Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

ÀPILẸ̀KỌ FÚN ÌKẸ́KỌ̀Ọ́ 35

Mọyì Àwọn Míì Nínú Ìjọ

Mọyì Àwọn Míì Nínú Ìjọ

“Ojú kò lè sọ fún ọwọ́ pé, ‘Mi ò nílò rẹ,’ bẹ́ẹ̀ ni orí kò lè sọ fún ẹsẹ̀ pé, ‘Mi ò nílò rẹ.’”​—1 KỌ́R. 12:21.

ORIN 124 Jẹ́ Adúróṣinṣin

OHUN TÁ A MÁA JÍRÒRÒ *

1. Àǹfààní wo ni Jèhófà fún gbogbo àwa ìránṣẹ́ rẹ̀ olóòótọ́?

JÈHÓFÀ fún gbogbo àwa ìránṣẹ́ rẹ̀ olóòótọ́ láǹfààní láti wà nínú ìjọ rẹ̀. Òótọ́ ni pé ojúṣe ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ la ní nínú ìjọ, àmọ́ gbogbo wa pátá la wúlò. Kókó pàtàkì yìí ṣe kedere nínú ohun tí àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù sọ. Kí ló sọ?

2. Bó ṣe wà nínú Éfésù 4:​16, kí nìdí tó fi ṣe pàtàkì pé ká mọyì ara wa lẹ́nì kìíní kejì, ká sì wà níṣọ̀kan?

2 Bó ṣe wà nínú ẹsẹ Ìwé Mímọ́ tá a gbé àpilẹ̀kọ yìí kà, Pọ́ọ̀lù tẹnu mọ́ ọn pé kò sẹ́nì kankan nínú àwa ìránṣẹ́ Jèhófà tó yẹ kó wo ẹlòmíì nínú ìjọ sùn-ùn, kó wá sọ pé: “Mi ò nílò rẹ.” (1 Kọ́r. 12:21) Tí àlàáfíà bá máa wà nínú ìjọ, ó ṣe pàtàkì pé ká mọyì ara wa ká sì wà níṣọ̀kan. (Ka Éfésù 4:16.) Tá a bá ń ṣiṣẹ́ pọ̀ níṣọ̀kan, ìfẹ́ á wà láàárín wa, kò sì ní sẹ́ni tó máa ronú pé òun ò wúlò nínú ìjọ.

3. Kí la máa jíròrò nínú àpilẹ̀kọ yìí?

3 Àwọn ọ̀nà wo la lè gbà fi hàn pé a mọyì àwọn míì nínú ìjọ, a sì ń bọ̀wọ̀ fún wọn? Nínú àpilẹ̀kọ yìí, a máa jíròrò báwọn alàgbà ṣe lè fi hàn pé àwọn ń bọ̀wọ̀ fáwọn alàgbà míì tí wọ́n jọ wà nínú ìjọ. Lẹ́yìn náà, a máa jíròrò bí gbogbo wa ṣe lè fi hàn pé a mọyì àwọn arákùnrin àtàwọn arábìnrin tí kò tíì ṣègbéyàwó. Paríparí ẹ̀, àá rí bá a ṣe lè fi hàn pé a mọyì àwọn ará tí kò fi bẹ́ẹ̀ gbédè wa.

MÁA BỌ̀WỌ̀ FÁWỌN ALÀGBÀ MÍÌ

4. Ìmọ̀ràn wo ni Pọ́ọ̀lù gba àwọn alàgbà nínú Róòmù 12:10?

4 Ẹ̀mí mímọ́ Jèhófà ló yan gbogbo àwọn alàgbà tó wà nínú ìjọ. Síbẹ̀ ẹ̀bùn ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ ni wọ́n ní, ohun tí wọ́n sì lágbára láti ṣe ò dọ́gba. (1 Kọ́r. 12:​17, 18) Bí àpẹẹrẹ, kò pẹ́ táwọn kan di alàgbà, wọn ò sì fi bẹ́ẹ̀ nírìírí. Àwọn míì lára wọn ti dàgbà, wọn ò sì fi bẹ́ẹ̀ lókun. Síbẹ̀, kò yẹ kí alàgbà kankan wo alàgbà míì sùn-ùn, kó wá sọ pé “Mi ò nílò rẹ.” Dípò bẹ́ẹ̀, ńṣe ló yẹ kí gbogbo alàgbà fi ìmọ̀ràn Pọ́ọ̀lù tó wà nínú Róòmù 12:10 sílò.​—Kà á.

