Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

ÀPILẸ̀KỌ FÚN ÌKẸ́KỌ̀Ọ́ 31

Ṣé Wàá Dúró De Jèhófà?

Ṣé Wàá Dúró De Jèhófà?

“Màá dúró de Ọlọ́run.”​—MÍKÀ 7:7.

ORIN 128 Bí A Ṣe Lè Fara Dà Á Dópin

OHUN TÁ A MÁA JÍRÒRÒ *

1-2. Kí la máa jíròrò nínú àpilẹ̀kọ yìí?

BÁWO ló ṣe máa rí lára ẹ tí ẹrù kan tó ò ń retí lójú méjèèjì ò bá dé lásìkò? Ṣé inú ẹ máa dùn? Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run sọ nínú Òwe 13:12 pé: “Ìrètí pípẹ́ máa ń mú ọkàn ṣàìsàn.” Ká wá sọ pé wọ́n ṣàlàyé fún ẹ pé kí nǹkan kan má bàa ṣe ẹrù náà ni ò ṣe dé lásìkò tó o retí ẹ̀, báwo ló ṣe máa rí lára ẹ? Ó dájú pé inú ẹ á dùn, wàá sì mú sùúrù.

2 Nínú àpilẹ̀kọ yìí, a máa rí àwọn ìlànà Bíbélì mélòó kan táá jẹ́ ká mọ bá a ṣe lè máa mú sùúrù. (Míkà 7:7) Lẹ́yìn náà, a máa rí apá méjì nígbèésí ayé wa tá a ti gbọ́dọ̀ mú sùúrù ká sì dúró de Jèhófà. Paríparí ẹ̀, àá sọ̀rọ̀ nípa àwọn ìbùkún táwọn tó dúró de Jèhófà máa rí.

ÀWỌN ÌLÀNÀ BÍBÉLÌ TÓ JẸ́ KÁ RÍDÌÍ TÓ FI ṢE PÀTÀKÌ PÉ KÁ MÁA MÚ SÙÚRÙ

3. Kí la rí kọ́ nínú Òwe 13:11?

3 Ìlànà Bíbélì kan tó jẹ́ ká rídìí tó fi yẹ ká máa mú sùúrù wà nínú Òwe 13:11. Ó sọ pé: “Ọrọ̀ tí èèyàn fi ìkánjú kó jọ kì í pẹ́ tán, àmọ́ ọrọ̀ tí èèyàn ń kó jọ díẹ̀díẹ̀ á máa pọ̀ sí i.” Ẹ̀kọ́ wo lèyí kọ́ wa? Ẹ̀kọ́ ibẹ̀ ni pé tá a bá ń fara balẹ̀, tá a sì ń mú sùúrù, àá ṣèpinnu tó bọ́gbọ́n mu.

4. Kí ni Òwe 4:18 kọ́ wa?

4 Òwe 4:18 sọ pé: “Ipa ọ̀nà àwọn olódodo dà bí ìmọ́lẹ̀ àárọ̀ tó ń mọ́lẹ̀ sí i títí di ọ̀sán gangan.” Ọ̀rọ̀ yìí jẹ́ ká mọ̀ pé díẹ̀díẹ̀ ni Jèhófà ń mú káwọn èèyàn rẹ̀ mọ ohun tó ní lọ́kàn láti ṣe. Àmọ́, a tún lè lo ẹsẹ Bíbélì yìí láti ṣàpèjúwe bí Kristẹni kan ṣe ń ṣe ìyípadà nígbèésí ayé ẹ̀, tó sì túbọ̀ ń sún mọ́ Jèhófà. Gbogbo wa la mọ̀ pé ó máa ń gba àkókò kéèyàn tó lè fàwọn ìwà àtijọ́ sílẹ̀ kó sì sún mọ́ Jèhófà. Tá a bá ń fara balẹ̀ kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì àtàwọn ìtẹ̀jáde ètò Ọlọ́run, tá a sì ń fi àwọn ìmọ̀ràn inú ẹ̀ sílò, díẹ̀díẹ̀ a máa dà bíi Kristi. Yàtọ̀ síyẹn, àá túbọ̀ máa mọ Jèhófà sí i. Ẹ jẹ́ ká wo àpèjúwe kan tí Jésù fi ṣàlàyé kókó yìí.

