Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

ÀPILẸ̀KỌ FÚN ÌKẸ́KỌ̀Ọ́ 36

Mọyì Àwọn Ọ̀dọ́ Tó Wà Nínú Ìjọ

Mọyì Àwọn Ọ̀dọ́ Tó Wà Nínú Ìjọ

“Ògo àwọn ọ̀dọ́kùnrin ni agbára wọn.”​—ÒWE 20:29.

ORIN 88 Mú Mi Mọ Àwọn Ọ̀nà Rẹ

OHUN TÁ A MÁA JÍRÒRÒ *

1. Kí la lè pinnu láti ṣe bá a ṣe ń dàgbà?

BÁRA ṣe ń dara àgbà, ó lè máa ṣe wá bíi pé a ò ní wúlò fún Jèhófà bíi ti tẹ́lẹ̀ mọ́. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé a lè má ní okun bíi ti tẹ́lẹ̀ mọ́, a lè pinnu láti fi ọgbọ́n àti ìrírí tá a ní ran àwọn ọ̀dọ́ lọ́wọ́ kí wọ́n lè tẹ̀ síwájú, kí wọ́n sì túbọ̀ wúlò nínú ètò Ọlọ́run. Alàgbà kan tó ti ń sìn fún ọ̀pọ̀ ọdún sọ pé: “Nígbà tí mo rí i pé mi ò lè ṣe bíi ti tẹ́lẹ̀ mọ́ torí ara tó ń dara àgbà, inú mi dùn pé a ní àwọn ọ̀dọ́ tó kúnjú ìwọ̀n táá máa báṣẹ́ lọ nínú ìjọ.”

2. Kí la máa jíròrò nínú àpilẹ̀kọ yìí?

2 Nínú àpilẹ̀kọ tó ṣáájú, a jíròrò àǹfààní táwọn ọ̀dọ́ máa rí tí wọ́n bá sún mọ́ àwọn àgbàlagbà. Nínú àpilẹ̀kọ yìí, a máa rí i pé táwọn àgbàlagbà bá lẹ́mìí ìrẹ̀lẹ̀, tí wọ́n mọ̀wọ̀n ara wọn, tí wọ́n moore tí wọ́n sì lawọ́, wọ́n á lè ṣiṣẹ́ pẹ̀lú àwọn ọ̀dọ́, ìyẹn á sì ṣe gbogbo ìjọ láǹfààní.

JẸ́ ONÍRẸ̀LẸ̀

3. Bó ṣe wà nínú Fílípì 2:3, 4, kí ló túmọ̀ sí tá a bá sọ pé ẹnì kan lẹ́mìí ìrẹ̀lẹ̀, báwo sì ni ẹ̀mí ìrẹ̀lẹ̀ ṣe lè ran Kristẹni kan lọ́wọ́?

3 Ó ṣe pàtàkì káwọn àgbàlagbà lẹ́mìí ìrẹ̀lẹ̀ kí wọ́n tó lè ran àwọn ọ̀dọ́ lọ́wọ́. Ẹni tó lẹ́mìí ìrẹ̀lẹ̀ máa ń gbà pé àwọn míì sàn ju òun lọ. (Ka Fílípì 2:3, 4.) Àwọn àgbàlagbà tó bá lẹ́mìí ìrẹ̀lẹ̀ máa ń gbà pé onírúurú ọ̀nà lèèyàn lè gbà bójú tó iṣẹ́ kan. Torí náà, wọn kì í rin kinkin mọ́ ọ̀nà tí wọ́n ń gbà ṣe nǹkan tẹ́lẹ̀. (Oníw. 7:10) Òótọ́ ni pé àwọn àgbàlagbà ní ọ̀pọ̀ ìrírí tí wọ́n lè fi ran àwọn ọ̀dọ́ lọ́wọ́. Síbẹ̀, wọ́n gbọ́dọ̀ fi sọ́kàn pé “ìrísí ayé yìí ń yí pa dà,” ó sì ṣe pàtàkì pé káwọn náà ṣe àwọn àtúnṣe kan bí nǹkan ṣe ń yí pa dà.​—1 Kọ́r. 7:31.

