Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

ÀPILẸ̀KỌ FÚN ÌKẸ́KỌ̀Ọ́ 42

Bá A Ṣe Lè Ran Àwọn Akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì Wa Lọ́wọ́ Kí Wọ́n Lè Ṣèrìbọmi—Apá Kejì

Bá A Ṣe Lè Ran Àwọn Akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì Wa Lọ́wọ́ Kí Wọ́n Lè Ṣèrìbọmi—Apá Kejì

“Máa kíyè sí ara rẹ àti ẹ̀kọ́ rẹ nígbà gbogbo.”​—1 TÍM. 4:16.

ORIN 77 Ìmọ́lẹ̀ Nínú Ayé Tó Ṣókùnkùn

OHUN TÁ A MÁA JÍRÒRÒ *

1. Báwo la ṣe mọ̀ pé iṣẹ́ ìgbẹ̀mílà ni iṣẹ́ sísọni dọmọ ẹ̀yìn?

IṢẸ́ ìgbẹ̀mílà ni iṣẹ́ sísọni dọmọ ẹ̀yìn. Báwo la ṣe mọ̀? Nígbà tí Jésù ń pàṣẹ fáwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ nínú Mátíù 28:​19, 20, ó sọ pé: “Ẹ lọ, kí ẹ máa sọ àwọn èèyàn . . . di ọmọ ẹ̀yìn, ẹ máa batisí wọn.” Kí nìdí tó fi ṣe pàtàkì pé kéèyàn ṣèrìbọmi? Ìdí ni pé téèyàn bá máa rí ìgbàlà, àfi kó ṣèrìbọmi. Ẹni tó fẹ́ ṣèrìbọmi gbọ́dọ̀ gbà pé torí pé Jésù kú ó sì jíǹde nìkan ni aráyé á fi rí ìgbàlà. Ìdí nìyẹn tí àpọ́sítélì Pétérù fi sọ fáwọn Kristẹni bíi tiẹ̀ pé: “Ìrìbọmi [ló] tún ń gbà yín là báyìí . . . nípasẹ̀ àjíǹde Jésù Kristi.” (1 Pét. 3:21) Torí náà, bí ọmọ ẹ̀yìn kan bá ṣèrìbọmi, á nírètí àtiwà láàyè títí láé.

2. Kí ni 2 Tímótì 4:​1, 2 sọ pé ó yẹ káwa tá à ń kọ́ni lẹ́kọ̀ọ́ ṣe?

2 Ká tó lè sọni dọmọ ẹ̀yìn, a gbọ́dọ̀ máa lo “ọ̀nà ìkọ́nilẹ́kọ̀ọ́ tó dáa.” (Ka 2 Tímótì 4:​1, 2.) Kí nìdí? Ìdí ni pé Jésù pàṣẹ fún wa pé: “Ẹ lọ, kí ẹ máa sọ àwọn èèyàn . . . di ọmọ ẹ̀yìn . . . , ẹ máa kọ́ wọn.” Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù sọ pé ká “rí i pé [a] ò jáwọ́” nínú iṣẹ́ náà, ‘torí tí a bá ń ṣe é, àá lè gba ara wa àti àwọn tó ń fetí sí wa là.’ Abájọ tí Pọ́ọ̀lù fi sọ pé: “Máa kíyè sí . . . ẹ̀kọ́ rẹ nígbà gbogbo.” (1 Tím. 4:16) Níwọ̀n bí a ò ti lè sọni dọmọ ẹ̀yìn tá ò bá mọ̀ọ̀yàn kọ́, ó ṣe pàtàkì nígbà náà pé ká ṣe gbogbo ohun tá a lè ṣe ká lè jẹ́ olùkọ́ tó já fáfá.

3. Nínú àpilẹ̀kọ yìí, kí la máa jíròrò nípa bó ṣe yẹ ká máa kọ́ àwọn èèyàn lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì?

3 Ọ̀pọ̀ mílíọ̀nù èèyàn là ń kọ́ lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì kárí ayé. Àmọ́ bá a ṣe jíròrò nínú àpilẹ̀kọ tó ṣáájú, a fẹ́ mọ ohun tá a lè ṣe kí èyí tó pọ̀ jù lára wọn lè ṣèrìbọmi kí wọ́n sì di ọmọlẹ́yìn Jésù. Nínú àpilẹ̀kọ yìí, a máa jíròrò nǹkan márùn-ún míì tó yẹ káwa akéde máa ṣe káwọn akẹ́kọ̀ọ́ wa lè ṣèrìbọmi.

