Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

ÀPILẸ̀KỌ FÚN ÌKẸ́KỌ̀Ọ́ 17

“Mo Pè Yín Ní Ọ̀rẹ́”

“Mo Pè Yín Ní Ọ̀rẹ́”

“Mo pè yín ní ọ̀rẹ́, torí pé mo ti jẹ́ kí ẹ mọ gbogbo ohun tí mo gbọ́ látọ̀dọ̀ Baba mi.”​—JÒH. 15:15.

ORIN 13 Kristi, Àwòkọ́ṣe Wa

OHUN TÁ A MÁA JÍRÒRÒ *

1. Báwo lo ṣe lè di ọ̀rẹ́ ẹnì kan?

KÓ O tó lè di ọ̀rẹ́ ẹnì kan, ó ṣe pàtàkì kó o lo àkókò pẹ̀lú onítọ̀hún, kẹ́ ẹ sì jọ máa sọ̀rọ̀. Bẹ́ ẹ ṣe jọ ń sọ̀rọ̀, tẹ́ ẹ sì ń sọ àwọn nǹkan tó ń ṣẹlẹ̀ sí yín, bẹ́ẹ̀ lẹ ṣe máa túbọ̀ mọwọ́ ara yín. Àmọ́ tó bá di pé ká di ọ̀rẹ́ Jésù kì í fi bẹ́ẹ̀ rọrùn. Kí làwọn nǹkan tó lè mú kó ṣòro?

2. Kí lohun àkọ́kọ́ tó lè mú kó ṣòro láti dọ̀rẹ́ Jésù?

2 Ohun àkọ́kọ́ tó lè mú kó ṣòro láti dọ̀rẹ́ Jésù ni pé a ò rí Jésù sójú. Bó ṣe rí fún ọ̀pọ̀ Kristẹni ní ọgọ́rùn-ún ọdún kìíní náà nìyẹn. Síbẹ̀, àpọ́sítélì Pétérù sọ pé: “Bí ẹ ò tiẹ̀ rí i rí, ẹ nífẹ̀ẹ́ rẹ̀. Bí ẹ ò tiẹ̀ rí i báyìí, síbẹ̀ ẹ ní ìgbàgbọ́ nínú rẹ̀.” (1 Pét. 1:8) Torí náà, ó ṣeé ṣe ká di ọ̀rẹ́ tímọ́tímọ́ pẹ̀lú Jésù bá ò tiẹ̀ rí i rí.

3. Kí lohun kejì tó lè mú kó ṣòro?

3 Ohun kejì tó lè mú kó ṣòro ni pé a ò lè bá Jésù sọ̀rọ̀ ní tààràtà. Tá a bá ń gbàdúrà, Jèhófà là ń bá sọ̀rọ̀. Lóòótọ́ a máa ń gbàdúrà lórúkọ Jésù, àmọ́ kì í ṣe òun là ń bá sọ̀rọ̀ ní tààràtà. Kódà, Jésù gan-an ò fẹ́ ká gbàdúrà sí òun. Kí nìdí? Ìdí ni pé àdúrà wà lára ìjọsìn wa, Jèhófà nìkan ló sì yẹ ká jọ́sìn. (Mát. 4:10) Síbẹ̀, a ṣì lè fi hàn pé a nífẹ̀ẹ́ Jésù.

4. Kí lohun kẹta tó lè mú kó ṣòro, kí la sì máa jíròrò nínú àpilẹ̀kọ yìí?

4 Ohun kẹta tó lè mú kó ṣòro ni pé ọ̀run ni Jésù ń gbé, torí náà kò sí bá a ṣe lè jọ wà pa pọ̀. Àmọ́, a ṣì lè mọ ọ̀pọ̀ nǹkan nípa Jésù láìsí pé a wà pa pọ̀. Nínú àpilẹ̀kọ yìí, a máa jíròrò àwọn nǹkan mẹ́rin tá a lè ṣe táá mú ká di ọ̀rẹ́ tímọ́tímọ́ pẹ̀lú Jésù. Lákọ̀ọ́kọ́ ná, ẹ jẹ́ ká jíròrò ìdí tó fi ṣe pàtàkì pé ká di ọ̀rẹ́ tímọ́tímọ́ pẹ̀lú Jésù.