Àwọn àgbàlagbà máa ń fi ìrírí wọn gbé àwọn míì ró (Wo ìpínrọ̀ 4-5) *

4. Ọ̀nà wo làwọn alábòójútó àyíká gbà fìwà jọ àwọn ọmọ Léfì?

4 Àwọn àgbàlagbà tó lẹ́mìí ìrẹ̀lẹ̀ mọ̀ pé àwọn ò lè ṣe tó báwọn ṣe máa ń ṣe nígbà táwọn wà lọ́dọ̀ọ́. Ẹ jẹ́ ká wo àpẹẹrẹ àwọn alábòójútó àyíká. Tí wọ́n bá ti pé ẹni àádọ́rin (70) ọdún, wọ́n máa fiṣẹ́ alábòójútó àyíká sílẹ̀, wọ́n á sì máa bójú tó iṣẹ́ míì. Ká sòótọ́, ìyẹn kì í rọrùn rárá. Ìdí ni pé ó wù wọ́n láti máa lo ara wọn fáwọn ará. Yàtọ̀ síyẹn, wọ́n mọyì iṣẹ́ ìsìn wọn, ó sì wù wọ́n kí wọ́n máa bá iṣẹ́ náà lọ. Àmọ́ wọ́n mọ̀ pé àwọn ọ̀dọ́ tó lókun máa lè ṣiṣẹ́ náà dáadáa. Ṣe ni wọ́n fìwà jọ àwọn ọmọ Léfì ní Ísírẹ́lì àtijọ́ tí wọ́n máa ń fiṣẹ́ ìsìn wọn ní àgọ́ ìjọsìn sílẹ̀ tí wọ́n bá ti pé ẹni àádọ́ta (50) ọdún. Kì í ṣe iṣẹ́ ìsìn kan pàtó ló ń fún àwọn ọmọ Léfì yìí láyọ̀. Àmọ́ wọ́n máa ń ṣe gbogbo ohun tí wọ́n lè ṣe lẹ́nu iṣẹ́ èyíkéyìí tí wọ́n bá yàn fún wọn, wọ́n sì máa ń ran àwọn ọ̀dọ́ lọ́wọ́. (Nọ́ń. 8:25, 26) Bákan náà lónìí, bó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn alábòójútó àyíká yìí kì í bẹ àwọn ìjọ wò mọ́, ìbùkún ńlá ni wọ́n jẹ́ fáwọn ìjọ tí wọ́n yàn wọ́n sí báyìí.

5. Kí lo rí kọ́ nínú àpẹẹrẹ Dan àti Katie?

5 Ẹ jẹ́ ká wo àpẹẹrẹ Dan tó ṣiṣẹ́ alábòójútó àyíká fún ọdún mẹ́tàlélógún (23). Nígbà tí Dan pé ẹni àádọ́rin (70) ọdún, ètò Ọlọ́run sọ òun àti Katie ìyàwó ẹ̀ di aṣáájú-ọ̀nà àkànṣe. Kí ni wọ́n wá ṣe? Dan sọ pé òun ti jẹ́ kọ́wọ́ òun dí ju ti tẹ́lẹ̀ lọ. Bí àpẹẹrẹ, ó máa ń bójú tó iṣẹ́ tí wọ́n bá yàn fún un nínú ìjọ, ó máa ń ran àwọn arákùnrin lọ́wọ́ kí wọ́n lè kúnjú ìwọ̀n láti di ìránṣẹ́ iṣẹ́ òjíṣẹ́, ó sì máa ń dá àwọn míì lẹ́kọ̀ọ́ kí wọ́n lè mọ bí wọ́n ṣe ń wàásù níbi térò pọ̀ sí àti lọ́gbà ẹ̀wọ̀n. Ẹ̀yin àgbàlagbà, yálà ẹ wà lẹ́nu iṣẹ́ ìsìn alákòókò kíkún tàbí bẹ́ẹ̀ kọ́, ọ̀pọ̀ nǹkan lẹ lè ṣe láti ran àwọn míì lọ́wọ́. Báwo lẹ ṣe lè ṣe bẹ́ẹ̀? Ẹ ṣe àwọn àyípadà tó yẹ, ẹ ní àfojúsùn kí ẹ sì gbájú mọ́ àwọn nǹkan tágbára yín gbé dípò kẹ́ ẹ máa ronú nípa ohun tẹ́ ò lè ṣe mọ́.

