Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

ÀPILẸ̀KỌ FÚN ÌKẸ́KỌ̀Ọ́ 6

“Orí Obìnrin Ni Ọkùnrin”

“Orí Obìnrin Ni Ọkùnrin”

“Orí obìnrin ni ọkùnrin.”​—1 KỌ́R. 11:3.

ORIN 13 Kristi, Àwòkọ́ṣe Wa

OHUN TÁ A MÁA JÍRÒRÒ *

1. Àwọn ìbéèrè wo ló yẹ kí arábìnrin kan tí ò tíì lọ́kọ bi ara ẹ̀ kó tó yan ẹni tó máa fẹ́?

ABẸ́ Jésù Kristi tó jẹ́ ẹni pípé ni gbogbo àwa Kristẹni wà. Àmọ́, tí arábìnrin kan bá ṣègbéyàwó, abẹ́ ọkọ tó jẹ́ aláìpé ló máa wà, ìyẹn kì í sì í rọrùn. Torí náà, tó bá ń ronú nípa ẹni tó máa fẹ́, ó yẹ kó bi ara ẹ̀ láwọn ìbéèrè yìí: ‘Kí ló fi hàn pé arákùnrin yìí máa jẹ́ olórí ìdílé gidi? Ṣé ìjọsìn Jèhófà ló gbawájú nígbèésí ayé ẹ̀? Tí kò bá fọwọ́ gidi mú ìjọsìn Jèhófà, báwo ni mo ṣe mọ̀ pé ó máa jẹ́ olórí ìdílé gidi lẹ́yìn tá a bá fẹ́ra?’ Síbẹ̀, ó yẹ kí arábìnrin náà bi ara ẹ̀ pé: ‘Ṣé èmi náà ní àwọn ànímọ́ táá jẹ́ kí ìgbéyàwó wa yọrí sí rere? Ṣé mo máa ń mú sùúrù, ṣé mo sì lawọ́? Ṣé mo ní àjọṣe tó dáa pẹ̀lú Jèhófà?’ (Oníw. 4:​9, 12) Àwọn ìpinnu tí obìnrin kan bá ṣe kó tó ṣègbéyàwó ló máa jẹ́ kó mọ̀ bóyá ìgbéyàwó ẹ̀ á ládùn á sì lóyin.

2. Kí la máa jíròrò nínú àpilẹ̀kọ yìí?

2 Àpẹẹrẹ àtàtà ni ẹgbẹẹgbẹ̀rún àwọn arábìnrin wa tí wọ́n ti ṣègbéyàwó jẹ́ ní ti pé wọ́n ń fi ara wọn sábẹ́ àwọn ọkọ wọn. Tẹ̀gàn ni hẹ̀, ó yẹ ká gbóríyìn fún wọn! Inú wa ń dùn bá a ṣe ń sin Jèhófà pẹ̀lú àwọn arábìnrin wa olóòótọ́ yìí! Nínú àpilẹ̀kọ yìí, a máa dáhùn àwọn ìbéèrè mẹ́ta yìí: (1) Kí ni díẹ̀ lára ìṣòro táwọn aya máa ń ní? (2) Kí nìdí tó fi yẹ káwọn aya máa fi ara wọn sábẹ́ àwọn ọkọ wọn? (3) Tó bá di pé ká bọ̀wọ̀ fúnni ká sì ṣègbọràn, kí làwọn tọkọtaya lè kọ́ látinú àpẹẹrẹ Jésù, Ábígẹ́lì àti Màríà ìyá Jésù?

ÌṢÒRO WO LÀWỌN AYA MÁA Ń NÍ?

3. Kí nìdí tó fi jẹ́ pé kò sí ìgbéyàwó tí kò ní ìṣòro tiẹ̀?

3 Jèhófà ló fi ìgbéyàwó jíǹkí wa, ẹ̀bùn tí ò lábùkù sì ni. Àmọ́, aláìpé làwa èèyàn. (1 Jòh. 1:8) Ìdí nìyẹn tí Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run fi kìlọ̀ fún àwọn tọkọtaya pé wọ́n máa ní “ìpọ́njú nínú ara wọn.” (1 Kọ́r. 7:28) Ẹ jẹ́ ká sọ díẹ̀ lára ìṣòro táwọn aya máa ń ní.

