Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

ÀPILẸ̀KỌ FÚN ÌKẸ́KỌ̀Ọ́ 39

Ẹ Máa Fún Àwọn Arábìnrin Níṣìírí

Ẹ Máa Fún Àwọn Arábìnrin Níṣìírí

“Àwọn obìnrin tó ń kéde ìhìn rere jẹ́ agbo ọmọ ogun ńlá.”​—SM. 68:11.

ORIN 137 Àwọn Obìnrin Olóòótọ́, Àwọn Arábìnrin Wa

OHUN TÁ A MÁA JÍRÒRÒ *

Àwọn arábìnrin tó nítara máa ń kópa nínú ìpàdé, wọ́n máa ń lọ sóde ẹ̀rí, wọ́n máa ń tún Gbọ̀ngàn Ìjọba ṣe, wọ́n sì máa ń fìfẹ́ hàn sáwọn ará míì (Wo ìpínrọ̀ 1)

1. Àwọn nǹkan wo làwọn arábìnrin ń ṣe nínú ètò Ọlọ́run, àmọ́ ìṣòro wo ni wọ́n ń kojú? (Wo àwòrán iwájú ìwé.)

INÚ wa dùn pé a ní àwọn arábìnrin tó ń ṣiṣẹ́ kára nínú ìjọ! Bí àpẹẹrẹ, wọ́n máa ń kópa nínú ìpàdé, wọ́n sì máa ń lọ sóde ẹ̀rí déédéé. Àwọn kan máa ń lọ́wọ́ nínú àtúnṣe Gbọ̀ngàn Ìjọba, wọ́n sì máa ń fìfẹ́ hàn sáwọn ará. Síbẹ̀, wọ́n ní àwọn ìṣòro tó ń bá wọn fínra. Bí àpẹẹrẹ, àwọn kan ń tọ́jú àwọn òbí wọn tó ti dàgbà. Àwọn míì ń kojú inúnibíni nínú ìdílé wọn. Òbí tó ń dá tọ́mọ làwọn kan, èyí sì gba pé kí wọ́n ṣiṣẹ́ kára kí wọ́n lè bójú tó àwọn ọmọ wọn.

2. Kí nìdí tó fi yẹ ká sapá láti máa fún àwọn arábìnrin wa níṣìírí?

2 Kí nìdí tó fi yẹ ká sapá láti máa fún àwọn arábìnrin wa níṣìírí? Ìdí ni pé nínú ayé, wọn ò ka àwọn obìnrin sí rárá. Yàtọ̀ síyẹn, Bíbélì rọ̀ wá pé ká mọyì àwọn obìnrin, ká sì máa fún wọn níṣìírí. Bí àpẹẹrẹ, àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù sọ fún ìjọ tó wà ní Róòmù pé kí wọ́n gba Fébè tọwọ́tẹsẹ̀ kí wọ́n sì “ràn án lọ́wọ́ nínú ohun tó bá nílò.” (Róòmù 16:​1, 2) Nígbà tí Pọ́ọ̀lù ṣì jẹ́ Farisí, ó ṣeé ṣe kóun náà máa tẹ́ńbẹ́lú àwọn obìnrin bíi tàwọn Farisí yòókù. Àmọ́ lẹ́yìn tó di Kristẹni, ó dẹni tó ń bọ̀wọ̀ fáwọn obìnrin tó sì ń finú rere hàn sí wọn bíi ti Jésù.​—1 Kọ́r. 11:1.

3. Ojú wo ni Jésù fi ń wo àwọn obìnrin, ọwọ́ wo ló sì fi mú àwọn obìnrin tó ṣe ìfẹ́ Ọlọ́run?

3 Gbogbo obìnrin ni Jésù máa ń buyì fún. (Jòh. 4:27) Kì í tẹ́ńbẹ́lú àwọn obìnrin bíi tàwọn aṣáájú ẹ̀sìn Júù ìgbà ayé ẹ̀. Kódà, ìwé kan tó ń ṣàlàyé Bíbélì sọ pé: “Kò sígbà kankan tí Jésù sọ̀rọ̀ burúkú nípa àwọn obìnrin tàbí bẹnu àtẹ́ lù wọ́n.” Yàtọ̀ síyẹn, Jésù mọyì àwọn obìnrin tó ń ṣe ìfẹ́ Baba rẹ̀ gan-an. Kódà, ó pè wọ́n ní arábìnrin òun, ó gbà pé àwọn obìnrin yìí àtàwọn ọkùnrin tó ń tẹ̀ lé òun jọ wà nínú ìdílé kan náà pẹ̀lú òun.​—Mát. 12:50.

