Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

ÀPILẸ̀KỌ FÚN ÌKẸ́KỌ̀Ọ́ 16

Máa Fi Hàn Pé O Mọyì Ìràpadà Nígbà Gbogbo

Máa Fi Hàn Pé O Mọyì Ìràpadà Nígbà Gbogbo

‘Ọmọ èèyàn wá kó lè fi ẹ̀mí rẹ̀ ṣe ìràpadà ní pàṣípààrọ̀ fún ọ̀pọ̀lọpọ̀ èèyàn.’​—MÁÀKÙ 10:45.

ORIN 18 A Mọyì Ìràpadà

OHUN TÁ A MÁA JÍRÒRÒ *

1-2. Kí ni ìràpadà, kí sì nìdí tá a fi nílò rẹ̀?

ẸNI pípé ni Ádámù nígbà tí Ọlọ́run dá a, àmọ́ nígbà tó ṣẹ̀, ó pàdánù àǹfààní tó ní àtèyí táwọn ọmọ ẹ̀ máa ní láti wà láàyè títí láé. Ṣe ni Ádámù mọ̀ọ́mọ̀ dẹ́ṣẹ̀ sí Ọlọ́run, torí náà, kò ní àwíjàre. Kò sí àní-àní pé ikú tọ́ sí Ádámù fún nǹkan tó ṣe. Àmọ́, àwọn ọmọ rẹ̀ ńkọ́, wọn ò ṣáà sí níbẹ̀ nígbà tí Ádámù dẹ́ṣẹ̀? (Róòmù 5:​12, 14) Kí ni Jèhófà máa ṣe láti dá wọn nídè? Kò pẹ́ lẹ́yìn tí Ádámù dẹ́ṣẹ̀, Jèhófà bẹ̀rẹ̀ sí í sọ àwọn nǹkan tóun máa ṣe láti dá àwọn ọmọ Ádámù nídè kúrò lọ́wọ́ ẹ̀ṣẹ̀ àti ikú. (Jẹ́n. 3:15) Tó bá sì tó àsìkò lójú Jèhófà, ó máa rán Ọmọ rẹ̀ wá sáyé kó lè “fi ẹ̀mí rẹ̀ ṣe ìràpadà ní pàṣípààrọ̀ fún ọ̀pọ̀lọpọ̀ èèyàn.”​—Máàkù 10:45; Jòh. 6:51.

2 Kí ni ìràpadà? Nínú Ìwé Mímọ́ Kristẹni Lédè Gíríìkì, ìràpadà lohun tí Jésù san láti dá wa nídè lọ́wọ́ ẹ̀ṣẹ̀ àti ikú. (1 Kọ́r. 15:22) Kí nìdí tá a fi nílò ìràpadà? Ìdí ni pé nínú Òfin tí Jèhófà fún àwọn ọmọ Ísírẹ́lì, tí ohunkóhun bá la ẹ̀mí lọ, Jèhófà sọ pé kí wọ́n fi ẹ̀mí dípò ẹ̀mí. (Ẹ́kís. 21:​23, 24) Ìwàláàyè pípé ni Ádámù gbé sọ nù nígbà tó ṣẹ̀. Torí náà, ó pọn dandan kí Jésù fi ẹ̀mí rẹ̀ pípé lélẹ̀ kó lè mú ìdájọ́ òdodo Ọlọ́run ṣẹ. (Róòmù 5:17) Ó wá tipa bẹ́ẹ̀ di “Baba Ayérayé” fún gbogbo àwọn tó nígbàgbọ́ nínú ìràpadà.​—Àìsá. 9:6; Róòmù 3:​23, 24.

