Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

ÀPILẸ̀KỌ FÚN ÌKẸ́KỌ̀Ọ́ 7

Mọyì Ipò Orí Tí Jèhófà Ṣètò Nínú Ìjọ

Mọyì Ipò Orí Tí Jèhófà Ṣètò Nínú Ìjọ

“Kristi . . .  jẹ́ orí ìjọ, òun sì ni olùgbàlà ara yìí.”​—ÉFÉ. 5:23.

ORIN 137 Àwọn Obìnrin Olóòótọ́, Àwọn Arábìnrin Wa

OHUN TÁ A MÁA JÍRÒRÒ *

1. Kí ló mú kí àwa tá a wà nínú ìdílé Jèhófà wà níṣọ̀kan?

INÚ wa dùn pé a wà nínú ìdílé Jèhófà, àlàáfíà wà láàárín wa, a sì wà níṣọ̀kan. Kí ló mú kíyẹn ṣeé ṣe? Ìdí kan ni pé gbogbo wa là ń fọwọ́ sowọ́ pọ̀ pẹ̀lú ìṣètò ipò orí tí Jèhófà ṣe. Kódà, tá a bá túbọ̀ lóye ètò tí Jèhófà ṣe yìí, tá a sì fọwọ́ sowọ́ pọ̀ pẹ̀lú ẹ̀, àá túbọ̀ wà níṣọ̀kan.

2. Àwọn ìbéèrè wo la máa dáhùn nínú àpilẹ̀kọ yìí?

2 Nínú àpilẹ̀kọ yìí, a máa jíròrò ọ̀rọ̀ ipò orí nínú ìjọ. Lára àwọn ìbéèrè tá a máa dáhùn ni: Ipa wo làwọn arábìnrin ń kó nínú ìjọ? Ṣé òótọ́ ni pé gbogbo àwọn arákùnrin ló láṣẹ lórí àwọn arábìnrin? Ṣé irú àṣẹ tí àwọn olórí ìdílé ní lórí ìyàwó àtàwọn ọmọ wọn làwọn alàgbà náà ní lórí àwọn ará nínú ìjọ? Ní báyìí, ẹ jẹ́ ká kọ́kọ́ jíròrò ojú tó yẹ ká fi máa wo àwọn arábìnrin nínú ìjọ.

OJÚ TÓ YẸ KÁ FI MÁA WO ÀWỌN ARÁBÌNRIN

3. Kí lá jẹ́ ká túbọ̀ mọyì iṣẹ́ táwọn arábìnrin wa ń ṣe?

3 A mọyì àwọn arábìnrin wa gan-an torí pé iṣẹ́ kékeré kọ́ ni wọ́n ń ṣe bí wọ́n ṣe ń bójú tó ìdílé wọn, tí wọ́n ń wàásù ìhìn rere, tí wọ́n sì ń ran àwọn míì lọ́wọ́ nínú ìjọ. Àá túbọ̀ mọyì wọn tá a bá ń wò wọ́n bí Jèhófà àti Jésù ṣe ń wò wọ́n. Àá tún kẹ́kọ̀ọ́ látinú ọwọ́ tí àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù fi mú àwọn obìnrin.

