Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

1921—Ní Ọgọ́rùn-ún Ọdún Sẹ́yìn

1921—Ní Ọgọ́rùn-ún Ọdún Sẹ́yìn

“KÍ NI iṣẹ́ tó ṣe pàtàkì jù lọ tó yẹ ká dáwọ́ lé lọ́dún yìí?” Ìbéèrè yìí ni Ilé Ìṣọ́ January 1, 1921 (lédè Gẹ̀ẹ́sì) bi àwọn Akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì tí wọ́n ti gbára dì. Ọ̀rọ̀ tó wà nínú Àìsáyà 61:​1, 2 ló dáhùn ìbéèrè náà. Àwọn ẹsẹ Bíbélì yẹn rán wọn létí iṣẹ́ ìwàásù tí wọ́n máa ṣe, ó ní: “Jèhófà ti yàn mí kí n lè kéde ìhìn rere fún àwọn oníwà pẹ̀lẹ́ . . . , láti kéde ọdún ìtẹ́wọ́gbà Jèhófà àti ọjọ́ ẹ̀san Ọlọ́run wa.”

WỌ́N WÀÁSÙ LÁÌBẸ̀RÙ

Àwọn Akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì gbọ́dọ̀ nígboyà kí wọ́n tó lè wàásù. Ìdí ni pé wọ́n gbọ́dọ̀ wàásù ìhìn rere fáwọn oníwà pẹ̀lẹ́, kí wọ́n sì kéde “ọjọ́ ẹ̀san” fáwọn èèyàn burúkú.

Arákùnrin J. H. Hoskin tó gbé ní Kánádà wàásù láìbẹ̀rù bó tilẹ̀ jẹ́ pé ó kojú àtakò. Ní ìbẹ̀rẹ̀ ọdún 1921, ó kojú àlùfáà ṣọ́ọ̀ṣì Mẹ́tọ́díìsì kan. Nígbà tí Arákùnrin Hoskin bẹ̀rẹ̀ ọ̀rọ̀ rẹ̀, ó sọ fún un pé: “Kò yẹ ká máa bá ara wa jà lórí ohun tí Ìwé Mímọ́ sọ, tí èrò wa ò bá tiẹ̀ ṣọ̀kan lórí àwọn nǹkan kan, ìyẹn ò ní ká gbéná wojú ara wa.” Àmọ́ ohun tó ṣẹlẹ̀ kọ́ nìyẹn. Arákùnrin Hoskin sọ pé: “Ìṣẹ́jú díẹ̀ la ṣì fi sọ̀rọ̀ tí àlùfáà náà fìbínú gbá ilẹ̀kùn, ńṣe làyà mi já, àfi bíi pé gíláàsì ilẹ̀kùn náà máa bọ́ fọ́ sílẹ̀.”

Àlùfáà náà pariwo mọ́ mi pé: “Kí ló dé tó ò lọ bá àwọn tí kì í ṣe Kristẹni sọ̀rọ̀? Arákùnrin Hoskin ò sọ nǹkan kan, àmọ́ bó ṣe ń kúrò níbẹ̀, ó ń sọ fún ara ẹ̀ pé, ‘Mo tiẹ̀ rò pé Kristẹni lẹni tí mò ń bá sọ̀rọ̀!’

