Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

ÀPILẸ̀KỌ FÚN ÌKẸ́KỌ̀Ọ́ 35

Ǹjẹ́ O Mọyì Àwọn Àgbàlagbà Tó Wà Láàárín Wa?

Ǹjẹ́ O Mọyì Àwọn Àgbàlagbà Tó Wà Láàárín Wa?

“Ewú orí jẹ́ adé ẹwà.”​—ÒWE 16:31.

ORIN 138 Ẹwà Orí Ewú

OHUN TÁ A MÁA JÍRÒRÒ *

1-2. (a) Bó ṣe wà nínú Òwe 16:31, irú ojú wo ló yẹ ká fi máa wo àwọn àgbàlagbà tó wà nínú ètò Jèhófà? (b) Àwọn ìbéèrè wo la máa dáhùn nínú àpilẹ̀kọ yìí?

ÌLÚ kan wà lórílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà téèyàn ti lè rí dáyámọ́ǹdì nílẹ̀ẹ́lẹ̀. Lójú ọ̀pọ̀, bí òkúta lásánlàsàn ló ṣe máa ń rí torí pé àwọn alágbẹ̀dẹ ò tíì ṣiṣẹ́ lé e lórí débi táá ṣe é lò. Abájọ tí ọ̀pọ̀ kì í kíyè sí i torí wọn ò mọ̀ pé òkúta iyebíye làwọn ń gba ẹ̀gbẹ́ ẹ̀ kọjá.

2 Bíi dáyámọ́ǹdì yẹn làwọn àgbàlagbà tó jẹ́ olóòótọ́ rí. Ẹni iyì ni wọ́n, wọ́n sì ṣeyebíye gan-an. Kódà, Bíbélì fi ewú orí wọn wé adé ẹwà. (Ka Òwe 16:31; 20:29) Àmọ́, ó rọrùn láti gbójú fò wọ́n. Àwọn ọ̀dọ́ tó bá mọyì àwọn àgbàlagbà máa ń rí àǹfààní tó níye lórí ju owó lọ. Nínú àpilẹ̀kọ yìí, a máa dáhùn àwọn ìbéèrè mẹ́ta: Kí nìdí táwọn àgbàlagbà tó jẹ́ olóòótọ́ fi ṣeyebíye lójú Jèhófà? Ipa pàtàkì wo làwọn àgbàlagbà ń kó nínú ètò Jèhófà? Kí ló yẹ ká ṣe ká lè jàǹfààní látinú ìrírí wọn?

ÌDÍ TÍ ÀWỌN ÀGBÀLAGBÀ TÓ JẸ́ OLÓÒÓTỌ́ FI ṢEYEBÍYE LÓJÚ JÈHÓFÀ

Àwọn àgbàlagbà ṣeyebíye gan-an lójú Jèhófà àtàwọn èèyàn rẹ̀ (Wo ìpínrọ̀ 3)

3. Bó ṣe wà nínú Sáàmù 92:12-15, kí nìdí tí Jèhófà fi mọyì àwọn àgbàlagbà tó jẹ́ olóòótọ́?

3 Àwọn àgbàlagbà tó jẹ́ olóòótọ́ ṣeyebíye gan-an lójú Jèhófà. Ó mọ irú ẹni tí wọ́n jẹ́ gan-an, ó sì mọyì àwọn ànímọ́ rere tí wọ́n ní. Inú Jèhófà máa ń dùn tó bá ń rí i táwọn àgbàlagbà ń sọ fáwọn ọ̀dọ́ nípa àwọn ìrírí tí wọ́n ti ní àtàwọn ohun tí wọ́n ti kọ́ lẹ́nu iṣẹ́ ìsìn Jèhófà. (Jóòbù 12:12; Òwe 1:1-4) Jèhófà tún mọyì ẹ̀mí ìfaradà tí wọ́n ní. (Mál. 3:16) Ìgbàgbọ́ tí wọ́n ní nínú Jèhófà ò yingin láìka ọ̀pọ̀ ìṣòro tí wọ́n kojú nígbèésí ayé wọn sí. Ìrètí tí wọ́n ní ti túbọ̀ dá wọn lójú ju ti ìgbà tí wọ́n kọ́kọ́ kẹ́kọ̀ọ́ òtítọ́. Yàtọ̀ síyẹn, Jèhófà nífẹ̀ẹ́ wọn torí pé wọ́n ṣì ń kéde orúkọ rẹ̀ “kódà nígbà arúgbó wọn.”​—Ka Sáàmù 92:12-15.

