Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

ÀPILẸ̀KỌ FÚN ÌKẸ́KỌ̀Ọ́ 37

“Èmi Yóò Mi Gbogbo Orílẹ̀-Èdè Jìgìjìgì”

“Èmi Yóò Mi Gbogbo Orílẹ̀-Èdè Jìgìjìgì”

“Èmi yóò mi gbogbo orílẹ̀-èdè jìgìjìgì, àwọn ohun iyebíye nínú gbogbo orílẹ̀-èdè yóò sì wọlé wá.”​—HÁG. 2:7.

ORIN 24 Ẹ Wá sí Òkè Jèhófà

OHUN TÁ A MÁA JÍRÒRÒ *

1-2. Kí ni Hágáì sọ tẹ́lẹ̀ pé ó máa ṣẹlẹ̀ lásìkò wa?

LỌ́DÚN 2015, ìmìtìtì ilẹ̀ kan ṣẹlẹ̀ lórílẹ̀-èdè Nepal. Àwọn kan tó là á já sọ pé: “Láàárín ìṣẹ́jú mélòó kan, ọ̀pọ̀ ilé àti ṣọ́ọ̀bù ló wó lulẹ̀ bẹẹrẹbẹ.” Ẹlòmíì sọ pé: “Ṣe làyà gbogbo èèyàn ń já . . . Ọ̀pọ̀ èèyàn sọ pé bí ìṣẹ́jú méjì péré ni gbogbo ẹ̀ fi ṣẹlẹ̀, àmọ́ lójú mi ṣe ló dà bí odindi ọjọ́ kan.” Tírú nǹkan bẹ́ẹ̀ bá ṣẹlẹ̀ lágbègbè yín, ó dájú pé o ò ní gbàgbé ẹ̀ láé.

2 Àmọ́ lónìí, ìmìtìtì kan ń ṣẹlẹ̀ tó yàtọ̀ síyẹn, kì í sì í ṣe ìlú kan tàbí orílẹ̀-èdè kan ló ti ń ṣẹlẹ̀. Kàkà bẹ́ẹ̀ kárí ayé ni, ó sì ti ń ṣẹlẹ̀ bẹ́ẹ̀ fún ọ̀pọ̀ ọdún. Wòlíì Hágáì ti sọ tẹ́lẹ̀ nípa ìṣẹ̀lẹ̀ yìí. Ó ní: “Ohun tí Jèhófà Ọlọ́run àwọn ọmọ ogun sọ nìyí, ‘Lẹ́ẹ̀kan sí i, màá mi ọ̀run, ayé, òkun àti ilẹ̀ gbígbẹ jìgìjìgì; kò ní pẹ́ mọ́.’”​—Hág. 2:6.

3. Ìyàtọ̀ wo ló wà láàárín ìmìtìtì tí Hágáì sọ tẹ́lẹ̀ àti ìmìtìtì ilẹ̀ tó ń wáyé lónìí?

3 Ìmìtìtì tí Hágáì sọ tẹ́lẹ̀ máa ń mú káwọn nǹkan rere ṣẹlẹ̀. Ó sì yàtọ̀ pátápátá sí ìmìtìtì ilẹ̀ tó ń wáyé lónìí tó jẹ́ pé àjálù nìkan ló máa ń fà. Jèhófà fúnra ẹ̀ sọ fún wa pé: “Èmi yóò mi gbogbo orílẹ̀-èdè jìgìjìgì, àwọn ohun iyebíye nínú gbogbo orílẹ̀-èdè yóò sì wọlé wá; èmi yóò sì fi ògo kún ilé yìí.” (Hág. 2:7) Kí ni àsọtẹ́lẹ̀ yìí túmọ̀ sí fún àwọn tó gbé nígbà ayé Hágáì, kí ló sì túmọ̀ sí fún àwa náà lónìí? Àá dáhùn àwọn ìbéèrè yìí, àá sì tún rí bá a ṣe lè kópa nínú bí Jèhófà ṣe ń mi àwọn orílẹ̀-èdè jìgìjìgì lónìí.

