Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

ÀPILẸ̀KỌ FÚN ÌKẸ́KỌ̀Ọ́ 29

Jẹ́ Kí Ìtẹ̀síwájú Rẹ Máa Múnú Rẹ Dùn

Jẹ́ Kí Ìtẹ̀síwájú Rẹ Máa Múnú Rẹ Dùn

“Kí kálukú máa . . . láyọ̀ nítorí ohun tí òun fúnra rẹ̀ ṣe, kì í ṣe torí pé ó fi ara rẹ̀ wé ẹlòmíì.”​—GÁL. 6:4.

ORIN 34 Máa Rìn Nínú Ìwà Títọ́

OHUN TÁ A MÁA JÍRÒRÒ *

1. Kí nìdí tí Jèhófà kì í fi àwa ìránṣẹ́ rẹ̀ wéra?

JÈHÓFÀ ò dá wa pé ká rí bákan náà, ó sì mọyì bá a ṣe yàtọ̀ síra. Ohun tó jẹ́ ká mọ èyí ni pé onírúurú ewéko, ẹranko títí kan èèyàn ni Jèhófà dá. Gbogbo wa lẹ́nì kọ̀ọ̀kan la sì ní ohun kan tó mú ká yàtọ̀ sáwọn míì. Torí náà, Jèhófà kì í fi wá wéra. Ọkàn wa ni Jèhófà ń wò, ìyẹn ẹni tá a jẹ́ ní inú. (1 Sám. 16:7) Ó mọ ipò àtilẹ̀wá wa, ohun tágbára wa gbé àti ibi tá a kù sí. Bákan náà, kì í béèrè ohun tó ju agbára wa lọ. Torí náà, ẹ jẹ́ ká fara wé Jèhófà, ká máa wo ara wa bí òun náà ṣe ń wò wá. Tá a bá ṣe bẹ́ẹ̀, ìyẹn á fi hàn pé a ‘ní àròjinlẹ̀’ ní ti pé a ò ní máa ro ara wa jù tàbí ká máa ro ara wa pin.​—Róòmù 12:3.

2. Kí nìdí tí ò fi dáa ká máa fi ara wa wé àwọn míì?

2 Ká sòótọ́, a lè kẹ́kọ̀ọ́ lára àwọn míì. Bí àpẹẹrẹ, a lè mọ arákùnrin tàbí arábìnrin kan tó já fáfá lẹ́nu iṣẹ́ ìwàásù. (Héb. 13:7) A lè kẹ́kọ̀ọ́ lára ẹ̀, ká sì rí ọ̀nà tá a lè gbà sunwọ̀n sí i lẹ́nu iṣẹ́ ìwàásù. (Fílí. 3:17) Àmọ́, ìyàtọ̀ wà nínú ká kẹ́kọ̀ọ́ lára ẹnì kan àti ká máa fi ara wa wé ẹni náà. Tá a bá ń fi ara wa wé ẹnì kan, ìyẹn lè mú ká bẹ̀rẹ̀ sí í jowú ẹ̀, ká rẹ̀wẹ̀sì tàbí ká tiẹ̀ ronú pé a ò wúlò. Bákan náà bá a ṣe rí i nínú àpilẹ̀kọ tó ṣáájú, tá a bá ń fi ara wa wé àwọn míì nínú ìjọ, ó lè da ìjọ rú. Abájọ tí Jèhófà fi rọ̀ wá pé: “Kí kálukú máa yẹ ohun tó ń ṣe wò, nígbà náà, yóò láyọ̀ nítorí ohun tí òun fúnra rẹ̀ ṣe, kì í ṣe torí pé ó fi ara rẹ̀ wé ẹlòmíì.”​—Gál. 6:4.

3. Àwọn nǹkan wo lo ti ṣe nínú ìjọsìn Jèhófà tó ń fún ẹ láyọ̀?