Àwọn alàgbà lè fi hàn pé àwọn mọyì àwọn alàgbà míì tí wọ́n bá ń fara balẹ̀ tẹ́tí sí wọn (Wo ìpínrọ̀ 5-6)

5. Báwo làwọn alàgbà ṣe lè fi hàn pé àwọn mọyì àwọn alàgbà míì, kí sì nìdí tó fi ṣe pàtàkì kí wọ́n máa ṣe bẹ́ẹ̀?

5 Àwọn alàgbà lè fi hàn pé àwọn mọyì àwọn alàgbà míì tí wọ́n bá ń fara balẹ̀ tẹ́tí sí wọn. Ó ṣe pàtàkì kí wọ́n ṣe bẹ́ẹ̀ pàápàá nígbà tí wọ́n bá wà nípàdé ìgbìmọ̀ àwọn alàgbà. Kí nìdí? Ẹ kíyè sóhun tí Ilé-Ìṣọ́nà October 1, 1988 sọ lórí kókó yìí: “Àwọn alàgbà máa ń fi sọ́kàn pé Kristi lè tipasẹ̀ ẹ̀mí mímọ́ darí èrò èyíkéyìí lára àwọn alàgbà láti sọ ìlànà Bíbélì tó máa jẹ́ kí wọ́n yanjú ìṣòro èyíkéyìí tàbí táá jẹ́ kí wọ́n ṣe àwọn ìpinnu pàtàkì kan. (Ìṣe 15:​6-15) Kò sí alàgbà kankan tó lè sọ pé òun nìkan lẹ̀mí mímọ́ ń ṣiṣẹ́ lára rẹ̀.”

6. Kí ló máa jẹ́ káwọn alàgbà ṣiṣẹ́ pọ̀ níṣọ̀kan, báwo nìyẹn ṣe máa ṣe àwọn ará ìjọ láǹfààní?

6 Alàgbà kan tó ń bọ̀wọ̀ fáwọn alàgbà míì kò ní jẹ́ pé òun lá máa kọ́kọ́ sọ̀rọ̀ ní gbogbo ìpàdé àwọn alàgbà. Kì í gba ọ̀rọ̀ mọ́ àwọn míì lẹ́nu kó lè sọ tiẹ̀, ó sì máa ń dẹ́nu dúró káwọn míì lè sọ̀rọ̀. Yàtọ̀ síyẹn, kì í ronú pé òun nìkan lòun gbọ́n tàbí pé ọ̀rọ̀ tòun nìkan làwọn yòókù gbọ́dọ̀ gbà. Dípò bẹ́ẹ̀, ó máa ń fìrẹ̀lẹ̀ sọ èrò ẹ̀, kì í sì í rin kinkin mọ́ ohun tó bá sọ. Bákan náà, ó máa ń fara balẹ̀ gbọ́ ọ̀rọ̀ àwọn míì. Ju gbogbo ẹ̀ lọ, ó máa ń ṣe tán láti jíròrò àwọn ìlànà inú Ìwé Mímọ́, ó sì máa ń yá a lára láti tẹ̀ lé ìtọ́ni “ẹrú olóòótọ́ àti olóye.” (Mát. 24:​45-47) Táwọn alàgbà bá ń fìfẹ́ hàn, tí wọ́n sì ń bọ̀wọ̀ fún ara wọn nínú ìpàdé àwọn alàgbà, ẹ̀mí mímọ́ máa wà pẹ̀lú wọn, á sì ràn wọ́n lọ́wọ́ láti ṣèpinnu tó máa ṣe ìjọ láǹfààní.​—Jém. 3:​17, 18.