Nígbà tí àlùfáà náà ń wàásù nínú ṣọ́ọ̀ṣì rẹ̀ lọ́jọ́ kejì, ó sọ ohun tí ò dáa nípa mi. Arákùnrin Hoskin sọ pé: “Ó kìlọ̀ fáwọn ọmọ ìjọ ẹ̀ pé kí wọ́n máa sá fún mi. Ó ní èmi ni ẹlẹ́tàn tó burú jù lọ ní ìlú yẹn àti pé ńṣe ló yẹ kí wọ́n yìnbọn pa mí.” Arákùnrin Hoskin kò jẹ́ kí gbogbo ohun tó ṣẹlẹ̀ yẹn kó ìrẹ̀wẹ̀sì bá òun, ó ń wàásù nìṣó, àwọn èèyàn sì ń tẹ́tí gbọ́ ọ̀rọ̀ rẹ̀. Ó sọ pé: “Mo gbádùn iṣẹ́ ìwàásù tí mo ṣe níbẹ̀ gan-an. Kódà, àwọn kan lára àwọn èèyàn tó wà níbẹ̀ sọ pé, ‘A mọ̀ pé èèyàn Ọlọ́run ni ẹ́!’ wọ́n sì sọ pé kí n jẹ́ káwọn mọ̀ tí mo bá nílò ohunkóhun.”

ÌDÁKẸ́KỌ̀Ọ́ ÀTI ÌKẸ́KỌ̀Ọ́ ÌDÍLÉ

Kí àwọn tó nífẹ̀ẹ́ sí ẹ̀kọ́ òtítọ́ lè tẹ̀ síwájú, àwọn Akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì ṣe ìtòlẹ́sẹẹsẹ kan sínú ìwé ìròyìn The Golden Age. * Wọ́n gbé ọ̀wọ́ àpilẹ̀kọ kan jáde tí wọ́n ń pè ní Juvenile Bible Study. Àpilẹ̀kọ yìí ní àwọn ìbéèrè táwọn òbí lè jíròrò pẹ̀lú àwọn ọmọ wọn. Ètò Ọlọ́run dábàá pé kí àwọn òbí “bi àwọn ọmọ wọn ní ìbéèrè, kí wọ́n sì jẹ́ kí wọ́n mọ ibi tí wọ́n ti máa rí ìdáhùn náà nínú Bíbélì.” Ọ̀kan lára àwọn ìbéèrè tó ń jẹ́ kí wọ́n mọ̀ nípa Bíbélì ni: “Ìwé mélòó ló wà nínú Bíbélì?” Ìbéèrè míì ni: “Ṣé gbogbo àwọn Kristẹni ló máa kojú inúnibíni?” Irú àwọn ìbéèrè yìí máa ń jẹ́ káwọn ọ̀dọ́ nígboyà láti wàásù.

A tún gbé ọ̀wọ́ àpilẹ̀kọ kan jáde tá a pè ní Advanced Studies in the Divine Plan of the Ages. Àpilẹ̀kọ yìí ní àwọn ìbéèrè tó máa jẹ́ kí àwọn Akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì tó jẹ́ àgbàlagbà lè ronú jinlẹ̀. Inú ìdìpọ̀ àkọ́kọ́ ìwé Studies in the Scriptures la sì ti mú àwọn ìbéèrè náà. Ọ̀pọ̀ àwọn tó ka àwọn àpilẹ̀kọ yìí ló jàǹfààní látinú wọn. Àmọ́ ìwé ìròyìn The Golden Age ti December 21, 1921 kéde pé wọn ò ní gbé àwọn àpilẹ̀kọ méjèèjì yẹn jáde mọ́. Àmọ́, kí nìdí tí wọ́n fi ṣe ìpinnu yẹn?

A ṢE ÌWÉ TUNTUN KAN!

Ìwé Duru Ọlọrun

Káàdì tó ń sọ ibi tí wọ́n máa kà

Káàdì tó ní àwọn ìbéèrè

Àwọn arákùnrin tó ń ṣàbójútó ètò Ọlọ́run rí i pé ipele-ipele ló yẹ káwọn tó ṣẹ̀ṣẹ̀ ń kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì máa kẹ́kọ̀ọ́ òtítọ́. Torí náà, ní November ọdún 1921, a ṣe ìwé kan tó ń jẹ́ Duru Ọlọrun. Àwọn tó gba ìwé Duru Ọlọrun bẹ̀rẹ̀ ètò ìdálẹ́kọ̀ọ́ kan tí wọ́n ń fi ìwé náà ṣe fúnra wọn. Ìwé yìí ran àwọn tó kà á lọ́wọ́ láti mọ̀ pé “Ohun tí Ọlọ́run fẹ́ ni pé káwọn èèyàn jogún ìyè àìnípẹ̀kun.” Báwo ni wọ́n ṣe ń fi ìwé náà dáni lẹ́kọ̀ọ́?