KÍ NÌDÍ TÓ FI YẸ KÁ DI Ọ̀RẸ́ JÉSÙ?

5. Kí nìdí tó fi ṣe pàtàkì pé ká di ọ̀rẹ́ Jésù? (Tún wo àwọn àpótí náà, “ Tá A Bá Jẹ́ Ọ̀rẹ́ Jésù, Àá Di Ọ̀rẹ́ Jèhófà” àti “ Máa Fojú Tó Tọ́ Wo Jésù.”)

5 A gbọ́dọ̀ di ọ̀rẹ́ Jésù ká tó lè di ọ̀rẹ́ Jèhófà. Kí nìdí tá a fi sọ bẹ́ẹ̀? Ẹ jẹ́ ká wo ìdí méjì. Àkọ́kọ́, Jésù sọ fún àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ pé: “Baba fúnra rẹ̀ ní ìfẹ́ tó jinlẹ̀ fún yín, torí pé ẹ ní ìfẹ́ tó jinlẹ̀ fún mi.” (Jòh. 16:27) Ó tún sọ pé: “Kò sí ẹni tó ń wá sọ́dọ̀ Baba àfi nípasẹ̀ mi.” (Jòh. 14:6) Téèyàn bá fẹ́ di ọ̀rẹ́ Jèhófà láìkọ́kọ́ di ọ̀rẹ́ Jésù dà bí ìgbà téèyàn fẹ́ wọnú ilé kan láìgba ẹnu ọ̀nà wọlé. Jésù lo àkàwé yìí nígbà tó sọ pé òun ni “ẹnu ọ̀nà fún àwọn àgùntàn.” (Jòh. 10:7) Ìdí kejì ni pé Jésù gbé àwọn ànímọ́ Baba rẹ̀ yọ lọ́nà tó pé pérépéré. Ó sọ fún àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ pé: “Ẹnikẹ́ni tó bá ti rí mi ti rí Baba náà.” (Jòh. 14:9) Torí náà, ọ̀nà pàtàkì kan tá a lè gbà mọ Jèhófà ni pé ká kẹ́kọ̀ọ́ nípa ìgbésí ayé Jésù. Bá a ṣe túbọ̀ ń kẹ́kọ̀ọ́ nípa Jésù bẹ́ẹ̀ ni ìfẹ́ tá a ní fún un á túbọ̀ lágbára. Bá a ṣe túbọ̀ ń nífẹ̀ẹ́ Jésù, bẹ́ẹ̀ ni ìfẹ́ tá a ní fún Baba rẹ̀ á túbọ̀ jinlẹ̀.

6. Kí nìdí míì tó fi yẹ ká di ọ̀rẹ́ Jésù? Ṣàlàyé.

6 A gbọ́dọ̀ di ọ̀rẹ́ Jésù kí Jèhófà tó lè dáhùn àdúrà wa. Èyí kọjá ká kàn sọ pé “ní orúkọ Jésù” níparí àdúrà wa. A gbọ́dọ̀ mọ bí Jèhófà ṣe ń lo Jésù láti dáhùn àdúrà wa. Jésù sọ fún àwọn àpọ́sítélì rẹ̀ pé: “Ohunkóhun tí ẹ bá béèrè ní orúkọ mi, màá ṣe é.” (Jòh. 14:13) Bó tiẹ̀ jẹ́ pé Jèhófà ló ń gbọ́ àdúrà wa, Jésù ló fún láṣẹ láti mú ìpinnu Òun ṣẹ. (Mát. 28:18) Kí Jèhófà tó dáhùn àdúrà wa, ó máa wò ó bóyá à ń fi ìmọ̀ràn Jésù sílò. Bí àpẹẹrẹ, Jésù sọ pé: “Tí ẹ bá dárí ẹ̀ṣẹ̀ àwọn èèyàn jì wọ́n, Baba yín ọ̀run náà máa dárí jì yín; àmọ́ tí ẹ kò bá dárí ẹ̀ṣẹ̀ àwọn èèyàn jì wọ́n, Baba yín ò ní dárí àwọn ẹ̀ṣẹ̀ yín jì yín.” (Mát. 6:14, 15) Ẹ wo bó ti ṣe pàtàkì tó nígbà náà pé ká máa bá àwọn èèyàn lò bí Jèhófà àti Jésù ṣe ń bá wa lò!

