Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

ÀPILẸ̀KỌ FÚN ÌKẸ́KỌ̀Ọ́ 21

Ṣé O Mọyì Àwọn Ẹ̀bùn Tí Ọlọ́run Fún Ẹ?

Ṣé O Mọyì Àwọn Ẹ̀bùn Tí Ọlọ́run Fún Ẹ?

Wo bí àwọn ohun tí o ṣe ti pọ̀ tó, Jèhófà Ọlọ́run mi, àwọn iṣẹ́ àgbàyanu rẹ àti èrò rẹ sí wa.”​SM. 40:5.

ORIN 5 Àwọn Iṣẹ́ Àgbàyanu Ọlọ́run

OHUN TÁ A MÁA JÍRÒRÒ *

1-2. Bó ṣe wà nínú Sáàmù 40:​5, àwọn ẹ̀bùn wo ni Jèhófà fún wa, kí sì nìdí tá a fi máa sọ̀rọ̀ nípa wọn?

Ọ̀LÀWỌ́ ni Jèhófà Ọlọ́run. Ẹ wo díẹ̀ lára àwọn ẹ̀bùn tó fún wa: àkọ́kọ́ ni ayé tó rẹwà tó sì dùn ún gbé; ìkejì ni ọpọlọ wa tí kò láfiwé; ìkẹta sì ni Bíbélì Ọ̀rọ̀ rẹ̀. Ayé tí Jèhófà fún wa yìí ló jẹ́ ká ríbi gbé, ọpọlọ tó fún wa ló jẹ́ ká lè máa ronú ká sì máa bára wa sọ̀rọ̀. Bíbélì Ọ̀rọ̀ rẹ̀ ló sì jẹ́ ká rí ìdáhùn sáwọn ìbéèrè tó ṣe pàtàkì jù.​—Ka Sáàmù 40:5.

2 Nínú àpilẹ̀kọ yìí, a máa sọ̀rọ̀ ṣókí nípa àwọn ẹ̀bùn mẹ́ta yìí. Tá a bá ronú jinlẹ̀ nípa àwọn ẹ̀bùn yìí, àá túbọ̀ mọyì wọn, á sì túbọ̀ máa wù wá láti múnú Jèhófà Ẹlẹ́dàá wa dùn. (Ìfi. 4:11) Èyí á mú kó rọrùn fún wa láti ṣèrànwọ́ fún àwọn tí kò gbà pé Ọlọ́run wà tàbí tó nígbàgbọ́ nínú ẹ̀kọ́ ẹfolúṣọ̀n.

AYÉ YÌÍ ṢÀRÀ Ọ̀TỌ̀

3. Kí ló mú kí ayé yìí ṣàrà ọ̀tọ̀?

3 Tá a bá fara balẹ̀ wo bí Jèhófà ṣe dá ayé yìí, àá gbà pé ọgbọ́n rẹ̀ kò láfiwé. (Róòmù 1:20; Héb. 3:4) Kì í ṣe ayé yìí nìkan ló ń yí oòrùn po, àmọ́ ayé yìí ṣàrà ọ̀tọ̀ torí pé òun nìkan ló ní gbogbo nǹkan tó ń gbẹ́mìí èèyàn ró.

