Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

ÀPILẸ̀KỌ FÚN ÌKẸ́KỌ̀Ọ́ 27

Ṣé O Máa Ń Fara Dà Á Bíi Ti Jèhófà?

Ṣé O Máa Ń Fara Dà Á Bíi Ti Jèhófà?

“Tí ẹ bá ní ìfaradà, ẹ máa lè pa ẹ̀mí yín mọ́.”​—LÚÙKÙ 21:19.

ORIN 114 Ẹ Máa Ní Sùúrù

OHUN TÁ A MÁA JÍRÒRÒ *

1-2. Báwo ni ohun tí Jèhófà sọ nínú Àìsáyà 65:16, 17 ṣe lè fún wa lókun ká má bàa sọ̀rètí nù?

“MÁ SỌ̀RÈTÍ NÙ!” ni ẹṣin ọ̀rọ̀ àpéjọ agbègbè alárinrin tá a ṣe lọ́dún 2017. Àpéjọ yẹn jẹ́ ká mọ bá a ṣe lè fara da àwọn ìṣòro tá à ń kojú. Ọdún mẹ́rin ti kọjá lẹ́yìn àpéjọ yẹn, síbẹ̀ ọ̀pọ̀ ìṣòro la ṣì ń fara dà nínú ayé burúkú yìí.

2 Ìṣòro wo ló ń bá ẹ fínra báyìí? Ṣé mọ̀lẹ́bí ẹ kan ló kú àbí ọ̀rẹ́ ẹ kan tó o nífẹ̀ẹ́? Àbí àìsàn kan ló kọ̀ tí ò lọ? Ṣé ara tó ń dara àgbà ló ń kó ìdààmú bá ẹ? Ṣé àjálù kan ló ṣẹlẹ̀ àbí àwọn jàǹdùkú ló ń ṣọṣẹ́ lágbègbè yín? Ṣé inúnibíni ni wọ́n ń ṣe sí ẹ àbí àrùn kan tó ń jà ràn-ìn irú bíi Corona ló ń mú kí nǹkan nira fún ẹ? Tó bá jẹ́ bẹ́ẹ̀, a kí yín pé ẹ kú ìfaradà. Gbogbo wa là ń retí ìgbà tí àwọn ìṣòro yìí á kásẹ̀ nílẹ̀ tí gbogbo ohun tó ń kó ìdààmú bá wa á sì roko ìgbàgbé!​—Ka Àìsáyà 65:16, 17.

3. Kí ló yẹ ká ṣe báyìí, kí sì nìdí?

3 Nǹkan nira gan-an lákòókò tá a wà yìí, ó sì ṣeé ṣe kí nǹkan tún nira jù báyìí lọ lọ́jọ́ iwájú. (Mát. 24:21) Torí náà, ó ṣe pàtàkì ká túbọ̀ lẹ́mìí ìfaradà. Kí nìdí? Jésù sọ pé: “Tí ẹ bá ní ìfaradà, ẹ máa lè pa ẹ̀mí yín mọ́.” (Lúùkù 21:19) Tá a bá ń ronú nípa àwọn tó nírú ìṣòro táwa náà ní, tí wọ́n sì ń fara dà á láìbọ́hùn, á rọrùn fáwa náà láti fara da àwọn ìṣòro wa.

4. Kí nìdí tó fi jẹ́ pé Jèhófà ni àpẹẹrẹ tó dáa jù tó bá dọ̀rọ̀ ìfaradà?

4 Ta ni àpẹẹrẹ tó dáa jù tó bá dọ̀rọ̀ ìfaradà? Jèhófà ni. Ìdáhùn yẹn lè yà ẹ́ lẹ́nu. Àmọ́ tó o bá rò ó dáadáa, wàá lóye ìdí tó fi rí bẹ́ẹ̀. Èṣù ló ń ṣàkóso ayé, torí náà kò síbi tá a yíjú sí tí ìṣòro ò sí. Jèhófà lágbára láti fòpin sí gbogbo ìṣòro yẹn lójú ẹsẹ̀, àmọ́ ó ń mú sùúrù di àsìkò tó ti ṣètò láti ṣe bẹ́ẹ̀. (Róòmù 9:22) Kó tó dìgbà yẹn, Jèhófà ń fara dà á títí àkókò tó ní lọ́kàn á fi pé. Ní báyìí, ẹ jẹ́ ká jíròrò nǹkan mẹ́sàn-án tí Jèhófà ti pinnu láti fara dà.

