Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Ìkóra-Ẹni-Níjàánu​—Ànímọ́ Táá Jẹ́ Ká Rí Ojúure Jèhófà

Ìkóra-Ẹni-Níjàánu​—Ànímọ́ Táá Jẹ́ Ká Rí Ojúure Jèhófà

“Nígbà tí èmi àti mọ̀lẹ́bí mi kan ní èdèkòyédè, mo gbá a mú, mo sì fún un lọ́rùn. Ṣe ló dá bíi pé kí n pa á.”​—Paul.

“Mi ò kì í pẹ́ bínú, mo sì máa ń gbaná jẹ mọ́ àwọn tá a jọ ń gbélé. Kò sóhun tí mi ò lè bà jẹ́, ó lè jẹ́ àga tàbí ohun ìṣeré ọmọdé.”​—Marco.

Ọ̀rọ̀ tiwa lè má le tó ti Paul àti Marco. Síbẹ̀ gbogbo wa la nílò ìkóra-ẹni-níjàánu. Ohun tó sì fà á ni pé a ti jogún ẹ̀ṣẹ̀ látọ̀dọ̀ Ádámù. (Róòmù 5:12) Àwọn kan máa ń bínú sódì bíi tàwọn méjì tá a sọ̀rọ̀ wọn yìí. Èrò òdì ló sì máa ń gba àwọn míì lọ́kàn. Wọ́n lè máa ronú ṣáá nípa ohun tó ń kó ẹ̀dùn ọkàn bá wọn. Ní tàwọn míì, ṣe ni wọ́n ń tiraka kí wọ́n má bàa lọ́wọ́ nínú ìṣekúṣe, ọtí àmujù tàbí ìlòkulò oògùn.

Àbámọ̀ ló sábà máa ń gbẹ̀yìn ẹ̀ fáwọn tí kì í kápá èrò wọn, ohun tọ́kàn wọn ń fà sí àti ìwà wọn. Àmọ́ a ò ní kábàámọ̀ nígbèésí ayé wa tá a bá kóra wa níjàánu. Ká lè kó ara wa níjàánu, ẹ jẹ́ ká jíròrò àwọn ìbéèrè mẹ́ta yìí: (1) Kí ni ìkóra-ẹni-níjàánu? (2) Kí nìdí tó fi ṣe pàtàkì? (3) Báwo lèèyàn ṣe lè ní ànímọ́ tó jẹ́ apá kan “èso ti ẹ̀mí” yìí? (Gál. 5:​22, 23) Lẹ́yìn náà, a máa jíròrò ohun tẹ́nì kọ̀ọ̀kan wa lè ṣe tó bá ṣòro fún wa láti kó ara wa níjàánu.

KÍ NI ÌKÓRA-ẸNI-NÍJÀÁNU?

Ẹni tó ń kó ara ẹ̀ níjàánu kì í ṣe nǹkan láìronú jinlẹ̀. Ó máa ń kíyè sára kó má bàa sọ̀rọ̀ tàbí ṣe ohun tó máa múnú bí Jèhófà.

Ó dájú pé Jésù kó ara ẹ̀ níjàánu gan-an

Jésù fi àpẹẹrẹ tó dáa lélẹ̀ lórí kókó yìí. Bíbélì sọ pé: “Nígbà tí wọ́n sọ̀rọ̀ àbùkù sí i, kò sọ̀rọ̀ àbùkù sí wọn pa dà. Nígbà tó ń jìyà, kò bẹ̀rẹ̀ sí í halẹ̀, àmọ́ ó fi ara rẹ̀ sí ìkáwọ́ Ẹni tó ń dájọ́ òdodo.” (1 Pét. 2:23) Ohun tí Jésù ṣe gẹ́lẹ́ nìyẹn nígbà tó wà lórí òpó igi oró táwọn alátakò sì ń fi ṣe yẹ̀yẹ́. (Mát. 27:​39-44) Ṣáájú ìgbà yẹn, Jésù ò sọ̀rọ̀ láìronú nígbà táwọn alátakò fẹ́ dẹkùn mú un. (Mát. 22:​15-22) Ẹ ò rí i pé àpẹẹrẹ àtàtà ló fi lélẹ̀ nígbà táwọn Júù fẹ́ sọ ọ́ lókùúta! Dípò tó fi máa sọ̀rọ̀ burúkú sí wọn, ṣe ni “Jésù fara pa mọ́, ó sì kúrò nínú tẹ́ńpìlì.”​—Jòh. 8:​57-59.