Bó ṣe jẹ́ pé díẹ̀díẹ̀ ni irúgbìn kan máa ń dàgbà, bẹ́ẹ̀ náà ló ṣe jẹ́ pé díẹ̀díẹ̀ lẹni tó ń kẹ́kọ̀ọ́ òtítọ́ máa ń tẹ̀ síwájú (Wo ìpínrọ̀ 5)

5. Àpèjúwe wo ni Jésù lò tó jẹ́ ká mọ̀ pé díẹ̀díẹ̀ ni èèyàn máa ń tẹ̀ síwájú?

5 Jésù lo àpèjúwe bí irúgbìn ṣe ń dàgbà láti jẹ́ ká mọ bí òtítọ́ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run ṣe ń mú káwọn tó ń kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì yí pa dà díẹ̀díẹ̀. Ó sọ pé: “Irúgbìn náà rú jáde, ó sì dàgbà, àmọ́ [afúnrúgbìn náà] kò mọ bó ṣe ṣẹlẹ̀. Ilẹ̀ náà mú èso jáde fúnra rẹ̀ ní kẹ̀rẹ̀kẹ̀rẹ̀, ohun ọ̀gbìn náà kọ́kọ́ yọ, lẹ́yìn náà erín ọkà, nígbẹ̀yìn-gbẹ́yín, èso jáde lódindi nínú erín ọkà.” (Máàkù 4:27, 28) Kí ni Jésù ń sọ gan-an? Ohun tó ń sọ ni pé bó ṣe jẹ́ pé díẹ̀díẹ̀ ni irúgbìn kan máa ń dàgbà, bẹ́ẹ̀ náà ló ṣe jẹ́ pé díẹ̀díẹ̀ ni ẹni tó kẹ́kọ̀ọ́ òtítọ́ máa ń tẹ̀ síwájú. Bí àpẹẹrẹ, bí àwọn akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì wa ṣe túbọ̀ ń sún mọ́ Jèhófà, bẹ́ẹ̀ làá máa rí àwọn ìyípadà tí wọ́n ń ṣe nígbèésí ayé wọn. (Éfé. 4:22-24) Àmọ́ ká fi sọ́kàn pé Jèhófà ló ń mú kí irúgbìn kékeré yẹn dàgbà.​—1 Kọ́r. 3:7.

6-7. Kí la kọ́ látinú bí Jèhófà ṣe dá ayé yìí?

6 Jèhófà máa ń fi sùúrù ṣe gbogbo ohun tó bá ń ṣe. Ó máa ń ṣe bẹ́ẹ̀ kó lè mú ìyìn àti ògo wá fún orúkọ rẹ̀, kó sì ṣe àwọn míì náà láǹfààní. Bí àpẹẹrẹ, ẹ jẹ́ ká wo bí Jèhófà ṣe dá ayé yìí ní ṣísẹ̀-n-tẹ̀lé káwa èèyàn lè gbádùn rẹ̀.

7 Nígbà tí Bíbélì ń sọ bí Jèhófà ṣe dá ayé yìí, ó sọ pé ó “díwọ̀n rẹ̀,” ó ri “àwọn ìtẹ́lẹ̀ rẹ̀,” ó sì fi “òkúta igun ilé rẹ̀” lélẹ̀. (Jóòbù 38:5, 6) Kódà, Jèhófà lo àkókò láti yẹ ohun tó ń ṣe wò. (Jẹ́n. 1:10, 12) Ẹ wo bó ṣe máa rí lára àwọn áńgẹ́lì bí wọ́n ṣe ń rí gbogbo ohun tí Jèhófà ń dá ní ṣísẹ̀-n-tẹ̀lé. Ó dájú pé inú wọn máa dùn gan-an. Kódà, ìgbà kan wà tí wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí í ‘hó yèè, tí wọ́n sì ń yìn ín.’ (Jóòbù 38:7) Kí la rí kọ́? Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ó gba ọ̀pọ̀ ọdún kí Jèhófà tó parí gbogbo ohun tó dá, síbẹ̀ lẹ́yìn tó yẹ gbogbo ẹ̀ wò, ó sọ pé “ó dára gan-an.”​—Jẹ́n. 1:31.

