Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

ÀPILẸ̀KỌ FÚN ÌKẸ́KỌ̀Ọ́ 29

“Nígbà Tí Mo Bá Jẹ́ Aláìlera, Ìgbà Náà Ni Mo Di Alágbára”

“Nígbà Tí Mo Bá Jẹ́ Aláìlera, Ìgbà Náà Ni Mo Di Alágbára”

“Mò ń láyọ̀ nínú àìlera, nínú ìwọ̀sí, ní àkókò àìní, nínú inúnibíni àti ìṣòro, nítorí Kristi.”​—2 KỌ́R. 12:10.

ORIN 38 Yóò Sọ Ọ́ Di Alágbára

OHUN TÁ A MÁA JÍRÒRÒ *

1. Kí ni Pọ́ọ̀lù gbà pé òun ní?

ÀPỌ́SÍTÉLÌ Pọ́ọ̀lù gbà pé òun ní àwọn kùdìẹ̀-kudiẹ tàbí àìlera kan. * Ó gbà pé ẹni tí òun jẹ́ lóde “ń joro,” pé kì í rọrùn fún òun láti ṣe ohun tó tọ́ àti pé kì í ṣe gbogbo ìgbà ni Jèhófà máa ń dáhùn àdúrà òun lọ́nà tí òun fẹ́. (2 Kọ́r. 4:16; 12:​7-9; Róòmù 7:​21-23) Pọ́ọ̀lù tún sọ pé àwọn alátakò kan ń tẹ́ńbẹ́lú òun pé òun ò lókun nínú. Síbẹ̀, kò jẹ́ kí ọ̀rọ̀ àìdáa táwọn èèyàn ń sọ nípa ẹ̀ àtàwọn kùdìẹ̀-kudiẹ òun fúnra ẹ̀ mú kó ro ara ẹ̀ pin.​—2 Kọ́r. 10:​10-12, 17, 18.

2. Bó ṣe wà nínú 2 Kọ́ríńtì 12:​9, 10, ẹ̀kọ́ pàtàkì wo ni Pọ́ọ̀lù kọ́?

2 Pọ́ọ̀lù kọ́ ẹ̀kọ́ pàtàkì kan pé èèyàn ṣì lè jẹ́ alágbára kódà tó bá tiẹ̀ ronú pé òun jẹ́ aláìlera. (Ka 2 Kọ́ríńtì 12:​9, 10.) Jèhófà sọ fún Pọ́ọ̀lù pé “à ń sọ agbára [òun] di pípé nínú àìlera.” Lédè míì, Jèhófà máa fún Pọ́ọ̀lù lágbára láti ṣe àwọn ohun tóun fúnra ẹ̀ ò lè dá ṣe. Ní báyìí ná, ẹ jẹ́ ká jíròrò ìdí tí kò fi yẹ ká máa da ara wa láàmú táwọn alátakò bá ń ṣáátá wa.

“MÒ Ń LÁYỌ̀ . . . NÍNÚ ÌWỌ̀SÍ”

