Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

ÀPILẸ̀KỌ FÚN ÌKẸ́KỌ̀Ọ́ 47

Ṣé Wàá Máa Ṣe Ìyípadà Tó Yẹ?

Ṣé Wàá Máa Ṣe Ìyípadà Tó Yẹ?

“Tóò, ẹ̀yin ará, ẹ máa yọ̀, ẹ máa ṣe ìyípadà.”​—2 KỌ́R. 13:11.

ORIN 54 “Èyí Ni Ọ̀nà”

OHUN TÁ A MÁA JÍRÒRÒ *

1. Bó ṣe wà nínú Mátíù 7:​13, 14, kí nìdí tá a fi lè sọ pé a wà lẹ́nu ìrìn àjò?

GBOGBO wa pátá là ń rìnrìn àjò. Ibo là ń lọ? À ń lọ sínú ayé tuntun níbi tá a ti máa wà lábẹ́ àkóso Jèhófà. Ojoojúmọ́ là ń sapá láti máa rìn ní ọ̀nà tó lọ sí ìyè. Àmọ́ bí Jésù ti sọ, ojú ọ̀nà yẹn há, ó sì ṣòro rìn. (Ka Mátíù 7:​13, 14.) Torí pé a jẹ́ aláìpé, ó rọrùn gan-an ká ṣìnà kúrò lójú ọ̀nà yẹn.​—Gál. 6:1.

2. Kí la máa jíròrò nínú àpilẹ̀kọ yìí? (Wo àpótí náà “ Ẹ̀mí Ìrẹ̀lẹ̀ Ló Máa Jẹ́ Ká Lè Ṣe Àwọn Ìyípadà Tó Yẹ.”)

2 Tá ò bá fẹ́ kúrò lójú ọ̀nà tó lọ sí ìyè, a gbọ́dọ̀ ṣe tán láti ṣe àwọn ìyípadà tó yẹ nínú bá a ṣe ń ronú, bá a ṣe ń sọ̀rọ̀ àti nínú ìwà wa. Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù gba àwọn Kristẹni tó wà ní Kọ́ríńtì níyànjú pé, “ẹ máa ṣe ìyípadà” tó yẹ. (2 Kọ́r. 13:11) Ìmọ̀ràn yẹn wúlò fún àwa náà lónìí. Torí náà, nínú àpilẹ̀kọ yìí, a máa jíròrò bí Bíbélì ṣe lè ràn wá lọ́wọ́ láti ṣe àwọn àtúnṣe tó yẹ àti bí àwọn ọ̀rẹ́ tí òtítọ́ jinlẹ̀ nínú wọn ṣe lè ràn wá lọ́wọ́ ká lè máa rìn nìṣó lójú ọ̀nà tó lọ sí ìyè. Bákan náà, a máa jíròrò ohun tó lè mú kó ṣòro fún wa láti tẹ̀ lé ìtọ́ni ètò Ọlọ́run. Paríparí ẹ̀, a máa rí bí ẹ̀mí ìrẹ̀lẹ̀ ṣe lè ràn wá lọ́wọ́ láti ṣe àwọn ìyípadà tó yẹ ká má sì rẹ̀wẹ̀sì lẹ́nu iṣẹ́ ìsìn Jèhófà.

JẸ́ KÍ Ọ̀RỌ̀ ỌLỌ́RUN TỌ́ Ẹ SỌ́NÀ

3. Kí ni Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run lè ṣe fún ẹ?

3 Kì í rọrùn fún wa láti mọ irú ẹni tá a jẹ́ nínú, ìdí sì ni pé ọkàn wa máa ń tàn wá jẹ. Ó sì lè mú kó ṣòro fún wa láti mọ ìgbésẹ̀ tó yẹ ká gbé. (Jer. 17:9) Ó rọrùn gan-an láti fi “èrò èké” tan ara wa jẹ. (Jém. 1:22) Torí náà, a gbọ́dọ̀ máa fi Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run yẹ ara wa wò. Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run máa ń jẹ́ ká mọ irú ẹni tá a jẹ́ nínú, ó sì máa ń jẹ́ ká mọ “ìrònú àti ohun tí ọkàn [wa] ń gbèrò.” (Héb. 4:​12, 13) Ṣe ni Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run dà bí ẹ̀rọ tí wọ́n fi máa ń ṣàyẹ̀wò inú ara lọ́hùn-ún torí ó máa ń jẹ́ ká mọ irú ẹni tá a jẹ́ nínú gan-an. Àmọ́, ká tó lè jàǹfààní látinú ìmọ̀ràn Bíbélì àti ìmọ̀ràn táwọn aṣojú Ọlọ́run fún wa, a gbọ́dọ̀ lẹ́mìí ìrẹ̀lẹ̀.