MỌYÌ ÀWỌN TÍ KÒ TÍÌ ṢÈGBÉYÀWÓ

7. Ojú wo ni Jésù fi wo àwọn tí kò ṣègbéyàwó?

7 Lára àwọn tó wà nínú ìjọ làwọn tọkọtaya tí kò bímọ àtàwọn tó ti bímọ. Àwọn arákùnrin àtàwọn arábìnrin tí kò tíì ṣègbéyàwó náà wà níbẹ̀. Ojú wo ló yẹ ká máa fi wo àwọn tí kò tíì ṣègbéyàwó? Ojú tí Jésù fi wò wọ́n ló yẹ káwa náà máa fi wò wọ́n. Nígbà tí Jésù ń ṣe iṣẹ́ òjíṣẹ́ rẹ̀ lórí ilẹ̀ ayé, kò ṣègbéyàwó. Ó wà láìní aya ó sì tipa bẹ́ẹ̀ fi gbogbo ayé ẹ̀ ṣe iṣẹ́ tí Jèhófà gbé fún un. Kò sígbà kankan tí Jésù kọ́ni pé ó di dandan kéèyàn ṣègbéyàwó tàbí kéèyàn má ṣe bẹ́ẹ̀. Àmọ́ ó sọ pé àwọn Kristẹni kan lè pinnu pé àwọn ò ní láya tàbí lọ́kọ. (Mát. 19:​11, 12) Jésù bọ̀wọ̀ fún àwọn tí kò ṣègbéyàwó. Kò ronú pé wọn ò dáa tó àwọn tó ṣègbéyàwó tàbí pé wọn ò tẹ́gbẹ́.

8. Bó ṣe wà nínú 1 Kọ́ríńtì 7:​7-9, kí ni Pọ́ọ̀lù gba àwọn Kristẹni níyànjú pé kí wọ́n ṣe?

8 Bíi ti Jésù, àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù náà kò gbéyàwó nígbà tó ń ṣe iṣẹ́ òjíṣẹ́ rẹ̀. Pọ́ọ̀lù ò fìgbà kankan sọ pé àwọn Kristẹni ò gbọ́dọ̀ ṣègbéyàwó torí ó gbà pé ẹnì kọ̀ọ̀kan ló máa ṣèpinnu fúnra ẹ̀. Síbẹ̀, ó gba àwọn Kristẹni níyànjú pé kí wọ́n ronú àtisin Jèhófà láìṣègbéyàwó. (Ka 1 Kọ́ríńtì 7:​7-9.) Kò sí àní-àní pé Pọ́ọ̀lù kò fojú pa àwọn tí kò ṣègbéyàwó rẹ́. Kódà ojúṣe pàtàkì ló gbé fún Tímótì tó jẹ́ ọ̀dọ́ tí kò sì tíì ṣègbéyàwó. * (Fílí. 2:​19-22) Torí náà, kò ní bójú mu kó jẹ́ torí pé arákùnrin kan ṣègbéyàwó tàbí kò ṣègbéyàwó la máa fi pinnu bóyá ó kúnjú ìwọ̀n fún iṣẹ́ nínú ìjọ tàbí kò kúnjú ìwọ̀n.​—1 Kọ́r. 7:​32-35, 38.

9. Kí la lè sọ tó bá dọ̀rọ̀ kéèyàn ṣègbéyàwó tàbí kó má ṣe bẹ́ẹ̀?

9 Kò sígbà kankan tí Jésù tàbí Pọ́ọ̀lù sọ pé dandan ni káwọn Kristẹni ṣègbéyàwó tàbí kí wọ́n má ṣe bẹ́ẹ̀. Kí wá la lè sọ tó bá dọ̀rọ̀ kéèyàn ṣègbéyàwó tàbí kó má ṣe bẹ́ẹ̀? Ẹ gbọ́ ohun tí Ilé Ìṣọ́ October 1, 2012 sọ lórí kókó yìí, ó ní: “Ní tòdodo, ipò méjèèjì [ìyẹn kéèyàn ṣègbéyàwó tàbí kó má ṣe bẹ́ẹ̀] la lè sọ pé ó jẹ́ ẹ̀bùn látọ̀dọ̀ Ọlọ́run. . . . Jèhófà kò ka [wíwà láìní ọkọ tàbí aya] sí nǹkan ìtìjú tàbí ìbànújẹ́.” Torí náà, ó yẹ ká mọyì àwọn arákùnrin àtàwọn arábìnrin wa tí kò tíì ṣègbéyàwó, ká sì máa bọ̀wọ̀ fún wọn.

