Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

ÀPILẸ̀KỌ FÚN ÌKẸ́KỌ̀Ọ́ 34

Báwo La Ṣe Lè Tọ́ Oore Jèhófà Wò?

Báwo La Ṣe Lè Tọ́ Oore Jèhófà Wò?

“Ẹ tọ́ ọ wò, kí ẹ sì rí i pé ẹni rere ni Jèhófà, aláyọ̀ ni ọkùnrin tí ó fi í ṣe ibi ààbò.”​—SM. 34:8.

ORIN 117 Ìwà Rere

OHUN TÁ A MÁA JÍRÒRÒ *

1-2. Kí ni Sáàmù 34:8 sọ pé ká ṣe ká lè mọ̀ pé Jèhófà jẹ́ ẹni rere?

KÁ SỌ pé ẹnì kan fi oúnjẹ kan tó ò jẹ rí lọ̀ ẹ́, kí ni wàá ṣe? Kó o lè mọyì oúnjẹ náà, o lè béèrè bí wọ́n ṣe sè é, o lè wo ojú ẹ̀, o lè kíyè sí bó ṣe ń ta sánsán, kó o sì bi àwọn tó ti jẹ ẹ́ rí nípa bó ṣe rí. Àmọ́, ọ̀nà kan ṣoṣo tó o lè gbà mọyì oúnjẹ náà ni pé kó o tọ́ ọ wò. Ó ṣe tán, wọ́n máa ń sọ pé ìtọ́wò la fi ń mọ adùn ọbẹ̀.

2 A lè túbọ̀ mọ̀ pé Jèhófà jẹ́ ẹni rere tá a bá ń ka Bíbélì àtàwọn ìtẹ̀jáde wa tá a sì ń bi àwọn míì nípa bí Jèhófà ṣe bù kún wọn. Àmọ́, ó dìgbà tá a bá “tọ́” Jèhófà wò fúnra wa ká tó lè mọ bí oore ẹ̀ ṣe pọ̀ tó. (Ka Sáàmù 34:8.) Ẹ jẹ́ ká wo ọ̀nà kan tá a lè gbà ṣe bẹ́ẹ̀. Ká sọ pé ó wù wá láti ṣe iṣẹ́ ìsìn alákòókò kíkún, àmọ́ ká tó lè ṣe bẹ́ẹ̀, ó máa gba pé ká ṣe àwọn àyípadà kan. Ó ṣeé ṣe kó jẹ́ pé ọ̀pọ̀ ìgbà la ti ka ìlérí tí Jésù ṣe pé tá a bá fi ire Ìjọba náà sípò àkọ́kọ́, Jèhófà máa pèsè gbogbo ohun tá a nílò. Àmọ́ àwa fúnra wa ò tíì gbé ìgbésẹ̀ débi tá a fi máa rí bí Jèhófà ṣe ń mú ìlérí yẹn ṣẹ. (Mát. 6:33) Torí pé a nígbàgbọ́ nínú ìlérí tí Jésù ṣe, a dín ìnáwó wa kù, a dín iṣẹ́ oúnjẹ òòjọ́ wa kù, a sì gbájú mọ́ iṣẹ́ ìwàásù. Bá a ṣe ń ṣe bẹ́ẹ̀, àwa fúnra wa máa rí bí Jèhófà ṣe ń pèsè àwọn nǹkan tá a nílò. Nípa bẹ́ẹ̀, à ń “tọ́” Jèhófà wò, àá sì rí i pé ẹni rere ni.

3. Bó ṣe wà nínú Sáàmù 16:1, 2, àwọn wo ní pàtàkì ló máa ń rí oore Jèhófà?

3 Gbogbo èèyàn ni Jèhófà “ń ṣoore fún” títí kan àwọn tí ò mọ̀ ọ́n. (Sm. 145:9; Mát. 5:45) Àmọ́ àwọn tó nífẹ̀ẹ́ Jèhófà tó sì ń fi gbogbo ọkàn wọn sìn ín ló máa ń rí oore Jèhófà jù. (Ka Sáàmù 16:1, 2.) Ẹ jẹ́ ká wo díẹ̀ lára àwọn nǹkan rere tí Jèhófà ti ṣe fún wa.