BÍBÉLÌ NI KÓ O MÁA FI KỌ́NI

Ní kí ẹnì kan tó nírìírí sọ àwọn ohun tó o lè ṣe kó o lè mọ béèyàn ṣe ń fi Bíbélì kọ́ni bó ṣe yẹ (Wo ìpínrọ̀ 4-6) *

4. Kí nìdí tí kò fi yẹ kí akéde máa sọ̀rọ̀ jù tó bá ń darí ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì? (Tún wo àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé.)

4 Kò sí àní-àní pé a nífẹ̀ẹ́ ohun tá à ń kọ́ nínú Bíbélì. Torí náà, tá ò bá ṣọ́ra a lè sọ̀rọ̀ jù nípa wọn. Àmọ́, kò yẹ kí ẹni tó ń darí ìkẹ́kọ̀ọ́ máa sọ̀rọ̀ jù, yálà Ìkẹ́kọ̀ọ́ Ilé Ìṣọ́ ló ń darí tàbí Ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì Ìjọ tàbí nígbà tó bá ń kọ́ ẹnì kan lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. Tá a bá máa fi Bíbélì kọ́ni lóòótọ́, a ò gbọ́dọ̀ sọ̀rọ̀ jù, kò sì yẹ ká ṣàlàyé gbogbo nǹkan tá a mọ̀ tán nípa ẹsẹ Ìwé Mímọ́ kan tàbí kókó tá à ń jíròrò. * (Jòh. 16:12) Bí àpẹẹrẹ, báwo ni ìmọ̀ tó o ní nígbà tó o ṣèrìbọmi ṣe pọ̀ tó tá a bá fi wé ohun tó o mọ̀ báyìí? Ó ṣeé ṣe kó jẹ́ pé àwọn ẹ̀kọ́ àkọ́kọ́bẹ̀rẹ̀ nìkan lo mọ̀ nígbà yẹn. (Héb. 6:1) Ọ̀pọ̀ ọdún ló gbà ẹ́ kó o tó mọ ohun tó o mọ̀ lónìí, torí náà má ṣe rọ́ gbogbo ẹ̀ sí akẹ́kọ̀ọ́ lórí lẹ́ẹ̀kan náà.

5. (a) Kí la fẹ́ káwọn akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì wa mọ̀ bó ṣe wà nínú 1 Tẹsalóníkà 2:13? (b) Báwo lo ṣe lè mú kí akẹ́kọ̀ọ́ rẹ ṣàlàyé àwọn nǹkan tó ń kọ́ fún ẹ?

5 A fẹ́ kẹ́ni tá à ń kọ́ lẹ́kọ̀ọ́ mọ̀ pé inú Bíbélì lohun tá à ń kọ́ ọ ti wá. (Ka 1 Tẹsalóníkà 2:13.) Báwo la ṣe lè ṣe bẹ́ẹ̀? Sọ fún un pé kó ṣàlàyé àwọn nǹkan tó ń kọ́ fún ẹ. Dípò tí wàá fi máa ṣàlàyé ẹsẹ Ìwé Mímọ́ fún un ní gbogbo ìgbà, ní kó ṣàlàyé àwọn kan fún ẹ. Jẹ́ kó rí bó ṣe lè fi àwọn ohun tó ń kọ́ nínú Ìwé Mímọ́ sílò ní ìgbésí ayé ẹ̀. Lo àwọn ìbéèrè tó ń tọ́ni sọ́nà àtàwọn ìbéèrè tó máa jẹ́ kó o mọ ohun tó wà lọ́kàn ẹ̀. Ìyẹn á jẹ́ kó o mọ èrò ẹ̀ nípa ẹsẹ Ìwé Mímọ́ tó kà. (Lúùkù 10:​25-28) Bí àpẹẹrẹ, béèrè lọ́wọ́ rẹ̀ pé: “Èwo nínú àwọn ànímọ́ Jèhófà ni ẹsẹ Ìwé Mímọ́ yìí sọ nípa ẹ̀?” “Báwo lo ṣe lè fi ẹsẹ Ìwé Mímọ́ yìí sílò?” “Báwo ni ohun tó o ṣẹ̀ṣẹ̀ kà yìí ṣe rí lára ẹ?” (Òwe 20:5) Ohun tó ṣe pàtàkì jù ni pé kí akẹ́kọ̀ọ́ ẹ nífẹ̀ẹ́ ohun tó ń kọ́, kó sì máa fi í sílò, kì í ṣe bí ìmọ̀ rẹ̀ ṣe pọ̀ tó.