Tá a bá fẹ́ fi hàn pé a lẹ́mìí ìgbatẹnirò fáwọn ará wa tí kò tíì ṣègbéyàwó, kí ni kò yẹ ká ṣe? (Wo ìpínrọ̀ 10)

10. Báwo la ṣe lè fi ìgbatẹnirò hàn fún àwọn arákùnrin àtàwọn arábìnrin wa tí kò tíì ṣègbéyàwó?

10 Báwo la ṣe lè fi ìgbatẹnirò hàn fún àwọn arákùnrin àtàwọn arábìnrin wa tí kò tíì ṣègbéyàwó? Ó yẹ ká máa fi sọ́kàn pé ṣe làwọn kan lára wọn dìídì pinnu pé àwọn ò ní ṣègbéyàwó. Ó wu àwọn míì lára wọn kí wọ́n ṣègbéyàwó àmọ́ wọn ò kàn tíì rí ẹni tí wọ́n máa fẹ́ ni. Nígbà tó jẹ́ pé ọkọ tàbí aya àwọn kan ti kú. Èyí ó wù ó jẹ́, ṣó yẹ káwọn tó wà nínú ìjọ máa lọ́ àwọn ará yìí nífun pé kí nìdí tí wọn ò fi tíì ṣègbéyàwó tàbí ṣó yẹ kí wọ́n máa sọ fún wọn pé àwọn á bá wọn wá ọkọ tàbí aya? Òótọ́ ni pé àwọn kan lè ní ká bá àwọn wá ọkọ tàbí aya. Àmọ́ tí wọn ò bá bẹ̀ wá níṣẹ́, báwo ló ṣe máa rí lára wọn tá a bá lọ ń bá wọn wá ọkọ tàbí aya? (1 Tẹs. 4:11; 1 Tím. 5:13) Ẹ jẹ́ ká gbọ́ ohun táwọn arákùnrin àtàwọn arábìnrin kan tí kò tíì ṣègbéyàwó sọ.

11-12. Kí lèèyàn lè ṣe tó lè fa ẹ̀dùn ọkàn fáwọn tí kò tíì ṣègbéyàwó?

11 Alábòójútó àyíká kan tó ń ṣe dáadáa lẹ́nu iṣẹ́ rẹ̀ sọ pé ọ̀pọ̀ àǹfààní ló wà nínú kéèyàn wà láìṣègbéyàwó. Síbẹ̀, ó sọ pé inú òun kì í dùn táwọn ará bá ń béèrè lọ́wọ́ òun ṣáá pé: “Kí nìdí tẹ́ ò fi tíì gbéyàwó?” Arákùnrin kan tó ń sìn ní Bẹ́tẹ́lì tí kò sì tíì gbéyàwó sọ pé: “Ọ̀rọ̀ táwọn ará kan ń sọ máa ń ṣe mí bíi pé wọ́n ń káàánú àwa tá ò tíì ṣègbéyàwó. Àwa tá ò tíì ṣègbéyàwó mọ̀ pé ẹ̀bùn la ní, àmọ́ ohun tí wọ́n ń sọ yìí máa ń jẹ́ kó dà bíi pé a níṣòro.”

12 Arábìnrin kan tó ń sìn ní Bẹ́tẹ́lì tí kò sì tíì lọ́kọ sọ pé: “Àwọn ará kan gbà pé gbogbo àwọn tí kò tíì ṣègbéyàwó ló ń wá ọkọ tàbí aya àti pé gbogbo ìgbà tí wọ́n bá jáde ni wọ́n ń wá ẹni tí wọ́n máa fẹ́. Nígbà kan tí wọ́n rán mi lọ ṣiṣẹ́ lápá ibì kan lórílẹ̀-èdè wa, alẹ́ ọjọ́ ìpàdé ni mo débẹ̀. Arábìnrin tí mo dé sọ́dọ̀ ẹ̀ sọ pé àwọn arákùnrin méjì kan wà níjọ àwọn tí wọn ò fi bẹ́ẹ̀ jù mí lọ. Ó sọ fún mi pé kì í ṣe pé òun ń bá mi wá ọkọ o, àmọ́ kí la wọ Gbọ̀ngàn Ìjọba sí, ṣe ló fà mí lọ sọ́dọ̀ àwọn arákùnrin náà. Ẹ̀yin náà ẹ wo bó ṣe máa rí lára èmi àtàwọn arákùnrin méjèèjì yẹn, inú wa ò dùn rárá.”

13. Àpẹẹrẹ àwọn wo ló fún arábìnrin kan tí kò tíì lọ́kọ níṣìírí?