ÌRÒYÌN AYỌ̀ NÍGBÀ AYÉ HÁGÁÌ

4. Kí nìdí tí Jèhófà fi rán wòlíì Hágáì sí àwọn èèyàn Rẹ̀?

4 Jèhófà gbé iṣẹ́ pàtàkì kan fún wòlíì Hágáì. Ẹ jẹ́ ká kọ́kọ́ wo bí nǹkan ṣe rí nígbà yẹn. Ó ṣeé ṣe kí Hágáì wà lára àwọn Júù tó pa dà sí Jerúsálẹ́mù láti Bábílónì lọ́dún 537 Ṣ.S.K. Àkókò díẹ̀ lẹ́yìn tí wọ́n débẹ̀, wọ́n fi ìpìlẹ̀ ilé Jèhófà lélẹ̀. (Ẹ́sírà 3:8, 10) Kò pẹ́ lẹ́yìn ìyẹn ni wọ́n rẹ̀wẹ̀sì, tí wọ́n sì dáwọ́ iṣẹ́ náà dúró torí pé àwọn èèyàn ń ta kò wọ́n. (Ẹ́sírà 4:4; Hág. 1:1, 2) Torí náà lọ́dún 520 Ṣ.S.K., Jèhófà rán Hágáì sí wọn kó lè fún wọn níṣìírí láti parí iṣẹ́ náà. *​—Ẹ́sírà 6:14, 15.

5. Kí ló mú kí ọ̀rọ̀ Hágáì fún àwọn èèyàn Ọlọ́run níṣìírí?

5 Jèhófà rán Hágáì sáwọn èèyàn rẹ̀ kí wọ́n lè túbọ̀ nígbàgbọ́. Wòlíì náà sọ fáwọn Júù tó rẹ̀wẹ̀sì pé: “‘Kí gbogbo ẹ̀yin èèyàn ilẹ̀ náà pẹ̀lú jẹ́ onígboyà, kí ẹ sì ṣiṣẹ́’ ni Jèhófà wí. ‘Torí mo wà pẹ̀lú yín,’ ni Jèhófà Ọlọ́run àwọn ọmọ ogun wí.” (Hág. 2:4) Ó dájú pé gbólóhùn náà “Jèhófà Ọlọ́run àwọn ọmọ ogun” máa fún àwọn èèyàn náà lókun. Jèhófà ní ọ̀pọ̀ àwọn áńgẹ́lì alágbára tí wọ́n jẹ́ ọmọ ogun, torí náà kò sídìí fáwọn Júù láti bẹ̀rù. Tí wọ́n bá gbẹ́kẹ̀ lé e, wọ́n á ṣàṣeyọrí.

6. Kí ni ìmìtìtì tí Hágáì sọ tẹ́lẹ̀ máa yọrí sí?

6 Jèhófà mí sí Hágáì láti sọ fún àwọn èèyàn náà pé òun máa mi àwọn orílẹ̀-èdè jìgìjìgì lọ́nà ìṣàpẹẹrẹ. Àsọtẹ́lẹ̀ yẹn fún àwọn Júù tó ti rẹ̀wẹ̀sì lókun, ó sì jẹ́ kí wọ́n mọ̀ pé Jèhófà máa mi Páṣíà tó jẹ́ agbára ayé nígbà yẹn jìgìjìgì. Kí nìyẹn máa yọrí sí? Lákọ̀ọ́kọ́, àwọn èèyàn Ọlọ́run máa parí kíkọ́ tẹ́ńpìlì náà. Lẹ́yìn ìyẹn, àwọn tí kì í ṣe Júù máa dara pọ̀ mọ́ wọn láti jọ́sìn Jèhófà nínú tẹ́ńpìlì tí wọ́n ṣẹ̀ṣẹ̀ kọ́ náà. Ó dájú pé ìran yìí máa fáwọn èèyàn Ọlọ́run lókun gan-an!​—Sek. 8:9.

IṢẸ́ KAN TÓ Ń MI GBOGBO AYÉ JÌGÌJÌGÌ LÓNÌÍ

Ṣé ò ń kópa tó jọjú nínú bí Jèhófà ṣe ń mi àwọn orílẹ̀-èdè lónìí? (Wo ìpínrọ̀ 7-8) *