8. Kí la máa jíròrò báyìí?

8 Àwọn àpẹẹrẹ tá a jíròrò lókè yìí ti jẹ́ ká rí àwọn ìlànà Bíbélì tó jẹ́ ká mọ bó ti ṣe pàtàkì tó láti máa mú sùúrù. Ní báyìí, ẹ jẹ́ ká wo apá méjì nígbèésí ayé wa tá a ti gbọ́dọ̀ máa mú sùúrù.

ÀWỌN ÌGBÀ WO LÓ YẸ KÁ DÚRÓ DE JÈHÓFÀ?

9. Ìgbà wo ló yẹ ká dúró de Jèhófà?

9 Ó lè gba pé ká ní sùúrù kí Jèhófà tó dáhùn àdúrà wa. Tá a bá gbàdúrà pé kí Jèhófà fún wa lókun láti fara da ìṣòro kan tàbí láti borí kùdìẹ̀-kudiẹ kan, ó lè máa ṣe wá bíi pé Jèhófà ò tètè dáhùn àdúrà náà. Kí nìdí tó fi jẹ́ pé kì í ṣe gbogbo àdúrà wa ni Jèhófà máa ń dáhùn lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀?

10. Kí nìdí tó fi yẹ ká ní sùúrù dìgbà tí Jèhófà máa dáhùn àdúrà wa?

10 Bíbélì sọ pé Jèhófà máa ń tẹ́tí sí àdúrà wa. (Sm. 65:2) Ó mọ̀ pé ìgbàgbọ́ tá a ní ló mú ká máa gbàdúrà sí òun. (Héb. 11:6) Tá a bá gbàdúrà pé kí Jèhófà ràn wá lọ́wọ́ láti ṣe ìfẹ́ rẹ̀, ó máa fẹ́ rí i pé àwa náà ń sapá láti máa fi àwọn ìlànà rẹ̀ sílò. (1 Jòh. 3:22) Bí àpẹẹrẹ, tá a bá bẹ Jèhófà pé kó jẹ́ ká jáwọ́ nínú ìwà kan tí ò dáa, àwa náà gbọ́dọ̀ ṣe gbogbo ohun tá a lè ṣe láti yẹra fún ohun tó lè mú ká tún hùwà náà, ká má sì jẹ́ kó sú wa. Jésù jẹ́ kó ṣe kedere pé kì í ṣe gbogbo àdúrà wa ni Jèhófà máa dáhùn lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀. Ó wá gbà wá níyànjú pé: “Ẹ máa béèrè, a sì máa fún yín; ẹ máa wá kiri, ẹ sì máa rí; ẹ máa kan ilẹ̀kùn, a sì máa ṣí i fún yín; torí gbogbo ẹni tó bá ń béèrè máa rí gbà, gbogbo ẹni tó bá ń wá kiri máa rí, gbogbo ẹni tó bá sì ń kan ilẹ̀kùn la máa ṣí i fún.” (Mát. 7:7, 8) Tá a bá tẹ̀ lé ìmọ̀ràn yìí, tá a sì “tẹra mọ́ àdúrà gbígbà,” ó dájú pé Baba wa ọ̀run máa gbọ́ wa, ó sì máa dáhùn àdúrà wa lásìkò tó tọ́.​—Kól. 4:2.