3 Jèhófà fẹ́ kó o máa láyọ̀ bó o ṣe ń tẹ̀ síwájú nínú ìjọsìn ẹ. Bí àpẹẹrẹ tó o bá ti ṣèrìbọmi, ó yẹ kí inú ẹ dùn pé o ti lé ohun kan bá. Ìwọ fúnra ẹ lo ṣe ìpinnu yẹn, ìfẹ́ tó o sì ní fún Ọlọ́run ló mú kó o ṣe bẹ́ẹ̀. Wá ronú nípa àwọn nǹkan míì tó o ti ṣe lẹ́yìn tó o ṣèrìbọmi. Bí àpẹẹrẹ, ṣé o túbọ̀ ń gbádùn bó o ṣe ń ka Bíbélì tó o sì ń dá kẹ́kọ̀ọ́? Ṣé àdúrà ẹ túbọ̀ ń nítumọ̀? (Sm. 141:2) Ṣé o ti túbọ̀ mọ béèyàn ṣe ń wàásù, ṣé o sì ti túbọ̀ já fáfá nínú bá a ṣe ń lo àwọn ìtẹ̀jáde wa lẹ́nu iṣẹ́ ìwàásù? Tó o bá jẹ́ ọkọ, aya tàbí òbí, ṣé Jèhófà ti ràn ẹ́ lọ́wọ́ kó o lè túbọ̀ sunwọ̀n sí i? Ó yẹ kí inú ẹ máa dùn sí àwọn ìtẹ̀síwájú tó o ti ṣe yìí.

4. Kí la máa jíròrò nínú àpilẹ̀kọ yìí?

4 A lè ran àwọn míì náà lọ́wọ́ kí wọ́n lè máa láyọ̀ bí wọ́n ṣe ń tẹ̀ síwájú nínú ìjọsìn Jèhófà. A tún lè ṣe ohun tí ò ní jẹ́ kí wọ́n máa fi ara wọn wé àwọn míì. Nínú àpilẹ̀kọ yìí, a máa rí báwọn òbí ṣe lè ran àwọn ọmọ wọn lọ́wọ́ lọ́nà yìí, àá rí báwọn tọkọtaya ṣe lè ran ara wọn lọ́wọ́ àti bí àwọn alàgbà àtàwọn míì ṣe lè ran àwọn ará lọ́kùnrin àti lóbìnrin lọ́wọ́. Paríparí ẹ̀, a máa jíròrò àwọn ìlànà Bíbélì táá jẹ́ ká mọ bá a ṣe lè ṣe ohun tí agbára wa gbé.

OHUN TÍ ÀWỌN ÒBÍ ÀTÀWỌN TỌKỌTAYA LÈ ṢE

Ẹ̀yin òbí, ẹ mọyì ohun tí ọmọ kọ̀ọ̀kan ń ṣe (Wo ìpínrọ̀ 5 sí 6) *

5. Kí ni Éfésù 6:4 sọ pé àwọn òbí ò gbọ́dọ̀ ṣe?

5 Àwọn òbí gbọ́dọ̀ ṣọ́ra kó má di pé wọ́n ń fi àwọn ọmọ wọn wéra tàbí kí wọ́n ní káwọn ọmọ wọn ṣe ohun tó ju agbára wọn lọ. Àìjẹ́ bẹ́ẹ̀, àwọn ọmọ wọn lè rẹ̀wẹ̀sì. (Ka Éfésù 6:4.) Arábìnrin kan tó ń jẹ́ Sachiko * sọ pé: “Àwọn olùkọ́ mi nílé ìwé fẹ́ kí n máa gbégbá orókè nígbà gbogbo. Màmá mi náà fẹ́ kí n máa fakọ yọ nílé ìwé kí n lè fìyẹn jẹ́rìí fún àwọn olùkọ́ mi àti bàbá mi tí kì í ṣe Ẹlẹ́rìí Jèhófà. Kódà, wọ́n fẹ́ kí n máa gba gbogbo máàkì nígbà ìdánwò, ìyẹn ò sì ṣeé ṣe. Bó tiẹ̀ jẹ́ pé ọ̀pọ̀ ọdún ti kọjá tí mo ti jáde ilé ẹ̀kọ́, ó ṣì máa ń ṣe mí bíi pé inú Jèhófà ò lè dùn sí mi bí mo tiẹ̀ ń ṣe gbogbo ohun tí mo lè ṣe nínú ìjọsìn rẹ̀.”

