Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

ÀPILẸ̀KỌ FÚN ÌKẸ́KỌ̀Ọ́ 40

Kí Ló Ń Fi Hàn Pé Ẹnì Kan Ti Ronú Pìwà Dà Tọkàntọkàn?

Kí Ló Ń Fi Hàn Pé Ẹnì Kan Ti Ronú Pìwà Dà Tọkàntọkàn?

“Kì í ṣe àwọn olódodo ni mo wá pè kí wọ́n ronú pìwà dà, àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀ ni.”​—LÚÙKÙ 5:32.

ORIN 36 À Ń Dáàbò Bo Ọkàn Wa

OHUN TÁ A MÁA JÍRÒRÒ *

1-2. Kí ni ìyàtọ̀ tó wà láàárín Áhábù àti Mánásè, àwọn ìbéèrè wo la sì máa dáhùn?

Ẹ JẸ́ ká sọ̀rọ̀ nípa àwọn ọba méjì nínú Bíbélì. Ọ̀kan ṣàkóso lórí ẹ̀yà mẹ́wàá Ísírẹ́lì, èkejì sì ṣàkóso lórí ẹ̀yà méjì ti Júdà. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé àsìkò ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ làwọn méjèèjì gbé ayé, ọ̀pọ̀ nǹkan ni wọ́n fi jọra. Àwọn ọba méjèèjì ṣọ̀tẹ̀ sí Jèhófà, wọ́n sì tún mú káwọn èèyàn dẹ́ṣẹ̀. Àwọn méjèèjì tún lọ́wọ́ nínú ìbọ̀rìṣà, wọ́n sì pa ọ̀pọ̀ èèyàn. Àmọ́, ohun kan wà tó mú káwọn méjèèjì yàtọ̀ síra. Ọ̀kan ò jáwọ́ nínú ìwà burúkú tó ń hù títí tó fi kú, àmọ́ èkejì ronú pìwà dà, Jèhófà sì dárí jì í. Àwọn ọba méjì wo là ń sọ?

2 Àwọn tá à ń sọ̀rọ̀ nípa wọn ni Áhábù ọba Ísírẹ́lì àti Mánásè ọba Júdà. Àpẹẹrẹ àwọn méjèèjì kọ́ wa ní ọ̀pọ̀ nǹkan nípa ìrònúpìwàdà. (Ìṣe 17:30; Róòmù 3:23) Kí ni ìrònúpìwàdà? Báwo la sì ṣe lè fi hàn pé a ronú pìwà dà látọkàn wá? Ó ṣe pàtàkì ká mọ ìdáhùn sí ìbéèrè yìí torí a fẹ́ kí Jèhófà dárí jì wá tá a bá ṣẹ̀. Ká lè dáhùn àwọn ìbéèrè yìí, a máa jíròrò ohun táwọn ọba méjèèjì ṣe, àá sì rí ohun tá a lè kọ́ látinú àpẹẹrẹ wọn. Lẹ́yìn náà, a máa jíròrò ohun tí Jésù kọ́ wa nípa ìrònúpìwàdà.

OHUN TÁ A RÍ KỌ́ LÁTINÚ ÀPẸẸRẸ ỌBA ÁHÁBÙ

3. Irú ọba wo ni Áhábù?

3 Áhábù ni ọba keje tó jẹ lórí ẹ̀yà mẹ́wàá Ísírẹ́lì. Ó fẹ́ Jésíbẹ́lì, ọmọ ọba Sídónì tó jẹ́ ìlú ọlọ́rọ̀. Ó ṣeé ṣe kí ìgbéyàwó yìí mú kí orílẹ̀-èdè Ísírẹ́lì túbọ̀ lọ́rọ̀. Àmọ́ ṣe ló mú káwọn ọmọ Ísírẹ́lì túbọ̀ jìnnà sí Jèhófà. Òrìṣà Báálì ni Jésíbẹ́lì ń sìn, ó sì mú kí Áhábù náà gbé ìjọsìn burúkú yìí lárugẹ. Lára ohun tí wọ́n máa ń ṣe nínú ìjọsìn Báálì ni pé wọ́n máa ń ṣiṣẹ́ aṣẹ́wó nínú tẹ́ńpìlì, wọ́n sì máa ń fàwọn ọmọ wọn rúbọ. Yàtọ̀ síyẹn, ọ̀pọ̀ àwọn ìránṣẹ́ Jèhófà ni Jésíbẹ́lì pa. (1 Ọba 18:13) Áhábù fúnra ẹ̀ “burú lójú Jèhófà ju . . . gbogbo àwọn tí ó wà ṣáájú rẹ̀.” (1 Ọba 16:30) Gbogbo ohun tí Áhábù àti Jésíbẹ́lì ń ṣe ni Jèhófà rí. Àmọ́ torí pé aláàánú ni Jèhófà, ó rán wòlíì Èlíjà láti lọ kìlọ̀ fáwọn èèyàn rẹ̀ pé kí wọ́n yí pa dà kó tó pẹ́ jù. Àmọ́ Áhábù àti Jésíbẹ́lì ò tẹ́tí sí ìkìlọ̀ náà.

