Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

ÀPILẸ̀KỌ FÚN ÌKẸ́KỌ̀Ọ́ 28

Jẹ́ Kí Òtítọ́ Tó O Gbà Gbọ́ Dá Ẹ Lójú

Jẹ́ Kí Òtítọ́ Tó O Gbà Gbọ́ Dá Ẹ Lójú

“Kí ìwọ má ṣe fi àwọn nǹkan tí o ti kọ́ sílẹ̀, tí a sì mú kí o gbà gbọ́.”​—2 TÍM. 3:14.

ORIN 56 Sọ Òtítọ́ Di Tìrẹ

OHUN TÁ A MÁA JÍRÒRÒ *

1. Kí la ní lọ́kàn tá a bá lo ọ̀rọ̀ náà “òtítọ́”?

“BÁWO lo ṣe rí òtítọ́?” “Ṣé inú òtítọ́ ni wọ́n bí ẹ sí?” “Ìgbà wo lo rí òtítọ́?” Ó ṣeé ṣe kí wọ́n ti bi ẹ́ láwọn ìbéèrè yìí rí, ìwọ náà sì ti lè bi àwọn míì. Kí la ní lọ́kàn tá a bá lo ọ̀rọ̀ náà “òtítọ́”? Ó sábà máa ń túmọ̀ sí àwọn ohun tá a gbà gbọ́, bá a ṣe ń jọ́sìn àti bá a ṣe ń gbé ìgbésí ayé wa. Àwọn tó wà “nínú òtítọ́” mọ ohun tí Bíbélì fi kọ́ni, àwọn ìlànà Bíbélì ni wọ́n sì ń tẹ̀ lé. Nípa bẹ́ẹ̀, wọn ò gba ẹ̀kọ́ èké táwọn ẹ̀sìn èké fi ń kọ́ni gbọ́, ìgbésí ayé tó dáa jù ni wọ́n sì ń gbé nínú ayé Sátánì yìí.​—Jòh. 8:32.

2. Bó ṣe wà nínú Jòhánù 13:34, 35, kí lẹnì kan lè kọ́kọ́ kíyè sí táá mú kó nífẹ̀ẹ́ sí òtítọ́?

2 Kí ló mú kó o kọ́kọ́ nífẹ̀ẹ́ òtítọ́? Ó lè jẹ́ ìwà rere táwọn èèyàn Jèhófà ń hù. (1 Pét. 2:12) Ó sì lè jẹ́ ìfẹ́ tí wọ́n fi hàn. Ohun tí ọ̀pọ̀ kíyè sí nìyẹn nípàdé àkọ́kọ́ tí wọ́n lọ, ìyẹn ló sì mú kí wọ́n nífẹ̀ẹ́ sí òtítọ́ dípò ohun tí wọ́n gbọ́ nípàdé lọ́jọ́ yẹn. Kò sì yani lẹ́nu torí Jésù sọ pé ìfẹ́ yìí la fi máa dá àwọn ọmọlẹ́yìn òun mọ̀. (Ka Jòhánù 13:​34, 35.) Àmọ́ ká tó lè nígbàgbọ́ tó lágbára tó sì dúró sán-ún, àwọn nǹkan míì wà tá a gbọ́dọ̀ ṣe.