6. Ẹ̀kọ́ wo làwọn òbí lè rí kọ́ látinú ohun tó wà nínú Sáàmù 131:1, 2?

6 Ẹ̀kọ́ pàtàkì kan wà táwọn òbí lè kọ́ látinú ohun tó wà nínú Sáàmù 131:1, 2. (Kà á.) Ọba Dáfídì sọ pé òun ò “lé nǹkan ńláńlá” tàbí àwọn nǹkan tó kọjá agbára òun. Torí pé ó lẹ́mìí ìrẹ̀lẹ̀, ọkàn ẹ̀ balẹ̀, ó sì nítẹ̀ẹ́lọ́rùn. Kí làwọn òbí lè rí kọ́ nínú ọ̀rọ̀ tí Dáfídì sọ yìí? Àwọn òbí tó nírẹ̀lẹ̀ kì í ṣe kọjá ohun tí wọ́n lè ṣe, wọn kì í sì í retí pé káwọn ọmọ wọn ṣe ohun tó ju agbára wọn lọ. Táwọn òbí bá mọ ohun tí ọmọ wọn lè ṣe àtohun tí ò lè ṣe, wọ́n á fi í lọ́kàn balẹ̀, wọn ò sì ní máa retí pé kó ṣe ohun tágbára rẹ̀ ò gbé. Arábìnrin kan tó ń jẹ́ Marina sọ pé: “Màmá mi kì í fi mí wé ẹ̀gbọ́n mi àtàwọn àbúrò mi tàbí àwọn ọmọ míì. Wọ́n kọ́ mi pé ohun tí kálukú wa lè ṣe yàtọ̀ síra àti pé gbogbo wa la ṣeyebíye lójú Jèhófà. Ohun tí wọ́n kọ́ mi yìí ni ò jẹ́ kí n máa fi ara mi wé àwọn míì.”

7-8. Kí ni ọkọ kan lè máa ṣe táá fi hàn pé ó ń bọlá fún ìyàwó ẹ̀?

7 Àwọn ọkọ tó jẹ́ Kristẹni gbọ́dọ̀ máa bọlá fún ìyàwó wọn. (1 Pét. 3:7) Tá a bá sọ pé a bọlá fún ẹnì kan, ó túmọ̀ sí pé a ka ẹni náà sí lọ́nà tó ṣàrà ọ̀tọ̀, a sì bọ̀wọ̀ fún un. Bí àpẹẹrẹ, ọkọ kan lè bọlá fún ìyàwó ẹ̀ tó bá ń pọ́n ọn lé, tó sì ń buyì kún un. Kì í retí pé kó ṣe ju agbára ẹ̀ lọ bẹ́ẹ̀ ni kì í fi wé àwọn obìnrin míì. Kí ló lè ṣẹlẹ̀ tó bá ń fi ìyàwó ẹ̀ wé àwọn obìnrin míì? Ọkọ arábìnrin Rosa kì í ṣe Ẹlẹ́rìí Jèhófà, ó sì máa ń fi í wé àwọn obìnrin míì. Ọ̀rọ̀ tó máa ń sọ ti jẹ́ kí Rosa ronú pé òun ò wúlò àti pé kò sẹ́ni tó nífẹ̀ẹ́ òun. Arábìnrin náà sọ pé: “Mo máa ń fẹ́ kó dá mi lójú pé Jèhófà nífẹ̀ẹ́ mi.” Bó ti wù kó rí, àwọn ọkọ tó jẹ́ Kristẹni máa ń bọlá fún ìyàwó wọn. Wọ́n mọ̀ pé ọwọ́ tí àwọn bá fi mú ìyàwó àwọn ló máa pinnu bí àjọṣe àárín àwọn pẹ̀lú ìyàwó wọn ṣe máa rí àti bí àjọṣe wọn pẹ̀lú Jèhófà ṣe máa rí. *

