Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

ÀPILẸ̀KỌ FÚN ÌKẸ́KỌ̀Ọ́ 30

Ẹ Máa Rìn Nínú Òtítọ́

Ẹ Máa Rìn Nínú Òtítọ́

“Kò sí ohun tó ń mú inú mi dùn bíi kí n máa gbọ́ pé àwọn ọmọ mi ń rìn nínú òtítọ́.”​—3 JÒH. 4.

ORIN 54 “Èyí Ni Ọ̀nà”

OHUN TÁ A MÁA JÍRÒRÒ *

1. Bó ṣe wà nínú 3 Jòhánù 3, 4, kí ló ń fún wa láyọ̀?

Ẹ WO bínú àpọ́sítélì Jòhánù ṣe máa dùn tó nígbà tó gbọ́ pé àwọn tóun ràn lọ́wọ́ láti wá sínú òtítọ́ ṣì ń rìn nínú òtítọ́. Wọ́n kojú ọ̀pọ̀ ìṣòro, Jòhánù sì ń sapá gan-an kó lè fún àwọn Kristẹni tó mú bí ọmọ yìí lókun. Lọ́nà kan náà, inú wa máa ń dùn nígbà táwọn ọmọ wa tàbí àwọn tá a mú bí ọmọ nínú ìjọ bá ya ara wọn sí mímọ́ sí Jèhófà tí wọ́n sì ń sìn ín nìṣó.​—Ka 3 Jòhánù 3, 4.

2. Kí nìdí tí Jòhánù fi kọ àwọn lẹ́tà tó kọ?

2 Ó ṣeé ṣe kó jẹ́ ìlú Éfésù tàbí ìtòsí rẹ̀ ni Jòhánù ń gbé lọ́dún 98 S.K. Ó lè jẹ́ pé ẹ̀yìn tí wọ́n dá a sílẹ̀ lẹ́wọ̀n ní erékùṣù Pátímọ́sì ló lọ síbẹ̀. Àsìkò yẹn ni ẹ̀mí Ọlọ́run mú kó kọ àwọn lẹ́tà mẹ́ta kan. Ó kọ àwọn lẹ́tà náà kó lè fún àwọn Kristẹni yẹn níṣìírí láti jẹ́ adúróṣinṣin kí wọ́n sì máa rìn nínú òtítọ́.

3. Àwọn ìbéèrè wo la máa dáhùn?

3 Jòhánù ló gbẹ̀yìn nínú gbogbo àwọn àpọ́sítélì, ọkàn ẹ̀ ò sì balẹ̀ torí pé àwọn apẹ̀yìndà ti ń kọ́ àwọn èèyàn ní ẹ̀kọ́ èké nínú ìjọ. * (1 Jòh. 2:​18, 19, 26) Àwọn apẹ̀yìndà yẹn sọ pé àwọn mọ Ọlọ́run, àmọ́ wọn ò pa àwọn òfin Jèhófà mọ́. Ní báyìí, ẹ jẹ́ ká sọ̀rọ̀ nípa ìmọ̀ràn tí Jòhánù fún àwọn ará. A sì máa dáhùn àwọn ìbéèrè mẹ́ta yìí: Kí ló túmọ̀ sí láti máa rìn nínú òtítọ́? Kí làwọn nǹkan tó lè mú kó nira láti máa rìn nínú òtítọ́? Báwo la ṣe lè ran àwọn míì lọ́wọ́ ká lè jọ máa rìn nínú òtítọ́?

KÍ LÓ TÚMỌ̀ SÍ LÁTI MÁA RÌN NÍNÚ ÒTÍTỌ́?