4. Ìdájọ́ wo ni Jèhófà kéde sórí Áhábù, kí ni Áhábù sì ṣe?

4 Nígbà tó yá, Jèhófà pinnu láti fòpin sí ìwà burúkú wọn. Ó rán wòlíì Èlíjà pé kó lọ kéde ìdájọ́ sórí Áhábù àti Jésíbẹ́lì. Wòlíì náà sọ fún wọn pé gbogbo ìdílé wọn ni Jèhófà máa pa run. Ọ̀rọ̀ Èlíjà wọ Áhábù lọ́kàn gan-an, ó sì yani lẹ́nu pé ọba agbéraga yìí “rẹ ara rẹ̀ sílẹ̀.”​—1 Ọba 21:19-29.

Torí pé Ọba Áhábù ò ronú pìwà dà tọkàntọkàn, ó sọ wòlíì Jèhófà sẹ́wọ̀n (Wo ìpínrọ̀ 5-6) *

5-6. Kí ló jẹ́ ká mọ̀ pé Áhábù ò ronú pìwà dà látọkàn wá?

5 Bó tilẹ̀ jẹ́ pé Áhábù rẹ ara ẹ̀ sílẹ̀ nígbà tí Èlíjà kéde ìdájọ́ Jèhófà fún un. Ohun tó ṣe lẹ́yìn náà jẹ́ ká mọ̀ pé kò ronú pìwà dà látọkàn wá. Kò ṣe ohunkóhun láti fòpin sí ìjọsìn Báálì ní ilẹ̀ náà, kò sì gbé ìjọsìn Jèhófà lárugẹ. Yàtọ̀ síyẹn, Áhábù ṣe àwọn nǹkan míì tó fi hàn pé ìrònúpìwàdà ẹ̀ ò tọkàn wá.

6 Nígbà tó yá, Áhábù sọ fún Jèhóṣáfátì ọba Júdà tó jẹ́ olùjọsìn Jèhófà pé káwọn jọ pawọ́ pọ̀ láti bá àwọn ará Síríà jagun. Jèhóṣáfátì wá dábàá pé káwọn kọ́kọ́ béèrè ọ̀rọ̀ lọ́wọ́ wòlíì Jèhófà káwọn tó lọ sójú ogun. Áhábù ò kọ́kọ́ fara mọ́ àbá yẹn, ó sọ pé: “Ọkùnrin kan ṣì wà tí a lè ní kó bá wa wádìí lọ́dọ̀ Jèhófà; ṣùgbọ́n mo kórìíra rẹ̀, nítorí kò sọ àsọtẹ́lẹ̀ rere nípa mi rí, àfi ibi.” Síbẹ̀, wọ́n ṣì wádìí ọ̀rọ̀ lọ́dọ̀ọ́ wòlíì Mikáyà. Bí Áhábù ṣe sọ náà lọ̀rọ̀ rí! Wòlíì yẹn sọ tẹ́lẹ̀ pé nǹkan burúkú máa ṣẹlẹ̀ sí Áhábù. Dípò kí Áhábù ronú pìwà dà, kó sì ní kí Jèhófà dárí ji òun, ṣe ni ọba burúkú yìí pàṣẹ pé kí wọ́n sọ wòlíì náà sẹ́wọ̀n. (1 Ọba 22:7-9, 23, 27) Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ọba náà lágbára láti ju wòlíì Jèhófà sẹ́wọ̀n, kò sóhun tó lè ṣe láti dá àsọtẹ́lẹ̀ Jèhófà dúró pé kó má ṣẹ. Nígbẹ̀yìn-gbẹ́yín, wọ́n pa Áhábù nínú ogun tí wọ́n lọ jà náà.​—1 Ọba 22:34-38.