4. Kí ló jẹ́ ká mọ̀ pé Ọba Sọ́ọ̀lù di agbéraga?

4 Àpẹẹrẹ Ọba Sọ́ọ̀lù jẹ́ ká mọ ohun tó lè ṣẹlẹ̀ téèyàn ò bá lẹ́mìí ìrẹ̀lẹ̀. Ìgbéraga wọ Sọ́ọ̀lù lẹ́wù débi pé kò gbà pé ó yẹ kóun yí èrò àti ìwà òun pa dà. (Sm. 36:​1, 2; Háb. 2:4) Èyí ṣe kedere nígbà tí Jèhófà fún Sọ́ọ̀lù ní ìtọ́ni pàtó nípa ohun tó máa ṣe lẹ́yìn tó bá ṣẹ́gun àwọn ọmọ Ámálékì. Àmọ́ Sọ́ọ̀lù ò ṣègbọràn sí Jèhófà. Kódà, Sọ́ọ̀lù ò gbà pé òun jẹ̀bi nígbà tí wòlíì Sámúẹ́lì kò ó lójú lórí ọ̀rọ̀ náà. Kàkà bẹ́ẹ̀, ṣe ló ń wí àwíjàre pé ohun tóun ṣe ò fi bẹ́ẹ̀ burú, ó sì tún di ẹ̀bi ru àwọn míì. (1 Sám. 15:​13-24) Kẹ́ ẹ sì máa wò ó, kì í ṣèyẹn nìgbà àkọ́kọ́ tí Sọ́ọ̀lù máa ṣe bẹ́ẹ̀. (1 Sám. 13:​10-14) Ó dunni pé Sọ́ọ̀lù jẹ́ kí ìgbéraga wọ òun lẹ́wù. Torí pé kò tún èrò ẹ̀ ṣe, Jèhófà bá a wí, ó sì kọ̀ ọ́ sílẹ̀.

5. Kí la rí kọ́ látinú àpẹẹrẹ Sọ́ọ̀lù?

5 Ká má bàa dà bíi Sọ́ọ̀lù, ó yẹ ká bi ara wa láwọn ìbéèrè yìí: ‘Tí mo bá rí ìmọ̀ràn tó yẹ kí n fi sílò nínú Ìwé Mímọ́, ṣé mo máa ń ṣàwáwí? Ṣé mo máa ń fojú kéré ìwà àìtọ́ tí mo hù? Ṣé mo máa ń di ẹ̀bi ohun tí mo ṣe ru àwọn míì?’ Tí ìdáhùn wa sí èyíkéyìí lára àwọn ìbéèrè yẹn bá jẹ́ bẹ́ẹ̀ ni, a jẹ́ pé a gbọ́dọ̀ ṣàtúnṣe sí èrò àti ìwà wa. Àìjẹ́ bẹ́ẹ̀, ìgbéraga máa wọ̀ wá lẹ́wù, ìyẹn á sì mú kí Jèhófà kọ̀ wá lọ́rẹ̀ẹ́.​—Jém. 4:6.

6. Sọ ìyàtọ̀ tó wà láàárín Ọba Sọ́ọ̀lù àti Ọba Dáfídì.

6 Ìyàtọ̀ gbọ̀ọ̀rọ̀gbọọrọ ló wà láàárín Ọba Sọ́ọ̀lù àti Dáfídì tó rọ́pò rẹ̀ torí pé “òfin Jèhófà” máa ń mú inú Dáfídì dùn ní tiẹ̀. (Sm. 1:​1-3) Bákan náà, Dáfídì mọ̀ pé Jèhófà máa ń gba àwọn onírẹ̀lẹ̀ là àmọ́ ó kórìíra àwọn agbéraga. (2 Sám. 22:28) Torí náà, Dáfídì jẹ́ kí òfin Jèhófà tọ́ òun sọ́nà, ó sì tún èrò ẹ̀ ṣe. Ó sọ pé: “Màá yin Jèhófà, ẹni tó fún mi ní ìmọ̀ràn. Kódà láàárín òru, èrò inú mi ń tọ́ mi sọ́nà.”​—Sm. 16:7.