4. Kí ni Jèhófà sọ tí ò ní jẹ́ káwọn àgbàlagbà rẹ̀wẹ̀sì?

4 Tó bá jẹ́ pé o ti ń dàgbà, o ò sì lè ṣe bíi ti tẹ́lẹ̀ mọ́, jẹ́ kó dá ẹ lójú pé Jèhófà rántí gbogbo iṣẹ́ rere tó o ti ṣe sẹ́yìn. (Héb. 6:10) Bí àpẹẹrẹ, inú Jèhófà ń dùn sí ẹ torí pé o ti fìtara ṣiṣẹ́ ìwàásù. Yàtọ̀ síyẹn, o ti fara da onírúurú ìṣòro títí kan àwọn èyí tó gba omijé lójú ẹ, síbẹ̀ o jẹ́ olóòótọ́ sí Jèhófà. Bákan náà, ọ̀pọ̀ ojúṣe pàtàkì lo ti bójú tó nínú ètò Ọlọ́run, o sì ti dá àwọn míì lẹ́kọ̀ọ́. Kò mọ síbẹ̀ o, o tún ń ṣe gbogbo ohun tó o lè ṣe láti máa fọwọ́ sowọ́ pọ̀ bí àwọn ìyípadà ṣe ń wáyé nínú ètò Ọlọ́run. Bákan náà, ò ń fún àwọn tó wà lẹ́nu iṣẹ́ ìsìn Jèhófà níṣìírí kí wọ́n lè máa báṣẹ́ wọn nìṣó. Jèhófà nífẹ̀ẹ́ rẹ, ó sì mọyì bó o ṣe jẹ́ adúróṣinṣin. Ó ṣèlérí pé òun ò “ní kọ àwọn ẹni ìdúróṣinṣin [òun] sílẹ̀”! (Sm. 37:28) Ó tún ṣèlérí pé: “Títí irun rẹ fi máa funfun, mi ò ní yéé gbé ọ.” (Àìsá. 46:4) Torí náà, má ṣe ronú pé o ò wúlò mọ́ nínú ètò Ọlọ́run torí pé o ti dàgbà. Jẹ́ kó dá ẹ lójú pé o wúlò, o sì ṣeyebíye gan-an!

ÀWỌN ÀGBÀLAGBÀ ṢEYEBÍYE GAN-AN NÍNÚ ÈTÒ ỌLỌ́RUN

5. Kí ló yẹ káwọn àgbàlagbà fi sọ́kàn?

5 Ọ̀pọ̀ nǹkan làwọn àgbàlagbà lè ṣe nínú ètò Ọlọ́run. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé wọn ò lè ṣe tó bí wọ́n ṣe ń ṣe tẹ́lẹ̀, síbẹ̀ ìrírí tí wọ́n ti ní ò ṣeé fowó rà. Torí náà, ọ̀pọ̀ nǹkan ni Jèhófà lè lo àwọn àgbàlagbà láti ṣe nínú ìjọ. Ní báyìí, ẹ jẹ́ ká wo àwọn àpẹẹrẹ kan nínú Bíbélì àti lóde òní ká lè rí bí Jèhófà ṣe ń lo àwọn àgbàlagbà.

6-7. Sọ àpẹẹrẹ àwọn àgbàlagbà nínú Bíbélì tí Jèhófà bù kún torí pé wọ́n fòótọ́ ọkàn ṣe iṣẹ́ ìsìn rẹ̀.

