Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Onésime àti Géraldine

Òjò Ìbùkún Rọ̀ Sórí Àwọn Tó Pa Dà sí Ìlú Ìbílẹ̀ Wọn

Òjò Ìbùkún Rọ̀ Sórí Àwọn Tó Pa Dà sí Ìlú Ìbílẹ̀ Wọn

ÀWỌN ará wa kan lọ́kùnrin àti lóbìnrin tí wọ́n ti fìgbà kan rí ṣí lọ sí ìlú òyìnbó ti kó pa dà sí ìlú ìbílẹ̀ wọn. Ìfẹ́ tí wọ́n ní fún Jèhófà àtàwọn èèyàn ti mú kí wọ́n kó lọ sí àwọn agbègbè tí àìní gbé pọ̀. (Mát. 22:​37-39) Àwọn nǹkan wo ni wọ́n yááfì, àwọn ìbùkún wo sì ni wọ́n rí? Ẹ jẹ́ ká wo àpẹẹrẹ àwọn tó ṣe bẹ́ẹ̀ lórílẹ̀-èdè Kamẹrúùnù.

“MO WÀ NÍBI TÍ MO TI LÈ RÍ ‘ẸJA’ PA”

Lọ́dún 1998, arákùnrin kan tó ń jẹ́ Onésime kó kúrò ní Kamẹrúùnù tó jẹ́ ìlú ìbílẹ̀ rẹ̀ lọ sí ìlú òyìnbó, ó sì gbébẹ̀ fún ọdún mẹ́rìnlá (14). Ìpàdé ló wà lọ́jọ́ kan tí olùbánisọ̀rọ̀ kan lo àpèjúwe nípa iṣẹ́ ìwàásù tá à ń ṣe. Olùbánisọ̀rọ̀ náà sọ pé, “Tí ọ̀rẹ́ méjì bá ń pa ẹja níbi ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀, tí ọ̀kan sì ń pa ẹja ju ìkejì lọ, ṣé ìkejì yẹn kò ní lọ síbi tí ẹni àkọ́kọ́ wà kóun náà lè rí ẹja tó pọ̀ pa?”

Àpèjúwe yẹn ló mú kí Onésime bẹ̀rẹ̀ sí í ronú pé á dáa kóun pa dà sí Kamẹrúùnù níbi tí àwọn akéde ti ń rí ẹja tó pọ̀ pa nípa tẹ̀mí. Àmọ́, ó tún ronú pé ṣé òun á lè gbé ní Kamẹrúùnù lẹ́yìn ọ̀pọ̀ ọdún tóun ti lò nílùú òyìnbó? Kó lè mọ̀ bóyá á ṣeé ṣe, ó lọ lo oṣù mẹ́fà ní Kamẹrúùnù. Nígbà tó sì di ọdún 2012, ó kó pa dà sílé pátápátá.

Onésime sọ pé: “Ibí máa ń gbóná gan-an, nǹkan ò sì rọrùn. Àmọ́ díẹ̀díẹ̀, ara mi mọlé. Nígbà tí mo wà nílùú òyìnbó, orí àga tìmùtìmù la máa ń jókòó ní Gbọ̀ngàn Ìjọba, àmọ́ nígbà tí mo débí, orí bẹ́ǹṣì lásán la máa ń jókòó. Bó ti wù kó rí, bí mo ṣe túbọ̀ ń pọkàn pọ̀ nípàdé, bẹ́ẹ̀ ni mi ò rí ti ọ̀rọ̀ ìjókòó rò mọ́.”

Lọ́dún 2013, Onésime fẹ́ Géraldine, tóun náà pa dà sí Kamẹrúùnù lẹ́yìn tó ti lo ọdún mẹ́sàn-án lórílẹ̀-èdè Faransé. Torí pé iṣẹ́ ìsìn Jèhófà ni tọkọtaya yìí gbájú mọ́, ìbùkún wo ni wọ́n rí? Onésime sọ pé: “A lọ sí Ilé Ẹ̀kọ́ Àwọn Ajíhìnrere, a sì sìn ní Bẹ́tẹ́lì. Lọ́dún tó kọjá, àwọn akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì tó jẹ́ ogún (20) ló ṣèrìbọmi níjọ wa. Mo gbà pé ìsinsìnyí gan-an ni mo wà níbi tí mo ti lè rí ‘ẹja’ pa.” (Máàkù 1:​17, 18) Géraldine fi kún un pé: “Jèhófà ti bù kún wa kọjá ohun tá a lérò.”