Ṣé a máa lè ṣe bíi ti Jésù? A lè ṣe bẹ́ẹ̀ déwọ̀n àyè kan. Àpọ́sítélì Pétérù sọ pé: “Kristi . . . jìyà torí yín, ó fi àpẹẹrẹ lélẹ̀ fún yín kí ẹ lè máa tọ ipasẹ̀ rẹ̀ pẹ́kípẹ́kí.” (1 Pét. 2:21) Bá a tiẹ̀ jẹ́ aláìpé, a lè tẹ̀ lé àpẹẹrẹ Jésù pẹ́kípẹ́kí ká sì ní ìkóra-ẹni-níjàánu. Kí nìdí tíyẹn fi ṣe pàtàkì?

KÍ NÌDÍ TÍ ÌKÓRA-ẸNI-NÍJÀÁNU FI ṢE PÀTÀKÌ?

Ó ṣe pàtàkì ká máa kó ara wa níjàánu tá a bá fẹ́ rí ojúure Jèhófà. A lè ti pẹ́ nínú òtítọ́, síbẹ̀ tá ò bá kó ara wa níjàánu lọ́rọ̀ àti níṣe, àjọṣe wa pẹ̀lú Jèhófà lè bà jẹ́.

Ẹ wo àpẹẹrẹ Mósè tí Bíbélì sọ pé ó “jẹ́ oníwà pẹ̀lẹ́ jù lọ nínú gbogbo èèyàn tó wà láyé” nígbà yẹn. (Nọ́ń. 12:3) Lẹ́yìn ọ̀pọ̀ ọdún tó ti fara da ìwà àwọn ọmọ Ísírẹ́lì, ó ṣìwà hù lọ́jọ́ kan. Ó bínú sí wọn nígbà tí wọ́n ráhùn pé àwọn ò rómi mu. Ló bá fìkanra sọ fún wọn pé: “Ẹ gbọ́, ẹ̀yin ọlọ̀tẹ̀! Ṣé látinú àpáta yìí ni ká ti fún yín lómi ni?”​—Nọ́ń. 20:​2-11.

Ó hàn pé Mósè ò kóra ẹ̀ níjàánu. Kò gbé ògo fún Jèhófà tó mú káwọn èèyàn náà rómi mu lọ́nà ìyanu. (Sm. 106:​32, 33) Fún ìdí yìí, Jèhófà ò jẹ́ kó wọ Ilẹ̀ Ìlérí. (Nọ́ń. 20:12) Ó ṣeé ṣe kí Mósè kábàámọ̀ ohun tó ṣe yìí títí tó fi kú.​—Diu. 3:​23-27.

Kí la rí kọ́? Bó ti wù ká pẹ́ tó nínú ètò Jèhófà, a gbọ́dọ̀ kíyè sára ká má bàa sọ̀rọ̀ burúkú sáwọn tó múnú bí wa tàbí sí àwọn tá a fẹ́ tọ́ sọ́nà. (Éfé. 4:32; Kól. 3:12) Ká sòótọ́, béèyàn ṣe ń dàgbà sí i ló máa ń nira féèyàn láti rí ara gba nǹkan. Àmọ́ ká máa rántí Mósè. Ká má ṣe jẹ́ kí àjọṣe tá a ní pẹ̀lú Jèhófà bà jẹ́ torí àìní ìkóra-ẹni-níjàánu. Báwo la ṣe lè ní ànímọ́ pàtàkì yìí?

BÍ A ṢE LÈ NÍ ÌKÓRA-ẸNI-NÍJÀÁNU

Bẹ Jèhófà pé kó fún ẹ ní ẹ̀mí mímọ́. Kí nìdí? Ìdí ni pé apá kan èso ti ẹ̀mí ni ìkóra-ẹni-níjàánu, tá a bá sì béèrè fún ẹ̀mí mímọ́ Jèhófà, ó máa fún wa. (Lúùkù 11:13) Jèhófà máa ń lo ẹ̀mí mímọ́ rẹ̀ láti fún wa lókun. (Fílí. 4:13) Ó tún lè ràn wá lọ́wọ́ láti ní àwọn apá míì lára èso ti ẹ̀mí bí ìfẹ́ tó máa jẹ́ ká túbọ̀ kó ara wa níjàánu.​—1 Kọ́r. 13:5.

Sá fún ohunkóhun tó lè mú kó nira fún ẹ láti kó ara ẹ níjàánu

Sá fún ohunkóhun tó lè mú kó nira fún ẹ láti kó ara ẹ níjàánu. Ṣe ni kó o sá fún àwọn ìkànnì àtàwọn eré tó ń gbé ìṣekúṣe àti ìwà àìmọ́ lárugẹ. (Éfé. 5:​3, 4) Àní sẹ́, má tiẹ̀ sún mọ́ ohunkóhun tó lè mú kó o ro èròkerò tàbí hùwàkiwà. (Òwe 22:3; 1 Kọ́r. 6:12) Bí àpẹẹrẹ, ó máa bọ́gbọ́n mu kí ẹni tọ́kàn ẹ̀ máa ń fà sí ìṣekúṣe yẹra pátápátá fún ìwé àtàwọn fíìmù tó ń gbé ìṣekúṣe lárugẹ.