3. Kí ló lè mú ká máa láyọ̀ tí wọ́n bá tiẹ̀ ń fi ìwọ̀sí lọ̀ wá?

3 Kò sí ẹni tó fẹ́ kí wọ́n fi ìwọ̀sí lọ òun tàbí kí wọ́n kan òun lábùkù. Àmọ́, tó bá jẹ́ gbogbo ìgbà là ń ronú nípa àbùkù táwọn alátakò fi ń kàn wá, ó lè mú ká rẹ̀wẹ̀sì. (Òwe 24:10) Torí náà, ojú wo ló yẹ ká fi wò ó? Bíi ti Pọ́ọ̀lù, ó yẹ ká máa “láyọ̀ . . . nínú ìwọ̀sí.” (2 Kọ́r. 12:10) Kí nìdí? Torí pé ọmọlẹ́yìn Jésù ni wá, àwọn èèyàn máa tàbùkù sí wa, wọ́n á fi ìwọ̀sí lọ̀ wá, kódà wọ́n á ṣe inúnibíni sí wa. Ìyẹn sì wà lára ohun tó ń fi hàn pé lóòótọ́ la jẹ́ ọmọlẹ́yìn Kristi. (1 Pét. 4:14) Ó ṣe tán, Jésù ti sọ pé wọ́n máa ṣe inúnibíni sáwọn ọmọlẹ́yìn òun. (Jòh. 15:​18-20) Tẹ́ ò bá sì gbàgbé, ohun tó ṣẹlẹ̀ ní ọgọ́rùn-ún ọdún kìíní nìyẹn. Bí àpẹẹrẹ, ojú àbùkù làwọn Gíríìkì fi máa ń wo àwọn Kristẹni. Kódà, ojú táwọn Júù fi wo Pétérù àti Jòhánù náà ni wọ́n fi wo gbogbo àwọn Kristẹni yòókù, wọ́n gbà pé “wọn ò kàwé àti pé wọ́n jẹ́ gbáàtúù.” (Ìṣe 4:13) Àwọn èèyàn gbà pé àwọn Kristẹni ò lágbára torí pé wọn kì í dá sí ọ̀rọ̀ òṣèlú, wọn kì í sì í dara pọ̀ mọ́ ẹgbẹ́ ológun kankan, torí náà wọn ò lẹ́nu láwùjọ.

4. Kí làwọn Kristẹni ọgọ́rùn-ún ọdún kìíní ṣe nígbà táwọn èèyàn bẹnu àtẹ́ lù wọ́n?

4 Ṣé ọ̀rọ̀ àbùkù táwọn alátakò ń sọ sáwọn Kristẹni yẹn mú kí wọ́n dá iṣẹ́ ìwàásù dúró? Rárá. Bí àpẹẹrẹ, wọ́n fìyà jẹ àpọ́sítélì Pétérù àti Jòhánù torí pé wọ́n ń tẹ̀ lé Jésù wọ́n sì ń wàásù ọ̀rọ̀ rẹ̀, síbẹ̀ ṣe ni inú àwọn àpọ́sítélì yẹn ń dùn. (Ìṣe 4:​18-21; 5:​27-29, 40-42) Ojú ò ti àwọn ọmọ ẹ̀yìn yẹn, bó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn èèyàn ò kà wọ́n sí, iṣẹ́ ìwàásù wọn ṣàǹfààní fáwọn èèyàn ju ohun táwọn alátakò ṣe fáwọn èèyàn lọ. Bí àpẹẹrẹ, ìwé táwọn kan lára àwọn Kristẹni yẹn kọ ran àwọn èèyàn lọ́wọ́, ó sì fún wọn nírètí. Ìjọba Ọlọ́run tí wọ́n wàásù ti ń ṣàkóso báyìí, ó sì máa ṣàkóso gbogbo ayé láìpẹ́. (Mát. 24:14) Àmọ́ àwọn alákòóso tó ṣe inúnibíni sáwọn Kristẹni nígbà yẹn ti roko ìgbàgbé, wọ́n ti dìtàn. Bákan náà, àwọn olóòótọ́ ọmọlẹ́yìn ìgbà yẹn wà lọ́run báyìí, tí wọ́n ń ṣàkóso. Àmọ́, àwọn alátakò yẹn ti kú fin-ín fin-ín, tí wọ́n bá sì jíǹde rárá lọ́jọ́ iwájú, abẹ́ Ìjọba Ọlọ́run táwọn Kristẹni yẹn wàásù rẹ̀ ni wọ́n máa wà.​—Ìfi. 5:10.