Tí ẹnì kan bá gba ìwé Duru Ọlọrun, wọ́n máa ń fi káàdì kékeré kan sínú rẹ̀ kó lè mọ ibi tó máa kà. Tó bá di ọ̀sẹ̀ tó tẹ̀ lé e wọ́n máa fi káàdì míì ránṣẹ́ sí i. Àwọn ìbéèrè tó dá lórí ibi tó kà àti ibi tó máa kà lọ́sẹ̀ tó tẹ̀ lé e ló wà nínú káàdì náà.

Ọ̀sọ̀ọ̀sẹ̀ ni ìjọ tó wà nítòsí á máa fi káàdì tuntun ránṣẹ́ sí akẹ́kọ̀ọ́ náà. Ọ̀sẹ̀ méjìlá ni wọ́n á sì fi ṣe bẹ́ẹ̀. Lọ́pọ̀ ìgbà, àwọn àgbàlagbà tí ò lè lọ wàásù láti ilé délé tàbí àwọn tí ò fi bẹ́ẹ̀ lókun nínú ìjọ ló máa ń fi káàdì náà ránṣẹ́. Bí àpẹẹrẹ, Arábìnrin Anna K. Gardnrer tó ń gbé ní Millvale lórílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà rántí ohun tó ṣẹlẹ̀, ó ní: “Mo ní ẹ̀gbọ́n kan tó ń jẹ́ Thayle tí kò lè rìn, àmọ́ nígbà tí wọ́n tẹ ìwé Duru Ọlọrun jáde, ìyẹn mú kọ́wọ́ ẹ̀ dí gan-an torí pé ọ̀sọ̀ọ̀sẹ̀ ló ń fi káàdì ránṣẹ́ sáwọn èèyàn.” Tí ètò ìdálẹ́kọ̀ọ́ náà bá ti parí, ẹnì kan á lọ sọ́dọ̀ akẹ́kọ̀ọ́ náà láti ràn án lọ́wọ́ kó lè túbọ̀ tẹ̀ síwájú nínú ẹ̀kọ́ Bíbélì rẹ̀.

Arábìnrin Thayle Gardner wà lórí kẹ̀kẹ́ arọ

IṢẸ́ ṢÌ PỌ̀ TÁ A MÁA ṢE

Ní ìparí ọdún yẹn, Arákùnrin J. F. Rutherford fi lẹ́tà ránṣẹ́ sí gbogbo ìjọ. Ó sọ pé: “Ìwàásù tá a ṣe lọ́dún yìí pọ̀ ju gbogbo èyí tá a ti ṣe láwọn ọdún tó ṣáájú, òun ló sì gbéṣẹ́ jù.” Ó fi kún un pé: “Iṣẹ́ ṣì pọ̀ tá a máa ṣe. Torí náà, ẹ gba àwọn míì níyànjú láti dara pọ̀ mọ́ iṣẹ́ pàtàkì yìí.” Ó sì dájú pé àwọn Akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì ṣe ohun tó sọ yẹn. Lọ́dún tó tẹ̀ lé e, ó hàn gbangba pé àwọn Akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì fi ìgboyà wàásù Ìjọba Ọlọ́run lọ́nà àrà ọ̀tọ̀.

^ ìpínrọ̀ 9 Ní 1937 a bẹ̀rẹ̀ sí í pe ìwé ìròyìn The Golden Age Consolation, nígbà tó sì di 1946 a bẹ̀rẹ̀ sí í pè é ní Awake!