Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

ÀPILẸ̀KỌ FÚN ÌKẸ́KỌ̀Ọ́ 5

“Orí Gbogbo Ọkùnrin Ni Kristi”

“Orí Gbogbo Ọkùnrin Ni Kristi”

“Orí gbogbo ọkùnrin ni Kristi.”​—1 KỌ́R. 11:3.

ORIN 12 Jèhófà, Ọlọ́run Atóbilọ́lá

OHUN TÁ A MÁA JÍRÒRÒ *

1. Àwọn nǹkan wo ló lè mú kí ọkùnrin kan lo ipò orí rẹ̀ lọ́nà tí kò tọ́?

KÍ LO rò pé ó túmọ̀ sí tá a bá pe ẹnì kan ní olórí ìdílé? Àwọn ọkùnrin kan ti jẹ́ kí àṣà ìbílẹ̀ wọn tàbí bí wọ́n ṣe tọ́ wọn dàgbà nípa lórí ọwọ́ tí wọ́n fi mú ìyàwó àtàwọn ọmọ wọn. Ẹ gbọ́ ohun tí Arábìnrin Yanita tó ń gbé ní Yúróòpù sọ. Ó ní: “Lágbègbè wa, ojú ẹrú lásánlàsàn làwọn ọkùnrin fi máa ń wo àwa obìnrin, wọ́n sì gbà pé obìnrin ò yẹ lẹ́ni tá à ń pọ́n lé.” Bákan náà, Arákùnrin Luke tó ń gbé lórílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà sọ pé, “Àwọn bàbá kan máa ń sọ fún àwọn ọmọkùnrin wọn pé kò sọ́gbọ́n nínú ọ̀rọ̀ àwọn obìnrin, torí náà ọ̀rọ̀ wọn ò tà.” Bó ti wù kó rí, àwọn èrò yìí ò tọ́, Jèhófà ò sì fẹ́ káwọn ọkùnrin máa fi irú ojú burúkú bẹ́ẹ̀ wo àwọn obìnrin. (Fi wé Máàkù 7:13.) Torí náà, báwo ni ọkùnrin kan ṣe lè lo ipò orí ẹ̀ lọ́nà tó dáa?

2. Kí ni olórí ìdílé kan gbọ́dọ̀ mọ̀, kí sì nìdí?

2 Kí ọkùnrin kan tó lè lo ipò orí ẹ̀ lọ́nà tó dáa nínú ìdílé, ó gbọ́dọ̀ lóye ohun tí Jèhófà fẹ́ kóun ṣe. Yàtọ̀ síyẹn, ó tún yẹ kó mọ ìdí tí Jèhófà fi ṣètò pé kóun jẹ́ olórí ìdílé àti ní pàtàkì bóun ṣe lè fara wé Jèhófà àti Jésù. Kí nìdí tá a fi sọ bẹ́ẹ̀? Ìdí ni pé Jèhófà ti fún àwọn olórí ìdílé ní àṣẹ nínú ìdílé wọn, ó sì fẹ́ kí wọ́n lò ó bó ṣe tọ́ àti bó ṣe yẹ.​—Lúùkù 12:48b.

OHUN TÍ IPÒ ORÍ TÚMỌ̀ SÍ

3. Kí ni 1 Kọ́ríńtì 11:3 sọ nípa ipò orí?

3 Ka 1 Kọ́ríńtì 11:3. Ẹsẹ Ìwé Mímọ́ yìí jẹ́ ká rí bí Jèhófà ṣe ṣètò ìdílé rẹ̀ lọ́run àti láyé. Torí pé Jèhófà ni Ẹlẹ́dàá, òun ló ní gbogbo àṣẹ láyé àti lọ́run. Jèhófà wá ṣètò ipò orí, ó sì fún àwọn kan ní àṣẹ, àmọ́ àwọn tó fún láṣẹ yìí máa jíhìn fún un. (Róòmù 14:10; Éfé. 3:​14, 15) Bí àpẹẹrẹ, Jèhófà fún Jésù ní àṣẹ lórí ìjọ, àmọ́ Jésù máa jíhìn fún Jèhófà nípa ọwọ́ tó fi mú wa. (1 Kọ́r. 15:27) Yàtọ̀ síyẹn, Jèhófà tún fún ọkọ ní àṣẹ lórí ìyàwó àtàwọn ọmọ rẹ̀, àmọ́ ọkọ náà máa jíhìn fún Jèhófà àti Jésù nípa ọwọ́ tó fi mú ìdílé rẹ̀.​—1 Pét. 3:7.