8 Ọkọ tó ń bọlá fún ìyàwó ẹ̀ máa ń sọ̀rọ̀ ẹ̀ dáadáa fáwọn míì, ó máa ń gbóríyìn fún un, ó máa ń sọ fún un pé òun nífẹ̀ẹ́ rẹ̀, òun sì mọyì rẹ̀. (Òwe 31:28) Ohun tí ọkọ Katerina tá a mẹ́nu kàn nínú àpilẹ̀kọ tó ṣáájú ṣe gan-an nìyẹn, ìyẹn sì mú kí Katerina borí èrò tó ní pé òun ò já mọ́ nǹkan kan. Nígbà tó wà ní kékeré, ìyá ẹ̀ máa ń bẹnu àtẹ́ lù ú, ó sì máa ń fi wé àwọn ọ̀rẹ́ ẹ̀. Ìyẹn ló mú kí Katerina máa fi ara ẹ̀ wé àwọn míì kódà lẹ́yìn tó kẹ́kọ̀ọ́ òtítọ́. Àmọ́ ọkọ ẹ̀ ràn án lọ́wọ́ kó lè borí èrò yìí kó sì máa fi ojú tó tọ́ wo ara ẹ̀. Katerina sọ pé: “Ó nífẹ̀ẹ́ mi, ó máa ń kíyè sí àwọn nǹkan tí mo bá ṣe, ó sì máa ń gbóríyìn fún mi. Bákan náà, ó máa ń gbàdúrà fún mi. Ó tún máa ń rán mi létí ojú tí Jèhófà fi ń wò mí, ìyẹn sì mú kí n sapá láti borí èrò òdì tí mo ní nípa ara mi.”

OHUN TÁWỌN ALÀGBÀ ÀTÀWỌN MÍÌ LÈ ṢE

9-10. Báwo làwọn alàgbà onífẹ̀ẹ́ ṣe ran arábìnrin kan lọ́wọ́ tí ò fi fi ara ẹ̀ wé àwọn míì mọ́?

9 Báwo làwọn alàgbà ṣe lè ṣèrànwọ́ fáwọn tó ń fi ara wọn wé àwọn míì? Ẹ jẹ́ ká wo àpẹẹrẹ arábìnrin kan tó ń jẹ́ Hanuni tí wọn kì í gbóríyìn fún nígbà tó wà ní kékeré. Ó sọ pé: “Ojú máa ń tì mí, mo sì máa ń ronú pé àwọn míì dáa jù mí lọ. Àtikékeré ni mo ti máa ń fi ara mi wé àwọn míì.” Kódà lẹ́yìn tó kẹ́kọ̀ọ́ òtítọ́, Hanuni ṣì máa ń fi ara ẹ̀ wé àwọn míì. Ìyẹn mú kó máa ronú pé òun ò já mọ́ nǹkan kan nínú ìjọ. Àmọ́ ní báyìí, ó ti ń fayọ̀ bá iṣẹ́ aṣáájú-ọ̀nà ẹ̀ lọ. Kí ló mú kó yí èrò ẹ̀ pa dà?

10 Hanuni sọ pé àwọn alàgbà kan kíyè sí mi, wọ́n sì ràn mí lọ́wọ́. Wọ́n jẹ́ kó mọ̀ pé àwọn mọyì iṣẹ́ takuntakun tó ń ṣe nínú ìjọ, wọ́n sì gbóríyìn fún un. Ó sọ pé: “Àwọn ìgbà kan wà táwọn alàgbà sọ pé kí n ran àwọn arábìnrin kan lọ́wọ́. Iṣẹ́ tí wọ́n gbé fún mi yìí jẹ́ kí n mọ̀ pé mo wúlò nínú ìjọ. Mo rántí ìgbà táwọn alàgbà yẹn wá dúpẹ́ lọ́wọ́ mi torí ìṣírí tí mo fún àwọn ọ̀dọ́bìnrin kan nínú ìjọ. Lẹ́yìn náà, wọ́n ka 1 Tẹsalóníkà 1:2, 3 fún mi. Ẹsẹ Bíbélì yẹn mà wọ̀ mí lọ́kàn o! Mo dúpẹ́ lọ́wọ́ àwọn alàgbà onífẹ̀ẹ́ yẹn. Ní báyìí, mo ti wá mọ̀ pé mo wúlò gan-an nínú ìjọ.”