13 Arábìnrin míì tó ń sìn ní Bẹ́tẹ́lì tóun náà ò tíì lọ́kọ sọ pé: “Mo mọ àwọn aṣáájú-ọ̀nà kan tó jù mí lọ dáadáa síbẹ̀ tí wọn ò ṣègbéyàwó. Wọ́n nírìírí, wọ́n ń pọkàn pọ̀ sórí iṣẹ́ ìsìn wọn, wọ́n ń fara wọn jìn fáwọn míì, iṣẹ́ ìsìn wọn ń fún wọn láyọ̀, wọ́n sì ń ran ìjọ lọ́wọ́ gan-an. Ojú tó tọ́ ni wọ́n fi ń wo ara wọn, wọn ò ronú pé àwọn sàn ju àwọn tó ti ṣègbéyàwó lọ tàbí pé àwọn níṣòro torí pé àwọn ò tíì ṣègbéyàwó.” Bó ṣe máa ń rí nìyẹn téèyàn bá wà ní ìjọ tí wọ́n ti ń fojú tó tọ́ wo àwọn tí kò tíì ṣègbéyàwó. Kò ní máa ṣe ẹ́ bíi pé wọ́n ń káàánú ẹ tàbí pé wọ́n ń jowú ẹ, bẹ́ẹ̀ sì ni wọn ò ní fojú burúkú wò ẹ́ tàbí kí wọ́n máa gbé ẹ gẹṣin aáyán. Ìwọ alára á mọ̀ pé wọ́n mọyì ẹ, o sì wúlò.

14. Báwo la ṣe lè fi hàn pé a mọyì àwọn tí kò tíì ṣègbéyàwó?

14 Inú àwọn arákùnrin àtàwọn arábìnrin tí kò tíì ṣègbéyàwó máa dùn tá a bá mọyì wọn torí ànímọ́ dáadáa tí wọ́n ní, tá ò sì káàánú wọn torí pé wọn ò tíì ṣègbéyàwó. Dípò ká máa káàánú wọn, ẹ jẹ́ ká mọyì wọn, ká sì máa yìn wọ́n torí pé wọ́n jẹ́ adúróṣinṣin sí Jèhófà. Tá a bá ń ṣe bẹ́ẹ̀, àwọn ará wa yìí ò ní máa rò pé ohun tá à ń sọ fún wọn ni pé: “Mi ò nílò rẹ.” (1 Kọ́r. 12:21) Dípò bẹ́ẹ̀, wọ́n á mọ̀ pé a mọyì àwọn, inú wọn á sì dùn pé àwọn wúlò nínú ìjọ.

Ẹ MỌYÌ ÀWỌN ARÁ TÍ KÒ FI BẸ́Ẹ̀ GBÉDÈ YÍN

15. Kí làwọn kan ṣe kí wọ́n lè mú iṣẹ́ ìsìn wọn gbòòrò sí i?

15 Lẹ́nu àìpẹ́ yìí, ọ̀pọ̀ àwọn ará ló ń kọ́ èdè míì kí wọ́n lè ṣe púpọ̀ sí i lẹ́nu iṣẹ́ ìsìn wọn, ìyẹn sì gba pé kí wọ́n ṣe àwọn àyípadà kan. Àwọn arákùnrin àtàwọn arábìnrin yìí ti kúrò ní ìjọ tó ń sọ èdè ìbílẹ̀ wọn kí wọ́n lè lọ sìn níbi tí àìní gbé pọ̀ láwọn ìjọ tó ń sọ èdè míì. (Ìṣe 16:9) Ẹnì kọ̀ọ̀kan wọn ló pinnu pé àwọn fẹ́ ṣe púpọ̀ sí i lẹ́nu iṣẹ́ ìsìn Jèhófà. Ó lè gba ọ̀pọ̀ ọdún kí wọ́n tó gbọ́ èdè náà dáadáa, síbẹ̀ ọ̀pọ̀ nǹkan ribiribi ni wọ́n ń gbé ṣe. Àwọn ànímọ́ dáadáa tí wọ́n ní àti ìrírí wọn ń gbé ìjọ ró, ó sì ń fáwọn ará lókun. A mà mọyì àwọn arákùnrin àtàwọn arábìnrin wa yìí gan-an o!