4. Kí la máa jíròrò nínú àpilẹ̀kọ yìí?

4 Ó máa ń yá Jésù lára láti ran àwọn obìnrin tó ń jọ́sìn Jèhófà lọ́wọ́. Ó mọyì wọn, ó sì máa ń gbèjà wọn. Ẹ jẹ́ ká jíròrò bá a ṣe lè máa gba tàwọn arábìnrin wa rò bíi ti Jésù.

Ẹ MÁA GBA TI ÀWỌN ARÁBÌNRIN RÒ

5. Kí ló máa ń mú kó ṣòro fáwọn arábìnrin kan láti ní ìbákẹ́gbẹ́ tó ń gbéni ró?

5 Gbogbo wa lọ́kùnrin àti lóbìnrin la máa ń nílò àwọn ọ̀rẹ́ tó ń gbéni ró. Àmọ́ nígbà míì, ó máa ń ṣòro fáwọn arábìnrin láti nírú àwọn ọ̀rẹ́ bẹ́ẹ̀. Kí nìdí? Ẹ jẹ́ ká gbọ́ ohun táwọn arábìnrin kan sọ. Arábìnrin Jordan * sọ pé, “Torí pé mi ò lọ́kọ, ó máa ń ṣe mí bíi pé mi ò rẹ́ni fojú jọ nínú ìjọ.” Aṣáájú-ọ̀nà kan tó ń jẹ́ Kristen tó ń sìn níbi àìní gbé pọ̀ sọ pé, “Tí èèyàn bá ṣẹ̀ṣẹ̀ dé ìjọ kan, ó máa ń ṣe èèyàn bíi pé òun dá wà.” Àmọ́ kì í ṣe àwọn arábìnrin nìkan nirú ẹ̀ máa ń ṣe, ó máa ń ṣe àwọn arákùnrin kan náà bẹ́ẹ̀. Yàtọ̀ síyẹn, téèyàn bá wà nínú ìdílé tí wọ́n ti ń ṣe ẹ̀sìn ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀, ó lè máa ṣe é bíi pé àwọn tó wà nínú ìdílé ẹ̀ ò lóye ẹ̀, ó sì tún lè máa ṣe é bíi pé kò rẹ́ni fojú jọ nínú ìjọ. Ó lè máa ṣe àwọn tí kò lè jáde nílé bíi pé àwọn dá wà, bó sì ṣe máa ń rí lára àwọn mọ̀lẹ́bí tó ń tọ́jú wọn náà nìyẹn. Arábìnrin Annette sọ pé, “Mi ò kì í lè lọ síbi àpèjẹ tí wọ́n bá pè mí sí torí pé èmi nìkan ni mò ń tójú màmá mi.”

Bíi ti Jésù, a lè fi hàn pé a nífẹ̀ẹ́ àwọn arábìnrin wa (Wo ìpínrọ̀ 6-9) *

6. Bó ṣe wà nínú Lúùkù 10:​38-42, báwo ni Jésù ṣe ran Màtá àti Màríà lọ́wọ́?

6 Jésù máa ń lo àkókò pẹ̀lú àwọn obìnrin tó ń sin Ọlọ́run, ó sì mú wọn lọ́rẹ̀ẹ́. Ẹ jẹ́ ká wo ọwọ́ tó fi mú Màtá àti Màríà tó ṣeé ṣe kí wọ́n wà láìlọ́kọ. (Ka Lúùkù 10:​38-42.) Jésù máa ń mú kára tù wọ́n kọ́kàn wọn sì balẹ̀ nínú ọ̀rọ̀ àti ìṣe ẹ̀. Kódà, ọkàn Màríà balẹ̀ láti jókòó síbi ẹsẹ̀ Jésù. * Yàtọ̀ síyẹn, ó yá Màtá lára láti fẹjọ́ sun Jésù pé Màríà ò ran òun lọ́wọ́. Nípa bẹ́ẹ̀, ó rọrùn fún Jésù láti kọ́ àwọn méjèèjì lẹ́kọ̀ọ́. Jésù sì fi hàn pé òun nífẹ̀ẹ́ àwọn obìnrin yìí àti Lásárù arákùnrin wọn torí pé ọ̀pọ̀ ìgbà ló ń dé sọ́dọ̀ wọn. (Jòh. 12:​1-3) Abájọ tó fi yá Màtá àti Màríà lára láti ránṣẹ́ pe Jésù nígbà tí Lásárù ń ṣàìsàn.​—Jòh. 11:​3, 5.

