Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

ÀPILẸ̀KỌ FÚN ÌKẸ́KỌ̀Ọ́ 2

Kẹ́kọ̀ọ́ Lára “Ọmọ Ẹ̀yìn Tí Jésù Nífẹ̀ẹ́”

Kẹ́kọ̀ọ́ Lára “Ọmọ Ẹ̀yìn Tí Jésù Nífẹ̀ẹ́”

“Ẹ jẹ́ ká túbọ̀ máa nífẹ̀ẹ́ ara wa, torí pé ọ̀dọ̀ Ọlọ́run ni ìfẹ́ ti wá.”​—1 JÒH. 4:7.

ORIN 105 “Ọlọ́run Jẹ́ Ìfẹ́”

OHUN TÁ A MÁA JÍRÒRÒ *

1. Báwo ni ìfẹ́ tí Ọlọ́run ní sí wa ṣe rí lára rẹ?

ÀPỌ́SÍTÉLÌ Jòhánù sọ pé: “Ọlọ́run jẹ́ ìfẹ́.” (1 Jòh. 4:8) Ọ̀rọ̀ yìí rán wa létí òtítọ́ pàtàkì kan: Yàtọ̀ sí pé Jèhófà ni Ẹlẹ́dàá wa, ọ̀dọ̀ rẹ̀ ni ìfẹ́ ti wá. Jèhófà nífẹ̀ẹ́ wa gan-an. Ìfẹ́ tó ní sí wa yìí ló mú kọ́kàn wa balẹ̀, ká sì láyọ̀.

2. Kí ni àṣẹ méjì tó tóbi jù bó ṣe wà nínú Mátíù 22:​37-40, kí ló sì lè mú kó ṣòro láti pa àṣẹ kejì mọ́?

2 Àwa Kristẹni gbọ́dọ̀ máa fìfẹ́ hàn torí pé àṣẹ ni, kì í ṣọ̀rọ̀ bóyá ó wù wá tàbí kò wù wá. (Ka Mátíù 22:37-40.) Tá a bá mọ Jèhófà dáadáa, kò ní ṣòro fún wa àtipa àṣẹ àkọ́kọ́ mọ́. Ó ṣe tán, ẹni pípé ni Jèhófà, ó ń gba tiwa rò, ó sì ń fìfẹ́ bójú tó wa. Àmọ́ ó lè má rọrùn fún wa láti pa àṣẹ kejì mọ́. Kí nìdí? Ìdí ni pé aláìpé làwọn arákùnrin àtàwọn arábìnrin wa, wọ́n sì wà lára àwọn tó sún mọ́ wa jù. Nígbà míì, wọ́n lè sọ̀rọ̀ tàbí ṣe ohun kan tó mú ká rò pé wọn ò gba tiwa rò, wọn ò sì nífẹ̀ẹ́ wa. Jèhófà mọ̀ pé ó lè ṣòro fún wa láti pa àṣẹ kejì yìí mọ́, ìdí nìyẹn tó fi mí sí àwọn kan tó kọ Bíbélì láti sọ̀rọ̀ nípa ìfẹ́. Wọ́n jẹ́ ká mọ ìdí tó fi ṣe pàtàkì pé ká fìfẹ́ hàn síra wa àti bá a ṣe lè ṣe bẹ́ẹ̀. Ọ̀kan lára àwọn tí Ọlọ́run mí sí yìí ni Jòhánù.​—1 Jòh. 3:11, 12.

3. Kí ni Jòhánù sọ pé káwa Kristẹni máa ṣe?

3 Nínú àwọn ìwé tí Jòhánù kọ, ó sọ pé àwa Kristẹni gbọ́dọ̀ máa fìfẹ́ hàn. Kódà, nínú àkọsílẹ̀ Jòhánù nípa ìgbésí ayé Jésù, ó lo ọ̀rọ̀ náà “ìfẹ́” àti “nífẹ̀ẹ́” ju iye ìgbà tí àpapọ̀ àwọn ìwé Ìhìn Rere mẹ́ta tó kù lò ó. Jòhánù ti tó nǹkan bí ẹni ọgọ́rùn-ún ọdún nígbà tó kọ ìwé Ìhìn Rere àti àwọn lẹ́tà rẹ̀ mẹ́tẹ̀ẹ̀ta. Àwọn ìwé tó kọ jẹ́ ká rí i pé ìfẹ́ ló gbọ́dọ̀ máa mú ká ṣe gbogbo ohun tá a bá ń ṣe. (1 Jòh. 4:​10, 11) Àmọ́ ó ṣe díẹ̀ kí Jòhánù fúnra ẹ̀ tó kọ́ ẹ̀kọ́ yìí.