4. Tá a bá wo bí Jèhófà ṣe dá ayé yìí, kí ló fi hàn pé ọgbọ́n rẹ̀ kò láfiwé? Ṣàpèjúwe.

4 Ojú òfúrufú gbalasa ni ayé wa yìí wà bí ìgbà tí ọkọ̀ kan wà lójú agbami. Àmọ́ ìyàtọ̀ wà láàárín ayé wa yìí àti ọkọ̀ táwọn èèyàn kúnnú ẹ̀. Bí àpẹẹrẹ, ẹ jẹ́ ká sọ pé àwọn tó wà nínú ọkọ̀ náà ló máa pèsè afẹ́fẹ́ oxygen tí wọ́n á máa mí, àwọn ló máa gbin oúnjẹ tí wọ́n á máa jẹ, àwọn ló máa pèsè omi tí wọ́n á máa mu, tí kò sì sí ibi tí wọ́n á da ìgbọ̀nsẹ̀ àtàwọn ìdọ̀tí míì sí. Ọdún mélòó lẹ rò pé wọ́n á lè lò nínú ọkọ̀ náà? Ó ṣe kedere pé wọn ò ní pẹ́ kú. Lọ́wọ́ kejì, ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọdún ni àìlóǹkà èèyàn, àwọn ẹranko àtàwọn nǹkan míì ti ń gbé lórí ilẹ̀ ayé yìí. Òun fúnra ẹ̀ ló ń pèsè afẹ́fẹ́ oxygen, oúnjẹ, omi àtàwọn nǹkan míì tó ń gbé ẹ̀mí wa ró, wọn ò sì dín kù látọjọ́ tí Ọlọ́run ti dá ayé yìí. Bó tiẹ̀ jẹ́ pé inú ayé yìí náà làwọn ìgbọ̀nsẹ̀ wa àtàwọn ìdọ̀tí míì wà, síbẹ̀ ayé yìí ṣì rẹwà, ó sì dùn ún gbé. Kí ló jẹ́ kíyẹn ṣeé ṣe? Ìdí ni pé ọ̀nà àgbàyanu kan wà tí ayé yìí gbà ń ṣe àtúnlò àwọn nǹkan tó ń gbẹ́mìí wa ró. Ẹ jẹ́ ká jíròrò méjì nínú wọn ní ṣókí, ìyẹn ìyípo afẹ́fẹ́ oxygen àti ìyípo omi.

5. Kí ló ṣàrà ọ̀tọ̀ nípa ìyípo afẹ́fẹ́ oxygen, kí nìyẹn sì jẹ́ kó ṣe kedere?

5 Afẹ́fẹ́ Oxygen tí àwa èèyàn àtàwọn ẹranko ń mí sínú ló ń jẹ́ ká wà láàyè. Àwọn onímọ̀ ìjìnlẹ̀ fojú bù ú pé ọgọ́rùn-ún bílíọ̀nù tọ́ọ̀nù afẹ́fẹ́ oxygen ni àwa èèyàn àtàwọn ẹranko ń mí sínú lọ́dún. Àwọn ohun alààyè yìí kan náà ń mí afẹ́fẹ́ carbon dioxide síta, èyí tá a lè fi wé ìdọ̀tí. Síbẹ̀, àwa èèyàn àtàwọn ẹranko ò lo afẹ́fẹ́ oxygen tó wà nínú ayé yìí tán, bẹ́ẹ̀ sì ni afẹ́fẹ́ carbon dioxide tá à ń mí síta kò gba ilé ayé kan. Kí ló mú kí èyí ṣeé ṣe? Ìdí ni pé Jèhófà dá àwọn ewéko, igi àtàwọn nǹkan tín-tìn-tín tí wọ́n ń lo afẹ́fẹ́ carbon dioxide tí wọ́n sì ń tú afẹ́fẹ́ oxygen síta. Ìyípo afẹ́fẹ́ oxygen yìí mú kí ọ̀rọ̀ inú Ìṣe 17:​24, 25 túbọ̀ ṣe kedere pé: “Ọlọ́run . . . ló ń fún gbogbo èèyàn ní ìyè àti èémí.”