3. Kí ló lè ṣẹlẹ̀ tó bá jẹ́ pé ìfẹ́ tó wà láàárín ẹgbẹ́ ará nìkan ló mú ká nífẹ̀ẹ́ òtítọ́?

3 Kì í ṣe ìfẹ́ tó wà láàárín ẹgbẹ́ ará nìkan ló yẹ kó mú ká máa jọ́sìn Jèhófà. Kí nìdí tá a fi sọ bẹ́ẹ̀? Jẹ́ ká sọ pé ẹnì kan nínú ìjọ dẹ́ṣẹ̀ tó wúwo, pàápàá tẹ́ni náà bá lọ jẹ́ alàgbà tàbí aṣáájú-ọ̀nà, kí lo rò pé ó máa ṣẹlẹ̀ sí ìtara tó o ní? Tí arákùnrin tàbí arábìnrin kan bá ṣe ohun tó dùn ẹ́ gan-an ńkọ́? Tàbí kẹ̀, kí ló lè ṣẹlẹ̀ tẹ́nì kan bá di apẹ̀yìndà, tó sì ń sọ pé irọ́ la fi ń kọ́ni? Tírú àwọn nǹkan yìí bá ṣẹlẹ̀, ṣé wàá ṣì máa sin Jèhófà, àbí wàá fi òtítọ́ sílẹ̀? Kókó ibẹ̀ rèé: Tó bá jẹ́ torí nǹkan táwọn míì ń ṣe nìkan ló mú kó o nígbàgbọ́ nínú Jèhófà, ìgbàgbọ́ ẹ ò ní lágbára. Òótọ́ ni pé báwọn èèyàn Jèhófà ṣe ń fìfẹ́ hàn lè mú kó o nígbàgbọ́ déwọ̀n àyè kan. Àmọ́ ó tún yẹ kó o máa ka Bíbélì dáadáa, kó o lóye ẹ̀kọ́ òtítọ́, kó o sì ṣèwádìí tó jinlẹ̀ kí ẹ̀kọ́ òtítọ́ lè dá ẹ lójú. Ó yẹ kó o fúnra rẹ ṣàwárí àwọn òtítọ́ tó wà nínú Bíbélì, kó o sì jẹ́ kó dá ẹ lójú.​—Róòmù 12:2.

4. Bó ṣe wà nínú Mátíù 13:3-6, 20, 21, kí ló máa ń ṣẹlẹ̀ sáwọn kan tí wọ́n bá kojú àdánwò?

4 Jésù sọ pé àwọn kan máa fi “ayọ̀ tẹ́wọ́ gba” òtítọ́, àmọ́ wọ́n á pa dà sẹ́yìn nígbà tí wọ́n bá kojú àdánwò. (Ka Mátíù 13:​3-6, 20, 21.) Bóyá wọn ò mọ̀ pé àwọn máa kojú àdánwò táwọn bá di ọmọ ẹ̀yìn Jésù. (Mát. 16:24) Wọ́n sì lè ronú pé téèyàn bá di Kristẹni, kò ní níṣòro kankan, ìgbé ayé ìdẹ̀rùn nìkan lá máa gbé. Àmọ́, ṣé èèyàn lè gbé inú ayé burúkú yìí kó má sì níṣòro? Rárá torí pé ipò nǹkan máa ń yí pa dà, èèyàn sì lè ní ẹ̀dùn ọkàn fúngbà díẹ̀ torí àwọn nǹkan tó ṣẹlẹ̀.​—Sm. 6:6; Oníw. 9:11.

5. Báwo lèyí tó pọ̀ jù lára àwọn ará wa ṣe ń fi hàn pé ó dá àwọn lójú pé inú òtítọ́ làwọn wà?

5 Èyí tó pọ̀ jù lára àwọn ará wa ló ń fi hàn pé ó dá àwọn lójú pé inú òtítọ́ làwọn wà. Lọ́nà wo? Wọn kì í fi Jèhófà sílẹ̀ kódà tẹ́nì kan nínú ìjọ bá ṣe ohun tó dùn wọ́n tàbí tó dẹ́ṣẹ̀ tó wúwo. (Sm. 119:165) Gbogbo ìgbà tí wọ́n bá kojú àdánwò ni ìgbàgbọ́ wọn túbọ̀ ń lágbára. (Jém. 1:​2-4) Kí lo lè ṣe táá jẹ́ kí ìgbàgbọ́ tìẹ náà lágbára bẹ́ẹ̀?