11. Kí la lè ṣe fáwọn tí Àìsáyà 57:15 sọ pé a “tẹ̀ rẹ́, tí wọ́n sì rẹ̀wẹ̀sì ní ẹ̀mí”?

11 Ka Àìsáyà 57:15. Jèhófà nífẹ̀ẹ́ àwọn tí a “tẹ̀ rẹ́, tí wọ́n sì rẹ̀wẹ̀sì ní ẹ̀mí,” ó sì ń bójú tó wọn. Kì í ṣe àwọn alàgbà nìkan ló lè fún àwọn arákùnrin àtàwọn arábìnrin yìí níṣìírí, gbogbo wa ló yẹ ká máa ṣe bẹ́ẹ̀. Ọ̀nà kan tá a lè gbà ṣe bẹ́ẹ̀ ni pé ká fìfẹ́ hàn sí wọn. Ìfẹ́ tá a bá fi hàn sí wọn á jẹ́ kí wọ́n mọ̀ pé Jèhófà nífẹ̀ẹ́ àwọn gan-an. (Òwe 19:17) Ọ̀nà míì tá a tún lè gbà ràn wọ́n lọ́wọ́ ni pé ká lẹ́mìí ìrẹ̀lẹ̀, ká má sì máa fọ́nnu. Kò yẹ ká máa pe àfiyèsí sí ara wa ṣáá torí ìyẹn lè jẹ́ káwọn míì bẹ̀rẹ̀ sí í jowú. Kàkà bẹ́ẹ̀, ohun tó máa gbé àwọn ará ró ló yẹ ká máa sọ ká sì máa ṣe.​—1 Pét. 4:10, 11.

Àwọn ọmọ ẹ̀yìn Jésù nífẹ̀ẹ́ rẹ̀ gan-an torí pé kì í gbéra ga. Òun náà sì gbádùn kó máa wà pẹ̀lú wọn (Wo ìpínrọ̀ 12)

12. Kí nìdí tí àwọn tí ò já mọ́ nǹkan kan lójú àwọn èèyàn fi nífẹ̀ẹ́ Jésù? (Wo àwòrán iwájú ìwé.)

12 A lè kẹ́kọ̀ọ́ nípa bó ṣe yẹ ká máa ṣe sáwọn míì tá a bá wo ọwọ́ tí Jésù fi mú àwọn ọmọ ẹ̀yìn ẹ̀. Nínú gbogbo àwọn tó tíì gbé ayé yìí, kò sẹ́ni tó dà bíi Jésù. Síbẹ̀, “oníwà tútù àti ẹni tó rẹlẹ̀ ní ọkàn” ni. (Mát. 11:28-30) Bó tiẹ̀ jẹ́ pé ó ní ọgbọ́n ó sì ní ìmọ̀ gan-an, kì í ṣe fọ́rífọ́rí. Ọ̀rọ̀ tó máa yé tèwe tàgbà ló máa ń lò, ó sì lo àwọn àpèjúwe tó ń wọni lọ́kàn. (Lúùkù 10:21) Jésù ò dà bí àwọn aṣáájú ẹ̀sìn tó máa ń gbéra ga. (Jòh. 6:37) Kàkà bẹ́ẹ̀, ó máa ń jẹ́ káwọn èèyàn mọ̀ pé wọ́n ṣeyebíye lójú Ọlọ́run, ó sì máa ń pọ́n wọn lé.