3. Kí ni Jésù sọ nínú Jòhánù 14:31 àti 15:13 tó jẹ́ ká mọ ìdí tó fi fínnúfíndọ̀ fi ẹ̀mí rẹ̀ lélẹ̀?

3 Jésù fínnúfíndọ̀ fi ẹ̀mí rẹ̀ lélẹ̀ torí ìfẹ́ tó ní fún Jèhófà àti fún wa. (Ka Jòhánù 14:31; 15:13.) Ìfẹ́ tó ní yìí ló mú kó jẹ́ olóòótọ́ dójú ikú kó lè mú ìfẹ́ Baba rẹ̀ ṣẹ. Nípa bẹ́ẹ̀, ohun tí Jèhófà ní lọ́kàn fún àwa èèyàn àti ilẹ̀ ayé máa ṣẹ. Nínú àpilẹ̀kọ yìí, a máa jíròrò ìdí tí Jèhófà fi jẹ́ kí Jésù jìyà tó bẹ́ẹ̀ kó tó kú. A tún máa sọ̀rọ̀ ṣókí nípa ẹnì kan nínú Bíbélì tó mọyì ìràpadà gan-an. Paríparí ẹ̀, a máa jíròrò bá a ṣe lè fi hàn pé a moore tí Jèhófà àti Jésù ṣe fún wa, àá sì sọ bá a ṣe lè túbọ̀ mọyì ìràpadà náà.

KÍ NÌDÍ TÍ JÈHÓFÀ FI JẸ́ KÍ JÉSÙ JÌYÀ?

Ronú nípa adúrú ìyà tí Jésù jẹ kó lè rà wá pa dà! (Wo ìpínrọ̀ 4)

4. Sọ ohun tí ojú Jésù rí títí tó fi kú.

4 Fojú inú wo ohun tó ṣẹlẹ̀ sí Jésù lọ́jọ́ tó lò kẹ́yìn láyé. Bó tiẹ̀ jẹ́ pé ó lè pe ọ̀pọ̀lọpọ̀ áńgẹ́lì láti dá òun nídè, kò ṣe bẹ́ẹ̀. Ṣe ló gbà kí àwọn ọmọ ogun Róòmù mú òun, wọ́n sì fìyà jẹ ẹ́ bí ẹni máa kú. (Mát. 26:​52-54; Jòh. 18:3; 19:1) Wọ́n fi kòbókò tó ní egungun nà án, ìyẹn sì fa ẹran ara ẹ̀ ya. Nígbà tó yá, wọ́n mú kó wọ́ igi ńlá kan pẹ̀lú ẹ̀yìn tó ti bó yánnayànna. Jésù gbìyànjú láti wọ́ igi náà lọ síbi tí wọ́n ti máa pa á, àmọ́ kò pẹ́ sígbà yẹn, àwọn ọmọ ogun Róòmù fipá mú ọkùnrin kan láti bá a gbé igi náà. (Mát. 27:32) Nígbà tí Jésù dé ibi tí wọ́n ti máa pa á, àwọn ọmọ ogun yẹn kan ọwọ́ àti ẹsẹ̀ rẹ̀ mọ́ òpó náà. Nígbà tí wọ́n gbé òpó yẹn nà ró, ṣe ni ojú ọgbẹ́ tí wọ́n fi ìṣó kàn náà ya. Ìyá ẹ̀ ń sunkún, bẹ́ẹ̀ sì ni ẹ̀dùn ọkàn bá àwọn ọ̀rẹ́ rẹ̀, àmọ́ ńṣe làwọn aṣáájú ẹ̀sìn àwọn Júù ń fi í ṣe yẹ̀yẹ́. (Lúùkù 23:​32-38; Jòh. 19:25) Odindi wákàtí mẹ́ta ni Jésù fi joró lórí òpó igi oró yìí, ó le débi pé agbára káká ló fi ń mí. Nígbà tó ku díẹ̀ kó kú, ó gba àdúrà ìkẹyìn, lẹ́yìn náà, ó dorí kodò, ó sì kú. (Máàkù 15:37; Lúùkù 23:46; Jòh. 10:​17, 18; 19:30) Ẹ ò rí i pé ikú oró, ikú ẹ̀sín ni Jésù kú!