4. Bó ṣe wà nínú 1 Jòhánù 2:​3-6 àti 2 Jòhánù 4, 6, kí ló yẹ ká ṣe tá a bá fẹ́ máa rìn nínú òtítọ́?

4 Tá a bá fẹ́ máa rìn nínú òtítọ́, a gbọ́dọ̀ mọ òtítọ́ tó wà nínú Bíbélì Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run. Yàtọ̀ síyẹn, a gbọ́dọ̀ máa “pa àwọn àṣẹ [Jèhófà] mọ́.” (Ka 1 Jòhánù 2:​3-6; 2 Jòhánù 4, 6.) Jésù ló fi àpẹẹrẹ tó ta yọ jù lọ lélẹ̀ tó bá di pé ká pa àwọn àṣẹ Jèhófà mọ́. Torí náà, ọ̀nà kan tá a lè gbà ṣègbọràn sí Jèhófà ni pé ká máa tẹ̀ lé àpẹẹrẹ Jésù pẹ́kípẹ́kí tó bá ti lè ṣeé ṣe tó.​—Jòh. 8:29; 1 Pét. 2:21.

5. Kí ló yẹ kó dá wa lójú?

5 Tá a bá fẹ́ máa bá a lọ ní rírìn nínú òtítọ́, ó gbọ́dọ̀ dá wa lójú pé Jèhófà ni Ọlọ́run òtítọ́ àti pé òtítọ́ ni gbogbo ohun tó wà nínú Bíbélì Ọ̀rọ̀ rẹ̀. Ó tún gbọ́dọ̀ dá wa lójú pé Jésù ni Mèsáyà tí Ọlọ́run ṣèlérí. Lónìí, ọ̀pọ̀ ni ò gbà pé Jésù Ọba tí Ọlọ́run yàn ti ń ṣàkóso lọ́run. Jòhánù kìlọ̀ pé àwọn “ẹlẹ́tàn” máa pọ̀ gan-an, wọ́n á sì máa ṣi àwọn tí kò gba Jèhófà àti Jésù gbọ́ lọ́nà. (2 Jòh. 7-11) Jòhánù sọ pé: “Ta ni òpùrọ́ tí kì í bá ṣe ẹni tó sọ pé Jésù kọ́ ni Kristi?” (1 Jòh. 2:22) Ohun kan ṣoṣo tí ò ní jẹ́ kí wọ́n tàn wá jẹ ni pé ká máa kẹ́kọ̀ọ́ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run déédéé. Ó dìgbà tá a bá ṣe bẹ́ẹ̀ ká tó mọ Jèhófà àti Jésù. (Jòh. 17:3) Ohun tó sì máa jẹ́ kó dá wa lójú pé òtítọ́ la gbà gbọ́ nìyẹn.

ÀWỌN NǸKAN WO LÓ LÈ MÚ KÓ NIRA LÁTI MÁA RÌN NÍNÚ ÒTÍTỌ́?

6. Kí ló lè mú kó nira fáwọn ọ̀dọ́ láti máa rìn nínú òtítọ́?

6 Gbogbo àwa Kristẹni ló yẹ ká ṣọ́ra kí ọgbọ́n orí èèyàn má bàa ṣì wá lọ́nà. (1 Jòh. 2:26) Àmọ́ àwọn ọ̀dọ́ ló yẹ kó ṣọ́ra jù kí wọ́n má bàa kó sínú ìdẹwò yìí. Bí àpẹẹrẹ, ọmọ ọdún mẹ́ẹ̀ẹ́dọ́gbọ̀n (25) ni Arábìnrin Alexia * tó wá láti orílẹ̀-èdè Faransé, ó sọ pé: “Nígbà tí mo ṣì kéré, àwọn nǹkan bí ẹ̀kọ́ ẹfolúṣọ̀n àti ọgbọ́n orí èèyàn máa ń dà mí láàmú. Nígbà míì, ó máa ń ṣe mí bíi pé òótọ́ làwọn ẹ̀kọ́ yẹn. Àmọ́ mo mọ̀ pé kì í ṣe àwọn nìkan ló yẹ kí n tẹ́tí sí, ó yẹ kí n gbọ́ ti Jèhófà náà.” Torí náà, Alexia kẹ́kọ̀ọ́ ìwé náà Life​—How Did It Get Here? By Evolution or by Creation? Ká sì tó ṣẹ́jú pẹ́, láàárín ọ̀sẹ̀ bíi mélòó kan kò ṣiyèméjì mọ́. Ó wá sọ pé: “Mo jẹ́ kó dá mi lójú pé òótọ́ ló wà nínú Bíbélì. Mo sì rí i pé tí mo bá ń tẹ̀ lé àwọn ìlànà Bíbélì nìkan lọkàn mi máa balẹ̀ tí màá sì láyọ̀.”