13. Báwo ni ọwọ́ tí Jésù fi mú àwọn ọmọ ẹ̀yìn ẹ̀ ṣe fi hàn pé ó nífẹ̀ẹ́ wọn?

13 Ọwọ́ tí Jésù fi mú àwọn ọmọ ẹ̀yìn ẹ̀ fi hàn pé ó nífẹ̀ẹ́ wọn, ó sì ń gba tiwọn rò. Jésù mọ̀ pé ẹ̀bùn ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ ni wọ́n ní àti pé ohun tágbára wọn gbé yàtọ̀ síra. Torí náà, ohun tí kálukú wọn lè bójú tó yàtọ̀ síra, ohun tí wọ́n sì lè ṣe lẹ́nu iṣẹ́ ìwàásù ò dọ́gba. Síbẹ̀ Jésù mọyì iṣẹ́ takuntakun tí ọ̀kọ̀ọ̀kan wọn ṣe. Èyí sì ṣe kedere nínú àkàwé nípa tálẹ́ńtì tó sọ fáwọn ọmọlẹ́yìn ẹ̀. Nínú àkàwé yẹn, ọ̀gá kan fún àwọn ẹrú rẹ̀ níṣẹ́ “bí agbára [ọ̀kọ̀ọ̀kan wọn] ṣe mọ.” Bó tiẹ̀ jẹ́ pé èrè tí ọ̀kan lára àwọn ẹrú náà rí ju ti èkejì lọ, ọ̀rọ̀ kan náà ni ọ̀gá wọn fi gbóríyìn fún wọn. Ó ní: “O káre láé, ẹrú rere àti olóòótọ́!”​—Mát. 25:14-23.

14. Báwo làwa náà ṣe lè máa fìfẹ́ hàn sáwọn míì bíi ti Jésù?

14 Jésù nífẹ̀ẹ́ wa, ó sì máa ń gba tiwa rò. Ó mọ̀ pé ohun tá a lè ṣe ò dọ́gba, ipò wa sì yàtọ̀ síra. Síbẹ̀, inú ẹ̀ máa ń dùn tá a bá ṣe gbogbo ohun tágbára wa gbé. Torí náà, ó yẹ káwa náà máa fìfẹ́ hàn sáwọn míì, ká sì máa gba tiwọn rò bíi ti Jésù. Kò yẹ ká máa fojú kéré àwọn ará wa tàbí ká máa dójú tì wọ́n torí pé wọn ò lè ṣe tó àwọn míì. Dípò bẹ́ẹ̀, ẹ jẹ́ ká máa kíyè sí ibi táwọn ará wa dáa sí ká sì máa gbóríyìn fún wọn torí bí wọ́n ṣe ń sa gbogbo ipá wọn lẹ́nu iṣẹ́ ìsìn Jèhófà.

NÍ ÀWỌN ÀFOJÚSÙN TỌ́WỌ́ RẸ LÈ BÀ

Tó o bá ní àwọn àfojúsùn tọ́wọ́ ẹ lè bà, tó o sì lé wọn bá, inú ẹ máa dùn (Wo ìpínrọ̀ 15 sí 16) *

15-16. Báwo ló ṣe rí lára arábìnrin kan nígbà tọ́wọ́ ẹ̀ tẹ àwọn nǹkan tó ń lé?

15 Tá a bá ní àfojúsùn nínú ìjọsìn Jèhófà, ọkàn wa á pa pọ̀, ìgbésí ayé wa sì máa nítumọ̀. Àmọ́, ipò wa àtohun tágbára wa gbé ni ká fi pinnu àfojúsùn tá a fẹ́ lé, kì í ṣe ohun táwọn míì ń ṣe. Tó bá jẹ́ pé ohun táwọn míì ń ṣe là ń lé, ìyẹn lè mú ká rẹ̀wẹ̀sì tọ́wọ́ wa ò bá bà á. (Lúùkù 14:28) Ẹ jẹ́ ká wo ohun tó ṣẹlẹ̀ sí aṣáájú-ọ̀nà kan tó ń jẹ́ Midori.