WỌ́N LÁYỌ̀ TORÍ WỌ́N RÍ ÀWỌN ỌMỌ TẸ̀MÍ

Judith àti Sam-Castel

Orílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà ni Judith ṣí lọ ní tiẹ̀, àmọ́ ó wù ú pé kóun náà lè ṣe púpọ̀ sí i lẹ́nu iṣẹ́ ìwàásù. Ó sọ pé, “Ní gbogbo ìgbà tí mo bá ṣèbẹ̀wò sí ìdílé mi ní Kamẹrúùnù, ṣe ni mo máa ń sunkún nígbà tí mo bá ń pa dà torí pé ọ̀pọ̀ àwọn tó nífẹ̀ẹ́ sí òtítọ́ tí mo ti bá pàdé ni màá tún fi sílẹ̀.” Síbẹ̀, kò rọrùn fún Judith láti pa dà sí Kamẹrúùnù torí pé ó níṣẹ́ tó ń mówó gidi wọlé fún un, ìyẹn sì mú kó lè máa tọ́jú bàbá rẹ̀ tó ń ṣàìsàn ní Kamẹrúùnù. Àmọ́ ó gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà, ó sì pa dà sí Kamẹrúùnù. Ó sọ pé ọkàn òun ṣì máa ń fà sáwọn nǹkan tóun ń gbádùn nílùú òyìnbó. Torí náà, ó gbàdúrà sí Jèhófà pé kó ran òun lọ́wọ́ kára òun lè mọlé, alábòójútó àyíká kan àtìyàwó rẹ̀ sì tún fún un níṣìírí.

Nígbà tí Judith ronú nípa àwọn ìbùkún tó ti rí, ó sọ pé, “Inú mi dùn pé, láàárín ọdún mẹ́ta péré, mo ní àwọn ọmọ tẹ̀mí mẹ́rin.” Nígbà tó yá, Judith di aṣáájú-ọ̀nà àkànṣe. Ní báyìí, ó ń sìn pẹ̀lú ọkọ rẹ̀ Sam-Castel, tó jẹ́ alábòójútó àyíká. Kí ló wá ṣẹlẹ̀ sí bàbá Judith tó ń ṣàìsàn? Wọ́n rí ilé ìwòsàn kan lókè òkun tó gbà láti sanwó iṣẹ́ abẹ tí wọ́n fẹ́ ṣe fún bàbá rẹ̀. Inú wọn sì dùn pé iṣẹ́ abẹ náà yọrí sí rere.

WỌ́N RỌ́WỌ́ JÈHÓFÀ LÁYÉ WỌN

Caroline àti Victor

Orílẹ̀-èdè Kánádà ni arákùnrin kan tó ń jẹ́ Victor ṣí lọ. Àmọ́ nígbà tó ka àpilẹ̀kọ kan nínú Ilé Ìṣọ́ tó sọ̀rọ̀ nípa lílọ sí yunifásítì, ó tún èrò ẹ̀ pa. Ó fi yunifásítì tó wà sílẹ̀, ó sì lọ sí ilé ìwé tí wọ́n ti ń kọ́ iṣẹ́ ọwọ́, èyí tí kì í gba àkókò púpọ̀. Victor sọ pé: “Ìyẹn jẹ́ kí n tètè ríṣẹ́, ó sì jẹ́ kí n lè ṣe iṣẹ́ aṣáájú-ọ̀nà tó ti ń wù mí tipẹ́tipẹ́.” Nígbà tó yá, Victor fẹ́ Caroline, àwọn méjèèjì sì ṣèbẹ̀wò sí Kamẹrúùnù. Nígbà tí wọ́n ṣèbẹ̀wò sí ẹ̀ka ọ́fíìsì tó wà níbẹ̀, àwọn kan rọ̀ wọ́n pé á dáa tí wọ́n bá lè wá sìn ní Kamẹrúùnù. Victor sọ pé, “A ò rídìí tá ò fi lè lọ, ó ṣe tán, a ti jẹ́ kí ohun ìní díẹ̀ tẹ́ wa lọ́rùn tẹ́lẹ̀. Torí náà, a kọ̀wé pé a máa wá.” Bó tiẹ̀ jẹ́ pé Caroline ìyàwó rẹ̀ ní àwọn àìlera kan, wọ́n pinnu pé àwọn máa lọ, wọ́n sì ṣe bẹ́ẹ̀.