Ọ̀RỌ̀ ỌLỌ́RUN

Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run máa ń kìlọ̀ fún wa tá a bá yà bàrá kúrò lójú ọ̀nà tó lọ sí ìyè. Tá a bá lẹ́mìí ìrẹ̀lẹ̀, àá jẹ́ kí Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run tún èrò wa ṣe (Wo ìpínrọ̀ 7)

7. Tá a bá lẹ́mìí ìrẹ̀lẹ̀, kí la máa ṣe?

7 Tá a bá lẹ́mìí ìrẹ̀lẹ̀, a máa jẹ́ kí Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run tún èrò wa ṣe ká má bàa ṣìwà hù. Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run máa dà bí ohùn tó ń sọ fún wa pé: “Èyí ni ọ̀nà. Ẹ máa rìn nínú rẹ̀.” Á sì kìlọ̀ fún wa tá a bá fẹ́ yà bàrá yálà sí ọ̀tún tàbí sí òsì. (Àìsá. 30:21) Ọ̀pọ̀ àǹfààní la máa rí tá a bá ń ṣègbọràn sí Jèhófà. (Àìsá. 48:17) Bí àpẹẹrẹ, tá ò bá ṣègbọràn sí Jèhófà, ó lè di dandan kí ẹlòmíì bá wa wí, ìyẹn sì lè kó ìtìjú bá wa. Àǹfààní míì ni pé àá túbọ̀ sún mọ́ Jèhófà torí a mọ̀ pé ó nífẹ̀ẹ́ wa bí bàbá ṣe ń nífẹ̀ẹ́ ọmọ.​—Héb. 12:7.

8. Bó ṣe wà nínú Jémíìsì 1:​22-25, báwo la ṣe lè wo Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run bí dígí?

8 Bíbélì fi Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run wé dígí. (Ka Jémíìsì 1:​22-25.) Ọ̀pọ̀ wa la máa ń wo dígí láàárọ̀ ká tó kúrò nílé. Ìyẹn máa ń jẹ́ ká lè ṣe àtúnṣe tó yẹ kó tó di pé a jáde káwọn míì sì rí wa. Lọ́nà kan náà, tá a bá ń ka Bíbélì lójoojúmọ́, a máa rí àwọn ibi tó ti yẹ ká tún èrò wa tàbí ìwà wa ṣe. Ọ̀pọ̀ máa ń ka ẹsẹ ojúmọ́ láàárọ̀ kí wọ́n tó kúrò nílé torí wọ́n gbà pé ó máa ṣe àwọn láǹfààní. Wọ́n máa ń ronú lé ẹsẹ ojúmọ́ yẹn jálẹ̀ ọjọ́ náà, wọ́n máa ń jẹ́ kó tọ́ àwọn sọ́nà, wọ́n sì máa ń wá àwọn ọ̀nà tí wọ́n lè gbà fi ìmọ̀ràn inú ẹ̀ sílò. Yàtọ̀ síyẹn, ó yẹ ká máa wáyè láti máa kẹ́kọ̀ọ́ ká sì máa ṣàṣàrò lórí Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run lójoojúmọ́. Lójú wa, ìyẹn lè dà bí ohun tó kéré. Àmọ́ ó wà lára àwọn nǹkan tó ṣe pàtàkì jù tá a gbọ́dọ̀ ṣe tá ò bá fẹ́ kúrò lójú ọ̀nà tó há tó lọ sí ìyè àìnípẹ̀kun.