7. Sọ ọ̀nà kan tá a lè gbà fún àwọn arábìnrin níṣìírí.

7 Ìpàdé nìkan làwọn arábìnrin kan ti máa ń láǹfààní láti wà pẹ̀lú àwọn ará. Torí náà, ó yẹ ká máa lo àǹfààní yẹn láti bá wọn sọ̀rọ̀, ká jẹ́ kí wọ́n mọ̀ pé a mọyì wọn àti pé a nífẹ̀ẹ́ wọn. Arábìnrin Jordan tá a sọ̀rọ̀ ẹ̀ lẹ́ẹ̀kan sọ pé, “Inú mi máa ń dùn táwọn èèyàn bá sọ pé àwọn gbádùn ìdáhùn mi, tí wọ́n bá sọ pé àwọn fẹ́ bá mi ṣiṣẹ́ lóde ẹ̀rí tàbí tí wọ́n fìfẹ́ hàn sí mi láwọn ọ̀nà míì.” Ó yẹ ká jẹ́ káwọn arábìnrin wa mọ̀ pé wọ́n ṣe pàtàkì sí wa. Arábìnrin kan tó ń jẹ́ Kia sọ pé, “Tí mi ò bá lọ sípàdé lọ́jọ́ kan, mo mọ̀ pé àwọn ará máa fi àtẹ̀jíṣẹ́ ránṣẹ́ sí mi láti béèrè àlàáfíà mi. Ìyẹn máa ń jẹ́ kí n mọ̀ pé àwọn ará lọ́kùnrin àti lóbìnrin nífẹ̀ẹ́ mi gan-an.”

8. Àwọn ọ̀nà míì wo la lè gbà fara wé Jésù?

8 Bíi ti Jésù, ó yẹ káwa náà máa wáyè láti wà pẹ̀lú àwọn arábìnrin. A lè pè wọ́n pé ká jọ jẹun tàbí ká jọ ṣeré jáde. Nírú àwọn àsìkò yẹn, ká rí i pé àwọn ọ̀rọ̀ tó ń gbéni ró là ń sọ. (Róòmù 1:​11, 12) Ó ṣe pàtàkì pé káwọn alàgbà máa fara wé Jésù. Ó mọ̀ pé kò rọrùn fáwọn kan láti wà láìṣègbéyàwó, síbẹ̀ ó jẹ́ kó ṣe kedere pé kò dìgbà téèyàn bá ṣègbéyàwó tàbí tó lọ́mọ kó tó lè ní ojúlówó ayọ̀. (Lúùkù 11:​27, 28) Dípò bẹ́ẹ̀, téèyàn bá ń fi ìjọsìn Jèhófà sípò àkọ́kọ́ nìkan ló máa ní ojúlówó ayọ̀.​—Mát. 19:12.

9. Báwo làwọn alàgbà ṣe lè ran àwọn arábìnrin lọ́wọ́?

9 Ó ṣe pàtàkì gan-an pé káwọn alàgbà mú àwọn arábìnrin bí ọmọ ìyá tàbí bí ìyá wọn. (1 Tím. 5:​1, 2) Á dáa káwọn alàgbà máa wáyè bá àwọn arábìnrin sọ̀rọ̀ kí ìpàdé tó bẹ̀rẹ̀ àti lẹ́yìn ìpàdé. Arábìnrin Kristen tá a sọ̀rọ̀ ẹ̀ lẹ́ẹ̀kan sọ pé, “Alàgbà kan kíyè sí i pé ọwọ́ mi máa ń dí gan-an, ó sì fẹ́ mọ àwọn nǹkan tí mo máa ń ṣe. Mo mọyì bí wọ́n ṣe fìfẹ́ hàn sí mi gan-an.” Táwọn alàgbà bá ń wáyè bá àwọn arábìnrin sọ̀rọ̀ déédéé, wọ́n á fi hàn pé wọ́n nífẹ̀ẹ́ wọn lóòótọ́, wọ́n sì ń gba tiwọn rò. * Arábìnrin Annette tá a sọ̀rọ̀ ẹ̀ lẹ́ẹ̀kan sọ àǹfààní tó wà nínú ká máa bá àwọn alàgbà sọ̀rọ̀. Ó sọ pé: “Ó ti mú kí n túbọ̀ mọ̀ wọ́n, káwọn náà sì túbọ̀ mọ̀ mí. Tí mo bá wá níṣòro, ó máa ń yá mi lára láti sọ fún wọn.”