7. Iṣẹ́ wo là ń ṣe lónìí tó ń mi gbogbo ayé jìgìjìgì? Ṣàlàyé.

7 Kí ni àsọtẹ́lẹ̀ Hágáì túmọ̀ sí fún wa lónìí? Bíi ti ìgbà ayé Hágáì, Jèhófà ń mi gbogbo ayé jìgìjìgì lónìí, àwa náà sì ń lọ́wọ́ sí iṣẹ́ náà. Lọ́dún 1914, Jèhófà fi Jésù Kristi jẹ Ọba Ìjọba Ọlọ́run. (Sm. 2:6) Àmọ́ inú àwọn alákòóso ayé ò dùn sí ohun tó ṣẹlẹ̀ yìí torí pé “àkókò tí a yàn fún àwọn orílẹ̀-èdè” ti pé. Lédè míì, àsìkò tí kò ní sí ọba tó ń ṣàkóso lórí ìtẹ́ Jèhófà ti dópin. (Lúùkù 21:24) Torí náà, pàápàá láti ọdún 1919, àwa èèyàn Jèhófà ti ń kéde pé Ìjọba Ọlọ́run nìkan ṣoṣo ni ojútùú sí gbogbo ìṣòro aráyé. Iṣẹ́ ìwàásù “ìhìn rere Ìjọba yìí” ti mi gbogbo ayé jìgìjìgì.​—Mát. 24:14.

8. Kí ni Sáàmù 2:1-3 sọ pé àwọn orílẹ̀-èdè ṣe nígbà tí wọ́n gbọ́ ọ̀rọ̀ Ìjọba náà?

8 Kí làwọn èèyàn ṣe nígbà tí wọ́n gbọ́ ọ̀rọ̀ nípa Ìjọba Ọlọ́run? Ọ̀pọ̀ ni ò kọbi ara sí i. (Ka Sáàmù 2:1-3.) Inú bí àwọn orílẹ̀-èdè gan-an, wọ́n sì kọ̀ láti gba Ọba tí Jèhófà yàn. Wọn ò gbà pé “ìhìn rere” ni ohun tá à ń wàásù. Kódà, àwọn ìjọba kan ti fòfin de iṣẹ́ ìwàásù wa. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ọ̀pọ̀ àwọn aláṣẹ yẹn sọ pé Ọlọ́run làwọn ń sìn, síbẹ̀ wọn ò fara mọ́ Ìjọba Ọlọ́run. Torí náà bíi ti ìgbà ayé Jésù, àwọn aláṣẹ lónìí ń ta ko Ẹni Àmì Òróró Jèhófà bí wọ́n ṣe ń ṣenúnibíni sáwọn ọmọlẹ́yìn ẹ̀.​—Ìṣe 4:25-28.

9. Àǹfààní wo ni Jèhófà ń fún àwọn tí ò kọbi ara sí iṣẹ́ ìwàásù wa?

9 Àǹfààní wo ni Jèhófà ń fún àwọn tí ò kọbi ara sí iṣẹ́ ìwàásù wa? Sáàmù 2:10-12 sọ pé: “Nítorí náà, ẹ̀yin ọba, ẹ lo ìjìnlẹ̀ òye; ẹ gba ìtọ́sọ́nà, ẹ̀yin onídàájọ́ ayé. Ẹ fi ìbẹ̀rù sin Jèhófà, kí inú yín sì máa dùn nínú ìbẹ̀rù. Ẹ bọlá fún ọmọ náà, àìjẹ́ bẹ́ẹ̀ Ọlọ́run máa bínú, ẹ sì máa ṣègbé kúrò lójú ọ̀nà, nítorí ìbínú Rẹ̀ tètè máa ń ru. Aláyọ̀ ni gbogbo àwọn tó fi Í ṣe ibi ààbò.” Torí pé Jèhófà jẹ́ onínúure, ó fún àwọn alátakò yìí láǹfààní láti yí pa dà, kí wọ́n sì fara mọ́ Ìjọba Ọlọ́run. Àmọ́ àkókò ń lọ torí pé a ti wà ní “àwọn ọjọ́ ìkẹyìn” ètò àwọn nǹkan yìí. (2 Tím. 3:1; Àìsá. 61:2) Ó ti wá di kánjúkánjú báyìí fáwọn èèyàn láti mọ òtítọ́ kí wọ́n sì fara mọ́ Ìjọba Ọlọ́run.

ÌMÌTÌTÌ NÁÀ MÚ KÁWỌN KAN ṢÈPINNU TÓ TỌ́

10. Ìpinnu tó tọ́ wo ni Hágáì 2:7-9 sọ pé ìmìtìtì náà mú káwọn kan ṣe?

