Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

ÌTÀN ÌGBÉSÍ AYÉ

“Mo Kẹ́kọ̀ọ́ Gan-an Lára Àwọn Míì!”

“Mo Kẹ́kọ̀ọ́ Gan-an Lára Àwọn Míì!”

Ọ̀DỌ́ ni mí nígbà tí mo wọṣẹ́ ológun. Òkè kan lórílẹ̀-èdè Algeria làwa ọmọ ogun Faransé pabùdó sí, bẹ́ẹ̀ ni ọta ìbọn ń dún lọ́tùn-ún lósì. Lálẹ́ ọjọ́ kan tí mò ń ṣọ́ ibùdó, mo fara pa mọ́ síbì kan pẹ̀lú ìbọn mi lọ́wọ́. Ṣàdédé ni mo gbọ́ bíi pé àwọn kan ń bọ̀ lọ́dọ̀ mi. Ẹ̀rù bà mí torí pé ọ̀dọ́ ṣì ni mí nígbà yẹn. Mi ò fẹ́ pààyàn, èmi náà ò sì fẹ́ kú. Ni mo bá kígbe pé: “Áà! Ọlọ́run gbà mí o!”

Ohun tó ṣẹlẹ̀ lọ́jọ́ yẹn ló yí ìgbésí ayé mi pa dà torí àtìgbà yẹn ni mo ti bẹ̀rẹ̀ sí í wá Ọlọ́run. Kí n tó máa bá ìtàn yẹn lọ, ẹ jẹ́ kí n sọ ohun tó ṣẹlẹ̀ sí mi ní kékeré tó mú kí n máa wá Ọlọ́run nígbà tí mo dàgbà.

MO KẸ́KỌ̀Ọ́ LÁRA BÀBÁ MI

Ọdún 1937 ni wọ́n bí mi ní ìlú Guesnain, ìyẹn ìlú kan tí wọ́n ti ń wa kùsà lórílẹ̀-èdè Faransé. Awakùsà ni bàbá mi, àwọn ló sì kọ́ mi pé ó ṣe pàtàkì kéèyàn máa ṣiṣẹ́ kára. Bàbá mi ò fẹ́ kéèyàn máa rẹ́ni jẹ, ìyẹn ló mú kémi náà kórìíra ìwà ìrẹ́jẹ. Bí àpẹẹrẹ, wọ́n kíyè sí i pé ìyà ń jẹ àwọn awakùsà gan-an. Torí náà, wọ́n dara pọ̀ mọ́ àwọn ẹgbẹ́ tó ń gbèjà àwọn awakùsà, ìyẹn sì mú kí wọ́n máa daṣẹ́ sílẹ̀ lọ́pọ̀ ìgbà. Yàtọ̀ síyẹn, wọ́n kórìíra àwọn àlùfáà ṣọ́ọ̀ṣì tó wà ládùúgbò wa torí ìwà àgàbàgebè wọn. Ọ̀pọ̀ wọn ló ń gbé ìgbé ayé ìdẹ̀rùn, síbẹ̀ wọ́n tún máa ń gba tọwọ́ àwọn awakùsà tí ò ní lọ́wọ́. Bàbá mi kórìíra àwọn àlùfáà yìí débi pé wọn ò jẹ́ kí n lọ sílé ìjọsìn kankan. Kódà, wọn ò bá mi sọ̀rọ̀ nípa Ọlọ́run rí.

Bí mo ṣe ń dàgbà, èmi náà kórìíra ìwà ìrẹ́jẹ. Kódà inú máa ń bí mi tí n bá ń rí i tí wọ́n ń hùwà àìdáa sáwọn àjèjì tó ń gbé lórílẹ̀-èdè Faransé. Mo máa ń bá àwọn ọmọ àjèjì gbá bọ́ọ̀lù, a sì jọ máa ń ṣeré. Yàtọ̀ síyẹn, ọmọ ilẹ̀ Poland ni màmá mi, wọn kì í ṣe ọmọ Faransé. Torí náà, ó wù mí kí ìrẹ́pọ̀ wà láàárín gbogbo èèyàn láìka ibi tí wọ́n ti wá sí.