6. Kí nìdí tó fi dáa pé kó o mú àwọn akéde tó nírìírí lọ síbi ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì rẹ?

6 Ṣé o máa ń mú àwọn akéde tó nírìírí lọ síbi ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì rẹ? Tó o bá ń ṣe bẹ́ẹ̀, o lè ní kí wọ́n sọ ohun tí wọ́n kíyè sí nípa bó o ṣe darí ìkẹ́kọ̀ọ́ náà, kí wọ́n sì sọ fún ẹ bóyá o lo Bíbélì bó ṣe yẹ tàbí pé àlàyé ẹ pọ̀ jù. O gbọ́dọ̀ lẹ́mìí ìrẹ̀lẹ̀ kó o tó lè sunwọ̀n sí i. (Fi wé Ìṣe 18:​24-26.) Lẹ́yìn náà, ní kí akéde tó nírìírí náà sọ ohun tó kíyè sí nípa akẹ́kọ̀ọ́ rẹ bóyá ó lóye ohun tó kọ́. O sì lè ní kí akéde yẹn bá ẹ darí ìkẹ́kọ̀ọ́ náà tí o kò bá ní sí nílé fún ọ̀sẹ̀ kan tàbí jù bẹ́ẹ̀ lọ. Ìyẹn ò ní jẹ́ kẹ́ ẹ pa ìkẹ́kọ̀ọ́ náà jẹ, á sì jẹ́ kí akẹ́kọ̀ọ́ náà mọ̀ pé ìkẹ́kọ̀ọ́ òun ṣe pàtàkì. Má ṣe ronú láé pé ìkẹ́kọ̀ọ́ “mi” ni torí náà kò sẹ́ni tó lè bá ẹ darí ẹ̀. Ó ṣe tán, ohun tó o fẹ́ ni pé kí akẹ́kọ̀ọ́ náà tẹ̀ síwájú, ìyẹn ló sì ṣe pàtàkì jù.

FI HÀN PÉ O NÍFẸ̀Ẹ́ OHUN TÓ O FI Ń KỌ́NI Ó SÌ DÁ Ẹ LÓJÚ

Sọ ìrírí àwọn tó nírú ìṣòro tí akẹ́kọ̀ọ́ rẹ ní kóun náà lè mọ bó ṣe lè fi ìlànà Bíbélì sílò (Wo ìpínrọ̀ 7-9) *

7. Kí ló máa mú kí akẹ́kọ̀ọ́ rẹ nífẹ̀ẹ́ ohun tó ń kọ́?

7 Ẹni tó ò ń kọ́ lẹ́kọ̀ọ́ gbọ́dọ̀ rí i pé o nífẹ̀ẹ́ òtítọ́ Bíbélì, ó sì dá ẹ lójú. (1 Tẹs. 1:5) Ìyẹn á mú kí òun náà nífẹ̀ẹ́ ohun tó ń kọ́. Láwọn ìgbà tó bá yẹ bẹ́ẹ̀, jẹ́ kó mọ àwọn àǹfààní tó ò ń rí bó o ṣe ń fàwọn ìlànà Bíbélì sílò nígbèésí ayé ẹ. Ìyẹn á jẹ́ kóun náà rí i pé àwọn ìlànà Bíbélì wúlò, ó sì máa ṣe òun láǹfààní.

8. Kí làwọn nǹkan míì tó o lè fi kún ìkẹ́kọ̀ọ́ yín, kí sì nìdí tó fi yẹ kó o ṣe bẹ́ẹ̀?

8 Tẹ́ ẹ bá ń ṣe ìkẹ́kọ̀ọ́, máa sọ ìrírí àwọn tó nírú ìṣòro tí akẹ́kọ̀ọ́ rẹ ní tí wọ́n sì borí ẹ̀. O lè mú ẹnì kan nínú ìjọ yín tí ìrírí ẹ̀ máa ṣe akẹ́kọ̀ọ́ rẹ láǹfààní lọ sọ́dọ̀ ẹ̀. O sì lè rí àwọn ìrírí táá wọ̀ ọ́ lọ́kàn látinú ọ̀wọ́ àpilẹ̀kọ tá a pè ní “Bíbélì Máa Ń Yí Ìgbésí Ayé Àwọn Èèyàn Pa Dà * lórí ìkànnì jw.org. Àwọn àpilẹ̀kọ àtàwọn fídíò yẹn máa jẹ́ kí akẹ́kọ̀ọ́ rẹ rí bó ṣe bọ́gbọ́n mu tó pé kéèyàn máa fi ìlànà Bíbélì sílò.