NÍ “ÌMỌ̀ TÓ PÉYE” NÍPA ỌLỌ́RUN

6. Kí ló mú káwọn Kristẹni ọgọ́rùn-ún ọdún kìíní nígbàgbọ́?

6 Àwọn Kristẹni ọgọ́rùn-ún ọdún kìíní nígbàgbọ́ torí pé wọ́n fara balẹ̀ kẹ́kọ̀ọ́ Ìwé Mímọ́ àtàwọn nǹkan tí Jésù Kristi fi kọ́ni, ìyẹn “òtítọ́ ìhìn rere.” (Gál. 2:5) Òtítọ́ yìí ni àpapọ̀ gbogbo nǹkan tí àwa Kristẹni gbà gbọ́, títí kan ẹ̀kọ́ nípa ìràpadà tí Jésù san àti àjíǹde rẹ̀. Ó dá àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù lójú pé òtítọ́ làwọn ẹ̀kọ́ yìí. Kí nìdí? Ìdí ni pé ó lo Ìwé Mímọ́, ó sì tọ́ka sí “àwọn ohun tó fi ẹ̀rí hàn pé ó pọn dandan kí Kristi jìyà, kí ó sì dìde kúrò nínú ikú.” (Ìṣe 17:​2, 3) Àwọn Kristẹni ọgọ́rùn-ún ọdún kìíní gba àwọn ẹ̀kọ́ yẹn gbọ́, wọ́n sì gbára lé ẹ̀mí mímọ́ kí wọ́n lè lóye Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run. Wọ́n fara balẹ̀ ṣèwádìí kó lè dá wọn lójú pé inú Ìwé Mímọ́ làwọn ẹ̀kọ́ náà ti wá. (Ìṣe 17:​11, 12; Héb. 5:14) Kì í ṣe bọ́rọ̀ ṣe rí lára wọn ló mú kí wọ́n gba àwọn ẹ̀kọ́ náà gbọ́, kì í sì í ṣe bí àwọn ará ṣe kó wọn mọ́ra nígbà tí wọ́n dara pọ̀ mọ́ ìjọ nìkan ló mú kí wọ́n sin Jèhófà. Kàkà bẹ́ẹ̀, “ìmọ̀ tó péye” tí wọ́n ní nípa Jèhófà ló mú kí wọ́n nígbàgbọ́.​—Kól. 1:​9, 10.

7. Tá a bá nígbàgbọ́ nínú ẹ̀kọ́ òtítọ́, kí nìyẹn máa ṣe fún wa?

7 Òtítọ́ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run kì í yí pa dà. (Sm. 119:160) Bí àpẹẹrẹ, òtítọ́ yìí kò ní yí pa dà kódà tẹ́nì kan nínú ìjọ bá ṣe ohun tó dùn wá tàbí tó dẹ́ṣẹ̀ tó wúwo. Bẹ́ẹ̀ sì ni kò ní yí pa dà tá a bá kojú àdánwò. Torí náà, a gbọ́dọ̀ mọ ẹ̀kọ́ Bíbélì dunjú ká sì jẹ́ kó dá wa lójú pé òtítọ́ ni. Bí ìdákọ̀ró kò ṣe ní jẹ́ kí ọkọ̀ ojú omi kan sojú dé lásìkò ìjì líle, bẹ́ẹ̀ ni ẹ̀kọ́ òtítọ́ tá a kọ́ kò ṣe ní jẹ́ kí ọkọ̀ ìgbàgbọ́ wa sojú dé nígbà àdánwò. Kí lo lè ṣe táá mú kó túbọ̀ dá ẹ lójú pé òtítọ́ lohun tó o gbà gbọ́?

GBA OHUN TÓ O KỌ́ GBỌ́

8. Bó ṣe wà nínú 2 Tímótì 3:14, 15, báwo ni Tímótì ṣe dẹni tó nígbàgbọ́?

8 Ó dá Tímótì lójú pé òtítọ́ ni wọ́n fi kọ́ òun. Kí ló jẹ́ kó dá a lójú? (Ka 2 Tímótì 3:​14, 15.) Bó tiẹ̀ jẹ́ pé ìyá rẹ̀ àti ìyá ìyá rẹ̀ ló fi “ìwé mímọ́” kọ́ ọ lẹ́kọ̀ọ́, ó dájú pé òun fúnra rẹ̀ wáyè kẹ́kọ̀ọ́, ó sì ṣèwádìí nínú àwọn ìwé mímọ́ náà. Ohun tó ṣe yìí ló mú kó gba àwọn ẹ̀kọ́ òtítọ́ náà gbọ́. Nígbà tó yá, Tímótì, ìyá rẹ̀ àti ìyá ìyá rẹ̀ di Kristẹni. Kò sí àní-àní pé inú Tímótì dùn báwọn Kristẹni yòókù ṣe fìfẹ́ hàn sí i, ó sì wù ú pé kóun dara pọ̀ mọ́ wọn, kóun náà sì ran àwọn Kristẹni yẹn lọ́wọ́. (Fílí. 2:​19, 20) Síbẹ̀, kì í ṣe ìfẹ́ tí wọ́n fi hàn sí i nìkan ló mú kó nígbàgbọ́ bí kò ṣe ẹ̀kọ́ òtítọ́ tó kọ́ látinú Ìwé Mímọ́. Torí náà, ìwọ náà gbọ́dọ̀ máa fara balẹ̀ kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, kó o sì jẹ́ káwọn nǹkan tó ò ń kọ́ dá ẹ lójú.