Victor àti Caroline bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ aṣáájú-ọ̀nà déédéé, kí wọ́n lè ran ọ̀pọ̀ èèyàn lọ́wọ́ láti kẹ́kọ̀ọ́ òtítọ́. Fáwọn àkókò kan, owó tí wọ́n tọ́jú pa mọ́ ni wọ́n fi ń bójú tó ara wọn. Àmọ́ nígbà tó yá, wọ́n lọ ṣiṣẹ́ ní Kánádà fún oṣù díẹ̀, ìyẹn sì jẹ́ kí wọ́n lè máa bá iṣẹ́ aṣáájú-ọ̀nà wọn lọ ní Kamẹrúùnù. Àwọn ìbùkún wo ni wọ́n rí? Wọ́n lọ sí Ilé Ẹ̀kọ́ Àwọn Ajíhìnrere Ìjọba Ọlọ́run, wọ́n di aṣáájú-ọ̀nà àkànṣe, ní báyìí, wọ́n wà lára àwọn tó ń kọ́ ilé ètò Ọlọ́run. Victor sọ pé: “Torí pé a fi ibi tí nǹkan ti dẹrùn fún wa sílẹ̀, ìyẹn jẹ́ ká túbọ̀ rọ́wọ́ Jèhófà láyé wa.”

WỌ́N Ń LÁYỌ̀ BÍ WỌ́N ṢE Ń RAN ÀWỌN ÈÈYÀN LỌ́WỌ́ LÁTI YA ARA WỌN SÍ MÍMỌ́ FÚN JÈHÓFÀ

Stéphanie àti Alain

Lọ́dún 2002, Alain, tó ń lọ sí yunifásítì kan lórílẹ̀-èdè Jámánì ka ìwé àṣàrò kúkúrú wa kan tá a pè ní Ẹ̀yin Ọ̀dọ́​—Kí Lẹ Máa Fi Ìgbésí Ayé Yín Ṣe? Ohun tó kà nínú ìwé yìí mú kó pinnu pé òun á fayé òun sin Jèhófà. Torí náà, lọ́dún 2006, ó lọ sí Ilé Ẹ̀kọ́ Iṣẹ́ Òjíṣẹ́, lẹ́yìn náà wọ́n rán an lọ sí Kamẹrúùnù tó jẹ́ ìlú ìbílẹ̀ rẹ̀.

Nígbà tí Alain dé Kamẹrúùnù, ó rí iṣẹ́ kan tó fún un láyè láti máa jáde òde ẹ̀rí dáadáa. Nígbà tó yá, ó ríṣẹ́ míì tó máa mówó gidi wọlé, àmọ́ iṣẹ́ náà kò jẹ́ kó ráyè òde ẹ̀rí bíi ti tẹ́lẹ̀ mọ́. Kò pẹ́ sígbà yẹn ni wọ́n sọ ọ́ di aṣáájú-ọ̀nà àkànṣe, inú ẹ̀ sì dùn gan-an. Ọ̀gá rẹ̀ sọ pé òun máa fi kún owó oṣù rẹ̀, àmọ́ Alain dúró lórí ìpinnu tó ti ṣe. Nígbà tó yá, Alain fẹ́ Stéphanie, tó ti lo ọ̀pọ̀ ọdún lórílẹ̀-èdè Faransé. Àwọn ìṣòro wo ni Stéphanie ní nígbà tó pa dà sí Kamẹrúùnù?

Stéphanie sọ pé: “Mo ní àwọn àìlera pẹ́ẹ́pẹ̀ẹ̀pẹ́ mélòó kan, àwọn nǹkan kan sì wà tí kò bá mi lára mu. Àmọ́ mo rí ìtọ́jú gbà, ara mi sì balẹ̀.” Jèhófà bù kún tọkọtaya yìí nítorí pé wọ́n fara dà á. Alain sọ pé: “Nígbà tá a lọ wàásù ní Katé, ìyẹn abúlé kan tó jìnnà sígboro gan-an, a rí ọ̀pọ̀ èèyàn tó fẹ́ kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. Nígbà tó yá, a bẹ̀rẹ̀ sí í darí ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì wọn látorí fóònù. Méjì lára àwọn akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì yẹn ti ṣèrìbọmi, kódà àwùjọ kan ti wà níbẹ̀ báyìí.” Stéphanie sọ pé: “Kò sóhun míì tó lè fúnni láyọ̀ bíi kéèyàn ran ẹnì kan lọ́wọ́ láti ya ara ẹ̀ sí mímọ́ fún Jèhófà. Ọ̀pọ̀ ìgbà la ti nírú ayọ̀ yìí torí pé a wá sìn níbí.” Ní báyìí, Alain àti Stéphanie ti di alábòójútó àyíká.

“OHUN TÓ YẸ KÁ ṢE GAN-AN LA ṢE”

Léonce àti Gisèle

Ilé ẹ̀kọ́ ìṣègùn lórílẹ̀-èdè Ítálì ni Gisèle wà nígbà tó ṣèrìbọmi. Ohun tó wú Gisèle lórí ni pé tọkọtaya aṣáájú-ọ̀nà tó ń kọ́ ọ lẹ́kọ̀ọ́ jẹ́ kí ohun díẹ̀ tẹ́ wọn lọ́rùn, ìyẹn sì mú kí Gisèle náà pinnu pé òun á ṣe púpọ̀ sí i lẹ́nu iṣẹ́ ìwàásù. Ló bá bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ aṣáájú-ọ̀nà déédéé bó tiẹ̀ jẹ́ pé ó ṣì wà nílé ẹ̀kọ́.