4. Kí ni Bíbélì sọ tó jẹ́ ká mọ̀ pé tọkùnrin tobìnrin ni Jèhófà mọyì?

4 Bíbélì fi hàn pé bí Jèhófà ṣe mọyì àwọn ọkùnrin náà ló mọyì àwọn obìnrin. Bí àpẹẹrẹ ní ọgọ́rùn-ún ọdún kìíní, àtọkùnrin àtobìnrin ni Jèhófà fún ní ẹ̀mí mímọ́, ó sì fún wọn lágbára láti ṣe àwọn iṣẹ́ ìyanu, kí wọ́n sì sọ onírúurú èdè. (Ìṣe 2:​1-4, 15-18) Bákan náà, tọkùnrin tobìnrin ni Jèhófà fẹ̀mí yàn, tó sì fún wọn láǹfààní láti jọba pẹ̀lú Kristi lọ́run. (Gál. 3:​26-29) Yàtọ̀ síyẹn, tọkùnrin tobìnrin ló máa jogún ìyè àìnípẹ̀kun lórí ilẹ̀ ayé. (Ìfi. 7:​9, 10, 13-15) Ìyẹn nìkan kọ́ o, bí Jèhófà ṣe fún àwọn ọkùnrin láǹfààní láti wàásù ìhìn rere kí wọ́n sì kọ́ni lẹ́kọ̀ọ́ náà ló fún àwọn obìnrin. (Mát. 28:​19, 20) Bí àpẹẹrẹ, ìwé Ìṣe sọ̀rọ̀ nípa arábìnrin kan tó ń jẹ́ Pírísílà tóun àti ọkọ rẹ̀ tó ń jẹ́ Ákúílà ran ọkùnrin sọ̀rọ̀sọ̀rọ̀ kan tó ń jẹ́ Àpólò lọ́wọ́ kó lè túbọ̀ mọ Ìwé Mímọ́ dunjú.​—Ìṣe 18:​24-26.

5. Kí ni Lúùkù 10:​38, 39, 42 sọ nípa irú ọwọ́ tí Jésù fi mú àwọn obìnrin?

5 Jésù máa ń bọ̀wọ̀ fáwọn obìnrin, ó sì máa ń pọ́n wọn lé. Kò ṣe bíi tàwọn Farisí tí wọ́n máa ń fojú burúkú wo àwọn obìnrin, kódà wọn kì í bá wọn sọ̀rọ̀ ní gbangba, ká má tíì sọ pé wọ́n á kọ́ wọn ní Ìwé Mímọ́. Dípò bẹ́ẹ̀, Jésù máa ń kọ́ àwọn obìnrin láwọn ẹ̀kọ́ òtítọ́ tó ṣe pàtàkì bó ṣe ń kọ́ àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ yòókù. * (Ka Lúùkù 10:​38, 39, 42.) Bákan náà, àwọn obìnrin wà lára àwọn tí wọ́n jọ ń wàásù láti ìlú kan dé ibòmíì. (Lúùkù 8:​1-3) Kódà, àwọn obìnrin ni Jésù rán pé kí wọ́n lọ sọ fún àwọn àpọ́sítélì pé òun ti jíǹde.​—Jòh. 20:​16-18.

6. Kí ni àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù ṣe tó fi hàn pé ó bọ̀wọ̀ fáwọn obìnrin?

6 Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù dìídì sọ fún Tímótì pé kó máa bọ̀wọ̀ fáwọn obìnrin. Ó sọ fún un pé kó máa wo “àwọn àgbà obìnrin bí ìyá” àti “àwọn ọ̀dọ́bìnrin bí ọmọ ìyá.” (1 Tím. 5:​1, 2) Iṣẹ́ ńlá ni Pọ́ọ̀lù ṣe láti mú kí òtítọ́ túbọ̀ jinlẹ̀ lọ́kàn Tímótì, àmọ́ ó gbà pé ìyá Tímótì àti ìyá rẹ̀ àgbà ló kọ́kọ́ gbin ẹ̀kọ́ òtítọ́ sọ́kàn rẹ̀. (2 Tím. 1:5; 3:​14, 15) Bákan náà, Pọ́ọ̀lù dìídì dárúkọ àwọn arábìnrin tó fẹ́ kí wọ́n bá òun kí nínú lẹ́tà tó kọ sáwọn ará ní Róòmù. Kì í ṣe pé ó mọyì iṣẹ́ táwọn arábìnrin yẹn ṣe nìkan, ó tún gbóríyìn fún wọn.​—Róòmù 16:​1-4, 6, 12; Fílí. 4:3.

7. Àwọn ìbéèrè wo la máa dáhùn báyìí?

