Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

ÀPILẸ̀KỌ FÚN ÌKẸ́KỌ̀Ọ́ 32

Jẹ́ Kó Túbọ̀ Dá Ẹ Lójú Pé Ẹlẹ́dàá Wà

Jẹ́ Kó Túbọ̀ Dá Ẹ Lójú Pé Ẹlẹ́dàá Wà

“Ìgbàgbọ́ ni . . . ẹ̀rí tó dájú nípa àwọn ohun gidi tí a kò rí.”​—HÉB. 11:1.

ORIN 11 Ìṣẹ̀dá Ń Yin Ọlọ́run

OHUN TÁ A MÁA JÍRÒRÒ *

1. Kí lo ti kọ́ nípa Ẹlẹ́dàá?

TÓ BÁ jẹ́ pé Ẹlẹ́rìí Jèhófà làwọn òbí ẹ, ó ṣeé ṣe kí wọ́n ti kọ́ ẹ nípa Jèhófà láti kékeré. Wọ́n kọ́ ẹ pé òun ni Ẹlẹ́dàá, pé ó láwọn ànímọ́ tó dáa àti pé ó máa sọ ayé di Párádísè.​—Jẹ́n. 1:1; Ìṣe 17:24-27.

2. Ojú wo làwọn kan fi ń wo àwọn tó gbà pé Ẹlẹ́dàá wà?

2 Ọ̀pọ̀ èèyàn ò gbà pé Ọlọ́run wà débi tí wọ́n á fi gbà pé òun ló dá gbogbo nǹkan. Wọ́n gbà pé ṣe ni gbogbo nǹkan ṣàdédé wà àti pé ara àwọn nǹkan ẹlẹ́mìí kéékèèké làwọn ẹranko àtàwa èèyàn ti wá. Ó yani lẹ́nu pé àwọn kan tó gba ẹ̀kọ́ yìí gbọ́ kàwé dáadáa. Wọ́n lè sọ pé sáyẹ́ǹsì ti fi hàn pé ohun tó wà nínú Bíbélì kì í ṣe òótọ́ àti pé àwọn aláìmọ̀kan àtàwọn tí ò lajú ló gbà pé Ẹlẹ́dàá wà.

3. Kí nìdí tó fi ṣe pàtàkì pé ká jẹ́ kí ìgbàgbọ́ wa lágbára?

3 Ṣé ohun táwọn kan tó kàwé sọ yìí máa mú ká bẹ̀rẹ̀ sí í ṣiyèméjì pé Jèhófà ló dá gbogbo nǹkan? Ká tó lè dáhùn ìbéèrè yìí, a gbọ́dọ̀ mọ ìdí tá a fi gbà pé Jèhófà ló dá gbogbo nǹkan. Ṣé a kàn gbà bẹ́ẹ̀ torí ohun tí wọ́n kọ́ wa nìyẹn, àbí àwa fúnra wa ti wáyè ṣèwádìí àwọn ẹ̀rí tó fi hàn pé Jèhófà ló dá gbogbo nǹkan? (1 Kọ́r. 3:12-15) Láìka bó ti pẹ́ tó tá a ti ń sin Jèhófà, gbogbo wa gbọ́dọ̀ máa ṣe ohun táá mú kí ìgbàgbọ́ wa lágbára sí i. Tá a bá ṣe bẹ́ẹ̀, “ọgbọ́n orí àti ìtànjẹ lásán” táwọn èèyàn gbé lárugẹ ò ní ṣì wá lọ́nà. (Kól. 2:8; Héb. 11:6) Torí náà nínú àpilẹ̀kọ yìí, a máa jíròrò (1) ìdí tí ọ̀pọ̀ ò fi gbà pé Ẹlẹ́dàá wà, (2) bó o ṣe lè túbọ̀ nígbàgbọ́ nínú Jèhófà Ẹlẹ́dàá rẹ àti (3) ohun tó o lè ṣe kí ìgbàgbọ́ rẹ má bàa jó rẹ̀yìn.