9. Báwo lo ṣe lè gba akẹ́kọ̀ọ́ rẹ níyànjú pé kó máa sọ ohun tó ń kọ́ fún tẹbítọ̀rẹ́?

9 Tí akẹ́kọ̀ọ́ rẹ bá ti ṣègbéyàwó, ṣé ọkọ tàbí aya rẹ̀ náà ń kẹ́kọ̀ọ́? Tẹ́ni náà kò bá tíì máa kẹ́kọ̀ọ́, fi ìkẹ́kọ̀ọ́ lọ̀ ọ́. Gba akẹ́kọ̀ọ́ rẹ níyànjú pé kó máa sọ ohun tó ń kọ́ fún tẹbítọ̀rẹ́. (Jòh. 1:​40-45) Báwo lo ṣe lè ṣe bẹ́ẹ̀? O lè bi í pé: “Báwo lo ṣe máa ṣàlàyé kókó yìí fáwọn ará ilé rẹ?” tàbí “Tó o bá ń ṣàlàyé kókó yìí fún ọ̀rẹ́ rẹ, ẹsẹ Ìwé Mímọ́ wo ni wàá tọ́ka sí?” Tó o bá ń ṣe bẹ́ẹ̀, ṣe lò ń kọ́ akẹ́kọ̀ọ́ rẹ kóun náà lè di olùkọ́. Tó bá sì ti kúnjú ìwọ̀n, òun náà lè bẹ̀rẹ̀ sí í wàásù kó sì di akéde tí kò tíì ṣèrìbọmi. O lè bi í bóyá ó mọ ẹnì kan táá nífẹ̀ẹ́ sí ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. Tó bá wà, kàn sí onítọ̀hún lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀ kó o sì bẹ̀rẹ̀ sí í kọ́ ẹni náà lẹ́kọ̀ọ́. Fi fídíò Báwo La Ṣe Máa Ń Ṣe Ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì? * han onítọ̀hún.

GBA AKẸ́KỌ̀Ọ́ RẸ NÍYÀNJÚ PÉ KÓ NÍ ÀWỌN Ọ̀RẸ́ NÍNÚ ÌJỌ

Gba akẹ́kọ̀ọ́ rẹ níyànjú pé kó ní àwọn ọ̀rẹ́ nínú ìjọ (Wo ìpínrọ̀ 10-11) *

10. Báwo ni àwa tá à ń kọ́ni lẹ́kọ̀ọ́ ṣe lè fara wé Pọ́ọ̀lù bó ṣe wà nínú 1 Tẹsalóníkà 2:​7, 8?

10 Àwa tá à ń kọ́ni lẹ́kọ̀ọ́ gbọ́dọ̀ fi hàn pé a nífẹ̀ẹ́ àwọn akẹ́kọ̀ọ́ wa dénú, ọ̀rọ̀ wọn sì jẹ wá lógún. Gbà pé wọ́n ṣì máa di arákùnrin tàbí arábìnrin rẹ. (Ka 1 Tẹsalóníkà 2:​7, 8.) Kò rọrùn fún wọn láti pa àwọn ọ̀rẹ́ tí wọ́n ní tẹ́lẹ̀ tì, kí wọ́n sì ṣe àwọn àyípadà tó yẹ kí wọ́n lè sin Jèhófà. Torí náà, ó yẹ ká ràn wọ́n lọ́wọ́ kí wọ́n lè láwọn ọ̀rẹ́ nínú ìjọ. Mú akẹ́kọ̀ọ́ rẹ lọ́rẹ̀ẹ́, kó o sì máa lọ sọ́dọ̀ ẹ̀ láwọn àkókò míì yàtọ̀ sígbà tẹ́ ẹ̀ ń ṣe ìkẹ́kọ̀ọ́. O lè pè é lórí fóònù, o lè fi àtẹ̀jíṣẹ́ ránṣẹ́ sí i tàbí kó o lọ kí i láwọn ọjọ́ tó yàtọ̀ sí ọjọ́ tẹ́ ẹ máa ń ṣe ìkẹ́kọ̀ọ́. Nípa bẹ́ẹ̀, wàá fi hàn pé o nífẹ̀ẹ́ rẹ̀ lóòótọ́.