4. Kí ló lè mú kí aya kan máa ronú pé ó bu òun kù tí òun bá ń fi ara òun sábẹ́ ọkọ òun?

4 Nígbà míì, ibi tí obìnrin kan ti wá àti bí wọ́n ṣe tọ́ ọ dàgbà lè mú kó máa ronú pé àbùkù ni tóun bá fara òun sábẹ́ ọkọ òun. Arábìnrin Marisol tó ń gbé lórílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà sọ pé: “Níbi tí mo dàgbà sí, ohun tí wọ́n sábà máa ń sọ ni pé ohun tí ọkùnrin lè ṣe, obìnrin náà lè ṣe é àti pé ọkùnrin ò ju obìnrin lọ. Mo mọ̀ pé Jèhófà ló fi àwọn ọkọ ṣe olórí ìdílé àti pé ó yẹ káwa aya máa fi ara wa sábẹ́ àwọn ọkọ wa, síbẹ̀ ó fẹ́ káwọn ọkọ máa pọ́n àwọn aya wọn lé, kí wọ́n sì máa bọ̀wọ̀ fún wọn. Àmọ́ kì í ṣe ìgbà gbogbo ló máa ń rọrùn fún mi láti ṣègbọràn sí ọkọ mi torí ibi tá à ń gbé.”

5. Èrò tí ò tọ́ wo làwọn ọkùnrin kan ní nípa àwọn obìnrin?

5 Lọ́wọ́ kejì, obìnrin kan lè ní ọkọ tó gbà pé àwọn obìnrin ò já mọ́ nǹkan kan. Arábìnrin Ivon tó ń gbé ní South America sọ pé: “Ládùúgbò wa, àwọn ọkùnrin ló máa ń kọ́kọ́ jẹun, ẹ̀yìn tí wọ́n bá jẹun tán làwọn obìnrin máa jẹun. Àwọn ọmọbìnrin ló máa ń se oúnjẹ, tí wọ́n sì máa ń tún ilé ṣe. Àmọ́, ibi tí ọmọkùnrin kan bá jókòó gẹlẹtẹ sí ni màmá ẹ̀ àtàwọn ẹ̀gbọ́n tàbí àbúrò ẹ̀ tó jẹ́ obìnrin ti máa wá gbé oúnjẹ fún un. Yàtọ̀ síyẹn, wọ́n tún máa ń sọ fún wọn pé àwọn ni ‘ọ̀gá ilé.’ ” Arábìnrin Yingling tó ń gbé nílẹ̀ Éṣíà sọ pé: “Ní èdè wa, ọ̀rọ̀ kan wà tí wọ́n máa ń sọ tó fi hàn pé kò pọn dandan kí obìnrin ní làákàyè tàbí ẹ̀bùn èyíkéyìí. Tiwọn ò ju pé kí wọ́n máa ṣiṣẹ́ ilé, kódà wọn ò lẹ́tọ̀ọ́ láti sọ èrò wọn fún ọkọ wọn.” Irú àwọn nǹkan yìí ò fìfẹ́ hàn, kò sì bá Bíbélì mu. Tí ọkọ kan bá ń ṣe bẹ́ẹ̀, kò ní fara wé Jésù, á máa fayé ni ìyàwó ẹ̀ lára, kò sì ní múnú Jèhófà dùn.​—Éfé. 5:​28, 29; 1 Pét. 3:7.