ÀWỌN NǸKAN WO NI JÈHÓFÀ Ń FARA DÀ?

5. Báwo ni wọ́n ṣe kó ẹ̀gàn bá orúkọ Ọlọ́run, báwo nìyẹn sì ṣe rí lára rẹ?

5 Ẹ̀gàn tí wọ́n kó bá orúkọ rẹ̀. Jèhófà nífẹ̀ẹ́ orúkọ rẹ̀, ó sì fẹ́ kí gbogbo wa máa bọ̀wọ̀ fún un. (Àìsá. 42:8) Àmọ́ láti nǹkan bí ẹgbẹ̀rún mẹ́fà ọdún báyìí ni wọ́n ti ń kó ẹ̀gàn bá orúkọ rẹ̀. (Sm. 74:10, 18, 23) Èṣù tó túmọ̀ sí “Abanijẹ́” ló kọ́kọ́ kó ẹ̀gàn bá orúkọ Ọlọ́run nínú ọgbà Édẹ́nì. Ó fẹ̀sùn kan Ọlọ́run pé kò fún Ádámù àti Éfà ní ohun tó máa jẹ́ kí wọ́n láyọ̀. (Jẹ́n. 3:1-5) Àtìgbà yẹn ni wọ́n ti ń fẹ̀sùn kan Jèhófà pé kò fún àwa èèyàn ní ohun tá a nílò gan-an. Inú Jésù ò dùn bó ṣe ń rí i táwọn èèyàn ń kó ẹ̀gàn bá orúkọ Ọlọ́run. Ìdí nìyẹn tó fi kọ́ àwọn ọmọlẹ́yìn ẹ̀ kí wọ́n máa gbàdúrà pé: “Baba wa tí ń bẹ ní ọ̀run, kí orúkọ rẹ di mímọ́.”​—Mát. 6:9.

6. Kí nìdí tí Jèhófà ò fi tíì jẹ́ kó ṣe kedere látọdún yìí pé òun ni Ọba Aláṣẹ Ayé Àtọ̀run?

6 Bí wọ́n ṣe ń ta ko ipò ọba aláṣẹ rẹ̀. Jèhófà nìkan ló lẹ́tọ̀ọ́ láti máa ṣàkóso ayé àtọ̀run, ìṣàkóso rẹ̀ ló sì dáa jù. (Ìfi. 4:11) Àmọ́ Èṣù ti gbìyànjú láti mú káwọn áńgẹ́lì àtàwa èèyàn ronú pé Ọlọ́run ò lẹ́tọ̀ọ́ láti ṣàkóso. Jèhófà mọ̀ pé ẹ̀sùn tí Sátánì fi kan òun yìí ò lè yanjú lọ́sàn-án kan òru kan. Ìdí nìyẹn tí Ọlọ́run fi jẹ́ káwọn èèyàn ṣàkóso ara wọn fún àkókò tó gùn kí wọ́n lè rí i pé ohunkóhun tí wọ́n bá ṣe láìsí ìrànlọ́wọ́ Ọlọ́run máa forí ṣánpọ́n. (Jer. 10:23) Sùúrù tí Ọlọ́run ní yìí ló máa jẹ́ kí ọ̀rọ̀ náà yanjú pátápátá. Ìgbà yẹn ló máa ṣe kedere pé Jèhófà ló lẹ́tọ̀ọ́ láti ṣàkóso ayé àtọ̀run àti pé Ìjọba ẹ̀ nìkan ló lè mú àlàáfíà wá.

7. Àwọn wo ló ti ṣọ̀tẹ̀ sí Jèhófà, kí sì ni Jèhófà máa ṣe fún wọn?