4. Báwo ni Jèhófà ṣe ń ṣoore fáwọn tó ṣẹ̀ṣẹ̀ bẹ̀rẹ̀ sí í mọ̀ ọ́n?

4 Gbogbo ìgbà tá a bá ń fi ohun tá a kọ́ lọ́dọ̀ Jèhófà sílò ló máa ń ṣe wá láǹfààní. Bá a ṣe túbọ̀ ń mọ̀ ọ́n tá a sì ń nífẹ̀ẹ́ rẹ̀, Jèhófà ràn wá lọ́wọ́ láti borí èrò òdì àtàwọn àṣà tí kò bá Bíbélì mu. (Kól. 1:21) Nígbà tá a ya ara wa sí mímọ́ tá a sì ṣèrìbọmi, a túbọ̀ rí oore Jèhófà nígbèésí ayé wa, ó fún wa ní ẹ̀rí ọkàn tó dáa, ó sì mú ká túbọ̀ sún mọ́ òun.​—1 Pét. 3:21.

5. Báwo la ṣe ń rí ọwọ́ Jèhófà lẹ́nu iṣẹ́ ìwàásù?

5 A máa ń rí bí Jèhófà ṣe ń ràn wá lọ́wọ́ lẹ́nu iṣẹ́ ìwàásù. Bí àpẹẹrẹ, ṣé o máa ń tijú? Òótọ́ ibẹ̀ ni pé ọ̀pọ̀ àwa èèyàn Jèhófà la máa ń tijú. Ó ṣeé ṣe kó jẹ́ pé kó o tó di ọ̀kan lára àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà, o ò lè ronú ẹ̀ láé pé wàá lọ kan ilẹ̀kùn ẹni tí o ò mọ̀ rí, wàá sì máa sọ̀rọ̀ Ọlọ́run fún un. Àmọ́ ní báyìí, o ti ń ṣe bẹ́ẹ̀ lóòrèkóòrè. Yàtọ̀ síyẹn, Jèhófà ń ràn ẹ́ lọ́wọ́, o sì ti ń gbádùn iṣẹ́ ìwàásù gan-an! Bí àpẹẹrẹ, ó ti ràn ẹ́ lọ́wọ́ kó o lè máa mú sùúrù táwọn èèyàn bá sọ̀rọ̀ burúkú sí ẹ lóde ẹ̀rí. Yàtọ̀ síyẹn, ó máa ń jẹ́ kó o rántí àwọn ẹsẹ Bíbélì tó o lè kà táá wọ onílé lọ́kàn. Bákan náà, ó ti fún ẹ lókun kó o lè máa bá iṣẹ́ ìwàásù nìṣó báwọn èèyàn ò tiẹ̀ ń fẹ́ gbọ́ ìwàásù ní ìpínlẹ̀ yín.​—Jer. 20:7-9.

6. Báwo ni ìdálẹ́kọ̀ọ́ tí Jèhófà ń fún wa ṣe ń ṣe wá láǹfààní?

6 Ọ̀nà míì tá à ń gbà jàǹfààní oore Jèhófà ni pé ó ń dá wa lẹ́kọ̀ọ́ ká lè túbọ̀ já fáfá lẹ́nu iṣẹ́ ìwàásù. (Jòh. 6:45) Láwọn ìpàdé àárín ọ̀sẹ̀, a máa ń wo àwọn àṣefihàn àtàwọn fídíò tó dá lórí ohun tá a lè bá àwọn èèyàn sọ. Wọ́n sì máa ń rọ̀ wá pé ká lo àwọn àbá yẹn lẹ́nu iṣẹ́ ìwàásù. Ó lè kọ́kọ́ ṣòro fún wa láti lo àwọn ọ̀nà tuntun tá à ń gbà wàásù, àmọ́ tá a bá gbìyànjú ẹ̀ wò, a lè wá rí i pé àwọn ọ̀nà yẹn gbéṣẹ́ gan-an ní ìpínlẹ̀ ìwàásù wa. Láwọn ìpàdé àtàwọn àpéjọ wa, wọ́n máa ń rọ̀ wá pé ká lo àwọn ọ̀nà tuntun tá ò lò rí láti wàásù. Ẹ̀rù lè máa bà wá láti lo àwọn ọ̀nà tuntun yìí, àmọ́ tá a bá ṣe bẹ́ẹ̀, Jèhófà máa bù kún wa. Ní báyìí, ẹ jẹ́ ká wo díẹ̀ lára àwọn ìbùkún tá a máa rí tá a bá ṣe gbogbo ohun tá a lè ṣe nínú ìjọsìn wa láìka ipò tá a wà sí. Lẹ́yìn náà, a máa wo àwọn ọ̀nà tá a lè gbà ṣe púpọ̀ sí i lẹ́nu iṣẹ́ ìsìn wa.

