Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Ǹjẹ́ O Mọ̀?

Ǹjẹ́ O Mọ̀?

Ṣé wọ́n máa ń fi òrépèté ṣe ọkọ̀ ojú omi láyé ìgbà tí wọ́n ń kọ Bíbélì?

Igi òrépèté

Ọ̀PỌ̀ èèyàn mọ̀ pé ewéko kan tí wọ́n ń pè ní òrépèté làwọn ará Íjíbítì àtijọ́ máa ń kọ̀wé sí. Bákan náà, òrépèté làwọn Gíríìkì àtàwọn ará Róòmù fi máa ń kọ̀wé. * Àmọ́, ọ̀pọ̀ èèyàn ò mọ̀ pé wọ́n tún máa ń lo òrépèté láti fi ṣe ọkọ̀ ojú omi.

Ẹ̀dà ọkọ̀ ojú omi tí wọ́n fi òrépèté ṣe tí wọ́n rí nínú ibojì kan nílẹ̀ Íjíbítì

Ní ohun tó lé ní ẹgbẹ̀rún ọdún méjì ààbọ̀ (2,500) sẹ́yìn, wòlíì Àìsáyà sọ pé àwọn tó ń gbé “ní agbègbè àwọn odò Etiópíà . . . rán àwọn aṣojú gba ojú òkun, wọ́n gba orí omi nínú àwọn ọkọ̀ tí wọ́n fi òrépèté ṣe.” Nígbà tó yá, wòlíì Jeremáyà sọ tẹ́lẹ̀ pé nígbà táwọn ọmọ ogun Mídíà àti Páṣíà bá máa gbógun ja ìlú Bábílónì, wọ́n máa finá sun “ọkọ̀ ojú omi tí a fi òrépèté ṣe” káwọn ará Bábílónì má bàa rọ́nà sá lọ.​—Àìsá. 18:1, 2; Jer. 51:32.

Ìwé tí Ọlọ́run mí sí ni Bíbélì, torí náà kò ya àwa akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì lẹ́nu pé àwọn awalẹ̀pìtàn rí i pé wọ́n fi òrépèté ṣe ọkọ̀ ojú omi láyé ìgbàanì. (2 Tím. 3:16) Kí lohun tí wọ́n rí gan-an? Àwọn awalẹ̀pìtàn ṣàwárí ọ̀pọ̀ ẹ̀rí tó fi hàn pé àwọn ará Íjíbítì máa ń fi òrépèté ṣe ọkọ̀ ojú omi.

BÁWO NI WỌ́N ṢE MÁA Ń FI ÒRÉPÈTÉ ṢE ỌKỌ̀ OJÚ OMI?

Àwọn àwòrán tí wọ́n rí lára àwọn ibojì kan nílẹ̀ Íjíbítì ṣàfihàn bí wọ́n ṣe máa ń kórè òrépèté àti bí wọ́n ṣe ń lò ó láti ṣe ọkọ̀ ojú omi. Àwọn ọkùnrin máa la igi òrépèté, wọ́n á kó wọn jọ, wọ́n á sì dì wọ́n pa pọ̀. Igun mẹ́ta ni igi òrépèté sábà máa ń ní. Tí wọ́n bá dì wọ́n pa pọ̀, ṣe ni wọ́n máa ń le dan-in dan-in. Ìwé A Companion to Ancient Egypt sọ pé àwọn ọkọ̀ ojú omi tí wọ́n fi òrépèté ṣe lè gùn ju mítà mẹ́tàdínlógún (17) lọ, wọ́n sì lè lo àjẹ̀ mẹ́wàá tàbí méjìlá lẹ́gbẹ̀ẹ́ kọ̀ọ̀kan.

Àwòrán kan nílẹ̀ Íjíbítì jẹ́ ká rí bí wọ́n ṣe máa ń fi òrépèté ṣe ọkọ̀ ojú omi

KÍ NÌDÍ TÍ WỌ́N FI Ń LO ÒRÉPÈTÉ LÁTI ṢE ỌKỌ̀ OJÚ OMI?

Igi òrépèté wọ́pọ̀ gan-an ní agbègbè Odò Náílì. Ó sì rọrùn láti fi òrépèté ṣe ọkọ̀ ojú omi. Kódà, nígbà tí wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí í fi igi ṣe àwọn ọkọ̀ ojú omi ńláńlá, àwọn apẹja àtàwọn ọlọ́dẹ ṣì máa ń lo òrépèté láti ṣe ọkọ̀ ojú omi kékeré.

Ó pẹ́ káwọn èèyàn tó ṣíwọ́ àtimáa lo ọkọ̀ ojú omi tí wọ́n fi òrépèté ṣe. Òǹkọ̀wé ọmọ ilẹ̀ Gíríìsì kan tó ń jẹ́ Plutarch, tó gbé láyé láàárín ọgọ́rùn-ún ọdún kìíní àti kejì S.K. sọ pé àwọn ṣì ń lo ọkọ̀ ojú omi tí wọ́n fi òrépèté ṣe lásìkò òun.

^ ìpínrọ̀ 3 Àwọn ibi ẹrọ̀fọ̀ tàbí adágún ni òrépèté ti sábà máa ń hù. Òrépèté lè ga tó mítà márùn-ún, ó sì lè fẹ̀ tó sẹ̀ǹtímítà mẹ́ẹ̀ẹ́dógún (15) nísàlẹ̀.