MỌ̀WỌ̀N ARA Ẹ

6. Kí nìdí tó fi bọ́gbọ́n mu pé kéèyàn mọ̀wọ̀n ara ẹ̀? Ṣàpèjúwe.

6 Ẹni tó mọ̀wọ̀n ara ẹ̀ máa ń mọ ibi tágbára òun mọ. (Òwe 11:2) Ẹni tó bá mọ̀wọ̀n ara ẹ̀ máa ń mọ̀ pé bóun ṣe ń dàgbà, ohun tóun lè ṣe máa dín kù. Ìyẹn á mú kó máa láyọ̀, kó má sì dẹwọ́ lẹ́nu iṣẹ́ ìsìn Jèhófà. A lè fi ẹni tó mọ̀wọ̀n ara ẹ̀ wé ẹni tó ń rìn lórí ilẹ̀ tó ń yọ̀. Irú ẹni bẹ́ẹ̀ máa ní láti rọra máa rìn kó má bàa yọ̀ ṣubú. Òótọ́ ni pé kò ní yára rìn mọ́ bíi ti tẹ́lẹ̀. Àmọ́, kò ní dúró sójú kan. Lọ́nà kan náà, ẹni tó bá mọ̀wọ̀n ara ẹ̀ máa mọ̀gbà tó yẹ kóun rọra máa rìn kóun lè máa báṣẹ́ lọ lẹ́nu iṣẹ́ ìsìn Jèhófà.​—Fílí. 4:5.

7. Báwo ni Básíláì ṣe fi hàn pé òun mọ̀wọ̀n ara òun?

7 Ẹ jẹ́ ká wo àpẹẹrẹ Básíláì tó jẹ́ ẹni ọgọ́rin (80) ọdún nígbà tí Ọba Dáfídì sọ pé kó wá di ìjòyè láàfin òun. Básíláì kọ̀ torí pé ó mọ̀wọ̀n ara ẹ̀. Ó mọ̀ pé ìwọ̀nba lòun á lè ṣe nítorí ọjọ́ orí òun. Básíláì wá dábàá Kímúhámù tó jẹ́ ọ̀dọ́ pé kó tẹ̀ lé ọba dípò òun. (2 Sám. 19:35-37) Bíi ti Básíláì, inú àwọn arákùnrin tó jẹ́ àgbàlagbà máa ń dùn láti jẹ́ kí àwọn ọ̀dọ́kùnrin máa bójú tó àwọn àǹfààní iṣẹ́ ìsìn kan.

Ọba Dáfídì fara mọ́ ìpinnu tí Jèhófà ṣe pé ọmọ rẹ̀ ló máa kọ́ tẹ́ńpìlì fún òun (Wo ìpínrọ̀ 8)

8. Báwo ni Ọba Dáfídì ṣe mọ̀wọ̀n ara ẹ̀ nígbà tó pinnu pé òun fẹ́ kọ́ tẹ́ńpìlì?

8 Àpẹẹrẹ rere ni Ọba Dáfídì jẹ́ tó bá di pé kéèyàn mọ̀wọ̀n ara ẹ̀. Ó wù ú gan-an láti kọ́ ilé fún Jèhófà, àmọ́ nígbà tí Jèhófà sọ fún un pé Sólómọ́nì ọmọ rẹ̀ ló máa kọ́ ilé náà, Dáfídì ò jiyàn, ó sì fi gbogbo ọkàn ẹ̀ ti iṣẹ́ náà lẹ́yìn. (1 Kíró. 17:4; 22:5) Dáfídì ò ronú pé òun ló yẹ kóun ṣiṣẹ́ náà torí pé Sólómọ́nì “jẹ́ ọ̀dọ́, kò [sì] ní ìrírí.” (1 Kíró. 29:1) Yàtọ̀ síyẹn, ó tún gbà pé ìbùkún Jèhófà ló máa jẹ́ kí iṣẹ́ náà yọrí sí rere, kì í ṣe ọjọ́ orí tàbí ìrírí àwọn tó ń múpò iwájú lẹ́nu iṣẹ́ náà. Bíi ti Dáfídì, àwọn àgbàlagbà lónìí máa ń ṣe gbogbo ohun tí wọ́n lè ṣe lẹ́nu iṣẹ́ ìsìn Jèhófà bó tilẹ̀ jẹ́ pé iṣẹ́ tí wọ́n ń bójú tó lè yí pa dà, ó sì dá wọn lójú pé Jèhófà máa bù kún àwọn ọ̀dọ́ tó ń ṣe iṣẹ́ táwọn ń ṣe tẹ́lẹ̀.