MO BẸ̀RẸ̀ SÍ Í RONÚ NÍPA ÌGBÉSÍ AYÉ ÀWA ÈÈYÀN

Nígbà tí mo wà lẹ́nu iṣẹ́ ológun

Ọdún 1957 ni mo wọṣẹ́ ológun. Ìyẹn ló gbé mi dé ibi òkè tí mo mẹ́nu bà níbẹ̀rẹ̀. Lẹ́yìn tí mo pariwo pé, “Ọlọ́run gbà mí o!” Mo gbójú sókè, ǹjẹ́ ẹ mọ ohun tí mo rí? Kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ igbó lásán ni kì í ṣe àwọn ọ̀tá! Ṣe lọkàn mi balẹ̀. Ohun tó ṣẹlẹ̀ lọ́jọ́ yẹn títí kan ogun náà ló mú kí n bẹ̀rẹ̀ sí í ronú nípa ìgbésí ayé àwa èèyàn. Mo wá bẹ̀rẹ̀ sí í bi ara mi pé, kí la wá ṣe láyé gan-an? Ṣé Ọlọ́run tiẹ̀ nífẹ̀ẹ́ wa? Ìgbà wo ni àlàáfíà máa jọba láyé yìí?

Nígbà kan tí mo gba ìsinmi lẹ́nu iṣẹ́, mo lọ kí àwọn òbí mi, ibẹ̀ ni mo ti pàdé Ẹlẹ́rìí Jèhófà kan. Ó fún mi ní Bíbélì kan táwọn Kátólíìkì ṣe lédè Faransé, ìyẹn La Sainte Bible, mo sì bẹ̀rẹ̀ sí í kà á lẹ́yìn tí mo pa dà sí Algeria. Ẹsẹ Bíbélì kan tó wọ̀ mí lọ́kàn ni Ìfihàn 21:3, 4 tó kà pé: “Àgọ́ Ọlọ́run wà pẹ̀lú aráyé . . . Ó máa nu gbogbo omijé kúrò ní ojú wọn, ikú ò ní sí mọ́, kò ní sí ọ̀fọ̀ tàbí ẹkún tàbí ìrora mọ́.” * Àwọn ọ̀rọ̀ yẹn yà mí lẹ́nu. Mo ronú pé, ‘Ṣé ó lè jóòótọ́ ṣá?’ Ìdí ni pé nígbà yẹn, mi ò mọ ohunkóhun nípa Ọlọ́run àti Bíbélì.

Lẹ́yìn tí mo fiṣẹ́ ológun sílẹ̀ lọ́dún 1959, mo pàdé Ẹlẹ́rìí Jèhófà kan tó ń jẹ́ François, ó sì kọ́ mi lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. Bí àpẹẹrẹ, ó fi hàn mí nínú Bíbélì pé Jèhófà ni orúkọ Ọlọ́run. (Sm. 83:18) Ó tún ṣàlàyé fún mi pé Jèhófà máa fòpin sí ìwà ìrẹ́jẹ, á sọ ayé di Párádísè, á sì mú àsọtẹ́lẹ̀ tó wà nínú Ìfihàn 21:3, 4 ṣẹ.

Àwọn ohun tó kọ́ mi yẹn bọ́gbọ́n mu, ó sì wọ̀ mí lọ́kàn. Ohun tí mo kọ́ yẹn jẹ́ kí n mọ̀ pé ẹ̀kọ́ èké làwọn àlùfáà ṣọ́ọ̀ṣì fi ń kọ́ni, ìyẹn múnú bí mi gan-an, ó sì ṣe mí bíi kí n tú àṣírí wọn fáyé gbọ́! Ara mi ò balẹ̀ rárá, ó sì jọ pé irú èrò tí bàbá mi ní lèmi náà ní. Mi ò kì í ṣe sùúrù.