7. Kí ni Jèhófà sọ nípa Áhábù lẹ́yìn tó kú?

7 Lẹ́yìn tí Áhábù kú, Jèhófà sọ ojú tóun fi wo ọkùnrin yẹn. Nígbà tí Ọba Jèhóṣáfátì pa dà délé láyọ̀, Jèhófà rán wòlíì Jéhù pé kó lọ bá a wí torí pé ó lọ ran Áhábù lọ́wọ́. Wòlíì Jèhófà sọ fún un pé: “Ṣé èèyàn burúkú ló yẹ kí o máa ràn lọ́wọ́, ṣé àwọn tó kórìíra Jèhófà ló sì yẹ kí o nífẹ̀ẹ́?” (2 Kíró. 19:1, 2) Rò ó wò ná: Ká sọ pé Áhábù ronú pìwà dà látọkàn wá ni, ó dájú pé wòlíì yẹn ò ní pè é ní èèyàn burúkú tó kórìíra Jèhófà. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé Áhábù kábàámọ̀ ohun tó ṣe déwọ̀n àyè kan, ó ṣe kedere pé kò ronú pìwà dà tọkàntọkàn.

8. Kí ni àpẹẹrẹ Áhábù kọ́ wa nípa ìrònúpìwàdà?

8 Kí la rí kọ́ látinú ohun tí Áhábù ṣe? Nígbà tí Èlíjà sọ fún Áhábù pé Jèhófà máa fìyà jẹ òun àti ìdílé rẹ̀, Áhábù kọ́kọ́ rẹ ara rẹ̀ sílẹ̀, ìyẹn sì dáa. Àmọ́, àwọn ohun tó ṣe lẹ́yìn náà fi hàn pé kò ronú pìwà dà látọkàn wá. Èyí jẹ́ ká rí i pé ìrònúpìwàdà tó tọkàn wá kọjá kéèyàn kàn sọ pé òun kábàámọ̀ ohun tóun ṣe. Ní báyìí, ẹ jẹ́ ká wo àpẹẹrẹ míì táá jẹ́ ká túbọ̀ lóye ohun tó ń fi hàn pé ẹnì kan ti ronú pìwà dà tọkàntọkàn.

OHUN TÁ A RÍ KỌ́ LÁTINÚ ÀPẸẸRẸ ỌBA MÁNÁSÈ

9. Irú ọba wo ni Mánásè?

9 Nǹkan bí ọgọ́rùn-ún ọdún méjì lẹ́yìn náà, Mánásè di ọba ilẹ̀ Júdà. Ó jọ pé ohun tí Mánásè ṣe tún burú ju ti Áhábù lọ torí Bíbélì sọ pé: “Ohun búburú tó pọ̀ gan-an ló ṣe lójú Jèhófà, ó sì tipa bẹ́ẹ̀ mú un bínú.” (2 Kíró. 33:1-9) Mánásè ṣe àwọn pẹpẹ òrìṣà, ó tún lórí-láyà gbé ère òpó òrìṣà tó gbẹ́ wá sínú tẹ́ńpìlì Jèhófà! Ó ṣeé ṣe kó jẹ́ òrìṣà ìbímọlémọ ni ère náà. Yàtọ̀ síyẹn, ó ń pidán, ó ń woṣẹ́, ó sì ń ṣe oṣó. Bákan náà, ó “ta ẹ̀jẹ̀ àwọn aláìṣẹ̀ sílẹ̀ lọ́pọ̀lọpọ̀.” Ó pa ọ̀pọ̀ èèyàn, ó sì “sun àwọn ọmọ rẹ̀ nínú iná” láti fi wọ́n rúbọ sáwọn òrìṣà.​—2 Ọba 21:6, 7, 10, 11, 16.