9. Àwọn nǹkan mẹ́ta wo ló yẹ kó dá ẹ lójú?

9 Àwọn nǹkan mẹ́ta kan wà tó jóòótọ́ tó gbọ́dọ̀ dá ẹ lójú. Àkọ́kọ́, ó gbọ́dọ̀ dá ẹ lójú pé Jèhófà ló dá ohun gbogbo láyé àti lọ́run. (Ẹ́kís. 3:​14, 15; Héb. 3:4; Ìfi. 4:11) Ìkejì, ó gbọ́dọ̀ dá ẹ lójú pé Ọlọ́run ló mí sí Bíbélì. (2 Tím. 3:​16, 17) Ìkẹta, ó gbọ́dọ̀ dá ẹ lójú pé Jèhófà ní àwùjọ àwọn èèyàn kan tó ń jọ́sìn rẹ̀ lábẹ́ ìdarí Kristi, àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà sì ni àwùjọ náà. (Àìsá. 43:​10-12; Jòh. 14:6; Ìṣe 15:14) Kò dìgbà tó o bá di igi ìwé tàbí àká ìmọ̀ káwọn nǹkan yìí tó dá ẹ lójú. Ohun tó ṣe pàtàkì jù ni pé kó o lo “agbára ìrònú” rẹ láti jẹ́ káwọn nǹkan yìí túbọ̀ dá ẹ lójú.​—Róòmù 12:1.

ṢE OHUN TÁÁ JẸ́ KÍ ÒTÍTỌ́ DÁ ÀWỌN MÍÌ LÓJÚ

10. Yàtọ̀ sí pé ká mọ òtítọ́, kí ló yẹ ká ṣe?

10 Tó bá ti dá ẹ lójú pé Jèhófà ló dá gbogbo nǹkan, pé Ọ̀rọ̀ rẹ̀ ni Bíbélì àti pé àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà nìkan là ń jọ́sìn rẹ̀, o gbọ́dọ̀ lè fi Bíbélì ṣàlàyé ẹ̀ fáwọn míì. Kí nìdí? Ìdí ni pé ojúṣe gbogbo àwa Kristẹni ni pé ká kọ́ àwọn tó bá nífẹ̀ẹ́ òtítọ́ lẹ́kọ̀ọ́. * (1 Tím. 4:16) Bá a sì ṣe ń kọ́ àwọn èèyàn lẹ́kọ̀ọ́ òtítọ́ bẹ́ẹ̀ lá túbọ̀ máa dá àwa náà lójú pé òtítọ́ lohun tá a gbà gbọ́.

11. Àpẹẹrẹ wo ni àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù fi lélẹ̀ tó bá di pé ká kọ́ni?

11 Tí àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù bá ń kọ́ àwọn èèyàn, ó máa ń lo Òfin Mósè àti ìwé àwọn Wòlíì láti “yí èrò tí wọ́n ní nípa Jésù pa dà.” (Ìṣe 28:23) Báwo la ṣe lè fara wé Pọ́ọ̀lù tá a bá ń kọ́ àwọn èèyàn lẹ́kọ̀ọ́ òtítọ́? Kì í ṣe ká kàn máa kó ìmọ̀ Bíbélì sí wọn lórí. Ó yẹ ká ran àwọn akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì wa lọ́wọ́ kí wọ́n lè ronú jinlẹ̀ lórí ohun tí wọ́n ń kọ́ látinú Ìwé Mímọ́, kí wọ́n sì tipa bẹ́ẹ̀ sún mọ́ Jèhófà. A ò fẹ́ kí wọ́n wá sínú òtítọ́ torí pé wọ́n nífẹ̀ẹ́ wa nìkan, àmọ́ kó jẹ́ torí pé wọ́n fúnra wọn ṣèwádìí, ó sì dá wọn lójú pé òtítọ́ nípa Jèhófà làwọn ń kọ́.

Ẹ̀yin òbí, ẹ máa kọ́ àwọn ọmọ yín ní “àwọn ohun ìjìnlẹ̀ Ọlọ́run” kí wọ́n lè nígbàgbọ́ tó lágbára (Wo ìpínrọ̀ 12 àti 13) *

12-13. Báwo lẹ̀yin òbí ṣe lè ran àwọn ọmọ yín lọ́wọ́ kí wọ́n lè sọ òtítọ́ di tiwọn?