5. Bó ṣe wà nínú Jòhánù 15:​19, kí nìdí táwọn èèyàn fi ń fojú burúkú wò wá?

5 Lónìí, àwọn èèyàn ń fojú burúkú wo àwa èèyàn Jèhófà, wọ́n gbà pé a ò ní làákàyè a ò sì já mọ́ nǹkan. Kí nìdí? Ìdí ni pé a kì í hùwà bí àwọn èèyàn ayé. A lẹ́mìí ìrẹ̀lẹ̀, a máa ń hùwà pẹ̀lẹ́, a sì máa ń pa òfin mọ́. Àmọ́ ẹ̀mí ìgbéraga, ìjọra-ẹni-lójú àti ìwà ọ̀tẹ̀ ni ayé ń gbé lárugẹ. Bákan náà, a kì í dá sí ọ̀rọ̀ òṣèlú, a kì í sì í dara pọ̀ mọ́ ẹgbẹ́ ológun èyíkéyìí. Torí pé a yàtọ̀ pátápátá sáwọn èèyàn ayé, wọ́n gbà pé a ò já mọ́ nǹkan kan.​—Ka Jòhánù 15:19; Róòmù 12:2.

6. Àwọn nǹkan ribiribi wo ni Jèhófà ń ṣe nípasẹ̀ àwa èèyàn rẹ̀?

6 Bó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn èèyàn ń fojú burúkú wò wá, Jèhófà ń gbé àwọn nǹkan ribiribi ṣe nípasẹ̀ wa. Bí àpẹẹrẹ, ju ti ìgbàkigbà rí lọ, Jèhófà ń mú ká wàásù ìhìn rere níbi gbogbo láyé. Àwa èèyàn Jèhófà là ń tẹ ìwé tí wọ́n túmọ̀ sí èdè tó pọ̀ jù lọ tí wọ́n sì ń pín kiri jù lọ láyé. Yàtọ̀ síyẹn, à ń fi Bíbélì tún ìgbésí ayé àìmọye èèyàn ṣe. Kò sí àní-àní pé Jèhófà ni ìyìn yẹ torí pé àwa táwọn èèyàn kà sí aláìjámọ́ nǹkan kan ni Jèhófà ń lò láti gbé àwọn nǹkan yìí ṣe. Àmọ́ àwa lẹ́nì kọ̀ọ̀kan ńkọ́? Ṣé Jèhófà lè sọ wá di alágbára? Tó bá rí bẹ́ẹ̀, kí la lè ṣe kí Jèhófà lè ràn wá lọ́wọ́? Ní báyìí, ẹ jẹ́ ká wo ẹ̀kọ́ mẹ́ta tá a lè kọ́ látinú àpẹẹrẹ àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù.

MÁ ṢE GBÁRA LÉ ARA RẸ

7. Sọ ẹ̀kọ́ kan tá a lè kọ́ látinú àpẹẹrẹ Pọ́ọ̀lù.

7 Ọ̀kan lára àwọn ẹ̀kọ́ tá a lè kọ́ lára Pọ́ọ̀lù ni pé ká má ṣe gbára lé ara wa bá a ṣe ń sin Jèhófà. Tá a bá fojú èèyàn wò ó, Pọ́ọ̀lù ní àwọn nǹkan tó lè mú kó gbéra ga kó sì gbára lé ara ẹ̀. Bí àpẹẹrẹ, Tásù ló dàgbà sí, ìyẹn ọ̀kan lára àwọn ìlú ńlá Róòmù. Ìlú tó lókìkí tó sì ní ilé ẹ̀kọ́ gíga tó gbayì ni Tásù. Pọ́ọ̀lù kàwé dójú àmì, àní Gàmálíẹ́lì tó jẹ́ ọ̀kan lára àwọn olùkọ́ Júù táwọn èèyàn bọ̀wọ̀ fún ló kọ́ ọ lẹ́kọ̀ọ́. (Ìṣe 5:34; 22:3) Kódà, ó tẹ̀ síwájú débi pé ó di ọ̀kan lára àwọn abẹnugan láàárín àwọn Júù. Ó sọ pé: “Mò ń tẹ̀ síwájú nínú Ìsìn Àwọn Júù ju ọ̀pọ̀ nínú àwọn tí a jọ jẹ́ ẹgbẹ́ lórílẹ̀-èdè mi.” (Gál. 1:​13, 14; Ìṣe 26:4) Pẹ̀lú gbogbo ohun tá a sọ yìí, Pọ́ọ̀lù ò gbára lé ara rẹ̀.