10. Báwo ni Jèhófà ṣe bá Mánásè wí, kí sì ni ọba náà ṣe?

10 Bíi ti Áhábù, Mánásè náà ò gba ìkìlọ̀ tí Jèhófà fún un nípasẹ̀ àwọn wòlíì Rẹ̀. Níkẹyìn, “Jèhófà mú kí àwọn olórí ọmọ ogun ọba Ásíríà wá gbéjà [ko Júdà], wọ́n fi ìwọ̀ mú Mánásè, wọ́n fi ṣẹkẹ́ṣẹkẹ̀ bàbà méjì dè é, wọ́n sì mú un lọ sí Bábílónì.” Nígbà tí Mánásè wà lẹ́wọ̀n ní Bábílónì, ó jọ pé ó fara balẹ̀ ronú nípa àwọn nǹkan tó ti ṣe. Ó wá “bẹ̀rẹ̀ sí í rẹ ara rẹ̀ sílẹ̀ gidigidi níwájú Ọlọ́run àwọn baba ńlá rẹ̀.” Àmọ́, kò fi mọ síbẹ̀ o. “Ó bẹ Jèhófà Ọlọ́run rẹ̀ pé kó ṣíjú àánú wo òun.” Kódà, Mánásè “ń gbàdúrà sí Ọlọ́run.” Àbí ẹ ò rí nǹkan, ọba búburú yìí ti ń yí pa dà! Ó bẹ̀rẹ̀ sí í rí Jèhófà bí “Ọlọ́run rẹ̀,” ó sì ń gbàdúrà sí i lemọ́lemọ́.​—2 Kíró. 33:10-13.

Ọba Mánásè ò fara mọ́ ìbọ̀rìṣà torí pé ó ronú pìwà dà tọkàntọkàn (Wo ìpínrọ̀ 11) *

11. Kí ni 2 Kíróníkà 33:15, 16 sọ pé Mánásè ṣe tó fi hàn pé ó ronú pìwà dà tọkàntọkàn?

11 Nígbà tó yá, Jèhófà dáhùn àdúrà Mánásè. Àwọn àdúrà tí Mánásè gbà jẹ́ kí Jèhófà mọ̀ pé ó ti yí pa dà tọkàntọkàn. Torí náà, Jèhófà dárí jì í, ó sì mú kó pa dà di ọba. Mánásè wá ṣe gbogbo ohun tó lè ṣe láti fi hàn pé lóòótọ́ lòun ronú pìwà dà. Ó ṣe ohun tí Áhábù ò ṣe. Ó yíwà ẹ̀ pa dà, kò fara mọ́ ìbọ̀rìṣà, ó sì gbé ìjọsìn mímọ́ lárugẹ. (Ka 2 Kíróníkà 33:15, 16.) Ohun tó ṣe yẹn gba ìgboyà àti ìgbàgbọ́, torí ṣáájú ìgbà yẹn, ọ̀pọ̀ ọdún ni Mánásè fi jẹ́ àpẹẹrẹ burúkú fún ìdílé ẹ̀, àwọn ìjòyè ẹ̀ àti àwọn èèyàn náà lápapọ̀. Ní báyìí tí Mánásè ti dàgbà, ó ṣe gbogbo ohun tó lè ṣe láti jẹ́ àpẹẹrẹ rere fáwọn míì títí kan Jòsáyà ọmọ ọmọ ẹ̀ tó jẹ́ ọba rere.​—2 Ọba 22:1, 2.

12. Kí ni àpẹẹrẹ Mánásè kọ́ wa nípa ìrònúpìwàdà?

12 Kí la rí kọ́ látinú àpẹẹrẹ Mánásè? Ó rẹ ara ẹ̀ sílẹ̀, àmọ́ kò fi mọ síbẹ̀. Ó tún gbàdúrà pé kí Jèhófà ṣàánú òun, ó sì yíwà pa dà. Ó sapá gan-an láti fòpin sí ìbọ̀rìṣà tóun fúnra ẹ̀ ń gbé lárugẹ tẹ́lẹ̀, ó ṣe gbogbo ohun tó lè ṣe láti máa jọ́sìn Jèhófà, ó sì ran àwọn èèyàn náà lọ́wọ́ láti máa ṣe bẹ́ẹ̀. Àpẹẹrẹ Mánásè jẹ́ ká rí i pé àwọn tó ti dẹ́ṣẹ̀ tó burú jáì ṣì lè rí ojúure Jèhófà. A tún rí ẹ̀rí tó ṣe kedere pé ‘ẹni rere ni Jèhófà, ó sì ṣe tán láti dárí jini.’ (Sm. 86:5) Ó dájú pé Jèhófà máa dárí ji àwọn tó bá ronú pìwà dà tọkàntọkàn.