François àtàwọn Ẹlẹ́rìí míì tí wọ́n jẹ́ ọ̀rẹ́ mi ràn mí lọ́wọ́ kí n lè máa fara balẹ̀, kí n má sì tètè máa bínú. Wọ́n ṣàlàyé fún mi pé àwa Kristẹni kì í ṣèdájọ́ àwọn èèyàn, àmọ́ a máa ń jẹ́ kí wọ́n mọ̀ pé Ìjọba Ọlọ́run nìkan ṣoṣo ló máa yanjú ìṣòro aráyé. Iṣẹ́ tí Jésù ṣe nìyẹn, òun náà ló sì ní káwọn ọmọlẹ́yìn òun máa ṣe. (Mát. 24:14; Lúùkù 4:43) Wọ́n tún kọ́ mi bí mo ṣe lè máa fọgbọ́n bá àwọn èèyàn sọ̀rọ̀ tìfẹ́tìfẹ́ láìka ẹ̀sìn tí wọ́n ń ṣe sí. Ìyẹn sì bá ohun tí Bíbélì sọ mu pé: “Kò yẹ kí ẹrú Olúwa máa jà, àmọ́ ó yẹ kó máa hùwà jẹ́jẹ́ sí gbogbo èèyàn.”​—2 Tím. 2:24.

Mo ṣe àwọn àyípadà tó yẹ, mo sì ṣèrìbọmi ní àpéjọ àyíká kan tá a ṣe lọ́dún 1959. Ibẹ̀ ni mo ti pàdé ọ̀dọ́bìnrin kan tó ń jẹ́ Angèle, mo sì dẹnu ìfẹ́ kọ ọ́. Mo máa ń lọ kí i níjọ ẹ̀, a sì ṣègbéyàwó lọ́dún 1960. Obìnrin àtàtà ni ìyàwó mi, aya rere lọ́ọ̀dẹ̀ ọkọ ni, kódà ẹ̀bùn ló jẹ́ fún mi látọ̀dọ̀ Jèhófà.​—Òwe 19:14.

Ọjọ́ ìgbéyàwó wa

MO KẸ́KỌ̀Ọ́ GAN-AN LÁRA ÀWỌN ỌKÙNRIN TÓ NÍRÌÍRÍ

Bọ́dún ṣe ń gorí ọdún, mo túbọ̀ ń kọ́ àwọn ẹ̀kọ́ pàtàkì látọ̀dọ̀ àwọn arákùnrin tó nírìírí. Ọ̀kan lára àwọn ẹ̀kọ́ pàtàkì tí mo kọ́ ni pé, kéèyàn tó lè ṣàṣeyọrí lẹ́nu iṣẹ́ ìsìn èyíkéyìí, ó gbọ́dọ̀ nírẹ̀lẹ̀, kó sì fi ìmọ̀ràn tó wà nínú Òwe 15:22 sọ́kàn, tó sọ pé: “Nípasẹ̀ ọ̀pọ̀ agbani-nímọ̀ràn, àṣeyọrí á wà.”

Nígbà tá à ń ṣiṣẹ́ alábòójútó àyíká lórílẹ̀-èdè Faransé lọ́dún 1965

Ohun kan ṣẹlẹ̀ lọ́dún 1964 tó jẹ́ kí n gbà pé òótọ́ lọ̀rọ̀ Bíbélì yẹn. Ọdún yẹn ni wọ́n sọ mí di alábòójútó àyíká, mo sì ń bẹ àwọn ìjọ wò láti fún wọn níṣìírí. Àmọ́ ọmọ ọdún mẹ́tàdínlọ́gbọ̀n (27) péré ni mí nígbà yẹn, torí náà mo máa ń ṣàṣìṣe. Síbẹ̀, mo máa ń kẹ́kọ̀ọ́ látinú àwọn àṣìṣe mi. Ju gbogbo ẹ̀ lọ, mo kọ́ àwọn ẹ̀kọ́ pàtàkì látọ̀dọ̀ àwọn “agbani-nímọ̀ràn” tó nírìírí.