7. Kí ló yẹ ká ṣọ́ra fún, kí sì nìdí?

7 Gbogbo àwa Kristẹni lọ́mọdé àti lágbà ló yẹ ká ṣọ́ra kó má bàa di pé à ń lọ́wọ́ sóhun tínú Jèhófà ò dùn sí lẹ́sẹ̀ kan náà ká tún máa díbọ́n pé à ń sin Jèhófà. Jòhánù jẹ́ kó ṣe kedere pé a ò lè máa hùwàkiwà ká sì sọ pé à ń rìn nínú òtítọ́. (1 Jòh. 1:6) Tá a bá fẹ́ kínú Jèhófà dùn sí wa nísinsìnyí àti lọ́jọ́ iwájú, a gbọ́dọ̀ máa rántí pé gbogbo ohun tá a bá ń ṣe ni Jèhófà ń rí. Lédè míì, kò sóhun tó ń jẹ́ ẹ̀ṣẹ̀ ìkọ̀kọ̀.​—Héb. 4:13.

8. Kí ló yẹ ká yẹra fún pátápátá?

8 Kò yẹ ká gba ohun táwọn èèyàn ayé ń sọ nípa ẹ̀ṣẹ̀ gbọ́. Àpọ́sítélì Jòhánù sọ pé: “Tí a bá sọ pé, ‘A ò ní ẹ̀ṣẹ̀,’ à ń tan ara wa.” (1 Jòh. 1:8) Nígbà ayé Jòhánù, àwọn apẹ̀yìndà gbà pé èèyàn lè máa dẹ́ṣẹ̀ síbẹ̀ kó ní àjọṣe tó dáa pẹ̀lú Ọlọ́run. Irú èrò yìí náà làwọn èèyàn ní lónìí. Ọ̀pọ̀ ló máa ń sọ pé àwọn gba Ọlọ́run gbọ́ àmọ́ wọn ò fara mọ́ àwọn ìlànà Ọlọ́run nípa ẹ̀ṣẹ̀, ní pàtàkì tó bá kan ọ̀rọ̀ ìṣekúṣe. Bí àpẹẹrẹ, wọ́n máa ń sọ pé ohun tó bá wu àwọn làwọn máa ṣe tó bá kan ìbálòpọ̀, wọ́n sì gbà pé ìgbésí ayé kan tó yàtọ̀ làwọn ń gbé, bẹ́ẹ̀ sì rèé ẹ̀ṣẹ̀ tó wúwo ni Jèhófà kà á sí.

Ẹ̀yin ọ̀dọ́, ẹ ṣèwádìí kẹ́ ẹ lè mọ ìdí tí Jèhófà fi sọ pé àwọn nǹkan kan tọ́, àwọn nǹkan kan ò sì tọ́. Tẹ́ ẹ bá ṣe bẹ́ẹ̀, ẹ̀ẹ́ lè ṣàlàyé ìdí tẹ́ ẹ fi pinnu láti máa ṣe ohun tó tọ́ (Wo ìpínrọ̀ 9) *

9. Àǹfààní wo làwọn ọ̀dọ́ máa rí tí wọ́n bá ń jẹ́ káwọn ìlànà Bíbélì máa darí wọn?