6. Kí ló ṣàrà ọ̀tọ̀ nípa ìyípo omi, kí ló sì jẹ́ ká mọ̀ nípa Jèhófà? (Tún wo àpótí náà “ Ìyípo Omi Tí Jèhófà Fún Wa.”)

6 Omi wà lórí ilẹ̀ ayé yìí torí pé ayé ò jìnnà jù sí oòrùn bẹ́ẹ̀ sì ni kò sún mọ́ ọn jù. Bí ayé bá sún mọ́ oòrùn jù, ooru rẹ̀ á fa gbogbo omi ayé gbẹ; bó bá sì jìnnà jù, omi inú ayé yóò di yìnyín gbagidi. Bí Jèhófà ṣe dá ayé yìí tó sì fi í síbi tó yẹ ló mú kí ìyípo omi ṣeé ṣe kó lè máa gbé ẹ̀mí wa ró. Oòrùn máa ń fà lára omi tó wà nínú òkun, adágún, odò tàbí òkìtì yìnyín lọ sí ojú ọ̀run níbi tó ti máa gbára jọ. Lọ́dọọdún, iye omi tí oòrùn máa ń fà lọ sókè pọ̀ gan-an, kódà wọ́n fojú bù ú pé ó fẹ́rẹ̀ẹ́ tó máìlì ẹgbẹ̀rún lọ́nà ọgọ́fà (120,000) lóròó àti níbùú. Lẹ́yìn tí omi náà bá ti wà lójú òfúrufú fún nǹkan bí ọjọ́ mẹ́wàá, á rọ̀ bí òjò tàbí yìnyín. Àgbàrá òjò náà á ṣàn pa dà sínú òkun, adágún àti odò, ìyípo náà á sì máa bá a lọ bẹ́ẹ̀. Bí Jèhófà ṣe ṣe é kí omi máa yípo lọ́nà yìí jẹ́ kó ṣe kedere pé Jèhófà jẹ́ ọlọ́gbọ́n àti alágbára.​—Jóòbù 36:​27, 28; Oníw. 1:7.

7. Báwo la ṣe lè fi hàn pé a mọyì ẹ̀bùn tí Sáàmù 115:16 sọ̀rọ̀ nípa rẹ̀?

7 Kò sí àní-àní pé ẹ̀bùn tó ṣàrà ọ̀tọ̀ ni ayé wa yìí àtàwọn nǹkan rere míì tí Jèhófà dá sínú ẹ̀. Kí lá jẹ́ ká túbọ̀ mọyì wọn? (Ka Sáàmù 115:16.) Ọ̀kan lára ohun tá a lè ṣe ni pé ká máa ṣàṣàrò lórí àwọn nǹkan tí Jèhófà dá. Èyí á mú ká máa dúpẹ́ lọ́wọ́ rẹ̀ lójoojúmọ́ fáwọn nǹkan rere tó ń pèsè fún wa. Ohun míì tá a lè ṣe ni pé ká jẹ́ kí àyíká wa máa wà ní mímọ́ tónítóní nígbà gbogbo.

ÀGBÀYANU NI ỌPỌLỌ WA

8. Kí nìdí tá a fi sọ pé ọ̀nà àgbàyanu ni Jèhófà gbà dá ọpọlọ wa?

8 Ọpọlọ àwa èèyàn ṣàrà ọ̀tọ̀, kódà àgbàyanu ni. Ìgbà tí ọmọ kan bá wà nínú ìyá rẹ̀ ni ọpọlọ rẹ̀ á ti wà létòletò, tí ọpọlọ náà à máa dàgbà díẹ̀díẹ̀, ẹgbẹẹgbẹ̀rún sẹ́ẹ̀lì tuntun á sì máa rú yọ níṣẹ̀ẹ́jú kọ̀ọ̀kan. Àwọn onímọ̀ ìjìnlẹ̀ fojú bù ú pé iṣan tó wà nínú ọpọlọ ẹnì kan tó ti dàgbà tó bílíọ̀nù lọ́nà ọgọ́rùn-ún. Jèhófà fara balẹ̀ ṣètò àwọn iṣan ọpọlọ wa yìí lọ́nà àgbàyanu, tá a bá sì gbé e sórí òṣùwọ̀n ó fẹ́rẹ̀ẹ́ tó kílò kan ààbọ̀ (1.5 kg). Ẹ jẹ́ ká wo díẹ̀ lára ohun tó mú kí ọpọlọ wa ṣàrà ọ̀tọ̀.