7 Àwọn kan lára àwọn ọmọ ẹ̀ ṣọ̀tẹ̀ sí i. Jèhófà dá àwa ọmọ ẹ̀, ìyẹn àwọn áńgẹ́lì àtàwa èèyàn lọ́nà tó pé. Àmọ́, Sátánì tó túmọ̀ sí “Alátakò” ṣọ̀tẹ̀ sí Jèhófà, ó sì mú kí Ádámù àti Éfà náà kẹ̀yìn sí Jèhófà. Lẹ́yìn náà, àwọn áńgẹ́lì àtàwọn èèyàn míì náà ṣọ̀tẹ̀ sí Jèhófà. (Júùdù 6) Nígbà tó yá, àwọn kan lára àwọn ọmọ Ísírẹ́lì tí Jèhófà dìídì yàn kẹ̀yìn sí i, wọ́n sì ń bọ̀rìṣà. (Àìsá. 63:8, 10) Àwọn ohun tó ṣẹlẹ̀ yẹn dun Jèhófà gan-an. Síbẹ̀, Jèhófà fara dà á. Á sì máa fara dà á títí dìgbà tí àkókò á tó láti pa gbogbo àwọn ọlọ̀tẹ̀ náà run. Tó bá dìgbà yẹn, inú Jèhófà àtàwọn olóòótọ́ máa dùn pé kò sí àwọn ẹni ibi mọ́.

8-9. Irọ́ wo làwọn kan ti pa mọ́ Jèhófà, kí ló sì yẹ ká ṣe nípa ẹ̀?

8 Irọ́ tí Èṣù ń pa mọ́ ọn lemọ́lemọ́. Sátánì fẹ̀sùn kan Jóòbù pé torí ohun tó ń rí gbà lọ́dọ̀ Ọlọ́run ló ṣe ń sìn ín, ẹ̀sùn yẹn sì kan gbogbo àwa tá à ń fòótọ́ ọkàn sin Jèhófà. (Jóòbù 1:8-11; 2:3-5) Èṣù ṣì ń fẹ̀sùn kan àwa ìránṣẹ́ Jèhófà títí dòní olónìí. (Ìfi. 12:10) A lè fi hàn pé irọ́ lèṣù ń pa tá a bá ń fara da àwọn ìṣòro wa, tá a sì jẹ́ adúróṣinṣin sí Jèhófà torí pé a nífẹ̀ẹ́ Rẹ̀. Ó sì dájú pé bí Jèhófà ṣe bù kún Jóòbù, á bù kún àwa náà tá a bá fara dà á.​—Jém. 5:11.

9 Sátánì máa ń mú kí àwọn ẹlẹ́sìn èké kọ́ni pé ìkà ni Ọlọ́run àti pé òun ló ń fa ìyà tó ń jẹ aráyé. Táwọn ọmọdé bá kú, àwọn kan máa ń sọ pé Ọlọ́run ló mú wọn lọ torí pé ó nílò àwọn áńgẹ́lì míì lọ́run. Ẹ ò rí i pé irọ́ burúkú nìyẹn! Àwa mọ ohun tó jẹ́ òótọ́. A kì í dá Ọlọ́run lẹ́bi tá a bá ń ṣàìsàn tàbí téèyàn wa kan bá kú. Dípò ìyẹn, a nígbàgbọ́ pé láìpẹ́, Jèhófà máa mú àìsàn kúrò, á sì jí àwọn òkú dìde. Torí náà, a máa ń fayọ̀ sọ fún gbogbo èèyàn pé Ọlọ́run onífẹ̀ẹ́ ni Jèhófà. Ìyẹn sì ń jẹ́ kí Jèhófà fún ẹni tó ń pẹ̀gàn rẹ̀ lésì.​—Òwe 27:11.

10. Kí ni Sáàmù 22:23, 24 jẹ́ ká mọ̀ nípa Jèhófà?

10 Bí àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ olóòótọ́ ṣe ń jìyà. Ọlọ́run aláàánú ni Jèhófà. Ó máa ń dùn ún tó bá rí i pé à ń jìyà bóyá torí inúnibíni, àìsàn tàbí àìpé wa. (Ka Sáàmù 22:23, 24.) Jèhófà mọ̀ ọ́n lára tá a bá ń jìyà, ó wù ú láti fòpin sí i, á sì fòpin sí i. (Fi wé Ẹ́kísódù 3:7, 8; Àìsáyà 63:9.) Ọjọ́ kan ń bọ̀ tí Jèhófà “máa nu gbogbo omijé kúrò ní ojú [wa], ikú ò ní sí mọ́, kò ní sí ọ̀fọ̀ tàbí ẹkún tàbí ìrora mọ́.”​—Ìfi. 21:4.