12 Ó dájú pé ẹ̀yin òbí fẹ́ káwọn ọmọ yín sọ òtítọ́ di tiwọn. Ẹ lè máa ronú pé táwọn ọmọ yín bá ń kẹ́gbẹ́ pẹ̀lú àwọn tó nífẹ̀ẹ́ òtítọ́ nínú ìjọ, wọ́n á máa ṣe dáadáa. Òótọ́ ni pé wọ́n nílò àwọn ọ̀rẹ́ gidi, àmọ́ ìyẹn nìkan ò tó láti mú kí wọ́n sọ òtítọ́ di tiwọn. Àwọn fúnra wọn gbọ́dọ̀ ní àjọṣe tó dáa pẹ̀lú Ọlọ́run, kó sì dá wọn lójú pé òtítọ́ ni Bíbélì fi kọ́ni.

13 Tí ẹ̀yin òbí bá máa kọ́ àwọn ọmọ yín lẹ́kọ̀ọ́ òtítọ́, ẹ̀kọ́ òtítọ́ gbọ́dọ̀ yé ẹ̀yin náà dáadáa. Torí náà, ẹ gbọ́dọ̀ máa wáyè kẹ́kọ̀ọ́ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run kẹ́ ẹ sì máa ṣàṣàrò lórí ẹ̀. Ìgbà yẹn lẹ tó lè kọ́ àwọn ọmọ yín pé káwọn náà máa ṣe bẹ́ẹ̀. Ó yẹ kẹ́ ẹ kọ́ àwọn ọmọ yín bí wọ́n ṣe lè lo àwọn ohun èlò tá a fi ń kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì bẹ́ ẹ ṣe ń kọ́ àwọn akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì yín níta. Tẹ́ ẹ bá ń ṣe bẹ́ẹ̀, àwọn ọmọ yín á mọyì Jèhófà àtàwọn tí Jèhófà ń lò láti pèsè oúnjẹ tẹ̀mí, ìyẹn “ẹrú olóòótọ́ àti olóye.” (Mát. 24:​45-47) Ẹ̀yin òbí, kì í ṣe àwọn ẹ̀kọ́ àkọ́kọ́bẹ̀rẹ̀ Bíbélì nìkan ló yẹ kẹ́ ẹ máa kọ́ àwọn ọmọ yín. Ẹ máa kọ́ wọn ní “àwọn ohun ìjìnlẹ̀ Ọlọ́run” débi tí òye wọn gbé e dé. Tẹ́ ẹ bá ń ṣe bẹ́ẹ̀, ìgbàgbọ́ wọn á lágbára.​—1 Kọ́r. 2:10.

KẸ́KỌ̀Ọ́ NÍPA ÀWỌN ÀSỌTẸ́LẸ̀ BÍBÉLÌ

14. Kí nìdí tó fi yẹ ká máa kẹ́kọ̀ọ́ nípa àwọn àsọtẹ́lẹ̀ Bíbélì? (Tún wo àpótí náà, “ Ṣé O Lè Ṣàlàyé Àwọn Àsọtẹ́lẹ̀ Yìí?”)

14 Apá pàtàkì ni àsọtẹ́lẹ̀ jẹ́ nínú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run, ó sì ń mú kí ìgbàgbọ́ wa nínú Jèhófà túbọ̀ lágbára. Àwọn àsọtẹ́lẹ̀ wo ló ti mú kí ìgbàgbọ́ rẹ túbọ̀ lágbára? Ó ṣeé ṣe kó o tọ́ka sáwọn àsọtẹ́lẹ̀ nípa “àwọn ọjọ́ ìkẹyìn.” (2 Tím. 3:​1-5; Mát. 24:​3, 7) Àmọ́, àwọn àsọtẹ́lẹ̀ tó ti nímùúṣẹ wo ló lè mú kí ìgbàgbọ́ rẹ túbọ̀ lágbára? Bí àpẹẹrẹ, ṣé o lè ṣàlàyé bí àwọn àsọtẹ́lẹ̀ tó wà nínú Dáníẹ́lì orí kejì tàbí Dáníẹ́lì orí kọkànlá ṣe nímùúṣẹ sẹ́yìn àti bí wọ́n ṣe ń nímùúṣẹ báyìí? * Tó bá jẹ́ pé òtítọ́ Bíbélì ló mú kí ìgbàgbọ́ rẹ lágbára, kò ní sí àdánwò tó máa mú kó o yẹsẹ̀. Bí ọ̀rọ̀ àwọn ará wa tí wọ́n ṣenúnibíni tó gbóná janjan sí lórílẹ̀-èdè Jámánì nígbà Ogun Àgbáyé Kejì ṣe rí nìyẹn. Bí wọn ò tiẹ̀ fi bẹ́ẹ̀ lóye àwọn àsọtẹ́lẹ̀ nípa àwọn ọjọ́ ìkẹyìn, ìgbàgbọ́ wọn nínú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run lágbára, wọn ò sì yẹsẹ̀.