JÈHÓFÀ MÁA Ń BÙ KÚN ÀWỌN TÓ BÁ GBẸ́KẸ̀ LÉ E

7. Àwọn ìbùkún wo la máa rí tá a bá ń ṣe púpọ̀ sí i lẹ́nu iṣẹ́ òjíṣẹ́ wa?

7 A máa túbọ̀ sún mọ́ Jèhófà. Ẹ jẹ́ ká wo àpẹẹrẹ alàgbà kan tó ń jẹ́ Samuel * tóun àti ìyàwó ẹ̀ ń sìn ní Kòlóńbíà. Tọkọtaya yìí ń gbádùn iṣẹ́ aṣáájú-ọ̀nà tí wọ́n ń ṣe níjọ wọn, àmọ́ ó wù wọ́n láti lọ ran ìjọ míì tó ní àìní lọ́wọ́. Àmọ́ kí wọ́n tó lè ṣe bẹ́ẹ̀, wọ́n gbọ́dọ̀ ṣe àwọn àyípadà kan. Arákùnrin Samuel sọ pé: “A fi ohun tó wà nínú Mátíù 6:33 sílò, a ò sì ra àwọn nǹkan tí ò pọn dandan. Àmọ́ èyí tó le jù fún wa ni ilé wa tá a fi sílẹ̀. A fẹ́ràn ilé yẹn gan-an, a ò sì jẹ gbèsè kankan lórí ẹ̀.” Ní ìjọ tuntun tí wọ́n lọ, ìwọ̀nba owó díẹ̀ ni wọ́n fi ń gbọ́ bùkátà ara wọn. Arákùnrin Samuel tún sọ pé: “A ti rí bí Jèhófà ṣe ń tọ́ wa sọ́nà tó sì ń dáhùn àdúrà wa. A mọ̀ pé inú Jèhófà ń dùn sí wa, ó sì ń fìfẹ́ hàn sí wa lọ́nà tó ṣàrà ọ̀tọ̀.” Ṣé ìwọ náà lè ṣe púpọ̀ sí i lẹ́nu iṣẹ́ òjíṣẹ́ rẹ? Tó o bá ṣe bẹ́ẹ̀, wàá túbọ̀ sún mọ́ Jèhófà, ó sì dájú pé Jèhófà máa bójú tó ẹ.​—Sm. 18:25.

8. Kí lo rí kọ́ látinú ohun tí Ivan àti Viktoria sọ?

8 Àá túbọ̀ máa láyọ̀ lẹ́nu iṣẹ́ ìsìn wa. Ẹ jẹ́ ká gbọ́ ohun tí tọkọtaya aṣáájú-ọ̀nà kan tó ń jẹ́ Ivan àti Viktoria sọ, orílẹ̀-èdè Kyrgyzstan ni wọ́n ń gbé. Wọ́n jẹ́ kí ohun díẹ̀ tẹ́ wọn lọ́rùn kí wọ́n lè ráyè yọ̀ǹda ara wọn fún onírúurú iṣẹ́ títí kan iṣẹ́ ìkọ́lé. Ivan sọ pé: “A máa ń ṣe gbogbo ohun tágbára wa gbé nínú iṣẹ́ ìkọ́lé èyíkéyìí tá a bá ń ṣe. Bó tiẹ̀ jẹ́ pé ó máa ń rẹ̀ wá lẹ́yìn iṣẹ́ ọjọ́ kọ̀ọ̀kan, inú wa máa ń dùn, ọkàn wa sì máa ń balẹ̀ torí a mọ̀ pé a ti lo ara wa lẹ́nu iṣẹ́ ìsìn Jèhófà. Yàtọ̀ síyẹn, a tún ń láyọ̀ torí a láwọn ọ̀rẹ́ tuntun, a sì ní àwọn ìrírí mánigbàgbé.”​—Máàkù 10:29, 30.

