Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

ÀPILẸ̀KỌ FÚN ÌKẸ́KỌ̀Ọ́ 40

“Máa Ṣọ́ Ohun Tí A Fi sí Ìkáwọ́ Rẹ”

“Máa Ṣọ́ Ohun Tí A Fi sí Ìkáwọ́ Rẹ”

“Tímótì, máa ṣọ́ ohun tí a fi sí ìkáwọ́ rẹ.”​—1 TÍM. 6:20.

ORIN 29 À Ń Jẹ́ Kí Orúkọ Wa Máa Rò Wá

OHUN TÁ A MÁA JÍRÒRÒ *

1-2. Kí lohun tí 1 Tímótì 6:20 sọ pé Jèhófà fi síkàáwọ́ Tímótì?

LỌ́PỌ̀ ìgbà, a máa ń fi àwọn ohun ìní wa tó ṣeyebíye síkàáwọ́ àwọn míì. Bí àpẹẹrẹ, a máa ń tọ́jú owó wa sí báǹkì torí a gbà pé wọ́n á bá wa tọ́jú ẹ̀, kò sẹ́ni tó máa jí i, kò sì ní sọnù. Torí náà, a mọ ohun tó túmọ̀ sí pé ká fi ohun tó ṣeyebíye síkàáwọ́ àwọn míì.

2 Ka 1 Tímótì 6:20. Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù rán Tímótì létí ohun iyebíye tí Jèhófà fi síkàáwọ́ rẹ̀, ìyẹn ìmọ̀ tó péye nípa ohun tí Ọlọ́run fẹ́ ṣe fún aráyé. Yàtọ̀ síyẹn, Jèhófà tún fún Tímótì láǹfààní láti “wàásù ọ̀rọ̀ náà” kó sì “ṣe iṣẹ́ ajíhìnrere.” (2 Tím. 4:​2, 5) Pọ́ọ̀lù wá rọ Tímótì pé kó máa ṣọ́ ohun tí Jèhófà fi sí ìkáwọ́ rẹ̀. Bíi ti Tímótì, Jèhófà ti fi àwọn ohun iyebíye kan síkàáwọ́ àwa náà. Àwọn nǹkan wo ni Jèhófà fi síkàáwọ́ wa? Kí sì nìdí tó fi yẹ ká máa ṣọ́ àwọn nǹkan náà?

JÈHÓFÀ JẸ́ KÁ MỌ ÒTÍTỌ́

3-4. Kí nìdí tí òtítọ́ Bíbélì fi ṣeyebíye?

3 Jèhófà ti jẹ́ ká ní ìmọ̀ tó péye nípa òtítọ́ tó wà nínú Bíbélì Ọ̀rọ̀ rẹ̀. Òtítọ́ yìí ṣeyebíye gan-an torí pé ó jẹ́ ká mọ bá a ṣe lè ní àjọṣe tó dáa pẹ̀lú Jèhófà àti bá a ṣe lè ní ojúlówó ayọ̀. Torí pé a gba àwọn ẹ̀kọ́ òtítọ́ yìí gbọ́, a sì ń fi wọ́n sílò, a ti bọ́ lọ́wọ́ ẹ̀kọ́ èké àti ìṣekúṣe tó gbayé kan.​—1 Kọ́r. 6:​9-11.

4 Ohun míì tó jẹ́ kí òtítọ́ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run ṣeyebíye ni pé àwọn onírẹ̀lẹ̀ tí wọ́n jẹ́ “olóòótọ́ ọkàn” nìkan ni Jèhófà jẹ́ kó mọ̀ ọ́n. (Ìṣe 13:48) Àwọn olóòótọ́ ọkàn yìí gbà pé ẹrú olóòótọ́ àti olóye ni Jèhófà ń lò láti pèsè oúnjẹ tẹ̀mí lónìí. (Mát. 11:25; 24:45) A ò lè fúnra wa lóye ẹ̀kọ́ òtítọ́ yìí, kò sì sóhun tó ṣeyebíye tó kéèyàn lóye òtítọ́.​—Òwe 3:​13, 15.