Ó yẹ ká máa gbàdúrà sí Jèhófà bá a ṣe ń dúró dè é torí ó dá wa lójú pé ó máa dáhùn àdúrà wa (Wo ìpínrọ̀ 11) *

11. Báwo lohun tó wà nínú Hébérù 4:16 ṣe lè fi wá lọ́kàn balẹ̀ tó bá dà bíi pé Jèhófà ò tètè dáhùn àdúrà wa?

11 Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ó lè máa ṣe wá bíi pé Jèhófà ò tètè dáhùn àdúrà wa, síbẹ̀ Jèhófà ṣèlérí pé òun máa dáhùn àdúrà wa “ní àkókò tó tọ́.” (Ka Hébérù 4:16.) Torí náà, kò yẹ ká máa dá Jèhófà lẹ́bi tí ohun tá à ń béèrè ò bá ṣẹlẹ̀ lásìkò tá a fẹ́. Bí àpẹẹrẹ, ọ̀pọ̀ ọdún làwọn kan ti ń gbàdúrà pé kí Ìjọba Ọlọ́run fòpin sí ayé burúkú yìí. Kódà, Jésù náà sọ pé ká máa gbàdúrà kí Ìjọba Ọlọ́run dé. (Mát. 6:10) Àmọ́ ìwà agọ̀ gbáà ló máa jẹ́ tẹ́nì kan bá fi Jèhófà sílẹ̀ torí òpin ò dé lásìkò táwa èèyàn retí! (Háb. 2:3; Mát. 24:44) Ohun tó máa bọ́gbọ́n mu ni pé ká dúró de Jèhófà ká sì nígbàgbọ́ pé ó máa dáhùn àdúrà wa. Jèhófà ti yan “ọjọ́ àti wákàtí” tí òpin máa dé. Torí náà, àsìkò tó tọ́ lòpin máa dé, àsìkò yẹn ló sì máa ṣe gbogbo èèyàn láǹfààní jù.​—Mát. 24:36; 2 Pét. 3:15.

Kí la rí kọ́ lára Jósẹ́fù tó bá di pé ká mú sùúrù? (Wo ìpínrọ̀ 12-14)

12. Ìgbà wo ló lè ṣòro fún wa láti mú sùúrù?

12 Ó lè ṣòro fún wa láti mú sùúrù táwọn èèyàn bá hùwà àìdáa sí wa. Àwọn èèyàn inú ayé sábà máa ń hùwà àìdáa sáwọn obìnrin, àwọn tó wá láti ẹ̀yà míì tàbí tí àṣà àti èdè wọn yàtọ̀. Àwọn míì tún máa ń hùwà àìdáa sáwọn tó jẹ́ aláàbọ̀ ara. Yàtọ̀ síyẹn, ọ̀pọ̀ àwa èèyàn Jèhófà là ń fara da inúnibíni torí ohun tá a gbà gbọ́. Tí wọ́n bá ṣerú nǹkan bẹ́ẹ̀ sí wa, ẹ jẹ́ ká fi ọ̀rọ̀ Jésù sọ́kàn pé: “Ẹni tó bá fara dà á dé òpin máa rí ìgbàlà.” (Mát. 24:13) Àmọ́ kí lo máa ṣe tó o bá mọ̀ nípa ẹ̀ṣẹ̀ tó burú jáì tẹ́nì kan nínú ìjọ dá? Táwọn alàgbà bá ti mọ̀ nípa ẹ̀, ṣé wàá mú sùúrù, wàá sì fọkàn tán wọn pé wọ́n á bójú tó ọ̀rọ̀ náà bí Jèhófà ṣe fẹ́? Ọ̀nà wo ni Jèhófà fẹ́ káwọn alàgbà gbà bójú tó irú ọ̀rọ̀ bẹ́ẹ̀?