10 Ìmìtìtì tí Hágáì sọ tẹ́lẹ̀ náà máa mú káwọn kan ṣèpinnu tó tọ́. Ó sọ pé ìmìtìtì náà máa mú kí ‘àwọn ohun iyebíye, ìyẹn àwọn tó nífẹ̀ẹ́ òtítọ́ nínú gbogbo orílẹ̀-èdè wọlé wá’ sin Jèhófà. * (Ka Hágáì 2:7-9.) Wòlíì Àìsáyà àti Míkà náà sọ tẹ́lẹ̀ pé irú nǹkan bẹ́ẹ̀ máa ṣẹlẹ̀ “ní àwọn ọjọ́ ìkẹyìn.”​—Àìsá. 2:2-4, àlàyé ìsàlẹ̀; Míkà 4:1, 2, àlàyé ìsàlẹ̀.

11. Kí ni arákùnrin kan ṣe nígbà tó kọ́kọ́ gbọ́ ìhìn rere Ìjọba Ọlọ́run?

11 Ẹ jẹ́ ká wo ohun tí Arákùnrin Ken, tó ń ṣiṣẹ́ ní oríléeṣẹ́ wa ṣe nígbà tó kọ́kọ́ gbọ́ ìhìn rere Ìjọba Ọlọ́run. Ó ṣì rántí ohun tó ṣẹlẹ̀ dáadáa nígbà tó kọ́kọ́ gbọ́ ìhìn rere Ìjọba náà ní nǹkan bí ogójì (40) ọdún sẹ́yìn. Ken sọ pé: “Inú mi dùn láti mọ̀ pé a ti wà ní apá ìgbẹ̀yìn ètò àwọn nǹkan yìí. Mo rí i pé kí n tó lè rí ojú rere Ọlọ́run kí n sì ní ìyè àìnípẹ̀kun, mo gbọ́dọ̀ fi àwọn ohun ti ayé sílẹ̀ kí n sì fara mọ́ Ìjọba Ọlọ́run. Torí náà, mo gbàdúrà sí Jèhófà, mo sì ṣàtúnṣe tó yẹ lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀. Mo wá fi àwọn nǹkan tí mò ń lé nínú ayé sílẹ̀, mo sì fara mọ́ Ìjọba Ọlọ́run torí pé kò sí mìmì kan tó lè mì ín.”

12. Báwo ni ògo ṣe kún inú tẹ́ńpìlì tẹ̀mí ti Jèhófà láwọn ọjọ́ ìkẹyìn yìí?

12 Kò sí àní-àní pé Jèhófà ń bù kún àwọn èèyàn rẹ̀. Láwọn ọjọ́ ìkẹyìn yìí, à ń rí bí iye àwọn tó ń sin Jèhófà ṣe ń pọ̀ sí i gan-an. Lọ́dún 1914, àwa tá à ń sin Jèhófà ò ju ẹgbẹ̀rún mélòó kan lọ. Àmọ́ ní báyìí, àwa tá à ń fìtara jọ́sìn Jèhófà ti lé ní mílíọ̀nù mẹ́jọ, ọ̀pọ̀ mílíọ̀nù ló sì ń dara pọ̀ mọ́ wa lọ́dọọdún láti ṣe Ìrántí Ikú Kristi. Nípa bẹ́ẹ̀, “àwọn ohun iyebíye nínú gbogbo orílẹ̀-èdè” ti kún inú apá ti ilẹ̀ ayé nínú tẹ́ńpìlì tẹ̀mí Jèhófà, ìyẹn ètò tí Jèhófà ṣe fún ìjọsìn mímọ́. Yàtọ̀ síyẹn, báwọn èèyàn yìí ṣe ń bọ́ ìwà àtijọ́ sílẹ̀ tí wọ́n sì ń gbé ìwà tuntun wọ̀ ń fògo fún orúkọ Jèhófà.​—Éfé. 4:22-24.

Àwọn èèyàn Ọlọ́run kárí ayé ń fayọ̀ wàásù nípa Ìjọba Ọlọ́run fáwọn míì (Wo ìpínrọ̀ 13)

13. Àwọn àsọtẹ́lẹ̀ wo ló tún ṣẹ báwa èèyàn Jèhófà ṣe túbọ̀ ń pọ̀ sí i? (Wo àwòrán iwájú ìwé.)