6 Ọ̀pọ̀ àpẹẹrẹ àwọn tó fòótọ́ ọkàn sin Jèhófà títí wọ́n fi dàgbà ló wà nínú Bíbélì. Bí àpẹẹrẹ, nǹkan bí ẹni ọgọ́rin (80) ọdún ni Mósè nígbà tí Jèhófà yàn án láti jẹ́ wòlíì àti aṣáájú àwọn ọmọ Ísírẹ́lì. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé Dáníẹ́lì ti lé lẹ́ni àádọ́rùn-ún (90) ọdún, síbẹ̀ Jèhófà ṣì ń lò ó gẹ́gẹ́ bíi wòlíì. Bákan náà, ó ṣeé ṣe kí àpọ́sítélì Jòhánù ti lé lẹ́ni àádọ́rùn-ún (90) ọdún nígbà tí Jèhófà mí sí i láti kọ ìwé Ìfihàn.

7 Ọ̀pọ̀ àwọn olóòótọ́ míì ni Bíbélì mẹ́nu kàn, a sì lè má rántí wọn torí pé a ò fi bẹ́ẹ̀ mọ̀ wọ́n. Síbẹ̀, Jèhófà rántí wọn, ó sì san wọ́n lẹ́san torí wọ́n jẹ́ adúróṣinṣin. Bí àpẹẹrẹ, Bíbélì ò sọ̀rọ̀ púpọ̀ nípa Síméónì bó tilẹ̀ jẹ́ pé ó pè é ní “olódodo àti ẹni tó ní ìfọkànsìn.” Àmọ́ Jèhófà kíyè sí ọkùnrin olóòótọ́ yìí, ó sì fún un láǹfààní láti rí Jésù nígbà tó wà ní kékeré, kó sì sọ tẹ́lẹ̀ nípa ohun tó máa ṣẹlẹ̀ sí Jésù àti ìyá rẹ̀. (Lúùkù 2:22, 25-35) Àpẹẹrẹ míì ni ti Ánà tó jẹ́ wòlíì obìnrin. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé opó ni, ó sì jẹ́ ẹni ọdún mẹ́rìnlélọ́gọ́rin (84), síbẹ̀ “kì í pa wíwá sí tẹ́ńpìlì jẹ.” Jèhófà mọyì bó ṣe máa ń “wá sí tẹ́ńpìlì déédéé,” ó sì fún òun náà láǹfààní láti rí Jésù nígbà tó wà ní kékeré. Èyí jẹ́ ká rí i pé Síméónì àti Ánà ṣeyebíye gan-an lójú Jèhófà.​—Lúùkù 2:36-38.

Arábìnrin Didur ṣì ń fòótọ́ ọkàn sin Jèhófà bó tiẹ̀ jẹ́ pé ó ti lé lẹ́ni ọgọ́rin (80) ọdún (Wo ìpínrọ̀ 8)

8-9. Àpẹẹrẹ wo làwọn opó ń fi lélẹ̀ fáwọn míì nínú ètò Ọlọ́run?