4. Àṣẹ wo ni Jèhófà àti Jésù ní?

4 Torí pé Jèhófà ni Ẹni Gíga Jù Lọ láyé àti lọ́run, ó láṣẹ láti fún àwa ọmọ rẹ̀ ní òfin nípa bó ṣe yẹ ká máa hùwà kó sì rí i dájú pé a pa àwọn òfin náà mọ́. (Àìsá. 33:22) Torí pé Jésù ni orí ìjọ, òun náà láṣẹ láti ṣe òfin kó sì rí i pé a pa òfin náà mọ́.​—Gál. 6:2; Kól. 1:​18-20.

5. Àṣẹ wo ni olórí ìdílé ní, ibo làṣẹ náà sì mọ?

5 Bíi ti Jèhófà àti Jésù, olórí ìdílé kan ní àṣẹ láti ṣèpinnu fún ìdílé rẹ̀. (Róòmù 7:2; Éfé. 6:4) Àmọ́, ó níbi tí àṣẹ ẹ̀ mọ. Bí àpẹẹrẹ, àwọn ìlànà tó wà nínú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run ló yẹ kó máa tẹ̀ lé tó bá fẹ́ ṣèpinnu. (Òwe 3:​5, 6) Yàtọ̀ síyẹn, olórí ìdílé kan kò láṣẹ láti ṣòfin fún àwọn tí kò sí nínú ìdílé ẹ̀. (Róòmù 14:4) Bákan náà, tí àwọn ọmọkùnrin tàbí àwọn ọmọbìnrin rẹ̀ bá ti dàgbà, tí wọ́n sì ti wà láyè ara wọn, kò láṣẹ lórí wọn mọ́.​—Mát. 19:5.

KÍ NÌDÍ TÍ JÈHÓFÀ FI ṢÈTÒ IPÒ ORÍ?

6. Kí nìdí tí Jèhófà fi ṣètò ipò orí?

6 Ìfẹ́ tí Jèhófà ní fún àwa tá a wà nínú ìdílé rẹ̀ ló mú kó ṣètò ipò orí, ó sì mọ̀ pé ó máa ṣe wá láǹfààní. Kí nìdí? Ìdí ni pé ipò orí yìí ló mú kí àwa tá a wà nínú ìdílé Jèhófà wà lálàáfíà kí nǹkan sì máa lọ létòlétò. (1 Kọ́r. 14:​33, 40) Tí ò bá sí àwọn tó ń múpò iwájú, nǹkan máa rí rúdurùdu, a ò sì ní láyọ̀. Bí àpẹẹrẹ, tí kò bá sí àwọn tó ń múpò iwájú, a ò ní mọ àwọn tó yẹ kó ṣe ìpinnu, a ò sì ní mọ àwọn tó yẹ kó ṣiṣẹ́ lórí ìpinnu náà.

7. Kí ni Éfésù 5:​25, 28 sọ tó jẹ́ ká mọ ọwọ́ tí Jèhófà fẹ́ káwọn ọkọ máa fi mú ìyàwó wọn?

7 Tí ètò tí Jèhófà ṣe pé káwọn ọkùnrin jẹ́ olórí ìdílé bá ń ṣeni láǹfààní lóòótọ́, kí nìdí tó fi ń ṣe ọ̀pọ̀ obìnrin bíi pé àwọn ọkọ wọn ń jẹ gàba lé wọn lórí, wọ́n sì ń fojú pọ́n wọn? Ìdí ni pé ọ̀pọ̀ ọkùnrin ni kì í tẹ̀ lé àwọn ìlànà Jèhófà nípa bó ṣe yẹ kí wọ́n bójú tó ìdílé wọn, kàkà bẹ́ẹ̀ àṣà ìbílẹ̀ wọn ni wọ́n ń tẹ̀ lé. Wọ́n tún máa ń le koko mọ́ àwọn ìyàwó wọn láti fi hàn pé àwọn ni olórí ìdílé. Bí àpẹẹrẹ, ọkọ kan lè máa jẹ gàba lórí ìyàwó ẹ̀ torí ó fẹ́ káwọn èèyàn gbà pé ọkùnrin lòun tàbí torí pé kò fẹ́ kí wọ́n máa fojú “gbẹ̀wù dání” wo òun. Ó lè ronú pé òun ò lè fipá mú ìyàwó òun láti nífẹ̀ẹ́ òun, àmọ́ òun lè mú kó máa bẹ̀rù òun, á sì tipa bẹ́ẹ̀ máa darí ẹ̀ bó ṣe wù ú. * Ṣe ló yẹ kí àwọn ọkọ máa bọlá kí wọ́n sì máa buyì kún ìyàwó wọn. Àmọ́ tí ọkọ kan bá ń hùwà burúkú sí ìyàwó ẹ̀, ohun tó ń ṣe lòdì sí ìlànà Jèhófà.​—Ka Éfésù 5:​25, 28.