7. Àwọn wo ló máa jàǹfààní látinú ẹbọ ìràpadà Jésù?

7 Àwọn tó jẹ́ ọ̀rẹ́ Jésù nìkan ló máa jàǹfààní ẹbọ ìràpadà rẹ̀. Báwo la ṣe mọ̀? Jésù sọ pé òun máa fi ‘ẹ̀mí òun lélẹ̀ nítorí àwọn ọ̀rẹ́ òun.’ (Jòh. 15:13) Àwọn olóòótọ́ tó gbáyé kí Jésù tó wá sáyé ṣì máa kẹ́kọ̀ọ́ nípa Jésù kí wọ́n sì nífẹ̀ẹ́ rẹ̀. Jèhófà máa jí àwọn ọkùnrin àti obìnrin olóòótọ́ bí Ábúráhámù, Sérà, Mósè àti Ráhábù dìde, àmọ́ wọ́n gbọ́dọ̀ di ọ̀rẹ́ Jésù kí wọ́n tó lè ní ìyè àìnípẹ̀kun.​—Jòh. 17:3; Ìṣe 24:15; Héb. 11:8-12, 24-26, 31.

8-9. Bó ṣe wà nínú Jòhánù 15:4, 5, kí ni àjọṣe tá a ní pẹ̀lú Jésù á jẹ́ ká lè ṣe, kí sì nìdí tíyẹn fi ṣe pàtàkì?

8 Inú wa ń dùn bá a ṣe ń ṣiṣẹ́ pẹ̀lú Jésù lẹ́nu iṣẹ́ ìwàásù Ìjọba Ọlọ́run tá a sì ń kọ́ àwọn èèyàn lẹ́kọ̀ọ́. Olùkọ́ ni Jésù nígbà tó wà láyé. Lẹ́yìn tó pa dà sọ́run, ó di orí ìjọ, àtìgbà yẹn ló sì ti ń darí iṣẹ́ ìwàásù àti kíkọ́ni tá à ń ṣe. Ó ń rí gbogbo bó o ṣe ń sapá láti ran ọ̀pọ̀ èèyàn lọ́wọ́ kí wọ́n lè mọ òun àti Jèhófà, ó sì mọyì ìsapá rẹ gan-an. Òótọ́ ibẹ̀ ni pé kò sí bá a ṣe lè ṣe iṣẹ́ yìí yanjú láìjẹ́ pé Jèhófà àti Jésù ràn wá lọ́wọ́.​—Ka Jòhánù 15:4, 5.

9 Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run jẹ́ kó ṣe kedere pé ká tó lè múnú Jèhófà dùn, a gbọ́dọ̀ nífẹ̀ẹ́ Jésù. Torí náà, ẹ jẹ́ ká jíròrò nǹkan mẹ́rin tá a lè ṣe ká lè di ọ̀rẹ́ Jésù.

BÍ A ṢE LÈ DI Ọ̀RẸ́ JÉSÙ

O lè di ọ̀rẹ́ Jésù tó o bá (1) túbọ̀ mọ Jésù, (2) ń ronú tó o sì ń hùwà bíi ti Jésù, (3) ń ti àwọn arákùnrin Kristi lẹ́yìn tó o sì ń (4) ti ètò tí ìjọ ṣe lẹ́yìn (Wo ìpínrọ̀ 10 sí 14) *