TẸ́TÍ SÍ ÀWỌN Ọ̀RẸ́ TÍ ÒTÍTỌ́ JINLẸ̀ NÍNÚ WỌN

ÀWỌN Ọ̀RẸ́ TÍ ÒTÍTỌ́ JINLẸ̀ NÍNÚ WỌN

Kristẹni kan tí òtítọ́ jinlẹ̀ nínú rẹ̀ lè kì wá nílọ̀ tá a bá fẹ́ ṣi ẹsẹ̀ gbé. Ṣé a máa dúpẹ́ lọ́wọ́ irú ẹni bẹ́ẹ̀ pé ó lo ìgboyà, ó sì sòótọ́ ọ̀rọ̀ fún wa? (Wo ìpínrọ̀ 9)

9. Kí ló lè mú kí ọ̀rẹ́ ẹ kan tọ́ ẹ sọ́nà?

9 Ṣé ìgbà kan wà, tó o bẹ̀rẹ̀ sí í ṣe ohun tó lè mú kó o jìnnà sí Jèhófà? (Sm. 73:​2, 3) Ṣé ọ̀rẹ́ ẹ kan tí òtítọ́ jinlẹ̀ nínú ẹ̀ lo ìgboyà, tó sì tọ́ ẹ sọ́nà? Nígbà tó ṣe bẹ́ẹ̀, ǹjẹ́ o tẹ́tí sí i, ṣé o sì fi ìmọ̀ràn ẹ̀ sílò? Tó o bá ṣe bẹ́ẹ̀, á jẹ́ pé ohun tó tọ́ lo ṣe, ó sì dájú pé inú ẹ máa dùn pé ọ̀rẹ́ ẹ kìlọ̀ fún ẹ lásìkò.​—Òwe 1:5.

10. Kí ló yẹ kó o ṣe tí ọ̀rẹ́ ẹ kan bá tọ́ ẹ sọ́nà?

10 Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run sọ fún wa pé: “Àwọn ọgbẹ́ tí ọ̀rẹ́ dá síni lára jẹ́ ìṣòtítọ́.” (Òwe 27:6) Ṣé òótọ́ lọ̀rọ̀ tí Bíbélì yìí sọ? Ẹ jẹ́ ká wo àpèjúwe yìí: Ká sọ pé o fẹ́ sọdá títì, àmọ́ fóònù tó ò ń lò ti jẹ́ kó o gbàgbéra, lo bá bọ́ sọ́nà láìwo títì. Bẹ́ẹ̀ ni ọ̀rẹ́ ẹ dì ẹ́ lápá mú, ó sì fà ẹ́ pa dà. Ibi tó ti dì ẹ́ mú yẹn dùn ẹ́ gan-an, àmọ́ ohun tó ṣe yẹn ni ò jẹ́ kí mọ́tò gbá ẹ. Ká tiẹ̀ sọ pé apá yẹn dùn ẹ́ fún ọjọ́ mélòó kan, ṣé wàá bínú pé ọ̀rẹ́ ẹ fà ẹ́ kúrò ní títì? Ó dájú pé o ò ní bínú! Kàkà bẹ́ẹ̀, ṣe ni wàá máa dúpẹ́ lọ́wọ́ ẹ̀. Lọ́nà kan náà, ó lè kọ́kọ́ dùn ẹ́ tí ọ̀rẹ́ ẹ kan bá sọ fún ẹ pé ọ̀rọ̀ ẹ tàbí ìwà ẹ kò bá ìlànà Bíbélì mu. Àmọ́ o, má ṣe bínú sí ọ̀rẹ́ ẹ yẹn tàbí kó o dì í sínú. Torí tó o bá ṣe bẹ́ẹ̀, ìwà òmùgọ̀ gbáà lo hù yẹn. (Oníw. 7:9) Dípò bẹ́ẹ̀, ṣe ló yẹ kó o máa dúpẹ́ lọ́wọ́ ọ̀rẹ́ ẹ pé ó bá ẹ sòótọ́ ọ̀rọ̀.

11. Kí ló lè mú kẹ́nì kan kọ ìmọ̀ràn tí ọ̀rẹ́ rẹ̀ fún un?

11 Kí ló lè mú kẹ́nì kan kọ ìmọ̀ràn onífẹ̀ẹ́ tí ọ̀rẹ́ rẹ̀ fún un? Ìgbéraga ló lè mú kó ṣe bẹ́ẹ̀. Àwọn agbéraga máa ń fẹ́ káwọn èèyàn “sọ ohun tí wọ́n fẹ́ gbọ́” fún wọn. Torí náà, “wọn [kì í] fetí sí òtítọ́.” (2 Tím. 4:​3, 4) Wọ́n máa ń ro ara wọn ju bó ṣe yẹ lọ. Àmọ́, àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù sọ pé: “Tí ẹnì kan bá rò pé òun jẹ́ nǹkan kan nígbà tí kò jẹ́ nǹkan kan, ó ń tan ara rẹ̀ jẹ ni.” (Gál. 6:3) Ọ̀rọ̀ Ọba Sólómọ́nì bá a mu rẹ́gí, ó ní: “Ọmọdé tó jẹ́ aláìní àmọ́ tó jẹ́ ọlọ́gbọ́n sàn ju àgbàlagbà ọba tó jẹ́ òmùgọ̀, tí làákàyè rẹ̀ kò tó láti gba ìkìlọ̀ mọ́.”​—Oníw. 4:13.