13. Báwo ni Jèhófà ṣe fẹ́ káwọn alàgbà bójú tó ọ̀rọ̀ ẹnì kan tó dẹ́ṣẹ̀ tó burú jáì nínú ìjọ?

13 Táwọn alàgbà bá gbọ́ pé ẹnì kan ti dá ẹ̀ṣẹ̀ tó burú jáì nínú ìjọ, wọ́n á kọ́kọ́ gbàdúrà fún “ọgbọ́n tó wá láti òkè” kí wọ́n lè mọ bí Jèhófà ṣe fẹ́ kí wọ́n bójú tó ọ̀rọ̀ náà. (Jém. 3:17) Ohun tó jẹ wọ́n lógún ni bí wọ́n ṣe máa “yí ẹlẹ́ṣẹ̀ [náà] pa dà kúrò nínú ìṣìnà rẹ̀” tó bá ṣeé ṣe. (Jém. 5:19, 20) Wọ́n tún máa ń ṣe gbogbo ohun tí wọ́n bá lè ṣe láti dáàbò bo ìjọ, kí wọ́n sì pèsè ìtùnú fún àwọn tí ọ̀rọ̀ náà kó ẹ̀dùn ọkàn bá. (2 Kọ́r. 1:3, 4) Táwọn alàgbà bá ń bójú tó irú ọ̀rọ̀ bẹ́ẹ̀, wọ́n á kọ́kọ́ ṣèwádìí kí wọ́n lè mọ gbogbo kúlẹ̀kúlẹ̀ ọ̀rọ̀ náà, ìyẹn sì lè gba àkókò díẹ̀. Lẹ́yìn tí wọ́n bá gbàdúrà, wọ́n á fi Ìwé Mímọ́ tọ́ ẹni náà sọ́nà, wọ́n á sì fún un ní ìbáwí tí ò “kọjá ààlà.” (Jer. 30:11) Bó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn alàgbà kò ní fi ọ̀rọ̀ náà falẹ̀, síbẹ̀ wọn kì í kánjú ṣèpinnu. Táwọn alàgbà bá ń tẹ̀ lé ìlànà Jèhófà lórí àwọn ọ̀rọ̀ bẹ́ẹ̀, gbogbo ìjọ ló máa jàǹfààní. Bó ti wù kó rí, táwọn alàgbà bá tiẹ̀ bójú tó ọ̀rọ̀ kan lọ́nà tó tọ́, ìyẹn lè má mú gbogbo ẹ̀dùn ọkàn ẹni tí ẹni náà ṣẹ̀ kúrò. Tó bá jẹ́ pé ohun tó ṣẹlẹ̀ sí ẹ nìyẹn, kí lo lè ṣe láti dín ẹ̀dùn ọkàn náà kù?

14. Àpẹẹrẹ inú Bíbélì wo ló lè ràn ẹ́ lọ́wọ́ láti fara dà á tí Kristẹni kan bá ṣẹ̀ ẹ́?

14 Ṣé ẹnì kan nínú ìjọ ti ṣẹ̀ ẹ́ rí tọ́rọ̀ náà sì dùn ẹ́ gan-an? Wàá rí àwọn àpẹẹrẹ nínú Bíbélì tó máa jẹ́ ká rí ìdí tó fi yẹ ká mú sùúrù dìgbà tí Jèhófà máa bójú tó ọ̀rọ̀ náà. Bí àpẹẹrẹ, àwọn ẹ̀gbọ́n Jósẹ́fù hùwà àìdáa sí i, síbẹ̀ kò dì wọ́n sínú tàbí kó máa wá bó ṣe máa gbẹ̀san. Kàkà bẹ́ẹ̀, bó ṣe máa múnú Jèhófà dùn ló gbájú mọ́. Jèhófà náà sì san án lẹ́san torí pé ó mú sùúrù, ó sì fara dà á. (Jẹ́n. 39:21) Nígbà tó yá, Jósẹ́fù dárí ji àwọn tó ṣẹ̀ ẹ́, ìyẹn sì mú kó rí ọwọ́ Jèhófà nígbèésí ayé ẹ̀. (Jẹ́n. 45:5) Bíi ti Jósẹ́fù, tá a bá sún mọ́ Jèhófà tá a sì fọ̀rọ̀ náà sọ́wọ́ ẹ̀, ara máa tù wá.​—Sm. 7:17; 73:28.