6. Kí ló yẹ káwọn aya máa ṣe kí wọ́n lè túbọ̀ ní àjọṣe tó dáa pẹ̀lú Jèhófà?

6 Bá a ṣe sọ nínú àpilẹ̀kọ tó ṣáájú, Jèhófà fẹ́ káwọn ọkọ máa pèsè ohun tí ìdílé wọn nílò nípa tẹ̀mí àti nípa tara, kí wọ́n sì mú kára tù wọ́n. (1 Tím. 5:8) Síbẹ̀, ó yẹ kí àwọn arábìnrin tó ti ṣègbéyàwó máa wáyè láti ka Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run lójoojúmọ́, kí wọ́n máa ronú lé ohun tí wọ́n kà, kí wọ́n sì máa gbàdúrà látọkàn wá. Àmọ́, ó lè má rọrùn nígbà míì. Kí nìdí? Ìdí ni pé ọwọ́ àwọn aya sábà máa ń dí, wọ́n sì lè ronú pé àwọn ò ráyè tàbí pé ó ti rẹ àwọn jù láti kẹ́kọ̀ọ́. Bó ti wù kó rí, ó ṣe pàtàkì kí wọ́n máa ṣe bẹ́ẹ̀. Kí nìdí? Ìdí ni pé Jèhófà fẹ́ kí gbogbo wa ní àjọṣe tó dáa pẹ̀lú òun, ká má sì jẹ́ kí ohunkóhun ba àjọṣe náà jẹ́.​—Ìṣe 17:27.

7. Kí ló máa mú kó rọrùn fún aya kan láti fi ara ẹ̀ sábẹ́ ọkọ ẹ̀?

7 Ká sòótọ́, ó máa gba ìsapá kí aya kan tó lè fi ara ẹ̀ sábẹ́ ọkọ ẹ̀ tó jẹ́ aláìpé. Àmọ́, ó máa rọrùn fún un láti ṣe bẹ́ẹ̀ tó bá mọ ìdí tí Jèhófà fi sọ pé kó fi ara ẹ̀ sábẹ́ ọkọ ẹ̀, tó sì gbà bẹ́ẹ̀.

KÍ NÌDÍ TÓ FI YẸ KÍ AYA FI ARA Ẹ̀ SÁBẸ́ ỌKỌ Ẹ̀?

8. Bó ṣe wà nínú Éfésù 5:​22-24, kí nìdí tí àwọn aya fi ń fi ara wọn sábẹ́ àwọn ọkọ wọn?

8 Ìdí pàtàkì tí àwọn aya fi ń fi ara wọn sábẹ́ àwọn ọkọ wọn ni pé Jèhófà ló pàṣẹ pé kí wọ́n ṣe bẹ́ẹ̀. (Ka Éfésù 5:​22-24.) Wọ́n fọkàn tán Jèhófà Baba wọn ọ̀run torí wọ́n mọ̀ pé ó nífẹ̀ẹ́ àwọn, kò sì ní sọ pé káwọn ṣe ohunkóhun tó máa pa àwọn lára.​—Diu. 6:24; 1 Jòh. 5:3.

9. Kí ló máa ṣẹlẹ̀ tí arábìnrin kan bá ń bọ̀wọ̀ fún ọkọ rẹ̀ bí Jèhófà ṣe pa láṣẹ?

9 Nínú ayé, àwọn èèyàn ò ka ìlànà Ọlọ́run sí, wọ́n sì gbà pé òmùgọ̀ ni obìnrin tó bá ń fi ara ẹ̀ sábẹ́ ọkọ rẹ̀. Ohun kan ni pé àwọn tó ń tan irú èrò yìí kálẹ̀ ò mọ Jèhófà Ọlọ́run onífẹ̀ẹ́ torí pé Jèhófà ò ní sọ fún àwọn ọmọbìnrin rẹ̀ ọ̀wọ́n pé kí wọ́n ṣe ohunkóhun tó máa bù wọ́n kù. Arábìnrin kan tó bá ń sapá láti fi ara ẹ̀ sábẹ́ ọkọ ẹ̀ bí Jèhófà ti ṣètò máa mú kí àlàáfíà wà nínú ìdílé rẹ̀. (Sm. 119:165) Nípa bẹ́ẹ̀, òun àti ọkọ ẹ̀ títí kan àwọn ọmọ wọn ló máa ṣe láǹfààní.