10. Kí lohun àkọ́kọ́ tá a gbọ́dọ̀ ṣe ká tó lè di ọ̀rẹ́ Jésù?

10 (1Mọ Jésù. A lè ṣe bẹ́ẹ̀ tá a bá ń ka àwọn Ìwé Ìhìn Rere Mátíù, Máàkù, Lúùkù àti Jòhánù. Bá a ṣe ń kíyè sí bí Jésù ṣe fìfẹ́ bá àwọn èèyàn lò nínú àwọn ìwé yìí tá a sì ń ṣàṣàrò lé wọn lórí, àá túbọ̀ nífẹ̀ẹ́ Jésù, àá sì ní ọ̀wọ̀ tó jinlẹ̀ fún un. Bí àpẹẹrẹ, kò ṣe àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ bí ẹrú bó tiẹ̀ jẹ́ pé òun ni Ọ̀gá wọn. Dípò bẹ́ẹ̀, ó jẹ́ kí wọ́n mọ gbogbo ohun tó wà lọ́kàn òun àti bí nǹkan ṣe rí lára òun. (Jòh. 15:15) Jésù bá wọn kẹ́dùn, kódà ó sunkún pẹ̀lú wọn. (Jòh. 11:32-36) Àwọn ọ̀tá rẹ̀ pàápàá gbà pé ó di ọ̀rẹ́ àwọn tó tẹ́tí sí ọ̀rọ̀ rẹ̀. (Mát. 11:19) Tá a bá tẹ̀ lé àpẹẹrẹ bí Jésù ṣe bá àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ lò, àá ní àjọṣe tó dáa pẹ̀lú àwọn míì, ọkàn wa máa balẹ̀, àá láyọ̀, àá sì túbọ̀ mọyì Kristi.

11. Kí lohun kejì tá a gbọ́dọ̀ ṣe ká tó lè di ọ̀rẹ́ Jésù, kí sì nìdí tíyẹn fi ṣe pàtàkì?

11 (2Máa ronú kó o sì máa hùwà bíi ti Jésù. Bá a ṣe túbọ̀ ń mọ Jésù tá a sì ń ronú bíi tiẹ̀, okùn ọ̀rẹ́ wa á túbọ̀ máa lágbára. (1 Kọ́r. 2:16) Báwo la ṣe lè fara wé Jésù? Ẹ jẹ́ ká wo àpẹẹrẹ kan. Bí Jésù ṣe máa ran àwọn míì lọ́wọ́ ló jẹ ẹ́ lógún, kì í ṣe bó ṣe máa tẹ́ ara ẹ̀ lọ́rùn. (Mát. 20:28; Róòmù 15:1-3) Torí pé ọ̀rọ̀ àwọn míì jẹ ẹ́ lógún ló mú kó fi ẹ̀mí ara rẹ̀ rúbọ, ìyẹn náà ló sì mú kó máa dárí jini. Kì í bínú táwọn èèyàn bá sọ̀rọ̀ tí kò dáa nípa ẹ̀. (Jòh. 1:46, 47) Kì í fi àṣìṣe téèyàn ṣe tipẹ́tipẹ́ hùwà sí i, kò sì ronú pé wọn ò lè yí pa dà. (1 Tím. 1:12-14) Jésù sọ pé: “Gbogbo èèyàn máa . . . mọ̀ pé ọmọ ẹ̀yìn mi ni yín, tí ìfẹ́ bá wà láàárín yín.” (Jòh. 13:35) O ò ṣe bi ara ẹ pé, “Ṣé mò ń tẹ̀ lé àpẹẹrẹ Jésù, ṣé mo sì ń wà ní àlàáfíà pẹ̀lú àwọn arákùnrin àtàwọn arábìnrin mi?”