9. Kí ni arábìnrin kan tí ipò ẹ̀ ò fi bẹ́ẹ̀ bára dé ṣe kó lè ṣe púpọ̀ sí i lẹ́nu iṣẹ́ ìsìn rẹ̀, kí sì nìyẹn yọrí sí?

9 A ṣì lè láyọ̀ lẹ́nu iṣẹ́ ìsìn Jèhófà kódà tí ipò wa ò bá bára dé. Bí àpẹẹrẹ, opó ni Arábìnrin Mirreh, ó ti dàgbà, West Africa ló sì ń gbé. Lẹ́yìn tó fẹ̀yìn tì lẹ́nu iṣẹ́ dókítà tó ṣe, ó bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ aṣáájú-ọ̀nà. Yàtọ̀ síyẹn, Mirreh ní àrùn aromọléegun tó le gan-an, wákàtí kan péré ló sì lè lò lẹ́nu iṣẹ́ ìwàásù ilé-dé-ilé. Àmọ́, ó máa ń lò jù bẹ́ẹ̀ lọ níbi àtẹ ìwé wa. Bákan náà, ó ní ọ̀pọ̀ ìpadàbẹ̀wò àti ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, kódà orí fóònù ló ti máa ń pe àwọn kan. Kí ló ń mú kí Mirreh máa ṣe gbogbo ohun tó ń ṣe yìí? Ó sọ pé: “Ìfẹ́ tí mo ní fún Jèhófà àti Jésù Kristi ló mú kí n máa ṣe bẹ́ẹ̀. Gbogbo ìgbà ni mo sì máa ń gbàdúrà pé kí Jèhófà ràn mí lọ́wọ́ kí n lè ṣe gbogbo ohun tí mo lè ṣe lẹ́nu iṣẹ́ ìsìn ẹ̀.”​—Mát. 22:36, 37.

10. Bó ṣe wà nínú 1 Pétérù 5:10, kí ni Jèhófà máa ń ṣe fáwọn tó ń ṣe púpọ̀ sí i lẹ́nu iṣẹ́ ìsìn rẹ̀?

10 Jèhófà ń dá wa lẹ́kọ̀ọ́ lónírúurú ọ̀nà. Aṣáájú-ọ̀nà kan tó ń jẹ́ Kenny tó ń gbé ní Mauritius gbà pé òótọ́ lọ̀rọ̀ yìí. Nígbà tó kẹ́kọ̀ọ́ òtítọ́, ó fi yunifásítì sílẹ̀, ó ṣèrìbọmi, ó sì bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ aṣáájú-ọ̀nà. Ó sọ pé: “Ohun tó mú kí n ṣe bẹ́ẹ̀ ni ọ̀rọ̀ wòlíì Àìsáyà tó sọ pé: ‘Èmi nìyí! Rán mi!’ ” (Àìsá. 6:8) Ọ̀pọ̀ ìgbà ni Kenny ti ṣiṣẹ́ pẹ̀lú àwọn tó ń kọ́ ilé ètò Ọlọ́run, ó sì tún ṣiṣẹ́ pẹ̀lú àwọn tó ń túmọ̀ ìwé wa sí èdè ìbílẹ̀ rẹ̀. Ó sọ pé: “Wọ́n dá mi lẹ́kọ̀ọ́ lórí bí mo ṣe lè ṣe àwọn iṣẹ́ yìí láṣeyọrí.” Àmọ́ kò mọ síbẹ̀ o. Ó tún sọ àwọn nǹkan míì tó kọ́. Ó ní: “Ní báyìí mo ti mọ ohun tágbára mi gbé, mo sì ti kọ́ àwọn ànímọ́ tó yẹ kí n ní kí n lè túbọ̀ sún mọ́ Jèhófà.” (Ka 1 Pétérù 5:10.) O ò ṣe kíyè sí ohun tó ò ń fi àkókò rẹ ṣe kó o sì wò ó bóyá o lè ṣe púpọ̀ sí i lẹ́nu iṣẹ́ ìsìn Jèhófà kó o sì tipa bẹ́ẹ̀ gba àwọn ìdálẹ́kọ̀ọ́ míì?