10. Kí la kọ́ látinú ohun tí Arábìnrin Carol sọ?

10 Obìnrin tó bá ń fi ara ẹ̀ sábẹ́ ọkọ ẹ̀ tó jẹ́ aláìpé fi hàn pé òun nífẹ̀ẹ́ Jèhófà tó ṣètò ipò orí, òun sì bọ̀wọ̀ fún un. Arábìnrin Carol tó ń gbé ní South America sọ pé: “Mo mọ̀ pé ọkọ mi lè ṣàṣìṣe, àmọ́ ohun tí mo bá ṣe nígbà tí ọkọ mi ṣàṣìṣe máa jẹ́ kí n mọ bí àjọṣe mi pẹ̀lú Jèhófà ṣe rí. Torí náà tó bá ṣàṣìṣe, mo ṣì máa ń bọ̀wọ̀ fún un torí mo fẹ́ múnú Jèhófà Baba mi dùn.”

11. Kí ló mú kí Arábìnrin Aneese máa dárí ji ọkọ rẹ̀, kí la sì kọ́ látinú ohun tó sọ?

11 Tó bá ń ṣe obìnrin kan bíi pé ọkọ ẹ̀ kì í gba tiẹ̀ rò, ó lè ṣòro fún un láti máa bọ̀wọ̀ fún ọkọ ẹ̀, kó sì fi ara ẹ̀ sábẹ́ rẹ̀. Àmọ́, ẹ jẹ́ ká gbọ́ ohun tí Arábìnrin Aneese sọ pé òun máa ń ṣe tírú ẹ̀ bá ṣẹlẹ̀. Ó ní: “Mo máa ń sapá gan-an láti gbé ọ̀rọ̀ náà kúrò lọ́kàn, torí mo mọ̀ pé gbogbo wa la máa ń ṣàṣìṣe. Mo máa ń fẹ́ fara wé Jèhófà, kí n sì dárí ji ọkọ mi fàlàlà. Ìdí ni pé tí n bá ṣe bẹ́ẹ̀, ọkàn mi máa ń balẹ̀ pẹ̀sẹ̀, ara sì máa ń tù mí.” (Sm. 86:5) Tí aya kan bá ń dárí ji ọkọ ẹ̀, á rọrùn fún un láti fi ara ẹ̀ sábẹ́ ọkọ ẹ̀.

OHUN TÁ A RÍ KỌ́ LÁTINÚ ÀWỌN ÀPẸẸRẸ INÚ BÍBÉLÌ

12. Àwọn àpẹẹrẹ wo ló wà nínú Bíbélì?

12 Àwọn kan máa ń ronú pé ọ̀dẹ̀ lẹni tó bá ń fara ẹ̀ sábẹ́ ẹlòmíì. Àmọ́ irọ́ gbuu nìyẹn. Nínú Bíbélì, a rí ọ̀pọ̀ àpẹẹrẹ àwọn tó fi ara wọn sábẹ́ àwọn míì, síbẹ̀ tí Bíbélì sọ pé wọ́n jẹ́ onígboyà. Ẹ jẹ́ ká wo ohun tá a lè kọ́ lára Jésù, Ábígẹ́lì àti Màríà.