11. Kí la fẹ́ káwọn akẹ́kọ̀ọ́ wa rí nínú ìjọ, kí sì nìdí?

11 Wọ́n sábà máa ń sọ pé: “Ẹnì kan ló ń bímọ, igba èèyàn ló ń wò ó.” Torí náà, a lè sọ pé: “Gbogbo ìjọ ló ń sọ ẹnì kan di ọmọ ẹ̀yìn.” Ìdí nìyẹn táwọn tó nírìírí fi máa ń fojú akẹ́kọ̀ọ́ wọn mọ àwọn tó lè mú kó tẹ̀ síwájú nínú ìjọ. Ìyẹn á mú kó ní àwọn ọ̀rẹ́ tó dáa láàárín àwa èèyàn Jèhófà, wọ́n á lè fún un níṣìírí, wọ́n á sì lè ràn án lọ́wọ́ tó bá níṣòro. A fẹ́ kí ọkàn akẹ́kọ̀ọ́ wa balẹ̀ nínú ìjọ kó sì mọ̀ pé apá kan ìjọ lòun náà. A fẹ́ kó mọ̀ pé àwọn ará lọ́kùnrin àti lóbìnrin nífẹ̀ẹ́ òun, kí òun náà sì nífẹ̀ẹ́ wọn. Ìgbà yẹn ló máa rọrùn fún un láti pa àwọn ọ̀rẹ́ ayé tó ní tẹ́lẹ̀ tì. (Òwe 13:20) Táwọn yẹn bá sì ń fojú burúkú wò ó, ọkàn ẹ̀ á balẹ̀ pé òun láwọn ọ̀rẹ́ nínú ìjọ.​—Máàkù 10:​29, 30; 1 Pét. 4:4.

JẸ́ KÓ MỌ̀ PÉ Ó ṢE PÀTÀKÌ KÓUN ṢE ÌYÀSÍMÍMỌ́ ÀTI ÌRÌBỌMI

Tí akẹ́kọ̀ọ́ kan bá gbé àwọn ìgbésẹ̀ tó yẹ, á ṣèrìbọmi! (Wo ìpínrọ̀ 12-13)

12. Kí nìdí tó fi yẹ ká bá akẹ́kọ̀ọ́ wa sọ̀rọ̀ nípa ìyàsímímọ́ àti ìrìbọmi?

12 Gbogbo ìgbà ni kó o máa sọ fún akẹ́kọ̀ọ́ rẹ pé ó ṣe pàtàkì pé kó ya ara ẹ̀ sí mímọ́ fún Jèhófà, kó sì ṣèrìbọmi. Ó ṣe tán, ìdí tá a fi ń kọ́ àwọn èèyàn lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì ni pé kí wọ́n ṣèrìbọmi, kí wọ́n sì di ọmọ ẹ̀yìn Jésù. Tó bá ti tó oṣù mélòó kan tá a ti ń kọ́ ẹnì kan lẹ́kọ̀ọ́, tí ìkẹ́kọ̀ọ́ ẹ̀ sì ń lọ déédéé, bóyá tó tiẹ̀ ti ń wá sípàdé, ó yẹ ká sọ fún un pé ìdí tá a fi ń kọ́ ọ lẹ́kọ̀ọ́ ni pé a fẹ́ kó di ọ̀kan lára àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà.

13. Àwọn ìgbésẹ̀ wo ni akẹ́kọ̀ọ́ kan máa gbé títí táá fi ṣèrìbọmi?

