Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

ÀPILẸ̀KỌ FÚN ÌKẸ́KỌ̀Ọ́ 49

Àjíǹde Dájú!

Àjíǹde Dájú!

‘Mo ní ìrètí nínú Ọlọ́run pé àjíǹde yóò wà.’​—ÌṢE 24:15.

ORIN 151 Òun Yóò Pè

OHUN TÁ A MÁA JÍRÒRÒ *

1-2. Ìrètí àgbàyanu wo làwọn ìránṣẹ́ Jèhófà ní?

Ó ṢE pàtàkì kéèyàn nírètí. Ohun táwọn kan ń fẹ́ tí wọ́n sì ń gbàdúrà fún ni pé kí wọ́n ní ìgbéyàwó aláyọ̀, kí wọ́n tọ́mọ yanjú tàbí kí wọ́n bọ́ lọ́wọ́ àìsàn tó ń ṣe wọ́n. Àwa Kristẹni náà lè máa fojú sọ́nà fún irú àwọn nǹkan bẹ́ẹ̀. Àmọ́ ohun tá à ń retí kọjá ìyẹn. À ń retí àtiwà láàyè títí láé, a sì ń retí ìgbà táwọn èèyàn wa tó ti kú náà máa jíǹde.

2 Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù sọ pé: “Mo ní ìrètí nínú Ọlọ́run . . . pé àjíǹde àwọn olódodo àti àwọn aláìṣòdodo yóò wà.” (Ìṣe 24:15) Kì í ṣe Pọ́ọ̀lù lẹni àkọ́kọ́ tó gbà pé àjíǹde máa wà, Jóòbù náà gbà bẹ́ẹ̀. Ó dá a lójú pé Ọlọ́run máa rántí òun, á sì jí òun dìde.​—Jóòbù 14:​7-10, 12-15.

3. Àǹfààní wo ni Kọ́ríńtì Kìíní orí 15 máa ṣe wá?

3 “Àjíǹde àwọn òkú” wà lára “ìpìlẹ̀” tàbí “àwọn ẹ̀kọ́ àkọ́bẹ̀rẹ̀” àwa Kristẹni. (Héb. 6:​1, 2) Inú Kọ́ríńtì Kìíní orí 15 ni ohun tí Pọ́ọ̀lù sọ nípa àjíǹde wà. Ó sì dájú pé ohun tó sọ máa fún àwọn Kristẹni ọgọ́rùn-ún ọdún kìíní níṣìírí. Bákan náà, ohun tí Pọ́ọ̀lù sọ yìí máa fún àwa náà níṣìírí á sì jẹ́ kí ìrètí yìí túbọ̀ dá wa lójú bó ti wù ká pẹ́ tó nínú ètò Ọlọ́run.

4. Kí ló mú ká gbà pé àwọn èèyàn wa tó ti kú máa jíǹde?

4 Àjíǹde Jésù ló mú kó dá wa lójú pé àwọn èèyàn wa tó ti kú máa jíǹde. Àjíǹde Jésù wà lára “ìhìn rere” tí Pọ́ọ̀lù kéde fáwọn ará Kọ́ríńtì. (1 Kọ́r. 15:​1, 2) Kódà, ó sọ pé tí Kristẹni kan ò bá gbà pé Jésù jíǹde, ìgbàgbọ́ rẹ̀ ò wúlò. (1 Kọ́r. 15:17) Torí náà, àjíǹde Jésù ló mú ká gbà pé àwọn míì náà máa jíǹde.

5-6. Àǹfààní wo ni ọ̀rọ̀ tó wà nínú 1 Kọ́ríńtì 15:​3, 4 máa ṣe wá?

5 Nígbà tí Pọ́ọ̀lù ń sọ̀rọ̀ nípa àjíǹde, ó mẹ́nu ba kókó pàtàkì mẹ́ta: (1) “Kristi kú nítorí àwọn ẹ̀ṣẹ̀ wa.” (2) Wọ́n “sin ín.” (3) Ọlọ́run “jí i dìde ní ọjọ́ kẹta bí Ìwé Mímọ́ ṣe sọ.”​—Ka 1 Kọ́ríńtì 15:​3, 4.