7 Níbi tá a bọ́rọ̀ dé yìí, ó ti ṣe kedere pé kò sí ibì kankan nínú Ìwé Mímọ́ tó fi hàn pé àwọn ọkùnrin ṣe pàtàkì ju àwọn obìnrin lọ. Kò sí àní-àní pé àwọn arábìnrin wa lawọ́ gan-an, wọ́n sì máa ń fìfẹ́ hàn, èyí ló mú kí wọ́n lè máa ran ọ̀pọ̀ lọ́wọ́ nínú ìjọ. Abájọ táwọn alàgbà fi mọyì bí wọ́n ṣe ń mú kí àlàáfíà àti ìṣọ̀kan wà nínú ìjọ. Àmọ́ o, àwọn ìbéèrè kan wà tó yẹ ká dáhùn. Bí àpẹẹrẹ: Kí nìdí tí Jèhófà fi sọ pé kí wọ́n máa fi nǹkan bo orí wọn tí wọ́n bá ń ṣe àwọn iṣẹ́ kan? Níwọ̀n bó ti jẹ́ pé àwọn arákùnrin nìkan ló máa ń di alàgbà àti ìránṣẹ́ iṣẹ́ òjíṣẹ́, ṣéyẹn wá túmọ̀ sí pé gbogbo àwọn arákùnrin ló jẹ́ orí fún àwọn arábìnrin nínú ìjọ?

ṢÉ GBOGBO ÀWỌN ARÁKÙNRIN LÓ JẸ́ ORÍ FÁWỌN ARÁBÌNRIN?

8. Bó ṣe wà nínú Éfésù 5:​23, ṣé gbogbo arákùnrin ló jẹ́ orí fáwọn arábìnrin? Ṣàlàyé.

8 Rárá ni ìdáhùn náà! Kò sí arákùnrin kankan tó jẹ́ orí fún gbogbo àwọn arábìnrin tó wà nínú ìjọ torí Jésù ni orí gbogbo wa. (Ka Éfésù 5:23.) Nínú ìdílé, ọkọ láṣẹ lórí ìyàwó rẹ̀. Àmọ́ ọmọkùnrin kan tó ti ṣèrìbọmi kì í ṣe orí fún ìyá rẹ̀. (Éfé. 6:​1, 2) Bákan náà nínú ìjọ, àṣẹ tí àwọn alàgbà ní lórí àwọn ará ní ibi tó mọ. (1 Tẹs. 5:12; Héb. 13:17) Àwọn arábìnrin tí ò tíì lọ́kọ tí ò sì gbé lọ́dọ̀ àwọn òbí wọn mọ́ ńkọ́? Wọ́n á ṣì máa bọ̀wọ̀ fáwọn òbí wọn bó tiẹ̀ jẹ́ pé wọn ò sí lábẹ́ àṣẹ wọn mọ́. Bákan náà nínú ìjọ, wọ́n á máa bọ̀wọ̀ fáwọn alàgbà bó tilẹ̀ jẹ́ pé bíi tàwọn arákùnrin, Jésù nìkan ni orí wọn.

Abẹ́ ìdarí Jésù làwọn tí ò tíì ṣègbéyàwó tó sì wà láyè ara wọn wà (Wo ìpínrọ̀ 8)

9. Kí nìdí tí Jèhófà fi sọ pé kí àwọn arábìnrin máa bo orí wọn tí wọ́n bá ń bójú tó àwọn iṣẹ́ kan?

9 Àwọn ọkùnrin ni Jèhófà yàn láti máa múpò iwájú nínú kíkọ́ni àti nínú ìjọsìn Jèhófà. Àmọ́ kò fún àwọn obìnrin láǹfààní yẹn. (1 Tím. 2:12) Kí nìdí? Ohun tó mú kí Jèhófà yan Jésù ṣe orí àwọn ọkùnrin náà ló mú kí Jèhófà yan àwọn ọkùnrin láti máa múpò iwájú nínú ìjọ. Ìdí sì ni pé, ó fẹ́ kí ìjọ wà létòlétò. Tí ipò nǹkan bá gba pé kí arábìnrin kan bójú tó iṣẹ́ táwọn arákùnrin máa ń ṣe, ohun tí Jèhófà retí ni pé kí arábìnrin náà bo orí rẹ̀. * (1 Kọ́r. 11:​4-7) Kì í ṣe torí pé Jèhófà fojú kéré àwọn obìnrin ló ṣe ní kí wọ́n máa borí. Àmọ́ ó ṣe bẹ́ẹ̀ kíyẹn lè fi hàn pé wọ́n bọ̀wọ̀ fún ipò orí tí Jèhófà ṣètò. Ní bàyìí, ẹ jẹ́ ká dáhùn ìbéèrè yìí: Àṣẹ wo ni àwọn olórí ìdílé àti àwọn alàgbà ní?