8 Lónìí, a ní ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn àgbàlagbà tó ń fòótọ́ ọkàn sin Jèhófà tí wọ́n sì jẹ́ àpẹẹrẹ tó dáa fáwọn ọ̀dọ́. Ẹ jẹ́ ká wo àpẹẹrẹ Arábìnrin Lois Didur. Ọmọ ọdún mọ́kànlélógún (21) péré ni nígbà tó di aṣáájú-ọ̀nà àkànṣe lórílẹ̀-èdè Kánádà. Nígbà tó yá, òun àti John ọkọ ẹ̀ jọ ṣiṣẹ́ alábòójútó àyíká fún ọ̀pọ̀ ọdún. Lẹ́yìn náà, wọ́n pè wọ́n sí Bẹ́tẹ́lì tó wà ní Kánádà, wọ́n sì lo ogún (20) ọdún níbẹ̀. Nígbà tí Lois wà lẹ́ni ọdún méjìdínlọ́gọ́ta (58), ètò Ọlọ́run ní kóun àti ọkọ ẹ̀ lọ sìn lórílẹ̀-èdè Ukraine. Kí ni wọ́n máa ṣe? Ṣé wọ́n ronú pé àwọn ti dàgbà jù láti lọ sìn lórílẹ̀-èdè míì? Rárá o, ṣe ni wọ́n tẹ́wọ́ gba iṣẹ́ náà, wọ́n sì ní kí ọkọ ẹ̀ di ọ̀kan lára Ìgbìmọ̀ Ẹ̀ka. Àmọ́ lẹ́yìn ọdún méje, ọkọ ẹ̀ kú. Ṣé Lois máa wá pa dà sílé àbí á máa bá iṣẹ́ ìsìn ẹ̀ lọ níbẹ̀? Lois pinnu láti dúró. Kódà ní báyìí tó ti pé ẹni ọdún mọ́kànlélọ́gọ́rin (81), ó ṣì ń fayọ̀ bá iṣẹ́ ìsìn ẹ̀ nìṣó ní Bẹ́tẹ́lì tó wà ní Ukraine, àwọn tó wà nínú ìdílé Bẹ́tẹ́lì sì fẹ́ràn ẹ̀ gan-an.

9 Ọ̀pọ̀ sábà máa ń gbójú fo àwọn opó bíi Lois, wọn kì í sì í rántí wọn bíi ti ìgbà tí àwọn ọkọ wọn ṣì wà láyé. Síbẹ̀, ti pé ẹnì kan jẹ́ opó kò túmọ̀ sí pé Jèhófà ò mọyì ẹ̀ mọ́. Jèhófà mọyì àwọn arábìnrin tí wọ́n ti ti ọkọ wọn lẹ́yìn fún ọ̀pọ̀ ọdún, tí wọn ò sì dẹwọ́ lẹ́nu iṣẹ́ ìsìn wọn lẹ́yìn tí ọkọ wọn kú. (1 Tím. 5:3) Àpẹẹrẹ àtàtà nirú àwọn arábìnrin bẹ́ẹ̀ jẹ́ fáwọn ọ̀dọ́.

10. Àpẹẹrẹ tó dáa wo ni Arákùnrin Tony fi lélẹ̀?

10 Ọ̀pọ̀ àwọn àgbàlagbà tó jẹ́ olóòótọ́ ló ń gbé nílé ìtọ́jú àwọn arúgbó tàbí kó jẹ́ pé wọn ò lè jáde nílé mọ́, síbẹ̀ wọ́n ṣeyebíye gan-an nínú ìjọ. Bí àpẹẹrẹ, ilé ìtọ́jú àwọn arúgbó ni Arákùnrin Tony ń gbé báyìí. Ọmọ ogún (20) ọdún ni nígbà tó ṣèrìbọmi ní Pennsylvania, lórílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà ní August 1942. Kò pẹ́ sígbà yẹn ni ìjọba sọ pé kó wọṣẹ́ ológun. Ó kọ̀, wọ́n sì rán an lọ sẹ́wọ̀n ọdún méjì àtààbọ̀. Nígbà tó yá, òun àti Hilda ìyàwó ẹ̀ tọ́ ọmọ méjì dàgbà nínú òtítọ́. Bọ́dún ṣe ń gorí ọdún, Arákùnrin Tony sìn gẹ́gẹ́ bí alábòójútó olùṣalága (tá a wá mọ̀ sí olùṣekòkáárí ìgbìmọ̀ àwọn alàgbà) ní ìjọ mẹ́ta, ó sì tún ṣe alábòójútó àpéjọ. Yàtọ̀ síyẹn, ó máa ń ṣètò ìpàdé àti ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì fáwọn ẹlẹ́wọ̀n. Ní báyìí tí Arákùnrin Tony ti pé ẹni ọdún méjìdínlọ́gọ́rùn-ún (98), ṣé ó wá ń tẹ̀ ẹ́ jẹ́jẹ́? Rárá o. Ó ń ṣe gbogbo ohun tó lè ṣe láti máa sin Jèhófà, ó sì ń fọwọ́ sowọ́ pọ̀ pẹ̀lú àwọn ará nínú ìjọ.