13. Sọ àpèjúwe kan tó jẹ́ ká túbọ̀ lóye ohun tí ìrònúpìwàdà jẹ́.

13 Mánásè kábàámọ̀ ohun tó ṣe, àmọ́ kò fi mọ síbẹ̀. Ó tún gbé àwọn ìgbésẹ̀ míì tó fi hàn pé ó ronú pìwà dà, ìyẹn sì kọ́ wa lẹ́kọ̀ọ́ pàtàkì kan nípa ìrònúpìwàdà. Ẹ jẹ́ ká wo àpèjúwe yìí. Ká sọ pé o fẹ́ ra búrẹ́dì lọ́wọ́ ẹnì kan, àmọ́ dípò kẹ́ni náà fún ẹ ní búrẹ́dì, ìyẹ̀fun ló gbé fún ẹ, ṣé wàá gbà á? Ó dájú pé o ò ní gbà á. Ká wá sọ pé ẹni náà ṣàlàyé fún ẹ pé ìyẹ̀fun wà lára àwọn nǹkan pàtàkì tí wọ́n fi ń ṣe búrẹ́dì, ṣéyẹn máa wá mú kó o gba ìyẹ̀fun náà? Ó dájú pé kò sí àlàyé tó máa ṣe táá mú kó o gba ìyẹ̀fun dípò búrẹ́dì. Lọ́nà kan náà, ohun tí Jèhófà fẹ́ ni pé kí ẹlẹ́ṣẹ̀ kan ronú pìwà dà tọkàntọkàn. Tí ẹlẹ́ṣẹ̀ kan bá kábàámọ̀ ohun tó ṣe, ìyẹn dáa. Ó ṣe tán kéèyàn kábàámọ̀ ohun tó ṣe wà lára àwọn ìgbésẹ̀ tẹ́nì kan máa gbé tó bá ronú pìwà dà. Àmọ́, ìyẹn nìkan ò tó. Kí lohun míì tẹ́ni náà gbọ́dọ̀ ṣe? A máa rí ìdáhùn nínú àkàwé kan tó wọni lọ́kàn tí Jésù ṣe.

BÁ A ṢE LÈ MỌ̀ TẸ́NÌ KAN BÁ RONÚ PÌWÀ DÀ TỌKÀNTỌKÀN

Lẹ́yìn tí orí ọmọ onínàákúnàá náà wálé, ó rìnrìn àjò ọ̀nà jíjìn pa dà sílé (Wo ìpínrọ̀ 14-15) *

14. Nínú àkàwé tí Jésù ṣe, àwọn nǹkan wo ló fi hàn pé ọmọ onínàákúnàá náà ronú pìwà dà?

14 Nínú Lúùkù 15:​11-32, Jésù sọ ìtàn nípa ọmọ onínàákúnàá. Ọ̀dọ́kùnrin náà ṣọ̀tẹ̀ sí bàbá ẹ̀, ó kúrò nílé, ó sì rìnrìn àjò “lọ sí ilẹ̀ tó jìnnà gan-an.” Nígbà tó débẹ̀, ó bẹ̀rẹ̀ sí í náwó ẹ̀ nínàákúnàá, ó sì ń gbé ìgbé ayé oníwà pálapàla. Nígbà tí ọwọ́ ìyà bà á, ó bẹ̀rẹ̀ sí í ronú nípa ìpinnu tí ò dáa tóun ṣe. Ó wá rí i pé ìgbésí ayé òun nítumọ̀ nígbà tóun wà lọ́dọ̀ Bàbá òun. Jésù sọ pé “nígbà tí orí rẹ̀ wálé,” ó pinnu láti pa dà sílé kó lè bẹ bàbá rẹ̀ pé kó dárí ji òun. Ó dáa gan-an bí ọ̀dọ́kùnrin náà ṣe kábàámọ̀ ohun tó ṣe, àmọ́ ṣé ìyẹn nìkan tó? Rárá o, ó tún gbọ́dọ̀ ṣe nǹkan míì!