Tọkọtaya kan ń wàásù níbi tí àìní gbé pọ̀; arábìnrin kan tó jẹ́ ọ̀dọ́ ń yọ̀ǹda ara ẹ̀ níbi tí wọ́n ti ń kọ́ Gbọ̀ngàn Ìjọba; tọkọtaya àgbàlagbà kan ń wàásù látorí fóònù. Gbogbo wọn ń láyọ̀ lẹ́nu iṣẹ́ ìsìn wọn (Wo ìpínrọ̀ 11)

11. Kí làwọn arábìnrin kan ṣe ní South Korea kí wọ́n lè wàásù, kí nìyẹn sì yọrí sí? (Wo àwòrán iwájú ìwé.)

11 Àwọn tó ti pẹ́ nínú ètò Ọlọ́run náà jàǹfààní gan-an nígbà tí wọ́n gbìyànjú àwọn ọ̀nà tuntun tá à ń gbà wàásù. Nígbà tí àrùn Corona ń jà lọ́wọ́, àwọn alàgbà tó wà níjọ kan ní South Korea sọ pé: “Àwọn kan tó ronú pé àwọn ò lè wàásù torí ìlera wọn ti ń ṣe bẹ́ẹ̀ báyìí lórí fóònù. Àwọn arábìnrin mẹ́ta kan tó ti lé lẹ́ni ọgọ́rin ọdún kọ́ bí wọ́n ṣe lè wàásù lórí fídíò orí Íńtánẹ́ẹ̀tì, ó sì fẹ́rẹ̀ẹ́ jẹ́ pé ojoojúmọ́ ni wọ́n ń wàásù.” (Sm. 92:14, 15) Ṣé ìwọ náà lè ṣe púpọ̀ sí i lẹ́nu iṣẹ́ ìsìn Jèhófà kó o lè tipa bẹ́ẹ̀ tọ́ Jèhófà wò kó o sì rí oore rẹ̀? Ẹ jẹ́ ká wo àwọn nǹkan táá jẹ́ kó o lè ṣe bẹ́ẹ̀.

OHUN TÁÁ JẸ́ KÓ O LÈ ṢE PÚPỌ̀ SÍ I

12. Ìlérí wo ni Jèhófà ṣe fún àwọn tó bá gbẹ́kẹ̀ lé e?

12 Gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà. Jèhófà ṣèlérí pé òun máa bù kún wa tá a bá gbẹ́kẹ̀ lé òun tá a sì ṣe gbogbo ohun tá a lè ṣe lẹ́nu iṣẹ́ ìsìn rẹ̀. (Mál. 3:10) Arábìnrin Fabiola tó ń gbé ní Kòlóńbíà rí i pé òótọ́ ni ọ̀rọ̀ yìí. Lẹ́yìn tó ṣèrìbọmi ló ti wù ú pé kó bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ aṣáájú-ọ̀nà. Àmọ́, òun ló ń gbọ́ bùkátà ọkọ ẹ̀ àtàwọn ọmọ wọn. Torí náà nígbà tó fẹ̀yìn tì lẹ́nu iṣẹ́, ó gbàdúrà pé kí Jèhófà ran òun lọ́wọ́. Ó sọ pé: “Ó máa ń pẹ́ gan-an káwọn èèyàn tó rí owó ìfẹ̀yìntì wọn gbà, àmọ́ mo rí tèmi gbà lẹ́yìn oṣù kan péré tí mo béèrè fún un. Ó yà mí lẹ́nu gan-an, mo mọ̀ pé Jèhófà ló jẹ́ kó ṣeé ṣe!” Lẹ́yìn oṣù méjì, ó bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ aṣáájú-ọ̀nà. Ní báyìí, ó ti lé lẹ́ni àádọ́rin (70) ọdún, ó sì ti ń ṣiṣẹ́ aṣáájú-ọ̀nà fún ohun tó lé lógún (20) ọdún. Láàárín àkókò yìí, ó ti ran èèyàn mẹ́jọ lọ́wọ́ débi tí wọ́n fi ṣèrìbọmi. Ó sọ pé: “Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ó máa ń rẹ̀ mí nígbà míì, Jèhófà ń ràn mí lọ́wọ́ kí n lè máa bá iṣẹ́ náà lọ.”

Báwo ni Ábúráhámù àti Sérà, Jékọ́bù àtàwọn àlùfáà tó sọdá Odò Jọ́dánì ṣe fi hàn pé àwọn gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà? (Wo ìpínrọ̀ 13)

13-14. Àwọn àpẹẹrẹ wo ló lè mú ká gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà kó lè wù wá láti ṣe púpọ̀ sí i?