13 Bí àwa èèyàn Jèhófà ṣe túbọ̀ ń pọ̀ sí i tún mú kí àsọtẹ́lẹ̀ tó wà nínú Àìsáyà orí ọgọ́ta (60) ṣẹ. Ẹsẹ kejìlélógún (22) nínú orí yẹn sọ pé: “Ẹni tó kéré máa di ẹgbẹ̀rún, ẹni kékeré sì máa di orílẹ̀-èdè alágbára. Èmi fúnra mi, Jèhófà, máa mú kó yára kánkán ní àkókò rẹ̀.” Ọ̀pọ̀ nǹkan rere ló ń ṣẹlẹ̀ torí báwọn èèyàn ṣe ń rọ́ wá sínú ètò Jèhófà. Ìdí sì ni pé ẹ̀bùn ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ ni “àwọn ohun iyebíye” tó ń wá sínú ètò Jèhófà yìí ní, wọ́n sì ń dara pọ̀ nínú wíwàásù “ìhìn rere Ìjọba yìí.” Torí náà bí Àìsáyà ṣe sọ, àwa èèyàn Jèhófà ń rí “wàrà àwọn orílẹ̀-èdè” mu. (Àìsá. 60:5, 16) Àwọn arákùnrin àtàwọn arábìnrin yìí ló mú kó ṣeé ṣe fún wa láti máa wàásù ká sì máa tẹ àwọn ìwé wa. A ti ń wàásù ní orílẹ̀-èdè ọgọ́rùn-ún méjì ó lé ogójì (240), a sì ń tẹ àwọn ìwé wa ní èdè tó lé ní ẹgbẹ̀rún kan (1,000).

ÀKÓKÒ TÓ YẸ KÁ ṢÈPINNU RÈÉ

14. Ìpinnu wo ló yẹ káwọn èèyàn ṣe báyìí?

14 Bí Jèhófà ṣe ń mi gbogbo orílẹ̀-èdè ń mú kó pọn dandan fáwọn èèyàn láti ṣèpinnu. Ṣé wọ́n máa fara mọ́ Ìjọba Ọlọ́run àbí wọ́n máa gbẹ́kẹ̀ lé àwọn ìjọba ayé yìí? Oníkálukú ló máa pinnu ohun tó fẹ́ ṣe. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà máa ń pa gbogbo òfin ìlú tá à ń gbé mọ́, síbẹ̀ a kì í dá sí ọ̀rọ̀ òṣèlú tí wọ́n ń ṣe níbẹ̀. (Róòmù 13:1-7) A mọ̀ pé Ìjọba Ọlọ́run nìkan ni ojútùú sí ìṣòro aráyé. Ìjọba yẹn kì í sì í ṣe apá kan ayé yìí.​—Jòh. 18:36, 37.

15. Àdánwò wo ni ìwé Ìfihàn sọ pé àwọn èèyàn Ọlọ́run máa kojú?

15 Ìwé Ìfihàn jẹ́ ká mọ̀ pé àwa èèyàn Ọlọ́run máa kojú àdánwò ìgbàgbọ́ láwọn ọjọ́ ìkẹyìn yìí. Àdánwò náà máa le gan-an, á sì mú káwọn èèyàn máa ṣenúnibíni sí wa. Àwọn alákòóso ayé á fẹ́ ká máa jọ́sìn àwọn, wọ́n á sì ṣenúnibíni sáwọn tí ò bá ṣe bẹ́ẹ̀. (Ìfi. 13:12, 15) Wọ́n máa “sọ ọ́ di ọ̀ranyàn fún gbogbo èèyàn​—ẹni kékeré àti ẹni ńlá, ọlọ́rọ̀ àti òtòṣì, ẹni tó wà lómìnira àti ẹrú—​pé kí wọ́n sàmì sí ọwọ́ ọ̀tún wọn tàbí iwájú orí wọn.” (Ìfi. 13:16) Láyé àtijọ́, wọ́n máa ń sàmì sára àwọn ẹrú kí wọ́n lè mọ olówó wọn. Bákan náà lónìí, wọ́n máa fẹ́ kí gbogbo èèyàn gba àmì sí ọwọ́ wọn tàbí síwájú orí wọn lọ́nà ìṣàpẹẹrẹ. Ó máa hàn nínú ọ̀rọ̀ àti ìṣe àwọn tó bá gba àmì náà pé ìjọba ayé ni wọ́n ń tì lẹ́yìn.