13. Kí nìdí tí Jésù ṣe fi ara ẹ̀ sábẹ́ Jèhófà? Ṣàlàyé.

13 Kì í ṣe torí pé Jésù ò gbọ́n tàbí pé kò mọ ohun tó yẹ kó ṣe ló ṣe ń fi ara ẹ̀ sábẹ́ Jèhófà. Kódà, bí Jésù ṣe kọ́ni lọ́nà tó ṣe kedere fi hàn pé òun ló gbọ́n jù nínú gbogbo àwọn tó tíì gbé lórí ilẹ̀ ayé. (Jòh. 7:​45, 46) Jèhófà mọ̀ pé Jésù kúnjú ìwọ̀n ó sì máa ń ṣiṣẹ́ kára, ìdí nìyẹn tó fi jẹ́ kí Jésù ṣiṣẹ́ pẹ̀lú òun nígbà tó ń dá gbogbo ohun tó wà lọ́run àti ayé. (Òwe 8:30; Héb. 1:​2-4) Yàtọ̀ síyẹn, àtìgbà tí Jésù ti jíǹde ni Jèhófà ti fún un ní “gbogbo àṣẹ ní ọ̀run àti ayé.” (Mát. 28:18) Bó tilẹ̀ jẹ́ pé Jésù gbọ́n gan-an, ó sì lágbára, ó ṣì fi ara ẹ̀ sábẹ́ Jèhófà. Kí nìdí? Ìdí ni pé ó nífẹ̀ẹ́ Baba rẹ̀ gan-an.​—Jòh. 14:31.

14. Kí ni àwọn ọkọ lè rí kọ́ látinú (a) ojú tí Jèhófà fi ń wo àwọn obìnrin? (b) ohun tó wà nínú Òwe orí 31?

14 Ohun táwọn ọkọ lè rí kọ́. Kì í ṣe torí pé Jèhófà ka àwọn ọkùnrin sí pàtàkì ju àwọn obìnrin lọ ló ṣe ní kí àwọn aya fi ara wọn sábẹ́ àwọn ọkọ wọn. Ó ṣe tán, àtọkùnrin àtobìnrin ni Jèhófà yàn láti jọba pẹ̀lú Jésù. (Gál. 3:​26-29) Jèhófà fi hàn pé òun fọkàn tán Jésù Ọmọ òun nígbà tó fún un ní ọlá àṣẹ. Lọ́nà kan náà, àwọn ọkọ tó gbọ́n máa ń fọkàn tán ìyàwó wọn, wọ́n sì máa ń jẹ́ kí wọ́n bójú tó àwọn nǹkan kan nínú ilé. Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run sọ ohun tí aya tó dáńgájíá máa ń ṣe, ó sọ pé ó lè bójú tó ilé, ó lè ra ilẹ̀ kó sì tà á, ó sì lè ṣòwò táá mérè wọlé. (Ka Òwe 31:​15, 16, 18.) Kì í ṣe ẹrú tí ò gbọdọ̀ sọ̀rọ̀ nínú ilé. Kàkà bẹ́ẹ̀, ọkọ ẹ̀ fọkàn tán an, ó sì máa ń tẹ́tí sí i. (Ka Òwe 31:​11, 26, 27.) Tí ọkọ kan bá ń ṣe bẹ́ẹ̀, á rọrùn fún ìyàwó rẹ̀ láti fi ara ẹ̀ sábẹ́ rẹ̀.

Kí làwọn aya tó dáńgájíá lè rí kọ́ látinú bí Jésù ṣe fi ara ẹ̀ sábẹ́ Jèhófà? (Wo ìpínrọ̀ 15)

15. Kí làwọn aya lè rí kọ́ lára Jésù?

15 Ohun táwọn aya lè rí kọ́. Láìka àwọn nǹkan tí Jésù gbé ṣe, kò ronú pé òun bu ara òun kù torí pé òun fara òun sábẹ́ Jèhófà. (1 Kọ́r. 15:28; Fílí. 2:​5, 6) Lọ́nà kan náà, aya tó dáńgájíá tó ń fara wé Jésù kò ní ronú pé òun ń bu ara òun kù tóun bá fi ara òun sábẹ́ ọkọ òun. Ìdí pàtàkì tó fi máa fi ara ẹ̀ sábẹ́ ọkọ ẹ̀ ni pé ó nífẹ̀ẹ́ Jèhófà, ó sì mọyì àwọn ìlànà rẹ̀, kì í ṣe torí pé ó nífẹ̀ẹ́ ọkọ ẹ̀ nìkan.

