Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Gbogbo Èèyàn Ló Fẹ́ Kí Ọjọ́ Ọ̀la Wọn Dáa

Gbogbo Èèyàn Ló Fẹ́ Kí Ọjọ́ Ọ̀la Wọn Dáa

Báwo lo ṣe fẹ́ kí ọjọ́ ọ̀la ẹ rí? Ó dájú pé ó máa wù ẹ́ kí ìwọ àti ìdílé rẹ máa láyọ̀, kí ara yín le, kí àlááfíà àti ọrọ̀ sì fi ilé yín ṣe ibùgbé.

Àmọ́, ọ̀pọ̀ èèyàn ló gbà pé ọwọ́ àwọn ò lè tẹ irú ìgbé ayé tó ń wu àwọn. Ìdí sì ni pé wọ́n ti fojú ara wọn rí àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ tó mú kí nǹkan yí pa dà bìrí. Bí àpẹẹrẹ, wọ́n ti rí bí àjàkálẹ̀ àrùn Corona (COVID-19) ṣe dojú gbogbo nǹkan rú, tó mú kí àtijẹ àtimu dìṣòro, tó sì gbẹ̀mí ọ̀pọ̀ èèyàn. Èyí wá mú kí ẹ̀rù máa bà wọ́n torí wọn ò mọ ohun tó tún máa ṣẹlẹ̀ lọ́jọ́ iwájú.

Pẹ̀lú bí nǹkan ṣe rí yìí, gbogbo ọ̀nà làwọn èèyàn fi ń wá ohun tó máa jẹ́ kí ọkàn wọn balẹ̀ kí ọjọ́ ọ̀la wọn sì dáa. Àwọn kan gbà pé àyànmọ́ tàbí àkọsílẹ̀ ló máa jẹ́ káwọn rìnnà kore, kí ọjọ́ ọ̀la àwọn sì dáa. Ọ̀pọ̀ ló sì gbà pé táwọn bá kàwé dáadáa, táwọn sì lówó rẹpẹtẹ, ọjọ́ ọ̀la àwọn máa dáa gan-an, ọkàn àwọn á sì balẹ̀. Àwọn míì sì gbà pé táwọn bá ṣáà ti jẹ́ èèyàn dáadáa, ìgbésí ayé àwọn máa dáa.

Ṣó o rò pé èyíkéyìí lára àwọn ohun tá a sọ yìí lè jẹ́ kí ọkàn ẹ balẹ̀ kí ọjọ́ ọ̀la ẹ sì dáa? Jẹ́ ká dáhùn àwọn ìbéèrè yìí:

  • Kí ló máa ń pinnu bí ọjọ́ ọ̀la wa ṣe máa rí?

  • Ṣó dájú pé ọkàn ẹnì kan á balẹ̀ tó bá kàwé dáadáa tó sì lówó rẹpẹtẹ?

  • Ṣé téèyàn bá ṣáà ti jẹ́ èèyàn dáadáa, ó dájú pé ọkàn ẹ̀ máa balẹ̀, ọjọ́ ọ̀la ẹ̀ á sì dáa?

  • Ibo lo ti lè rí ìmọ̀ràn tó dáa jù lọ tó máa jẹ́ kí ọkàn ẹ balẹ̀ kí ọjọ́ ọ̀la ẹ sì dáa?

Ka ìwé yìí, kó o lè rí ìdáhùn àwọn ìbéèrè yìí.