5. Nǹkan míì wo ni Jèhófà fi síkàáwọ́ wa?

5 Jèhófà tún fún wa láǹfààní láti máa kọ́ àwọn èèyàn ní òtítọ́ nípa òun àti ohun tóun fẹ́ ṣe fáráyé. (Mát. 24:14) Ẹ̀kọ́ òtítọ́ yìí ṣeyebíye gan-an torí pé ó ń jẹ́ káwọn èèyàn wá di ara ìdílé Jèhófà, ó sì ń fún wọn láǹfààní láti jogún ìyè àìnípẹ̀kun. (1 Tím. 4:16) Yálà ipò wa gbà wá láyè láti wàásù gan-an tàbí níwọ̀nba, ohun tó jà jù ni pé à ń lọ́wọ́ nínú iṣẹ́ tó ṣe pàtàkì jù lásìkò wa yìí. (1 Tím. 2:​3, 4) A mà dúpẹ́ o pé Jèhófà jẹ́ ká lè máa bá òun ṣiṣẹ́!​—1 Kọ́r. 3:9.

MÁA ṢỌ́ OHUN TÍ A FI SÍ ÌKÁWỌ́ RẸ!

Tímótì rọ̀ mọ́ òtítọ́ nígbà táwọn míì fi òtítọ́ sílẹ̀ (Wo ìpínrọ̀ 6)

6. Kí ló ṣẹlẹ̀ sáwọn kan tí kò ṣọ́ ohun tí Jèhófà fi síkàáwọ́ wọn?

6 Àwọn Kristẹni kan nígbà ayé Tímótì kò mọyì àǹfààní tí Jèhófà fún wọn pé kí wọ́n máa bá òun ṣiṣẹ́. Bí àpẹẹrẹ, Démà ò bá Pọ́ọ̀lù ṣiṣẹ́ ìwàásù mọ́ torí pé ó nífẹ̀ẹ́ ètò àwọn nǹkan yìí. (2 Tím. 4:10) Fíjẹ́lọ́sì àti Hẹmojẹ́nísì náà pa iṣẹ́ ìwàásù tì torí pé wọn ò fẹ́ káwọn èèyàn ṣenúnibíni sí wọn bíi ti Pọ́ọ̀lù. (2 Tím. 1:15) Híméníọ́sì, Alẹkisáńdà àti Fílétọ́sì di apẹ̀yìndà wọ́n sì kúrò nínu òtítọ́. (1 Tím. 1:​19, 20; 2 Tím. 2:​16-18) Ó ṣeé ṣe káwọn èèyàn yìí ti fìgbà kan rí nífẹ̀ẹ́ Jèhófà àmọ́ nígbà tó yá, wọn ò mọyì òtítọ́ mọ́.

7. Ọgbọ́n wo ni Sátánì ń lò kó lè rí wa mú?

7 Kí ni Sátánì ń ṣe ká lè pàdánù àwọn ohun tí Jèhófà fi síkàáwọ́ wa? Ẹ jẹ́ ká wo díẹ̀ lára wọn. Ó ń lo eré ìnàjú, tẹlifíṣọ̀n, rédíò àtàwọn ìwé ìròyìn láti mú ká máa ronú ká sì máa ṣe àwọn nǹkan táá jẹ́ kí òtítọ́ bọ́ mọ́ wa lọ́wọ́. Ó máa ń mú káwọn èèyàn fúngun mọ́ wa tàbí ṣenúnibíni sí wa ká lè dá iṣẹ́ ìwàásù dúró. Ó tún máa ń lo “àwọn ohun tí [àwọn apẹ̀yìndà] ń fi ẹ̀tàn pè ní ‘ìmọ̀’ ” ká lè fi òtítọ́ sílẹ̀.​—1 Tím. 6:​20, 21.