11. Báwo ló ṣe máa ń rí lára Jèhófà táwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ bá kú?

11 Ikú àwọn ọ̀rẹ́ rẹ̀. Báwo ló ṣe máa ń rí lára Jèhófà táwọn ìránṣẹ́ ẹ̀ lọ́kùnrin àti lóbìnrin bá kú? Ó máa ń wù ú gan-an pé kóun tún pa dà rí wọn! (Jóòbù 14:15) Fojú inú wo báá ṣe máa wu Jèhófà láti tún rí Ábúráhámù ọ̀rẹ́ rẹ̀. (Jém. 2:23) Tàbí Mósè tó bá sọ̀rọ̀ ní “ojúkojú.” (Ẹ́kís. 33:11) Ẹ sì wo báá ṣe máa wu Jèhófà tó láti gbọ́ ohùn Dáfídì àtàwọn onísáàmù míì bí wọ́n ṣe ń fayọ̀ kọrin ìyìn sí i! (Sm. 104:33) Bó tilẹ̀ jẹ́ pé gbogbo àwọn ìránṣẹ́ Jèhófà yìí ló ti kú, Jèhófà ò gbàgbé wọn. (Àìsá. 49:15) Ó rántí bí gbogbo wọn ṣe rí àti ànímọ́ tí ọ̀kọ̀ọ̀kan wọn ní. Bíbélì sọ pé “lójú rẹ̀, gbogbo wọn wà láàyè.” (Lúùkù 20:38) Lọ́jọ́ kan, á jí wọn dìde, á tẹ́wọ́ gba ìjọsìn wọn, á sì tún máa fetí sí àdúrà wọn. Tó bá jẹ́ pé ìwọ náà ń ṣàárò èèyàn ẹ kan tó ti kú, jẹ́ kí àwọn ọ̀rọ̀ yìí tù ẹ́ nínú, kó sì fún ẹ lókun.

12. Kí ni ọ̀kan lára ohun tó ń dun Jèhófà jù láwọn ọjọ́ ìkẹyìn yìí?

12 Bí àwọn ẹni burúkú ṣe ń fìyà jẹ àwọn èèyàn. Nígbà tí Sátánì mú kí Ádámù àti Éfà ṣọ̀tẹ̀ nínú ọgbà Édẹ́nì, Jèhófà mọ̀ pé nǹkan á burú gan-an kó tó di pé ó máa pa dà bọ̀ sípò. Jèhófà kórìíra ìwà ìkà, ìrẹ́jẹ àti ìwà ipá tó kúnnú ayé lónìí. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé gbogbo wa ni Jèhófà nífẹ̀ẹ́ tó sì ń bójú tó, ọ̀rọ̀ àwọn tí ò ní olùgbèjà máa ń jẹ ẹ́ lógún gan-an irú bí àwọn ọmọ aláìlóbìí àtàwọn opó. (Sek. 7:9, 10) Ó máa ń dun Jèhófà gan-an tó bá rí bí wọ́n ṣe ń fìyà jẹ àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ tí wọ́n sì ń jù wọ́n sẹ́wọ̀n. Jẹ́ kó dá ẹ lójú pé Jèhófà nífẹ̀ẹ́ gbogbo àwa tá à ń fara dà á bíi tiẹ̀.

13. Ìwà burúkú wo làwọn èèyàn ń hù lónìí, kí sì ni Jèhófà máa ṣe nípa ẹ̀?

13 Báwọn èèyàn ṣe sọ ara wọn dìdàkudà. Jèhófà dá wa ní àwòrán rẹ̀, àmọ́ Sátánì máa ń fẹ́ ká ṣèṣekúṣe ká sì máa hùwàkiwà. Nígbà tí Ọlọ́run “rí i pé ìwà burúkú èèyàn pọ̀ gan-an” nígbà ayé Nóà, “ó dun Jèhófà pé òun dá èèyàn sáyé, ọkàn rẹ̀ sì bà jẹ́.” (Jẹ́n. 6:5, 6, 11) Ṣé nǹkan ti wá yí pa dà látìgbà yẹn? Rárá o! Ẹ wo bínú Èṣù ṣe máa dùn tó bó ṣe ń rí i táwọn èèyàn ń lọ́wọ́ nínú onírúurú ìṣekúṣe, títí kan bí àwọn ọkùnrin ṣe ń bá àwọn ọkùnrin lò pọ̀ àti bí àwọn obìnrin ṣe ń bá àwọn obìnrin lò pọ̀! (Éfé. 4:18, 19) Inú Sátánì tún máa ń dùn yàtọ̀ tó bá lè mú kí ọ̀kan nínú àwọn ìránṣẹ́ Jèhófà dẹ́ṣẹ̀ tó wúwo. Nígbà tí àkókò bá tó lójú Jèhófà, ó máa pa gbogbo àwọn tó ń ṣèṣekúṣe tí wọn ò sì ronú pìwà dà run.