ÌDÍ TÍ Ọ̀PỌ̀ Ò FI GBÀ PÉ ẸLẸ́DÀÁ WÀ

4. Kí ni Hébérù 11:1 àti àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé sọ pé ìgbàgbọ́ jẹ́?

4 Àwọn kan ronú pé tẹ́nì kan bá sọ pé òun nígbàgbọ́, ṣe lẹni náà kàn gba ohun kan gbọ́ láìsí ẹ̀rí tó dájú. Àmọ́ ohun tí Bíbélì sọ pé ìgbàgbọ́ jẹ́ kọ́ nìyẹn. (Ka Hébérù 11:1 àti àlàyé ìsàlẹ̀.) A nígbàgbọ́ nínú àwọn ohun gidi tí a kò rí bíi Jèhófà, Jésù àti Ìjọba Ọlọ́run. Ìdí sì ni pé a ní ẹ̀rí tó ṣe kedere pé wọ́n wà. (Héb. 11:3) Ohun tí Ẹlẹ́rìí kan tó jẹ́ onímọ̀ sáyẹ́ǹsì sọ nìyí: “Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà kì í gba ohun kan gbọ́ láìsí ẹ̀rí tó ṣe kedere, a kì í sì fọwọ́ rọ́ ìwádìí àwọn onímọ̀ sáyẹ́ǹsì sẹ́yìn.”

5. Kí nìdí tí ọ̀pọ̀ fi gbà pé àwọn nǹkan kàn ṣàdédé wà ni?

5 Tí ẹ̀rí tó ṣe kedere bá wà pé Jèhófà ló dá gbogbo nǹkan, ‘kí wá nìdí tí ọ̀pọ̀ ò fi gbà pé Ẹlẹ́dàá wà?’ Àwọn kan ò tiẹ̀ ṣèwádìí nípa ọ̀rọ̀ náà rí. Robert tó ti di Ẹlẹ́rìí Jèhófà báyìí sọ pé: “Ohun tí wọ́n kọ́ wa níléèwé ni pé kò sí Ẹlẹ́dàá, ìyẹn mú kí èmi náà gbà pé kò sẹ́ni tó dá wa. Kódà, mo ti lé lọ́mọ ogún (20) ọdún kó tó di pé mo láǹfààní láti bá àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà sọ̀rọ̀ tí wọ́n sì fi Bíbélì ṣàlàyé fún mi lọ́nà tó ṣe kedere pé Ẹlẹ́dàá wà.” *​—Wo àpótí náà “ Ohun Tó Yẹ Kẹ́yin Òbí Ṣe.”

6. Kí nìdí táwọn kan ò fi gbà pé Ẹlẹ́dàá wà?

6 Àwọn kan ò gbà pé Ẹlẹ́dàá wà torí pé ohun tí wọ́n rí nìkan ni wọ́n gbà gbọ́. Àmọ́ àwọn nǹkan kan wà tí wọn ò rí, síbẹ̀ tí wọ́n gbà pé ó wà, irú bí agbára òòfà. Ìgbàgbọ́ tí Bíbélì ń sọ̀rọ̀ nípa ẹ̀ dá lórí ẹ̀rí tó ṣe kedere nípa “àwọn ohun gidi tí a kò rí.” (Héb. 11:1) Ó máa ń gba àkókò àti ìsapá ká tó lè kẹ́kọ̀ọ́ nípa àwọn ẹ̀rí tó fi hàn pé Jèhófà ló dá gbogbo nǹkan, ọ̀pọ̀ èèyàn ni ò sì ráyè irú ìwádìí bẹ́ẹ̀ rárá. Ẹni tí ò bá ṣèwádìí àwọn ẹ̀rí tó ṣe kedere yìí lè gbà pé kò sí Ọlọ́run.

7. Ṣé gbogbo àwọn tó kàwé ni ò gbà pé Ọlọ́run ló dá gbogbo nǹkan? Ṣàlàyé.