5. Lójú Jésù, kí ló burú ju ọ̀nà tí wọ́n gbà pa á lọ?

5 Lójú Jésù, kì í ṣe ọ̀nà tí wọ́n gbà pa á ló ká a lára jù. Ohun tó ká a lára jù ni ẹ̀sùn tí wọ́n fi kàn án. Wọ́n fẹ̀sùn èké kàn án pé ó sọ̀rọ̀ òdì sí Ọlọ́run. (Mát. 26:​64-66) Ẹ̀sùn tí wọ́n fi kàn án yìí dùn ún débi pé ó bẹ Jèhófà pé kó má jẹ́ kóun kú lọ́nà tó máa kó ẹ̀gàn bá orúkọ Rẹ̀. (Mát. 26:​38, 39, 42) Kí nìdí tí Jèhófà fi jẹ́ kí Ọmọ rẹ̀ ọ̀wọ́n jìyà, kó sì kú? Ẹ jẹ́ ká wo ìdí mẹ́ta tó fi ṣe bẹ́ẹ̀.

6. Kí nìdí tí wọ́n fi ní láti gbé Jésù kọ́ sórí òpó igi oró?

6 Àkọ́kọ́, wọ́n ní láti gbé Jésù kọ́ sórí òpó igi kó lè gba àwọn Júù sílẹ̀ lọ́wọ́ ègún tó wà lórí wọn. (Gál. 3:​10, 13) Kí nìdí táwọn Júù fi dẹni ègún? Ìdí ni pé wọ́n ṣèlérí pé àwọn máa pa Òfin Ọlọ́run mọ́, àmọ́ wọn ò ṣe bẹ́ẹ̀. Torí náà, ègún yìí jẹ́ àfikún sí ẹ̀ṣẹ̀ àti ikú tí wọ́n jogún látọ̀dọ̀ Ádámù. (Róòmù 5:12) Nínú Òfin tí Ọlọ́run fún àwọn ọmọ Ísírẹ́lì, ó sọ pé tí ẹnì kan bá dẹ́ṣẹ̀ tó yẹ fún ikú, kí wọ́n pa á. Lẹ́yìn náà, wọ́n lè gbé òkú rẹ̀ kọ́ sórí òpó igi. * (Diu. 21:​22, 23; 27:26) Bó tiẹ̀ jẹ́ pé àwọn ọmọ Ísírẹ́lì kọ Jésù, bí wọ́n ṣe gbé Jésù kọ́ sórí òpó igi mú kó ṣeé ṣe fún wọn láti bọ́ lọ́wọ́ ègún tó wà lórí wọn, kí wọ́n sì jàǹfààní látinú ìràpadà náà.

7. Kí nìdí kejì tí Ọlọ́run fi jẹ́ kí Ọmọ rẹ̀ jìyà?

7 Ẹ jẹ́ ká wo ìdí kejì tí Ọlọ́run fi jẹ́ kí Ọmọ rẹ̀ jìyà. Ṣe ni Jèhófà ń dá Ọmọ rẹ̀ lẹ́kọ̀ọ́ kó lè kúnjú ìwọ̀n láti di Àlùfáà Àgbà. Ohun tójú Jésù rí mú kó mọ bó ṣe nira tó láti ṣègbọràn sí Jèhófà lábẹ́ àdánwò tó lágbára. Àdánwò náà lágbára débi pé ó gbàdúrà pẹ̀lú “ẹkún tó rinlẹ̀ àti omijé.” Ẹ̀dùn ọkàn tó lékenkà tó ní mú kó lóye bí nǹkan ṣe ń rí lára wa, ó sì lè ràn wá lọ́wọ́ nígbàkigbà tá a bá kojú àdánwò. A mà dúpẹ́ o pé aláàánú lẹni tí Jèhófà yàn láti jẹ́ Àlùfáà Àgbà wa, ó sì “lè bá wa kẹ́dùn fún àwọn àìlera wa”!​—Héb. 2:​17, 18; 4:​14-16; 5:​7-10.