14. Kí làwọn èèyàn ń ṣe sí àwọn nǹkan tí Ọlọ́run dá sórílẹ̀ ayé?

14 Báwọn èèyàn ṣe ń run ilẹ̀ ayé. Yàtọ̀ sí pé èèyàn ń “jọba lórí èèyàn sí ìpalára rẹ̀,” wọ́n tún ń ba ilẹ̀ ayé jẹ́, wọ́n sì ń ṣèpalára fún àwọn ẹranko tí Jèhófà fi síkàáwọ́ wa. (Oníw. 8:9; Jẹ́n. 1:28) Àwọn ọ̀mọ̀wé kan sọ pé ohun táwọn èèyàn ń ṣe lónìí lè mú kí onírúurú ẹ̀dá alààyè tó lé ní mílíọ̀nù kan pòórá pátápátá lórí ilẹ̀ ayé láàárín ọdún mélòó kan sígbà tá a wà yìí. Abájọ tẹ́rù fi ń ba àwọn èèyàn! Àmọ́ inú wa dùn torí Jèhófà ti ṣèlérí pé òun máa “run àwọn tó ń run ayé,” òun á sì sọ ayé di Párádísè.​—Ìfi. 11:18; Àìsá. 35:1.

OHUN TÍ ÌFARADÀ JÈHÓFÀ KỌ́ WA

15-16. Kí lá mú ká máa fara dà á bíi ti Jèhófà? Ṣàpèjúwe.

15 Ronú nípa onírúurú ìṣòro tí Baba wa ọ̀run ti ń fara dà fún ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọdún. (Wo àpótí náà “ Ohun Tí Jèhófà Ń Fara Dà.”) Jèhófà lágbára láti fòpin sí ayé burúkú yìí nígbàkigbà, àmọ́ dípò bẹ́ẹ̀, ó ń mú sùúrù, sùúrù ẹ̀ sì ń ṣe wá láǹfààní. Ẹ jẹ́ ká wò ó báyìí ná. Ká ní dókítà kan sọ fún tọkọtaya kan pé ọmọ tí wọ́n máa tó bí ti ní àìsàn burúkú kan tó máa jẹ́ kí nǹkan nira fún un, ó sì máa kú láìtọ́jọ́. Síbẹ̀, inú tọkọtaya náà dùn gan-an nígbà tí wọ́n bí ọmọ náà, bó tiẹ̀ jẹ́ pé ó máa ná wọn ní ọ̀pọ̀ nǹkan. Ìfẹ́ tí wọ́n ní fún ọmọ náà mú kí wọ́n fara da gbogbo ìṣòro tó yọjú, wọ́n sì ṣe gbogbo ohun tí wọ́n lè ṣe láti bójú tó ọmọ náà.

16 Lọ́nà kan náà, aláìpé ni gbogbo àwa àtọmọdọ́mọ Ádámù àti Éfà nígbà tí wọ́n bí wa. Síbẹ̀, Jèhófà nífẹ̀ẹ́ wa, ó sì ń bójú tó wa. (1 Jòh. 4:19) Jèhófà ò dà bí àwọn tọkọtaya tá a sọ lẹ́ẹ̀kan torí pé òun lè yanjú àwọn ìṣòro wa ní tiẹ̀. Ó ti ní àsìkò kan lọ́kàn tó máa yanjú gbogbo ìṣòro tó ń bá aráyé fínra. (Mát. 24:36) Torí náà, ìfẹ́ tá a ní fún Jèhófà yẹ kó mú káwa náà fara dà á títí dìgbà tó máa yanjú gbogbo ìṣòro aráyé.

