Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

ÌTÀN ÌGBÉSÍ AYÉ

“Jèhófà Ò Gbàgbé Mi”

“Jèhófà Ò Gbàgbé Mi”

ABÚLÉ Orealla tó wà lórílẹ̀-èdè Guyana ni wọ́n bí mi sí. Àwọn ọmọ ìbílẹ̀ Amerindian tó fẹ́rẹ̀ẹ́ tó ẹgbẹ̀rún méjì (2,000) ló wà lábúlé náà. Abúlé náà jìnnà sígboro gan-an débi pé ọkọ̀ ojú omi tàbí ọkọ̀ òfúrufú kékeré nìkan lèèyàn fi lè débẹ̀.

Ọdún 1983 ni wọ́n bí mi, ara mi sì le koko nígbà tí mo wà lọ́mọdé. Àmọ́ nígbà tí mo pé ọmọ ọdún mẹ́wàá, gbogbo ara bẹ̀rẹ̀ sí í ro mí gan-an. Ní nǹkan bí ọdún méjì lẹ́yìn náà, mo jí láàárọ̀ ọjọ́ kan, àmọ́ mi ò lè gbéra rárá. Mo gbìyànjú gan-an láti gbé ẹsẹ̀ mi, àmọ́ kò ṣe é gbé. Àtìgbà yẹn ni mi ò ti lè rìn mọ́. Àìsàn tó ṣe mí yẹn ni ò jẹ́ kí n dàgbà bó ṣe yẹ. Kódà títí di báyìí, ṣe ni mo dà bí ọmọ kékeré.

Lẹ́yìn oṣù méjì tí mo ti ń ṣàìsàn, tí mi ò sì lè jáde nílé, àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà méjì kan wàásù délé wa. Ṣe ni mo máa ń sá pa mọ́ táwọn àlejò bá wá sílé wa, àmọ́ lọ́jọ́ yẹn mo jẹ́ káwọn obìnrin yẹn bá mi sọ̀rọ̀. Wọ́n sọ̀rọ̀ nípa Párádísè, ìyẹn sì mú kí n rántí ohun kan tí mo ti gbọ́ nígbà tí mo wà lọ́mọ ọdún márùn-ún. Nígbà yẹn, míṣọ́nnárì kan tó ń jẹ́ Jethro tó ń gbé ní Suriname máa ń wá sí abúlé wa lẹ́ẹ̀kan lóṣù láti kọ́ bàbá mi lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. Jethro nífẹ̀ẹ́ mi gan-an, ó sì máa ń bá mi ṣeré, ìyẹn mú kémi náà fẹ́ràn ẹ̀ gan-an. Bákan náà, àwọn òbí mi àgbà máa ń mú mi lọ sípàdé àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà tí wọ́n máa ń ṣe lábúlé wa nígbà yẹn. Torí náà, nígbà tí ọ̀kan lára àwọn obìnrin yẹn tó ń jẹ́ Florence béèrè lọ́wọ́ mi pé ṣé màá fẹ́ kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, mo dáhùn pé bẹ́ẹ̀ ni.

Nígbà tí Florence máa pa dà wá, òun àti ọkọ ẹ̀ tó ń jẹ́ Justus ni wọ́n jọ wá, wọ́n sì jọ ń kọ́ mi lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. Nígbà tí wọ́n kíyè sí pé mi ò mọ̀wé kà, wọ́n kọ́ mi bí wọ́n ṣe ń kàwé. Kò pẹ́ sígbà yẹn ni mo bẹ̀rẹ̀ sí í kàwé fúnra mi. Lọ́jọ́ kan, tọkọtaya yẹn sọ fún mi pé wọ́n ti gbé àwọn lọ sí Suriname. Ó dùn mí gan-an pé mi ò ní rẹ́ni táá máa kọ́ mi lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì mọ́, àmọ́ Jèhófà ò gbàgbé mi.