8. Kí nìdí kẹta tí Jèhófà fi jẹ́ kí wọ́n dán Jésù wò dé góńgó?

8 Ìkẹta, Jèhófà jẹ́ kí Jésù jìyà gan-an ká lè rí ìdáhùn sí ìbéèrè pàtàkì kan. Ìbéèrè náà ni pé: Ṣé ẹ̀dá èèyàn èyíkéyìí lè jẹ́ adúróṣinṣin lójú àdánwò tó lágbára? Sátánì sọ pé kò séèyàn tó máa lè jẹ́ olóòótọ́ torí pé ohun tá à ń rí gbà látọ̀dọ̀ Ọlọ́run ló mú ká máa sìn ín. Ó gbà pé a ò yàtọ̀ sí Ádámù bàbá wa àti pé a ò lè jẹ́ olóòótọ́ sí Jèhófà. (Jóòbù 1:​9-11; 2:​4, 5) Àmọ́, Jèhófà fọkàn tán Ọmọ rẹ̀ pé ó máa jẹ́ olóòótọ́, ìdí nìyẹn tó fi gbà kí wọ́n fìyà jẹ ẹ́ dé góńgó. Bọ́rọ̀ sì ṣe rí nìyẹn, Jésù jẹ́ olóòótọ́, ó sì tipa bẹ́ẹ̀ fi hàn pé òpùrọ́ ni Sátánì.

ÀPẸẸRẸ ẸNÌ KAN NÍNÚ BÍBÉLÌ TÓ MỌYÌ ÌRÀPADÀ GAN-AN

9. Àpẹẹrẹ wo ni àpọ́sítélì Jòhánù fi lélẹ̀ fún wa?

9 Ọ̀rọ̀ ìràpadà ló mú kí ìgbàgbọ́ ọ̀pọ̀ àwọn Kristẹni lágbára gan-an. Bí àpẹẹrẹ, wọn ò dẹ́kun àtimáa wàásù láìka àtakò sí, wọ́n sì fara da onírúurú àdánwò fún ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọdún. Àpẹẹrẹ kan ni àpọ́sítélì Jòhánù. Ó fòótọ́ ọkàn wàásù nípa Kristi àti ìràpadà fún ohun tó ju ọgọ́ta (60) ọdún lọ. Nígbà tó fẹ́rẹ̀ẹ́ pé ẹni ọgọ́rùn-ún (100) ọdún, ìjọba Róòmù kà á sí ẹni tó lè dá wàhálà sílẹ̀ nílùú. Torí náà, wọ́n fi í sẹ́wọ̀n ní erékùṣù Pátímọ́sì. Kí lẹ̀ṣẹ̀ ẹ̀? Ó sọ pé: “Mò ń sọ̀rọ̀ nípa Ọlọ́run, mo sì ń jẹ́rìí nípa Jésù.” (Ìfi. 1:9) Ẹ ò rí i pé àpẹẹrẹ àtàtà ni Jòhánù jẹ́ tó bá dọ̀rọ̀ ká nígbàgbọ́, ká sì lẹ́mìí ìfaradà!

10. Kí ni Jòhánù sọ tó fi hàn pé ó mọyì ìràpadà?

10 Ọ̀pọ̀ ìgbà ni Jòhánù sọ bó ṣe nífẹ̀ẹ́ Jésù tó àti bó ṣe mọyì ìràpadà. Nínú àwọn ìwé tó kọ, ó ju ọgọ́rùn-ún (100) ìgbà lọ tó tọ́ka sí ìràpadà tàbí àǹfààní tí ìràpadà ń mú wá. Bí àpẹẹrẹ, ó sọ pé: “Tí ẹnikẹ́ni bá dẹ́ṣẹ̀, a ní olùrànlọ́wọ́ lọ́dọ̀ Baba, Jésù Kristi, ẹni tó jẹ́ olódodo.” (1 Jòh. 2:​1, 2) Jòhánù tún tẹnu mọ́ bó ti ṣe pàtàkì tó pé ká máa “jẹ́rìí nípa Jésù.” (Ìfi. 19:10) Ó dájú pé Jòhánù mọyì ìràpadà gan-an. Báwo làwa náà ṣe lè fi hàn pé a mọyì ìràpadà?