Ẹ jẹ́ kí n fún yín lápẹẹrẹ kan. Lẹ́yìn tí mo bẹ ìjọ kan wò nílùú Paris, arákùnrin kan tó nírìírí sọ fún mi pé àwọn máa fẹ́ rí mi. Mo dá wọn lóhùn pé, “Ó dáa.”

Wọ́n bi mí pé, “Louis, àwọn wo ni dókítà máa ń lọ bẹ̀ wò?”

Mo fèsì pé, “àwọn aláìsàn ni.”

Wọ́n wá sọ fún mi pé: “Òótọ́ lo sọ. Àmọ́ mo kíyè sí i pé àwọn tó ń ṣe dáadáa nípa tẹ̀mí lo sábà máa ń wà pẹ̀lú, irú bí àwọn alábòójútó ìjọ. Bẹ́ẹ̀ sì rèé, ọ̀pọ̀ àwọn arákùnrin àtàwọn arábìnrin ló wà nínú ìjọ wa tó máa ń rẹ̀wẹ̀sì, àwọn míì ṣẹ̀ṣẹ̀ kẹ́kọ̀ọ́ òtítọ́, àwọn kan sì máa ń tijú. Inú wọn á dùn gan-an tó o bá lè máa lo àkókò pẹ̀lú wọn, kódà o lè lọ sílé wọn kẹ́ ẹ lè jọ jẹun.”

Mo mọyì ìmọ̀ràn tí arákùnrin yẹn fún mi gan-an. Ohun tí wọ́n ṣe yẹn jẹ́ kí n rí i pé wọ́n nífẹ̀ẹ́ àwọn àgùntàn Jèhófà. Torí náà, mo gbà pé ó yẹ kí n ṣàtúnṣe, mo sì bẹ̀rẹ̀ sí í fìmọ̀ràn yẹn sílò lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀. Mo dúpẹ́ lọ́wọ́ Jèhófà fún irú àwọn arákùnrin bẹ́ẹ̀.

Lọ́dún 1969 àti 1973, wọ́n ní kí n ṣe kòkáárí Ẹ̀ka Tó Ń Bójú Tó Oúnjẹ ní àpéjọ àgbáyé méjì tá a ṣe ní Colombes, nílùú Paris. Ní àpéjọ tá a ṣe lọ́dún 1973, àwọn tá a máa fún lóúnjẹ fẹ́rẹ̀ẹ́ tó ẹgbẹ̀rún lọ́nà ọgọ́ta (60,000), ọjọ́ márùn-ún la sì máa fi bọ́ wọn! Kí n má parọ́, iṣẹ́ yẹn kà mí láyà. Àmọ́ ohun tó wà nínú Òwe 15:22 tún ràn mí lọ́wọ́, ìyẹn ni pé kí n gbàmọ̀ràn lọ́dọ̀ àwọn tó nírìírí. Mo fọ̀rọ̀ lọ àwọn arákùnrin tí òtítọ́ jinlẹ̀ nínú wọn, tí wọ́n sì nírìírí tó bá kan ọ̀rọ̀ ṣíṣètò oúnjẹ. Àwọn kan lára wọn jẹ́ alápatà, àgbẹ̀, alásè àtàwọn tó mọ ọjà rà. Bá a ṣe pawọ́ pọ̀ ṣiṣẹ́ yìí mú ká ṣàṣeyọrí.