16 Nígbà tí Midori wà ní kékeré, bàbá ẹ̀ tí kì í ṣe Ẹlẹ́rìí máa ń sọ fún un pé àwọn àbúrò ẹ̀ àtàwọn ọmọ ilé ìwé ẹ̀ dáa jù ú lọ. Midori sọ pé: “Ó máa ń ṣe mí bíi pé mi ò já mọ́ nǹkan kan.” Àmọ́ bó ṣe ń dàgbà kì í ronú bẹ́ẹ̀ mọ́. Kí ló ràn án lọ́wọ́? Ó sọ pé: “Mo máa ń ka Bíbélì lójoojúmọ́, ìyẹn jẹ́ kọ́kàn mi balẹ̀ kí n sì mọ̀ pé Jèhófà nífẹ̀ẹ́ mi gan-an.” Yàtọ̀ síyẹn, ó pinnu láti ṣe àwọn nǹkan kan tọ́wọ́ ẹ̀ lè bà, ó sì gbàdúrà pé kí Jèhófà ran òun lọ́wọ́. Ìyẹn jẹ́ kínú Midori máa dùn bó ṣe ń rí àwọn nǹkan tó ń ṣe nínú ìjọsìn Jèhófà.

MÁA ṢE GBOGBO OHUN TÓ O LÈ ṢE NÍNÚ ÌJỌSÌN JÈHÓFÀ

17. Báwo la ṣe lè “máa di tuntun nínú agbára tó ń darí ìrònú” wa, kí nìyẹn sì máa yọrí sí?

17 Kì í ṣe ọ̀sán kan òru kan ni èrò tí ò tọ́ máa kúrò lọ́kàn wa. Ìdí nìyẹn tí Jèhófà fi rọ̀ wá pé: “Ẹ máa di tuntun nínú agbára tó ń darí ìrònú yín.” (Éfé. 4:23, 24) Àmọ́ ká tó lè ṣe bẹ́ẹ̀, a gbọ́dọ̀ máa gbàdúrà, ká máa kẹ́kọ̀ọ́ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run, ká sì máa ronú jinlẹ̀ lórí ohun tá a kà. Rí i pé ò ń ṣe àwọn nǹkan yìí déédéé, kó o sì bẹ Jèhófà kó o má bàa dẹwọ́. Ẹ̀mí mímọ́ Jèhófà máa ràn ẹ́ lọ́wọ́, ìyẹn ò sì ní jẹ́ kó o máa fi ara ẹ wé àwọn míì mọ́. Yàtọ̀ síyẹn, Jèhófà máa jẹ́ kó o tètè mọ̀ tó o bá ti ń jowú tàbí tó ò ń gbéra ga, á sì jẹ́ kó o tètè ṣe àwọn àtúnṣe tó yẹ.

18. Báwo lohun tó wà nínú 2 Kíróníkà 6:29, 30 ṣe lè tù ẹ́ nínú?

18 Ka 2 Kíróníkà 6:29, 30. Jèhófà mọ ohun tó wà lọ́kàn wa. Ó mọ bá a ṣe ń sapá tó láti borí ẹ̀mí burúkú tó wà nínú ayé yìí àti àìpé wa. Bí Jèhófà ṣe ń rí bá a ṣe ń sapá láti borí àwọn nǹkan yìí, bẹ́ẹ̀ ni ìfẹ́ tó ní fún wa á túbọ̀ máa jinlẹ̀ sí i.

19. Àpèjúwe wo ni Jèhófà lò ká lè lóye bó ṣe nífẹ̀ẹ́ wa tó?