8. Kí la rí kọ́ nínú ohun tó ṣẹlẹ̀ sí arákùnrin kan tó ń jẹ́ Daniel?

8 Tá ò bá ṣọ́ra, a lè bẹ̀rẹ̀ sí í fi òtítọ́ sílẹ̀ díẹ̀díẹ̀. Ẹ jẹ́ ká wo ohun tó ṣẹlẹ̀ sí arákùnrin kan tó ń jẹ́ Daniel, * tó fẹ́ràn kó máa gbá géèmù. Ó sọ pé: “Ìgbà tí mo wà ní nǹkan bí ọmọ ọdún mẹ́wàá ni mo ti bẹ̀rẹ̀ sí í gbá géèmù. Níbẹ̀rẹ̀, àwọn géèmù tí kò burú ni mo máa ń gbá. Àmọ́ nígbà tó yá, mo bẹ̀rẹ̀ sí í gbá àwọn géèmù tó kún fún ìwà ipá àti ẹ̀mí èṣù.” Kó tó mọ̀, ó ti ń lo wákàtí mẹ́ẹ̀ẹ́dógún (15) nídìí géèmù lójoojúmọ́. Ó sọ pé: “Mo mọ̀ nínú mi lọ́hùn-ún pé irú géèmù tí mò ń gbá àti àkókò tí mò ń lò nídìí ẹ̀ ti ń mú kí n jìnnà sí Jèhófà. Àmọ́ ọkàn mi ti yi débi pé mo gbà pé àwọn ìlànà Bíbélì kò kàn mí.” Torí náà tá ò bá fura, eré ìnàjú lè mú kí òtítọ́ bọ́ mọ́ wa lọ́wọ́. Tíyẹn bá sì ṣẹlẹ̀, a máa pàdánù ohun iyebíye tí Jèhófà fi síkàáwọ́ wa.

BÁ A ṢE LÈ ṢỌ́ ÒTÍTỌ́ TÓ WÀ NÍ ÌKÁWỌ́ WA

9. Ta ni Pọ́ọ̀lù fi Tímótì wé nínú 1 Tímótì 1:​18, 19?

9 Ka 1 Tímótì 1:​18, 19. Pọ́ọ̀lù fi Tímótì wé ọmọ ogun, ó sì gbà á níyànjú pé kó máa “ja ogun rere” nìṣó. Àmọ́ ìjà tẹ̀mí ni Pọ́ọ̀lù ń sọ nínú ẹsẹ yìí. Báwo làwọn Kristẹni ṣe dà bí àwọn ọmọ ogun tó wà lójú ogun? Àwọn ànímọ́ wo ló yẹ káwa ọmọ ogun Kristi ní? Ẹ jẹ́ ká wo nǹkan márùn-ún tá a lè kọ́ látinú àpèjúwe tí Pọ́ọ̀lù lò. Àwọn nǹkan yìí kò ní jẹ́ kí òtítọ́ bọ́ mọ́ wa lọ́wọ́.

10. Kí ni ìfọkànsin Ọlọ́run, kí sì nìdí tó fi ṣe pàtàkì?

10 Ní ìfọkànsin Ọlọ́run. Ọmọ ogun tó dáa máa ń jẹ́ adúróṣinṣin. Gbogbo ohun tó bá gbà ló máa ṣe kó lè dáàbò bo ẹni tó fẹ́ràn tàbí ohun tó ṣe pàtàkì sí i. Pọ́ọ̀lù gba Tímótì níyànjú pé kó ní ìfọkànsin Ọlọ́run, ìyẹn ni pé kó jẹ́ adúróṣinṣin sí Ọlọ́run, kó má sì yẹsẹ̀. (1 Tím. 4:7) Tá a bá nífẹ̀ẹ́ Jèhófà jinlẹ̀, tá a sì ń fi gbogbo ọkàn wa sìn ín, a máa fọwọ́ gidi mú òtítọ́, a ò sì ní jẹ́ kó bọ́ mọ́ wa lọ́wọ́.​—1 Tím. 4:​8-10; 6:6.