BÍ ỌKỌ KAN ṢE LÈ JẸ́ OLÓRÍ ÌDÍLÉ GIDI

8. Báwo ni ọkùnrin kan ṣe lè jẹ́ olórí ìdílé gidi?

8 Ọkùnrin kan lè jẹ́ olórí ìdílé gidi tó bá ń fara wé bí Jèhófà àti Jésù ṣe ń lo àṣẹ tí wọ́n ní. Ẹ jẹ́ ká wo bí Jèhófà àti Jésù ṣe ń fi ẹ̀mí ìrẹ̀lẹ̀ àti ìfẹ́ lo ọlá àṣẹ tí wọ́n ní. Lẹ́yìn náà, a máa rí bí olórí ìdílé kan ṣe lè fàwọn ànímọ́ yìí sílò nínú bó ṣe ń bá ìyàwó àtàwọn ọmọ rẹ̀ lò.

9. Báwo ni Jèhófà ṣe ń fi ẹ̀mí ìrẹ̀lẹ̀ hàn?

9 Ẹ̀mí ìrẹ̀lẹ̀. Jèhófà ló gbọ́n jù láyé àti lọ́run, síbẹ̀ ó máa ń fetí sí àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀. (Jẹ́n. 18:​23, 24, 32) Ó máa ń jẹ́ káwọn tó wà lábẹ́ ẹ̀ sọ èrò wọn. (1 Ọba 22:​19-22) Ẹni pípé ni Jèhófà, àmọ́ kò retí pé ká máa ṣe nǹkan lọ́nà pípé. Dípò bẹ́ẹ̀, ó máa ń ran àwa ìránṣẹ́ rẹ̀ tá a jẹ́ aláìpé lọ́wọ́ ká lè ṣàṣeyọrí. (Sm. 113:​6, 7) Kódà, Bíbélì pe Jèhófà ní “olùrànlọ́wọ́.” (Sm. 27:9; Héb. 13:6) Ọba Dáfídì gbà pé ẹ̀mí ìrẹ̀lẹ̀ tí Jèhófà ní ló mú kóun ṣàṣeyọrí lẹ́nu iṣẹ́ tó gbé fún òun.​—2 Sám. 22:36.

10. Báwo ni Jésù ṣe fi ẹ̀mí ìrẹ̀lẹ̀ hàn?

10 Ẹ jẹ́ ká wo àpẹẹrẹ Jésù. Bó tiẹ̀ jẹ́ pé òun ni Olúwa àti Aṣáájú fáwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀, ó fọ ẹsẹ̀ wọn. Kí nìdí tí Jèhófà fi jẹ́ kí àkọsílẹ̀ yìí wà nínú Bíbélì? Ìdí ni pé ó fẹ́ kí àwọn olórí ìdílé àtàwọn míì rí àpẹẹrẹ tí wọ́n á máa tẹ̀ lé. Jésù sọ pé: “Mo fi àpẹẹrẹ lélẹ̀ fún yín pé, bí mo ṣe ṣe fún yín gẹ́lẹ́ ni kí ẹ̀yin náà máa ṣe.” (Jòh. 13:​12-17) Bó tiẹ̀ jẹ́ pé Jésù lẹnì kejì tó láṣẹ jù láyé àti lọ́run, kò retí pé káwọn èèyàn ṣe ìránṣẹ́ fún òun, dípò bẹ́ẹ̀ òun ló ṣe ìránṣẹ́ fún wọn.​—Mát. 20:28.