OJÚṢE ÀWỌN OLÓRÍ ÌDÍLÉ ÀTI ÀWỌN ALÀGBÀ

10. Kí ló lè mú kí alàgbà kan máa ṣòfin fáwọn tó wà nínú ìjọ?

10 Àwọn alàgbà nífẹ̀ẹ́ Jésù, wọ́n sì nífẹ̀ẹ́ àwọn “àgùntàn” tí Jèhófà àti Jésù ti fi sí ìkáwọ́ wọn. (Jòh. 21:​15-17) Torí náà, alàgbà kan lè fẹ́ fi ara ẹ̀ ṣe bàbá fáwọn tó wà nínú ìjọ. Ó lè ronú pé tí olórí ìdílé kan bá láṣẹ láti ṣòfin tó máa dáàbò bo ìdílé rẹ̀, alàgbà kan náà láṣẹ láti ṣòfin tó máa dáàbò bo àwọn àgùntàn Ọlọ́run. Nígbà míì sì rèé, àwọn arákùnrin àtàwọn arábìnrin kan máa ń sọ fáwọn alàgbà pé kí wọ́n ṣèpinnu fáwọn, wọ́n sì ń tipa bẹ́ẹ̀ sọ àwọn alàgbà yẹn di baba wọn nípa tẹ̀mí. Àmọ́ ìbéèrè náà ni pé, ṣé bí olórí ìdílé kan ṣe láṣẹ lórí ìdílé rẹ̀ náà làwọn alàgbà láṣẹ lórí ìjọ?

Àwọn alàgbà máa ń ran àwọn tó wà nínú ìjọ lọ́wọ́ kí wọ́n lè ní àjọṣe tó dáa pẹ̀lú Jèhófà, wọ́n sì máa ń fìfẹ́ hàn sí wọn. Jèhófà tún fún wọn ní àṣẹ láti yọ àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀ tí kò bá ronú pìwà dà kúrò nínú ìjọ (Wo ìpínrọ̀ 11-12)

11. Báwo ni ojúṣe àwọn olórí ìdílé àti tàwọn alàgbà ṣe jọra?

11 Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù fi hàn pé ojúṣe àwọn olórí ìdílé àti tàwọn alàgbà jọra láwọn ọ̀nà kan. (1 Tím. 3:​4, 5) Bí àpẹẹrẹ, Jèhófà fẹ́ káwọn tó wà nínú ìdílé máa ṣègbọràn sí olórí ìdílé wọn. (Kól. 3:20) Ó sì fẹ́ káwọn tó wà nínú ìjọ máa ṣègbọràn sáwọn alàgbà. Jèhófà fẹ́ kí àwọn olórí ìdílé àti àwọn alàgbà rí i dájú pé àwọn tó wà lábẹ́ àbójútó wọn ní àjọṣe tó dáa pẹ̀lú Jèhófà, wọ́n sì gbọ́dọ̀ máa fìfẹ́ hàn sí wọn. Bákan náà bíi tàwọn olórí ìdílé, àwọn alàgbà máa ń ran àwọn tó níṣòro lọ́wọ́ nínú ìjọ. (Jém. 2:​15-17) Yàtọ̀ síyẹn, Jèhófà fẹ́ káwọn alàgbà àti àwọn olórí ìdílé máa tẹ̀ lé ìlànà rẹ̀, kí wọ́n má sì “kọjá àwọn ohun tó wà lákọsílẹ̀” nínú Bíbélì.​—1 Kọ́r. 4:6.