13 Àwọn ìgbésẹ̀ kan wà tí akẹ́kọ̀ọ́ kan máa gbé títí táá fi ṣèrìbọmi. Àkọ́kọ́, ó gbọ́dọ̀ mọ Jèhófà, kó nífẹ̀ẹ́ rẹ̀, kó sì nígbàgbọ́ nínú rẹ̀. (Jòh. 3:16; 17:3) Lẹ́yìn náà, á ní àjọṣe tó dáa pẹ̀lú Jèhófà, á sì di ọ̀rẹ́ pẹ̀lú àwọn ará nínú ìjọ. (Héb. 10:​24, 25; Jém. 4:8) Bọ́jọ́ ṣe ń gorí ọjọ́, akẹ́kọ̀ọ́ náà á pa àwọn ìwà rẹ̀ àtijọ́ tì, á sì ronú pìwà dà àwọn ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀. (Ìṣe 3:19) Bákan náà, ìgbàgbọ́ tó ní á mú kó máa sọ ohun tó ń kọ́ fáwọn míì. (2 Kọ́r. 4:13) Lẹ́yìn ìyẹn, á yara ẹ̀ sí mímọ́ fún Jèhófà, á sì ṣèrìbọmi. (1 Pét. 3:21; 4:2) Ẹ wo bí inú gbogbo ìjọ ṣe máa dùn lọ́jọ́ tó bá ṣèrìbọmi! Bí akẹ́kọ̀ọ́ náà ṣe ń gbé ìgbésẹ̀ kan tẹ̀ lé òmíì, máa gbóríyìn fún un, kó o sì máa fún un níṣìírí kó lè máa tẹ̀ síwájú.

MÁA KÍYÈ SÍ I LÁTÌGBÀDÉGBÀ BÓYÁ AKẸ́KỌ̀Ọ́ RẸ Ń TẸ̀ SÍWÁJÚ

14. Ìbéèrè wo ló yẹ kí akéde kan bi ara ẹ̀ tó bá fẹ́ mọ̀ bóyá akẹ́kọ̀ọ́ òun ń tẹ̀ síwájú?

14 Ó yẹ ká mú sùúrù bá a ṣe ń ran akẹ́kọ̀ọ́ wa lọ́wọ́ láti tẹ̀ síwájú títí táá fi yara ẹ̀ sí mímọ́ táá sì ṣèrìbọmi. Àmọ́ ó tún yẹ ká mọ̀ bóyá ó fẹ́ sin Jèhófà lóòótọ́. Ǹjẹ́ o rí ẹ̀rí tó fi hàn pé ó ń pa àṣẹ Jésù mọ́? Àbí ṣe ló kàn fẹ́ ní ìmọ̀ Bíbélì?

15. Àwọn nǹkan wo ló máa jẹ́ kí akéde mọ̀ bóyá akẹ́kọ̀ọ́ òun ń tẹ̀ síwájú?

15 Máa fiyè sí àwọn ohun tó fi hàn pé akẹ́kọ̀ọ́ rẹ ń tẹ̀ síwájú. Bí àpẹẹrẹ, ṣé ó máa ń sọ bóun ṣe nífẹ̀ẹ́ Jèhófà tó? Ṣé ó máa ń gbàdúrà sí Jèhófà? (Sm. 116:​1, 2) Ṣé ó máa ń ka Bíbélì déédéé? (Sm. 119:97) Ṣé ó máa ń wá sípàdé déédéé? (Sm. 22:22) Ṣé ó ti ṣe àwọn àyípadà tó yẹ? (Sm. 119:112) Ṣé ó ti ń sọ àwọn nǹkan tó ń kọ́ fún tẹbítọ̀rẹ́? (Sm. 9:1) Ju gbogbo ẹ̀ lọ, ṣé ó wù ú láti di Ẹlẹ́rìí Jèhófà? (Sm. 40:8) Tí akẹ́kọ̀ọ́ náà kò bá tíì ṣe èyíkéyìí nínú ohun tá a sọ yìí, bá a sọ ọ́ tìfẹ́tìfẹ́, síbẹ̀ rí i pé o sọ ojú abẹ níkòó. *

16. Kí lá fi hàn pé ó yẹ kó o dá ìkẹ́kọ̀ọ́ kan dúró?

16 Máa kíyè sí i látìgbàdégbà bóyá ó ṣì yẹ kó o máa bá ìkẹ́kọ̀ọ́ ẹnì kan lọ. Bi ara ẹ pé: ‘Ṣé kì í múra ìkẹ́kọ̀ọ́ ẹ̀ sílẹ̀? Ṣé kò tíì bẹ̀rẹ̀ sí í wá sípàdé? Ṣé ó ṣì ń hùwà tí kò dáa? Ṣé ó ṣì wà nínú ẹ̀sìn tó ń ṣe?’ Tó bá jẹ́ bẹ́ẹ̀ ni, tá a bá ń bá ìkẹ́kọ̀ọ́ náà lọ, ṣe ló máa dà bí ìgbà tá a fẹ́ kọ́ ẹnì kan ní ìwẹ̀ àmọ́ tí kò fẹ́ kí omi kan òun lára. Tí akẹ́kọ̀ọ́ náà kò bá mọyì ohun tó ń kọ́, tí kò sì ṣe tán láti yí pa dà, ṣé ó tún yẹ kó o máa bá ìkẹ́kọ̀ọ́ rẹ̀ lọ?

