Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Ohun Tó Yẹ Kó O Ṣe Tó O Bá Fẹ́ Gbé Inú Ayé Tuntun

Ohun Tó Yẹ Kó O Ṣe Tó O Bá Fẹ́ Gbé Inú Ayé Tuntun

Nínú orí tó ṣáájú èyí, a ti kẹ́kọ̀ọ́ pé Ọlọ́run máa tó pa àwọn èèyàn burúkú run, ó sì máa fòpin sí gbogbo ìṣòro. Ó dájú pé Ọlọ́run máa ṣe ohun tó sọ yìí. Kí nìdí? Ìdí ni pé Bíbélì Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run sọ pé:

“Ayé ń kọjá lọ.”​—1 JÒHÁNÙ 2:17.

Ó dájú pé àwọn kan máa là á já, torí pé ẹsẹ Bíbélì tó wà lókè yìí tún sọ pé:

“Ẹni tó bá ń ṣe ìfẹ́ Ọlọ́run ló máa wà títí láé.”

Torí náà, ohun tó máa jẹ́ ká la òpin ayé já ni pé ká máa ṣe ohun tí Ọlọ́run fẹ́. Ká tó lè mọ ohun tí Ọlọ́run fẹ́, àfi ká kọ́kọ́ mọ Ọlọ́run fúnra ẹ̀.

“WÁ MỌ” ỌLỌ́RUN KÓ O LÈ LÀ Á JÁ

Jésù sọ pé: “Èyí túmọ̀ sí ìyè àìnípẹ̀kun, pé kí wọ́n wá mọ ìwọ Ọlọ́run tòótọ́ kan ṣoṣo.” (Jòhánù 17:3) Tá a bá fẹ́ la ìparun tó ń bọ̀ já ká sì máa gbé ayé títí láé, àfi ká “wá mọ Ọlọ́run.” Èyí kọjá pé ká kàn gbà pé Ọlọ́run wà tàbí ká kàn mọ ohun díẹ̀ nípa ẹ̀. Ńṣe ló yẹ ká jẹ́ ọ̀rẹ́ Ọlọ́run. Bí àwa náà sì ṣe mọ̀, tá a bá fẹ́ kí àjọṣe àárín àwa àti ọ̀rẹ́ wa máa lágbára sí i, àfi ká máa lo àkókò wa pẹ̀lú ẹni náà. Ohun tó yẹ ká ṣe náà nìyẹn tá a bá fẹ́ kí àjọṣe wa pẹ̀lú Ọlọ́run máa lágbára sí i. Jẹ́ ká wo àwọn ẹ̀kọ́ pàtàkì kan tí Bíbélì kọ́ wa táá jẹ́ kí àjọṣe wa pẹ̀lú Ọlọ́run máa lágbára sí i.

MÁA KA BÍBÉLÌ Ọ̀RỌ̀ ỌLỌ́RUN LÓJOOJÚMỌ́

Tó o bá ń gbàdúrà pé kí Ọlọ́run ràn ẹ́ lọ́wọ́ tó o sì ń ṣe ohun tí Ọlọ́run fẹ́, wàá la ayé burúkú yìí já

Ìdí tá a fi ń jẹun ni pé a ò fẹ́ kú. Àmọ́ Jésù sọ pé: “Kì í ṣe oúnjẹ nìkan ṣoṣo ló ń mú kí èèyàn wà láàyè, àmọ́ gbogbo ọ̀rọ̀ tó ń ti ẹnu Jèhófà jáde ni èèyàn fi ń wà láàyè.”​—Mátíù 4:4.

Lóde òní, inú Bíbélì ni ọ̀rọ̀ Jèhófà wà. Bó o ṣe ń ka Ìwé Mímọ́ yìí, o máa kọ́ àwọn nǹkan pàtàkì tí Ọlọ́run ti ṣe nígbà àtijọ́, àwọn nǹkan tó ń ṣe ní báyìí àtàwọn nǹkan tó máa ṣe lọ́jọ́ iwájú.

GBÀDÚRÀ PÉ KÍ ỌLỌ́RUN RÀN Ẹ́ LỌ́WỌ́

Kí la lè ṣe tó bá ń wù wá láti máa ṣe ohun tí Ọlọ́run fẹ́, àmọ́ tó jẹ́ pé kò rọrùn fún wa láti jáwọ́ nínú àwọn nǹkan tí Ọlọ́run sọ pé kò dára? Ohun tó yẹ ká ṣe ni pé ká mọ Ọlọ́run dáadáa, torí pé ìyẹn ló máa jẹ́ kó rọrùn fún wa láti máa ṣe ohun tó fẹ́.

Ẹ jẹ́ ká wo ohun tó ṣẹlẹ̀ sí obìnrin kan tá a máa pe orúkọ ẹ̀ ní Sakura. Oníṣekúṣe ni obìnrin yìí tẹ́lẹ̀. Nígbà tó bẹ̀rẹ̀ sí í kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, ó kẹ́kọ̀ọ́ nípa àṣẹ Ọlọ́run tó sọ pé ká “máa sá fún ìṣekúṣe.” (1 Kọ́ríńtì 6:18) Sakura gbàdúrà sí Ọlọ́run pé kó ran òun lọ́wọ́ kóun lè jáwọ́ nínú ìwà tí kò dáa yìí, Ọlọ́run sì dáhùn àdúrà rẹ̀. Àmọ́, ó ṣì máa ń sapá gan-an láti borí èrò tí kò dáa tó máa ń wá sí i lọ́kàn. Ó sọ pé: “Tó bá ti ń ṣe mí bíi pé kí n ṣe ìṣekúṣe, mo máa ń gbàdúrà àtọkànwá sí Jèhófà, torí mo mọ̀ pé mi ò lè dá ogun yìí jà. Mo ti wá rí i pé àdúrà máa ń ṣiṣẹ́ gan-an, èyí sì ti jẹ́ kí n túbọ̀ sún mọ́ Jèhófà.” Àìmọye èèyàn lọ̀rọ̀ wọn dà bíi ti Sakura, àmọ́ àwọn náà ti wá mọ Ọlọ́run. Ó ń fún wọn lókun láti ṣe àwọn àyípadà tó yẹ nígbèésí ayé wọn, kí wọn sì lè máa ṣe ohun tó máa múnú ẹ̀ dùn.​—Fílípì 4:13.

Bó o bá ṣe túbọ̀ ń mọ Ọlọ́run, bẹ́ẹ̀ ni ‘Ọlọ́run á ṣe túbọ̀ máa mọ̀ ẹ́,’ wàá sì di ọ̀rẹ́ rẹ̀ tímọ́tímọ́. (Gálátíà 4:9; Sáàmù 25:14) Èyí á jẹ́ kó o wà lára àwọn tó máa la ayé burúkú yìí já sínú ayé tuntun. Àmọ́, báwo ni ayé tuntun yẹn ṣe máa rí? A máa rí ìdáhùn ìbéèrè yìí ní orí tó kàn.

a Bíbélì jẹ́ ká mọ̀ pé Jèhófà ni orúkọ Ọlọ́run.