12. Kí lohun kẹta tá a gbọ́dọ̀ ṣe ká tó lè di ọ̀rẹ́ Jésù, báwo la sì ṣe lè ṣe bẹ́ẹ̀?

12 (3Máa ti àwọn arákùnrin Kristi lẹ́yìn. Jésù gbà pé tá a bá ti àwọn arákùnrin òun tó jẹ́ ẹni àmì òróró lẹ́yìn, òun là ń tì lẹ́yìn. (Mát. 25:34-40) Ọ̀nà tó ṣe pàtàkì jù tá a lè gbà ti àwọn ẹni àmì òróró lẹ́yìn ni pé ká máa lọ́wọ́ nínú iṣẹ́ ìwàásù àti sísọni di ọmọ ẹ̀yìn bí Jésù ṣe pàṣẹ fáwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀. (Mát. 28:19, 20; Ìṣe 10:42) Láìsí ìtìlẹyìn àwọn “àgùntàn mìíràn,” àwọn arákùnrin Kristi kò ní lè wàásù ìhìn rere náà dé gbogbo ayé. (Jòh. 10:16) Tó o bá wà lára àwọn àgùntàn mìíràn, jẹ́ kó dá ẹ lójú pé bó o ṣe ń wàásù tó o sì ń sọni dọmọ ẹ̀yìn, àwọn ẹni àmì òróró nìkan kọ́ lò ń tì lẹ́yìn, ṣe lo tún ń fi hàn pé o nífẹ̀ẹ́ Jésù.

13. Báwo la ṣe lè fi ìmọ̀ràn Jésù tó wà nínú Lúùkù 16:9 sílò?

13 A tún lè di ọ̀rẹ́ Jèhófà àti Jésù tá a bá ń lo owó àtohun ìní wa fún ìtìlẹyìn iṣẹ́ ìwàásù tí wọ́n ń darí. (Ka Lúùkù 16:9.) Bí àpẹẹrẹ, a lè fi owó ti iṣẹ́ tí ètò Ọlọ́run ń ṣe kárí ayé lẹ́yìn. Lára ohun tí wọ́n ń lo owó yìí fún ni iṣẹ́ ìwàásù láwọn ibi àdádó, kíkọ́ àwọn ibi ìjọsìn wa àti títún wọn ṣe. Wọ́n sì tún ń lo owó náà láti ṣèrànwọ́ fún àwọn tí àjálù dé bá. Yàtọ̀ síyẹn, ó yẹ ká máa fowó sínú àpótí láwọn ìpàdé wa, ká sì tún máa ṣèrànwọ́ fáwọn tó nílò ìrànlọ́wọ́ nínú ìjọ wa. (Òwe 19:17) Tá a bá ń ṣe àwọn nǹkan yìí, ṣe là ń ti àwọn arákùnrin Kristi lẹ́yìn.

14. Bó ṣe wà nínú Éfésù 4:15, 16, kí lohun kẹrin tá a gbọ́dọ̀ ṣe ká tó lè di ọ̀rẹ́ Jésù?

14 (4Máa ti ètò tí ìjọ bá ṣe lẹ́yìn. Àá túbọ̀ di ọ̀rẹ́ Jésù tó jẹ́ orí ìjọ tá a bá ń fọwọ́ sowọ́ pọ̀ pẹ̀lú àwọn tí Jésù sọ pé kó máa bójú tó wa. (Ka Éfésù 4:15, 16.) Bí àpẹẹrẹ, ètò Ọlọ́run fẹ́ rí i dájú pé gbogbo Gbọ̀ngàn Ìjọba là ń lò, a sì ń lò wọ́n lẹ́kùn-ún rẹ́rẹ́. Nípa bẹ́ẹ̀, wọ́n ti da àwọn ìjọ mélòó kan pọ̀, wọ́n sì ti ṣe àtúnṣe sáwọn ìpínlẹ̀ ìwàásù wọn. Èyí ti mú ká túbọ̀ máa ṣọ́wó ná. Àmọ́, ìṣètò yìí ti mú kí àwọn akéde tọ́rọ̀ kàn ṣe àwọn àyípadà kan. Bí àpẹẹrẹ, ó ṣeé ṣe káwọn akéde yìí ti mọwọ́ àwọn ará ìjọ tí wọ́n wà tẹ́lẹ̀ torí pé ọ̀pọ̀ ọdún ni wọ́n ti jọ wà. Àmọ́ ní báyìí, ètò Ọlọ́run ti ní kí wọ́n máa dara pọ̀ mọ́ ìjọ míì. Ẹ wo bí inú Jésù ṣe máa dùn tó bó ṣe ń rí i táwọn akéde olóòótọ́ yìí ń mú ara wọn bá ipò tuntun náà mu!