Tá a bá ti ibi iṣẹ́ dé tó sì ti rẹ̀ wá tẹnutẹnu, ó lè gba pé ká sapá gan-an ká lè lọ sípàdé. Tá a bá ṣe bẹ́ẹ̀, Jèhófà máa bù kún wa (Wo ìpínrọ̀ 11)

11. Kí nìdí tó fi yẹ ká máa kó ara wa níjàánu?

11 Máa kó ara rẹ níjàánu. Ọmọ ogun kan gbọ́dọ̀ máa kó ara ẹ̀ níjàánu tó bá ṣì fẹ́ máa ja ogun nìṣó. Ohun tó jẹ́ kí Tímótì lè máa ja ogun tẹ̀mí nìṣó ni pé ó fi ìmọ̀ràn Pọ́ọ̀lù sílò pé kó sá fún ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́, kó ní àwọn ànímọ́ tó dáa, kó sì máa kẹ́gbẹ́ pẹ̀lú àwọn Kristẹni bíi tiẹ̀. (2 Tím. 2:22) Ìyẹn gba pé kí Tímótì máa kó ara ẹ̀ níjàánu. Táwa náà bá máa borí ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́, ó ṣe pàtàkì ká máa kó ara wa níjàánu. (Róòmù 7:​21-25) Yàtọ̀ síyẹn, a nílò ìkóra-ẹni-níjàánu tá a bá máa bọ́ ìwà àtijọ́ sílẹ̀ ká sì gbé ìwà tuntun wọ̀. (Éfé. 4:​22, 24) Bákan náà, ó gba ìkóra-ẹni-níjàánu ká tó lè lọ sípàdé lẹ́yìn tá a ti ibi iṣẹ́ dé tó sì ti rẹ̀ wá tẹnutẹnu.​—Héb. 10:​24, 25.

12. Kí lá jẹ́ ká máa lo Bíbélì lọ́nà tó túbọ̀ já fáfá?

12 Àwọn ọmọ ogun gbọ́dọ̀ máa fi ohun ìjà ogun wọn dánra wò. Tí wọ́n bá sì máa já fáfá, wọ́n gbọ́dọ̀ máa ṣe bẹ́ẹ̀ déédéé. Bíi tàwọn ọmọ ogun, àwa náà gbọ́dọ̀ já fáfá bá a ṣe ń lo Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run. (2 Tím. 2:15) Wọ́n ń kọ́ wa bá a ṣe lè já fáfá láwọn ìpàdé wa. Àmọ́ ká tó lè fi dá àwọn míì lójú pé ẹ̀kọ́ òtítọ́ ṣeyebíye, a gbọ́dọ̀ ní ètò tó ṣe gúnmọ́ láti máa dá kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, ká sì máa ṣe é déédéé. Ó yẹ ká máa kẹ́kọ̀ọ́ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run kí ìgbàgbọ́ wa lè lágbára. Èyí kọjá ká kàn máa ka Bíbélì. Ó gba pé ká máa ronú lórí nǹkan tá à ń kà, ká ṣèwádìí nínú àwọn ìtẹ̀jáde wa ká lè lóye Ìwé Mímọ́, ká sì mọ bá a ṣe lè fi sílò. (1 Tím. 4:​13-15) Tá a bá ń ṣe bẹ́ẹ̀, àá lè fi Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run kọ́ àwọn míì lọ́nà tó já fáfá. Ìyẹn kọjá ká kàn ka ẹsẹ Bíbélì fún wọn. Ó gba pé ká jẹ́ kí wọ́n lóye Ìwé Mímọ́ kí wọ́n sì mọ bí wọ́n ṣe máa fi í sílò. Tá a bá ń dá kẹ́kọ̀ọ́ déédéé, àá túbọ̀ já fáfá nínú bá a ṣe ń fi Bíbélì Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run kọ́ àwọn míì.​—2 Tím. 3:​16, 17.