15. Kí ni ọmọ onínàákúnàá náà ṣe tó fi hàn pé ó ronú pìwà dà?

15 Ọmọ onínàákúnàá yẹn ṣe ohun tó fi hàn pé ó ronú pìwà dà tọkàntọkàn. Lákọ̀ọ́kọ́, ó rìnrìn àjò ọ̀nà jíjìn pa dà sílé. Lẹ́yìn náà, ó sọ fún bàbá rẹ̀ pé: “Mo ti ṣẹ̀ sí ọ̀run, mo sì ti ṣẹ̀ ọ́. Mi ò yẹ lẹ́ni tí o lè pè ní ọmọ rẹ mọ́.” (Lúùkù 15:21) Bí ọ̀dọ́kùnrin náà ṣe jẹ́wọ́ látọkàn wá fi hàn pé ó fẹ́ kí àjọse òun àti Jèhófà pa dà gún régé. Yàtọ̀ síyẹn, ó mọ̀ pé àwọn nǹkan tóun ṣe dun bàbá òun gan-an, ó sì fẹ́ ṣe gbogbo ohun tó bá gbà kí bàbá rẹ̀ lè dárí jì í. Kódà, ó ṣe tán láti di ọ̀kan lára àwọn alágbàṣe bàbá rẹ̀. (Lúùkù 15:19) Ẹ̀kọ́ pàtàkì làwọn alàgbà lè rí kọ́ látinú àkàwé tí Jésù ṣe yìí. Ó lè ràn wọ́n lọ́wọ́ tí wọ́n bá fẹ́ mọ̀ bóyá ẹnì kan tó dẹ́ṣẹ̀ tó burú jáì ti ronú pìwà dà tọkàntọkàn.

16. Kí nìdí tó fi lè ṣòro fáwọn alàgbà láti mọ̀ bóyá ẹnì kan ti ronú pìwà dà tọkàntọkàn?

16 Kì í rọrùn fáwọn alàgbà láti mọ̀ bóyá ẹnì kan tó dẹ́ṣẹ̀ tó burú jáì ti ronú pìwà dà tọkàntọkàn. Kí nìdí? Ìdí ni pé àwọn alàgbà ò lè rí ọkàn. Torí náà, wọ́n máa ní láti wá àwọn ẹ̀rí tó fi hàn pé ẹni náà ti yí pa dà, ó sì ti kórìíra ohun tó ṣe. Nígbà míì, ohun tẹ́nì kan ṣe lè burú débi pé ó lè má dá àwọn alàgbà lójú pé ó ti ronú pìwà dà tọkàntọkàn.

17. (a) Àpẹẹrẹ wo ló jẹ́ ká rí i pé kẹ́nì kan sọ pé òun kábàámọ̀ ẹ̀ṣẹ̀ tóun dá lè má fi hàn pé ó ronú pìwà dà tọkàntọkàn? (b) Kí ni 2 Kọ́ríńtì 7:11 sọ pé ẹni tó ronú pìwà dà tọkàntọkàn máa ṣe?