Ó lè má fi bẹ́ẹ̀ rọrùn fún wa láti fi ìmọ̀ràn yìí sílò. Àmọ́ tá a bá sapá, Jèhófà máa ràn wá lọ́wọ́ ká lè kó ara wa níjàánu. (2 Pét. 1:​5-8) Nípa bẹ́ẹ̀, àá lè máa ṣọ́ èrò wa, ọ̀rọ̀ wa àti ìwà wa. Àpẹẹrẹ Paul àti Marco tá a sọ níbẹ̀rẹ̀ sì jẹ́ ká rí i pé òótọ́ lọ̀rọ̀ yìí. Àpẹẹrẹ míì ni ti arákùnrin kan tó máa ń bínú tó sì máa ń gbaná jẹ mọ́ àwọn awakọ̀ míì tó bá ń wakọ̀ lójú pópó. Kí ló ṣe kó lè kápá ìbínú rẹ̀? Ó sọ pé: “Mo máa ń gbàdúrà gan-an lójoojúmọ́ pé kí Jèhófà ràn mí lọ́wọ́. Mo ka àwọn ìtẹ̀jáde wa tó sọ̀rọ̀ nípa ìkóra-ẹni-níjàánu, mo sì há àwọn ẹsẹ Ìwé Mímọ́ kan sórí. Òótọ́ ni pé ọjọ́ pẹ́ tí mo ti ń sapá, síbẹ̀ àràárọ̀ ni mo máa ń rán ara mi létí pé ó yẹ kí n kó ara mi níjàánu. Bákan náà, mo máa ń tètè kúrò nílé kó má bàa di pé mò ń kánjú tíyẹn á sì mú kí n máa kanra mọ́ àwọn míì lójú ọ̀nà.”

TÁ A BÁ WÁ ṢÀÌ KÓ ARA WA NÍJÀÁNU ŃKỌ́?

Lẹ́ẹ̀kọ̀ọ̀kan, a lè ṣàì kó ara wa níjàánu. Tírú ẹ̀ bá ṣẹlẹ̀, ojú lè tì wá láti gbàdúrà sí Jèhófà. Àmọ́, àsìkò yẹn gan-an ló yẹ ká gbàdúrà. Torí náà, ẹsẹ̀kẹsẹ̀ ni kó o gbàdúrà. Bẹ Jèhófà pé kó dárí jì ẹ́, pé kó ràn ẹ́ lọ́wọ́, kíwọ náà sì pinnu pé o ò ní ṣerú ẹ̀ mọ́. (Sm. 51:​9-11) Jẹ́ kó dá ẹ lójú pé Jèhófà máa ṣàánú rẹ, kò sì ní kó àdúrà àtọkànwá rẹ dà nù. (Sm. 102:17) Àpọ́sítélì Jòhánù rán wa létí pé ẹ̀jẹ̀ Jésù “ń wẹ̀ wá mọ́ kúrò nínú gbogbo ẹ̀ṣẹ̀.” (1 Jòh. 1:7; 2:1; Sm. 86:5) Ṣó o rántí pé Jèhófà sọ fún wa pé ká máa dárí ji àwọn tó ṣẹ̀ wá? Torí náà, jẹ́ kó dá ẹ lójú pé ó máa dárí jì ẹ́.​—Mát. 18:​21, 22; Kól. 3:13.

Jèhófà bínú sí Mósè torí pé ó ṣìwà hù lọ́jọ́ kan nínú aginjù. Àmọ́ Jèhófà dárí jì í. Kódà Bíbélì pè é ní olóòótọ́, ó sì rọ̀ wá pé ká fara wé ìgbàgbọ́ rẹ̀. (Diu. 34:10; Héb. 11:​24-28) Òótọ́ ni pé Jèhófà ò jẹ́ kí Mósè wọ Ilẹ̀ Ìlérí, àmọ́ ó máa jí i dìde nígbà tí ayé yìí bá di Párádísè, á sì fún un láǹfààní láti wà láàyè títí láé. Ó máa ṣeé ṣe fáwa náà láti wà láàyè títí láé tá a bá ṣe gbogbo ohun tá a lè ṣe ká lè ní ànímọ́ pàtàkì yìí, ìyẹn ìkóra-ẹni-níjàánu.​—1 Kọ́r. 9:25.