16. Kí nìdí tó fi ṣe pàtàkì pé ká jẹ́ kí ìgbàgbọ́ tá a ní nínú Jèhófà lágbára lásìkò yìí?

16 Ṣé a máa gba àmì ìṣàpẹẹrẹ yìí ká sì tipa bẹ́ẹ̀ ti àwọn ìjọba ayé yìí lẹ́yìn? Wọ́n máa ṣenúnibíni sí àwọn tí kò bá gba àmì náà, wọ́n sì máa fìyà jẹ wọ́n gan-an. Ìwé Ìfihàn sọ pé: “Ẹnì kankan [ò ní] lè rà tàbí tà àfi ẹni tó bá ní àmì náà.” (Ìfi. 13:17) Àmọ́ ẹ̀rù ò ba àwa èèyàn Ọlọ́run torí a mọ ohun tí Ọlọ́run máa ṣe fáwọn tó bá gba àmì náà bó ṣe wà nínú Ìfihàn 14:9, 10. Dípò kí wọ́n gba àmì náà, ohun tí wọ́n máa kọ sí ọwọ́ wọn ni “Ti Jèhófà.” (Àìsá. 44:5) Ìsinsìnyí gan-an la gbọ́dọ̀ jẹ́ kí ìgbàgbọ́ tá a ní nínú Jèhófà túbọ̀ lágbára. Tá a bá ṣe bẹ́ẹ̀, inú Jèhófà á dùn láti kà wá mọ́ àwọn tó jẹ́ tirẹ̀!

ÌMÌTÌTÌ TÓ MÁA KẸ́YÌN

17. Kí ló yẹ ká fi sọ́kàn nípa sùúrù Jèhófà?

17 Jèhófà ti mú sùúrù gan-an láwọn ọjọ́ ìkẹyìn yìí. Ìdí sì ni pé kò fẹ́ kí ẹnikẹ́ni pa run. (2 Pét. 3:9) Ó ti fún gbogbo èèyàn láǹfààní láti yí pa dà, kí wọ́n sì ṣèpinnu tó tọ́. Àmọ́, sùúrù ẹ̀ máa dópin lọ́jọ́ kan. Ohun tó ṣẹlẹ̀ sí Fáráò nígbà ayé Mósè ló máa ṣẹlẹ̀ sí gbogbo àwọn tí ò bá yí pa dà lónìí. Jèhófà sọ fún Fáráò pé: “Mi ò bá ti na ọwọ́ mi kí n lè fi àjàkálẹ̀ àrùn tó le gan-an kọ lu ìwọ àti àwọn èèyàn rẹ, kí n sì pa ọ́ rẹ́ kúrò ní ayé. Àmọ́ ìdí tí mo fi dá ẹ̀mí rẹ sí ni pé: kí n lè fi agbára mi hàn ọ́, kí a sì lè ròyìn orúkọ mi ní gbogbo ayé.” (Ẹ́kís. 9:15, 16) Gbogbo orílẹ̀-èdè ló máa wá gbà láìjanpata pé Jèhófà nìkan ṣoṣo ni Ọlọ́run tòótọ́. (Ìsík. 38:23) Báwo nìyẹn ṣe máa ṣẹlẹ̀?

18. (a) Ìmìtìtì míì wo ni Hágáì 2:6, 20-22 sọ̀rọ̀ nípa ẹ̀? (b) Báwo la ṣe mọ̀ pé àsọtẹ́lẹ̀ Hágáì ṣì máa ṣẹ lọ́jọ́ iwájú?

18 Ọ̀pọ̀ ọdún lẹ́yìn ìgbà ayé Hágáì, àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù sọ pé àsọtẹ́lẹ̀ tó wà nínú Hágáì 2:6, 20-22 ṣì máa ṣẹ lọ́jọ́ iwájú. (Kà á.) Pọ́ọ̀lù ní: “Ní báyìí, ó ti ṣèlérí pé: ‘Lẹ́ẹ̀kan sí i, kì í ṣe ayé nìkan ni màá mì jìgìjìgì, màá mi ọ̀run pẹ̀lú.’ Ọ̀rọ̀ náà ‘lẹ́ẹ̀kan sí i’ tọ́ka sí i pé a máa mú àwọn ohun tí a mì kúrò, àwọn ohun tí a ti ṣe, kí àwọn ohun tí a ò mì lè dúró.” (Héb. 12:26, 27) Ìmìtìtì yìí yàtọ̀ sí èyí tó wà nínú Hágáì 2:7 ní ti pé ó máa yọrí sí ìparun ayérayé fáwọn tí ò fara mọ́ Ìjọba Jèhófà bíi ti Fáráò.