11. Kí la lè ṣe táá fi hàn pé a mọyì àwọn àgbàlagbà tó ń gbé nílé ìtọ́jú àwọn arúgbó tàbí tí wọn ò lè jáde nílé mọ́?

11 Kí la lè ṣe táá fi hàn pé a mọyì àwọn àgbàlagbà tó ń gbé nílé ìtọ́jú àwọn arúgbó tàbí tí wọn ò lè jáde nílé mọ́? Àwọn alàgbà lè ṣètò bí wọ́n á ṣe máa dara pọ̀ mọ́ ìpàdé àti bí wọ́n á ṣe máa kópa nínú iṣẹ́ ìwàásù. A tún lè fi hàn pé a nífẹ̀ẹ́ wọn tá a bá ń lọ bẹ̀ wọ́n wò tàbí tá à ń pè wọ́n látorí fídíò orí Íńtánẹ́ẹ̀tì ká lè rójú wọn. Ní pàtàkì, a fẹ́ fìfẹ́ hàn sáwọn àgbàlagbà tó ń gbé nílé ìtọ́jú àwọn arúgbó tó jìnnà gan-an síbi tí ìjọ wọn wà. Tá ò bá kíyè sára, a lè gbàgbé àwọn àgbàlagbà yìí. Ó lè má rọrùn fáwọn kan nínú wọn láti sọ àwọn nǹkan tó ti ṣẹlẹ̀ sí wọn sẹ́yìn. Àmọ́, a máa kẹ́kọ̀ọ́ gan-an lára wọn tá a bá fi sùúrù bi wọ́n láwọn ìbéèrè táá jẹ́ kí wọ́n sọ tọkàn wọn, tá a sì fara balẹ̀ tẹ́tí sí wọn bí wọ́n ṣe ń sọ àwọn ìrírí tó ń gbéni ró tí wọ́n ti ní nínú ètò Ọlọ́run.

12. Irú àwọn wo ló wà níjọ wa?

12 Ó lè yà wá lẹ́nu pé àwọn àgbàlagbà tó ti fòótọ́ ọkàn sin Jèhófà tó sì ní ọ̀pọ̀ ìrírí wà nínú ìjọ wa. Arábìnrin Harriette tó ń gbé ní New Jersey lórílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà ti sin Jèhófà fún ọ̀pọ̀ ọdún níjọ ẹ̀. Nígbà tó yá, ó kó lọ sọ́dọ̀ ọmọ ẹ̀. Àwọn ará tó wà níjọ tuntun tó dara pọ̀ mọ́ wáyè láti sún mọ́ ọn, wọ́n sì rí i pé ó ní ọ̀pọ̀ ìrírí tó ń fúnni lókun. Arábìnrin Harriette sọ ọ̀pọ̀ ìrírí nípa bí wọ́n ṣe ń ṣiṣẹ́ ìwàásù lásìkò tó kẹ́kọ̀ọ́ òtítọ́ ní nǹkan bí ọdún 1925. Ó sọ fún wọn pé nígbà yẹn lọ́hùn-ún, òun máa ń mú búrọ́ọ̀ṣì ìfọyín dání tóun bá ń lọ sẹ́nu iṣẹ́ ìwàásù torí pé ìgbàkigbà làwọn ọlọ́pàá lè mú òun, kí wọ́n sì ju òun sẹ́wọ̀n. Kódà, ẹ̀ẹ̀mejì ló lo ọ̀sẹ̀ kan lẹ́wọ̀n lọ́dún 1933. Ní gbogbo àkókò yẹn, ọkọ ẹ̀ tí kì í ṣe Ẹlẹ́rìí Jèhófà ló máa ń tọ́jú àwọn ọmọ wọn mẹ́tẹ̀ẹ̀ta. Kò sí àní-àní pé ó yẹ ká mọyì àwọn àgbàlagbà bíi Harriette tí wọ́n jẹ́ olóòótọ́.