Pọ́ọ̀lù wo ohun táwọn èèyàn kà sí pàtàkì bí “ìdọ̀tí” tó bá fi wé àǹfààní tó ní láti máa tẹ̀ lé Kristi (Wo ìpínrọ̀ 8) *

8. Bó ṣe wà nínú Fílípì 3:8 àti àlàyé ìsàlẹ̀ rẹ̀, ojú wo ni Pọ́ọ̀lù fi wo àwọn nǹkan tó fi sílẹ̀ sẹ́yìn, kí ló sì mú kó máa “láyọ̀ nínú àìlera”?

8 Kí Pọ́ọ̀lù tó di Kristẹni, ó ní ọ̀pọ̀ nǹkan táwọn èèyàn kà sí pàtàkì, àmọ́ tayọ̀tayọ̀ ló fi yááfì wọn. Kódà, ṣe ló kà wọ́n sí “ìdọ̀tí.” (Ka Fílípì 3:8 àti àlàyé ìsàlẹ̀.) Àmọ́ ojú Pọ́ọ̀lù rí màbo torí pé ó di ọmọlẹ́yìn Jésù. Kódà, àwọn Júù bíi tiẹ̀ kórìíra rẹ̀ tìkà-tẹ̀gbin. (Ìṣe 23:​12-14) Yàtọ̀ síyẹn, bó tilẹ̀ jẹ́ pé ọmọ ìbílẹ̀ Róòmù ni, àwọn aláṣẹ Róòmù lù ú, wọ́n sì jù ú sẹ́wọ̀n. (Ìṣe 16:​19-24, 37) Bákan náà, ọ̀pọ̀ ìgbà ni Pọ́ọ̀lù máa ń fẹ́ ṣe ohun tó dáa àmọ́ tí kò rọrùn fún un. (Róòmù 7:​21-25) Láìfi gbogbo ìyẹn pè, Pọ́ọ̀lù fi ìtara ṣe iṣẹ́ Ọlọ́run, ó sì ń “láyọ̀ nínú àìlera” rẹ̀. Kí ló mú kó ṣeé ṣe fún un? Ìdí ni pé ó túbọ̀ máa ń rí agbára Ọlọ́run láyé ẹ̀ láwọn ìgbà tí nǹkan bá nira fún un.​—2 Kọ́r. 4:7; 12:10.

9. Báwo ló ṣe yẹ kó rí lára ẹ tí o kò bá ní àwọn nǹkan táwọn èèyàn kà sí pàtàkì?

9 Kò yẹ ká ronú pé àwọn tó jẹ́ alágbára, àwọn tó kàwé, tó lówó lọ́wọ́ tàbí tí wọ́n wá láti ibi tó lórúkọ ló lè wúlò fún Jèhófà tí Jèhófà á sì fún lókun. Kì í ṣe àwọn nǹkan yìí ló máa jẹ́ ká wúlò fún Jèhófà. Òótọ́ ibẹ̀ ni pé kì í ṣe gbogbo àwọn tó ń sin Jèhófà ló jẹ́ ‘ọlọ́gbọ́n nípa ti ara, alágbára tàbí tí wọ́n bí ní ilé ọlá,’ tí wọ́n bá tiẹ̀ wà, ìwọ̀nba ni. Kàkà bẹ́ẹ̀, “àwọn ohun aláìlera ayé” ni Jèhófà yàn láti lò. (1 Kọ́r. 1:​26, 27) Torí náà, tí o kò bá tiẹ̀ ní àwọn nǹkan tá a sọ níbẹ̀rẹ̀ ìpínrọ̀ yìí, o ṣì lè sin Jèhófà. Bí nǹkan ṣe rí fún ẹ yìí ló máa mú kó o túbọ̀ rí ọwọ́ Jèhófà láyé ẹ. Bí àpẹẹrẹ, tí àyà ẹ bá ń já torí pé àwọn èèyàn ń ta kò ẹ́, ṣe ni kó o gbàdúrà pé kí Jèhófà fún ẹ nígboyà láti sọ ohun tó o gbà gbọ́ fáwọn èèyàn. (Éfé. 6:​19, 20) Tó o bá ní àìsàn tó lágbára tàbí àwọn ìṣòro míì, bẹ Jèhófà pé kó fún ẹ lókun kó o lè ṣe gbogbo ohun tágbára ẹ gbé nínú ìjọsìn rẹ̀. Bó o bá ṣe ń rí ọwọ́ Jèhófà láyé ẹ, bẹ́ẹ̀ ni ìgbàgbọ́ ẹ á túbọ̀ máa lágbára.