9 Ó lè má rọrùn fáwọn ọ̀dọ́ láti ní èrò tó tọ́ nípa ìbálòpọ̀ pàápàá táwọn ọmọ ilé ìwé wọn tàbí àwọn tí wọ́n jọ ń ṣiṣẹ́ bá ní èrò òdì nípa ẹ̀. Ohun tó ṣẹlẹ̀ sí Arákùnrin Aleksandar nìyẹn. Ó sọ pé: “Nígbà tí mo wà nílé ìwé, àwọn ọmọbìnrin kan máa ń fúngun mọ́ mi pé kí n ní ìbálòpọ̀ pẹ̀lú àwọn, àmọ́ mi ò gbà. Wọ́n wá sọ pé ó ní láti jẹ́ pé abẹ́yà-kan-náà-lòpọ̀ ni mí torí pé mi ò ní ọ̀rẹ́bìnrin.” Tíwọ náà bá ń kojú irú nǹkan bẹ́ẹ̀, máa rántí pé tó o bá jẹ́ kí àwọn ìlànà Bíbélì máa darí ẹ, wàá níyì lójú ara ẹ, o ò ní kó àrùnkárùn, ọkàn ẹ á balẹ̀, wàá sì ní àjọṣe tó dáa pẹ̀lú Jèhófà. Gbogbo ìgbà tó o bá borí àdánwò lá túbọ̀ máa rọrùn fún ẹ láti ṣe ohun tó tọ́. Máa rántí pé Sátánì ló ń jẹ́ káwọn èèyàn máa ní èrò òdì nípa ìbálòpọ̀. Torí náà tí o kò bá gba èrò burúkú yìí láyè, wàá “ṣẹ́gun ẹni burúkú náà.”​—1 Jòh. 2:14.

10. Báwo lohun tó wà nínú 1 Jòhánù 1:9 ṣe lè jẹ́ ká sin Jèhófà pẹ̀lú ẹ̀rí ọkàn tó mọ́?

10 A gbà pé Jèhófà ló lẹ́tọ̀ọ́ láti pinnu ohun tó tọ́ àtohun tí kò tọ́. A sì ń sapá ká má bàa dẹ́ṣẹ̀ sí i. Àmọ́ tá a bá ṣẹ̀, ó yẹ ká jẹ́wọ́ ohun tá a ṣe fún Jèhófà nínú àdúrà. (Ka 1 Jòhánù 1:9.) Tá a bá sì dẹ́ṣẹ̀ tó wúwo, ó yẹ ká lọ sọ́dọ̀ àwọn alàgbà tí Jèhófà yàn láti bójú tó wa. (Jém. 5:​14-16) Síbẹ̀ kò yẹ ká máa ronú ṣáá nípa ẹ̀ṣẹ̀ tá a ti dá sẹ́yìn. Kí nìdí? Ìdí ni pé Baba wa onífẹ̀ẹ́ ti pèsè ìràpadà nípasẹ̀ Ọmọ rẹ̀ ká lè rí ìdáríjì àwọn ẹ̀ṣẹ̀ wa gbà. Jèhófà ti sọ pé òun máa dárí ji àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀ tó bá ronú pìwà dà, ó sì máa ṣe bẹ́ẹ̀ lóòótọ́. Torí náà, kò sóhun tó ní ká má fi ẹ̀rí ọkàn tó mọ́ sin Jèhófà.​—1 Jòh. 2:​1, 2, 12; 3:​19, 20.

11. Kí la lè ṣe tá ò fi ní gba ẹ̀kọ́ èké láyè nínú ọkàn wa?

11 A gbọ́dọ̀ sá fún ẹ̀kọ́ àwọn apẹ̀yìndà pátápátá. Àtìgbà tí ìjọ Kristẹni ti bẹ̀rẹ̀ ni Sátánì ti ń lo àwọn ẹlẹ́tàn láti ṣi àwọn ìránṣẹ́ Ọlọ́run lọ́nà. Torí náà, ó yẹ ká mọ ìyàtọ̀ láàárín irọ́ àti òótọ́. * Àwọn tó kórìíra wa lè lo Íńtánẹ́ẹ̀tì tàbí ìkànnì àjọlò láti tan irọ́ kálẹ̀ nípa wa kí ìgbàgbọ́ wa nínú Jèhófà má bàa lágbára mọ́, kí ìfẹ́ tá a ní sáwọn ará wa sì dín kù. Àmọ́ má gbàgbé o, Sátánì ló wà nídìí irú àwọn irọ́ bẹ́ẹ̀, torí náà má gba irú ẹ̀ láyè láé!​—1 Jòh. 4:​1, 6; Ìfi. 12:9.