13 Kẹ́kọ̀ọ́ látinú àpẹẹrẹ àwọn tó gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà. Nínú Bíbélì, a máa rí àpẹẹrẹ àwọn tí wọ́n lo gbogbo okun wọn lẹ́nu iṣẹ́ ìsìn Jèhófà. Ọ̀pọ̀ wọn ló ní láti kọ́kọ́ gbé ìgbésẹ̀ tó fi hàn pé wọ́n gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà kí Jèhófà tó bù kún wọn lọ́nà tó ṣàrà ọ̀tọ̀. Bí àpẹẹrẹ, ẹ̀yìn tí Ábúráhámù fi ilé rẹ̀ sílẹ̀ ni Jèhófà bù kún un “bí kò tiẹ̀ mọ ibi tó ń lọ.” (Héb. 11:8) Bákan náà, ẹ̀yìn tí Jékọ́bù bá áńgẹ́lì jìjàkadì ló tó rí ìbùkún tó ṣàrà ọ̀tọ̀ gbà. (Jẹ́n. 32:24-30) Yàtọ̀ síyẹn, ẹ̀yìn táwọn àlùfáà ki ẹsẹ̀ bọ Odò Jọ́dánì làwọn ọmọ Ísírẹ́lì tó lè sọdá láti wọ Ilẹ̀ Ìlérí.​—Jóṣ. 3:14-16.

14 Ọ̀pọ̀ àwọn ará wa lónìí náà ló ti fi hàn pé àwọn gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà tí wọ́n sì ṣe púpọ̀ sí i, a sì lè kẹ́kọ̀ọ́ lára wọn. Bí àpẹẹrẹ, Arákùnrin Payton àti ìyàwó ẹ̀ Diana gbádùn kí wọ́n máa ka ìrírí àwọn ará tí wọ́n ń ṣe púpọ̀ sí i lẹ́nu iṣẹ́ ìsìn Jèhófà irú èyí tó wà nínú ọ̀wọ́ àpilẹ̀kọ náà “Wọ́n Yọ̀ǹda Ara Wọn Tinútinú.” * Payton sọ pé: “Tá a bá ń ka àwọn ìrírí yẹn, ó máa ń ṣe wá bíi pé à ń wo ẹnì kan tó ń gbádùn oúnjẹ aládùn. Bá a ṣe túbọ̀ ń ka àwọn ìrírí yẹn, bẹ́ẹ̀ ló ṣe túbọ̀ ń wù wá láti ‘tọ́ Jèhófà wò, ká sì rí i pé ẹni rere ni.’ ” Nígbà tó yá, Payton àti Diana lọ sìn níbi tí àìní gbé pọ̀. Ṣé ìwọ náà ti ka àwọn àpilẹ̀kọ yìí? Ṣé o sì ti wo fídíò Wíwàásù ní Agbègbè Àdádó​—Ọsirélíà àti Wíwàásù ní Agbègbè Àdádó​—Ireland lórí ìkànnì jw.org? Tó o bá ṣe bẹ́ẹ̀, wàá rí àwọn ọ̀nà tó o lè gbà ṣe púpọ̀ sí i lẹ́nu iṣẹ́ ìsìn Jèhófà.

15. Àǹfààní wo la máa rí tá a bá ń kẹ́gbẹ́ pẹ̀lú àwọn tó nífẹ̀ẹ́ iṣẹ́ ìsìn Jèhófà?

15 Máa kẹ́gbẹ́ pẹ̀lú àwọn tó nífẹ̀ẹ́ iṣẹ́ ìsìn Jèhófà. Ó máa yá wa lára láti jẹ oúnjẹ kan tá ò jẹ rí tá a bá wà pẹ̀lú àwọn tó fẹ́ràn oúnjẹ náà. Bákan náà, tá a bá ń kẹ́gbẹ́ pẹ̀lú àwọn tó nífẹ̀ẹ́ iṣẹ́ ìsìn Jèhófà, ó ṣeé ṣe kíyẹn mú kó wù wá láti ṣe púpọ̀ sí i lẹ́nu iṣẹ́ ìsìn wa. Tọkọtaya kan tó ń jẹ́ Kent àti Veronica náà gbà pé òótọ́ lọ̀rọ̀ yìí. Kent sọ pé: “Àwọn ọ̀rẹ́ wa àtàwọn mọ̀lẹ́bí wa rọ̀ wá pé ká gbìyànjú láti fi kún iṣẹ́ ìsìn wa. A wá rí i pé bá a ṣe ń kẹ́gbẹ́ pẹ̀lú àwọn tó ń fi ire Ìjọba Ọlọ́run sípò àkọ́kọ́ ń mú kọ́kàn wa balẹ̀ pé àwa náà lè ṣe púpọ̀ sí i fún Jèhófà.” Ní báyìí, Kent àti Veronica ti di aṣáájú-ọ̀nà àkànṣe lórílẹ̀-èdè Serbia.