12. Kí la rí kọ́ látinú ohun tí àpọ́sítélì Pétérù ṣe bó ṣe wà nínú Gálátíà 2:​11-14?

12 Ẹ jẹ́ ká wo ohun tí àpọ́sítélì Pétérù ṣe nígbà tí àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù bá a wí lójú gbogbo èèyàn. (Ka Gálátíà 2:​11-14.) Pétérù lè máa bínú sí Pọ́ọ̀lù nítorí bó ṣe bá a sọ̀rọ̀, àti pé ó bá a wí lójú gbogbo èèyàn. Àmọ́ Pétérù ò ṣe bẹ́ẹ̀ torí pé ọlọ́gbọ́n ni. Ó gba ìbáwí tí Pọ́ọ̀lù fún un, kò sì dì í sínú. Kódà nígbà tó yá, ó pe Pọ́ọ̀lù ní “arákùnrin wa ọ̀wọ́n.”​—2 Pét. 3:15.

13. Kí ló yẹ ká fi sọ́kàn tá a bá fẹ́ fún ẹnì kan nímọ̀ràn?

13 Tó bá pọn dandan pé kó o fún ọ̀rẹ́ ẹ kan nímọ̀ràn, àwọn nǹkan wo ló yẹ kó o fi sọ́kàn? Kó o tó lọ bá a, bi ara ẹ pé, ‘Ṣé mi ò máa ṣe “òdodo àṣelékè”?’ (Oníw. 7:16) Ìlànà ara ẹ̀ lẹni tó jẹ́ olódodo àṣelékè fi máa ń dá àwọn míì lẹ́jọ́ dípò ìlànà Jèhófà, kì í sì í lójú àánú. Lẹ́yìn tó o bá ti da ọ̀rọ̀ náà rò, tó o sì rí i pé ó pọn dandan pé kó o bá ọ̀rẹ́ ẹ sọ̀rọ̀, jẹ́ kó mọ ohun tó o kíyè sí ní pàtó, bi í láwọn ìbéèrè táá jẹ́ kó sọ ohun tó wà lọ́kàn ẹ̀, kó sì rí ibi tóun ti ṣàṣìṣe. Rí i dájú pé orí Ìwé Mímọ́ lo gbé ìmọ̀ràn rẹ kà, má sì gbàgbé pé Jèhófà ni ọ̀rẹ́ rẹ máa jíhìn fún, kì í ṣe ìwọ. (Róòmù 14:10) Yàtọ̀ síyẹn, jẹ́ kí ọgbọ́n Ọlọ́run darí ẹ nígbà tó o bá ń gbani nímọ̀ràn, kó o sì máa fàánú hàn bíi ti Jésù. (Òwe 3:5; Mát. 12:20) Kí nìdí? Ìdí ni pé ọwọ́ tá a bá fi mú àwọn èèyàn ni Jèhófà náà máa fi mú wa.​—Jém. 2:13.

MÁA TẸ̀ LÉ ÌLÀNÀ ÈTÒ ỌLỌ́RUN

ÈTÒ ỌLỌ́RUN

Ètò Ọlọ́run máa ń pèsè àwọn ìwé àti fídíò, wọ́n sì máa ń ṣètò àwọn ìpàdé tó ń jẹ́ ká mọ bá a ṣe lè fi ìlànà Bíbélì sílò. Nígbà míì, Ìgbìmọ̀ Olùdarí máa ń ṣàtúnṣe sí bá a ṣe ń ṣiṣẹ́ ìwàásù (Wo ìpínrọ̀ 14)

14. Àwọn nǹkan wo ni ètò Jèhófà ń pèsè fún wa?