6 Kí ni ikú Jésù, bí wọ́n ṣe sin ín àti àjíǹde rẹ̀ máa ṣe fún wa? Wòlíì Àìsáyà sọ tẹ́lẹ̀ pé wọ́n máa mú Mèsáyà “kúrò lórí ilẹ̀ alààyè” àti pé wọ́n máa “sin ín pẹ̀lú àwọn ẹni burúkú.” Kò tán síbẹ̀ o. Àìsáyà tún fi kún un pé Mèsáyà máa ru “ẹ̀ṣẹ̀ ọ̀pọ̀ èèyàn.” Jésù mú àsọtẹ́lẹ̀ yìí ṣẹ nígbà tó fi ẹ̀mí ẹ̀ rà wá pa dà. (Àìsá. 53:​8, 9, 12; Mát. 20:28; Róòmù 5:8) Torí náà, ikú Jésù, bí wọ́n ṣe sin ín àti àjíǹde rẹ̀ ló mú kó túbọ̀ dá wa lójú pé a máa bọ́ lọ́wọ́ ẹ̀ṣẹ̀ àti ikú àti pé a máa pa dà rí àwọn èèyàn wa tó ti kú.

Ọ̀PỌ̀ JẸ́RÌÍ SÍ I PÉ JÉSÙ JÍǸDE

7-8. Kí ló mú kó dá àwa Kristẹni lójú pé Jésù jíǹde?

7 Ká tó lè gbà pé àwọn òkú máa jíǹde, ó gbọ́dọ̀ dá wa lójú pé Jésù jíǹde. Kí ló mú kó dá wa lójú pé Jèhófà jí Jésù dìde?

8 Ọ̀pọ̀ èèyàn ló jẹ́rìí sí i pé Jésù jíǹde. (1 Kọ́r. 15:​5-7) Ẹni àkọ́kọ́ tí Pọ́ọ̀lù sọ pé ó rí Jésù ni àpọ́sítélì Pétérù (tàbí Kéfà). Àwọn ọmọlẹ́yìn kan jẹ́rìí sí i pé Pétérù rí Jésù lẹ́yìn tó jíǹde. (Lúùkù 24:​33, 34) Yàtọ̀ síyẹn “àwọn Méjìlá náà,” ìyẹn àwọn àpọ́sítélì rí Jésù lẹ́yìn tó jíǹde. Lẹ́yìn náà, Kristi “fara han èyí tó ju ọgọ́rùn-ún márùn-ún (500) àwọn ará lẹ́ẹ̀kan ṣoṣo,” ó ṣeé ṣe kó jẹ́ níbi ìpàdé tí wọ́n ṣe ní Gálílì bó ṣe wà nínú Mátíù 28:​16-20. Nígbà tó yá, Jésù “fara han Jémíìsì” tó ṣeé ṣe kó jẹ́ àbúrò ẹ̀ tí kò gbà tẹ́lẹ̀ pé Òun ni Mèsáyà. (Jòh. 7:5) Lẹ́yìn tí Jémíìsì rí Jésù, ó gbà pé òun ni Mèsáyà. Nígbà tí Pọ́ọ̀lù kọ lẹ́tà yìí ní nǹkan bí ọdún 55 S.K., ọ̀pọ̀ àwọn tó rí Jésù lẹ́yìn tó jíǹde ló ṣì wà láyé. Torí náà, tí ẹnikẹ́ni bá ń ṣiyèméjì, ó lè kàn sí èyíkéyìí lára wọn.

9. Kí nìdí tí Pọ́ọ̀lù fi lè jẹ́rìí sí i pé Jésù jíǹde bó ṣe wà nínú Ìṣe 9:​3-5?

9 Nígbà tó yá, Jésù fara han Pọ́ọ̀lù fúnra ẹ̀. (1 Kọ́r. 15:8) Ojú ọ̀nà Damásíkù ni Pọ́ọ̀lù tá a mọ̀ sí Sọ́ọ̀lù tẹ́lẹ̀ wà nígbà tó gbọ́ ohùn Jésù tó ti jíǹde, ó sì tún rí Jésù nínú ìran pé ó wà lọ́run. (Ka Ìṣe 9:​3-5.) Ohun tó ṣẹlẹ̀ sí Pọ́ọ̀lù yìí jẹ́ kó túbọ̀ dá wa lójú pé Jésù jíǹde lóòótọ́.​—Ìṣe 26:​12-15.