4. Ṣé àtìbẹ̀rẹ̀ ni Jòhánù ti máa ń fìfẹ́ hàn sáwọn míì?

4 Nígbà tí Jòhánù wà pẹ̀lú Jésù, àwọn ìgbà kan wà tí kò fìfẹ́ hàn. Bí àpẹẹrẹ, ìgbà kan wà tí Jésù àtàwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ ń lọ sí Jerúsálẹ́mù, wọ́n sì gba Samáríà kọjá. Nígbà tí wọ́n dé abúlé kan ní Samáríà, àwọn èèyàn ibẹ̀ ò tẹ́wọ́ gbà wọ́n. Kí wá ni Jòhánù ṣe? Ṣe ló sọ fún Jésù pé kó jẹ́ káwọn pe iná wá látọ̀run, kó sì pa gbogbo àwọn ará ìlú náà run! (Lúùkù 9:52-56) Ìgbà kan tún wà tí Jòhánù ò fìfẹ́ hàn sáwọn àpọ́sítélì tó kù. Ó jọ pé òun àti Jémíìsì arákùnrin rẹ̀ ló lọ bá ìyá wọn pé kó bá àwọn bẹ Jésù kó lè fún àwọn ní ipò pàtàkì nínú Ìjọba rẹ̀. Nígbà táwọn àpọ́sítélì tó kù gbọ́ ohun tí Jémíìsì àti Jòhánù ṣe, inú bí wọn gan-an! (Mát. 20:20, 21, 24) Síbẹ̀, láìka gbogbo kùdìẹ̀-kudiẹ Jòhánù sí, Jésù ṣì nífẹ̀ẹ́ rẹ̀.​—Jòh. 21:7.

5. Kí la máa jíròrò nínú àpilẹ̀kọ yìí?

5 Nínú àpilẹ̀kọ yìí, a máa jíròrò àwọn ohun tí Jòhánù ṣe àti díẹ̀ lára ohun tó sọ nípa ìfẹ́. Nípa bẹ́ẹ̀, àá rí bá a ṣe lè máa fìfẹ́ hàn sáwọn arákùnrin àtàwọn arábìnrin wa. Yàtọ̀ síyẹn, a tún máa jíròrò ọ̀nà pàtàkì kan tó yẹ káwọn olórí ìdílé máa gbà fìfẹ́ hàn sí ìdílé wọn.

BÁ A ṢE LÈ MÁA FÌFẸ́ HÀN

Jèhófà fi hàn pé òun nífẹ̀ẹ́ wa nígbà tó rán Ọmọ rẹ̀ wá sáyé láti kú fún wa (Wo ìpínrọ̀ 6-7)

6. Kí ni Jèhófà ṣe tó jẹ́ ká mọ̀ pé ó nífẹ̀ẹ́ wa?

6 Lọ́pọ̀ ìgbà, ohun tẹ́nì kan sọ ló máa ń jẹ́ ká mọ̀ pé ó nífẹ̀ẹ́ wa. Àmọ́ ohun tó bá ṣe ló máa fi hàn pé ó nífẹ̀ẹ́ wa lóòótọ́. (Fi wé Jémíìsì 2:17, 26.) Bí àpẹẹrẹ, Jèhófà nífẹ̀ẹ́ wa. (1 Jòh. 4:19) Báwo la ṣe mọ̀? Àwọn ọ̀rọ̀ ìtùnú tó wà nínú Bíbélì ló jẹ́ ká mọ̀. (Sm. 25:10; Róòmù 8:38, 39) Àmọ́ o, kì í ṣe àwọn ohun tó sọ nìkan ló jẹ́ ká mọ̀ bẹ́ẹ̀, àwọn nǹkan tó ń ṣe fún wa ló jẹ́ ká gbà pé Jèhófà nífẹ̀ẹ́ wa lóòótọ́. Jòhánù sọ pé: “Bí a ṣe fi ìfẹ́ Ọlọ́run hàn kedere nínú ọ̀rọ̀ wa nìyí, Ọlọ́run rán Ọmọ bíbí rẹ̀ kan ṣoṣo wá sí ayé, ká lè ní ìyè nípasẹ̀ rẹ̀.” (1 Jòh. 4:9) Jèhófà gbà kí Ọmọ ẹ̀ jìyà, kó sì kú nítorí wa. (Jòh. 3:16) Torí náà, ṣé ó tún yẹ ká máa ṣiyèméjì pé Jèhófà nífẹ̀ẹ́ wa?

