, báwo ni Jèhófà ṣe ran Hágárì lọ́wọ́?

8 Hágárì ìránṣẹ́ Sáráì hùwà òmùgọ̀ lẹ́yìn tó di ìyàwó Ábúrámù. Nígbà tí Hágárì lóyún, ó bẹ̀rẹ̀ sí í fojú burúkú wo Sáráì torí pé kò bímọ. Ọ̀rọ̀ náà le débi pé ṣe ni Sáráì lé Hágárì kúrò nílé. (Jẹ́n. 16:4-6) Tá a bá fojú èèyàn lásán wò ó, ó lè jọ pé agbéraga èèyàn ni Hágárì àti pé ìyà tó tọ́ sí i nìyẹn. Àmọ́, ojú tí Jèhófà fi wo Hágárì yàtọ̀ síyẹn. Ó rán áńgẹ́lì rẹ̀ sí i. Nígbà tí áńgẹ́lì náà rí i, ó tún ojú ìwòye ẹ̀ ṣe, ó sì bù kún un. Hágárì wá mọ̀ pé Jèhófà ti ń wo òun, ó sì mọ gbogbo ohun tó ń ṣẹlẹ̀ sóun. Ìyẹn mú kó pe Jèhófà ní “Ọlọ́run tó ń ríran, . . . ẹni tó ń rí mi lóòótọ́.”​—Ka Jẹ́nẹ́sísì 16:7-13.

9. Kí nìdí tí Jèhófà fi gba ti Hágárì rò?

9 Kí ni Jèhófà kíyè sí nípa Hágárì? Jèhófà mọ ipò àtilẹ̀wá rẹ̀ àtàwọn nǹkan tó ti fara dà. (Òwe 15:3) Ọmọ Íjíbítì ni Hágárì, àmọ́ àárín àwọn Hébérù ló ń gbé. Ṣé ó máa ń ronú pé kò sẹ́ni tó rí tòun rò? Ṣé àárò ilé máa ń sọ ọ́? Yàtọ̀ síyẹn, kì í ṣe òun nìkan ni Ábúrámù fẹ́. Lásìkò yẹn, àwọn ọkùnrin olóòótọ́ kan ní ju ìyàwó kan lọ, bó tilẹ̀ jẹ́ pé kì í ṣe bí Jèhófà ṣe fẹ́ kó rí nìyẹn látìbẹ̀rẹ̀. (Mát. 19:4-6) Kò yani lẹ́nu pé irú ẹ̀ máa ń fa owú àti aáwọ̀. Lóòótọ́ Jèhófà ò dá Hágárì láre pé kò bọ̀wọ̀ fún Sáráì, síbẹ̀ ó dájú pé Jèhófà gba tiẹ̀ rò.

Túbọ̀ mọ àwọn arákùnrin àtàwọn arábìnrin rẹ dáadáa (Wo ìpínrọ̀ 10 sí 12) *

10. Báwo la ṣe lè túbọ̀ mọ àwọn ará wa?

10 A lè fara wé Jèhófà tá a bá ń sapá láti túbọ̀ mọ àwọn ará wa. Torí náà, sún mọ́ àwọn ará lọ́kùnrin àti lóbìnrin kó o lè túbọ̀ mọ̀ wọ́n. Máa bá wọn sọ̀rọ̀ kí ìpàdé tó bẹ̀rẹ̀ àti lẹ́yìn ìpàdé, bá wọn ṣiṣẹ́ lóde ẹ̀rí, tó bá sì ṣeé ṣe ní kí wọ́n wá jẹun nílé ẹ. Tó o bá ṣe bẹ́ẹ̀, o lè wá rí i pé ojú ló ń ti arábìnrin kan tó o rò pé kò kóni mọ́ra. Bákan náà, o lè wá rí i pé arákùnrin kan tó o rò pé ó nífẹ̀ẹ́ owó nífẹ̀ẹ́ àlejò gan-an, o sì lè wá mọ̀ pé ìdílé kan tó máa ń pẹ́ dé ìpàdé ń fara da ọ̀pọ̀ inúnibíni. (Jóòbù 6:29) Àmọ́ o, ìyẹn ò wá ní ká máa “tojú bọ ọ̀rọ̀ ọlọ́rọ̀.” (1 Tím. 5:13) Síbẹ̀, ó ṣe pàtàkì ká mọ àwọn ará wa lọ́kùnrin àti lóbìnrin dáadáa, ká sì mọ ohun tó ń mú kí wọ́n máa ṣe ohun tí wọ́n ń ṣe.