Tá a bá ń fara balẹ̀ kẹ́kọ̀ọ́ òtítọ́ títí kan àwọn àsọtẹ́lẹ̀ Bíbélì, a ò ní yẹsẹ̀ nígbà àdánwò (Wo ìpínrọ̀ 15 sí 17) *

15-17. Báwo ni ẹ̀kọ́ òtítọ́ ṣe mú kí ìgbàgbọ́ àwọn ará wa túbọ̀ lágbára nígbà tí wọ́n ṣenúnibíni sí wọn lábẹ́ ìjọba Násì?

15 Ẹgbẹẹgbẹ̀rún àwọn ará wa ni wọ́n rán lọ sí àgọ́ ìṣẹ́niníṣẹ̀ẹ́ nígbà ìjọba Násì lórílẹ̀-èdè Jámánì. Hitler àti olórí àwọn SS tórúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Heinrich Himmler kórìíra àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà tìkà-tẹ̀gbin. Bí arábìnrin kan ṣe sọ, Himmler sọ fáwọn arábìnrin tó wà ní àgọ́ ìṣẹ́niníṣẹ̀ẹ́ kan pé: “Jèhófà yín lè máa pàṣẹ lọ́run o, àmọ́ àwa là ń pàṣẹ láyé ńbí! Bí ikún ló loko bí pàkúté ni, àá mọ̀ láàárín àwa àtẹ̀yin!” Kí ló wá ran àwọn èèyàn Jèhófà lọ́wọ́ tí wọn ò fi yẹsẹ̀ ní gbogbo àsìkò yẹn?

16 Ó dá àwọn Akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì yẹn lójú pé Ìjọba Ọlọ́run ti bẹ̀rẹ̀ sí í ṣàkóso ní 1914. Torí náà, kò yà wọ́n lẹ́nu pé àwọn èèyàn ń ṣenúnibíni sí àwọn. Àmọ́, ó dá àwọn èèyàn Jèhófà lójú pé kò sí ìjọba èèyàn kankan tó lè ní kí ìfẹ́ Jèhófà má ṣẹ. Ó dá wọn lójú pé Hitler kò ní lè pa ìjọsìn tòótọ́ run, ìjọba rẹ̀ kò sì ní lè ṣe ohun tí Ìjọba Ọlọ́run máa ṣe. Bákan náà, ó dá àwọn ará yẹn lójú pé bópẹ́ bóyá ìjọba Hitler máa dópin.

17 Ohun táwọn ará yẹn gbà pé ó máa ṣẹlẹ̀ náà ló ṣẹlẹ̀. Nígbà tó yá, ìjọba Násì forí ṣánpọ́n, ni Heinrich Himmler tó sọ pé “àwa là ń pàṣẹ láyé ńbí” bá ń sá kiri kí wọ́n má bàa pa á. Ibi tó ti ń sá lọ, ó pàdé Arákùnrin Lübke tó mọ̀ dáadáa torí pé arákùnrin yẹn ti wà lẹ́wọ̀n tẹ́lẹ̀. Pẹ̀lú ìbànújẹ́ àti ẹ̀dùn ọkàn, Himmler bi Arákùnrin Lübke pé: “Akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, kí ló wá kàn báyìí?” Arákùnrin Lübke sọ fún un pé àtìbẹ̀rẹ̀ làwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà ti mọ̀ pé ìjọba Násì máa forí ṣánpọ́n àti pé Jèhófà máa dá àwa èèyàn ẹ̀ nídè. Ṣe ni ẹnu Himmler wọhò, bẹ́ẹ̀ sì rèé òun ló ń fọ́nnu tó sì ń ta ko àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà tẹ́lẹ̀. Kò pẹ́ lẹ́yìn ìyẹn, Himmler pa ara ẹ̀. Kí la rí kọ́? Tá a bá ń fara balẹ̀ kẹ́kọ̀ọ́ òtítọ́ títí kan àwọn àsọtẹ́lẹ̀ Bíbélì, ìgbàgbọ́ wa á túbọ̀ lágbára, a ò sì ní yẹsẹ̀ kódà nígbà àdánwò.​—2 Pét. 1:​19-21.