Ẹ MỌYÌ OHUN TÁWỌN ARÁBÌNRIN Ń ṢE

10. Kí la lè ṣe táá mú kínú àwọn arábìnrin máa dùn?

10 Yálà ọkùnrin ni wá tàbí obìnrin, inú gbogbo wa ló máa ń dùn táwọn èèyàn bá mọyì ẹ̀bùn tá a ní, tí wọ́n sì gbóríyìn fún wa torí ohun tá a ṣe. Lọ́wọ́ kejì, inú wa kì í dùn táwọn èèyàn ò bá mọyì ẹ̀bùn tá a ní tí wọn ò sì kíyè sóhun tá a ṣe. Aṣáájú-ọ̀nà kan tí kò tíì lọ́kọ tórúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Abigail sọ pé ó máa ń ṣe òun bíi pé àwọn èèyàn ò rí tòun rò, ó ní: “Táwọn èèyàn bá rí mi, wọ́n sábà máa ń sọ pé àbúrò lágbájá nìyí tàbí ọmọ lágbájá nìyẹn, àfi bíi pé mi kì í ṣe èèyàn.” Àmọ́ ẹ gbọ́ ohun tí arábìnrin kan tó ń jẹ́ Pam sọ. Pam ò lọ́kọ, síbẹ̀ ọ̀pọ̀ ọdún ló fi ṣiṣẹ́ míṣọ́nnárì. Nígbà tó yá, ó pa dà sílé láti tọ́jú àwọn òbí ẹ̀. Ní báyìí, ó ti lé lẹ́ni àádọ́rin (70) ọdún, síbẹ̀ ó ṣì ń ṣiṣẹ́ aṣáájú-ọ̀nà. Ó sọ pé: “Ohun tó máa ń múnú mi dùn jù ni báwọn èèyàn ṣe máa ń sọ fún mi pé àwọn mọyì ohun tí mò ń ṣe.”

11. Kí ni Jésù ṣe tó fi hàn pé ó mọyì àwọn obìnrin tó ń tẹ̀ lé e?

11 Jésù mọyì àwọn obìnrin tó ń tẹ̀ lé e bí wọ́n ṣe “ń fi àwọn ohun ìní wọn ṣe ìránṣẹ́” fún òun àtàwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀. (Lúùkù 8:​1-3) Kì í ṣe pé ó jẹ́ kí wọ́n tè lé òun nìkan ni, ó tún kọ́ wọn láwọn òtítọ́ tó jinlẹ̀. Bí àpẹẹrẹ, ó jẹ́ kí wọ́n mọ̀ pé òun máa kú, òun sì máa jíǹde. (Lúùkù 24:​5-8) Ó múra àwọn obìnrin yìí sílẹ̀ fún inúnibíni tí wọ́n máa kojú bó ṣe ṣe fáwọn àpọ́sítélì rẹ̀. (Máàkù 9:​30-32; 10:​32-34) Bó tiẹ̀ jẹ́ pé gbogbo àwọn àpọ́sítélì pátá ló sá lọ nígbà tí wọ́n mú Jésù, àwọn kan lára àwọn obìnrin yẹn wà lẹ́gbẹ̀ẹ́ rẹ̀ nígbà tó wà lórí òpó igi oró.​—Mát. 26:56; Máàkù 15:​40, 41.