BÁ A ṢE LÈ FI HÀN PÉ A MỌ OORE TÍ JÈHÓFÀ ṢE FÚN WA

Tá a bá mọyì ìràpadà lóòótọ́, a máa sá fún ẹ̀ṣẹ̀ (Wo ìpínrọ̀ 11) *

11. Kí la lè ṣe tá ò fi ní kó sínú ìdẹwò?

11 Sá fún ẹ̀ṣẹ̀. Tá a bá mọyì ìràpadà lóòótọ́, a ò ní máa ronú pé: ‘Ẹlẹ́ran ara ni mí, kò sídìí tó fi yẹ kí n máa tiraka láti má dẹ́ṣẹ̀. Mo lè dẹ́ṣẹ̀, màá sì tọrọ ìdáríjì.’ Kàkà bẹ́ẹ̀, tá a bá kojú ìdẹwò, ṣe ló yẹ ká sọ pé: ‘Láé mi ò jẹ́ ṣe bẹ́ẹ̀! Báwo ni màá ṣe ṣe irú nǹkan bẹ́ẹ̀ ládúrú gbogbo ohun tí Jèhófà àti Jésù ti ṣe fún mi?’ Torí pé ó wù ẹ́ láti ṣe ohun tó tọ́, o lè bẹ Jèhófà pé kó fún ẹ lókun, kó má sì jẹ́ kó o dẹ́ṣẹ̀ tó o bá kojú ìdẹwò.​—Mát. 6:13.

12. Báwo la ṣe lè fi ìmọ̀ràn tó wà nínú 1 Jòhánù 3:​16-18 sílò?

12 Nífẹ̀ẹ́ àwọn arákùnrin àtàwọn arábìnrin rẹ. Tá a bá nífẹ̀ẹ́ àwọn ará wa, ṣe là ń fi hàn pé a mọyì ìràpadà. Kí nìdí tá a fi sọ bẹ́ẹ̀? Ìdí ni pé kì í ṣe àwa nìkan ni Jésù kú fún, ó kú fún gbogbo àwọn ará wa lọ́kùnrin àti lóbìnrin náà. Ti pé Jésù kú fún wọn fi hàn pé wọ́n ṣeyebíye lójú rẹ̀. (Ka 1 Jòhánù 3:​16-18.) Ohun tá a bá ṣe fún àwọn ará wa ló máa fi hàn bóyá a nífẹ̀ẹ́ wọn tàbí a ò nífẹ̀ẹ́ wọn. (Éfé. 4:​29, 31–5:2) Bí àpẹẹrẹ, a máa ń ràn wọ́n lọ́wọ́ nígbà tí wọ́n bá ń ṣàìsàn, tí wọ́n ń kojú àdánwò tàbí tí àjálù dé bá wọn. Àmọ́ kí ló yẹ ká ṣe tí ẹnì kan nínú ìjọ bá sọ ọ̀rọ̀ tàbí ṣe ohun kan tó dùn wá?