9. Báwo ni Arákùnrin Shigeo tó jẹ́ ara Ìgbìmọ̀ Ẹ̀ka kan ṣe fi hàn pé òun mọ̀wọ̀n ara òun?

9 A ní àpẹẹrẹ àwọn ará wa lóde òní tó fi hàn pé àwọn mọ̀wọ̀n ara àwọn. Àpẹẹrẹ kan ni ti Arákùnrin Shigeo. Ẹni ọgbọ̀n (30) ọdún ni lọ́dún 1976 nígbà tó di ara Ìgbìmọ̀ Ẹ̀ka. Lọ́dún 2004, ó di olùṣekòkáárí Ìgbìmọ̀ Ẹ̀ka. Nígbà tó yá, ó rí i pé òun ò lókun mọ́ bíi ti tẹ́lẹ̀ àti pé ó máa ń pẹ́ kóun tó parí iṣẹ́ òun. Ó wá fọ̀rọ̀ náà sádùúrà, ó sì ronú lórí àǹfààní tó wà níbẹ̀ tóun bá fiṣẹ́ náà sílẹ̀ fún arákùnrin tó jẹ́ ọ̀dọ́. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé Arákùnrin Shigeo kì í ṣe olùṣekòkáárí Ìgbìmọ̀ Ẹ̀ka mọ́, ó ṣì ń fọwọ́ sowọ́ pọ̀ pẹ̀lú àwọn yòókù tí wọ́n jọ wà nínú Ìgbìmọ̀ Ẹ̀ka. Bá a ṣe rí i nínú àpẹẹrẹ Básíláì, Ọba Dáfídì àti Shigeo, ẹni tó bá lẹ́mìí ìrẹ̀lẹ̀ tó sì mọ̀wọ̀n ara ẹ̀ máa ń pọkàn pọ̀ sórí ohun táwọn ọ̀dọ́ lè ṣe dípò kó máa ronú nípa ohun tí wọn ò mọ̀. Bákan náà, kò ní máa wò wọ́n bíi pé wọ́n fẹ́ gbaṣẹ́ mọ́ òun lọ́wọ́, àmọ́ á kà wọ́n sí alábàáṣiṣẹ́ òun.​—Òwe 20:29.

MÁA MOORE

10. Ojú wo làwọn àgbàlagbà fi ń wo àwọn ọ̀dọ́ tó wà nínú ìjọ?

10 Àwọn àgbàlagbà gbà pé ẹ̀bùn látọ̀dọ̀ Jèhófà làwọn ọ̀dọ́ jẹ́, wọ́n sì mọyì ohun táwọn ọ̀dọ́ ń ṣe. Bí okun àwọn àgbàlagbà ṣe ń dín kù, inú wọn máa ń dùn pé àwọn ọ̀dọ́ tó lókun, tó sì múra tán láti tẹ́wọ́ gba àǹfààní iṣẹ́ ìsìn èyíkéyìí wà nínú ìjọ.

11. Báwo ni Rúùtù 4:13-16 ṣe jẹ́ ká mọ ìbùkún táwọn àgbàlagbà máa rí tí wọ́n bá jẹ́ káwọn tí ò tó wọn lọ́jọ́ orí ran àwọn lọ́wọ́?