12. Iṣẹ́ pàtàkì wo ni Jésù gbé fáwọn obìnrin?

12 Iṣẹ́ pàtàkì ni Jésù gbé fáwọn obìnrin. Bí àpẹẹrẹ, àwọn obìnrin tó jẹ́ ọmọ ẹ̀yìn ẹ̀ ló kọ́kọ́ rí i lẹ́yìn tó jíǹde. Àwọn obìnrin yẹn ló rán pé kí wọ́n lọ sọ fún àwọn àpọ́sítélì rẹ̀ pé òun ti jíǹde. (Mát. 28:​5, 9, 10) Ní Pẹ́ńtíkọ́sì 33 Sànmánì Kristẹni, ó ṣeé ṣe káwọn obìnrin náà wà níbẹ̀ nígbà tí ẹ̀mí mímọ́ bà lé àwọn ọmọ ẹ̀yìn. Tó bá rí bẹ́ẹ̀, á jẹ́ pé àwọn náà sọ èdè àjèjì lọ́nà ìyanu, wọ́n sì kéde “àwọn ohun àgbàyanu Ọlọ́run.”​—Ìṣe 1:14; 2:​2-4, 11.

13. Iṣẹ́ wo làwọn arábìnrin ń ṣe lónìí, báwo la ṣe lè fi hàn pé a mọyì ohun tí wọ́n ń ṣe?

13 Ó yẹ ká máa gbóríyìn fáwọn arábìnrin wa torí iṣẹ́ takuntakun tí wọ́n ń ṣe lẹ́nu iṣẹ́ ìsìn Jèhófà. Àwọn kan lára wọn ń kọ́ àwọn ilé tá à ń lò fún ìjọsìn, wọ́n sì ń tún wọn ṣe. Àwọn kan wà láwọn ìjọ tàbí àwùjọ tó ń sọ èdè ilẹ̀ òkèèrè, àwọn kan sì ń yọ̀ǹda ara wọn ní Bẹ́tẹ́lì. Àwọn kan máa ń ṣèrànwọ́ nígbà àjálù, àwọn míì sì ń túmọ̀ ìtẹ̀jáde wa sáwọn èdè míì, nígbà táwọn kan jẹ́ aṣáájú-ọ̀nà tàbí míṣọ́nnárì. Bíi tàwọn arákùnrin, àwọn arábìnrin náà máa ń lọ sí Ilé Ẹ̀kọ́ Àwọn Aṣáájú-Ọ̀nà, Ilé Ẹ̀kọ́ Àwọn Ajíhìnrere Ìjọba Ọlọ́run àti Ilé Ẹ̀kọ́ Gílíádì. Yàtọ̀ síyẹn, àwọn ìyàwó máa ń ran àwọn ọkọ wọn lọ́wọ́ bí wọ́n ṣe ń bójú tó ojúṣe ńlá tí wọ́n ní nínú ìjọ àti nínú ètò Ọlọ́run. Torí pé àwọn obìnrin yìí ń ti àwọn ọkọ wọn lẹ́yìn, ó jẹ́ kó rọrùn fún àwọn arákùnrin yẹn láti fi hàn pé “ẹ̀bùn tí ó jẹ́ èèyàn” làwọn. (Éfé. 4:8) Kí lo rò pé o lè ṣe láti fi hàn pé o mọyì iṣẹ́ táwọn arábìnrin yìí ń ṣe?

14. Táwọn alàgbà bá fi ohun tó wà nínú Sáàmù 68:11 sọ́kàn, kí ló yẹ kí wọ́n ṣe?

14 Àwọn alàgbà tó gbọ́n mọ̀ pé “agbo ọmọ ogun ńlá” làwọn arábìnrin wa torí pé wọ́n wà lára àwọn tó ń fìtara wàásù ìhìn rere jù. (Ka Sáàmù 68:11.) Torí náà, àwọn alàgbà máa ń wá bí wọ́n á ṣe jàǹfààní látinú ìrírí wọn. Arábìnrin Abigail tá a sọ̀rọ̀ ẹ̀ lẹ́ẹ̀kan sọ bí inú ẹ̀ ṣe máa ń dùn tó táwọn arákùnrin bá béèrè lọ́wọ́ rẹ̀ pé àwọn ọ̀nà wo ló dáa jù láti bá àwọn èèyàn sọ̀rọ̀ ní ìpínlẹ̀ ìwàásù wọn. Ó ní, “Ó jẹ́ kí n rí i pé mo wúlò gan-an nínú ètò Ọlọ́run.” Yàtọ̀ síyẹn, àwọn alàgbà mọ̀ pé iṣẹ́ ńlá làwọn àgbà obìnrin ń ṣe bí wọ́n ṣe ń ran àwọn ọ̀dọ́bìnrin lọ́wọ́ láti kojú ìṣòro wọn. (Títù 2:​3-5) Ká sọ̀rọ̀ síbi tọ́rọ̀ wà, ó yẹ ká mọyì àwọn arábìnrin wa, ká sì máa gbóríyìn fún wọn!

