Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Amọ̀nà Tó Ṣeé Gbára Lé Nípa Bí Ọjọ́ Ọ̀la Wa Ṣe Máa Dáa

Amọ̀nà Tó Ṣeé Gbára Lé Nípa Bí Ọjọ́ Ọ̀la Wa Ṣe Máa Dáa

Nínú àwọn àpilẹ̀kọ tó ṣáájú, a ti sọ̀rọ̀ nípa ohun táwọn èèyàn máa ń ṣe kí ọjọ́ ọ̀la wọn lè dáa. Bí àpẹẹrẹ, wọ́n gbà gbọ́ nínú àyànmọ́, wọ́n máa ń kàwé dáadáa, wọ́n máa ń lé bí wọ́n ṣe máa dolówó rẹpẹtẹ, wọ́n sì máa ń hùwà rere. Àmọ́, ohun tó ṣẹlẹ̀ sọ́pọ̀ èèyàn ti jẹ́ ká rí i pé tẹ́nì kan bá gbà pé àwọn nǹkan yìí ló máa jẹ́ kí ọjọ́ ọ̀la òun dáa, ṣe lọ̀rọ̀ ẹni náà máa dà bíi tẹnì kan tó fẹ́ lọ síbì tí ò dé rí tó wá lọ ń béèrè ọ̀nà lọ́wọ́ ẹni tí kò mọ̀nà. Ṣéyẹn wá túmọ̀ sí pé kò sẹ́ni tó lè fún wa nímọ̀ràn tó lè fi wá lọ́kàn balẹ̀, táá sì jẹ́ ká gbà pé ọjọ́ ọ̀la wa máa dáa? Rárá o!

AMỌ̀NÀ TÍ KÒ LẸ́GBẸ́

Tá a bá fẹ́ ṣèpinnu, a sábà máa ń fẹ́ gbàmọ̀ràn látọ̀dọ̀ ẹni tó dàgbà tó sì tún gbọ́n jù wá lọ. Lọ́nà kan náà, a lè rí ìmọ̀ràn tó ṣeé gbára lé nípa bí ọjọ́ ọ̀la wa ṣe máa rí látọ̀dọ̀ ẹnì kan tó dàgbà jù wá lọ fíìfíì, tó sì tún gbọ́n jù wá lọ. Ìmọ̀ràn ẹni náà wà nínú ìwé kan tí wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí í kọ ní nǹkan bí ẹgbẹ̀rún mẹ́tà ààbọ̀ (3,500) ọdún sẹ́yìn. Bíbélì lorúkọ ìwé náà.

Kí nìdí tó fi yẹ kó o gbára lé Bíbélì? Ìdí ni pé ọ̀dọ̀ ẹni tó dàgbà jù lọ tó sì gbọ́n jù lọ ni àwọn nǹkan tó wà nínú ẹ̀ ti wá. Òun ni “Ẹni Ọjọ́ Àtayébáyé,” ó sì wà “láti ayérayé dé ayérayé.” (Dáníẹ́lì 7:9; Sáàmù 90:2) Bákan náà, òun ni “Ẹlẹ́dàá ọ̀run, Ọlọ́run tòótọ́, ẹni tó dá ayé.” (Àìsáyà 45:18) Ó jẹ́ ká mọ̀ pé Jèhófà ni orúkọ òun.​—Sáàmù 83:18.

Torí pé ọ̀dọ̀ ẹni tó dá gbogbo èèyàn ni Bíbélì ti wá, gbogbo èèyàn ló lè jàǹfààní látinú ohun tó wà nínú rẹ̀. Kò sígbà táwọn ìmọ̀ràn inú ẹ̀ ò wúlò, ó sì ti ṣe ọ̀pọ̀ èèyàn láǹfààní níbi gbogbo láyé. Nínú gbogbo ìwé tó wà láyé, Bíbélì ni ìwé tó dé ibi tó pọ̀ jù lọ, òun ló sì wà ní èdè tó pọ̀ jù lọ. * Torí náà, ó rọrùn fún gbogbo èèyàn láti kà, ó sì ń ṣe gbogbo àwọn tó ń kà á láǹfààní. Ìyẹn sì bá ohun tí Bíbélì fúnra rẹ̀ sọ mu pé:

“Ọlọ́run kì í ṣe ojúsàájú, àmọ́ ní gbogbo orílẹ̀-èdè, ẹni tó bá bẹ̀rù rẹ̀, tó sì ń ṣe ohun tí ó tọ́ ni ẹni ìtẹ́wọ́gbà lọ́dọ̀ rẹ̀.”​—ÌṢE 10:34, 35.

Bó ṣe jẹ́ pé àwọn òbí tó nífẹ̀ẹ́ àwọn ọmọ wọn máa ń tọ́ wọn sọ́nà, bẹ́ẹ̀ náà ni Jèhófà Bàbá wa ọ̀run ṣe nífẹ̀ẹ́ wa, tó sì fún wa ní Bíbélì Ọ̀rọ̀ rẹ̀ kó lè máa tọ́ wa sọ́nà. (2 Tímótì 3:16) A lè gbára lè Bíbélì, ó ṣe tán Jèhófà tó fún wa ní Bíbélì ni Ẹlẹ́dàá wa, ó sì mọ ohun tá a lè ṣe káyé wa lè ládùn kó sì lóyin.

Kí ló yẹ kó o ṣe tó o bá fẹ́ gbádùn àwọn nǹkan yìí? Wàá rí ìdáhùn ìbéèrè yìí nínú àpilẹ̀kọ tó kàn.

^ ìpínrọ̀ 6 Tó o bá fẹ́ àlàyé sí i nípa bí wọ́n ṣe ń túmọ̀ Bíbélì àti bó ṣe ń dọ́wọ́ àwọn èèyàn, lọ sórí ìkànnì www.pr418.com, wo abẹ́ Ẹ̀KỌ́ BÍBÉLÌ > ÌTÀN ÀTI BÍBÉLÌ.

^ ìpínrọ̀ 16 Tó o bá fẹ́ mọ púpọ̀ sí i, wo orí 9 nínú ìwé The Bible​—God’s Word or Man’s? Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà la ṣe ìwé yìí, ó sì wà lórí ìkànnì www.pr418.com. Lọ sí abẹ́ OHUN TÁ A NÍ > ÌWÉ ŃLÁ ÀTI ÌWÉ PẸLẸBẸ.