15. Kí ló ran arábìnrin kan lọ́wọ́ tó fi lè mú sùúrù nígbà tẹ́nì kan sọ̀rọ̀ ẹ̀ láìdáa?

15 Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ohun táwọn kan ṣe fún wa lè má burú tó ohun táwọn ẹ̀gbọ́n Jósẹ́fù ṣe fún un, síbẹ̀ kò sí bí ohun tí wọ́n ṣe ṣe kéré tó, ó ṣì máa ń kó ẹ̀dùn ọkàn bá wa nígbà míì. Tẹ́nì kan bá ṣẹ̀ wá, yálà ẹni náà jẹ́ Ẹlẹ́rìí Jèhófà tàbí kì í ṣe Ẹlẹ́rìí Jèhófà, a máa jàǹfààní tá a bá fi àwọn ìlànà Bíbélì sílò. (Fílí. 2:3, 4) Ẹ jẹ́ ká wo ohun tó ṣẹlẹ̀ sí arábìnrin kan. Ó dun arábìnrin náà gan-an nígbà tó gbọ́ pé ẹnì kan tí wọ́n jọ ń ṣiṣẹ́ ń sọ̀rọ̀ ẹ̀ láìdáa fáwọn míì. Dípò táá fi gbaná jẹ, ṣe ló mú sùúrù tó sì ronú nípa àpẹẹrẹ Jésù. Bíbélì sọ pé nígbà tí wọ́n sọ̀rọ̀ àbùkù sí Jésù, kò sọ̀rọ̀ àbùkù sí wọn pa dà. (1 Pét. 2:21, 23) Torí náà, ó pinnu pé òun máa gbàgbé ọ̀rọ̀ náà. Ìgbà tó yá ló wá mọ̀ pé ẹni tó ń sọ̀rọ̀ òun láìdáa náà ní àìsàn kan tó ń bá yí, nǹkan ò sì rọrùn fún un rárá. Torí náà, arábìnrin yẹn gbà pé ẹni náà ò mọ̀ọ́mọ̀ sọ ohun tó sọ. Lẹ́yìn-ọ̀-rẹyìn, inú arábìnrin náà dùn pé òun mú sùúrù, ìyẹn sì jẹ́ kọ́kàn ẹ̀ balẹ̀.

16. Kí ló lè tù ẹ́ nínú tó o bá ń fara da ìwà àìdáa táwọn kan hù sí ẹ? (1 Pétérù 3:12)

16 Tó bá jẹ́ pé ò ń fara da ìwà àìdáa kan tí wọ́n hù sí ẹ tàbí ìṣòro míì tó ń kó ẹ̀dùn ọkàn bá ẹ, rántí pé Jèhófà wà nítòsí “àwọn tó ní ọgbẹ́ ọkàn.” (Sm. 34:18) Inú ẹ̀ ń dùn bó ṣe ń rí i pé ò ń mú sùúrù, o sì gbẹ́kẹ̀ lé òun. (Sm. 55:22) Jèhófà ni Onídàájọ́ gbogbo ayé, kò sì sóhun tó pa mọ́ fún un. (Ka 1 Pétérù 3:12.) Torí náà tó o bá ní àwọn ìṣòro tó ń bá ẹ fínra, tó ò sì lè yanjú báyìí, ṣé wàá dúró de Jèhófà?

ÀWỌN TÓ BÁ DÚRÓ DE JÈHÓFÀ MÁA GBÁDÙN ÌBÙKÚN TÍ Ò LÓPIN

17. Kí ni Jèhófà sọ pé òun máa ṣe fún wa nínú Àìsáyà 30:18?

17 Láìpẹ́, Ìjọba Ọlọ́run máa mú ọ̀pọ̀ ìbùkún wá fún gbogbo wa. Àìsáyà 30:18 sọ pé: “Jèhófà ń fi sùúrù dúró láti ṣojúure sí yín, ó sì máa dìde láti ṣàánú yín. Torí pé Ọlọ́run ìdájọ́ òdodo ni Jèhófà. Aláyọ̀ ni gbogbo àwọn tó ń retí rẹ̀.” Gbogbo àwọn tó bá ń fi sùúrù dúró de Jèhófà máa gba ọ̀pọ̀ ìbùkún nísinsìnyí àti nínú ayé tuntun.