10. Kí ni Pọ́ọ̀lù ṣe lẹ́yìn tó dá a lójú pé Jésù ti jíǹde?

10 Ọ̀rọ̀ Pọ́ọ̀lù máa wọ àwọn kan lọ́kàn gan-an torí pé ṣáájú ìgbà yẹn, ó máa ń ṣe inúnibíni sáwọn Kristẹni. Lẹ́yìn tó dá Pọ́ọ̀lù lójú pé Jésù ti jíǹde, ó ṣe gbogbo ohun tó lè ṣe káwọn míì lè gbà pé Jésù ti jíǹde. Wọ́n lù ú, wọ́n jù ú sẹ́wọ̀n, ọkọ̀ tó wọ̀ sì rì bó ṣe ń wàásù kiri pé Jésù kú, ó sì ti jíǹde. (1 Kọ́r. 15:​9-11; 2 Kọ́r. 11:​23-27) Ó dá Pọ́ọ̀lù lójú pé Jésù jíǹde débi pé ó ṣe tán láti kú torí ohun tó gbà gbọ́. Bí àwọn Kristẹni ọgọ́rùn-ún ọdún kìíní ṣe jẹ́rìí sí i pé Jésù jíǹde mú kó túbọ̀ dá àwa náà lójú pé Jésù jíǹde, àbí bẹ́ẹ̀ kọ́? Ǹjẹ́ ìyẹn ò mú kó túbọ̀ dá ẹ lójú pé àjíǹde máa wáyé?

PỌ́Ọ̀LÙ TÚN ÈRÒ ÀWỌN KAN ṢE

11. Kí ló mú káwọn kan ní Kọ́ríńtì ní èrò tí kò tọ́ nípa àjíǹde?

11 Àwọn Kristẹni kan nílùú Kọ́ríńtì ní èrò tí kò tọ́ nípa àjíǹde, kódà wọ́n sọ pé kò sí “àjíǹde àwọn òkú.” Kí nìdí tí wọ́n fi sọ bẹ́ẹ̀? (1 Kọ́r. 15:12) Àwọn Gíríìkì tó jẹ́ onímọ̀ ọgbọ́n orí tó ń gbé nílùú Áténì náà sọ pé irọ́ ni pé Jésù jíǹde. Ó ṣeé ṣe kó jẹ́ pé ìyẹn ló mú káwọn kan nílùú Kọ́ríńtì náà gbà pé kò sí àjíǹde. (Ìṣe 17:​18, 31, 32) Àwọn míì ronú pé èdè ìṣàpẹẹrẹ ni Bíbélì lò nígbà tó ń sọ̀rọ̀ nípa àjíǹde ní ti pé wọ́n “kú” torí wọ́n jẹ́ ẹlẹ́ṣẹ̀, wọ́n sì “wá sí ìyè” nígbà tí wọ́n di Kristẹni. Ohun yòówù kó fà á tí wọ́n fi ronú bẹ́ẹ̀, asán ni ìgbàgbọ́ wọn tí wọn ò bá gbà pé àjíǹde wà. Tí Ọlọ́run ò bá jí Jésù dìde, á jẹ́ pé kò sí ìràpadà fún ẹ̀ṣẹ̀ wa nìyẹn, a ò sì lè rí ìdáríjì gbà. Torí náà, àwọn tí kò gbà pé àjíǹde wà kò ní ìrètí kankan.​—1 Kọ́r. 15:​13-19; Héb. 9:​12, 14.

12. Kí ni 1 Pétérù 3:​18, 22 sọ tó jẹ́ ká mọ̀ pé àjíǹde Jésù yàtọ̀ sí àwọn àjíǹde tó ti wáyé ṣáájú tiẹ̀?

12 Pọ́ọ̀lù fúnra ẹ̀ mọ̀ pé Ọlọ́run “ti gbé Kristi dìde kúrò nínú ikú.” Àjíǹde Jésù sàn ju àwọn àjíǹde tó ti wáyé ṣáájú tiẹ̀ torí pé àwọn ẹni yẹn tún pa dà kú lẹ́yìn tí wọ́n jí wọn dìde. Pọ́ọ̀lù sọ pé Jésù ni “àkọ́so nínú àwọn tó ti sùn nínú ikú.” Ọ̀nà wo ni Jésù gbà jẹ́ àkọ́so? Òun lẹni àkọ́kọ́ tí Ọlọ́run jí dìde ní ẹ̀dá ẹ̀mí, òun náà sì lẹni àkọ́kọ́ tó lọ sí ọ̀run lẹ́yìn tó jíǹde.​—1 Kọ́r. 15:20; Ìṣe 26:23; ka 1 Pétérù 3:​18, 22.