13. Báwo lo ṣe lè fi hàn pé o mọyì ipa táwọn àgbàlagbà ń kó nínú ètò Jèhófà?

13 Ipa ribiribi làwọn arákùnrin àtàwọn arábìnrin tó jẹ́ àgbàlagbà ń kó nínú ètò Jèhófà. Wọ́n ti rí onírúurú ọ̀nà tí Jèhófà gbà bù kún ètò rẹ̀ àti bó ṣe ràn wọ́n lọ́wọ́ nígbèésí ayé wọn. Yàtọ̀ síyẹn, wọ́n ti kẹ́kọ̀ọ́ látinú àwọn àṣìṣe tí wọ́n ṣe. Torí náà, gbà pé àwọn àgbàlagbà jẹ́ “orísun ọgbọ́n,” kó o sì kẹ́kọ̀ọ́ lára wọn. (Òwe 18:4) Tó o bá sún mọ́ wọn, ó dájú pé ìgbàgbọ́ rẹ á túbọ̀ lágbára, wàá sì rí ọ̀pọ̀ nǹkan kọ́ lára wọn.

KẸ́KỌ̀Ọ́ LÁTINÚ ÀPẸẸRẸ ÀWỌN ÀGBÀLAGBÀ

Bí Èlíṣà ṣe kẹ́kọ̀ọ́ lára Èlíjà, àwọn ará lọ́kùnrin àti lóbìnrin náà lè kẹ́kọ̀ọ́ lára àwọn tó ti fòótọ́ ọkàn sin Jèhófà fún ọ̀pọ̀ ọdún (Wo ìpínrọ̀ 14-15)

14. Kí ni Diutarónómì 32:7 sọ pé káwọn ọ̀dọ́ ṣe?

14 Wáyè láti bá àwọn àgbàlagbà sọ̀rọ̀. (Ka Diutarónómì 32:7.) Lóòótọ́, ojú wọn lè ti di bàìbàì, ara wọn lè má ta pọ́ún pọ́ún bíi ti tẹ́lẹ̀, ọ̀rọ̀ sì lè má já geere lẹ́nu wọn mọ́. Síbẹ̀, ó máa ń wù wọ́n láti ṣe púpọ̀ lẹ́nu iṣẹ́ ìsìn wọn, wọ́n sì ti ṣe “orúkọ rere” fún ara wọn lọ́dọ̀ Jèhófà. (Oníw. 7:1) Máa rántí pé Jèhófà mọyì wọn. Torí náà, ó yẹ kíwọ náà máa ṣe bẹ́ẹ̀. Á dáa kó o ṣe bí Èlíṣà. Lọ́jọ́ tó lò kẹ́yìn pẹ̀lú Èlíjà, ẹ̀ẹ̀mẹta ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ ló sọ fún Èlíjà pé: “Mi ò ní fi ọ́ sílẹ̀.”​—2 Ọba 2:2, 4, 6.

15. Àwọn ìbéèrè wo lo lè bi àwọn àgbàlagbà?

15 O lè fi hàn pé o nífẹ̀ẹ́ àwọn àgbàlagbà dénú tó o bá ń béèrè àwọn ìbéèrè táá jẹ́ kí wọ́n sọ ohun tó wà lọ́kàn wọn. (Òwe 1:5; 20:5; 1 Tím. 5:1, 2) O lè bi wọ́n pé: “Nígbà tẹ́ ẹ wà lọ́dọ̀ọ́, kí ló mú kó dá yín lójú pé ẹ ti rí òtítọ́?” “Báwo làwọn ohun tó ti ṣẹlẹ̀ sí yín ṣe mú kẹ́ ẹ túbọ̀ sún mọ́ Jèhófà?” “Kí ló ń fún yín láyọ̀ lẹ́nu iṣẹ́ ìsìn Jèhófà?” (1 Tím. 6:6-8) Lẹ́yìn náà, fara balẹ̀ tẹ́tí sílẹ̀ bí wọ́n ṣe ń dáhùn àwọn ìbéèrè yẹn.