11. Kí nìdí tó fi ṣe pàtàkì pé káwọn alàgbà mọ àwọn ará inú ìjọ dáadáa?

11 Ó ṣe pàtàkì gan-an pé káwọn alàgbà mọ àwọn ará inú ìjọ dáadáa. Ẹ jẹ́ ká wo àpẹẹrẹ alábòójútó àyíká kan tó ń jẹ́ Artur. Òun àti alàgbà kan lọ ṣèbẹ̀wò sọ́dọ̀ arábìnrin kan tó máa ń tijú. Alábòójútó àyíká náà sọ pé: “Ó sọ fún wa pé kò pẹ́ lẹ́yìn tóun ṣègbéyàwó ni ọkọ òun kú. Láìfi ìyẹn pè, ó tọ́ àwọn ọmọbìnrin wọn méjì dàgbà nínú òtítọ́. Ní báyìí kò fi bẹ́ẹ̀ ríran dáadáa mọ́, ìyẹn sì ń mú kó máa rẹ̀wẹ̀sì. Síbẹ̀, ó ṣì nífẹ̀ẹ́ Jèhófà gan-an, ìgbàgbọ́ rẹ̀ ò sì jó rẹ̀yìn. Ọ̀pọ̀ nǹkan la ti rí kọ́ látinú àpẹẹrẹ arábìnrin yìí.” (Fílí. 2:3) Jèhófà ni alábòójútó àyíká yìí ń fara wé torí pé Jèhófà mọ àwọn àgùntàn rẹ̀, ó sì mọ ohun tí wọ́n ń bá yí. (Ẹ́kís. 3:7) Táwọn alàgbà bá mọ àwọn ará inú ìjọ dáadáa, á rọrùn fún wọn láti ràn wọ́n lọ́wọ́.

12. Àǹfààní wo ni Arábìnrin Yip Yee rí nígbà tó túbọ̀ mọ arábìnrin kan tí wọ́n jọ wà nínú ìjọ?

12 Tó o bá túbọ̀ mọ arákùnrin tàbí arábìnrin kan tí inú ẹ̀ máa ń bí ẹ, ó ṣeé ṣe kó o bẹ̀rẹ̀ sí í gba tiẹ̀ rò. Ẹ jẹ́ ká wo àpẹẹrẹ Arábìnrin Yip Yee tó ń gbé nílẹ̀ Éṣíà, ó sọ pé: “Ohùn arábìnrin kan nínú ìjọ wa máa ń lọ sókè gan-an tó bá ń sọ̀rọ̀, èrò mi sì ni pé kò lẹ́kọ̀ọ́. Àmọ́ nígbà tá a jọ ṣiṣẹ́ lóde ẹ̀rí, ó sọ fún mi pé òun ti bá àwọn òbí òun ta ẹja lọ́jà rí, ìyẹn sì gba pé kóun máa pariwo kóun lè pe àwọn oníbàárà.” Arábìnrin Yip Yee wá fi kún un pé: “Mo wá kẹ́kọ̀ọ́ pé kí n tó lè lóye àwọn arákùnrin àtàwọn arábìnrin mi dáadáa, mo gbọ́dọ̀ mọ ipò àtilẹ̀wá wọn.” Ó máa ń gba ìsapá kéèyàn tó lè mọ àwọn ará dáadáa. Síbẹ̀, tá a bá fi ìmọ̀ràn Bíbélì sílò tó ní ká ṣí ọkàn wa sílẹ̀ pátápátá, Jèhófà tó nífẹ̀ẹ́ “onírúurú èèyàn” là ń fara wé.​—1 Tím. 2:3, 4; 2 Kọ́r. 6:11-13.