Kò pẹ́ sígbà yẹn ni aṣáájú-ọ̀nà kan tó ń jẹ́ Floyd wá sí abúlé wa, ó sì pàdé mi nígbà tó ń wàásù láti ahéré kan sí òmíì. Nígbà tó béèrè lọ́wọ́ mi bóyá màá fẹ́ kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, ṣe ni mo rẹ́rìn-ín. Ó béèrè lọ́wọ́ mi pé kí ló ń pa mí lẹ́rìn-ín, mo wá sọ fún un pé mo ti parí ìwé Kí Ni Ọlọ́run Ń Béèrè Lọ́wọ́ Wa? mo sì ti bẹ̀rẹ̀ ìwé Ìmọ̀ Tí Ń Sinni Lọ sí Ìyè Àìnípẹ̀kun. * Mo wá ṣàlàyé ìdí tí ìkẹ́kọ̀ọ́ náà fi dúró fún un, Floyd sì bá mi ṣe ìkẹ́kọ̀ọ́ àwọn orí tó kù nínú ìwé Ìmọ̀. Àmọ́ lẹ́yìn ìyẹn, wọ́n gbé òun náà lọ síbòmíì. Bí mi ò ṣe tún lẹ́ni táá máa kọ́ mi lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì mọ́ nìyẹn.

Àmọ́ nígbà tó di ọdún 2004, wọ́n rán Granville àti Joshua tí wọ́n jẹ́ aṣáájú-ọ̀nà àkànṣe wá sí abúlé wa. Bí wọ́n ṣe ń wàásù láti ahéré kan sí òmíì, wọ́n dé ọ̀dọ̀ mi. Nígbà tí wọ́n béèrè lọ́wọ́ mi bóyá màá fẹ́ kẹ́kọ̀ọ́, ṣe ni mo rẹ́rìn-ín. Mo wá sọ fún wọn pé kí wọ́n fi ìwé Ìmọ̀ kọ́ mi lẹ́kọ̀ọ́ látìbẹ̀rẹ̀. Mo fẹ́ mọ̀ bóyá ohun táwọn ti tẹ́lẹ̀ fi kọ́ mi làwọn náà máa kọ́ mi. Granville sọ fún mi pé àwọn máa ń ṣèpàdé lábúlé náà. Bó tiẹ̀ jẹ́ pé ó ti ń lọ bí ọdún mẹ́wàá tí mi ò jáde nílé, ó wù mí kí n lọ sípàdé yẹn. Torí náà, Granville wá, ó gbé mi sórí kẹ̀kẹ́ arọ, ó sì tì mí lọ sí Gbọ̀ngàn Ìjọba.

Nígbà tó yá, Granville gbà mí níyànjú pé kí n forúkọ sílẹ̀ ní Ilé Ẹ̀kọ́ Ìjọba Ọlọ́run. Ó sọ fún mi pé: “Òótọ́ ni pé o ò lè rìn, àmọ́ o lè sọ̀rọ̀. Lọ́jọ́ kan, wàá sọ àsọyé fún gbogbo èèyàn. Ó dájú pé wàá ṣe bẹ́ẹ̀.” Ọ̀rọ̀ tó sọ lọ́jọ́ yẹn fún mi níṣìírí gan-an.

Bọ́jọ́ ṣe ń gorí ọjọ́, mo bẹ̀rẹ̀ sí í bá Granville lọ sóde ẹ̀rí. Àmọ́ ọ̀nà gbágungbàgun tó wà lábúlé wa mú kó ṣòro fún mi láti máa lo kẹ̀kẹ́ arọ. Mo wá sọ fún Granville pé kó gbé mi sínú kẹ̀kẹ́ akẹ́rù, ìyẹn wheelbarrow. Ìyẹn jẹ́ kí n lè máa wàásù láti ibì kan dé ibòmíì. Ní April 2005, mo ṣèrìbọmi. Kò pẹ́ lẹ́yìn náà, àwọn arákùnrin yẹn dá mi lẹ́kọ̀ọ́ láti máa bójú tó ìwé àti ẹ̀rọ ìgbóhùnsáfẹ́fẹ́ ní Gbọ̀ngàn Ìjọba.