7 Ìwádìí táwọn onímọ̀ sáyẹ́ǹsì kan ṣe mú kí wọ́n gbà pé Ọlọ́run ló dá gbogbo nǹkan. * Bíi ti Robert tá a sọ̀rọ̀ ẹ̀ lẹ́ẹ̀kan, àwọn kan lè gbà pé kò sí Ẹlẹ́dàá torí pé ohun tí wọ́n fi kọ́ wọn ní yunifásítì nìyẹn. Síbẹ̀, ọ̀pọ̀ àwọn onímọ̀ sáyẹ́ǹsì ló ti kẹ́kọ̀ọ́ nípa Jèhófà tí wọ́n sì nífẹ̀ẹ́ rẹ̀. Bíi tàwọn onímọ̀ sáyẹ́ǹsì yìí, gbogbo wa la gbọ́dọ̀ mú kí ìgbàgbọ́ tá a ní nínú Ọlọ́run túbọ̀ lágbára, yálà a kàwé tàbí a ò kàwé. Kò sẹ́ni tó lè ṣèyẹn fún wa.

OHUN TÓ O LÈ ṢE KÓ LÈ TÚBỌ̀ DÁ Ẹ LÓJÚ PÉ ẸLẸ́DÀÁ WÀ

8-9. (a) Ìbéèrè wo la máa jíròrò báyìí? (b) Àǹfààní wo lo máa rí tó o bá kẹ́kọ̀ọ́ nípa ìṣẹ̀dá?

8 Kí lo lè ṣe táá jẹ́ kó túbọ̀ dá lójú pé Ẹlẹ́dàá wà? Ẹ jẹ́ ká jíròrò nǹkan mẹ́rin tá a lè ṣe.

9 Kẹ́kọ̀ọ́ nípa àwọn nǹkan tó wà láyìíká ẹ. Tó o bá kẹ́kọ̀ọ́ nípa àwọn ẹranko, ewéko àti ìràwọ̀, ìyẹn á jẹ́ kó túbọ̀ dá ẹ lójú pé Ẹlẹ́dàá wà. (Sm. 19:1; Àìsá. 40:26) Bó o bá ṣe túbọ̀ ń kẹ́kọ̀ọ́ nípa àwọn nǹkan yìí, bẹ́ẹ̀ lá túbọ̀ máa dá ẹ lójú pé Jèhófà ló dá gbogbo nǹkan. Àwọn ìtẹ̀jáde wa sábà máa ń ní àwọn àpilẹ̀kọ tó ṣàlàyé onírúurú nǹkan tí Jèhófà dá. Tó bá tiẹ̀ ṣòro fún ẹ láti lóye àwọn àpilẹ̀kọ náà, má ṣe tìtorí ẹ̀ pa á tì. Gbogbo ohun tó o bá lè kà ni kó o kà. Yàtọ̀ síyẹn, máa wo àwọn fídíò tó dá lórí àwọn ohun tí Jèhófà dá tó jáde láwọn àpéjọ agbègbè tá a ṣe láwọn ọdún àìpẹ́ yìí. Wàá rí àwọn fídíò yìí lórí ìkànnì jw.org.

10. Sọ àpẹẹrẹ kan tó jẹ́ ká gbà pé Ẹlẹ́dàá wà. (Róòmù 1:20)

10 Tó o bá ń kẹ́kọ̀ọ́ nípa àwọn nǹkan tó wà láyìíká ẹ, máa ronú nípa ohun tí wọ́n ń jẹ́ kó o mọ̀ nípa Ẹlẹ́dàá. (Ka Róòmù 1:20.) Bí àpẹẹrẹ, ooru àti ìmọ́lẹ̀ tó ń jáde látinú oòrùn máa ń ṣe wá láǹfààní, àmọ́ ìtànṣán kan tún máa ń jáde lára oòrùn tó lè pa wá lára. Àmọ́, nǹkan kan wà tó máa ń dáàbò bò wá. Kí ni nǹkan náà? Afẹ́fẹ́ kan wà tí wọ́n ń pè ní ozone tí kì í jẹ́ kí ìtànṣán tó ń pani lára yẹn dé ọ̀dọ̀ wa. Bí ìtànṣán tó ń pani lára látinú oòrùn bá ṣe ń lágbára sí i, bẹ́ẹ̀ ni afẹ́fẹ́ ozone tó ń dáàbò bò wá á ṣe máa pọ̀ sí i. Ṣé o rò pé àwọn nǹkan tá a ṣẹ̀ṣẹ̀ jíròrò yìí kàn ṣàdédé wà ni, àbí ẹnì kan tó nífẹ̀ẹ́ wa tó sì jẹ́ ọlọ́gbọ́n ló dá wọn?