11 Bíbélì sọ pé Náómì jẹ́ àpẹẹrẹ rere fáwọn àgbàlagbà. Ó gbà kí ẹni tí ò tó òun lọ́jọ́ orí ran òun lọ́wọ́, ó sì mọyì ìrànlọ́wọ́ náà. Lẹ́yìn tí àwọn ọmọ Náómì kú, Náómì rọ Rúùtù tó jẹ́ ìyàwó ọ̀kan nínú àwọn ọmọ ẹ̀ pé kó pa dà sọ́dọ̀ àwọn mọ̀lẹ́bí ẹ̀. Àmọ́ Rúùtù kọ̀, ó ní òun máa tẹ̀ lé Náómì pa dà sí Bẹ́tílẹ́hẹ́mù, Náómì sì gbà kó ran òun lọ́wọ́. (Rúùtù 1:7, 8, 18) Ohun tí wọ́n ṣe yẹn ṣe àwọn méjèèjì láǹfààní! (Ka Rúùtù 4:13-16.) Àwọn àgbàlagbà tó bá lẹ́mìí ìrẹ̀lẹ̀ máa tẹ̀ lé àpẹẹrẹ Náómì.

12. Kí ni Pọ́ọ̀lù ṣe tó fi hàn pé ó moore ohun táwọn ará ṣe fún un?

12 Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù mọyì ìrànlọ́wọ́ táwọn ará ṣe fún un. Bí àpẹẹrẹ, ó dúpẹ́ lọ́wọ́ àwọn Kristẹni tó wà ní Fílípì torí àwọn nǹkan tí wọ́n fi ránṣẹ́ sí i. (Fílí. 4:16) Yàtọ̀ síyẹn, Pọ́ọ̀lù tún mọyì bí Tímótì ṣe ràn án lọ́wọ́. (Fílí. 2:19-22) Bákan náà, Pọ́ọ̀lù dúpẹ́ lọ́wọ́ Ọlọ́run nítorí àwọn ará tó wá fún un níṣìírí nígbà tí wọ́n ń mú un lọ sí Róòmù gẹ́gẹ́ bí ẹlẹ́wọ̀n. (Ìṣe 28:15) Pọ́ọ̀lù lókun, ó sì rìnrìn àjò ọ̀pọ̀ máìlì kó lè wàásù, kó sì fún àwọn ìjọ lókun. Síbẹ̀, ìrẹ̀lẹ̀ mú kó gbà káwọn míì ran òun lọ́wọ́.

13. Báwo làwọn àgbàlagbà ṣe lè fi hàn pé àwọn mọyì àwọn ọ̀dọ́?

13 Ẹ̀yin àgbàlagbà, onírúurú ọ̀nà lẹ lè gbà fi hàn pé ẹ mọyì àwọn ọ̀dọ́ tó wà níjọ yín. Bí àpẹẹrẹ, tí wọ́n bá fẹ́ bá yín ṣe àwọn nǹkan kan, bóyá wọ́n fẹ́ fi ọkọ̀ gbé yín, wọ́n fẹ́ bá yín ra ọjà tàbí ṣe àwọn nǹkan míì, ẹ jẹ́ kí wọ́n ṣe bẹ́ẹ̀, kẹ́ ẹ sì dúpẹ́ lọ́wọ́ wọn. Fi sọ́kàn pé torí pé Jèhófà nífẹ̀ẹ́ ẹ ló ṣe ń lò wọ́n láti ràn ẹ́ lọ́wọ́, ìyẹn sì lè mú kíwọ àtàwọn ọ̀dọ́ náà di ọ̀rẹ́ tímọ́tímọ́. Bákan náà, máa sapá nígbà gbogbo láti ran àwọn ọ̀rẹ́ rẹ yìí lọ́wọ́ kí wọ́n lè túbọ̀ sún mọ́ Jèhófà, kó o sì jẹ́ kí wọ́n mọ̀ pé inú ẹ máa ń dùn tó o bá rí àwọn ọ̀dọ́ tó ń sapá láti máa ṣe púpọ̀ sí i nínú ìjọ. Yàtọ̀ síyẹn, máa lo àkókò pẹ̀lú wọn, kó o sì sọ àwọn ìrírí tó o ti ní nígbèésí ayé fún wọn. Tó o bá ṣe bẹ́ẹ̀, ìyẹn á fi hàn pé ò ń “dúpẹ́” lọ́wọ́ Jèhófà, o sì mọyì àwọn ọ̀dọ́ tó ti fà sínú ètò rẹ̀.​—Kól. 3:15; Jòh. 6:44; 1 Tẹs. 5:18.