Olórí ìdílé kan lè fi hàn pé òun lẹ́mìí ìrẹ̀lẹ̀ àti ìfẹ́ tó bá ń bá ìyàwó ẹ̀ ṣiṣẹ́ ilé tó sì ń pèsè ohun tí ìdílé ẹ̀ nílò nípa tẹ̀mí (Wo ìpínrọ̀ 11, 13)

11. Báwo ni olórí ìdílé kan ṣe lè fi ẹ̀mí ìrẹ̀lẹ̀ hàn bíi ti Jèhófà àti Jésù?

11 Ohun tá a rí kọ́. Onírúurú ọ̀nà ni olórí ìdílé kan lè gbà fi ẹ̀mí ìrẹ̀lẹ̀ hàn. Bí àpẹẹrẹ, kì í retí pé kí ìyàwó tàbí àwọn ọmọ òun máa ṣe nǹkan lọ́nà tó pé tàbí kí wọ́n má ṣàṣìṣe. Ó máa ń fetí sí èrò àwọn tó wà nínú ìdílé ẹ̀, kódà tí èrò wọn bá yàtọ̀ sí tiẹ̀. Arábìnrin Marley tó ń gbé lórílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà sọ pé: “Nígbà míì, èmi àti ọkọ mi máa ń ní èrò tó yàtọ̀ síra, àmọ́ mo mọ̀ pé ó mọyì mi, ó sì máa ń bọ̀wọ̀ fún mi torí pé ó máa ń béèrè ohun tí mo rò, ó sì máa ń ronú lé e kó tó ṣèpinnu.” Yàtọ̀ síyẹn, ọkọ kan tó lẹ́mìí ìrẹ̀lẹ̀ máa ń bá ìyàwó rẹ̀ ṣiṣẹ́ ilé, kódà bí àwọn tó wà ládùúgbò bá ka irú iṣẹ́ bẹ́ẹ̀ sí iṣẹ́ obìnrin. Lóòótọ́ ó lè má rọrùn. Kí nìdí? Arábìnrin kan tó ń jẹ́ Rachel sọ pé: “Lágbègbè wa, tí ọkọ kan bá ń fọbọ́ tàbí tó ń gbálẹ̀, àwọn ẹbí àtàwọn aládùúgbò máa ń sọ pé obìnrin náà ti sọ ọkọ ẹ̀ di ‘gbẹ̀wù dání,’ wọ́n tiẹ̀ lè máa sọ pé bóyá ìyàwó ẹ̀ ti fún un ní nǹkan jẹ àti pé ó ti di ẹrú ìyàwó ẹ̀.” Tó bá jẹ́ pé irú èrò yìí làwọn èèyàn ní ládùúgbò rẹ, rántí pé Jésù fọ ẹsẹ̀ àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ bó tiẹ̀ jẹ́ pé àwọn ẹrú ló máa ń ṣe iṣẹ́ yìí. Kì í ṣe bí olórí ìdílé kan ṣe máa gbayì lójú ẹbí àti aládùúgbò ló yẹ kó jẹ ẹ́ lọ́kàn, bí kò ṣe bó ṣe máa mú inú ìyàwó àti àwọn ọmọ rẹ̀ dùn. Yàtọ̀ sí ẹ̀mí ìrẹ̀lẹ̀, báwo ni ìfẹ́ ṣe lè mú kí ọkọ kan jẹ́ olórí ìdílé gidi?

12. Kí ni ìfẹ́ mú kí Jèhófà àti Jésù ṣe?

12 Ìfẹ́. Ìfẹ́ ló ń mú kí Jèhófà ṣe gbogbo ohun tó ń ṣe. (1 Jòh. 4:​7, 8) Torí pé ó nífẹ̀ẹ́ wa, ó ń lo Bíbélì Ọ̀rọ̀ rẹ̀ àti ètò rẹ̀ láti pèsè àwọn nǹkan tá a nílò nípa tẹ̀mí. Ìgbà gbogbo ló máa ń fi dá wa lójú pé òun nífẹ̀ẹ́ wa, ìyẹn sì máa ń fi wá lọ́kàn balẹ̀. Àwọn nǹkan tá a nílò nípa tara ńkọ́? Bíbélì sọ pé Jèhófà “ń pèsè gbogbo ohun tí à ń gbádùn fún wa lọ́pọ̀ rẹpẹtẹ.” (1 Tím. 6:17) Tá a bá ṣàṣìṣe, ó máa ń bá wa wí, àmọ́ kì í pa wá tì. Ìfẹ́ tó ní ló mú kó pèsè ìràpadà fún wa. Jésù náà nífẹ̀ẹ́ wa gan-an débi pé ó fẹ̀mí ẹ̀ lélẹ̀ fún wa. (Jòh. 3:16; 15:13) Kò sí ohunkóhun tó lè mú kí Jèhófà àti Jésù má nífẹ̀ẹ́ àwọn tó jẹ́ olóòótọ́.​—Jòh. 13:1; Róòmù 8:​35, 38, 39.