KẸ́KỌ̀Ọ́ LÁTINÚ ÀWỌN ÀPẸẸRẸ TÓ WÀ NÍNÚ BÍBÉLÌ

10. Kí nìdí tó fi yẹ ká kẹ́kọ̀ọ́ lára àwọn olóòótọ́ tí Bíbélì mẹ́nu kàn nínú Hébérù 11:​32-34?

10 Pọ́ọ̀lù mọ Ìwé Mímọ́ dunjú. Ó fara balẹ̀ kẹ́kọ̀ọ́ Ìwé Mímọ́, ó sì kẹ́kọ̀ọ́ látinú àpẹẹrẹ àwọn olóòótọ́ tí Ìwé Mímọ́ mẹ́nu kàn. Nígbà tí Pọ́ọ̀lù ń kọ lẹ́tà sáwọn Kristẹni tó jẹ́ Hébérù, ó ní kí wọ́n ronú nípa àpẹẹrẹ àwọn olóòótọ́ ìránṣẹ́ Jèhófà. (Ka Hébérù 11:​32-34.) Ẹ jẹ́ ká gbé àpẹẹrẹ ọ̀kan lára wọn yẹ̀ wò, ìyẹn Ọba Dáfídì. Yàtọ̀ sí pé àwọn ọ̀tá ẹ̀ fojú pọ́n ọn, àwọn kan tó jẹ́ ọ̀rẹ́ ẹ̀ tún dalẹ̀ ẹ̀. Bá a ṣe ń kẹ́kọ̀ọ́ nípa Dáfídì, àá rídìí tí Pọ́ọ̀lù fi sọ pé àpẹẹrẹ Dáfídì fún òun lókun, àá sì rí bá a ṣe lè fara wé Pọ́ọ̀lù.

Dáfídì ò bẹ̀rù láti bá Gòláyátì jà bó tiẹ̀ jẹ́ pé ọmọdé ni, kò sì lágbára. Ó gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà torí ó mọ̀ pé Jèhófà máa fún òun lágbára láti ṣẹ́gun Gòláyátì, Jèhófà ò sì já a kulẹ̀ (Wo ìpínrọ̀ 11)

11. Kí ló mú kí Dáfídì dà bí ẹni tí kò lágbára? (Wo àwòrán iwájú ìwé.)

11 Lójú Gòláyátì tó jẹ́ òmìrán, ṣe ni Dáfídì dà bí èèrà. Nígbà tí Gòláyátì rí Dáfídì ó “wò ó tẹ̀gàntẹ̀gàn.” Ó ṣe tán, Gòláyátì rí fàkìàfakia, ó di ìhámọ́ra ogun, ó sì jẹ́ akínkanjú lójú ogun. Lọ́wọ́ kejì, Dáfídì dà bí ọmọ kékeré kan tí ò nírìírí. Bí nǹkan ṣe rí fún Dáfídì yìí mú kó gbára lé Jèhófà. Torí pé ó gbára lé Jèhófà, Jèhófà fún un lókun, ó sì ṣẹ́gun Gòláyátì.​—1 Sám. 17:​41-45, 50.