ÀWỌN TÓ MÁA “DI ÀÀYÈ”

13. Ìyàtọ̀ wo ni Pọ́ọ̀lù sọ pé ó wà láàárín Ádámù àti Jésù?

13 Báwo ni ikú ọkùnrin kan ṣoṣo ṣe lè mú kí ọ̀pọ̀ èèyàn wà láàyè? Pọ́ọ̀lù dáhùn ìbéèrè yìí nígbà tó ń sọ ìyàtọ̀ tó wà láàárín ohun tí Ádámù fà fún aráyé àtohun tí Kristi mú kó ṣeé ṣe fún wa. Pọ́ọ̀lù sọ pé: ‘Ikú wá nípasẹ̀ ẹnì kan.’ Nígbà tí Ádámù dẹ́ṣẹ̀, ó fa àjálù àti ikú bá òun fúnra ẹ̀ àti àwọn àtọmọdọ́mọ rẹ̀. Títí dòní la ṣì ń jìyà àìgbọràn tí Ádámù ṣe. Ẹ wo ìyàtọ̀ gbọ̀ọ̀rọ̀gbọọrọ tó wà láàárín ohun tí Ádámù ṣe àtohun tí Ọlọ́run mú kó ṣeé ṣe nígbà tó jí Ọmọ rẹ̀ dìde! Kí ni Ọlọ́run mú kó ṣeé ṣe? Pọ́ọ̀lù sọ pé: “Àjíǹde òkú náà wá nípasẹ̀ ẹnì kan,” ìyẹn Jésù. Pọ́ọ̀lù fi kún un pé: “Nítorí bí gbogbo èèyàn ṣe ń kú nínú Ádámù, bẹ́ẹ̀ ni a ó sọ gbogbo èèyàn di ààyè nínú Kristi.”​—1 Kọ́r. 15:​21, 22.

14. Ṣé Ọlọ́run máa jí Ádámù dìde? Ṣàlàyé.

14 Kí ni Pọ́ọ̀lù ní lọ́kàn nígbà tó sọ pé ‘gbogbo èèyàn ń kú nínú Ádámù’? Àwọn àtọmọdọ́mọ Ádámù ni Pọ́ọ̀lù ní lọ́kàn, torí pé wọ́n ti jogún ẹ̀ṣẹ̀ àti àìpé látọ̀dọ̀ Ádámù àti pé bópẹ́bóyá àwọn náà máa kú. (Róòmù 5:12) Ádámù ò sí lára àwọn tó máa “di ààyè.” Ìdí ni pé Ádámù ò sí lára àwọn tó máa jàǹfààní ìràpadà Jésù torí ẹni pípé ni àti pé ṣe ló mọ̀ọ́mọ̀ ṣàìgbọràn sí Ọlọ́run. Ohun tó ṣẹlẹ̀ sí Ádámù náà ló máa ṣẹlẹ̀ sí gbogbo àwọn tí “Ọmọ èèyàn” bá kà sí “ewúrẹ́,” ìyẹn àwọn tó máa lọ sínú “ìparun àìnípẹ̀kun.”​—Mát. 25:​31-33, 46; Héb. 5:9.

Jésù lẹni àkọ́kọ́ lára ọ̀pọ̀ tí Ọlọ́run máa jí dìde sí ọ̀run (Wo ìpínrọ̀ 15-16) *

15. Àwọn wo ló wà lára “gbogbo” àwọn tí Ọlọ́run ‘máa sọ di ààyè’?

15 Kíyè sí pé Pọ́ọ̀lù sọ pé “a ó sọ gbogbo èèyàn di ààyè nínú Kristi.” (1 Kọ́r. 15:22) Àwọn Kristẹni ẹni àmì òróró ní Kọ́ríńtì tí wọ́n máa jíǹde sí ọ̀run ni Pọ́ọ̀lù kọ lẹ́tà sí. A sọ àwọn Kristẹni yẹn ‘di mímọ́ nínú Kristi Jésù, a sì pè wọ́n láti jẹ́ ẹni mímọ́.’ Ó tún mẹ́nu kan “àwọn tó ti sun oorun ikú nínú Kristi.” (1 Kọ́r. 1:2; 15:18; 2 Kọ́r. 5:17) Nínú lẹ́tà míì tí Ọlọ́run mí sí Pọ́ọ̀lù láti kọ, ó sọ pé àwọn tó “wà ní ìṣọ̀kan pẹ̀lú [Jésù] lọ́nà tó gbà kú” máa “wà níṣọ̀kan pẹ̀lú rẹ̀ lọ́nà tó gbà jíǹde.” (Róòmù 6:​3-5) Ọlọ́run jí Jésù dìde ní ẹ̀dá ẹ̀mí, ó sì lọ sọ́run. Ohun kan náà ni Ọlọ́run máa ṣe fún gbogbo àwọn tó wà “nínú Kristi,” ìyẹn àwọn Kristẹni ẹni àmì òróró.