JẸ́ Ọ̀LÀWỌ́

14. Kí ni Ọba Dáfídì ṣe tó fi hàn pé ó lawọ́?

14 Ànímọ́ pàtàkì míì tí Ọba Dáfídì ní ni pé ó lawọ́, ó sì yẹ káwọn àgbàlagbà náà máa ṣe bẹ́ẹ̀. Dáfídì fi ọ̀pọ̀lọpọ̀ owó àtàwọn nǹkan míì tó ní ṣètìlẹyìn fún iṣẹ́ kíkọ́ tẹ́ńpìlì náà. (1 Kíró. 22:11-16; 29:3, 4) Ó ṣe bẹ́ẹ̀ láìka pé orúkọ Sólómọ́nì ni wọ́n á fi pe tẹ́ńpìlì náà. Tá ò bá tiẹ̀ lókun láti lọ́wọ́ nínú iṣẹ́ ìkọ́lé ètò Ọlọ́run mọ́, a ṣì lè lo owó wa àtàwọn nǹkan míì tá a ní láti ti iṣẹ́ náà lẹ́yìn débi tágbára wa bá gbé e dé. Bákan náà, a lè fi àwọn ìrírí tá a ti ní látọdún yìí wá fún àwọn ọ̀dọ́ lókun kí wọ́n lè lọ́wọ́ nínú iṣẹ́ Jèhófà.

15. Ẹ̀bùn tó ṣeyebíye wo ni àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù fún Tímótì?

15 Ẹ jẹ́ ká wo àpẹẹrẹ àtàtà tí àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù fi lélẹ̀ tó bá dọ̀rọ̀ pé kéèyàn jẹ́ ọ̀làwọ́. Pọ́ọ̀lù ní kí òun àti Tímótì jọ ṣiṣẹ́ míṣọ́nnárì pa pọ̀, ó sì fi sùúrù kọ́ ọ̀dọ́kùnrin náà ní gbogbo ohun tó mọ̀ nípa iṣẹ́ ìwàásù àti kíkọ́ni. (Ìṣe 16:1-3) Ìdálẹ́kọ̀ọ́ yìí ran Tímótì lọ́wọ́ kó lè já fáfá lẹ́nu iṣẹ́ ìwàásù. (1 Kọ́r. 4:17) Lẹ́yìn náà, Tímótì lo àwọn ohun tí Pọ́ọ̀lù kọ́ ọ láti dá àwọn míì lẹ́kọ̀ọ́ káwọn náà lè já fáfá lẹ́nu iṣẹ́ ìwàásù àti kíkọ́ni.

16. Kí nìdí tí Shigeo fi dá àwọn míì lẹ́kọ̀ọ́?

16 Àwọn àgbàlagbà kì í bẹ̀rù pé àwọn ò ní wúlò mọ́ nínú ìjọ táwọn bá dá àwọn ọ̀dọ́ lẹ́kọ̀ọ́ láti máa bójú tó iṣẹ́ tí wọ́n ń ṣe. Ẹ jẹ́ ká wo àpẹẹrẹ Arákùnrin Shigeo tá a sọ̀rọ̀ ẹ̀ lẹ́ẹ̀kan. Bọ́dún ṣe ń gorí ọdún, ó dá àwọn arákùnrin tó kéré sí i lọ́jọ́ orí nínú Ìgbìmọ̀ Ẹ̀ka lẹ́kọ̀ọ́. Kí nìdí tó fi ṣe bẹ́ẹ̀? Ó ṣe bẹ́ẹ̀ kí iṣẹ́ Jèhófà lè máa tẹ̀ síwájú lórílẹ̀-èdè tó ti ń sìn. Torí náà, nígbà tí ọjọ́ ogbó ò jẹ́ kí Arákùnrin Shigeo lè máa ṣe olùṣekòkáárí Ìgbìmọ̀ Ẹ̀ka mọ́, arákùnrin míì tó kúnjú ìwọ̀n tó sì ti gba ìdálẹ́kọ̀ọ́ wà ní sẹpẹ́ láti máa bá iṣẹ́ náà lọ. Ní báyìí, Arákùnrin Shigeo ti lo ohun tó ju ọdún márùndínláàádọ́ta (45) lọ nínú Ìgbìmọ̀ Ẹ̀ka, ó sì ń lo ìrírí ẹ̀ láti fún àwọn ọ̀dọ́ lókun. Ẹ ò rí i pé ìbùkún ńlá ni irú àwọn arákùnrin bẹ́ẹ̀ jẹ́ nínú ètò Ọlọ́run!