11. Ibo lo ti lè rí àwọn nǹkan táá jẹ́ kó dá ẹ lójú pé Jèhófà ló dá gbogbo nǹkan? (Wo àpótí náà “ Àwọn Ìtẹ̀jáde Táá Jẹ́ Kó Dá Ẹ Lójú Pé Jèhófà Ló Dá Gbogbo Nǹkan.”)

11 Wàá rí àwọn àpilẹ̀kọ táá jẹ́ kó túbọ̀ dá ẹ lójú pé Jèhófà ló dá àwọn nǹkan nínú Ìwé Ìwádìí fún Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà àti lórí ìkànnì jw.org. O lè wo fídíò, kó o sì ka ọ̀wọ́ àpilẹ̀kọ tá a pè ní “Ta Ló Ṣiṣẹ́ Àrà Yìí?” Àwọn àpilẹ̀kọ àti fídíò yìí kì í gùn, wọ́n sì máa ń jẹ́ ká mọ àwọn nǹkan tó ṣàrà ọ̀tọ̀ nípa àwọn ẹranko àtàwọn nǹkan míì tí Jèhófà dá. Wọ́n tún máa ń jẹ́ ká rí ohun táwọn onímọ̀ sáyẹ́ǹsì kọ́ àtohun tí wọ́n ń gbé ṣe bí wọ́n ṣe ń wo àwọn nǹkan tí Ọlọ́run dá.

12. Àwọn nǹkan wo ló yẹ ká fi sọ́kàn tá a bá ń kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì?

12 Máa kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. Onímọ̀ sáyẹ́ǹsì tá a sọ̀rọ̀ ẹ̀ lẹ́ẹ̀kan kò kọ́kọ́ gbà pé Ọlọ́run ló dá gbogbo nǹkan. Àmọ́ nígbà tó yá, ó gbà pé Ẹlẹ́dàá kan wà. Ó sọ pé: “Kì í ṣe ohun tí mo kọ́ nínú ìmọ̀ sáyẹ́ǹsì nìkan ló jẹ́ kí n gbà pé Ẹlẹ́dàá wà. Mo tún fara balẹ̀ kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì.” O lè ti kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. Síbẹ̀, ó ṣì yẹ kó o máa kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì sí i kí ìgbàgbọ́ rẹ nínú Jèhófà Ẹlẹ́dàá wa lè túbọ̀ lágbára. (Jóṣ. 1:8; Sm. 119:97) Bí àpẹẹrẹ, kíyè sí bí Bíbélì ṣe ṣàlàyé àwọn ohun tó ṣẹlẹ̀ tipẹ́tipẹ́ lọ́nà tó péye. Tún kíyè sí àwọn àsọtẹ́lẹ̀ Bíbélì tó ti ṣẹ àti bí àwọn ọ̀rọ̀ inú ẹ̀ ṣe bára mu látòkèdélẹ̀. Tó o bá ṣe bẹ́ẹ̀, ìyẹn á jẹ́ kó túbọ̀ dá ẹ lójú pé ẹnì kan tó nífẹ̀ẹ́ wa tó sì jẹ́ ọlọgbọ́n ló dá wa, òun náà ló sì mí sí àwọn tó kọ Bíbélì. *​—2 Tím. 3:14; 2 Pét. 1:21.