Lọ́dún 2007, àjálù kan ṣẹlẹ̀ sí ìdílé wa, bàbá mi kú nínú ìjàǹbá ọkọ̀ ojú omi. Torí náà, Granville gbàdúrà pẹ̀lú wa, ó sì ka àwọn ẹsẹ Bíbélì kan láti tù wá nínú. Ọdún méjì lẹ́yìn náà, àjálù míì tún ṣẹlẹ̀, Granville náà kú nínú ìjàǹbá ọkọ̀ ojú omi.

Àdánù ńlá ló ṣẹlẹ̀ sí ìjọ wa torí a ò ní alàgbà kankan mọ́ àyàfi ìránṣẹ́ iṣẹ́ òjíṣẹ́ kan ṣoṣo. Ọgbẹ́ ńlá ni ikú Granville dá sí mi lọ́kàn torí pé ọ̀rẹ́ mi tímọ́tímọ́ ni. Kì í ṣe pé ó bójú tó mi nípa tẹ̀mí nìkan, ó tún ràn mí lọ́wọ́ nípa tara. Ní ìpàdé tá a ṣe lẹ́yìn ikú rẹ̀, èmi ni wọ́n ní kí n ka Ilé Ìṣọ́. Nígbà tí màá fi parí ìpínrọ̀ kejì, ńṣe ni mo bẹ̀rẹ̀ sí í sunkún, tí mo sì ń hu. Ó le débi pé mi ò lè parí Ilé Ìṣọ́ yẹn.

Mo bẹ̀rẹ̀ sí í túra ká nígbà tí àwọn arákùnrin láti ìjọ míì wá ràn wá lọ́wọ́ ní Orealla. Bákan náà, ẹ̀ka ọ́fíìsì rán Kojo tó jẹ́ aṣáájú-ọ̀nà àkànṣe wá sí abúlé wa. Inú mi dùn gan-an nígbà tí màámi àti àbúrò mi ọkùnrin bẹ̀rẹ̀ sí í kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì tí wọ́n sì ṣèrìbọmi. Nígbà tó di March 2015, mo di ìránṣẹ́ iṣẹ́ òjíṣẹ́. Kò pẹ́ lẹ́yìn ìyẹn, mo sọ àsọyé fún gbogbo èèyàn fúngbà àkọ́kọ́. Lọ́jọ́ yẹn, pẹ̀lú omijé lójú àti ẹ̀rín músẹ́, mo rántí ọ̀rọ̀ tí Granville sọ fún mi lọ́dún mélòó kan sẹ́yìn pé: “Lọ́jọ́ kan, wàá sọ àsọyé fún gbogbo èèyàn. Ó dájú pé wàá ṣe bẹ́ẹ̀.”

Ètò tẹlifíṣọ̀n JW Broadcasting® ti jẹ́ kí n mọ àwọn ará míì tí wọ́n nírú ìṣòro tí mo ní. Bó tiẹ̀ jẹ́ pé wọ́n jẹ́ aláàbọ̀ ara, wọ́n ń ṣe gbogbo ohun tí wọ́n lè ṣe lẹ́nu iṣẹ́ ìsìn Jèhófà, wọ́n sì ń láyọ̀. Mo wá rí i pé èmi náà lè ṣe púpọ̀ sí i, ìyẹn sì mú kí n pinnu pé màá di aṣáájú-ọ̀nà déédéé. Ohun kan ṣẹlẹ̀ ní September 2019 tó yà mí lẹ́nu ga-an! Lóṣù yẹn, mo di alàgbà. Nígbà tá a sì ń sọ yìí, ogójì (40) làwa akéde tá a wà níjọ wa.

Mo dúpẹ́ lọ́wọ́ àwọn arákùnrin àtàwọn arábìnrin tí wọ́n kọ́ mi lẹ́kọ̀ọ́, tí wọ́n sì ràn mí lọ́wọ́ lẹ́nu iṣẹ́ ìsìn Jèhófà. Ju gbogbo ẹ̀ lọ, mo dúpẹ́ lọ́wọ́ Jèhófà pé kò gbàgbé mi.

^ ìpínrọ̀ 8 Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà la ṣe é, àmọ́ a ò tẹ̀ ẹ́ mọ́ báyìí.