16. Bó ṣe wà nínú àpèjúwe tí Jésù ṣe nínú Lúùkù 12:16-21, kí ló yẹ ká múra tán láti ṣe?

16 Múra tán láti yááfì àwọn nǹkan kan. Kò dìgbà tá a bá yááfì gbogbo ohun tá à ń gbádùn ká tó lè múnú Jèhófà dùn. (Oníw. 5:19, 20) Àmọ́ tá ò bá ṣe púpọ̀ lẹ́nu iṣẹ́ ìsìn Jèhófà torí pé ó nira fún wa láti yááfì àwọn nǹkan tá à ń gbádùn, ṣe lọ̀rọ̀ wa máa dà bí ọkùnrin tí Jésù ṣàkàwé ẹ̀ pé bó ṣe máa gbádùn ayé ẹ̀ ló gbà á lọ́kàn dípò bó ṣe máa ṣe ohun tí Ọlọ́run fẹ́. (Ka Lúùkù 12:16-21.) Arákùnrin Christian tó ń gbé nílẹ̀ Faransé sọ pé: “Mo kíyè sí i pé mi ò kì í fi bẹ́ẹ̀ ráyè fún Jèhófà àti ìdílé mi.” Òun àti ìyàwó ẹ̀ wá pinnu láti di aṣáájú-ọ̀nà, àmọ́ ó máa gba pé kí wọ́n fi iṣẹ́ wọn sílẹ̀ kí wọ́n tó lè ṣe bẹ́ẹ̀. Lẹ́yìn tí wọ́n fiṣẹ́ wọn sílẹ̀, wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí í bá àwọn èèyàn tún ilé àti ọ́fíìsì wọn ṣe, wọ́n sì jẹ́ kí ohun díẹ̀ tẹ́ wọn lọ́rùn. Báwo ni ohun tí wọ́n ṣe yẹn ṣe rí lára wọn? Christian sọ pé: “Ní báyìí, à ń gbádùn iṣẹ́ ìwàásù gan-an, inú wa sì ń dùn bá a ṣe ń rí i tí àwọn ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì wa àtàwọn ìpadàbẹ̀wò wa túbọ̀ ń mọ Jèhófà.”

17. Kí ló lè mú kó nira fún wa láti lo àwọn ọ̀nà tuntun tá à ń gbà wàásù?

17 Sapá láti lo àwọn ọ̀nà tuntun tá à ń gbà wàásù. (Ìṣe 17:16, 17; 20:20, 21) Aṣáájú-ọ̀nà kan tó ń jẹ́ Shirley lórílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà ní láti yí ọ̀nà tó ń gbà wàásù pa dà lásìkò àjàkálẹ̀ àrùn Corona. Níbẹ̀rẹ̀, kò kọ́kọ́ rọrùn fún un láti wàásù lórí fóònù. Àmọ́ lẹ́yìn tí wọ́n gba ìbẹ̀wò, tí alábòójútó àyíká sì dá wọn lẹ́kọ̀ọ́, ó bẹ̀rẹ̀ sí í wàásù lórí fóònù déédéé. Ó sọ pé: “Nígbà tí mo bẹ̀rẹ̀, ẹ̀rù kọ́kọ́ bà mí, àmọ́ mo ti ń gbádùn ẹ̀ gan-an. Ní báyìí, àwọn tá a máa ń bá sọ̀rọ̀ ti pọ̀ ju ti ìgbà tá à ń wàásù láti ilé dé ilé lọ!”