MÁA GBA TÀWỌN ARÁ RÒ

13. Bó ṣe wà nínú Jẹ́nẹ́sísì 19:15, 16, kí làwọn áńgẹ́lì ṣe fún Lọ́ọ̀tì nígbà tó ń lọ́ra ṣáá, kí sì nìdí?

13 Ìgbà kan wà tó yẹ kí Lọ́ọ̀tì tètè ṣe ohun tí Jèhófà ní kó ṣe, àmọ́ tó jẹ́ pé ṣe ló ń lọ́ra. Àwọn áńgẹ́lì méjì tó dé sílé ẹ̀ sọ fún un pé kóun àti ìdílé ẹ̀ tètè kúrò nílùú Sódómù. Kí nìdí? Wọ́n sọ pé: “A máa pa ìlú yìí run.” (Jẹ́n. 19:12, 13) Ó yani lẹ́nu pé títí di àárọ̀ ọjọ́ kejì, Lọ́ọ̀tì àti ìdílé ẹ̀ ṣì wà nínú ilé. Torí náà, àwọn áńgẹ́lì náà tún kìlọ̀ fún un. Síbẹ̀, ṣe ló “ń lọ́ra ṣáá.” Lójú wa, ó lè jọ pé Lọ́ọ̀tì ò ka ọ̀rọ̀ Jèhófà sí tàbí pé aláìgbọràn ni. Àmọ́ Jèhófà ò jẹ́ kọ́rọ̀ ẹ̀ sú òun. “Torí Jèhófà yọ́nú sí i,” àwọn áńgẹ́lì yẹn fà wọ́n lọ́wọ́, wọ́n sì mú wọn jáde sí ìta ìlú náà.​—Ka Jẹ́nẹ́sísì 19:15, 16.

14. Kí nìdí tí Jèhófà fi gba ti Lọ́ọ̀tì rò?

14 Ọ̀pọ̀ ìdí ló wà tí Jèhófà fi gba ti Lọ́ọ̀tì rò. Ó ṣeé ṣe kí Lọ́ọ̀tì máa bẹ̀rù àwọn tó wà ní òde ìlú náà. Yàtọ̀ síyẹn, ó ṣeé ṣe kó mọ̀ nípa àwọn ọba méjì tó já sínú kòtò tó ní ọ̀dà bítúmẹ́nì nítòsí ìlú wọn. (Jẹ́n. 14:8-12) Ká má sì gbàgbé pé olórí ìdílé ni Lọ́ọ̀tì, torí náà ó lè máa ṣàníyàn nípa ìdílé rẹ̀. Bákan náà, ọlọ́rọ̀ ni, ó sì ṣeé ṣe kó ní ilé tó rẹwà gan-an ní Sódómù. (Jẹ́n. 13:5, 6) Ká sòótọ́, kò yẹ kí Lọ́ọ̀tì torí àwọn ìdí yìí ṣàìgbọràn sí Jèhófà. Bó ti wù kó rí, Jèhófà gbójú fo àwọn àṣìṣe Lọ́ọ̀tì, ó sì pè é ní “ọkùnrin olódodo.”​—2 Pét. 2:7, 8.

Tá a bá ń tẹ́tí sáwọn míì, àá lóye wọn, àá sì máa gba tiwọn rò (Wo ìpínrọ̀ 15 àti 16) *

15. Dípò tá a fi máa ṣàríwísí àwọn èèyàn, kí ló yẹ ká ṣe?

15 Dípò tá a fi máa ṣàríwísí àwọn èèyàn, ṣe ló yẹ ká gbìyànjú láti mọ bí nǹkan ṣe rí lára wọn. Ohun tí Arábìnrin Veronica tó ń gbé ní Yúróòpù ṣe nìyẹn. Ó sọ pé: “Gbogbo ìgbà ni inú arábìnrin kan kì í dùn, ó sì fẹ́ràn kó máa dá wà. Torí náà, kì í yá mi lára láti bá a sọ̀rọ̀ nígbà míì. Mo wá ronú pé ‘Tó bá jẹ́ pé èmi ni mo wà nípò ẹ̀, ó dájú pé màá fẹ́ káwọn èèyàn sún mọ́ mi.’ Torí náà, mo sún mọ́ ọn kí n lè mọ ohun tó ń ṣe é. Bó ṣe bẹ̀rẹ̀ sí í sọ gbogbo nǹkan tó ń ṣe é fún mi nìyẹn o! Ní báyìí, ọ̀rọ̀ ẹ̀ ti yé mi dáadáa.”