Lẹ́yìn tí Ábígẹ́lì kó oúnjẹ ránṣẹ́ sí Dáfídì àtàwọn ọkùnrin tó wà pẹ̀lú rẹ̀, òun fúnra rẹ̀ wá síwájú Dáfídì. Lẹ́yìn náà, ó kúnlẹ̀, ó sì dojú bolẹ̀, ó bẹ̀ ẹ́ pé kó má gbẹ̀san torí pé ìyẹn lè mú kó jẹ̀bi ẹ̀jẹ̀ (Wo ìpínrọ̀ 16)

16. Ìṣòro wo ni Ábígẹ́lì ní bó ṣe wà nínú 1 Sámúẹ́lì 25:​3, 23-28? (Wo àwòrán iwájú ìwé.)

16 Nábálì ni ọkọ Ábígẹ́lì, onímọtara-ẹni-nìkan lọkùnrin yìí, agbéraga ni, ó sì tún ya aláìmoore. Síbẹ̀, Ábígẹ́lì ò wá bó ṣe máa fi ọkọ ẹ̀ sílẹ̀. Ká sọ pé ó fẹ́ fòpin sí ìgbéyàwó rẹ̀ ni, á jẹ́ kí Dáfídì àtàwọn ọkùnrin ẹ̀ pa ọkọ ẹ̀. Àmọ́ kò ṣe bẹ́ẹ̀. Kàkà bẹ́ẹ̀, ó gbé ìgbésẹ̀ láìjáfara kó lè dáàbò bo Nábálì ọkọ rẹ̀ àti agboolé wọn. Kò sí àní-àní pé ó máa gba ìgboyà kí Ábígẹ́lì tó lè dúró níwájú ọgọ́rùn-ún mẹ́rin (400) ọkùnrin tó dira ogun, kó sì ṣàlàyé ọ̀rọ̀ náà fún Dáfídì tọ̀wọ̀tọ̀wọ̀. Kódà, ó tún di ẹ̀bi ọ̀rọ̀ náà ru ara ẹ̀. (Ka 1 Sámúẹ́lì 25:​3, 23-28.) Dáfídì gbà pé Jèhófà ló rán obìnrin onígboyà yìí sóun láti fún òun nímọ̀ràn kóun má bàa jẹ̀bi ẹ̀jẹ̀.

17. Kí làwọn ọkọ lè kọ́ lára Dáfídì àti Ábígẹ́lì?

17 Ohun táwọn ọkọ lè rí kọ́. Obìnrin olóye ni Ábígẹ́lì. Torí náà, ó bọ́gbọ́n mu bí Dáfídì ṣe fetí sí i. Ìyẹn sì ni ò jẹ́ kó jẹ̀bi ẹ̀jẹ̀. Lọ́nà kan náà, ọkọ tó bá gbọ́n máa fara balẹ̀ tẹ́tí sí ìyàwó rẹ̀ kó tó ṣe àwọn ìpinnu pàtàkì. Ó ṣeé ṣe kó jẹ́ pé ìmọ̀ràn tí ìyàwó ẹ̀ bá fún un ni ò ní jẹ́ kó ṣi ìpinnu ṣe.

18. Kí làwọn aya lè rí kọ́ lára Ábígẹ́lì?

18 Ohun táwọn aya lè rí kọ́. Obìnrin tó bá nífẹ̀ẹ́ Jèhófà tó sì bọ̀wọ̀ fún un máa ṣe ìdílé rẹ̀ láǹfààní kódà tí ọkọ ẹ̀ ò bá sin Jèhófà, tí ò sì fi àwọn ìlànà ẹ̀ sílò. Kò ní máa wá bó ṣe máa fi ọkọ ẹ̀ sílẹ̀. Kàkà bẹ́ẹ̀, tó bá ń bọ̀wọ̀ fún ọkọ ẹ̀ tó sì ń fara ẹ̀ sábẹ́ rẹ̀, ìyẹn lè mú kí ọkọ ẹ̀ wá sin Jèhófà. (1 Pét. 3:​1, 2) Kódà, tí ọkọ ẹ̀ ò bá yí pa dà, Jèhófà mọyì bó ṣe jẹ́ olóòótọ́ sí ọkọ ẹ̀ tó sì ń bọ̀wọ̀ fún un.