Ẹ MÁA GBÈJÀ ÀWỌN ARÁBÌNRIN

15. Àwọn ìgbà wo ló lè gba pé ká gbèjà àwọn arábìnrin?

15 Nígbà míì, ó máa ń gba pé ká gbèjà àwọn arábìnrin wa tí wọ́n bá ń kojú ìṣòro. (Àìsá. 1:17) Bí àpẹẹrẹ, opó kan tàbí arábìnrin kan tóun àti ọkọ ẹ̀ ti fi ara wọn sílẹ̀ lè nílò ẹni tó máa gbẹnu sọ fún wọn táá sì ràn wọ́n lọ́wọ́ láti bójú tó àwọn iṣẹ́ kan tí ọkọ wọn máa ń ṣe tẹ́lẹ̀. Arábìnrin àgbàlagbà kan lè nílò ẹni tó máa gbẹnu sọ fún un lọ́dọ̀ dókítà. Arábìnrin aṣáájú-ọ̀nà kan tó ń yọ̀ǹda ara ẹ̀ fáwọn iṣẹ́ kan nínú ètò Ọlọ́run lè nílò ẹni táá gbèjà ẹ̀ táwọn kan bá ń fẹ̀sùn kàn án pé kì í lọ sóde ẹ̀rí déédéé bíi tàwọn aṣáájú-ọ̀nà yòókù. Kí làwọn nǹkan míì tá a lè ṣe fáwọn arábìnrin wa? Ẹ jẹ́ ká tún wo àpẹẹrẹ Jésù.

16. Báwo ni Jésù ṣe gbèjà Màríà bó ṣe wà nínú Máàkù 14:​3-9?

16 Ó máa ń yá Jésù lára láti gbèjà àwọn obìnrin tó jẹ́ ọmọ ẹ̀yìn ẹ̀ nígbà táwọn èèyàn bá ṣì wọ́n lóye. Bí àpẹẹrẹ, ó gbèjà Màríà nígbà tí Màtá fẹjọ́ ẹ̀ sùn. (Lúùkù 10:​38-42) Ó tún gbèjà ẹ̀ lẹ́ẹ̀kejì nígbà táwọn kan bẹnu àtẹ́ lù ú torí ohun tó ṣe. (Ka Máàkù 14:​3-9.) Jésù mọ ìdí tí Màríà fi ṣe àwọn nǹkan tó ṣe, ó sì gbóríyìn fún un. Ó ní: “Ohun tó dáa gan-an ló ṣe sí mi. . . . Ó ṣe ohun tó lè ṣe.” Kódà, Jésù sọ tẹ́lẹ̀ pé àwọn èèyàn á máa rántí ohun tó ṣe yẹn ní “ibikíbi tí a bá ti ń wàásù ìhìn rere náà ní gbogbo ayé,” ohun tá a sì ń ṣe nínú àpilẹ̀kọ yìí náà nìyẹn. Ǹjẹ́ kò yani lẹ́nu pé Jésù sọ tẹ́lẹ̀ nípa bí iṣẹ́ ìwàásù náà ṣe máa gbòòrò tó nígbà tó ń sọ̀rọ̀ nípa ohun rere tí obìnrin yìí ṣe? Ẹ wo bí ọ̀rọ̀ Jésù ṣe máa múnú Màríà dùn tó lẹ́yìn táwọn èèyàn ṣì í lóye!