18. Àwọn ìbùkún wo la máa gbádùn nínú ayé tuntun?

18 Tá a bá dénú ayé tuntun, kò ní sídìí tó fi yẹ ká máa fara da àwọn ìṣòro tá à ń kojú lónìí yìí mọ́. Kò sẹ́ni tó máa hùwà àìdáa sí wa, kò sì ní sí ìrora èyíkéyìí mọ́. (Ìfi. 21:4) Tó bá dìgbà yẹn, a ò ní máa ṣàníyàn nípa àwọn nǹkan tá a nílò mọ́ torí pé ọ̀pọ̀ nǹkan ló máa wà fún gbogbo wa. (Sm. 72:16; Àìsá. 54:13) Ẹ ò rí i pé àsìkò yẹn máa lárinrin gan-an!

19. Kí ni Jèhófà ń múra wa sílẹ̀ fún báyìí?

19 Ní báyìí, Jèhófà ń múra wa sílẹ̀ láti gbé lábẹ́ Ìjọba yẹn ní ti pé ó ń ràn wá lọ́wọ́ láti jáwọ́ nínú àwọn ìwà tí ò dáa, ká sì láwọn ìwà tó ń múnú ẹ̀ dùn. Torí náà má jẹ́ kó sú ẹ, má sì fi Jèhófà sílẹ̀. Ìdí ni pé ọ̀pọ̀ nǹkan la máa gbádùn nínú ayé tuntun! Bá a ṣe ń dúró dìgbà yẹn, ẹ jẹ́ ká máa fayọ̀ dúró de Jèhófà ká sì jẹ́ kó dá wa lójú pé gbogbo ohun tí Jèhófà ṣèlérí ló máa ṣe lásìkò tó ti pinnu gẹ́lẹ́!

ORIN 118 “Fún Wa Ní Ìgbàgbọ́ Sí I”

^ ìpínrọ̀ 5 Ṣé o ti gbọ́ ọ rí kí ẹnì kan tó ti pẹ́ nínú ètò Jèhófà sọ pé, ‘Mi ò ronú pé ayé burúkú yìí ṣì máa wà títí di àsìkò yìí’? Gbogbo wa pátá là ń gbàdúrà pé kí Jèhófà fòpin sí ayé burúkú yìí, pàápàá lásìkò tí nǹkan nira gan-an yìí. Bó ti wù kó rí, a gbọ́dọ̀ mú sùúrù. Nínú àpilẹ̀kọ yìí, a máa rí àwọn ìlànà Bíbélì táá jẹ́ ká lè mú sùúrù de àsìkò Jèhófà. Àá tún wo apá méjì nígbèésí ayé wa tá a ti gbọ́dọ̀ mú sùúrù ká sì dúró de Jèhófà. Paríparí ẹ̀, àá sọ̀rọ̀ nípa àwọn ìbùkún táwọn tó ń dúró de Jèhófà máa rí.

^ ìpínrọ̀ 56 ÀWÒRÁN:Ojú Ìwé: Àtikékeré ni arábìnrin kan ti máa ń gbàdúrà sí Jèhófà. Nígbà tó wà lọ́mọdé, àwọn òbí ẹ̀ kọ́ ọ báá ṣe máa gbàdúrà. Nígbà tó wà lọ́dọ̀ọ́, ó di aṣáájú-ọ̀nà, ó sì máa ń bẹ Jèhófà pé kó ran òun lọ́wọ́ lẹ́nu iṣẹ́ ìsìn òun. Ọ̀pọ̀ ọdún lẹ́yìn náà, ọkọ ẹ̀ ṣàìsàn, ó sì bẹ Jèhófà pé kó fún òun lókun láti fara dà á. Ní báyìí, ó ti di opó, síbẹ̀ ó ṣì máa ń gbàdúrà déédéé torí ó dá a lójú pé Jèhófà Baba òun máa dáhùn àdúrà òun bó ti máa ń ṣe tẹ́lẹ̀.