7. Kí ni Jésù ṣe tó fi hàn pé ó nífẹ̀ẹ́ wa?

7 Jésù fi dá àwọn ọmọ ẹ̀yìn ẹ̀ lójú pé òun nífẹ̀ẹ́ wọn gan-an. (Jòh. 13:1; 15:15) Ohun tó ṣe ló jẹ́ ká mọ̀ pé ó nífẹ̀ẹ́ wọn, kì í ṣe ohun tó sọ nìkan, bó sì ṣe nífẹ̀ẹ́ àwa náà nìyẹn. Jésù sọ pé: “Kò sí ẹni tí ìfẹ́ rẹ̀ ju èyí lọ, pé kí ẹnì kan fi ẹ̀mí rẹ̀ lélẹ̀ nítorí àwọn ọ̀rẹ́ rẹ̀.” (Jòh. 15:13) Tá a bá ronú jinlẹ̀ nípa ohun tí Jèhófà àti Jésù ṣe fún wa, kí ló yẹ ká ṣe?

8. Kí ni 1 Jòhánù 3:18 sọ pé ká ṣe?

8 A lè fi hàn pé a nífẹ̀ẹ́ Jèhófà àti Jésù tá a bá ń ṣègbọràn sí wọn. (Jòh. 14:15; 1 Jòh. 5:3) Jésù sì dìídì pàṣẹ pé ká nífẹ̀ẹ́ ara wa lẹ́nì kìíní kejì. (Jòh. 13:34, 35) Kò yẹ kó jẹ́ ọ̀rọ̀ ẹnu wa nìkan làá fi máa sọ fáwọn ará wa pé a nífẹ̀ẹ́ wọn, ó tún gbọ́dọ̀ hàn nínú ohun tá à ń ṣe. (Ka 1 Jòhánù 3:18.) Àwọn nǹkan pàtó wo la lè ṣe táá fi hàn pé a nífẹ̀ẹ́ àwọn ará wa?

NÍFẸ̀Ẹ́ ÀWỌN ARÁ LỌ́KÙNRIN ÀTI LÓBÌNRIN

9. Kí ni ìfẹ́ mú kí Jòhánù ṣe?

9 Jòhánù lè pinnu pé òun á máa bá bàbá òun ṣiṣẹ́ ẹja pípa nìṣó kówó lè máa wọlé dáadáa, àmọ́ kò ṣe bẹ́ẹ̀. Kàkà bẹ́ẹ̀, ṣe ló lo ìyókù ìgbésí ayé rẹ̀ láti ran àwọn míì lọ́wọ́ kí wọ́n lè kẹ́kọ̀ọ́ nípa Jèhófà àti Jésù. Ìpinnu tí Jòhánù ṣe yìí ò rọrùn rárá. Ìdí ni pé wọ́n ṣenúnibíni sí i. Kódà, ní ọwọ́ ìparí ọgọ́rùn-ún ọdún kìíní nígbà tó ti darúgbó, wọ́n lé e kúrò nílùú. (Ìṣe 3:1; 4:1-3; 5:18; Ìfi. 1:9) Ní gbogbo ìgbà tí Jòhánù fi wà ní ẹ̀wọ̀n ní erékùṣù Pátímọ́sì, bó ṣe máa fáwọn Kristẹni bíi tiẹ̀ lókun ló gbà á lọ́kàn. Bí àpẹẹrẹ, erékùṣù yẹn ló wà nígbà tó kọ ìwé Ìfihàn, ó sì fi ránṣẹ́ sáwọn ìjọ kí wọ́n lè mọ “àwọn nǹkan tó gbọ́dọ̀ ṣẹlẹ̀ láìpẹ́.” (Ìfi. 1:1) Ó ṣeé ṣe kó jẹ́ pé ẹ̀yìn tí wọ́n dá a sílẹ̀ ní Pátímọ́sì ló kọ ìwé Ìhìn Rere nípa ìgbésí ayé Jésù àti iṣẹ́ òjíṣẹ́ rẹ̀. Ó tún kọ lẹ́tà mẹ́ta kó lè fún àwọn arákùnrin àtàwọn arábìnrin lókun, kó sì gbé wọn ró. Báwo làwọn ìpinnu tíwọ náà ń ṣe nígbèésí ayé rẹ ṣe lè fi hàn pé o ní ìfẹ́ tó jinlẹ̀ bíi ti Jòhánù?