18. Kí ló lè ràn wá lọ́wọ́ láti borí àwọn nǹkan tó lè mú kó ṣòro fún wa láti ṣe púpọ̀ sí i lẹ́nu iṣẹ́ ìwàásù?

18 Ní àfojúsùn, kó o sì gbé ìgbésẹ̀ kọ́wọ́ ẹ lè tẹ̀ ẹ́. Tá a bá kojú ìṣòro, ó yẹ ká gbàdúrà pé kí Jèhófà ràn wá lọ́wọ́, ká sì ronú nípa ohun tá a lè ṣe láti yanjú ìṣòro náà. (Òwe 3:21) Aṣáájú-ọ̀nà déédéé kan tó ń jẹ́ Sonia tó ń sìn pẹ̀lú àwùjọ tó ń sọ èdè Romany ní Yúróòpù sọ pé: “Mo máa ń kọ àwọn ohun tí mo fẹ́ ṣe sínú bébà kan, màá wá fi bébà náà síbi tí màá ti máa rí i. Yàtọ̀ síyẹn, mo lẹ àwòrán ọ̀nà tó pín sí méjì mọ́ tábìlì mi. Tí mo bá fẹ́ ṣe ìpinnu kan, màá wo àwòrán náà, ìyẹn sì máa ń jẹ́ kí n lè ronú bóyá ìpinnu tí mo fẹ́ ṣe náà máa jẹ́ kọ́wọ́ mi lè tẹ àfojúsùn mi.” Sonia kì í jẹ́ káwọn ìṣòro ẹ̀ kó o lọ́kàn sókè. Ó sọ pé: “Yálà ìṣòro tí mo ní máa dà bí ògiri tí ò ní jẹ́ kọ́wọ́ mi tẹ àfojúsùn mi tàbí ó máa dà bí afárá táá jẹ́ kọ́wọ́ mi tẹ̀ ẹ́, ọwọ́ mi ló kù sí.”

19. Kí la lè ṣe láti fi hàn pé a mọyì gbogbo nǹkan rere tí Jèhófà ti ṣe fún wa?

19 Ọ̀pọ̀ nǹkan rere ni Jèhófà ti ṣe fún wa. A lè fi hàn pé a mọyì àwọn nǹkan rere yìí tá a bá ń ṣe gbogbo ohun tá a lè ṣe láti fògo fún Jèhófà. (Héb. 13:15) A lè ṣe bẹ́ẹ̀ tá a bá ń wá onírúurú ọ̀nà tá a lè gbà ṣe púpọ̀ sí i lẹ́nu iṣẹ́ ìsìn rẹ̀, ìyẹn sì máa mú kí Jèhófà bù kún wa lọ́nà tó ṣàrà ọ̀tọ̀. Lójoojúmọ́, ẹ jẹ́ ká máa wá ọ̀nà tá a lè gbà ‘tọ́ Jèhófà wò, ká sì rí i pé ẹni rere ni.’ Tá a bá ṣe bẹ́ẹ̀, ṣe lọ̀rọ̀ wa máa dà bíi ti Jésù tó sọ pé: “Oúnjẹ mi ni pé kí n ṣe ìfẹ́ ẹni tó rán mi, kí n sì parí iṣẹ́ rẹ̀.”​—Jòh. 4:34.

ORIN 80 “Tọ́ Ọ Wò, Kó O sì Rí I Pé Ẹni Rere Ni Jèhófà”

^ ìpínrọ̀ 5 Ọ̀dọ̀ Jèhófà ni gbogbo nǹkan rere ti wá, gbogbo èèyàn ló máa ń ṣoore fún títí kan àwọn èèyàn burúkú. Àmọ́ inú ẹ̀ máa ń dùn láti ṣoore fún àwọn tó ń sìn ín tọkàntọkàn. Nínú àpilẹ̀kọ yìí, a máa jíròrò bí Jèhófà ṣe ń ṣoore fáwọn ìránṣẹ́ rẹ̀. Àá tún jíròrò bí àwọn tó bá ṣe púpọ̀ sí i lẹ́nu iṣẹ́ ìsìn wọn ṣe máa rí oore Jèhófà lọ́nà tó ṣàrà ọ̀tọ̀.

^ ìpínrọ̀ 7 A ti yí àwọn orúkọ kan pa dà.

^ ìpínrọ̀ 14 Ọ̀wọ́ àpilẹ̀kọ yìí máa ń jáde nínú Ilé Ìṣọ́ tẹ́lẹ̀, àmọ́ ní báyìí, orí ìkànnì jw.org ló máa ń wà. Lọ sí NÍPA WA > ÌRÍRÍ > ỌWỌ́ WỌN Ń TẸ OHUN TÍ WỌ́N Ń LÉ LẸ́NU IṢẸ́ ỌLỌ́RUN.