13. Kí nìdí tó fi yẹ ká máa dárí jini?

13 Ṣé o máa ń di ẹni tó bá ṣẹ̀ ẹ́ sínú? (Léf. 19:18) Tó bá rí bẹ́ẹ̀, fi ìmọ̀ràn Bíbélì yìí sílò pé: “Ẹ máa fara dà á fún ara yín, kí ẹ sì máa dárí ji ara yín fàlàlà, kódà tí ẹnikẹ́ni bá ní ìdí láti fẹ̀sùn kan ẹlòmíì. Bí Jèhófà ṣe dárí jì yín ní fàlàlà, ẹ̀yin náà gbọ́dọ̀ máa ṣe bẹ́ẹ̀.” (Kól. 3:13) Gbogbo ìgbà tá a bá dárí ji arákùnrin tàbí arábìnrin kan, ṣe là ń jẹ́ kí Jèhófà mọ̀ pé a mọyì ìràpadà náà lóòótọ́. Kí la lè ṣe táá jẹ́ ká túbọ̀ mọyì ìràpadà náà?

BÁ A ṢE LÈ TÚBỌ̀ MỌYÌ ÌRÀPADÀ

14. Sọ ohun kan tá a lè ṣe táá jẹ́ ká túbọ̀ mọyì ìràpadà.

14 Máa dúpẹ́ lọ́wọ́ Jèhófà fún ìràpadà náà. Arábìnrin Joanna tó jẹ́ ẹni ọdún mẹ́tàlélọ́gọ́rin (83), tó sì ń gbé lórílẹ̀-èdè India sọ pé: “Mo máa ń ronú nípa ìràpadà lójoojúmọ́, mo sì máa ń dúpẹ́ lọ́wọ́ Jèhófà nípa ẹ̀ nínú àdúrà. Lọ́jọ́ kọ̀ọ̀kan tó o bá ń gbàdúrà, sọ àwọn nǹkan tó kù díẹ̀ káàtó tó o ṣe fún Jèhófà, kó o sì bẹ̀ ẹ́ pé kó dárí jì ẹ́. Àmọ́ tó bá jẹ́ pé ẹ̀ṣẹ̀ tó wúwo ni, ó máa gba pé kó o sọ fáwọn alàgbà. Wọ́n á tẹ́tí sí ẹ, wọ́n á sì fi Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run ràn ẹ́ lọ́wọ́. Yàtọ̀ síyẹn, wọ́n á gbàdúrà fún ẹ, wọ́n á sì bẹ Jèhófà pé kó wo ọlá ẹbọ ìràpadà náà mọ́ ẹ lára kó o lè rí ìmúláradá nípa tẹ̀mí.”​—Jém. 5:​14-16.

15. Kí nìdí tó fi yẹ ká máa wáyè kẹ́kọ̀ọ́ nípa ìràpadà ká sì ronú jinlẹ̀ lé e lórí?

15 Máa ronú jinlẹ̀ nípa ìràpadà. Arábìnrin Rajamani tó jẹ́ ẹni ọdún mẹ́tàléláàádọ́rin (73) sọ pé: “Kò sígbà tí mò ń kà nípa ìyà tí wọ́n fi jẹ Jésù tí omi kì í lé ròrò sí mi lójú.” Ṣé ó máa ń dun ìwọ náà tó o bá ń kà nípa bí wọ́n ṣe fìyà jẹ Jésù gan-an? Tó bá rí bẹ́ẹ̀, bó o bá ṣe ń ronú jinlẹ̀ nípa ìràpadà tí Jésù ṣe, bẹ́ẹ̀ ni ìfẹ́ tó o ní fún un àti fún Bàbá rẹ̀ ṣe máa jinlẹ̀ sí i. Kó o lè túbọ̀ mọyì ìràpadà, o ò ṣe wáyè láti kẹ́kọ̀ọ́ nípa ẹ̀?