17 Ẹ jẹ́ ká wo àpẹẹrẹ kan. Ká sọ pé arákùnrin kan tó ti níyàwó nílé yan àlè fún ọ̀pọ̀ ọdún. Dípò kó wá ìrànlọ́wọ́ àwọn alàgbà, ṣe ló ń ṣojú ayé, kò sì jẹ́ kíyàwó ẹ̀, àwọn ọ̀rẹ́ ẹ̀ àtàwọn alàgbà mọ ohun tóun ń ṣe. Nígbà tó yá, àṣírí ẹ̀ tú. Nígbà táwọn alàgbà sọ fún un pé àwọn ní ẹ̀rí tó fi hàn pé ó ń ṣàgbèrè, kò jiyàn, ó sì jọ pé ó kábàámọ̀ ohun tó ṣe. Ṣé ìyẹn wá fi hàn pé ó ti ronú pìwà dà? Rárá o. Àwọn alàgbà tó ń bójú tó ọ̀rọ̀ náà máa ní láti rí àwọn ìgbésẹ̀ míì tó gbé kí wọ́n tó lè gbà pé ó ti ronú pìwà dà. Kì í ṣe pé arákùnrin náà kàn ṣàṣìṣe torí ìpinnu tí ò dáa tó ṣe, kàkà bẹ́ẹ̀ ṣe ló mọ̀ọ́mọ̀ hùwà burúkú yẹn fún ọ̀pọ̀ ọdún. Ohun míì ni pé òun kọ́ ló fúnra ẹ̀ jẹ́wọ́, ṣe ni àṣírí ẹ̀ tú. Torí náà, àwọn alàgbà máa ní láti rí ìyípadà nínú bí oníwà àìtọ́ náà ṣe ń ronú, bó ṣe ń hùwà àti bí nǹkan ṣe ń rí lára ẹ̀. (Ka 2 Kọ́ríńtì 7:11.) Ó lè pẹ́ díẹ̀ kí ẹni náà tó ṣe àwọn àyípadà yìí. Torí náà, ó ṣeé ṣe kí wọ́n yọ ọ́ lẹ́gbẹ́ fún àkókò kan.​—1 Kọ́r. 5:11-13; 6:9, 10.

18. Báwo lẹni tí wọ́n yọ lẹ́gbẹ́ ṣe lè fi hàn pé òun ti ronú pìwà dà tọkàntọkàn, kí nìyẹn sì máa yọrí sí?

18 Kí ẹnì kan tí wọ́n yọ lẹ́gbẹ́ tó lè fi hàn pé òun ronú pìwà dà, ó gbọ́dọ̀ máa wá sípàdé déédéé, kó sì máa tẹ̀ lé ìmọ̀ràn táwọn alàgbà fún un pé kó máa gbàdúrà, kó sì máa kẹ́kọ̀ọ́ déédéé. Á tún sapá láti máa yẹra fún ohun tó lè mú kó pa dà sínú ìwà burúkú náà. Tó bá ṣe gbogbo ohun tó lè ṣe láti ní àjọṣe tó dáa pẹ̀lú Jèhófà, ó dájú pé Jèhófà máa dárí jì í, àwọn alàgbà náà sì máa gbà á pa dà sínú ìjọ. Táwọn alàgbà bá ń bójú tó ọ̀rọ̀ ẹnì kan tó hùwà àìtọ́, wọ́n gbọ́dọ̀ fi sọ́kàn pé ọ̀rọ̀ ẹnì kọ̀ọ̀kan táwọn ń bójú tó yàtọ̀ síra. Torí náà, wọn ò gbọ́dọ̀ fọwọ́ tó le jù mú àwọn tí wọ́n ń gbọ́ ẹjọ́ wọn.

19. Kí lẹnì kan máa ṣe táá fi hàn pé ó ronú pìwà dà tọkàntọkàn? (Ìsíkíẹ́lì 33:14-16)

19 A ti rí i pé kéèyàn ronú pìwà dà tọkàntọkàn kọjá kéèyàn kábàámọ̀ ohun tó ṣe. Ó tún gba pé kẹ́ni náà yí bó ṣe ń ronú àti ìwà ẹ̀ pa dà, kó sì gbé àwọn ìgbésẹ̀ tó yẹ. Bákan náà, ó gbọ́dọ̀ jáwọ́ nínú ìwà burúkú náà, kó sì máa ṣèfẹ́ Jèhófà. (Ka Ìsíkíẹ́lì 33:14-16.) Ohun tó yẹ kó ṣe pàtàkì jù sí ẹlẹ́ṣẹ̀ náà ni bó ṣe máa pa dà ní àjọṣe tó dáa pẹ̀lú Jèhófà.

BÁ A ṢE LÈ RAN ÀWỌN ONÍWÀ ÀÌTỌ́ LỌ́WỌ́ LÁTI RONÚ PÌWÀ DÀ

20-21. Báwo la ṣe lè ṣèrànwọ́ fún ẹni tó dẹ́ṣẹ̀ tó burú jáì?