16. Báwo làwọn alàgbà ṣe máa ń pinnu bóyá arákùnrin kan kúnjú ìwọ̀n láti di alàgbà tàbí ìránṣẹ́ iṣẹ́ òjíṣẹ́?

16 Ìgbìmọ̀ àwọn alàgbà kò ní pinnu pé arákùnrin kan kò kúnjú ìwọ̀n láti di alàgbà tàbí ìránṣẹ́ iṣẹ́ òjíṣẹ́ kìkì nítorí pé kò fi bẹ́ẹ̀ gbọ́ èdè tí ìjọ náà ń sọ dáadáa. Ohun tí Ìwé Mímọ́ sọ pé àwọn arákùnrin gbọ́dọ̀ kúnjú ìwọ̀n ẹ̀ ká tò lè yàn wọ́n làwọn alàgbà fi máa gbé onítọ̀hún yẹ̀ wò, kì í ṣe bó ṣe gbọ́ èdè tí ìjọ náà ń sọ tó.​—1 Tím. 3:​1-10, 12, 13; Títù 1:​5-9.

17. Ìpinnu wo ló di dandan pé káwọn òbí ṣe tí ìdílé wọn bá ṣí lọ sórílẹ̀-èdè míì?

17 Àwọn ìdílé Kristẹni kan ti ṣí lọ sórílẹ̀-èdè míì torí ogun tàbí torí kí wọ́n lè ríṣẹ́. Irú àwọn ọmọ ìdílé bẹ́ẹ̀ sábà máa ń lọ síléèwé tí wọ́n ti ń fi èdè tí wọ́n ń sọ lórílẹ̀-èdè náà kọ́ wọn. Ó lè pọn dandan pé káwọn òbí náà kọ́ èdè yẹn kí wọ́n tó lè ríṣẹ́. Kí ni wọ́n máa ṣe tó bá jẹ́ pé ìjọ tó ń sọ èdè ìbílẹ̀ wọn wà lórílẹ̀-èdè yẹn? Ìjọ wo ni ìdílé náà máa lọ? Ṣé ìjọ tó ń sọ èdè ìbílẹ̀ wọn ni àbí èyí tó ń sọ èdè ibi tí wọ́n wà?

18. Bó ṣe wà nínú Gálátíà 6:​5, báwo la ṣe lè fi hàn pé a fara mọ́ ìpinnu tí olórí ìdílé kan ṣe?

18 Olórí ìdílé ló máa pinnu ìjọ tí ìdílé ẹ̀ máa lọ. Torí pé kò sẹ́ni tó máa báwọn ṣèpinnu yìí, ó gbọ́dọ̀ ronú nípa ohun tó máa ṣe ìdílé ẹ̀ láǹfààní jù. (Ka Gálátíà 6:5.) Lẹ́yìn tí wọ́n bá ti ṣèpinnu, a gbọ́dọ̀ fara mọ́ ìpinnu èyíkéyìí tí olórí ìdílé náà bá ṣe, ká jẹ́ kára tù wọ́n, ká sì fi hàn pé a mọyì wọn àti pé wọ́n wúlò nínú ìjọ.​—Róòmù 15:7.

19. Kí ló yẹ káwọn olórí ìdílé ronú lé tàdúràtàdúrà?

19 Lọ́wọ́ kejì, ó lè jẹ́ pé ìjọ tó ń sọ èdè ìbílẹ̀ wọn làwọn ìdílé kan ń lọ bó tiẹ̀ jẹ́ pé àwọn ọmọ wọn ò fi bẹ́ẹ̀ gbédè náà. Tó bá jẹ́ pé èdè tí wọ́n ń sọ lórílẹ̀-èdè yẹn ni wọ́n ń sọ lágbègbè tí wọ́n wà, àwọn ọmọ wọn lè má fi bẹ́ẹ̀ lóye ohun tí wọ́n ń sọ nípàdé, wọ́n sì lè má tẹ̀ síwájú. Kí nìdí? Ìdí ni pé ó lè ṣòro fáwọn ọmọ náà láti lóye èdè ìbílẹ̀ àwọn òbí wọn torí pé èdè tí wọ́n ń sọ lórílẹ̀-èdè yẹn ni wọ́n fi ń kọ́ wọn níléèwé. Tọ́rọ̀ bá rí bẹ́ẹ̀, ó yẹ káwọn olórí ìdílé fara balẹ̀ ronú lórí ọ̀rọ̀ náà tàdúràtàdúrà, kí wọ́n lè ṣèpinnu táá jẹ́ káwọn ọmọ wọn túbọ̀ sún mọ́ Jèhófà àtàwọn èèyàn ẹ̀. Wọ́n lè pinnu pé àwọn máa kọ́ àwọn ọmọ wọn lédè ìbílẹ̀ wọn tàbí kí wọ́n pinnu pé àwọn á lọ sí ìjọ tó ń sọ èdè táwọn ọmọ náà gbọ́ dáadáa. Ìpinnu yòówù kí olórí ìdílé náà ṣe, ó yẹ káwọn tó wà nínú ìjọ tí wọ́n ń dara pọ̀ mọ́ mú kára tù wọ́n, kí wọ́n sì jẹ́ kí ìdílé náà mọ̀ pé àwọn wúlò nínú ìjọ.