O LÈ DI Ọ̀RẸ́ JÉSÙ TÍTÍ LÁÉ

15. Kí lá mú kí àjọṣe tó wà láàárín àwa àti Jésù túbọ̀ lágbára lọ́jọ́ iwájú?

15 Àwọn ẹni àmì òróró máa wà pẹ̀lú Jésù títí láé torí pé wọ́n á jọ ṣàkóso nínú Ìjọba Ọlọ́run. Wọ́n á wà pẹ̀lú Jésù, wọ́n á rí i lójúkojú, wọ́n á jọ máa sọ̀rọ̀, wọ́n á sì jọ máa ṣe nǹkan pọ̀. (Jòh. 14:2, 3) Bákan náà, Jésù máa fìfẹ́ hàn sáwọn tó máa gbé títí láé lórí ilẹ̀ ayé, á sì máa bójú tó wọn. Bó tiẹ̀ jẹ́ pé wọn ò ní rí Jésù lójúkojú, àjọṣe tó wà láàárín wọn á túbọ̀ máa lágbára bí wọ́n ṣe ń gbádùn ìyè àìnípẹ̀kun tí Jèhófà àti Jésù mú kó ṣeé ṣe fún wọn.​—Àìsá. 9:6, 7.

16. Àǹfààní wo la máa rí tá a bá di ọ̀rẹ́ Jésù?

16 Tá a bá gbà láti di ọ̀rẹ́ Jésù, ọ̀pọ̀ àǹfààní la máa rí. Bí àpẹẹrẹ, à ń jàǹfààní nísinsìnyí bó ṣe ń fìfẹ́ hàn sí wa tó sì ń tì wá lẹ́yìn. Yàtọ̀ síyẹn, a tún láǹfààní láti wà láàyè títí láé lọ́jọ́ iwájú. Ju gbogbo ẹ̀ lọ, bá a ṣe jẹ́ ọ̀rẹ́ Jésù máa jẹ́ ká di ọ̀rẹ́ ẹni tó ga jù lọ láyé àti lọ́run, ìyẹn Jèhófà Baba Jésù. Ẹ ò rí i pé àǹfààní aláìlẹ́gbẹ́ la ní bá a ṣe jẹ́ ọ̀rẹ́ Jésù!

ORIN 17 “Mo Fẹ́ Bẹ́ẹ̀”

^ ìpínrọ̀ 5 Àwọn àpọ́sítélì lo ọdún mélòó kan pẹ̀lú Jésù, wọ́n jọ sọ̀rọ̀, wọ́n jọ ṣiṣẹ́, ìyẹn sì mú kí wọ́n di ọ̀rẹ́ ara wọn. Jésù fẹ́ káwa náà di ọ̀rẹ́ òun, àmọ́ àwọn nǹkan kan wà tó lè mú kó ṣòro fún wa láti dọ̀rẹ́ Jésù tí kò sì rí bẹ́ẹ̀ fáwọn àpọ́sítélì. Nínú àpilẹ̀kọ yìí, a máa jíròrò díẹ̀ lára àwọn nǹkan tó lè mú kó ṣòro láti di ọ̀rẹ́ Jésù, àá sì sọ àwọn nǹkan tá a lè ṣe táá jẹ́ ká di ọ̀rẹ́ rẹ̀ kí okùn ọ̀rẹ́ wa má sì já.

^ ìpínrọ̀ 55 ÀWÒRÁN: (1) A lè kẹ́kọ̀ọ́ nípa ìgbésí ayé Jésù àti iṣẹ́ òjíṣẹ́ rẹ̀ nígbà Ìjọsìn Ìdílé wa. (2) Nínú ìjọ, ó yẹ ká ṣe gbogbo ohun tá a lè ṣe ká lè wà ní àlàáfíà pẹ̀lú àwọn arákùnrin àtàwọn arábìnrin wa. (3) Tá a bá ń lọ́wọ́ nínú iṣẹ́ ìwàásù nígbà gbogbo, àwọn arákùnrin Kristi là ń tì lẹ́yìn. (4) Tí wọ́n bá da ìjọ wa pọ̀ pẹ̀lú ìjọ míì, ẹ jẹ́ ká fọwọ́ sowọ́ pọ̀ pẹ̀lú àwọn alàgbà.