Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Ìbéèrè Láti Ọwọ́ Àwọn Òǹkàwé

Ìbéèrè Láti Ọwọ́ Àwọn Òǹkàwé

Ṣé àwọn èèyàn tó ń ṣàkóso nìkan ni Oníwàásù 5:8 ń tọ́ka sí àbí ó kan Jèhófà náà?

Ẹsẹ Bíbélì yìí sọ pé: “Tí o bá rí i tí wọ́n ń ni àwọn aláìní lára tàbí tí wọ́n ń tẹ ìdájọ́ òdodo àti òtítọ́ lójú ní agbègbè rẹ, má ṣe jẹ́ kó yà ọ́ lẹ́nu. Torí ẹnì kan wà tó ń ṣọ́ ẹni tó wà nípò gíga, ẹni yẹn sì ga jù ú lọ, síbẹ̀ àwọn míì tún wà tó ga jù wọ́n lọ.”​—Oníw. 5:8.

Lójú àwa èèyàn, a lè sọ pé àwọn tó ń ṣàkóso nìkan ni ẹsẹ yìí ń sọ nípa ẹ̀. Àmọ́ ẹsẹ yẹn tún jẹ́ ká mọ òótọ́ kan nípa Jèhófà tó tù wá nínú, tó sì fi wá lọ́kàn balẹ̀.

Oníwàásù 5:8 ń sọ̀rọ̀ nípa alákòóso kan tó ń ni àwọn aláìní lára, tó sì ń fi ìdájọ́ òdodo dù wọ́n. Ó yẹ kí alákòóso bẹ́ẹ̀ máa rántí pé ó ṣeé ṣe kí ẹnì kan tó ga ju òun lọ tàbí tó wà nípò àṣẹ tó ju tòun lọ rí òun. Kókó ibẹ̀ ni pé àwọn míì tó wà nípò tó jù bẹ́ẹ̀ lọ tún lè máa wo onítọ̀hún. Ó bani nínú jẹ́ pé bóyá la rí ẹnì kan tó san ju òmíì lọ nínú àwọn alákòóso èèyàn. Ó fẹ́rẹ̀ẹ́ jẹ́ pé gbogbo wọn ni jẹgúdújẹrá. Torí náà, ó di dandan pé káwọn tó wà lábẹ́ wọn máa rọ́jú.

Síbẹ̀, bó ti wù kí nǹkan burú tó, ọkàn wa balẹ̀ pé Jèhófà ń ‘ṣọ́ àwọn tó wà nípò gíga’ nínú ìjọba èèyàn. Torí náà, a lè bẹ Jèhófà pé kó gbà wá lọ́wọ́ wọn, ká sì fọ̀rọ̀ wa lé e lọ́wọ́. (Sm. 55:22; Fílí. 4:​6, 7) A mọ̀ pé “ojú Jèhófà ń lọ káàkiri gbogbo ayé láti fi agbára rẹ̀ hàn nítorí àwọn tí wọ́n ń fi gbogbo ọkàn wọn sìn ín.”​—2 Kíró. 16:9.

Torí náà, ohun tó ń ṣẹlẹ̀ gan-an nínú ìjọba èèyàn ni Oníwàásù 5:8 sọ nípa ẹ̀, pé ẹnì kan wà nípò àṣẹ tó ju tiwọn lọ. Àmọ́ ohun tó ṣe pàtàkì jù nínú ẹsẹ Ìwé Mímọ́ yìí ni pé Jèhófà ga ju gbogbo wọn lọ, kódà òun ni Aláṣẹ Gíga Jù Lọ. Jèhófà ti ń ṣàkóso báyìí nípasẹ̀ Jésù Kristi. Torí náà, ọkàn wa balẹ̀ pé Jèhófà tó ń rí ohun gbogbo jẹ́ onídàájọ́ òdodo, bí Jésù Ọmọ ẹ̀ náà sì ṣe rí nìyẹn.