13. Kí nìdí tó fi yẹ ká máa lo ìfòyemọ̀ bí Hébérù 5:14 ṣe sọ?

13 Máa lo ìfòyemọ̀. Ọmọ ogun kan gbọ́dọ̀ lè fòye mọ ewu tó wà níwájú kó sì mọ bó ṣe lè yẹra fún un. Ó yẹ káwa náà lè fòye mọ àwọn nǹkan tó lè wu wá léwu, ká sì mọ bá a ṣe máa yẹra fún un. (Òwe 22:3; ka Hébérù 5:14.) Bí àpẹẹrẹ, ó yẹ ká máa fọgbọ́n yan irú eré ìnàjú tá a máa ṣe àtàwọn nǹkan tá a fi ń gbafẹ́. Lọ́pọ̀ ìgbà, àwọn eré tó ń gbé ìṣekúṣe lárugẹ ni wọ́n máa ń ṣe lórí tẹlifíṣọ̀n àtàwọn fíìmù. A mọ̀ pé Jèhófà kórìíra ìṣekúṣe àti pé ìṣekúṣe máa ń ṣàkóbá fáwọn tó ń lọ́wọ́ nínú ẹ̀. Torí náà, a gbọ́dọ̀ yẹra fún gbogbo eré ìnàjú tó lè ba àjọṣe wa pẹ̀lú Jèhófà jẹ́ láìfura.​—Éfé. 5:​5, 6.

14. Báwo ni ìfòyemọ̀ ṣe ran Daniel lọ́wọ́?

14 Nígbà tó yá, Daniel tá a sọ̀rọ̀ ẹ̀ lẹ́ẹ̀kan fòye mọ̀ pé ìṣòro ńlá ni àwọn géèmù tó kún fún ìwà ipá àti ẹ̀mí èṣù tóun ń gbá. Torí náà, ó ṣèwádìí nínú àwọn ìtẹ̀jáde wa nínú Watchtower Library nípa bóun ṣe lè jáwọ́. Báwo nìyẹn ṣe ràn án lọ́wọ́? Kò gbá àwọn géèmù burúkú yẹn mọ́, kò san àsansílẹ̀ owó géèmù orí kọ̀ǹpútà mọ́, kò sì bá àwọn tí wọ́n jọ ń gbá géèmù yẹn kẹ́gbẹ́ mọ́. Daniel sọ pé, “Ní báyìí, ṣe ni mo máa ń wá nǹkan ṣe nílé tàbí kí n kẹ́gbẹ́ pẹ̀lú àwọn ọ̀rẹ́ mi nínú ìjọ dípò kí n máa gbá géèmù.” Daniel ti di aṣáájú-ọ̀nà àti alàgbà báyìí.

15. Àkóbá wo ni àwọn ìtàn èké máa ń fà?

15 Bíi ti Tímótì, àwa náà gbọ́dọ̀ fòye mọ ewu tó wà nínú àwọn ìtàn èké táwọn apẹ̀yìndà ń tàn kálẹ̀. (1 Tím. 4:​1, 7; 2 Tím. 2:16) Bí àpẹẹrẹ, wọ́n lè máa sọ ohun tí kò jóòótọ́ nípa àwọn ará wa tàbí nípa ètò Jèhófà ká lè máa ṣiyèméjì. Irú àwọn irọ́ bẹ́ẹ̀ lè jin ìgbàgbọ́ wa lẹ́sẹ̀. Torí náà, ká má ṣe tẹ́tí sáwọn irọ́ bẹ́ẹ̀ tàbí gbà wọ́n gbọ́. Kí nìdí? Ìdí ni pé “àwọn èèyàn tí ìrònú wọn ti dìbàjẹ́, tí wọn ò mọ òtítọ́” ló máa ń tan irú àwọn irọ́ bẹ́ẹ̀ kálẹ̀. Ohun tí wọ́n ń fẹ́ ni pé ká máa bá àwọn ‘jiyàn ká sì máa bá wọn fa ọ̀rọ̀.’ (1 Tím. 6:​4, 5) Wọ́n fẹ́ ká gba ohun táwọn ń sọ gbọ́ ká sì bẹ̀rẹ̀ sí í fura sáwọn ará wa.

16. Àwọn nǹkan tó lè fa ìpínyà ọkàn wo ló yẹ ká yẹra fún?