Àwọn olórí ìdílé ni Jèhófà fún láṣẹ láti máa múpò iwájú nínú ìdílé wọn. Àmọ́ kí olórí ìdílé kan tó ṣèpinnu, á dáa kó fọ̀rọ̀ lọ ìyàwó rẹ̀ (Wo ìpínrọ̀ 13)

12-13. Róòmù 7:2 ṣe sọ, ìyàtọ̀ wo ló wà láàárín ojúṣe àwọn olórí ìdílé àti tàwọn alàgbà?

12 Àmọ́, ìyàtọ̀ wà láàárín àṣẹ táwọn alàgbà ní àti èyí táwọn olórí ìdílé ní. Bí àpẹẹrẹ, Jèhófà ti yan àwọn alàgbà ṣe onídàájọ́, ó sì fún wọn láṣẹ láti yọ àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀ tí kò bá ronú pìwà dà kúrò nínú ìjọ.​—1 Kọ́r. 5:​11-13.

13 Lọ́wọ́ kejì, Jèhófà fún àwọn olórí ìdílé láwọn àṣẹ kan tí kò fún àwọn alàgbà. Bí àpẹẹrẹ, ó fún àwọn olórí ìdílé láṣẹ láti ṣòfin nínú ìdílé wọn. (Ka Róòmù 7:2.) Olórí ìdílé kan láṣẹ láti pinnu ìgbà tí àwọn ọmọ rẹ̀ gbọ́dọ̀ máa wọlé. Ó tún lẹ́tọ̀ọ́ láti bá àwọn ọmọ ẹ̀ wí tí wọ́n bá rú òfin yẹn. (Éfé. 6:1) Àmọ́, ó yẹ kí olórí ìdílé kan fọ̀rọ̀ lọ ìyàwó rẹ̀ kó tó ṣòfin nínú ilé. Ó ṣe tán, Bíbélì sọ pé àwọn méjèèjì ti di “ara kan.” *​—Mát. 19:6.

BỌ̀WỌ̀ FÚN KRISTI TÓ JẸ́ ORÍ ÌJỌ

Jésù wà lábẹ́ ìdarí Jèhófà, ó sì ń fún àwọn tó wà nínú ìjọ nítọni (Wo ìpínrọ̀ 14)

14. (a) Kí ni Máàkù 10:45 sọ tó jẹ́ ká rí i pé ó bọ́gbọ́n mu bí Jèhófà ṣe yan Jésù ṣe orí ìjọ? (b) Kí ni ojúṣe Ìgbìmọ̀ Olùdarí? (Wo àpótí náà, “ Ojúṣe Ìgbìmọ̀ Olùdarí.”)

14 Ìràpadà tí Jèhófà ṣètò ló fi ra ẹ̀mí gbogbo àwa tá a wà nínú ìjọ àtàwọn míì tó bá ní ìgbàgbọ́ nínú Jésù. (Ka Máàkù 10:45; Ìṣe 20:28; 1 Kọ́r. 15:​21, 22) Torí náà, ó bọ́gbọ́n mu pé Jésù tó fi ẹ̀mí rẹ̀ lélẹ̀ ni Jèhófà yàn ṣe orí ìjọ. Torí pé Jésù ni orí ìjọ, ó láṣẹ láti ṣòfin kó sì rí i dájú pé gbogbo wa lẹ́nì kọ̀ọ̀kan ń tẹ̀ lé òfin náà, yálà nínú ìdílé tàbí nínú ìjọ. (Gál. 6:2) Àmọ́ kì í ṣe òfin nìkan ni Jésù ń ṣe, ó tún ń bọ́ wa, ó sì ń ṣìkẹ́ wa.​—Éfé. 5:29.

15-16. Kí lo rí kọ́ látinú ohun tí Arábìnrin Marley àti Arákùnrin Benjamin sọ?