14 Jèhófà ń lo apá ti ilẹ̀ ayé lára ètò rẹ̀ láti máa darí wa lójú ọ̀nà tó lọ sí ìyè. Ètò yìí sì ń pèsè àwọn ìwé àtàwọn fídíò. Bákan náà, wọ́n ń ṣètò àwọn ìpàdé tó ń jẹ́ ká mọ bá a ṣe lè máa fi Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run sílò. Inú Ìwé Mímọ́ ni wọ́n ti mú gbogbo àwọn nǹkan tá à ń gbádùn yìí. Ìgbìmọ̀ Olùdarí máa ń gbára lé ẹ̀mí mímọ́ tí wọ́n bá fẹ́ pinnu ọ̀nà tó dáa jù tá a lè gbà máa ṣiṣẹ́ ìwàásù. Síbẹ̀, ìgbà gbogbo ni Ìgbìmọ̀ Olùdarí máa ń yẹ ìpinnu tí wọ́n ṣe wò kí wọ́n lè mọ̀ bóyá kí wọ́n ṣàtúnṣe. Kí nìdí? Ìdí ni pé “ìrísí ayé yìí ń yí pa dà,” ètò Ọlọ́run sì gbọ́dọ̀ mọ ohun tó yẹ kí wọ́n ṣe bí nǹkan ṣe ń yí pa dà.​—1 Kọ́r. 7:31.

15. Kí ló ṣòro fáwọn akéde kan láti ṣe?

15 Tí ètò Ọlọ́run bá sọ òye tuntun tá a ní nípa ẹ̀kọ́ Bíbélì kan, a máa ń tẹ́wọ́ gbà á. Tí wọ́n bá sì tọ́ wa sọ́nà nípa bó ṣe yẹ ká máa hùwà, a máa ń fi ìtọ́ni náà sílò. Àmọ́, báwo ló ṣe máa ń rí lára wa tí ètò Ọlọ́run bá ṣàtúnṣe sí àwọn nǹkan míì tá à ń ṣe? Bí àpẹẹrẹ, láwọn ọdún àìpẹ́ yìí, iye tá a fi ń kọ́ Gbọ̀ngàn Ìjọba tá a sì fi ń bójú tó wọn ti lọ sókè gan-an. Torí náà, Ìgbìmọ̀ Olùdarí fún àwọn ará ní ìtọ́ni pé kí wọ́n máa lo Gbọ̀ngàn Ìjọba dé ẹ̀kúnrẹ́rẹ́. Nípa bẹ́ẹ̀, wọ́n da àwọn ìjọ kan pọ̀, wọ́n sì ti ta àwọn Gbọ̀ngàn Ìjọba kan. Wọ́n wá ń fi owó yìí kọ́ Gbọ̀ngàn Ìjọba láwọn ibi tí wọ́n ti nílò rẹ̀ gan-an. Tí wọ́n bá da ìjọ tó o wà pọ̀ mọ́ ìjọ míì tàbí tí wọ́n ta Gbọ̀ngàn Ìjọba yín, ó lè ṣòro fún ẹ láti ṣe àwọn àyípadà tó yẹ. Ìyípadà yìí ti mú kó pọn dandan fáwọn akéde kan láti lọ máa ṣèpàdé níbi tó jìnnà gan-an. Àwọn míì tó jẹ́ pé wọ́n ṣiṣẹ́ kára láti kọ́ Gbọ̀ngàn Ìjọba kan tàbí láti máa bójú tó o lè máa ronú pé kí ló dé tí wọ́n fi tà á. Ó lè máa ṣe wọ́n bíi pé ṣe làwọn fi àkókò àti okun àwọn ṣòfò. Síbẹ̀, wọ́n ń kọ́wọ́ ti ètò yìí, ó sì yẹ ká gbóríyìn fún wọn.