10. Báwo lo ṣe lè fi hàn pé o nífẹ̀ẹ́ àwọn èèyàn?

10 Ohun tó o bá pinnu láti fi ìgbésí ayé ẹ ṣe máa fi hàn bóyá lóòótọ́ lo nífẹ̀ẹ́ àwọn èèyàn. Ohun tí ayé Sátánì ń fẹ́ ni pé kó o máa lo gbogbo àkókò àti okun ẹ láti wá owó àti òkìkí. Dípò bẹ́ẹ̀, fara wé àwọn Kristẹni tó lẹ́mìí ìfara-ẹni-rúbọ tí wọ́n sì ní ìfẹ́ tó jinlẹ̀. Kárí ayé làwọn Kristẹni yìí ti máa ń lo àkókò àti okun wọn bó ti lè ṣeé ṣe tó láti wàásù ìhìn rere Ìjọba Ọlọ́run, wọ́n sì ń ran àwọn míì lọ́wọ́ láti wá mọ Jèhófà. Kódà àwọn kan ti pinnu láti máa lo ọ̀pọ̀ àkókò lẹ́nu iṣẹ́ ìwàásù.

Àwọn ohun tá a bá ń ṣe fún àwọn ará àti ìdílé wa ló máa fi hàn pé a nífẹ̀ẹ́ wọn (Wo ìpínrọ̀ 11, 17) *

11. Kí làwọn akéde kan ṣe kí wọ́n lè fi hàn pé àwọn nífẹ̀ẹ́ Jèhófà àtàwọn ará?

11 Ọ̀pọ̀ àwọn Kristẹni olóòótọ́ ló ń ṣiṣẹ́ bó-o-jí-o-jí-mi kí wọ́n lè pèsè fún ara wọn àti ìdílé wọn. Síbẹ̀ àwọn ará yìí ń ṣe gbogbo ohun tí wọ́n lè ṣe láti ti ètò Ọlọ́run lẹ́yìn. Bí àpẹẹrẹ, àwọn kan máa ń yọ̀ǹda ara wọn láti ṣèrànwọ́ nígbà àjálù, àwọn míì máa ń ṣiṣẹ́ níbi tá a ti ń kọ́lé, gbogbo wa la sì ń fowó ṣètìlẹyìn fún iṣẹ́ kárí ayé. Ìfẹ́ tí wọ́n ní fún Ọlọ́run àtàwọn míì ló mú kí wọ́n máa ṣe bẹ́ẹ̀. Lọ́sọ̀ọ̀sẹ̀, à ń fi hàn pé a nífẹ̀ẹ́ àwọn ará lọ́kùnrin àti lóbìnrin bá a ṣe ń pésẹ̀ sípàdé tá a sì ń kópa nínú ẹ̀. Bó tiẹ̀ jẹ́ pé ó máa ń rẹ̀ wá nígbà míì, a máa ń rí i dájú pé a lọ sípàdé. Táyà wa bá tiẹ̀ ń já, a ṣì máa ń dáhùn. Bákan náà, bá a tiẹ̀ láwọn ìṣòro tá à ń bá yí, ìyẹn ò ní ká má fún àwọn ará níṣìírí kí ìpàdé tó bẹ̀rẹ̀ àti lẹ́yìn ìpàdé. (Héb. 10:​24, 25) Kò sí àní-àní pé iṣẹ́ ńlá làwọn ará wa ń ṣe, a sì mọyì wọn gan-an!