19. Kí ló lè mú kí aya kan pinnu pé òun ò ní ṣe ohun tí ọkọ òun sọ?

19 Bó tiẹ̀ jẹ́ pé arábìnrin kan ń fi ara ẹ̀ sábẹ́ ọkọ ẹ̀, tí ọkọ ẹ̀ bá ní kó ṣe ohun tó lòdì sí ìlànà Bíbélì, kò ní ṣe bẹ́ẹ̀. Bí àpẹẹrẹ, ọkọ kan tí kì í ṣe Ẹlẹ́rìí Jèhófà lè sọ fún arábìnrin kan pé kó parọ́, kó jalè tàbí kó ṣe àwọn nǹkan míì tí kò bá Bíbélì mu. Àmọ́, Jèhófà ni gbogbo àwa Kristẹni, títí kan àwọn arábìnrin tó ti ṣègbéyàwó gbọ́dọ̀ kọ́kọ́ ṣègbọràn sí. Torí náà, tí ọkọ arábìnrin kan bá ní kó ṣe ohun tí kò bá ìlànà Bíbélì mu, arábìnrin náà gbọ́dọ̀ kọ̀ jálẹ̀, kó sì fara balẹ̀ ṣàlàyé ìdí tóun ò fi lè ṣe bẹ́ẹ̀.​—Ìṣe 5:29.

Wo ìpínrọ̀ 20 *

20. Báwo la ṣe mọ̀ pé Màríà ní àjọṣe tó dáa pẹ̀lú Jèhófà?

20 Màríà ní àjọṣe tó dáa pẹ̀lú Jèhófà. Ó ṣe kedere pé ó mọ Ìwé Mímọ́ dáadáa. Bí àpẹẹrẹ, nígbà tóun àti Èlísábẹ́tì ìyá Jòhánù Arinibọmi ń sọ̀rọ̀, ó lé ní ìgbà ogún (20) tí Màríà fa ọ̀rọ̀ yọ látinú Ìwé Mímọ́ Lédè Hébérù. (Lúùkù 1:​46-55) Ohun míì ni pé bó tiẹ̀ jẹ́ pé Màríà àti Jósẹ́fù ti ń fẹ́ra wọn sọ́nà, Màríà ni áńgẹ́lì Jèhófà kọ́kọ́ fara hàn, áńgẹ́lì náà sì sọ fún un pé òun ló máa bí Ọmọ Ọlọ́run. (Lúùkù 1:​26-33) Jèhófà mọ Màríà dáadáa, ó sì mọ̀ pé ó máa bójú tó Ọmọ òun bó ṣe tọ́ àti bó ṣe yẹ. Ó dájú pé Màríà ṣì ní àjọṣe tó dáa pẹ̀lú Jèhófà kódà lẹ́yìn tí Jésù kú tí Jèhófà sì jí i dìde sí ọ̀run.​—Ìṣe 1:14.

21. Kí làwọn ọkọ lè rí kọ́ látinú ohun tí Bíbélì sọ nípa Màríà?

21 Ohun táwọn ọkọ lè rí kọ́. Inú ọkọ tó bá jẹ́ olóye máa ń dùn tí ìyàwó ẹ̀ bá mọ Ìwé Mímọ́ dáadáa. Kò ní máa jowú, bẹ́ẹ̀ ni kò ní ronú pé ìyàwó òun á gbapò orí mọ́ òun lọ́wọ́. Á mọ̀ pé tí ìyàwó òun bá mọ Ìwé Mímọ́ dáadáa, á ṣe ìdílé òun láǹfààní. Kódà, tí ìyàwó bá tiẹ̀ kàwé ju ọkọ lọ, ojúṣe ọkọ ṣì ni láti múpò iwájú nínú ìjọsìn Jèhófà.​—Éfé. 6:4.