12. Ìṣòro míì wo ni Dáfídì tún kojú?

12 Dáfídì tún kojú ìṣòro míì tó lè mú kó máa wo ara rẹ̀ bíi pé òun ò já mọ́ nǹkan kan. Tọkàntọkàn ló fi ń sin Sọ́ọ̀lù ọba Ísírẹ́lì tí Jèhófà yàn. Níbẹ̀rẹ̀ Ọba Sọ́ọ̀lù nífẹ̀ẹ́ Dáfídì. Àmọ́ nígbà tó yá, ìgbéraga mú kí Sọ́ọ̀lù bẹ̀rẹ̀ sí í jowú ẹ̀. Sọ́ọ̀lù mú kí nǹkan nira fún Dáfídì, kódà ó fẹ́ pa á.​—1 Sám. 18:​6-9, 29; 19:​9-11.

13. Kí ni Dáfídì ṣe nígbà tí Ọba Sọ́ọ̀lù ṣàìdáa sí i?

13 Bó tiẹ̀ jẹ́ pé Ọba Sọ́ọ̀lù hùwà àìdáa sí Dáfídì, Dáfídì ṣì ń bọ̀wọ̀ fún un torí pé ọba tí Jèhófà yàn ni. (1 Sám. 24:6) Dáfídì ò dá Jèhófà lẹ́bi torí àwọn nǹkan tí Sọ́ọ̀lù ṣe sí i. Kàkà bẹ́ẹ̀, Dáfídì gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà pé ó máa fún òun lókun tóun á fi fara da ìṣòro náà.​—Sm. 18:​1, àkọlé.

14. Ìṣòro wo ni àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù kojú tó jọ ti Dáfídì?

14 Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù kojú àwọn ìṣòro tó jọ ti Dáfídì. Àwọn ọ̀tá Pọ́ọ̀lù pọ̀, wọ́n sì lágbára jù ú lọ. Àwọn aṣáájú ìsìn ìgbà ayé Pọ́ọ̀lù kórìíra ẹ̀ gan-an. Àwọn ìgbà kan wà tí wọ́n nà án, tí wọ́n sì sọ ọ́ sẹ́wọ̀n. Bíi ti Dáfídì, àwọn tó yẹ kó jẹ́ ọ̀rẹ́ Pọ́ọ̀lù ló hùwà àìdáa sí i. Kódà, àwọn kan nínú ìjọ tún ta kò ó. (2 Kọ́r. 12:11; Fílí. 3:18) Àmọ́ Pọ́ọ̀lù borí gbogbo àwọn alátakò rẹ̀. Lọ́nà wo? Ó ń bá iṣẹ́ ìwàásù rẹ̀ lọ láìka àtakò sí. Ó ṣì nífẹ̀ẹ́ àwọn arákùnrin àtàwọn arábìnrin rẹ̀ kódà nígbà tí wọ́n já a kulẹ̀. Ju gbogbo ẹ̀ lọ, ó jẹ́ adúróṣinṣin sí Jèhófà jálẹ̀ ìgbésí ayé rẹ̀. (2 Tím. 4:8) Ohun tó mú kó jẹ́ adúróṣinṣin délẹ̀ ni pé kò gbẹ́kẹ̀ lé ara ẹ̀, Jèhófà ló gbẹ́kẹ̀ lé.