12. Kí ni ohun míì tí Jòhánù ṣe tó fi hàn pé ó nífẹ̀ẹ́ àwọn ará?

12 Yàtọ̀ sí pé Jòhánù gbóríyìn fáwọn ará, ó tún gbà wọ́n nímọ̀ràn, ìyẹn sì fi hàn pé ó nífẹ̀ẹ́ wọn. Bí àpẹẹrẹ, nínú àwọn lẹ́tà tó kọ, Jòhánù gbóríyìn fáwọn ará nítorí ìgbàgbọ́ àti iṣẹ́ rere tí wọ́n ṣe, àmọ́ ó tún kìlọ̀ fún wọn nípa ẹ̀ṣẹ̀. (1 Jòh. 1:8–2:​1, 13, 14) Lọ́nà kan náà, ó yẹ ká máa gbóríyìn fáwọn arákùnrin àtàwọn arábìnrin wa torí àwọn nǹkan rere tí wọ́n ń ṣe. Àmọ́ tẹ́nì kan bá ń hùwà tí kò tọ́, ó yẹ ká bá a sòótọ́ ọ̀rọ̀, síbẹ̀ ká ṣe bẹ́ẹ̀ tìfẹ́tìfẹ́. Ó máa ń gba ìgboyà ká tó lè gba ọ̀rẹ́ wa nímọ̀ràn, àmọ́ Bíbélì sọ pé àwọn ọ̀rẹ́ gidi máa ń bá ara wọn sòótọ́ ọ̀rọ̀.​—Òwe 27:17.

13. Kí ni kò yẹ ká máa ṣe?

13 Tá a bá fẹ́ fi hàn pé a nífẹ̀ẹ́ àwọn ará wa, àwọn nǹkan kan wà tá ò ní máa ṣe. Bí àpẹẹrẹ, kò yẹ ká tètè máa bínú tí wọ́n bá sọ ohun tó dùn wá. Ẹ jẹ́ ká wo ohun tó ṣẹlẹ̀ nígbà tó ku díẹ̀ kí Jésù parí iṣẹ́ òjíṣẹ́ rẹ̀ lórí ilẹ̀ ayé. Ó sọ fún àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ pé wọ́n gbọ́dọ̀ jẹ ẹran ara òun kí wọ́n sì mu ẹ̀jẹ̀ òun tí wọ́n bá máa rí ìyè. (Jòh. 6:​53-57) Ọ̀rọ̀ yẹn dẹ́rù ba ọ̀pọ̀ lára wọn, wọ́n sì fi í sílẹ̀. Àmọ́ àwọn tó jẹ́ ọ̀rẹ́ rẹ̀ gidi títí kan Jòhánù ò fi í sílẹ̀. Bó tiẹ̀ jẹ́ pé ohun tí Jésù sọ yà wọ́n lẹ́nu, kò sì yé wọn, wọ́n dúró tì í gbágbáágbá. Wọn ò ronú pé ohun tí Jésù sọ ò tọ̀nà, kí wọ́n sì tìtorí ẹ̀ bínú. Kàkà bẹ́ẹ̀, wọ́n fọkàn tán Jésù torí wọ́n mọ̀ pé òtítọ́ ló máa ń sọ. (Jòh. 6:​60, 66-69) Ẹ ò rí i bó ti ṣe pàtàkì tó pé ká má tètè máa bínú táwọn ọ̀rẹ́ wa bá sọ ohun tó lè múnú bí wa! Kàkà bẹ́ẹ̀, ó yẹ ká mú sùúrù kí wọ́n lè ṣàlàyé bí ọ̀rọ̀ náà ṣe rí.​—Òwe 18:13; Oníw. 7:9.

14. Kí nìdí tí kò fi yẹ ká kórìíra àwọn ará wa?

14 Jòhánù tún gbà wá níyànjú pé ká má ṣe kórìíra àwọn ará wa. Tá ò bá fi ìmọ̀ràn yìí sílò, Èṣù lè rí wa mú. (1 Jòh. 2:11; 3:15) Ohun tó ṣẹlẹ̀ sáwọn kan nìyẹn ní ìparí ọgọ́rùn-ún ọdún kìíní S.K. Nígbà yẹn lọ́hùn-ún, Sátánì ṣe gbogbo ohun tó lè ṣe láti mú káwọn ará kórìíra ara wọn, kí wọ́n sì kẹ̀yìn síra wọn. Nígbà tí Jòhánù fi máa kọ àwọn lẹ́tà rẹ̀, àwọn tó nírú ẹ̀mí tí Sátánì ní ti yọ́ wọnú ìjọ. Àpẹẹrẹ kan ni ti Díótíréfè tó ń dá ìpínyà sílẹ̀ nínú ìjọ. (3 Jòh. 9, 10) Kì í bọ̀wọ̀ fún àwọn aṣojú tí ìgbìmọ̀ olùdarí rán wá. Ó kórìíra àwọn tó ń gba àwọn aṣojú yẹn lálejò, ó sì fẹ́ lé wọn kúrò nínú ìjọ. Ẹ ò rí i pé ó jọra ẹ̀ lójú gan-an! Títí dòní ni Sátánì ṣì ń gbìyànjú láti kẹ̀yìn àwa èèyàn Jèhófà síra wa. Torí náà, ẹ jẹ́ ká pinnu pé a ò ní jẹ́ kí ohunkóhun mú ká kórìíra àwọn ará wa.