Kí làwọn aya lè rí kọ́ lára Màríà ìyá Jésù tó bá di pé kí wọ́n máa kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, kí wọ́n sì máa ṣàṣàrò? (Wo ìpínrọ̀ 22) *

22. Kí làwọn aya lè kọ́ lára Màríà?

22 Ohun táwọn aya lè rí kọ́. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé aya kan gbọ́dọ̀ fi ara ẹ̀ sábẹ́ ọkọ ẹ̀, òun fúnra ẹ̀ gbọ́dọ̀ sapá láti ní àjọṣe tó dáa pẹ̀lú Jèhófà. (Gál. 6:5) Torí náà, ó gbọ́dọ̀ máa wáyè láti dá kẹ́kọ̀ọ́, kó sì máa ṣàṣàrò. Ìyẹn á mú kó túbọ̀ sún mọ́ Jèhófà, inú ẹ̀ á sì máa dùn bó ṣe ń fi ara ẹ̀ sábẹ́ ọkọ rẹ̀.

23. Tí aya kan bá ń fi ara ẹ̀ sábẹ́ ọkọ ẹ̀, báwo nìyẹn ṣe máa ṣe òun, ìdílé rẹ̀ àti ìjọ láǹfààní?

23 Inú àwọn aya tó ń fi ara wọn sábẹ́ àwọn ọkọ wọn torí pé wọ́n nífẹ̀ẹ́ Jèhófà máa ń dùn, ọkàn wọn sì máa ń balẹ̀ ju àwọn tí kò ṣe bẹ́ẹ̀ lọ. Yàtọ̀ síyẹn, wọ́n tún ń fi àpẹẹrẹ tó dáa lélẹ̀ fáwọn ọ̀dọ́ lọ́kùnrin àti lóbìnrin. Bákan náà, wọ́n máa ń jẹ́ kí ara tu àwọn tó wà nínú ìdílé kí àlàáfíà sì wà nínú ìjọ. (Títù 2:​3-5) Kódà, obìnrin ló pọ̀ jù lára àwọn tó ń fòótọ́ ọkàn sin Jèhófà lónìí. (Sm. 68:11) Bó ti wù kó rí, gbogbo wa la ní ojúṣe pàtàkì nínú ìjọ yálà ọkùnrin ni wá tàbí obìnrin. Nínú àpilẹ̀kọ tó kàn, a máa jíròrò bí ẹnì kọ̀ọ̀kan wa ṣe lè ṣe ojúṣe yìí.

ORIN 131 ‘Ohun Tí Ọlọ́run So Pọ̀’

^ ìpínrọ̀ 5 Ohun tí Jèhófà fẹ́ ni pé kí àwọn aya máa fi ara wọn sábẹ́ ọkọ wọn. Kí nìyẹn túmọ̀ sí? Tó bá di pé ká fi ara wa sábẹ́ àwọn ẹlòmíì, ọ̀pọ̀ nǹkan làwọn tọkọtaya Kristẹni lè kọ́ látinú àpẹẹrẹ Jésù àtàwọn obìnrin tí Bíbélì sọ̀rọ̀ nípa wọn.

^ ìpínrọ̀ 68 ÀWÒRÁN: Màríà mọ Ìwé Mímọ́ Lédè Hébérù dáadáa, ìdí nìyẹn tó fi lè fa ọ̀rọ̀ yọ látinú ẹ̀ nígbà tó ń bá Èlísábẹ́tì ìyá Jòhánù Arinibọmi sọ̀rọ̀.

^ ìpínrọ̀ 70 ÀWÒRÁN: Lọ́nà kan náà, aya kan ń wáyè kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì láyè ara ẹ̀ kí ìgbàgbọ́ ẹ̀ lè túbọ̀ lágbára.