12. Kí nìdí tó fi yẹ ká mọyì ẹ̀kọ́ òtítọ́ tá a ti kọ́?

12 Sátánì fẹ́ ká máa ṣiyèméjì nípa Jèhófà, torí náà tá a bá fẹ́ borí, a gbọ́dọ̀ nígbàgbọ́ nínú Jésù àtàwọn ohun tó máa ṣe kí ìfẹ́ Ọlọ́run lè ṣẹ. Yàtọ̀ síyẹn, a tún gbọ́dọ̀ fọkàn tán àwọn tí Jèhófà ń lò láti darí ètò rẹ̀ lónìí. (Mát. 24:​45-47) Tá a bá fẹ́ kí ìgbàgbọ́ wa lágbára, a gbọ́dọ̀ máa ka Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run déédéé. Ìgbà yẹn la máa dà bí igi tó ta gbòǹgbò dáadáa. Pọ́ọ̀lù sọ ohun tó jọ èyí nínú lẹ́tà tó kọ sáwọn ará Kólósè. Ó sọ pé: “Bí ẹ ṣe tẹ́wọ́ gba Kristi Jésù Olúwa, ẹ máa rìn ní ìṣọ̀kan pẹ̀lú rẹ̀, kí ẹ ta gbòǹgbò, kí ẹ sì máa dàgbà nínú rẹ̀, kí ẹ fẹsẹ̀ múlẹ̀ nínú ìgbàgbọ́.” (Kól. 2:​6, 7) Tá a bá sapá kí ìgbàgbọ́ wa lè lágbára, kò sóhun tí Sátánì tàbí àwọn alátìlẹ́yìn rẹ̀ máa ṣe táá mú ká kúrò nínú òtítọ́.​—2 Jòh. 8, 9.

13. Kí ló yẹ ká máa retí, kí sì nìdí?

13 A mọ̀ pé àwọn èèyàn ayé máa kórìíra wa. (1 Jòh. 3:13) Jòhánù rán wa létí pé “gbogbo ayé wà lábẹ́ agbára ẹni burúkú náà.” (1 Jòh. 5:19) Bí ayé búburú yìí ṣe ń lọ sópin, ṣe ni inú á túbọ̀ máa bí Sátánì. (Ìfi. 12:12) Kì í ṣe ìṣekúṣe tàbí irọ́ táwọn apẹ̀yìndà ń pa nìkan ni Sátánì máa ń fẹ́ fi mú wa. Ó tún máa ń jẹ́ kí wọ́n ṣe inúnibíni sí wa gan-an. Ó mọ̀ pé àsìkò díẹ̀ ló kù fóun, torí náà gbogbo ọ̀nà ló ń wá kó lè dá iṣẹ́ ìwàásù náà dúró kó sì ba ìgbàgbọ́ wa jẹ́. Kò yà wá lẹ́nu nígbà náà pé wọ́n ń fòfin de iṣẹ́ wa láwọn orílẹ̀-èdè kan. Síbẹ̀, àwọn ará wa lọkùnrin àti lóbìnrin láwọn orílẹ̀-èdè yẹn ò sọ̀rètí nù, wọ́n ń fara dà á. Wọ́n ń tipa bẹ́ẹ̀ fi hàn pé ohun yòówù kí Sátánì ṣe sáwa èèyàn Jèhófà, àwa la máa ṣẹ́gun!