17. Sọ àpẹẹrẹ ohun tó lè ṣẹlẹ̀ táá gba pé kó o gbèjà arábìnrin kan.

17 Ṣé o máa ń gbèjà àwọn arábìnrin nígbà tó bá yẹ bẹ́ẹ̀? Ẹ jẹ́ ká wo àpẹẹrẹ kan. Àwọn ará kan kíyè sí i pé arábìnrin kan tí ọkọ ẹ̀ kì í ṣe Ẹlẹ́rìí máa ń pẹ́ dé sípàdé, ẹsẹ̀kẹsẹ̀ tí ìpàdé bá sì ti parí ló máa ń lọ. Wọ́n tún kíyè sí i pé kì í sábà mú àwọn ọmọ ẹ̀ wá sípàdé. Torí náà, wọ́n ń sọ fún un ṣáá pé ó yẹ kí ọkọ ẹ̀ mọ̀ pé dandan ni kó máa mú àwọn ọmọ ẹ̀ wá sípàdé. Àmọ́, òótọ́ ibẹ̀ ni pé gbogbo ohun tí arábìnrin náà lè ṣe ló ń ṣe. Ó mọ̀ pé abẹ́ ọkọ òun lòun wà, ó sì níbi tí àṣẹ òun mọ. Kí lẹnì kọ̀ọ̀kan wa lè ṣe tá a bá gbọ́ irú ẹ̀? Ṣe ló yẹ ká gbóríyìn fún arábìnrin náà, ká sì sọ àwọn nǹkan dáadáa tó ń ṣe fáwọn tó ń sọ̀rọ̀ yẹn. Tá a bá ṣe bẹ́ẹ̀, ìyẹn lè pa wọ́n lẹ́nu mọ́.

18. Kí làwọn nǹkan míì tá a lè ṣe láti ran àwọn arábìnrin wa lọ́wọ́?

18 Tá a bá ń ran àwọn arábìnrin wa lọ́wọ́, ṣe là ń fi hàn pé a nífẹ̀ẹ́ wọn. (1 Jòh. 3:18) Arábìnrin Annette tó ń tọ́jú ìyá ẹ̀ sọ pé: “Àwọn ọ̀rẹ́ mi kan máa ń wá ràn mí lọ́wọ́ kódà wọ́n máa ń gbé oúnjẹ dání nígbà míì. Ó jẹ́ kí n mọ̀ pé wọ́n nífẹ̀ẹ́ mi, mo sì wúlò nínú ìjọ.” Àwọn ará ran Arábìnrin Jordan náà lọ́wọ́. Arákùnrin kan kọ́ ọ bó ṣe lè máa ṣe àwọn àtúnṣe kan lára mọ́tò ẹ̀. Ó sọ pé: “Inú mi dùn pé àwọn ará lọ́kùnrin àti lóbìnrin nífẹ̀ẹ́ mi, wọn ò sì fẹ́ kí ohunkóhun ṣe mí tí mo bá ń wa mọ́tò mi.”

19. Kí làwọn nǹkan míì táwọn alàgbà lè ṣe láti ran àwọn arábìnrin wa lọ́wọ́?

19 Ó yẹ káwọn alàgbà náà máa ronú bí wọ́n á ṣe ran àwọn arábìnrin lọ́wọ́. Wọ́n mọ̀ pé inú Jèhófà máa dùn táwọn bá ń bójú tó àwọn arábìnrin yẹn bó ṣe yẹ. (Jém. 1:27) Wọ́n máa ń fòye bá àwọn arábìnrin lò bíi ti Jésù, wọn kì í ṣòfin máṣu mátọ̀ níbi tó bá ti yẹ kí wọ́n gba tiwọn rò. (Mát. 15:​22-28) Táwọn alàgbà bá ń sapá láti ran àwọn arábìnrin lọ́wọ́ lọ́nà tó ṣe pàtó, inú àwọn arábìnrin yẹn á dùn, wọ́n á sì gbà pé ètò Jèhófà nífẹ̀ẹ́ àwọn. Nígbà tí alábòójútó àwùjọ tí Kia wà gbọ́ pé ó fẹ́ kó lọ sílé míì, ẹsẹ̀kẹsẹ̀ ló ṣètò bí wọ́n ṣe máa bá a kó ẹrù ẹ̀. Arábìnrin Kia sọ pé: “Ohun tí wọ́n ṣe yẹn mú kí nǹkan rọrùn fún mi gan-an. Yàtọ̀ síyẹn, àwọn ọ̀rọ̀ ìṣírí tí wọ́n sọ fún mi jẹ́ kí n mọ̀ pé àwọn alàgbà mọyì mi gan-an nínú ìjọ, wọn ò sì ní dá mi dá a nígbà tí mo bá níṣòro.”