13. Kí nìdí tó fi ṣe pàtàkì pé kí olórí ìdílé máa fìfẹ́ hàn sí ìdílé rẹ̀? (Tún wo àpótí náà “ Ohun Tí Ọkùnrin Tó Ṣẹ̀sẹ̀ Gbéyàwó Lè Ṣe Tí Ìyàwó Rẹ̀ Á Fi Máa Bọ̀wọ̀ Fún Un”)

13 Ohun tá a rí kọ́. Ìfẹ́ ló yẹ kó máa mú olórí ìdílé kan ṣe gbogbo ohun tó bá ń ṣe. Kí nìdí tí ìyẹn fi ṣe pàtàkì? Àpọ́sítélì Jòhánù sọ pé: “Ẹni tí kò nífẹ̀ẹ́ arákùnrin [tàbí ìdílé] rẹ̀ tó rí, kò lè nífẹ̀ẹ́ Ọlọ́run tí kò rí.” (1 Jòh. 4:​11, 20) Ọkùnrin tó nífẹ̀ẹ́ ìdílé rẹ̀ máa fara wé Jèhófà àti Jésù, á máa pèsè fún wọn nípa tara àti nípa tẹ̀mí, á sì máa ṣe ohun táá fi wọ́n lọ́kàn balẹ̀. (1 Tím. 5:8) Yàtọ̀ síyẹn, á máa kọ́ àwọn ọmọ rẹ̀, á sì máa bá wọn wí. Bákan náà, á máa ṣe ìpinnu táá mú inú Jèhófà dùn táá sì ṣe ìdílé ẹ̀ láǹfààní. Ní báyìí, ẹ jẹ́ ká jíròrò bí olórí ìdílé kan ṣe lè ṣe àwọn nǹkan yìí, kó sì fara wé Jèhófà àti Jésù.

OHUN TÓ YẸ KÍ OLÓRÍ ÌDÍLÉ MÁA ṢE

14. Báwo ni olórí ìdílé kan ṣe lè pèsè ohun tí ìdílé rẹ̀ nílò nípa tẹ̀mí?

14 Ó máa ń pèsè ohun tí ìdílé rẹ̀ nílò nípa tẹ̀mí. Bíi ti Jèhófà, Jésù máa ń pèsè ohun tí àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ nílò nípa tẹ̀mí. (Mát. 5:​3, 6; Máàkù 6:34) Lọ́nà kan náà, ohun tó yẹ kó jẹ olórí ìdílé kan lógún jù ni bó ṣe máa mú kí ìdílé rẹ̀ túbọ̀ sún mọ́ Jèhófà. (Diu. 6:​6-9) Kíyẹn lè ṣeé ṣe, ó máa ń rí i pé òun àti ìdílé òun jọ máa ń kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, wọ́n jọ ń lọ sípàdé, wọ́n jọ ń lọ́wọ́ nínú iṣẹ́ ìwàásù, wọ́n sì ní àjọṣe tó dáa pẹ̀lú Jèhófà.

15. Kí ni olórí ìdílé kan lè ṣe táá mú kí ara tu ìdílé rẹ̀?

15 Ó máa ń ṣe ohun táá mú kí ara tu ìdílé rẹ̀. Ìṣojú àwọn èèyàn ni Jèhófà ti sọ pé òun nífẹ̀ẹ́ Jésù. (Mát. 3:17) Bákan náà, ọ̀pọ̀ ìgbà ni Jésù máa ń sọ fáwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ pé òun nífẹ̀ẹ́ wọn, ó tún máa ń fi hàn nínú ìwà rẹ̀, ìyẹn sì mú káwọn náà máa fìfẹ́ hàn sí i. (Jòh. 15:​9, 12, 13; 21:16) Olórí ìdílé kan lè fi hàn nínú ìṣe ẹ̀ pé òun nífẹ̀ẹ́ ìyàwó àtàwọn ọmọ òun. Ọ̀nà kan tó sì lè gbà ṣe bẹ́ẹ̀ ni pé kí wọ́n jọ máa kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. Ó tún yẹ kó máa sọ fún wọn pé òun nífẹ̀ẹ́ wọn, òun sì mọyì wọn. Kódà, ó lè ṣe bẹ́ẹ̀ níṣojú àwọn míì.​—Òwe 31:​28, 29.