16. Àǹfààní wo làwọn àgbàlagbà àtàwọn ọ̀dọ́ máa rí tí wọ́n bá jọ ń sọ̀rọ̀?

16 Tí àgbàlagbà kan àti ọ̀dọ́ kan bá jọ ń sọ̀rọ̀, àwọn méjèèjì ló máa jàǹfààní. (Róòmù 1:12) Á túbọ̀ dá ọ̀dọ́ yẹn lójú pé Jèhófà máa ń bójú tó àwọn ìránṣẹ́ ẹ̀ tí wọ́n jẹ́ olóòótọ́. Àgbàlagbà náà á sì mọ̀ pé àwọn ará nífẹ̀ẹ́ òun, wọ́n sì mọyì òun. Inú àgbàlagbà náà á túbọ̀ máa dùn bó ṣe ń sọ àwọn ìbùkún tó ti rí gbà lọ́dọ̀ Jèhófà.

17. Kí nìdí tá a fi lè sọ pé àwọn àgbàlagbà tó jẹ́ olóòótọ́ máa ń lẹ́wà sí i lójú Jèhófà bọ́dún ṣe ń gorí ọdún?

17 Ẹwà ojú kì í tọ́jọ́, àmọ́ àwọn tó bá jẹ́ olóòótọ́ sí Jèhófà máa ń lẹ́wà sí i bọ́dún ṣe ń gorí ọdún. (1 Tẹs. 1:2, 3) Kí nìdí tá a fi sọ bẹ́ẹ̀? Ìdí ni pé bọ́dún ṣe ń gorí ọdún, wọ́n ń jẹ́ kí ẹ̀mí Ọlọ́run máa darí àwọn, wọ́n sì ń jẹ́ kó ran àwọn lọ́wọ́ láti ṣàtúnṣe tó yẹ. Bá a bá ṣe túbọ̀ ń mọ àwọn ará wa tó ti dàgbà, tá à ń bọlá fún wọn, tá a sì ń kẹ́kọ̀ọ́ lára wọn, bẹ́ẹ̀ làá túbọ̀ máa kà wọ́n sí ẹni ọ̀wọ́n bíi ti Jèhófà!

18. Kí la máa jíròrò nínú àpilẹ̀kọ tó kàn?

18 Kí ìjọ tó lè wà níṣọ̀kan, kì í ṣe àwọn ọ̀dọ́ nìkan ló yẹ kó mọyì àwọn àgbàlagbà, ó yẹ káwọn àgbàlagbà náà mọyì àwọn ọ̀dọ́. Nínú àpilẹ̀kọ tó kàn, a máa jíròrò báwọn àgbàlagbà náà ṣe lè fi hàn pé àwọn mọyì àwọn ọ̀dọ́ tó wà nínú ìjọ.

ORIN 144 Tẹjú Mọ́ Èrè Náà!

^ ìpínrọ̀ 5 Ẹni iyì làwọn àgbàlagbà tó wà láàárín wa, wọ́n sì ṣeyebíye gan-an. Nínú àpilẹ̀kọ yìí, a máa jíròrò bá a ṣe lè túbọ̀ mọyì wọn, àá sì rí bá a ṣe lè jàǹfààní látinú ìrírí àti ọgbọ́n tí wọ́n ní. Yàtọ̀ síyẹn, àpilẹ̀kọ yìí máa jẹ́ kó túbọ̀ dá àwọn àgbàlagbà yìí lójú pé ètò Jèhófà mọyì wọn gan-an, àá sì rí ipa ribiribi tí wọ́n ń kó nínú ìjọsìn Jèhófà.