16 Yẹra fún àwọn nǹkan tó lè fa ìpínyà ọkàn. “Ọmọ ogun rere fún Kristi Jésù” ni Tímótì, torí náà iṣẹ́ ìsìn rẹ̀ ló gbájú mọ́ dípò kó jẹ́ káwọn nǹkan tara tàbí àwọn nǹkan míì fa ìpínyà ọkàn fún òun. (2 Tím. 2:​3, 4) Bíi ti Tímótì, a ò gbọ́dọ̀ jẹ́ káwọn nǹkan tara gbà wá lọ́kàn débi tá ò fi ní gbájú mọ́ iṣẹ́ òjíṣẹ́ wa mọ́. Tá ò bá ṣọ́ra, “agbára ìtannijẹ ọrọ̀” lè paná ìfẹ́ tá a ní fún Jèhófà, a lè má mọyì òtítọ́ inú Bíbélì mọ́, ó sì lè má yá wa lára láti sọ ọ́ fáwọn èèyàn mọ́. (Mát. 13:22) Torí náà, ká jẹ́ kí ohun díẹ̀ tẹ́ wa lọ́rùn, ká sì máa lo okun wa àti àkókò wa láti “wá Ìjọba náà . . . lákọ̀ọ́kọ́.”​—Mát. 6:​22-25, 33.

17-18. Kí la lè ṣe tí àjọṣe wa pẹ̀lú Jèhófà kò fi ní bà jẹ́?

17 Mọ bó o ṣe máa tètè gbé ìgbésẹ̀. Ọmọ ogun kan máa ń ronú bóun ṣe máa tètè gbé ìgbésẹ̀ bí ogun bá dé. Táwa náà bá fẹ́ dáàbò bo ohun tí Jèhófà fi síkàáwọ́ wa, ó yẹ ká mọ ohun tá a máa ṣe tá a bá kíyè sóhun tó lè ṣèpalára fún wa. Kí lá jẹ́ ká tètè gbé ìgbésẹ̀? Ó yẹ ká ti pinnu ohun tá a máa ṣe kí ewu náà tó yọjú.

18 Ẹ jẹ́ ká ṣàpèjúwe ẹ̀ pẹ̀lú ohun tó máa ń ṣẹlẹ̀ láwọn ibì kan. Táwọn èrò bá pé jọ sínú gbọ̀ngàn kan, wọ́n sábà máa ń sọ ibi tí wọ́n lè gbà jáde tí nǹkan pàjáwìrì bá ṣẹlẹ̀. Lọ́nà kan náà, tá a bá ń wo fíìmù tàbí tá à ń lo Íńtánẹ́ẹ̀tì, ó yẹ ká ti ronú ohun tá a máa ṣe tí àwòrán ìṣekúṣe tàbí eré oníwà ipá tàbí èrò àwọn apẹ̀yìndà bá ṣàdédé yọjú. Tá a bá ti múra sílẹ̀, àá tètè gbé ìgbésẹ̀ káwọn nǹkan yẹn má bàa ba àjọṣe àwa àti Jèhófà jẹ́, ká sì jẹ́ mímọ́ lójú Jèhófà.​—Sm. 101:3; 1 Tím. 4:12.

19. Àwọn ìbùkún wo ni Jèhófà máa fún wa tá a bá ṣọ́ ohun tó fi síkàáwọ́ wa?

19 A gbọ́dọ̀ ṣọ́ àwọn ohun iyebíye tí Jèhófà fi síkàáwọ́ wa, ìyẹn ẹ̀kọ́ òtítọ́ tó wà nínú Bíbélì àti àǹfààní tá a ní láti fi kọ́ àwọn míì. Tá a bá ṣe bẹ́ẹ̀, àá ní ẹ̀rí ọkàn tó mọ́, ìgbésí ayé wa máa nítumọ̀, àá sì láyọ̀ bá a ṣe ń ran àwọn míì lọ́wọ́ láti wá mọ Jèhófà. Lágbára Jèhófà, àá lè ṣọ́ ohun tí Jèhófà fi síkàáwọ́ wa.​—1 Tím. 6:12, 19.

ORIN 127 Irú Èèyàn Tó Yẹ Kí N Jẹ́

^ ìpínrọ̀ 5 Àǹfààní ńlá la ní bá a ṣe mọ òtítọ́ tá a sì fi ń kọ́ àwọn míì. Àpilẹ̀kọ yìí máa jẹ́ ká túbọ̀ mọyì àǹfààní yìí, ká má sì jẹ́ kó bọ́ mọ́ wa lọ́wọ́.

^ ìpínrọ̀ 8 A ti yí orúkọ rẹ̀ pa dà.