18. Báwo ni ọ̀rọ̀ tó wà nínú Jòhánù 6:67, 68 ṣe tan mọ́ ohun tí Pọ́ọ̀lù sọ nínú Fílípì 1:9 pé ká ní “ìmọ̀ tó péye àti òye tó kún rẹ́rẹ́”?

18 Ó yẹ kí gbogbo wa máa fìfẹ́ hàn torí pé ìyẹn làwọn èèyàn máa fi mọ̀ pé ọmọlẹ́yìn Kristi ni wá lóòótọ́. Àmọ́, ó tún ṣe pàtàkì ká ní “ìmọ̀ tó péye àti òye tó kún rẹ́rẹ́.” (Fílí. 1:9) Àìjẹ́ bẹ́ẹ̀, “gbogbo ẹ̀fúùfù ẹ̀kọ́ ẹ̀tàn àwọn èèyàn” máa ṣì wá lọ́nà títí kan àwọn apẹ̀yìndà. (Éfé. 4:14) Ìgbà kan wà ní ọgọ́rùn-ún ọdún kìíní tí ọ̀pọ̀ lára àwọn ọmọ ẹ̀yìn Jésù ò tẹ̀ lé e mọ́, síbẹ̀ àpọ́sítélì Pétérù fi hàn pé Jésù ló ní “àwọn ọ̀rọ̀ ìyè àìnípẹ̀kun.” (Ka Jòhánù 6:​67, 68.) Bó tiẹ̀ jẹ́ pé Pétérù ò lóye kúlẹ̀kúlẹ̀ ohun tí Jésù sọ, kò fi Jésù sílẹ̀ torí ó fòye mọ̀ pé Jésù ni Kristi. Ìwọ náà lè ṣe ohun táá mú kí ẹ̀kọ́ òtítọ́ túbọ̀ dá ẹ lójú. Tó o bá ṣe bẹ́ẹ̀, ìgbàgbọ́ rẹ á dúró digbí lójú àdánwò, wàá sì tún lè ran àwọn míì lọ́wọ́ kí ìgbàgbọ́ tiwọn náà lè lágbára.​—2 Jòh. 1, 2.

ORIN 72 À Ń Kéde Òtítọ́ Ìjọba Náà

^ ìpínrọ̀ 5 Àpilẹ̀kọ yìí máa jẹ́ ká túbọ̀ mọyì ẹ̀kọ́ òtítọ́ tó wà nínú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run. Ó tún máa jẹ́ ká rí àwọn ohun tá a lè ṣe táá mú kó túbọ̀ dá wa lójú pé òtítọ́ lohun tá a gbà gbọ́.

^ ìpínrọ̀ 10 Kó lè rọrùn fún ẹ láti ṣàlàyé ohun tó o gbà gbọ́ fáwọn míì, wo ọ̀wọ́ àpilẹ̀kọ tá a pè ní “Ìjíròrò Láàárín Ẹlẹ́rìí Jèhófà àti Ẹnì Kan” tó jáde nínú Ilé Ìṣọ́ látọdún 2010 sí 2015. Lára àwọn àpilẹ̀kọ yìí ni “Ṣé Jésù Ni Ọlọ́run?,” “Ìgbà Wo Ni Ìjọba Ọlọ́run Bẹ̀rẹ̀?” àti “Ṣé Ọlọ́run Máa Ń Dá Àwọn Èèyàn Lóró Nínú Iná Ọ̀run Àpáàdì?

^ ìpínrọ̀ 14 Tó o bá fẹ́ àlàyé síwájú sí i nípa àwọn àsọtẹ́lẹ̀ yìí, wo Ilé Ìṣọ́ June 15, 2012 àti ti May 2020.

^ ìpínrọ̀ 60 ÀWÒRÁN: Nígbà ìjọsìn ìdílé, àwọn òbí kan ṣàlàyé àwọn àsọtẹ́lẹ̀ nípa ìpọ́njú ńlá fún àwọn ọmọ wọn.

^ ìpínrọ̀ 62 ÀWÒRÁN: Nígbà ìpọ́njú ńlá, àwọn ohun tó ń ṣẹlẹ̀ kò ya ìdílé náà lẹ́nu.