19. Kí la ò ní mì, báwo la sì ṣe mọ̀?

19 Kí la ò ní mì tàbí mú kúrò? Pọ́ọ̀lù tún sọ pé: “Bí a ṣe rí i pé a máa tẹ́wọ́ gba Ìjọba kan tí kò ṣeé mì, ẹ jẹ́ ká túbọ̀ máa gba inú rere àìlẹ́tọ̀ọ́sí, èyí tí a lè tipasẹ̀ rẹ̀ ṣe iṣẹ́ ìsìn mímọ́ tí Ọlọ́run máa tẹ́wọ́ gbà pẹ̀lú ìbẹ̀rù Ọlọ́run àti ọ̀wọ̀.” (Héb. 12:28) Ìjọba Ọlọ́run nìkan ṣoṣo ló máa ṣẹ́ kù, òun nìkan ṣoṣo ló sì máa dúró títí láé!​—Sm. 110:5, 6; Dán. 2:44.

20. Ìpinnu wo làwọn èèyàn gbọ́dọ̀ ṣe, báwo la sì ṣe lè ràn wọ́n lọ́wọ́?

20 Àkókò ń lọ, a ò sì rọ́jọ́ mú so lókùn! Torí náà àwọn èèyàn gbọ́dọ̀ pinnu. Tí wọ́n bá pinnu pé ayé yìí làwọn máa tì lẹ́yìn, wọ́n máa pa run títí láé. Àmọ́ tí wọ́n bá pinnu pé Jèhófà làwọn máa sìn tí wọ́n sì ṣe àwọn àyípadà tó yẹ, wọ́n máa wà láàyè títí láé. (Héb. 12:25) Iṣẹ́ ìwàásù tá a sì ń ṣe ló máa jẹ́ káwọn èèyàn lè ṣe ìpinnu pàtàkì yìí. Torí náà, ẹ jẹ́ ká ṣe gbogbo ohun tá a lè ṣe ká lè ran àwọn tó nífẹ̀ẹ́ òtítọ́ lọ́wọ́ bó bá ti lè ṣeé ṣe tó láti fara mọ́ Ìjọba Ọlọ́run. Ẹ sì jẹ́ ká máa fi ọ̀rọ̀ Jésù Olúwa wa sọ́kàn pé: “A ó sì wàásù ìhìn rere Ìjọba yìí ní gbogbo ilẹ̀ ayé tí à ń gbé, kó lè jẹ́ ẹ̀rí fún gbogbo orílẹ̀-èdè, nígbà náà ni òpin yóò dé.”​—Mát. 24:14.

ORIN 40 Ti Ta Ni A Jẹ́?

^ ìpínrọ̀ 5 Nínú àpilẹ̀kọ yìí, a máa jíròrò òye tuntun tá a ní nípa Hágáì 2:7. A tún máa kẹ́kọ̀ọ́ nípa bá a ṣe lè máa kópa nínú iṣẹ́ tó ń mi gbogbo orílẹ̀-èdè jìgìjìgì. Àá tún rí bí iṣẹ́ yìí ṣe ń mú káwọn kan ṣèpinnu tó tọ́ táwọn míì sì ń ta kò wá.

^ ìpínrọ̀ 4 A mọ̀ pé iṣẹ́ tí Jèhófà rán Hágáì yọrí sí rere torí wọ́n parí kíkọ́ tẹ́ńpìlì náà lọ́dún 515 Ṣ.S.K.

^ ìpínrọ̀ 10 Òye tuntun lèyí jẹ́. Tẹ́lẹ̀ a sọ pé kì í ṣe mímì tí Jèhófà ń mi àwọn orílẹ̀-èdè ló ń mú káwọn tó nífẹ̀ẹ́ òtítọ́ wá sin Jèhófà. Wo “Ìbéèrè Láti Ọwọ́ Àwọn Òǹkàwé” nínú Ilé Ìṣọ́ May 15, 2006.

^ ìpínrọ̀ 63 ÀWÒRÁN: Hágáì rọ àwọn èèyàn Ọlọ́run pé kí wọ́n má rẹ̀wẹ̀sì lẹ́nu iṣẹ́ tẹ́ńpìlì tí wọ́n ń kọ́. Àwa èèyàn Ọlọ́run lónìí náà ń fìtara kéde ìhìn rere Ìjọba Ọlọ́run fáwọn èèyàn. Tọkọtaya kan ń kéde ìmìtìtì kan tó máa wáyé lọ́jọ́ iwájú fáwọn èèyàn.