15 Àwọn arábìnrin lè fi hàn pé àwọn bọ̀wọ̀ fún Kristi tí wọ́n bá ń tẹ̀ lé ìtọ́ni tí àwọn ọkùnrin tó ń múpò iwájú bá fún wọn. Arábìnrin Marley tó ń gbé lórílẹ̀-èdè Amẹ́ríka sọ bọ́rọ̀ náà ṣe rí lára ọ̀pọ̀ àwọn arábìnrin. Ó ní: “Mo mọyì ipò mi gẹ́gẹ́ bí ìyàwó ilé àti arábìnrin nínú ìjọ. Gbogbo ìgbà ni mo máa ń rán ara mi létí pé ó yẹ kí n máa bọ̀wọ̀ fún ọkọ mi àtàwọn alàgbà tó ń bójú tó wa nínú ìjọ. Àmọ́, wọ́n mú kó rọrùn fún mi ní ti pé wọ́n máa ń pọ́n mi lé, wọ́n sì máa ń gbóríyìn fún mi.”

16 Àwọn arákùnrin lè fi hàn pé àwọn mọyì ètò ipò orí tí Jèhófà ṣe tí wọ́n bá ń bọ̀wọ̀ fáwọn arábìnrin tí wọ́n sì ń pọ́n wọn lé. Arákùnrin Benjamin tó ń gbé lórílẹ̀-èdè England sọ pé: “Ọ̀pọ̀ nǹkan ni mo ti kọ́ lára àwọn arábìnrin. Bí àpẹẹrẹ, mo máa ń kẹ́kọ̀ọ́ látinú ìdáhùn wọn àti nínú bí wọ́n ṣe ń kẹ́kọ̀ọ́. Wọ́n sì ti jẹ́ kí n mọ bí mo ṣe lè túbọ̀ já fáfá lẹ́nu iṣẹ́ ìwàásù. Iṣẹ́ kékeré kọ́ ni wọ́n ń ṣe nínú ìjọ.”

17. Kí nìdí tó fi yẹ ká fọwọ́ sowọ́ pọ̀ pẹ̀lú ètò ipò orí tí Jèhófà ṣe?

17 Tí gbogbo wa bá ń fọwọ́ sowọ́ pọ̀ pẹ̀lú ètò ipò orí tí Jèhófà ṣe, yálà a jẹ́ ọkùnrin tàbí obìnrin, olórí ìdílé tàbí alàgbà, àlàáfíà máa wà nínú ìjọ. Ju gbogbo ẹ̀ lọ, a máa mú ìyìn àti ògo wá fún Jèhófà Baba wa ọ̀run.​—Sm. 150:6.

ORIN 123 Máa Ṣègbọràn sí Ètò Ọlọ́run

^ ìpínrọ̀ 5 Ipa wo làwọn arábìnrin ń kó nínú ìjọ? Ṣé gbogbo àwọn arákùnrin ló jẹ́ orí fún àwọn arábìnrin? Ṣé àṣẹ kan náà ni àwọn alàgbà àti àwọn olórí ìdílé ní? Àá fi Bíbélì Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run dáhùn àwọn ìbéèrè yìí nínú àpilẹ̀kọ yìí.

^ ìpínrọ̀ 5 Wo ìpínrọ̀ 6 nínú àpilẹ̀kọ náà, “Ẹ Máa Fún Àwọn Arábìnrin Níṣìírí” nínú Ilé Ìṣọ́ September 2020.

^ ìpínrọ̀ 13 Tó o bá fẹ́ mọ ẹni tó yẹ kó pinnu ìjọ tí ìdílé kan máa lọ, wo ìpínrọ̀ 17-19 nínú àpilẹ̀kọ náà “Mọyì Àwọn Míì Nínú Ìjọ” tó wà nínú Ilé Ìṣọ́ August 2020.

^ ìpínrọ̀ 59 Tó o bá fẹ́ àlàyé sí i lórí kókó yìí, wo ìwé ‘Ẹ Dúró Nínú Ìfẹ́ Ọlọ́run’ ojú ìwé 209-212.

^ ìpínrọ̀ 64 Tó o bá fẹ́ mọ̀ nípa ojúṣe Ìgbìmọ̀ Olùdarí lẹ́kùn-ún rẹ́rẹ́, wo Ilé Ìṣọ́ July 15, 2013, ojú ìwé 20-25.