17. Báwo lohun tí Hébérù 12:2, 3 sọ nípa Jésù ṣe lè mú káwa náà máa fara dà á nìṣó?

17 Jèhófà ni àpẹẹrẹ tó dáa jù tó bá di pé ká fara da nǹkan. Jésù náà sì fìwà jọ Baba rẹ̀ láìkù síbì kan. Nígbà tí Jésù wà láyé, ó fara da ọ̀rọ̀ kòbákùngbé táwọn èèyàn sọ sí i, kò ka ìtìjú sí, ó sì fara da òpó igi oró nítorí wa. (Ka Hébérù 12:2, 3.) Àpẹẹrẹ Jèhófà ló fún Jésù lókun láti fara dà á, ó sì máa fún ìwọ náà lókun.

18. Báwo ni 2 Pétérù 3:9 ṣe jẹ́ ká túbọ̀ lóye àǹfààní tí sùúrù Jèhófà ń ṣe fún wa?

18 Ka 2 Pétérù 3:9. Jèhófà mọ ìgbà tó dáa jù láti fòpin sí ayé burúkú yìí. Sùúrù tó ní ló mú kí ogunlọ́gọ̀ èèyàn láǹfààní láti máa jọ́sìn rẹ̀ kí wọ́n sì máa yìn ín. Inú wọn ń dùn pé Jèhófà mú sùúrù títí di àkókò yìí. Ká sọ pé Jèhófà ti pa ayé búburú yìí run ni, wọn ò bá má bí wọn rárá, débi tí wọ́n á kẹ́kọ̀ọ́ òtítọ́ tí wọ́n á sì ya ara wọn sí mímọ́ fún un. Nígbà tí Jèhófà bá pa ayé burúkú yìí run, ogunlọ́gọ̀ èèyàn tó fara dà á dé òpin máa gba èrè wọn. Inú wọn máa dùn, wọ́n á sì gbà pé ó tọ́ bí Jèhófà ṣe mú sùúrù fún gbogbo wọn!

19. Kí ló yẹ ká pinnu láti ṣe, èrè wo sì ni Jèhófà máa fún wa?

19 A ti kẹ́kọ̀ọ́ lára Jèhófà nípa bá a ṣe lè máa láyọ̀ bá a tiẹ̀ ń fara da ọ̀pọ̀ nǹkan. Láìka gbogbo ìṣòro tí Sátánì ń fà, Bíbélì sọ pé “Ọlọ́run aláyọ̀” ni Jèhófà. (1 Tím. 1:11) Ó yẹ káwa náà máa láyọ̀ bá a ṣe ń fi sùúrù dúró dìgbà tí Jèhófà máa sọ orúkọ rẹ̀ di mímọ́, táá fi hàn pé òun lẹ́tọ̀ọ́ láti ṣàkóso ayé àtọ̀run, táá fòpin sí ìwà burúkú, táá sì mú gbogbo ìṣòro wa kúrò. Torí náà, ẹ jẹ́ ká pinnu pé àá máa fara dà á torí a mọ̀ pé Baba wa ọ̀run náà ń fara dà á. Tá a bá ṣe bẹ́ẹ̀, ọ̀rọ̀ ẹsẹ Bíbélì yìí máa ṣẹ sí ẹnì kọ̀ọ̀kan wa lára, tó ní: “Aláyọ̀ ni ẹni tó ń fara da àdánwò, torí tó bá rí ìtẹ́wọ́gbà, ó máa gba adé ìyè, tí Jèhófà ṣèlérí pé òun máa fún àwọn tí ò yéé nífẹ̀ẹ́ Rẹ̀.”​—Jém. 1:12.

ORIN 139 Fojú Inú Wo Ìgbà Tí Gbogbo Nǹkan Máa Di Tuntun

^ ìpínrọ̀ 5 Gbogbo wa la ní ìṣòro kan tá à ń bá yí. Kò sì sóhun tá a lè ṣe sí i àfi ká fara dà á. Àmọ́, àwa nìkan kọ́ la ní ohun tá à ń fara dà, Jèhófà náà ń fara da ọ̀pọ̀ nǹkan. Torí náà nínú àpilẹ̀kọ yìí, a máa jíròrò mẹ́sàn-án lára àwọn nǹkan tí Jèhófà ń fara dà. A tún máa rí àwọn ohun tá à ń gbádùn torí pé Jèhófà ń fara dà á, àá sì rí bá a ṣe lè fara wé e.