GBOGBO ÀWỌN ARÁBÌNRIN LÓ YẸ KÁ FÌFẸ́ HÀN SÍ

20-21. Báwo la ṣe lè fi hàn pé a nífẹ̀ẹ́ gbogbo àwọn arábìnrin?

20 Àìmọye àwọn arábìnrin tó ń ṣiṣẹ́ kára ló wà nínú àwọn ìjọ wa lónìí, ó sì yẹ ká fìfẹ́ hàn sí wọn. Bá a ṣe rí i nínú àpẹẹrẹ Jésù, ó yẹ ká máa wáyè láti wà pẹ̀lú wọn, ká sì túbọ̀ mọ̀ wọ́n. Ó yẹ ká máa gbóríyìn fún wọn torí ohun ribiribi tí wọ́n ń ṣe nínú iṣẹ́ ìsìn Jèhófà. Ó sì yẹ ká máa gbèjà wọn nígbà tó bá yẹ.

21 Ní orí tó kẹ́yìn lẹ́tà tí àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù kọ sáwọn ará Róòmù, ó dìídì dárúkọ àwọn arábìnrin mẹ́sàn-án. (Róòmù 16:​1, 3, 6, 12, 13, 15) Ẹ wo bí inú àwọn arábìnrin yìí ṣe máa dùn tó nígbà tí wọ́n gbọ́ ìkíni tí Pọ́ọ̀lù fi ránṣẹ́ àti bó ṣe gbóríyìn fún wọn. Torí náà, ẹ jẹ́ ká mọyì gbogbo àwọn arábìnrin tó wà nínú ìjọ wa, ká sì máa gbóríyìn fún wọn. Tá a bá ń ṣe bẹ́ẹ̀, ṣe là ń fi hàn pé a nífẹ̀ẹ́ wọn.

ORIN 136 “Ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ Èrè” Látọ̀dọ̀ Jèhófà

^ ìpínrọ̀ 5 Onírúurú ìṣòro làwọn arábìnrin máa ń kojú. Nínú àpilẹ̀kọ yìí, a máa jíròrò bá a ṣe lè fara wé Jésù ká sì máa fún àwọn arábìnrin wa níṣìírí. A máa rí bí Jésù ṣe lo àkókò pẹ̀lú àwọn obìnrin, bó ṣe fi hàn pé òun mọyì wọn àti bó ṣe gbèjà wọn.

^ ìpínrọ̀ 5 A ti yí àwọn orúkọ kan pa dà.

^ ìpínrọ̀ 6 Ìwé kan tó ń ṣàlàyé Bíbélì sọ pé: ‘Ibi ẹsẹ̀ olùkọ́ làwọn ọmọ ẹ̀yìn sábà máa ń jókòó sí kí wọ́n lè kẹ́kọ̀ọ́ jinlẹ̀ káwọn náà lè di olùkọ́ lọ́jọ́ iwájú. Bó tiẹ̀ jẹ́ pé àwọn Júù kò fàyè gba àwọn obìnrin láti jókòó síbi ẹsẹ̀ olùkọ́, ohun tí Màríà ṣe lọ́jọ́ yẹn fi hàn pé ó mọyì ẹ̀kọ́ Jésù gan-an dípò kó máa ṣe kùrùkẹrẹ nídìí oúnjẹ. Ohun tó ṣe yìí máa ya àwọn ọkùnrin Júù lẹ́nu, á sì bí wọn nínú.’

^ ìpínrọ̀ 9 Ó yẹ káwọn alàgbà kíyè sára tí wọ́n bá ń ran àwọn arábìnrin lọ́wọ́. Bí àpẹẹrẹ, kò yẹ kí alàgbà kan dá lọ ṣèbẹ̀wò sọ́dọ̀ arábìnrin kan.

^ ìpínrọ̀ 65 ÀWÒRÁN: Àwọn ará yìí ń fara wé Jésù. Arákùnrin kan ń bá àwọn arábìnrin kan pààrọ̀ táyà mọ́tò wọn. Arákùnrin míì lọ ṣèbẹ̀wò sọ́dọ̀ arábìnrin àgbàlagbà kan. Arákùnrin míì àti ìyàwó ẹ̀ sì lọ sọ́dọ̀ arábìnrin kan àti ọmọbìnrin ẹ̀ kí wọ́n lè jọ ṣe ìjọsìn ìdílé.