9. Kí ló mú kó o gbà pé ẹ̀bùn látọ̀dọ̀ Jèhófà ni bá a ṣe ń sọ̀rọ̀?

9 Téèyàn bá ronú jinlẹ̀, ó máa gbà pé iṣẹ́ ìyanu ni bá a ṣe ń sọ̀rọ̀. Jẹ́ ká wò ó báyìí ná. Gbogbo ìgbà tá a bá ń sọ̀rọ̀ ni ọpọlọ wa máa ń darí àwọn iṣan bí ọgọ́rùn-ún tó wà ní ahọ́n, ọ̀fun, ètè, àgbọ̀n àti àyà wa. Àwọn iṣan náà sì gbọdọ̀ ṣiṣẹ́ ní àsìkò tó yẹ gẹ́lẹ́, àìjẹ́ bẹ́ẹ̀ ọ̀rọ̀ wa ò ní já geere. Bákan náà, ìwádìí kan tí wọ́n ṣe lọ́dún 2019 fi hàn pé, àwọn ọmọ jòjòló lè dá ohùn èèyàn mọ̀ kí wọ́n sì gbọ́ èdè tẹ́nì kan bá sọ sí wọn. Ìwádìí yìí jẹ́rìí sí i pé àtikékeré la ti ní agbára láti kọ́ èdè ká sì lóye ọ̀rọ̀. Kò sí àní-àní pé ẹ̀bùn látọ̀dọ̀ Ọlọ́run ni bá a ṣe ń sọ̀rọ̀.​—Ẹ́kís. 4:11.

10. Báwo la ṣe lè fi hàn pé a mọyì ẹ̀bùn ọ̀rọ̀ sísọ tí Ọlọ́run fún wa?

10 Ọ̀kan lára ọ̀nà tá a lè gbà fi hàn pé a mọyì ẹ̀bùn ọ̀rọ̀ sísọ tí Ọlọ́run fún wa ni pé ká jẹ́ káwọn tó nígbàgbọ́ nínú ẹ̀kọ ẹfolúṣọ̀n mọ ìdí tá a fi gbà pé Ọlọ́run wà. (Sm. 9:1; 1 Pét. 3:15) Àwọn tó gba ẹ̀kọ́ yìí gbọ́ máa ń sọ pé ṣe ni ayé yìí kàn ṣàdédé wà. Torí náà, a lè lo Bíbélì àtàwọn kókó tá a ti jíròrò nínú àpilẹ̀kọ yìí láti jẹ́ káwọn èèyàn mọ̀ nípa Baba wa ọ̀run, ká sì ṣàlàyé fáwọn tó ṣe tán láti gbọ́ ìdí tá a fi gbà pé Jèhófà ni Ẹlẹ́dàá ọ̀run àti ayé.​—Sm. 102:25; Àìsá. 40:​25, 26.

11. Kí lohun kan tó mú kí ọpọlọ àwa èèyàn jọni lójú?

11 Agbára tá a ní láti rántí nǹkan jọni lójú gan-an. Ìgbà kan wà tí òǹkọ̀wé kan fojú bù ú pé ọpọlọ wa lágbára láti rántí ìsọfúnni tó lè kún ìwé bíi mílíọ̀nù lọ́nà ogún. Àmọ́ ní báyìí, àwọn olùṣèwádìí sọ pé agbára tí ọpọlọ wa ní láti rántí nǹkan jù bẹ́ẹ̀ lọ, kódà kò ṣeé díwọ̀n. Kí lẹ̀bùn yìí máa mú ká lè ṣe?

12. Báwo ni agbára tá a ní láti kẹ́kọ́ọ̀ ká sì fohun tá a kọ́ sílò ṣe mú ká yàtọ̀ sáwọn ẹranko?

12 Nínú gbogbo ohun tí Jèhófà dá sáyé, àwa èèyàn nìkan la lè kẹ́kọ̀ọ́ látinú ohun tó ti ṣẹlẹ̀ kọjá, ká sì fi ohun tá a kọ́ sílò. Èyí mú ká lè máa ṣàtúnṣe sí bá a ṣe ń ronú àti bá a ṣe ń gbé ìgbésí ayé wa. (1 Kọ́r. 6:​9-11; Kól. 3:​9, 10) Kódà, a lè kọ́ ẹ̀rí ọkàn wa láti fi ìyàtọ̀ sáàárín ohun tó tọ́ àti ohun tí kò tọ́. (Héb. 5:14) A lè fi hàn pé a nífẹ̀ẹ́ àwọn èèyàn, ká ṣojúure sí wọn, ká sì fàánú hàn sí wọn. Yàtọ̀ síyẹn, a lè fara wé bí Jèhófà ṣe máa ń ṣèdájọ́ òdodo.