13. Sọ ọ̀kan lára àwọn ìmọ̀ràn tó ń ṣeni láǹfààní tó wà nínú Bíbélì.

13 Tó o bá ń kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, kíyè sí àwọn ìmọ̀ràn tó gbéṣẹ́ tó wà nínú ẹ̀. Bí àpẹẹrẹ, ọjọ́ pẹ́ tí Bíbélì ti kìlọ̀ pé ó léwu téèyàn bá nífẹ̀ẹ́ owó àti pé ìfẹ́ owó máa ń fa “ìrora tó pọ̀.” (1 Tím. 6:9, 10; Òwe 28:20; Mát. 6:24) Ṣé ìkìlọ̀ yìí ṣì wúlò lónìí? Ìwé The Narcissism Epidemic sọ pé: “Àwọn tó nífẹ̀ẹ́ owó kì í fi bẹ́ẹ̀ láyọ̀, wọ́n sì máa ń ní ìdààmú ọkàn. Kódà, ọpọlọ àwọn tó sábà máa ń ṣàníyàn nípa bí wọ́n ṣe máa túbọ̀ lówó kì í fi bẹ́ẹ̀ jí pépé, wọ́n sì máa ń ní àwọn àìlera kan.” Torí náà, ìkìlọ̀ tí Bíbélì fún wa pé ká má ṣe nífẹ̀ẹ́ owó bọ́gbọ́n mu gan-an. Ṣé o lè ronú àwọn ìlànà Bíbélì míì tó ti ṣe ẹ́ láǹfààní? Tá a bá ronú nípa àwọn ìmọ̀ràn tó ń ṣe wá láǹfààní tó wà nínú Bíbélì, àá rí i pé Ẹlẹ́dàá wa nífẹ̀ẹ́ wa, ó sì mọ ohun tó dáa jù fún wa. Torí náà, á rọrùn fún wa láti gbẹ́kẹ̀ lé e. (Jém. 1:5) Ìyẹn á sì jẹ́ káyé wa túbọ̀ nítumọ̀.​—Àìsá. 48:17, 18.

14. Tá a bá ń kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, kí la máa kọ́ nípa Jèhófà?

14 Ìdí tó fi yẹ kó o máa kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì ni pé o fẹ́ túbọ̀ mọ Jèhófà. (Jòh. 17:3) Bó o ṣe ń kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, wàá túbọ̀ mọ irú ẹni tí Jèhófà jẹ́ àtàwọn ànímọ́ tó ní, àwọn ànímọ́ yìí sì ṣe kedere nínú àwọn nǹkan tó dá. Àwọn nǹkan tó o kọ́ yìí máa jẹ́ kó túbọ̀ dá ẹ lójú pé Jèhófà wà lóòótọ́. (Ẹ́kís. 34:6, 7; Sm. 145:8, 9) Bó o ṣe túbọ̀ ń mọ Jèhófà, ìgbàgbọ́ rẹ á túbọ̀ máa lágbára, ìfẹ́ tó o ní fún un á túbọ̀ jinlẹ̀, ìyẹn á sì jẹ́ kó o túbọ̀ sún mọ́ ọn.

15. Àǹfààní wo lo máa rí tó o bá ń sọ ohun tó o gbà gbọ́ fáwọn èèyàn?

15 Máa sọ ohun tó o gbà gbọ́ fáwọn míì. Tó o bá ń ṣe bẹ́ẹ̀, ìgbàgbọ́ rẹ á túbọ̀ máa lágbára. Àmọ́ tẹ́nì kan tó o wàásù fún ò bá gbà pé Ọlọ́run wà, tí o ò sì mọ ohun tó o máa sọ, kí ló yẹ kó o ṣe? O lè ṣèwádìí nínú àwọn ìtẹ̀jáde wa, kó o sì ṣàlàyé ẹ̀ fún ẹni náà. (1 Pét. 3:15) O tún lè ní kí Ẹlẹ́rìí kan tó nírìírí ràn ẹ́ lọ́wọ́. Yálà ẹni tó o wàásù fún náà gba àlàyé tó o ṣe látinú Bíbélì tàbí kò gbà á, ìwádìí tó o ti ṣe máa ràn ẹ́ lọ́wọ́, ìgbàgbọ́ rẹ á sì túbọ̀ lágbára. Nípa bẹ́ẹ̀, ohun táwọn ọ̀mọ̀wé inú ayé ń sọ pé kò sí Ọlọ́run ò ní mú kó o máa ṣiyèméjì.

MÁ ṢE JẸ́ KÍ ÌGBÀGBỌ́ RẸ JÓ RẸ̀YÌN!