Lọ́dún 1973, wọ́n ní kémi àtìyàwó mi wá máa sìn ní Bẹ́tẹ́lì tó wà lórílẹ̀-èdè Faransé. Iṣẹ́ tí wọ́n kọ́kọ́ yàn fún mi lọ́hùn-ún ò rọrùn rárá. Wọ́n ní kí n ṣètò bí àwọn ìtẹ̀jáde wa ṣe máa dé ọ̀dọ̀ àwọn ará tó wà ní Kamẹrúùnù níbi tí wọ́n ti fòfin de iṣẹ́ wa láti 1970 sí 1993. Kí n sòótọ́, iṣẹ́ yìí náà tún kà mí láyà. Nígbà tí arákùnrin tó ń bójú tó ẹ̀ka ọ́fíìsì yẹn kíyè sí mi, ó gbà mí níyànjú pé: “Ebi tẹ̀mí ń pa àwọn ará wa tó wà ní Kamẹrúùnù gan-an, ó sì yẹ ká wá nǹkan ṣe sí i!” Ohun tá a ṣe gan-an nìyẹn, a rí i dájú pé wọ́n róúnjẹ tẹ̀mí gbà déédéé.

Ní ìpàdé kan tá a ṣe ní Nàìjíríà pẹ̀lú àwọn ará láti Kamẹrúùnù lọ́dún 1973

Ọ̀pọ̀ ìgbà ni mo lọ sáwọn orílẹ̀-èdè tó múlé gbe Kamẹrúùnù kí n lè ṣèpàdé pẹ̀lú àwọn alàgbà tó wà lórílẹ̀-èdè Kamẹrúùnù. Onígboyà làwọn arákùnrin yẹn, wọ́n sì gbọ́n gan-an. Àwọn ló ràn mí lọ́wọ́ láti rí i dájú pé oúnjẹ tẹ̀mí ń wọ Kamẹrúùnù déédéé. Jèhófà bù kún ìsapá wa gan-an. Kódà, fún nǹkan bí ogún (20) ọdún, kò sígbà kan táwọn ará wa ní Kamẹrúùnù ṣaláìní Ilé Ìṣọ́ àti ìtẹ̀jáde oṣooṣù tá a pè ní Iṣẹ-Isin Ijọba Wa.

Lọ́dún 1977, èmi àti ìyàwó mi ṣèbẹ̀wò sí Nàìjíríà ká lè ṣèpàdé pẹ̀lú àwọn alábòójútó àyíká àti ìyàwó wọn tó wá láti Kamẹrúùnù

MO KẸ́KỌ̀Ọ́ GAN-AN LÁRA ÌYÀWÓ MI

Àtìgbà tá a ti ń fẹ́ra sọ́nà ni mo ti rí i pé ẹni tẹ̀mí ni Angèle. Èyí sì túbọ̀ hàn kedere lẹ́yìn tá a ṣègbéyàwó. Kódà, lálẹ́ ọjọ́ tá a ṣègbéyàwó, ó sọ fún mi pé kí n bẹ Jèhófà pé kó fún wa láǹfààní láti fi gbogbo ìgbésí ayé wa sìn ín. Jèhófà sì dáhùn àdúrà náà.

Angèle tún ràn mí lọ́wọ́ kí n lè túbọ̀ gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà. Bí àpẹẹrẹ, nígbà tí wọ́n ní ká wá sìn ní Bẹ́tẹ́lì lọ́dún 1973, kò wù mí lọ torí mò ń gbádùn iṣẹ́ alábòójútó àyíká. Àmọ́ ìyàwó mi rán mi létí pé Jèhófà la ya ara wa sí mímọ́ fún, ohunkóhun tí ètò rẹ̀ bá sì ní ká ṣe la máa ṣe, àbí bẹ́ẹ̀ kọ́? (Héb. 13:17) Òótọ́ ló kúkú sọ! Bá a ṣe lọ sí Bẹ́tẹ́lì nìyẹn o. Aláròjinlẹ̀ ni ìyàwó mi, ó máa ń gba tàwọn èèyàn rò, ó sì nífẹ̀ẹ́ Jèhófà gan-an. Èyí ti mú ká lè máa ṣe àwọn ìpinnu tó tọ́, kí ìgbéyàwó wa sì lárinrin.