Tí olórí ìdílé kan bá máa múnú Jèhófà dùn, ó gbọ́dọ̀ máa pèsè ohun tí ìdílé ẹ̀ nílò nípa tara (Wo ìpínrọ̀ 16)

 

16. Kí ló tún yẹ kí olórí ìdílé kan ṣe, àmọ́ kí ni ò gbọ́dọ̀ ṣe?

16 Ó máa ń pèsè ohun tí ìdílé rẹ̀ nílò nípa tara. Jèhófà pèsè gbogbo ohun tí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì nílò kódà ní àsìkò tí wọ́n ń jìyà torí àìgbọràn wọn. (Diu. 2:7; 29:5) Ó máa ń pèsè àwọn nǹkan táwa náà nílò lónìí. (Mát. 6:​31-33; 7:11) Bíi ti Jèhófà, Jésù náà pèsè fáwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀. (Mát. 14:​17-20) Yàtọ̀ síyẹn, ó tún mú àwọn aláìsàn lára dá. (Mát. 4:24) Tí olórí ìdílé kan bá fẹ́ múnú Jèhófà dùn, ó gbọ́dọ̀ pèsè ohun tí ìdílé rẹ̀ nílò nípa tara. Àmọ́ o, kò gbọ́dọ̀ ti àṣejù bọ̀ ọ́. Kò gbọ́dọ̀ jẹ́ kí iṣẹ́ oúnjẹ òòjọ́ gba àkókò òun débi pé kò ní ráyè bójú tó ìdílé rẹ̀ nípa tẹ̀mí àti láwọn ọ̀nà míì.

17. Báwo ni Jèhófà àti Jésù ṣe ń kọ́ wa, tí wọ́n sì ń bá wa wí?

17 Ó máa ń tọ́ wọn sọ́nà. Jèhófà máa ń tọ́ wa sọ́nà, ó sì máa ń bá wa wí ká lè sunwọ̀n sí i. (Héb. 12:​7-9) Bíi ti Jèhófà, Jésù náà máa ń fìfẹ́ tọ́ àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ sọ́nà. (Jòh. 15:​14, 15) Kì í fọ̀rọ̀ sábẹ́ ahọ́n sọ, síbẹ̀ kì í le koko mọ́ wọn. (Mát. 20:​24-28) Ó mọ̀ pé aláìpé ni wá àti pé a lè ṣàṣìṣe.​—Mát. 26:41.

18. Kí ni olórí ìdílé kan máa ń fi sọ́kàn?

18 Bíi ti Jèhófà àti Jésù, ó yẹ kí olórí ìdílé kan máa rántí pé aláìpé làwọn tó wà nínú ìdílé òun, wọ́n sì lè ṣàṣìṣe. Torí náà, kò ní máa bínú lódìlódì sí ìyàwó àtàwọn ọmọ rẹ̀. (Kól. 3:19) Kàkà bẹ́ẹ̀, ó máa rántí pé aláìpé ni òun náà, ìyẹn á sì mú kó “fi pẹ̀lẹ́pẹ̀lẹ́” tọ́ wọn sọ́nà bí Gálátíà 6:1 ṣe sọ. Bíi ti Jésù, ó mọ̀ pé ìwà tóun bá hù làwọn yòókù máa tẹ̀ lé.​—1 Pét. 2:21.

19-20. Báwo ni olórí ìdílé kan ṣe lè fara wé Jèhófà àti Jésù tó bá fẹ́ ṣèpinnu?

19 Ó máa ń gba tàwọn yòókù rò tó bá fẹ́ ṣèpinnu. Ìpinnu tó máa ṣe àwọn míì láǹfààní ni Jèhófà máa ń ṣe. Bí àpẹẹrẹ, kì í ṣe torí àǹfààní ara ẹ̀ ni Jèhófà ṣe dá àwọn nǹkan lọ́run àti láyé, bí kò ṣe torí àǹfààní àwọn míì. Kò sẹ́ni tó fipá mú un pé kó fi ọmọ rẹ̀ rúbọ nítorí ẹ̀ṣẹ̀ wa. Kàkà bẹ́ẹ̀, ṣe ló fínúfíndọ̀ yọ̀ǹda ẹ̀ ká lè rí ìyè. Ìpinnu tó máa ṣe àwọn míì láǹfààní ni Jésù náà máa ń ṣe. (Róòmù 15:3) Bí àpẹẹrẹ, ìgbà kan wà tó rẹ̀ ẹ́ tó sì fẹ́ sinmi, àmọ́ kò ṣe bẹ́ẹ̀ kó lè kọ́ àwọn èèyàn ní òtítọ́ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run.​—Máàkù 6:​31-34.

20 Olórí ìdílé kan mọ̀ pé, ó ṣe pàtàkì kóun ṣe àwọn ìpinnu tó bọ́gbọ́n mu tó sì máa ṣe ìdílé òun láǹfààní, kì í sì í fi ọwọ́ kékeré mú ojúṣe náà. Kì í ṣèpinnu torí bí nǹkan ṣe rí lára ẹ̀. Kàkà bẹ́ẹ̀, ó máa ń ronú jinlẹ̀ dáadáa, ó sì máa ń jẹ́ kí Jèhófà tọ́ òun sọ́nà. * (Òwe 2:​6, 7) Nípa bẹ́ẹ̀, kì í ṣe tara ẹ̀ nìkan ló máa rò tó bá fẹ́ ṣèpinnu, á ronú nípa bó ṣe máa ṣe àwọn míì láǹfààní.​—Fílí. 2:4.

21. Kí la máa jíròrò nínú àpilẹ̀kọ tó kàn?

21 Iṣẹ́ ńlá ni Jèhófà gbé fún àwọn olórí ìdílé, wọ́n á sì jíhìn bí wọ́n ṣe bójú tó ìdílé wọn. Bó ti wù kó rí, bí ọkọ kan bá tẹ̀ lé àpẹẹrẹ Jèhófà àti Jésù, ó máa ṣe iṣẹ́ náà láṣeyọrí. Bí ìyàwó náà bá sì ṣe ojúṣe ẹ̀ bó ṣe yẹ, ìdílé wọn á láyọ̀. Báwo ni aya kan ṣe lè fọwọ́ sowọ́ pọ̀ pẹ̀lú ọkọ rẹ̀ tó jẹ́ olórí ìdílé, kí ló sì lè mú kó ṣòro fún un? A máa rí ìdáhùn nínú àpilẹ̀kọ tó kàn.

ORIN 16 Ẹ Yin Jáà Nítorí Ọmọ Rẹ̀ Tó Fòróró Yàn

^ ìpínrọ̀ 5 Ọjọ́ tí ọkùnrin kan bá gbéyàwó ló di olórí ìdílé. Torí náà, nínú àpilẹ̀kọ yìí, a máa jíròrò ohun tó túmọ̀ sí láti jẹ́ olórí ìdílé, àá mọ ìdí tí Jèhófà fi ṣe ètò yìí àti ohun táwọn olórí ìdílé lè kọ́ lára Jèhófà àti Jésù. Nínú àpilẹ̀kọ kejì, a máa jíròrò ohun tí tọkọtaya lè kọ́ lára Jésù àtàwọn àpẹẹrẹ míì nínú Bíbélì. Nínú àpilẹ̀kọ kẹta, a máa sọ̀rọ̀ nípa ipò orí nínú ìjọ.

^ ìpínrọ̀ 7 Nínú ọ̀pọ̀ fíìmù, eré orí ìtàgé tàbí ìwé, wọ́n sábà máa ń jẹ́ kó dà bíi pé kò sóhun tó burú nínú kí ọkùnrin máa jẹ gàba lé ìyàwó ẹ̀ lórí, kó máa bú u tàbí kó máa lù ú. Nípa bẹ́ẹ̀, ọ̀pọ̀ èèyàn gbà pé kò sóhun tó burú tí ọkọ kan bá ń ṣe bẹ́ẹ̀ sí ìyàwó ẹ̀.

^ ìpínrọ̀ 20 Tó o bá fẹ́ mọ̀ sí i nípa bó o ṣe lè ṣèpinnu tó dáa, wo àpilẹ̀kọ náà “Ẹ Máa Ṣe Ìpinnu Tó Máa Gbé Orúkọ Ọlọ́run Ga” nínú Ilé Ìṣọ́ April 15, 2011, ojú ìwé 13-17.