Ó wu Gisèle pé kó pa dà sí Kamẹrúùnù kó lè sìn níbi tí àìní gbé pọ̀. Àmọ́ ìpinnu yẹn ò rọrùn fún un. Ó sọ pé: “Tí n bá lọ, màá pàdánù ìwé àṣẹ tí mo ní láti gbé lórílẹ̀-èdè Ítálì, màá sì jìnnà sí àwọn ọ̀rẹ́ mi àti ẹbí mi tó ń gbé níbẹ̀.” Láìfi ìyẹn pè, Gisèle pa dà sí Kamẹrúùnù ní May 2016. Nígbà tó yá, ó fẹ́ Léonce, ẹ̀ka ọ́fíìsì tó wà lórílẹ̀-èdè Kamẹrúùnù sì ní kí wọ́n lọ máa sìn ní ìlú kan tó ń jẹ́ Ayos, níbi tí àìní gbé pọ̀.

Báwo ni nǹkan ṣe rí ní Ayos? Gisèle sọ pé: “Ọ̀pọ̀ ìgbà ni wọn kì í fún wa ní iná fún ọ̀pọ̀ ọ̀sẹ̀, torí náà, kì í sí iná lórí fóònù wa. Mo kọ́ béèyàn ṣe ń dáná igi, yàtọ̀ síyẹn, a máa ń lọ sódò lọ pọnmi lálẹ́ torí pé kì í sí èrò, àá wá kó o sínú kẹ̀kẹ́ akẹ́rù, ìyẹn wheelbarrow, àá sì lo iná tọ́ọ̀ṣì láti fi ríran.” Kí ló jẹ́ kí tọkọtaya yìí lè fara dà á? Gisèle sọ pé: “Ẹ̀mí Jèhófà ràn wá lọ́wọ́ gan-an, èmi àti ọkọ mi sì máa ń fún ara wa níṣìírí. Yàtọ̀ síyẹn, àwọn ẹbí àtàwọn ọ̀rẹ́ wa máa ń fún wa níṣìírí, wọ́n sì máa ń fowó ránṣẹ́ sí wa lẹ́ẹ̀kọ̀ọ̀kan.”

Ṣé inú Gisèle dùn pé òun pa dà sí ìlú ìbílẹ̀ òun? Ó sọ pé, “Gbogbo ẹnu ni mo fi dáhùn pé bẹ́ẹ̀ ni! Lóòótọ́, a láwọn ìṣòro kan níbẹ̀rẹ̀, ìrẹ̀wẹ̀sì sì fẹ́ mú wa, àmọ́ lẹ́yìn tá a borí àwọn nǹkan yìí, inú èmi àti ọkọ mi dùn pé ohun tó yẹ ká ṣe gan-an la ṣe. A gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà, ìyẹn sì mú ká túbọ̀ sún mọ́ ọn.” Nígbà tó yá, Léonce àti Gisèle lọ sí Ilé Ẹ̀kọ́ Àwọn Ajíhìnrere Ìjọba Ọlọ́run. Ní báyìí, wọ́n ti di aṣáájú-ọ̀nà àkànṣe onígbà kúkúrú.

Bíi tàwọn apẹja tó máa ń fìgboyà lọ síbi tí nǹkan ò ti rọrùn kí wọ́n lè rẹ́ja púpọ̀ pa, bẹ́ẹ̀ lọ̀rọ̀ àwọn tó yááfì ọ̀pọ̀ nǹkan, tí wọ́n sì pa dà sí ìlú ìbílẹ̀ wọn torí kí wọ́n lè ran àwọn olóòótọ́ ọkàn lọ́wọ́ láti kẹ́kọ̀ọ́ òtítọ́. Kò sí àní-àní pé Jèhófà máa rántí iṣẹ́ ribiribi táwọn akéde yìí ṣe àti ìfẹ́ tí wọ́n fi hàn fún orúkọ rẹ̀, ó sì máa san wọ́n lẹ́san. (Neh. 5:19; Héb. 6:10) Tó o bá ń gbé ní òkè òkun tó o sì gbọ́ pé àìní wà ní ìlú ìbílẹ̀ rẹ, ṣé wàá lè pa dà? Tó o bá ṣe bẹ́ẹ̀, Jèhófà á rọ̀jò ìbùkún lé ìwọ náà lórí.​—Òwe 10:22.