Máa bọ̀wọ̀ fáwọn tó ń ta ko ohun tó o gbà gbọ́, kó o sì máa fi inú rere hàn sí wọn nígbà tó o bá ń bá wọn sọ̀rọ̀ (Wo ìpínrọ̀ 15) *

15. Kí la pinnu láti ṣe, báwo la ṣe lè ṣe é?

15 Ṣé gbogbo ìgbà làwọn ọmọ ilé ìwé ẹ, àwọn tẹ́ ẹ jọ ń ṣiṣẹ́ àtàwọn mọ̀lẹ́bí ẹ tí kì í ṣe Ẹlẹ́rìí Jèhófà máa ń bẹnu àtẹ́ lù ẹ́? Ṣé ẹnì kan nínú ìjọ ti hùwà àìdáa sí ẹ rí? Tó bá rí bẹ́ẹ̀, máa rántí àpẹẹrẹ Dáfídì àti Pọ́ọ̀lù. Ìwọ náà lè “máa fi ire ṣẹ́gun ibi.” (Róòmù 12:21) Kì í ṣe pé a fẹ́ ju òkúta lu àwọn èèyàn lágbárí bíi ti Dáfídì tó ju òkúta lu Gòláyátì lágbárí, àmọ́ a fẹ́ kí Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run wọ̀ wọ́n lọ́kàn kó sì mú kí wọ́n ṣe ohun tó tọ́. A lè ṣe bẹ́ẹ̀ tá a bá ń fi Bíbélì dáhùn ìbéèrè àwọn èèyàn, tá à ń bọ̀wọ̀ fáwọn tó hùwà àìdáa sí wa, tá a sì ń ṣe ohun tó dáa sí gbogbo èèyàn títí kan àwọn tó kórìíra wa.​—Mát. 5:44; 1 Pét. 3:​15-17.

JẸ́ KÁWỌN MÍÌ RÀN Ẹ́ LỌ́WỌ́

16-17. Kí ni Pọ́ọ̀lù ò jẹ́ gbàgbé?

16 Nígbà tí Pọ́ọ̀lù ṣì jẹ́ ọ̀dọ́, ìyẹn kó tó di ọmọ ẹ̀yìn Kristi, aláfojúdi ni, ó sì máa ń ṣenúnibíni sáwọn ọmọlẹ́yìn Kristi. (Ìṣe 7:58; 1 Tím. 1:13) Jésù fúnra ẹ̀ ló dá Pọ́ọ̀lù lẹ́kun àtimáa ṣenúnibíni sáwọn Kristẹni. Jésù bá a sọ̀rọ̀ látọ̀run, ó sì mú kó fọ́ lójú. Kí ojú ẹ̀ tó lè là, Jésù sọ fún un pé ó gbọ́dọ̀ lọ sọ́dọ̀ àwọn tó ti ń ṣenúnibíni sí tẹ́lẹ̀. Ó gbà kí Ananáyà, ọ̀kan lára àwọn ọmọlẹ́yìn Jésù ran òun lọ́wọ́, ojú ẹ̀ sì là.​—Ìṣe 9:​3-9, 17, 18.

17 Nígbà tó yá, Pọ́ọ̀lù dara pọ̀ mọ́ ìjọ Kristẹni, àwọn èèyàn sì mọ̀ ọ́n dáadáa. Síbẹ̀, kò jẹ́ gbàgbé ẹ̀kọ́ tí Jésù kọ́ ọ nígbà tó ń lọ sí Damásíkù. Ẹ̀mí ìrẹ̀lẹ̀ tí Pọ́ọ̀lù kọ́ mú kó jẹ́ káwọn ará lọ́kùnrin àti lóbìnrin ran òun lọ́wọ́. Ó gbà pé “orísun ìtùnú” ni wọ́n jẹ́ fún òun.​—Kól. 4:​10, 11.

