Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Ìbéèrè Láti Ọwọ́ Àwọn Òǹkàwé

Ìbéèrè Láti Ọwọ́ Àwọn Òǹkàwé

Ìgbà wo ni Jésù di Àlùfáà Àgbà, ìgbà wo sì ni májẹ̀mú tuntun fìdí múlẹ̀?

Ẹ̀rí fi hàn pé Jésù di Àlùfáà Àgbà lọ́dún 29 Sànmánì Kristẹni nígbà tó ṣèrìbọmi. Báwo la ṣe mọ̀ bẹ́ẹ̀? Nígbà tí Jésù ṣèrìbọmi, ó fi hàn pé òun ṣe tán láti ṣe “ìfẹ́” Ọlọ́run. Lédè míì, ó múra tán láti fi ara rẹ̀ san ìràpadà. (Gál. 1:4; Héb. 10:5-10) Ìfẹ́ Jèhófà tí Jésù ṣe ló dà bíi pẹpẹ, torí náà nígbà tó fi ẹ̀mí ara rẹ̀ rúbọ, ṣe ló dà bíi pé orí pẹpẹ yẹn ló ti rúbọ. Ètò tí Jèhófà ṣe fún ìjọsìn mímọ́ nípasẹ̀ ìràpadà Jésù ló dà bíi tẹ́ńpìlì náà. Àtìgbà tí Jésù ti ṣèrìbọmi ni pẹpẹ yẹn ti wà, àtìgbà yẹn náà ni tẹ́ńpìlì ńlá tẹ̀mí tó ṣàpẹẹrẹ ìjọsìn mímọ́ ti wà. Bí pẹpẹ ṣe ṣe pàtàkì nínú tẹ́ńpìlì, bẹ́ẹ̀ ni ìfẹ́ Jèhófà ṣe pàtàkì nínú ìjọsìn mímọ́.​—Mát. 3:16, 17; Héb. 5:4-6.

Nígbà tí Jèhófà ṣètò tẹ́ńpìlì ńlá tẹ̀mí náà, ó di dandan kí àlùfáà àgbà kan máa sìn níbẹ̀. Torí náà, Jésù ni Jèhófà yàn pẹ̀lú “ẹ̀mí mímọ́ àti agbára.” (Ìṣe 10:37, 38; Máàkù 1:9-11) Síbẹ̀, kí ló mú kó dá wa lójú pé ṣáájú ikú àti àjíǹde Jésù ni Jèhófà ti yàn án láti di Àlùfáà Àgbà? A máa rí ìdáhùn nínú àpẹẹrẹ Áárónì àtàwọn tó di àlùfáà lẹ́yìn ẹ̀.

Bó ṣe wà nínú Òfin Mósè, àlùfáà àgbà nìkan ló láṣẹ láti wọ Ibi Mímọ́ Jù Lọ nínú àgọ́ ìjọsìn bó sì ṣe rí náà nìyẹn nígbà tí wọ́n kọ́ tẹ́ńpìlì. Aṣọ ìdábùú ni wọ́n fi pààlà sáàárín Ibi Mímọ́ àti Ibi Mímọ́ Jù Lọ. Ọjọ́ Ètùtù nìkan sì ni àlùfáà àgbà máa la aṣọ ìdábùú náà kọjá wọnú Ibi Mímọ́ Jù Lọ. (Héb. 9:1-3, 6, 7) Bó ṣe jẹ́ pé wọ́n ti fòróró yan Áárónì àtàwọn tó di àlùfáà lẹ́yìn ẹ̀ kí wọ́n tó lè “la aṣọ ìdábùú [inú àgọ́ ìjọsìn tàbí tẹ́ńpìlì] kọjá,” bẹ́ẹ̀ náà ló ṣe jẹ́ pé Jésù ti di Àlùfáà Àgbà nínú tẹ́ńpìlì ńlá tẹ̀mí Jèhófà kó tó kú, kó sì tó “la aṣọ ìdábùú kọjá, ìyẹn ẹran ara rẹ̀” lọ sọ́run. (Héb. 10:20) Ìdí nìyẹn tí àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù fi sọ pé Jésù “dé bí àlùfáà àgbà” ó sì “gba inú àgọ́ tó tóbi jù, tó sì jẹ́ pípé jù, tí wọn ò fi ọwọ́ ṣe” kọjá, ó sì lọ sí “ọ̀run gangan.”​—Héb. 9:11, 24.

Ìgbà wo ni májẹ̀mú tuntun fìdí múlẹ̀? Lẹ́yìn tí Jésù kú tó sì gbé ìtóye ẹ̀jẹ̀ rẹ̀ lọ sọ́run nítorí wa ni májẹ̀mú tuntun náà fìdí múlẹ̀ tàbí bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́. Kí làwọn nǹkan tó ṣe tó fìdí májẹ̀mú náà múlẹ̀?

Ohun àkọ́kọ́ tí Jésù ṣe ni pé ó lọ síwájú Jèhófà, ohun kejì ni pé ó gbé ìtóye ẹ̀jẹ̀ rẹ̀ fún un, lẹ́yìn náà Jèhófà wá gba ìtóye ẹ̀jẹ̀ náà. Ẹ̀yìn tí àwọn nǹkan mẹ́ta yìí ṣẹlẹ̀ ni májẹ̀mú náà tó fìdí múlẹ̀.

Bíbélì ò sọ ìgbà tí Jèhófà gba ìtóye ẹ̀jẹ̀ Jésù gangan. Torí náà, a ò lè sọ pé ọjọ́ báyìí ni májẹ̀mú náà fìdí múlẹ̀ tó sì bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́. Àmọ́ ó dájú pé ọjọ́ mẹ́wàá ṣáájú ọjọ́ Pẹ́ńtíkọ́sì ni Jésù lọ sọ́run. (Ìṣe 1:3) Torí náà, àárín àkókò kúkúrú yìí, ìyẹn àárín ọjọ́ tí Jésù lọ sọ́run àti ọjọ́ Pẹ́ńtíkọ́sì ni Jésù gbé ìtóye ẹ̀jẹ̀ rẹ̀ fún Jèhófà, tí Jèhófà sì gbà á. (Héb. 9:12) A rí ẹ̀rí tó ṣe kedere pé májẹ̀mú tuntun náà ti bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ lọ́jọ́ Pẹ́ńtíkọ́sì. (Ìṣe 2:1-4, 32, 33) Ìgbà yẹn ló ṣe kedere pé májẹ̀mú tuntun náà ti fìdí múlẹ̀, ó sì ti bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́.

Ní kúkúrú, májẹ̀mú tuntun náà fìdí múlẹ̀, ó sì bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ lẹ́yìn tí Jèhófà gba ìtóye ẹ̀jẹ̀ Jésù tó sì mú àwọn ẹni àmì òróró wọnú májẹ̀mú náà. Torí náà, Jésù ni Àlùfáà Àgbà nígbà tí májẹ̀mú tuntun náà bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́, òun sì ni Alárinà rẹ̀.​—Héb. 7:25; 8:1-3, 6; 9:13-15.