Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Ìbéèrè Láti Ọwọ́ Àwọn Òǹkàwé

Ìbéèrè Láti Ọwọ́ Àwọn Òǹkàwé

Kí ni àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù ní lọ́kàn nígbà tó sọ pé: “Nípasẹ̀ òfin, mo ti di òkú sí òfin”?​—Gál. 2:19.

Pọ́ọ̀lù sọ pé: “Nípasẹ̀ òfin, mo ti di òkú sí òfin, kí n lè di alààyè sí Ọlọ́run.”​—Gál. 2:19.

Ìgbà tí Pọ́ọ̀lù ń bá àwọn Kristẹni tó wà níjọ Gálátíà sọ̀rọ̀ ló fa kókó yìí yọ. Kí nìdí? Ìdí ni pé àwọn Kristẹni kan ti bẹ̀rẹ̀ sí í gba ẹ̀kọ́ àwọn apẹ̀yìndà gbọ́. Àwọn apẹ̀yìndà yẹn ń kọ́ni pé kéèyàn tó lè rígbàlà, ó gbọ́dọ̀ máa pa àwọn Òfin Mósè mọ́, pàápàá èyí tó dá lórí ìdádọ̀dọ́. Àmọ́ Pọ́ọ̀lù mọ̀ pé kò pọn dandan káwọn Kristẹni dádọ̀dọ́ kí wọ́n tó lè rí ojú rere Ọlọ́run. Pọ́ọ̀lù wá jẹ́ kó ṣe kedere pé ẹ̀kọ́ èké ni wọ́n fi ń kọ́ni, ó sì mú kí àwọn ará túbọ̀ nígbàgbọ́ nínú ẹbọ ìràpadà Jésù Kristi.​—Gál. 2:4; 5:2.

Bíbélì sọ pé téèyàn bá ti kú, kò mọ nǹkan kan mọ́. (Oníw. 9:5) Nígbà tí Pọ́ọ̀lù sọ pé: “Mo ti di òkú sí òfin,” ohun tó ń sọ ni pé òun ò sí lábẹ́ Òfin Mósè mọ́. Dípò ìyẹn, ó dá Pọ́ọ̀lù lójú pé ìgbàgbọ́ tóun ní nínú ẹbọ ìràpadà Jésù ti mú kóun “di alààyè sí Ọlọ́run.”

Pọ́ọ̀lù sọ pé “nípasẹ̀ òfin” ni ìyípadà yìí fi wáyé. Kí nìdí tó fi rí bẹ́ẹ̀? Nínú àwọn ẹsẹ tó ṣáájú, Pọ́ọ̀lù ṣàlàyé pé “kì í ṣe àwọn iṣẹ́ òfin ló ń mú ká pe èèyàn ní olódodo, bí kò ṣe nípasẹ̀ ìgbàgbọ́ nínú Jésù Kristi nìkan.” (Gál. 2:16) Ká sòótọ́, ohun pàtàkì kan wà tí Òfin Mósè mú kó ṣeé ṣe. Pọ́ọ̀lù ṣàlàyé fáwọn ará Gálátíà pé: “A fi kún un láti mú kí àwọn àṣìṣe fara hàn kedere, títí ọmọ tí a ṣe ìlérí náà fún á fi dé.” (Gál. 3:19) Òfin Mósè mú kó ṣe kedere pé àwa èèyàn aláìpé ò lè pa Òfin mọ́ délẹ̀délẹ̀ àti pé a nílò ìràpadà tó pé pérépéré táá wẹ gbogbo ẹ̀ṣẹ̀ wa mọ́. Torí náà, Òfin yẹn ló ṣamọ̀nà àwọn èèyàn lọ sọ́dọ̀ Kristi, “ọmọ” tá a ṣèlérí náà. Nípa bẹ́ẹ̀, tẹ́nì kan bá nígbàgbọ́ nínú Jésù Kristi, Ọlọ́run máa kà á sí olódodo. (Gál. 3:24) Ohun tí Pọ́ọ̀lù ń sọ ni pé Òfin yẹn ló mú kóun nígbàgbọ́ nínú Jésù tí Ọlọ́run sì tipa bẹ́ẹ̀ ka òun sí olódodo. Torí náà, Pọ́ọ̀lù “di òkú sí òfin” ó sì “di alààyè sí Ọlọ́run.” Nípa bẹ́ẹ̀ kò sí lábẹ́ Òfin Mósè mọ́, òfin Ọlọ́run nípasẹ̀ Kristi ló ń darí ẹ̀ báyìí.

Pọ́ọ̀lù sọ ohun tó jọ èyí nínú lẹ́tà tó kọ sáwọn ará ní Róòmù. Ó ní: “Ẹ̀yin ará mi, a ti sọ ẹ̀yin náà di òkú sí Òfin nípasẹ̀ ara Kristi . . . A ti dá wa sílẹ̀ kúrò lọ́wọ́ Òfin, torí a ti kú sí èyí tó ń ká wa lọ́wọ́ kò tẹ́lẹ̀.” (Róòmù 7:4, 6) Nínú ẹsẹ Bíbélì yìí àti Gálátíà 2:19, Pọ́ọ̀lù ò sọ pé òun dá ẹ̀ṣẹ̀ táá mú kí wọ́n pa òun lábẹ́ Òfin Mósè. Kàkà bẹ́ẹ̀, ohun tó ń sọ ni pé òun ti wà lómìnira. Òun àtàwọn míì bíi tiẹ̀ ò sí lábẹ́ Òfin Mósè mọ́. Ìgbàgbọ́ tí wọ́n ní nínú ẹbọ ìràpadà Kristi ti mú kí wọ́n wà lómìnira.