13. Bó ṣe wà nínú Sáàmù 77:​11, 12, báwo la ṣe lè fi hàn pé a mọyì agbára tá a ní láti rántí nǹkan?

13 Ọ̀pọ̀ ọ̀nà la lè gbà fi hàn pé a mọyì agbára tá a ní láti rántí nǹkan. Ọ̀kan ni pé ká má ṣe gbàgbé àwọn ohun tí Jèhófà ti ṣe fún wa, bó ṣe ràn wá lọ́wọ́, tó sì tù wá nínú. Èyí máa jẹ́ kó túbọ̀ dá wa lójú pé ó máa ràn wá lọ́wọ́ lọ́jọ́ iwájú. (Ka Sáàmù 77:​11, 12; 78:​4, 7) Ohun míì tá a lè ṣe ni pé ká máa rántí ohun táwọn èèyàn ṣe fún wa, ká sì máa dúpẹ́ oore. Àwọn tó ń ṣèwádìí sọ pé àwọn tó bá moore máa ń láyọ̀. Ó tún yẹ ká fara wé Jèhófà tó máa ń yàn láti gbàgbé àwọn nǹkan kan. Bí àpẹẹrẹ, agbára ìrántí Jèhófà ò láàlà, síbẹ̀ tí ẹlẹ́ṣẹ̀ kan bá ronú pìwà dà, Jèhófà máa dárí jì í, á sì gbàgbé àṣìṣe tẹ́ni náà ṣe. (Sm. 25:7; 130:​3, 4) Ohun kan náà ni Jèhófà fẹ́ ká ṣe, ká máa dárí ji àwọn tó bá ṣẹ̀ wá, kódà bí ohun tí wọ́n ṣe bá tiẹ̀ dùn wá.​—Mát. 6:14; Lúùkù 17:​3, 4.

A lè fi hàn pé a mọyì ọpọlọ tí Jèhófà fún wa tá a bá fi ń bọlá fún un (Wo ìpínrọ̀ 14) *

14. Báwo la ṣe lè fi hàn pé a mọyì ẹ̀bùn àgbàyanu tí Jèhófà fún wa?

14 A lè fi hàn pé a mọyì ọpọlọ tí Jèhófà Ẹlẹ́dàá fún wa tá a bá ń lò ó láti bọlá fún un. Àwọn kan ò mọyì ẹ̀bùn yìí torí pé àǹfààní ara wọn nìkan ni wọ́n ń lò ó fún, wọ́n máa ń ṣe ohun tí wọ́n fẹ́ láìfi ìlànà Ọlọ́run pè. Àmọ́, ṣó tiẹ̀ yẹ kí Jèhófà fún wa ní ìlànà? Bẹ́ẹ̀ ni, ó bọ́gbọ́n mu torí pé òun ló dá wa, ìlànà rẹ̀ ló sì bọ́gbọ́n mu jù lọ. (Róòmù 12:​1, 2) Tá a bá ń tẹ̀ lé àwọn ìlànà rẹ̀, ọkàn wa máa balẹ̀. (Àìsá. 48:​17, 18) Àá mọ ohun tí Jèhófà fẹ́ ká fayé wa ṣe, ìyẹn ni pé ká máa bọlá fún Jèhófà tó jẹ́ Ẹlẹ́dàá wa, ká sì máa múnú ẹ̀ dùn.​—Òwe 27:11.

Ẹ̀BÙN IYEBÍYE NI BÍBÉLÌ

15. Báwo ni bí Jèhófà ṣe fún wa ní Bíbélì ṣe fi hàn pé ó nífẹ̀ẹ́ wa?

15 Ẹ̀bùn iyebíye ni Bíbélì látọ̀dọ̀ Ọlọ́run. Ìfẹ́ tí Baba wa ọ̀run ní sí àwa ọmọ rẹ̀ ló mú kó mí sí àwọn èèyàn láti kọ ọ́. Jèhófà ń lo Bíbélì láti dáhùn àwọn ìbéèrè tó ṣe pàtàkì jù tá a máa ń béèrè. Lára wọn ni: Ibo gan-an la ti wá? Kí nìdí tí Ọlọ́run fi dá wa sáyé? Kí ló sì máa ṣẹlẹ̀ lọ́jọ́ iwájú? Jèhófà fẹ́ kí gbogbo àwa ọmọ rẹ̀ mọ ìdáhùn sáwọn ìbéèrè yìí, torí náà ọ̀pọ̀ ọdún sẹ́yìn ló ti ń mú kí àwọn èèyàn túmọ̀ Bíbélì sí onírúurú èdè. Lónìí, odindi Bíbélì tàbí apá kan rẹ̀ ti wà ní èdè tó ju ẹgbẹ̀rún mẹ́ta (3,000) lọ. Òun ni ìwé tí wọ́n túmọ̀ sí èdè tó pọ̀ jù lọ, tí wọ́n sì pín kiri jù lọ látìgbà táláyé ti dáyé. Ibi yòówù káwọn èèyàn máa gbé, èdè yòówù kí wọ́n máa sọ, ọ̀pọ̀ èèyàn ló láǹfààní láti máa ka Bíbélì ní èdè ìbílẹ̀ wọn.​—Wo àpótí náà “ Bíbélì Wà ní Ọ̀pọ̀ Èdè Nílẹ̀ Áfíríkà.”

16. Bó ṣe wà nínú Mátíù 28:​19, 20 àti àlàyé inú ìpínrọ̀ yìí, báwo la ṣe lè fi hàn pé a mọyì Bíbélì?

16 A lè fi hàn pé a mọyì Bíbélì tá a bá ń kà á lójoojúmọ́, tá à ń kẹ́kọ̀ọ́ ẹ̀, tá à ń ṣàṣàrò lórí ohun tá a kọ́, tá a sì ń ṣe gbogbo ohun tá a lè ṣe láti fi ohun tá a kọ́ sílò. Bákan náà, a lè fi hàn pé a mọyì ẹ̀bùn tí Ọlọ́run fún wa yìí tá a bá ń sọ̀rọ̀ rẹ̀ fún gbogbo èèyàn.​—Sm. 1:​1-3; Mát. 24:14; ka Mátíù 28:​19, 20.

17. Àwọn ẹ̀bùn tí Ọlọ́run fún wa wo la jíròrò nínú àpilẹ̀kọ yìí, kí la sì máa jíròrò nínú àpilẹ̀kọ tó kàn?

17 Nínú àpilẹ̀kọ yìí, a ti sọ̀rọ̀ nípa àwọn ẹ̀bùn tí Ọlọ́run fún wa, ìyẹn ilé ayé wa yìí, ọpọlọ wa tó ṣàrà ọ̀tọ̀ àti Bíbélì Ọ̀rọ̀ rẹ̀. Àmọ́, àwọn ẹ̀bùn míì wà tí Jèhófà fún wa tá ò lè fojú rí. Àwọn ẹ̀bùn yìí la máa jíròrò nínú àpilẹ̀kọ tó kàn.

ORIN 12 Jèhófà, Ọlọ́run Atóbilọ́lá

^ ìpínrọ̀ 5 Àpilẹ̀kọ yìí máa jẹ́ ká túbọ̀ mọyì Jèhófà àti mẹ́ta lára àwọn ẹ̀bùn tó fún wa. Bákan náà, á jẹ́ ká mọ ohun tá a lè sọ fáwọn tí kò gbà pé Ọlọ́run wà.

^ ìpínrọ̀ 64 ÀWÒRÁN Ojú Ìwé: Arábìnrin kan ń kọ́ èdè àjèjì kó lè kọ́ àwọn tó kó wá sórílẹ̀-èdè rẹ̀ lẹ́kọ̀ọ́ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run.