RAN ÀWỌN MÍÌ LỌ́WỌ́ KÁ LÈ JỌ MÁA RÌN NÍNÚ ÒTÍTỌ́

14. Kí ni ọ̀kan lára ohun tá a lè ṣe káwọn ará wa lè máa rìn nínú òtítọ́?

14 Tá a bá fẹ́ káwọn ará wa máa rìn nínú òtítọ́, a gbọ́dọ̀ máa fi àánú hàn sí wọn. (1 Jòh. 3:​10, 11, 16-18) Kì í ṣe ìgbà tí nǹkan bá ń lọ dáadáa nìkan la fẹ́ fi hàn pé a nífẹ̀ẹ́ wọn, a tún fẹ́ ṣe bẹ́ẹ̀ nígbà tí wọ́n bá níṣòro. Bí àpẹẹrẹ, ṣé o mọ ẹnì kan téèyàn rẹ̀ kú tó sì nílò ìtùnú? Ṣé o mọ ẹnì kan tó níṣòro tó sì nílò ìrànlọ́wọ́? Àbí ṣé o gbọ́ nípa ìṣẹ̀lẹ̀ kan tó ṣẹlẹ̀ sáwọn ará wa tíyẹn mú kí wọ́n pàdánù ohun ìní wọn, tí wọ́n sì wá nílò Gbọ̀ngàn Ìjọba tàbí ilé míì? Kì í ṣe ohun tá a bá sọ nírú àkókò yìí nìkan ló máa tu àwọn ará wa nínú, a tún gbọ́dọ̀ ṣe nǹkan kan láti ràn wọ́n lọ́wọ́.

15. Bó ṣe wà nínú 1 Jòhánù 4:​7, 8, kí ló yẹ ká ṣe?

15 Tá a bá ń fìfẹ́ hàn sáwọn míì, Jèhófà là ń fara wé yẹn. (Ka 1 Jòhánù 4:​7, 8.) Ọ̀nà pàtàkì kan tá a lè gbà fìfẹ́ hàn ni pé ká máa dárí ji ara wa. Bí àpẹẹrẹ, ẹnì kan tó ṣẹ̀ wá lè bẹ̀ wá pé ká má bínú. Tá a bá fẹ́ fìfẹ́ hàn lóòótọ́, a gbọ́dọ̀ dárí jì í, kọ́rọ̀ náà sì tán nínú wa. (Kól. 3:13) Ohun tó ṣẹlẹ̀ sí arákùnrin kan tó ń jẹ́ Aldo nìyẹn, nígbà tó gbọ́ pé arákùnrin kan tóun bọ̀wọ̀ fún sọ ohun tí ò dáa nípa ìlú ìbílẹ̀ òun, inú bí i gan-an. Aldo sọ pé: “Mo gbàdúrà léraléra nípa arákùnrin yẹn kí n má bàa ní èrò tí kò dáa nípa ẹ̀.” Àmọ́ Aldo ò fi mọ síbẹ̀ o. Ó tún ní kí arákùnrin yẹn bá òun ṣiṣẹ́ lóde ẹ̀rí. Bí wọ́n ṣe ń ṣiṣẹ́, Aldo jẹ́ kó mọ bí ohun tó sọ ṣe rí lára òun. Aldo sọ pé: “Nígbà tí arákùnrin náà rí bí ọ̀rọ̀ yẹn ṣe rí lára mi, ó ní kí n má bínú. Bó ṣe ń sọ̀rọ̀, mo rí i pé ọ̀rọ̀ náà dùn ún gan-an, kódà ó kábàámọ̀ ohun tó sọ. Bó ṣe di pé a tún pa dà dọ̀rẹ́ nìyẹn, a sì gbàgbé ọ̀rọ̀ náà.”

16-17. Kí ló yẹ ká pinnu láti ṣe?