20 Jésù ṣàlàyé ọ̀kan lára ìdí tó fi wá sáyé. Ó ní: “Kì í ṣe àwọn olódodo ni mo wá pè kí wọ́n ronú pìwà dà, àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀ ni.” (Lúùkù 5:32) Ohun tó yẹ káwa náà ṣe nìyẹn. Ká sọ pé ọ̀rẹ́ wa kan dẹ́ṣẹ̀ tó burú jáì tá a wá mọ̀ nípa ẹ̀, kí ló yẹ ká ṣe?

21 Ṣe la máa dá kún ìṣòro ọ̀rẹ́ wa tá a bá bá a bo ẹ̀ṣẹ̀ náà mọ́lẹ̀. Ohun kan ni pé kò sí bá a ṣe lè bò ó tí àṣírí ò ní pa dà tú torí pé Jèhófà rí ohun tó ṣẹlẹ̀. (Òwe 5:21, 22; 28:13) O lè sọ fún ọ̀rẹ́ ẹ pé àwọn alàgbà máa ràn án lọ́wọ́ tó bá sọ ohun tó ṣẹlẹ̀ fún wọn. Tí ọ̀rẹ́ ẹ bá kọ̀ láti lọ jẹ́wọ́ fáwọn alàgbà, ó yẹ kó o lọ sọ ohun tó ṣẹlẹ̀ fáwọn alàgbà. Ìyẹn á sì fi hàn pé o fẹ́ ran ọ̀rẹ́ ẹ lọ́wọ́ lóòótọ́. Tó ò bá ṣe bẹ́ẹ̀, ọ̀rẹ́ ẹ lè pàdánù ojúure Jèhófà!

22. Kí la máa jíròrò nínú àpilẹ̀kọ tó kàn?

22 Ká sọ pé ẹnì kan ti jingíri sínú ẹ̀ṣẹ̀ débi táwọn alàgbà fi pinnu pé wọ́n gbọ́dọ̀ yọ ọ́ lẹ́gbẹ́ ńkọ́? Ṣé ìyẹn wá túmọ̀ sí pé àwọn alàgbà náà ò láàánú? Nínú àpilẹ̀kọ tó kàn, a máa jíròrò bí Jèhófà ṣe máa ń ṣàánú nígbà tó bá ń bá àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀ wí, àá sì rí bá a ṣe lè fara wé e.

ORIN 103 Ẹ̀bùn Ni Àwọn Olùṣọ́ Àgùntàn

^ ìpínrọ̀ 5 Ìrònúpìwàdà tó wá látọkàn kọjá kéèyàn kàn sọ pé òun kábàámọ̀ ohun tí òun ṣe. Nínú àpilẹ̀kọ yìí, a máa sọ̀rọ̀ nípa àpẹẹrẹ Ọba Áhábù, Ọba Mánásè àti ọmọ onínàákúnàá tó wà nínú àkàwé tí Jésù ṣe. Àpẹẹrẹ wọn máa jẹ́ ká mọ̀ tí ẹnì kan bá ronú pìwà dà tọkàntọkàn. A tún máa jíròrò ohun táwọn alàgbà gbọ́dọ̀ gbé yẹ̀ wò kí wọ́n lè mọ̀ bóyá ẹnì kan tó dẹ́ṣẹ̀ tó burú jáì nínú ìjọ ti ronú pìwà dà látọkàn wá.

^ ìpínrọ̀ 60 ÀWÒRÁN: Ọba Áhábù fìbínú sọ fáwọn ẹ̀ṣọ́ pé kí wọ́n lọ sọ Mikáyà tó jẹ́ wòlíì Jèhófà sẹ́wọ̀n.

^ ìpínrọ̀ 62 ÀWÒRÁN: Ọba Mánásè sọ fáwọn ìránṣẹ́ ẹ̀ pé kí wọ́n fọ́ àwọn ère òrìṣà tó gbé sínú tẹ́ńpìlì.

^ ìpínrọ̀ 64 ÀWÒRÁN: Ó ti rẹ ọmọ onínàákúnàá náà torí ìrìn àjò ọ̀nà jíjìn tó rìn, àmọ́ ara tù ú nígbà tó rí ilé wọn lọ́ọ̀ọ́kán.