18. Kí ló lè mú kó nira fún wa láti jẹ́ káwọn míì ràn wá lọ́wọ́?

18 Kí la lè rí kọ́ látinú àpẹẹrẹ Pọ́ọ̀lù? Nígbà tá a ṣẹ̀ṣẹ̀ dara pọ̀ mọ́ àwọn èèyàn Jèhófà, ó ṣeé ṣe kó máa yá wa lára láti gba ìrànlọ́wọ́ táwọn míì fẹ́ ṣe fún wa torí a mọ̀ pé ìmọ̀ Bíbélì tá a ní ò pọ̀. (1 Kọ́r. 3:​1, 2) Àmọ́ ní báyìí ńkọ́? Tó bá ti pẹ́ tá a ti ń sin Jèhófà tá a sì ti ní ìrírí gan-an, ó lè má rọrùn fún wa láti gbà pé kí ẹlòmíì ràn wá lọ́wọ́ pàápàá tí ẹni náà ò bá tíì pẹ́ tó wa nínú òtítọ́. Àmọ́ ká má gbàgbé pé àwọn ará wa lọ́kùnrin àti lóbìnrin ni Jèhófà máa ń lò láti fún wa lókun. (Róòmù 1:​11, 12) Torí náà, tá a bá fẹ́ kí Jèhófà fún wa lókun, àfi ká jẹ́ káwọn ará wa ràn wá lọ́wọ́.

19. Kí ló mú kí Pọ́ọ̀lù ṣàṣeyọrí?

19 Pọ́ọ̀lù gbé àwọn nǹkan ribiribi ṣe lẹ́yìn tó di Kristẹni. Kí ló ràn án lọ́wọ́? Ó gbà pé kì í ṣe agbára téèyàn ní, ìwé tó kà, bó ṣe lówó tó tàbí ibi tó ti wá ló máa jẹ́ kó ṣàṣeyọrí. Dípò bẹ́ẹ̀, èèyàn gbọ́dọ̀ lẹ́mìí ìrẹ̀lẹ̀ kó sì gbára lé Jèhófà. Torí náà, ẹ jẹ́ kí gbogbo wa máa tẹ̀ lé àpẹẹrẹ Pọ́ọ̀lù, ká máa gbára lé Jèhófà, ká máa kẹ́kọ̀ọ́ látinú àwọn àpẹẹrẹ tó wà nínú Bíbélì, ká sì gbà káwọn Kristẹni bíi tiwa ràn wá lọ́wọ́. Tá a bá ṣe bẹ́ẹ̀, Jèhófà máa sọ wá di alágbára láìka pé a jẹ́ aláìlera sí tàbí pé a láwọn kùdìẹ̀-kudiẹ tá à ń bá yí!

ORIN 71 Ọmọ Ogun Jèhófà Ni Wá

^ ìpínrọ̀ 5 A máa jíròrò àpẹẹrẹ àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù nínú àpilẹ̀kọ yìí. A máa rí i pé tá a bá lẹ́mìí ìrẹ̀lẹ̀, Jèhófà máa fún wa lágbára ká lè fara da inúnibíni àti ìwọ̀sí ká sì lè borí àwọn kùdìẹ̀-kudiẹ tàbí àìlera wa.

^ ìpínrọ̀ 1 ÀLÀYÉ Ọ̀RỌ̀: Onírúurú nǹkan ló lè mú ká di aláìlera, ó lè jẹ́ torí àìpé wa, torí pé a ò lówó lọ́wọ́, torí pé à ń ṣàìsàn tàbí torí pé a ò fi bẹ́ẹ̀ kàwé. Yàtọ̀ síyẹn, àwọn alátakò máa ń bú wa tàbí kí wọ́n tiẹ̀ bá wa jà.

^ ìpínrọ̀ 57 ÀWÒRÁN: Pọ́ọ̀lù fi gbogbo ohun tó ní sílẹ̀ nígbà tó di ọmọ ẹ̀yìn. Lára wọn ni àwọn akóló tí wọ́n ń kó ìwé mímọ́ sí àtàwọn àkájọ ìwé táwọn tó kàwé nígbà yẹn máa ń lò.

^ ìpínrọ̀ 61 ÀWÒRÁN: Àwọn kan níbi iṣẹ́ arákùnrin kan ń rọ̀ ọ́ pé kó dara pọ̀ mọ́ àwọn níbi tí wọ́n ti ń ṣe ayẹyẹ ọjọ́ ìbí.