16. Kí ni Pọ́ọ̀lù ní lọ́kàn nígbà tó pe Jésù ní “àkọ́so”?

16 Pọ́ọ̀lù sọ pé a ti gbé Kristi dìde, òun sì ni “àkọ́so nínú àwọn tó ti sùn nínú ikú.” Ká rántí pé Ọlọ́run ti jí àwọn míì bíi Lásárù dìde ṣáájú Jésù. Àmọ́, Jésù lẹni àkọ́kọ́ tí Ọlọ́run jí dìde ní ẹ̀dá ẹ̀mí tó sì fún ní ìyè àìnípẹ̀kun. A lè fi wé àkọ́so nínú ìkórè táwọn ọmọ Ísírẹ́lì máa ń fi rúbọ sí Ọlọ́run. Bákan náà, bí Pọ́ọ̀lù ṣe pe Jésù ní “àkọ́so” fi hàn pé Ọlọ́run máa jí àwọn míì náà dìde sí ọ̀run, ìyẹn àwọn àpọ́sítélì àtàwọn míì tí wọ́n wà “nínú Kristi.” Tó bá yá, Ọlọ́run máa jí àwọn náà dìde ní ẹ̀dá ẹ̀mí lọ sí ọ̀run bíi ti Jésù.

17. Ìgbà wo ni àwọn tó wà “nínú Kristi” máa gba èrè wọn ní ọ̀run?

17 Ọlọ́run ò tíì bẹ̀rẹ̀ sí í jí àwọn tó wà “nínú Kristi” sí ọ̀run nígbà tí Pọ́ọ̀lù kọ lẹ́tà rẹ̀ sáwọn ará Kọ́ríńtì. Kàkà bẹ́ẹ̀, Pọ́ọ̀lù sọ pé ọjọ́ iwájú nìyẹn máa ṣẹlẹ̀, ó ní: “Kálukú wà ní àyè rẹ̀: Kristi àkọ́so, lẹ́yìn náà àwọn tó jẹ́ ti Kristi nígbà tó bá wà níhìn-ín.” (1 Kọ́r. 15:23; 1 Tẹs. 4:​15, 16) Ìgbà wíwà níhìn-ín Kristi la wà báyìí. Torí náà, àwọn àpọ́sítélì àtàwọn Kristẹni ẹni àmì òróró tó ti kú máa ní láti dúró dìgbà wíwà níhìn-ín rẹ̀ kí wọ́n tó lè gba èrè wọn ti ọ̀run kí wọ́n sì “wà níṣọ̀kan pẹ̀lú [Jésù] lọ́nà tó gbà jíǹde.”

ÌRÈTÍ WA DÁJÚ!

18. (a) Kí ló mú ká gbà pé àjíǹde míì máa wà yàtọ̀ sí àjíǹde àwọn tó ń lọ sọ́run? (b) Kí ni 1 Kọ́ríńtì 15:​24-26 sọ pé ó máa ṣẹlẹ̀ lọ́run?

18 Àmọ́ àwọn Kristẹni tí ò nírètí àtilọ sí ọ̀run ńkọ́? Ọlọ́run máa jí àwọn náà dìde. Bíbélì sọ pé Pọ́ọ̀lù àtàwọn míì tó nírètí láti gbé lọ́run máa ní “àjíǹde àkọ́kọ́ kúrò nínú ikú.” (Fílí. 3:11) Èyí fi hàn pé àjíǹde míì máa wà lẹ́yìn ìyẹn. Ohun tí Jóòbù ní lọ́kàn nìyẹn nígbà tó sọ pé Ọlọ́run máa rántí òun lọ́jọ́ iwájú. (Jóòbù 14:15) “Àwọn tó jẹ́ ti Kristi nígbà tó bá wà níhìn-ín” máa wà pẹ̀lú Jésù lọ́run nígbà tó bá sọ gbogbo ìjọba àti gbogbo àṣẹ àti agbára di asán. Kódà, “ikú tó jẹ́ ọ̀tá ìkẹyìn” máa di asán. Ó dájú pé àwọn tó jíǹde sí ọ̀run máa bọ́ lọ́wọ́ ikú tá a jogún. Àmọ́ àwọn yòókù ńkọ́?​—Ka 1 Kọ́ríńtì 15:​24-26.