Jésù ṣe ètò ráńpẹ́ kan káwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ lè mọ bí wọ́n á ṣe máa rántí ìràpadà náà (Wo ìpínrọ̀ 16)

16. Tó o bá ń kọ́ àwọn míì nípa ìràpadà, àǹfààní wo nìyẹn máa ṣe ẹ́? (Wo àwòrán iwájú ìwé.)

16 Máa kọ́ àwọn míì nípa ìràpadà. Bá a bá ṣe ń kọ́ àwọn míì nípa ìràpadà, bẹ́ẹ̀ làwa náà á túbọ̀ máa mọyì ẹ̀. A ní àwọn ìwé àtàwọn fídíò tá a lè fi kọ́ àwọn míì nípa ìdí tí Jésù fi kú fún wa. Bí àpẹẹrẹ, a lè lo ẹ̀kọ́ kẹrin nínú ìwé Ìròyìn Ayọ̀ Látọ̀dọ̀ Ọlọ́run! tó ní àkòrí náà “Ta Ni Jésù Kristi?” A sì lè lo orí karùn-ún nínú ìwé Kí Ni Bíbélì Kọ́ Wa? Àkòrí ẹ̀ ni “Ìràpadà Ni Ẹ̀bùn Tó Dáa Jù Lọ Tí Ọlọ́run Fún Wa.” Yàtọ̀ síyẹn, bá a ṣe ń lọ sí Ìrántí Ikú Kristi lọ́dọọdún, tá a sì ń pe àwọn míì wá síbẹ̀ ń mú ká túbọ̀ mọyì ìràpadà. Àbí ẹ ò rí i pé àǹfààní ńlá ni Jèhófà fún wa láti máa kọ́ àwọn míì nípa Ọmọ rẹ̀!

17. Kí nìdí tá a fi sọ pé ìràpadà ni ẹ̀bùn tó ṣeyebíye jù lọ tí Ọlọ́run fún wa?

17 Láìsí tàbí-ṣùgbọ́n, a ní ọ̀pọ̀ ìdí tó fi yẹ ká mọyì ìràpadà. Ìràpadà yìí ló mú kó ṣeé ṣe fún wa láti ní àjọṣe tímọ́tímọ́ pẹ̀lú Jèhófà bá a tiẹ̀ jẹ́ aláìpé. Ìràpadà yìí ló máa jẹ́ kí Jésù fọ́ àwọn iṣẹ́ Èṣù túútúú. (1 Jòh. 3:8) Bákan náà, ìràpadà ló máa jẹ́ kí ohun tí Jèhófà ní lọ́kàn fún ayé yìí nímùúṣẹ. Láìpẹ́ gbogbo ayé máa di Párádísè. Ìwọ àti gbogbo àwọn tó bá gbé láyé nígbà yẹn máa nífẹ̀ẹ́ Jèhófà, ẹ̀ẹ́ sì máa sìn ín. Nítorí náà, ẹ jẹ́ ká máa wáyè lójoojúmọ́ láti fi hàn pé a mọyì ìràpadà tó jẹ́ ẹ̀bùn tó ṣeyebíye jù lọ tí Jèhófà fún wa!

ORIN 20 O Fún Wa Ní Ọmọ Rẹ Ọ̀wọ́n

^ ìpínrọ̀ 5 Kí nìdí tí Jésù fi kú ikú oró? A máa dáhùn ìbéèrè yìí nínú àpilẹ̀kọ yìí, ìyẹn á sì jẹ́ ká túbọ̀ mọyì ìràpadà.

^ ìpínrọ̀ 6 Ohun tí àwọn ará Róòmù sábà máa ń ṣe tí wọ́n bá fẹ́ pa ọ̀daràn kan ni pé wọ́n máa ń kàn án tàbí kí wọ́n so ó mọ́ òpó igi nígbà tó ṣì wà láàyè, Jèhófà sì fàyè gbà á pé kí wọ́n pa Ọmọ òun lọ́nà yẹn.

^ ìpínrọ̀ 55 ÀWÒRÁN: Àwọn arákùnrin mẹ́ta kojú ìdẹwò ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀. Ọ̀kan kọ̀ láti wo ìwòkuwò, èkejì kọ̀ láti mu sìgá, ẹnì kẹta sì kọ̀ láti gba àbẹ̀tẹ́lẹ̀.