17. Bó ṣe wà nínú Lúùkù 6:38, kí làwọn àgbàlagbà lè fún àwọn míì?

17 Àpẹẹrẹ ẹ̀yin arákùnrin àti arábìnrin wa tẹ́ ẹ ti dàgbà jẹ́ kó ṣe kedere pé kò sí ohun tó dáa tó kéèyàn fi ayé ẹ̀ sin Jèhófà, kó sì jẹ́ olóòótọ́. Bí ẹ ṣe ń gbé ìgbésí ayé yín ti jẹ́ ká rí i pé téèyàn bá mọ àwọn ìlànà Bíbélì, tó sì ń fi wọ́n sílò, ó máa ṣe é láǹfààní. Ẹ ti rí bí ètò Ọlọ́run ṣe ń ṣe nǹkan láwọn ìgbà kan, síbẹ̀ ẹ múra tán láti ṣàtúnṣe bí nǹkan ṣe ń yí pa dà. Ọ̀pọ̀ nǹkan ni ẹ̀yin àgbàlagbà tẹ́ ẹ ṣẹ̀ṣẹ̀ ṣèrìbọmi náà lè kọ́ àwọn míì. Bí àpẹẹrẹ, ẹ lè jẹ́ kí wọ́n mọ bí inú yín ṣe dùn tó láti wá mọ Jèhófà ní ọjọ́ ogbó yín. Inú àwọn ọ̀dọ́ máa dùn láti gbọ́ àwọn ìrírí yín àtàwọn ẹ̀kọ́ tẹ́ ẹ ti kọ́ nígbèésí ayé yín. Tẹ́ ẹ bá “sọ ọ́ di àṣà láti máa fúnni” láwọn ìrírí tẹ́ ẹ ti ní, ó dájú pé Jèhófà máa bù kún yín gan-an.​—Ka Lúùkù 6:38.

18. Báwo ni àwọn ọ̀dọ́ àti àwọn àgbàlagbà ṣe lè ran ara wọn lọ́wọ́?

18 Tí ẹ̀yin àgbàlagbà bá ń sún mọ́ àwọn ọ̀dọ́, ẹ̀ẹ́ lè ran ara yín lọ́wọ́. (Róòmù 1:12) Kálukú yín ló ní ohun kan tí ẹnì kejì ò ní. Àwọn àgbàlagbà ní ọgbọ́n àti ìrírí, àwọn ọ̀dọ́ sì ní okun àti agbára. Táwọn àgbàlagbà àtàwọn ọ̀dọ́ bá ń fọwọ́ sowọ́ pọ̀, tí wọ́n sì ṣe ara wọn lọ́kan, ó dájú pé wọ́n á mú ìyìn àti ògo bá Jèhófà Baba wa ọ̀run, wọ́n á sì ṣe gbogbo ìjọ láǹfààní.

ORIN 90 Ẹ Máa Gba Ara Yín Níyànjú

^ ìpínrọ̀ 5 Inú wa dùn pé a ní ọ̀pọ̀ àwọn ọ̀dọ́kùnrin àtàwọn ọ̀dọ́bìnrin tí wọ́n ń ṣe gbogbo ohun tí wọ́n lè ṣe lẹ́nu iṣẹ́ ìsìn Jèhófà. Láìka ibi tí wọ́n dàgbà sí àti àṣà ìbílẹ̀ wọn, àwọn àgbàlagbà lè ran àwọn ọ̀dọ́ lọ́wọ́ kí wọ́n lè lo gbogbo okun wọn lẹ́nu iṣẹ́ ìsìn Jèhófà.

^ ìpínrọ̀ 55 ÀWÒRÁN: Nígbà tí alábòójútó àyíká kan pé ẹni àádọ́rin (70) ọdún, ètò Ọlọ́run fún òun àtìyàwó ẹ̀ ní iṣẹ́ míì. Wọ́n wá ń fi ìrírí wọn dá àwọn míì lẹ́kọ̀ọ́ nínú ìjọ tí wọ́n wà báyìí.