19. Kí ni àwọn tó nírètí àtigbé lórí ilẹ̀ ayé lè máa retí?

19 Kí ni àwọn tó nírètí àtigbé lórí ilẹ̀ ayé lè máa retí? Wọ́n lè máa fojú sọ́nà fún ohun tí Pọ́ọ̀lù sọ pé: “Mo ní ìrètí . . . pé àjíǹde àwọn olódodo àti àwọn aláìṣòdodo yóò wà.” (Ìṣe 24:15) Ó dájú pé kò sí aláìṣòdodo kankan tó máa lọ sọ́run. Torí náà, àjíǹde orí ilẹ̀ ayé ni Pọ́ọ̀lù ń tọ́ka sí.

Tó bá dá wa lójú pé Ọlọ́run máa jí àwọn òkú dìde, àwa náà á máa fayọ̀ sin Jèhófà nìṣó (Wo ìpínrọ̀ 20) *

20. Báwo ni àpilẹ̀kọ yìí ṣe mú kí ìrètí àjíǹde túbọ̀ dá ẹ lójú?

20 Kò sí àní-àní pé ‘àjíǹde yóò wà!’ Àwọn tó nírètí àtijíǹde sórí ilẹ̀ ayé máa wà láàyè títí láé. Jẹ́ kó dá ẹ lójú pé ìlérí yìí máa ṣẹ. Ìlérí yìí máa tù ẹ́ nínú bó o ṣe ń ronú àwọn èèyàn ẹ tó ti kú. Ọlọ́run lè jí wọn dìde lásìkò tí Kristi àtàwọn míì bá ń “jọba . . . fún ẹgbẹ̀rún (1,000) ọdún náà.” (Ìfi. 20:6) Jẹ́ kó dá ẹ lójú pé tíwọ náà bá kú ṣáájú Ẹgbẹ̀rún Ọdún Ìṣàkóso Kristi, Ọlọ́run máa jí ẹ dìde. Bíbélì sọ pé ìrètí yìí kò ní “yọrí sí ìjákulẹ̀.” (Róòmù 5:5) Ìrètí yìí á fún ẹ lókun nísinsìnyí, á sì mú kó o túbọ̀ máa fayọ̀ sin Jèhófà. Nínú àpilẹ̀kọ tó kàn, a máa rí àwọn ẹ̀kọ́ míì tá a lè kọ́ nínú Kọ́ríńtì Kìíní orí 15.

ORIN 147 Ọlọ́run Ṣèlérí Ìyè Àìnípẹ̀kun

^ ìpínrọ̀ 5 Ọ̀rọ̀ àjíǹde ni Kọ́ríńtì Kìíní orí 15 dá lé. Kí nìdí tọ́rọ̀ àjíǹde fi ṣe pàtàkì? Ẹ̀rí wo ló sì fi hàn pé Jésù jíǹde? A máa dáhùn àwọn ìbéèrè yìí àtàwọn ìbéèrè pàtàkì míì nínú àpilẹ̀kọ yìí.

^ ìpínrọ̀ 56 ÀWÒRÁN: Jésù lẹni àkọ́kọ́ tí Ọlọ́run jí dìde sọ́run. (Ìṣe 1:9) Lára àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ tí Ọlọ́run máa jí dìde sí ọ̀run ni Tọ́másì, Jémíìsì, Lìdíà, Jòhánù, Màríà àti Pọ́ọ̀lù.

^ ìpínrọ̀ 58 ÀWÒRÁN: Ìyàwó arákùnrin kan kú lẹ́yìn tí wọ́n ti jọ sin Jèhófà fún ọ̀pọ̀ ọdún. Ó dá a lójú pé Ọlọ́run máa jí i dìde, ó sì ń fayọ̀ sin Jèhófà nìṣó.