16. Kí nìdí tó fi yẹ ká bẹ Jèhófà pé kó jẹ́ ká lè máa gba tàwọn míì rò?

16 Jèhófà nìkan ló mọ bí nǹkan ṣe ń rí lára wa gan-an. (Òwe 15:11) Torí náà, bẹ̀ ẹ́ pé kó jẹ́ kó o máa rí ohun tó ń rí lára àwọn èèyàn, kó o sì ní kó jẹ́ kó o mọ bó o ṣe lè máa gba tiwọn rò. Bí àpẹẹrẹ, àdúrà tí Arábìnrin Anzhela gbà ló jẹ́ kó máa gba tàwọn míì rò. Arábìnrin kan wà nínú ìjọ wọn tó ṣòro bá lò, Arábìnrin Anzhela wá sọ pé: “Ó ṣe mí bíi pé kí n ṣàríwísí arábìnrin náà, kí n sì pa á tì. Àmọ́, mo bẹ Jèhófà pé kó jẹ́ kí n lóye ẹ̀ kí n sì gba tiẹ̀ rò.” Ṣé Jèhófà dáhùn àdúrà Arábìnrin Anzhela? Ó sọ pé: “A jọ lọ sóde ẹ̀rí, ọ̀pọ̀ wákàtí la sì fi jọ sọ̀rọ̀ lẹ́yìn náà. Mo fara balẹ̀ tẹ́tí sí i, àánú ẹ̀ sì ṣe mí. Mo ti wá nífẹ̀ẹ́ ẹ̀ gan-an, mo sì pinnu pé màá ràn án lọ́wọ́.”

17. Kí ló yẹ kó o pinnu pé wàá ṣe?

17 Gbogbo àwọn ará wa ló yẹ ká máa gba tiwọn rò, ká má ṣe ya ẹnikẹ́ni sọ́tọ̀. Gbogbo wọn ló ń kojú ìṣòro bíi ti Jónà, Èlíjà, Hágárì àti Lọ́ọ̀tì. Díẹ̀ lára àwọn ìṣòro náà sì lè jẹ́ èyí tí wọ́n fọwọ́ ara wọn fà. Ká sòótọ́, ṣé a rẹ́ni tó lè sọ pé irú ẹ̀ ò ṣẹlẹ̀ sóun rí? Ó bọ́gbọ́n mu nígbà náà pé Jèhófà ní ká máa gba ti ara wa rò. (1 Pét. 3:8) Tá a bá ń ṣe bẹ́ẹ̀, àá máa pa kún ìṣọ̀kan tó wà láàárín ẹgbẹ́ ará kárí ayé. Torí náà, pinnu pé wàá máa fara balẹ̀ tẹ́tí sáwọn ará, wàá túbọ̀ mọ̀ wọ́n, wàá sì máa gba tiwọn rò.

ORIN 87 Ẹ Wá Gba Ìtura

^ ìpínrọ̀ 5 Torí pé aláìpé ni wá, a sábà máa ń ní èrò òdì nípa àwọn míì, a sì máa ń fura sí wọn. Àmọ́ Jèhófà “ń rí ohun tó wà nínú ọkàn.” (1 Sám. 16:7) Nínú àpilẹ̀kọ yìí, a máa rí bí Jèhófà ṣe fìfẹ́ ran Jónà, Èlíjà, Hágárì àti Lọ́ọ̀tì lọ́wọ́. Bákan náà, a máa rí bá a ṣe lè fara wé Jèhófà nínú bá a ṣe ń bá àwọn arákùnrin àtàwọn arábìnrin wa lò.

^ ìpínrọ̀ 52 ÀWÒRÁN: Inú bí arákùnrin àgbàlagbà kan sí arákùnrin míì tó pẹ́ dé sípàdé, àmọ́ nígbà tó yá, ó rí i pé torí pé wọ́n kọlu mọ́tò ẹ̀ ló jẹ́ kó pẹ́.

^ ìpínrọ̀ 54 ÀWÒRÁN: Alábòójútó àwùjọ kan ronú pé arábìnrin kan fẹ́ràn kó máa ya ara ẹ̀ sọ́tọ̀, àmọ́ nígbà tó yá, ó mọ̀ pé ojú máa ń tì í tó bá wà láàárín àwọn tí kò fi bẹ́ẹ̀ mọ̀ dáadáa.

^ ìpínrọ̀ 56 ÀWÒRÁN: Nígbà tí arábìnrin kan sún mọ́ arábìnrin míì tí wọ́n sì jọ sọ̀rọ̀ ló tó mọ̀ pé kì í ṣe ẹni tó máa ń ya ara ẹ̀ sọ́tọ̀ bóun ṣe rò nígbà táwọn kọ́kọ́ ríra ní Gbọ̀ngàn Ìjọba.