19 Jèhófà lo àpèjúwe ìfẹ́ tó wà láàárín ìyá àti ọmọ ká lè lóye bóun ṣe nífẹ̀ẹ́ wa tó. (Àìsá. 49:15) Ẹ jẹ́ ká wo àpẹẹrẹ ìyá kan tó ń jẹ́ Rachel. Ó sọ pé: “Kògbókògbó ni mo bí Stephanie ọmọ mi. Nígbà tí mo kọ́kọ́ rí i, ó rí jáńjálá, kò sì lókun nínú. Torí náà, wọ́n gbé e síbi tí wọ́n máa ń gbé àwọn ọmọ kògbókògbó sí. Àmọ́, àwọn dókítà máa ń jẹ́ kí n gbé e lójoojúmọ́ jálẹ̀ oṣù àkọ́kọ́ tá a lò níbẹ̀. Àwọn àsìkò yẹn jẹ́ ká mọ ojú ara wa dáadáa. Ní báyìí, ó ti pé ọmọ ọdún mẹ́fà, àmọ́ ó kéré ju àwọn ọmọ míì tí wọ́n jọ jẹ́ ẹgbẹ́. Síbẹ̀, mo nífẹ̀ẹ́ ẹ̀ torí pé ó sapá gan-an kó lè wà láàyè, ó sì ń fún mi láyọ̀!” Inú wa mà dùn o láti mọ̀ pé irú ìfẹ́ tí Jèhófà ní sáwa náà nìyẹn bó ṣe ń rí i tá à ń sapá láti ṣe gbogbo nǹkan tá a lè ṣe nínú ìjọsìn ẹ̀!

20. Kí ló ń múnú àwa ìránṣẹ́ Jèhófà dùn?

20 Torí pé ìránṣẹ́ Jèhófà ni ẹ́, o ṣeyebíye lójú ẹ̀, kò sì sí ẹlòmíì tó dà bíi rẹ. Kì í ṣe torí pé o dáa ju àwọn míì lọ ni Jèhófà ṣe fà ẹ́ sọ́dọ̀ ara ẹ̀. Ó fà ẹ́ sọ́dọ̀ ara ẹ̀ torí pé ó rí ọkàn ẹ, ó rí i pé o nírẹ̀lẹ̀, o sì ṣe tán láti gbẹ̀kọ́. (Sm. 25:9) Jẹ́ kó dá ẹ lójú pé ó mọyì bó o ṣe ń ṣe gbogbo ohun tó o lè ṣe nínú ìjọsìn ẹ̀. Bó o ṣe ń fara dà á tó o sì jẹ́ olóòótọ́ fi hàn pé o ní “ọkàn tó tọ́, tó sì dáa.” (Lúùkù 8:15) Torí náà, máa ṣe gbogbo ohun tó o lè ṣe nínú ìjọsìn Jèhófà. Tó o bá ṣe bẹ́ẹ̀, wàá máa láyọ̀ ‘nítorí ohun tí ìwọ fúnra rẹ ń ṣe.’

ORIN 38 Yóò Sọ Ọ́ Di Alágbára

^ ìpínrọ̀ 5 Jèhófà kì í fi wá wé àwọn míì. Àmọ́, nígbà míì àwọn kan lára wa máa ń fi ara wọn wé àwọn míì, ìyẹn sì máa ń jẹ́ kí wọ́n ro ara wọn pin. Nínú àpilẹ̀kọ yìí, a máa jíròrò ìdí tí kò fi yẹ ká máa ṣe bẹ́ẹ̀. A tún máa rí bá a ṣe lè mú káwọn tá a jọ wà nínú ìdílé àtàwọn míì nínú ìjọ máa wo ara wọn bí Jèhófà ṣe ń wò wọ́n.

^ ìpínrọ̀ 5 A ti yí àwọn orúkọ kan pa dà.

^ ìpínrọ̀ 7 Bó tiẹ̀ jẹ́ pé àwọn ọkọ la darí àwọn ìlànà yìí sí, ó kan àwọn aya náà.

^ ìpínrọ̀ 58 ÀWÒRÁN: Ìdílé kan ń kan ọkọ̀ áàkì nígbà ìjọsìn ìdílé. Inú àwọn òbí náà dùn nígbà tí wọ́n rí ohun tí ọmọ kọ̀ọ̀kan ti ṣe.

^ ìpínrọ̀ 62 ÀWÒRÁN: Ìyá kan tó ń dá tọ́mọ ń ronú bó ṣe máa ṣe aṣáájú-ọ̀nà olùrànlọ́wọ́, inú ẹ̀ sì dùn gan-an nígbà tọ́wọ́ ẹ̀ tẹ̀ ẹ́.