17. Kí ni 1 Tímótì 4:16 sọ tó yẹ káwa tá à ń kọ́ni lẹ́kọ̀ọ́ máa ṣe?

17 Ọwọ́ gidi la fi mú iṣẹ́ sísọni dọmọ ẹ̀yìn, a sì fẹ́ káwọn akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì wa ṣèrìbọmi. Ìdí nìyẹn tó fi yẹ ká máa fi Bíbélì kọ́ni, ká fi hàn pé a nífẹ̀ẹ́ ohun tá a fi ń kọ́ni ó sì dá wa lójú. Yàtọ̀ síyẹn, a máa gba akẹ́kọ̀ọ́ wa níyànjú pé kó láwọn ọ̀rẹ́ nínú ìjọ. Bákan náà, a máa jẹ́ kó mọ̀ pé ó ṣe pàtàkì kóun ṣe ìyàsímímọ́ àti ìrìbọmi, àá sì máa kíyè sí i látìgbàdégbà bóyá ó ń tẹ̀ síwájú. (Tún wo àpótí náà “ Ohun Tó Yẹ Káwa Akéde Ṣe Kí Àwọn Akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì Wa Lè Ṣèrìbọmi”.) Inú wa dùn pé à ń kópa nínú iṣẹ́ ìgbẹ̀mílà yìí. Torí náà, ẹ jẹ́ ká ṣe gbogbo ohun tá a lè ṣe láti máa kọ́ àwọn akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì wa lọ́nà táá mú kí wọ́n tẹ̀ síwájú kí wọ́n sì ṣèrìbọmi.

ORIN 79 Kọ́ Wọn Kí Wọ́n Lè Dúró Gbọn-in

^ ìpínrọ̀ 5 Àǹfààní ńlá la ní tá a bá ń kọ́ àwọn èèyàn lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì torí pé ṣe là ń jẹ́ kí wọ́n mọ bí Jèhófà ṣe fẹ́ kí wọ́n máa ronú àti bó ṣe yẹ kí wọ́n máa hùwà. Nínú àpilẹ̀kọ yìí, a máa rí bá a ṣe lè sunwọ̀n sí i nínú bá a ṣe ń kọ́ni.

^ ìpínrọ̀ 4 Wo àpilẹ̀kọ náà, “Àwọn Nǹkan Tó Yẹ Kó O Yẹra Fún Tó O Bá Ń Darí Ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì” nínú Ìwé Ìpàdé Ìgbésí Ayé àti Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ ti September 2016.

^ ìpínrọ̀ 8 Lọ sí NÍPA WA > ÌRÍRÍ.

^ ìpínrọ̀ 9JW Library®, lọ sí MEDIA > OUR MEETINGS AND MINISTRY > TOOLS FOR THE MINISTRY.

^ ìpínrọ̀ 77 ÀWÒRÁN: Lẹ́yìn tí wọ́n kúrò lọ́dọ̀ akẹ́kọ̀ọ́ kan, arábìnrin tó nírìírí bá ẹni tó darí ìkẹ́kọ̀ọ́ náà sọ̀rọ̀ nípa bí kò ṣe ní máa sọ̀rọ̀ jù nígbà ìkẹ́kọ̀ọ́.

^ ìpínrọ̀ 79 ÀWÒRÁN: Akẹ́kọ̀ọ́ yẹn kọ́ ohun tó yẹ kí ìyàwó tó dáa máa ṣe. Nígbà tó yá, ó sọ ohun tó kọ́ fún ọkọ ẹ̀.

^ ìpínrọ̀ 81 ÀWÒRÁN: Ọ̀kan lára àwọn ará tí akẹ́kọ̀ọ́ yẹn rí nípàdé pe òun àti ọkọ ẹ̀ wá sílé wọn.