16. Báwo ni ìmọ̀ràn tó wà nínú Kólósè 3:​23, 24 ṣe máa jẹ́ ká túbọ̀ láyọ̀?

16 Àá máa láyọ̀ tá a bá ń rántí pé Jèhófà là ń ṣiṣẹ́ fún àti pé òun ló ń darí ètò yìí. (Ka Kólósè 3:​23, 24.) Àpẹẹrẹ àtàtà ni Dáfídì fi lélẹ̀ fún wa nígbà tó kówó sílẹ̀ pé kí wọ́n fi kọ́ tẹ́ńpìlì, ó sọ pé: “Ta ni mí, ta sì ni àwọn èèyàn mi, tí a fi máa láǹfààní láti ṣe ọrẹ àtinúwá bí irú èyí? Nítorí ọ̀dọ̀ rẹ ni ohun gbogbo ti wá, ohun tó ti ọwọ́ rẹ wá ni a sì fi fún ọ.” (1 Kíró. 29:14) Tá a bá ń fi owó ṣètìlẹ́yìn, ẹ jẹ́ ká máa rántí pé àtinú ohun tí Jèhófà fún wa la ti ń ṣe ọrẹ náà. Síbẹ̀, Jèhófà mọyì gbogbo àkókò, okun àti ohunkóhun tá a bá yọ̀ǹda láti fi ti iṣẹ́ rẹ̀ lẹ́yìn.​—2 Kọ́r. 9:7.

MÁ ṢE KÚRÒ LÓJÚ Ọ̀NÀ TÓ LỌ SÍ ÌYÈ

17. Kí nìdí tí kò fi yẹ kó o rẹ̀wẹ̀sì tó bá pọn dandan pé kó o ṣe àwọn ìyípadà kan?

17 Tá ò bá fẹ́ kúrò lójú ọ̀nà tó lọ sí ìyè, a gbọ́dọ̀ máa tẹ̀ lé ipasẹ̀ Jésù pẹ́kípẹ́kí. (1 Pét. 2:21) Tó o bá rí i pé ó yẹ kó o ṣe àwọn àyípadà kan, má ṣe rẹ̀wẹ̀sì. Bó o ṣe mọ̀ pé ó yẹ kó o ṣe àwọn àtúnṣe kan fi hàn pé ó wù ẹ́ láti máa tẹ̀ lé àwọn ìlànà Jèhófà. Máa rántí pé Jèhófà mọ̀ pé aláìpé ni wá, torí náà kò retí pé ká tẹ̀ lé àpẹẹrẹ Jésù láìkù síbì kan.

18. Kí la gbọ́dọ̀ ṣe ká lè dé inú ayé tuntun?

18 Torí náà, ẹ jẹ́ kí gbogbo wa tẹjú mọ́ ibi tá à ń lọ, ká sì ṣe tán láti ṣe àwọn àyípadà tó yẹ nínú bá a ṣe ń ronú, bá a ṣe ń sọ̀rọ̀ àti nínú ìwà wa. (Òwe 4:25; Lúùkù 9:62) Ẹ jẹ́ ká lẹ́mìí ìrẹ̀lẹ̀, ká “máa yọ̀, [ká sì] máa ṣe ìyípadà.” (2 Kọ́r. 13:11) Tá a bá ṣe bẹ́ẹ̀, ‘Ọlọ́run ìfẹ́ àti àlàáfíà yóò wà pẹ̀lú wa.’ Kì í ṣe pé ó máa jẹ́ ká wọnú ayé tuntun nìkan ni, ó tún máa jẹ́ ká gbádùn ìrìn àjò wa.

ORIN 34 Máa Rìn Nínú Ìwà Títọ́

^ ìpínrọ̀ 5 Ó lè ṣòro fáwọn kan lára wa láti ṣe ìyípadà nínú bí wọ́n ṣe ń ronú, bí wọ́n ṣe ń sọ̀rọ̀ àti nínú ìwà wọn. Nínú àpilẹ̀kọ yìí, a máa ṣàlàyé ìdí tó fi yẹ ká ṣe ìyípadà àti bá ò ṣe ní rẹ̀wẹ̀sì bá a ṣe ń ṣe àwọn ìyípadà náà.

^ ìpínrọ̀ 76 ÀWÒRÁN: Arákùnrin kan tó jẹ́ ọ̀dọ́ ń sọ fún arákùnrin míì tó dàgbà jù ú lọ nípa ohun tó ṣẹlẹ̀ sí i nígbà tó ṣe ìpinnu tí kò tọ́. Arákùnrin náà (lápá ọ̀tún) fara balẹ̀ tẹ́tí sí i kó lè mọ̀ bóyá kóun gbà á nímọ̀ràn tàbí kóun má ṣe bẹ́ẹ̀.