16. Kí ló lè ṣẹlẹ̀ tá ò bá jẹ́ kí ìgbàgbọ́ wa máa lágbára sí i?

16 Láìka bó ti pẹ́ tó tá a ti ń sin Jèhófà bọ̀, a gbọ́dọ̀ máa ṣe ohun táá jẹ́ kí ìgbàgbọ́ wa túbọ̀ máa lágbára. Kí nìdí? Ìdí ni pé tá ò bá ṣọ́ra, ìgbàgbọ́ wa lè bẹ̀rẹ̀ sí í jó rẹ̀yìn. Ẹ rántí pé ohun tó ń jẹ́ kéèyàn nígbàgbọ́ ni ẹ̀rí tó dájú nípa àwọn ohun gidi tí a kò rí. Bẹ́ẹ̀ sì rèé, téèyàn ò bá rí nǹkan, èèyàn lè tètè gbàgbé rẹ̀. Abájọ tí Pọ́ọ̀lù fi sọ pé àìnígbàgbọ́ jẹ́ “ẹ̀ṣẹ̀ tó máa ń wé mọ́ wa tìrọ̀rùn-tìrọ̀rùn.” (Héb. 12:1) Kí wá la lè ṣe tí ìgbàgbọ́ wa ò fi ní jó rẹ̀yìn?​—2 Tẹs. 1:3.

17. Kí la lè ṣe tí ìgbàgbọ́ wa ò fi ní jó rẹ̀yìn?

17 Lákọ̀ọ́kọ́, bẹ Jèhófà pé kó fún ẹ ní ẹ̀mí mímọ́ rẹ̀, kó o sì máa ṣe bẹ́ẹ̀ déédéé. Kí nìdí? Ìdí ni pé ìgbàgbọ́ jẹ́ apá kan èso ti ẹ̀mí. (Gál. 5:22, 23) Ẹ̀mí mímọ́ nìkan ló lè mú ká nígbàgbọ́ nínú Ẹlẹ́dàá, òun náà sì ni ò ní jẹ́ kígbàgbọ́ wa jó rẹ̀yìn. Tá a bá ń bẹ Jèhófà pé kó fún wa ní ẹ̀mí mímọ́ rẹ̀, ó dájú pé ó máa fún wa. (Lúùkù 11:13) Kódà, a lè sọ fún un pé: “Fún wa ní ìgbàgbọ́ sí i.”​—Lúùkù 17:5.

18. Àǹfààní wo la ní báyìí táá jẹ́ ká lè máa ṣe ohun tó wà nínú Sáàmù 1:2, 3?

18 Bákan náà, máa kẹ́kọ̀ọ́ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run déédéé. (Ka Sáàmù 1:2, 3.) Nígbà tí wọ́n kọ Sáàmù yìí, ìwọ̀nba àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ló ní gbogbo Òfin Ọlọ́run látòkèdélẹ̀. Bó ti wù kó rí, àwọn ọba àtàwọn àlùfáà máa ń ní ẹ̀dà ìwé Òfin náà lọ́wọ́, wọ́n sì ṣètò pé lọ́dún méje-méje kí wọ́n ka Òfin Ọlọ́run sétí “àwọn ọkùnrin, àwọn obìnrin, àwọn ọmọdé” títí kan àwọn àjèjì tó wà ní Ísírẹ́lì. (Diu. 31:10-12) Nígbà ayé Jésù, inú sínágọ́gù àti ọwọ́ àwọn èèyàn díẹ̀ nìkan ni wọ́n ti lè rí àkájọ Ìwé Mímọ́. Àmọ́ lónìí, ọ̀pọ̀ èèyàn ló ní Bíbélì lọ́wọ́ bó tiẹ̀ jẹ́ apá kan nínú ẹ̀. Àǹfààní ńlá mà nìyẹn o. Kí la lè ṣe táá fi hàn pé a mọyì àǹfààní náà?