NÍFẸ̀Ẹ́ ÌDÍLÉ RẸ

Jésù ní kí Jòhánù máa bójú tó ìyá òun nípa tara àti nípa tẹ̀mí. Ó yẹ kí àwọn olórí ìdílé náà máa bójú tó ohun tí ìdílé wọn nílò, kí wọ́n sì rí i pé ìdílé wọn ní àjọṣe tó dáa pẹ̀lú Jèhófà (Wo ìpínrọ̀ 15-16)

15. Kí ló yẹ káwọn olórí ìdílé fi sọ́kàn?

15 Ọ̀nà pàtàkì kan tí olórí ìdílé kan lè gbà fi hàn pé òun nífẹ̀ẹ́ ìdílé òun ni pé kó máa pèsè fún wọn nípa tara. (1 Tím. 5:8) Àmọ́ ó gbọ́dọ̀ fi sọ́kàn pé, àjọṣe tí ìdílé ẹ̀ ní pẹ̀lú Jèhófà lohun tó ṣe pàtàkì jù, kì í ṣe àwọn ohun ìní tara. (Mát. 5:3) Ẹ jẹ́ ká wo àpẹẹrẹ àtàtà tí Jésù fi lélẹ̀ fáwọn olórí ìdílé. Ìwé Ìhìn Rere Jòhánù jẹ́ ká mọ̀ pé bí Jésù ṣe ń kú lọ lórí òpó igi oró, ó ṣì ń ronú nípa ìdílé rẹ̀. Lákòókò yẹn, Jòhánù wà pẹ̀lú Màríà ìyá Jésù níbi tí wọ́n ti pa Jésù. Bó tiẹ̀ jẹ́ pé Jésù ń jẹ ìrora tó le gan-an, ó ṣètò pé kí Jòhánù máa tọ́jú Màríà. (Jòh. 19:​26, 27) Òótọ́ ni pé Jésù láwọn àbúrò tó lè gbọ́ bùkátà Màríà, àmọ́ ó jọ pé kò sí ìkankan nínú wọn tó tíì di ọmọlẹ́yìn rẹ̀. Torí náà, Jésù rí i dájú pé òun ṣètò ẹni tó máa bójú tó Màríà nípa tara àti nípa tẹ̀mí.

16. Àwọn ojúṣe wo ni Jòhánù ní?

16 Ojúṣe tí Jòhánù ní pọ̀ gan-an. Bí àpẹẹrẹ, àpọ́sítélì ni, torí náà ó wà lára àwọn tó ń múpò iwájú lẹ́nu iṣẹ́ ìwàásù. Yàtọ̀ síyẹn, ó ṣeé ṣe kó níyàwó. Torí náà, bó ṣe ń bójú tó ìdílé ẹ̀ nípa tara, bẹ́ẹ̀ lá máa bójú tó wọn nípa tẹ̀mí. (1 Kọ́r. 9:5) Ẹ̀kọ́ wo làwọn olórí ìdílé lè kọ́ lára Jòhánù?