16 Ọ̀rọ̀ àwọn ará ní ọgọ́rùn-ún ọdún kìíní jẹ Jòhánù lógún gan-an, ó sì fẹ́ kí ìgbàgbọ́ wọn lágbára. Àwọn lẹ́tà mẹ́ta tó kọ sí wọn jẹ́ ká rí bó ṣe nífẹ̀ẹ́ wọn tó. Inú wa dùn gan-an pé àwọn ará lọ́kùnrin àti lóbìnrin tí wọ́n ń fìfẹ́ hàn bíi ti Jòhánù ni Jèhófà yàn láti bá Kristi jọba lọ́run!​—1 Jòh. 2:27.

17 Ẹ jẹ́ ká fi àwọn ìmọ̀ràn tá a jíròrò nínú àpilẹ̀kọ yìí sọ́kàn. Pinnu pé wàá máa rìn nínú òtítọ́, wàá sì máa ṣègbọràn sí Jèhófà jálẹ̀ ìgbésí ayé rẹ. Máa kẹ́kọ̀ọ́ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run, kó o sì nígbàgbọ́ nínú ohun tó ò ń kọ́. Ní ìgbàgbọ́ tó lágbára nínú Jésù. Sá fún ọgbọ́n orí èèyàn àti ẹ̀kọ́ àwọn apẹ̀yìndà. Má ṣe ohun táá jẹ́ kó o máa díbọ́n bíi pé ò ń sin Jèhófà nígbà tó jẹ́ pé ò ń dẹ́ṣẹ̀. Jẹ́ kí àwọn ìlànà Jèhófà máa darí ẹ lójoojúmọ́. Máa dárí ji àwọn ará, kó o sì máa ran àwọn tó wà nínú ìṣòro lọ́wọ́ kí wọ́n lè dúró nínú òtítọ́. Tó o bá ṣe bẹ́ẹ̀ láìka ìṣòro tàbí inúnibíni tó o lè kojú sí, ìwọ àtàwọn ará yòókù á máa bá a lọ ní rírìn nínú òtítọ́.

ORIN 49 Bá A Ṣe Lè Mú Ọkàn Jèhófà Yọ̀

^ ìpínrọ̀ 5 Sátánì tó jẹ́ baba irọ́ ló ń darí ayé tá à ń gbé yìí. Ìdí nìyẹn tó fi máa ń gba ìsapá ká tó lè máa rìn nínú òtítọ́. Bó sì ṣe rí nìyẹn fáwọn Kristẹni ní ọgọ́rùn-ún ọdún kìíní. Kí Jèhófà lè ran àwọn àtàwa lọ́wọ́, ó mí sí àpọ́sítélì Jòhánù láti kọ lẹ́tà mẹ́ta kan. Nínú àwọn lẹ́tà yẹn, a máa rí àwọn nǹkan tó lè mú kó nira fún wa láti máa rìn nínú òtítọ́ àtàwọn nǹkan tá a lè ṣe ká lè borí wọn.

^ ìpínrọ̀ 6 A ti yí àwọn orúkọ kan pa dà.

^ ìpínrọ̀ 11 Wo àpilẹ̀kọ fún ìkẹ́kọ̀ọ́ “Máa Rí Àrídájú Ọ̀rọ̀” nínú Ilé Ìṣọ́ August 2018.

^ ìpínrọ̀ 59 ÀWÒRÁN: Gbogbo ìgbà ni arábìnrin kan tó wà nílé ìwé máa ń rí ohun tí wọ́n fi ń gbé ìbẹ́yà-kan-náà-lòpọ̀ lárugẹ. (Láwọn ilẹ̀ kan, àmì tó ní oríṣiríṣi àwọ̀ ni wọ́n máa ń fi polówó àwọn abẹ́yà-kan-náà-lòpọ̀.) Nígbà tó yá, arábìnrin náà ṣèwádìí kí ohun tó gbà gbọ́ lè túbọ̀ dá a lójú. Ìyẹn sì mú kó lè gbèjà ìgbàgbọ́ ẹ̀.