19. Kí ló yẹ ká ṣe tá ò bá fẹ́ kí ìgbàgbọ́ wa jó rẹ̀yìn?

19 A lè fi hàn pé a mọyì Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run tá a bá ń kà á déédéé. Ó yẹ ká ní ètò tó ṣe gúnmọ́ tó bá di pé ká máa dá kẹ́kọ̀ọ́, kì í ṣe ká kàn máa ṣe é ní ìdákúrekú. Tá a bá ń dá kẹ́kọ̀ọ́ déédéé, ìgbàgbọ́ wa ò ní jó rẹ̀yìn.

20. Kí ló yẹ ká pinnu láti ṣe báyìí?

20 A yàtọ̀ pátápátá sí “àwọn ọlọ́gbọ́n àti àwọn amòye” ayé yìí, ìdí sì ni pé ìgbàgbọ́ wa fẹsẹ̀ múlẹ̀ torí àwọn ẹ̀rí tó dájú tá a rí nínú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run. (Mát. 11:25, 26) Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run ti jẹ́ ká mọ ìdí tí wàhálà fi pọ̀ láyé àtohun tí Jèhófà máa ṣe sí i. Torí náà, ẹ jẹ́ ká pinnu pé àá máa ṣe ohun táá jẹ́ kí ìgbàgbọ́ wa lágbára sí i, àá sì ran àwọn míì lọ́wọ́ kí wọ́n lè nígbàgbọ́ nínú Jèhófà. (1 Tím. 2:3, 4) Bákan náà, ẹ jẹ́ ká máa fojú sọ́nà fún ìgbà tí gbogbo àwọn tó wà láyé á panu pọ̀ láti yin Jèhófà pẹ̀lú ọ̀rọ̀ tó wà nínú Ìfihàn 4:11 pé: “Jèhófà, Ọlọ́run wa, ìwọ ló tọ́ sí láti gba ògo . . . torí ìwọ lo dá ohun gbogbo.”

ORIN 2 Jèhófà Ni Orúkọ Rẹ

^ ìpínrọ̀ 5 Bíbélì jẹ́ kó ṣe kedere pé Jèhófà Ọlọ́run ló dá gbogbo nǹkan. Àmọ́ ọ̀pọ̀ èèyàn ni ò gbà bẹ́ẹ̀. Wọ́n gbà pé ayé kàn ṣàdédé wà ni pé kò sẹ́ni tó dá a. Ṣé ohun tí wọ́n sọ yẹn lè mú ká máa ṣiyèméjì bóyá Jèhófà ló dá gbogbo nǹkan? A ò ní ṣiyèméjì tá a bá jẹ́ kí ìgbàgbọ́ tá a ní nínú Ọlọ́run àti Bíbélì túbọ̀ lágbára. Torí náà, nínú àpilẹ̀kọ yìí, a máa jíròrò bá a ṣe lè ṣe bẹ́ẹ̀.

^ ìpínrọ̀ 5 Ní ọ̀pọ̀ iléèwé, wọn kì í kọ́ àwọn ọmọ pé Ọlọ́run ló dá gbogbo nǹkan. Àwọn olùkọ́ kan ronú pé táwọn bá ṣe bẹ́ẹ̀, ṣe ló máa dà bí ìgbà táwọn fẹ́ fipá mú káwọn ọmọ gba Ọlọ́run gbọ́.

^ ìpínrọ̀ 7 Àá rí díẹ̀ lára ọ̀rọ̀ táwọn onímọ̀ sáyẹ́ǹsì sọ nínú Ìwé Ìwádìí fún Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà. Wo àkòrí náà “Ìmọ̀ Sáyẹ́ǹsì àti Ìmọ̀ Iṣẹ́ Ẹ̀rọ,” kó o wá wo ìsọ̀rí tá a pè ní “‘Ìfọ̀rọ̀wánilẹ́nuwò’ (ọ̀wọ́ àpilẹ̀kọ tó jáde nínú Jí!).”

^ ìpínrọ̀ 12 Bí àpẹẹrẹ, wo àpilẹ̀kọ náà “Are Science and the Bible Compatible?” nínú Awake! February 2011 àti àpilẹ̀kọ náà “Àsọtẹ́lẹ̀ Jèhófà Máa Ń Ṣẹ” nínú Ilé Ìṣọ́ January 1, 2008.