Báwo la ṣe lè fi hàn pé a mọyì àwọn tí ò fi bẹ́ẹ̀ gbédè wa? (Wo ìpínrọ̀ 20)

20. Báwo la ṣe lè fi hàn pé a mọyì àwọn arákùnrin àtàwọn arábìnrin tó ń kọ́ èdè wa?

20 Pẹ̀lú gbogbo àlàyé tá a ti ṣe yìí, kò sígbà tá ò ní rí àwọn arákùnrin àtàwọn arábìnrin tí kò fi bẹ́ẹ̀ gbọ́ èdè nínú ìjọ wa. Ó lè ṣòro fún wọn láti sọ ohun tó wà lọ́kàn wọn. Síbẹ̀ tá a bá wò wọ́n dáadáa, àá rí i pé wọ́n nífẹ̀ẹ́ Jèhófà gan-an, wọ́n sì ń jọ́sìn rẹ̀ tọkàntọkàn bí wọn ò tiẹ̀ fi bẹ́ẹ̀ gbédè wa. Tá a bá fara balẹ̀, àá kíyè sáwọn ànímọ́ dáadáa tí wọ́n ní, ìyẹn á sì mú ká túbọ̀ mọyì wọn. Nípa bẹ́ẹ̀, a ò ní sọ pé “mi ò nílò rẹ” kìkì nítorí pé wọn ò fi bẹ́ẹ̀ gbédè wa.

JÈHÓFÀ MỌYÌ WA GAN-AN

21-22. Àǹfààní tó ṣàrà ọ̀tọ̀ wo la ní?

21 Àǹfààní ńlá ni Jèhófà fún wa bó ṣe jẹ́ ká wà nínú ìjọ rẹ̀. Yálà ọkùnrin ni wá tàbí obìnrin, a ti ṣègbéyàwó tàbí a ò tíì ṣe, bóyá ọmọdé ni wá tàbí àgbà, yálà a gbédè tàbí a ò fi bẹ́ẹ̀ gbọ́, gbogbo wa pátá ni Jèhófà mọyì, ẹnì kọ̀ọ̀kan wa ló sì wúlò nínú ìjọ.​—Róòmù 12:​4, 5; Kól. 3:​10, 11.

22 Torí náà, ẹ jẹ́ ká máa fi àwọn ẹ̀kọ́ pàtàkì tá a kọ́ látinú àpèjúwe tí Pọ́ọ̀lù ṣe nípa ara èèyàn sílò. Tá a bá ń ṣe bẹ́ẹ̀, á túbọ̀ dá wa lójú pé a wúlò nínú ìjọ, àá sì túbọ̀ mọyì àwọn míì tá a jọ wà nínú ìjọ.

ORIN 90 Ẹ Máa Gba Ara Yín Níyànjú

^ ìpínrọ̀ 5 Ibi ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ làwa èèyàn Jèhófà ti wá, ojúṣe ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ la sì ní nínú ìjọ. Nínú àpilẹ̀kọ yìí, a máa rí ìdí tó fi ṣe pàtàkì pé ká mọyì gbogbo àwọn tó wà nínú ìjọ, ká sì máa bọ̀wọ̀ fún wọn.

^ ìpínrọ̀ 8 A ò lè fi gbogbo ẹnu sọ pé Tímótì kò gbéyàwó.