17. Kí nìdí tó fi ṣe pàtàkì pé kí olórí ìdílé kan máa bójú tó ìdílé ẹ̀ nípa tẹ̀mí?

17 Arákùnrin kan tó jẹ́ olórí ìdílé lè ní ọ̀pọ̀ ojúṣe láti bójú tó. Bí àpẹẹrẹ, ó gbọ́dọ̀ jẹ́ òṣìṣẹ́ kára níbi iṣẹ́ kí ìwà ẹ̀ lè máa fògo fún Jèhófà. (Éfé. 6:​5, 6; Títù 2:​9, 10) Yàtọ̀ síyẹn, ó tún lè láwọn ojúṣe míì nínú ìjọ, bíi kó máa ṣiṣẹ́ olùṣọ́ àgùntàn, kó sì máa múpò iwájú lẹ́nu iṣẹ́ ìwàásù. Bákan náà, ó ṣe pàtàkì kó máa wáyè kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì pẹ̀lú ìyàwó àtàwọn ọmọ ẹ̀ déédéé. Ó dájú pé ìyàwó àtàwọn ọmọ ẹ̀ máa mọyì bó ṣe ń sapá láti mú kí ìlera wọn dáa, kí wọ́n láyọ̀, kí wọ́n sì ní àjọṣe tó dán mọ́rán pẹ̀lú Jèhófà.​—Éfé. 5:​28, 29; 6:4.

‘Ẹ DÚRÓ NÍNÚ ÌFẸ́ MI’

18. Kí ló dá Jòhánù lójú?

18 Jòhánù pẹ́ láyé, ó sì ní ọ̀pọ̀ ìrírí. Ó kojú onírúurú ìṣòro tó lè mú kó fi Jèhófà sílẹ̀. Síbẹ̀, ó ṣe gbogbo ohun tó lè ṣe kó lè máa fìfẹ́ hàn sáwọn ará lọ́kùnrin àti lóbìnrin bí Jésù ṣe pa láṣẹ. Ìyẹn mú kó dá Jòhánù lójú pé Jèhófà àti Jésù nífẹ̀ẹ́ òun àti pé wọ́n máa fún òun lókun láti kojú ìṣòro èyíkéyìí. (Jòh. 14:​15-17; 15:10; 1 Jòh. 4:16) Láìka ohun tí Sátánì àti àwọn èèyàn burúkú ṣe fún un, Jòhánù ṣì ń fìfẹ́ hàn sáwọn ará lọ́rọ̀ àti níṣe.

19. Kí ni 1 Jòhánù 4:7 gbà wá níyànjú pé ká máa ṣe, kí sì nìdí?

19 Bíi ti Jòhánù, inú ayé tí Sátánì ẹni burúkú náà ń ṣàkóso là ń gbé. (1 Jòh. 3:​1, 10) Sátánì ń ṣe gbogbo ohun tó lè ṣe ká má bàa nífẹ̀ẹ́ àwọn ará wa mọ́, àmọ́ kò lè rí i ṣe àfi tá a bá fàyè gbà á. Torí náà, ẹ jẹ́ ká pinnu pé àá máa nífẹ̀ẹ́ àwọn ará wa, àá sì jẹ́ kó hàn nínú ọ̀rọ̀ àti ìṣe wa. Tá a bá ṣe bẹ́ẹ̀, inú wa á dùn pé a wà nínú ìdílé Jèhófà, àá sì gbádùn ìgbésí ayé wa gan-an.​—Ka 1 Jòhánù 4:7.

ORIN 88 Mú Mi Mọ Àwọn Ọ̀nà Rẹ

^ ìpínrọ̀ 5 Ó ṣeé ṣe kó jẹ́ àpọ́sítélì Jòhánù ni “ọmọ ẹ̀yìn tí Jésù nífẹ̀ẹ́.” (Jòh. 21:7) Èyí fi hàn pé nígbà tí Jòhánù wà pẹ̀lú Jésù, ó láwọn ànímọ́ tó fani mọ́ra. Ọ̀pọ̀ ọdún lẹ́yìn náà, Jèhófà mú kó kọ ọ̀pọ̀ nǹkan nípa ìfẹ́. Nínú àpilẹ̀kọ yìí, a máa jíròrò díẹ̀ lára àwọn ohun tí Jòhánù kọ, àá sì kẹ́kọ̀ọ́ lára òun fúnra ẹ̀.

^ ìpínrọ̀ 59 ÀWÒRÁN: Olórí ìdílé kan ń yọ̀ǹda ara ẹ̀ láti ṣèrànwọ́ nígbà àjálù, ó ń fowó ṣètìlẹyìn fún iṣẹ́ ìwàásù kárí ayé, ó sì pe àwọn míì wá sílé wọn kí wọ́n lè jọ ṣe ìjọsìn ìdílé.