Èmi àti Angèle ìyàwó mi nínú ọgbà kan ní Bẹ́tẹ́lì lórílẹ̀-èdè Faransé

Ìyàwó mi ṣì ń tì mí lẹ́yìn bó tiẹ̀ jẹ́ pé ara ti ń dara àgbà báyìí. Bí àpẹẹrẹ, ká lè lọ sáwọn ilé ẹ̀kọ́ ètò Ọlọ́run, èmi àtìyàwó mi sapá gan-an láti kọ́ èdè Gẹ̀ẹ́sì torí èdè yẹn ni wọ́n fi ń darí èyí tó pọ̀ jù nínú àwọn ilé ẹ̀kọ́ náà. Ìyẹn gba pé ká dara pọ̀ mọ́ ìjọ tó ń sọ èdè Gẹ̀ẹ́sì bó tiẹ̀ jẹ́ pé a ti lé lẹ́ni àádọ́rin (70) ọdún nígbà yẹn. Nígbà tí mò ń sọ yìí, mo wà lára Ìgbìmọ̀ Ẹ̀ka orílẹ̀-èdè Faransé torí náà, kò rọrùn fún mi rárá láti kọ́ èdè míì. Àmọ́ èmi àtìyàwó mi máa ń ran ara wa lọ́wọ́. Ní báyìí tá a ti lé lẹ́ni ọgọ́rin (80) ọdún, a ṣì máa ń múra ìpàdé sílẹ̀ ní èdè Gẹ̀ẹ́sì àti Faransé. A tún ń ṣe gbogbo ohun tá a lè ṣe láti rí i dájú pé à ń lóhùn sípàdé, a sì ń jáde òde ẹ̀rí pẹ̀lú ìjọ wa. Kò sí àní-àní pé Jèhófà ti bù kún ìsapá wa láti kọ́ èdè Gẹ̀ẹ́sì.

Lọ́dún 2017, ètò Ọlọ́run fún èmi àtìyàwó mi láǹfààní láti lọ sí Ilé Ẹ̀kọ́ Àwọn Ìgbìmọ̀ Ẹ̀ka Àtàwọn Ìyàwó Wọn ní Patterson New York. A ò lè gbàgbé ìbùkún tí Jèhófà fún wa yìí láé.

Jèhófà ni Olùkọ́ wa Atóbilọ́lá lóòótọ́. (Àìsá. 30:20) Torí náà, kò yani lẹ́nu pé gbogbo àwa èèyàn rẹ̀ lọ́mọdé àti lágbà là ń gba ẹ̀kọ́ tó dára jù lọ! (Diu. 4:5-8) Mo ti rí i pé àwọn ọ̀dọ́ tó bá ń fetí sí Jèhófà àtàwọn ará tó nírìírí máa ń tẹ̀ síwájú gan-an nípa tẹ̀mí, ìgbésí ayé wọn sì máa ń nítumọ̀. Ó dájú pé òótọ́ lọ̀rọ̀ inú Òwe 9:9 tó sọ pé: “Kọ́ ọlọ́gbọ́n, yóò sì gbọ́n sí i. Kọ́ olódodo, yóò sì kọ́ ẹ̀kọ́ sí i.”

Lẹ́ẹ̀kọ̀ọ̀kan, mo máa ń rántí ohun tó ṣẹlẹ̀ lálẹ́ ọjọ́ tí mo wà lórí òkè yẹn ní Algeria ní nǹkan bí ọgọ́ta (60) ọdún sẹ́yìn. Mi ò mọ̀ lálẹ́ ọjọ́ yẹn pé ìgbésí ayé mi ṣì máa dùn bí oyin. Mo ti kẹ́kọ̀ọ́ gan-an lára àwọn míì. Jèhófà sì ti mú kí ìgbésí ayé èmi àti Angèle ìyàwó mi lárinrin gan-an. Torí náà, a ti pinnu pé a ò ní yéé kẹ́kọ̀ọ́ lọ́dọ̀ Jèhófà Baba wa ọ̀run àti lọ́dọ̀ àwọn arákùnrin àtàwọn arábìnrin tó nírìírí, tí wọ́n sì nífẹ̀ẹ́ Jèhófà.

^ ìpínrọ̀ 11 Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun.